2 Awọn Ọba 9:1-37; 10:1-36

Lesson 317 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitoriti a kò mu idajọṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pāpa lati huwa ibi” (Oniwasu 8:11).
Cross References

I A Fi Ami Ororo Yan Jehu

1. Eliṣa rán ọmọkunrin kan ninu awọn woli lati fi ororo yan Jehu ni ọba lori Israẹli, 2 Awọn Ọba 9:1-3; 1 Awọn Ọba 19:15-17

2. A jé̩ iṣẹ gẹgẹ bi Eliṣa ti palaṣẹ, 2 Awọn Ọba 9:4-10

3. Awọn Balogun mọ Jehu ni ọba, wọn si ran an lọwọ lati mú aṣẹỌlọrun ṣẹ, 2 Awọn Ọba 9:11-14

II Iṣubu Ile Ahabu

1. Jehu bẹrẹ si i ṣiṣẹ fun Oluwa kikankikan lai ṣiyemeji, 2 Awọn Ọba 9:15-20

2. Joramu ati Ahasiah ni awọn ti o kọkọṣubu, 2 Awọn Ọba 9:21-29; 8:25-27

3. A bi Jesebẹli ṣubu nitori iwa buburu ati è̩ṣẹ rè̩, 2 Awọn Ọba 9:30-37; 1 Awọn Ọba 21:23

4. A pa aadọrin ọmọkunrin Ahabu ni Samaria, 2 Awọn Ọba 10:1-10

5. A ṣe iparun idile Ahabu patapata, lai kù si ibi kan, 2 Awọn Ọba 10:11-17; 1 Awọn Ọba 21:21, 22

III Iparun Ẹsin-Baali

1. Jehu pe gbogbo awọn olusin Baali sinu ile oriṣa Baali, 2 Awọn Ọba 10:18-22

2. A ṣe iwadii lati ri i pe ko si ẹlomiran laaarin wọn bi kòṣe kiki awọn olusin Baali nikan, 2 Awọn Ọba 10:23

3. Olukuluku olusin Baali ni a pa, a si wó ile Baali palẹ, 2 Awọn Ọba 10:24-28

IV Erè Igbọran

1. Ọlọrun ṣeleri pe titi de iran ẹkẹrin awọn ọmọ Jehu ni yoo maa joko lori itẹ Israẹli nitori pe Jehu ṣe iṣẹ naa gẹgẹ bi Ọlọrun ti lana rè̩ silẹ, 2 Awọn Ọba 10:29-36

Notes
ALAYE

“Emi ha ni inu-didun rara pe ki enia buburu ki o kú? ni Oluwa ỌLỌRUN wi: kòṣepe ki o yipada kuro ninu ọna rè̩, ki o si yè?” (Esekiẹli 18:23). A ti kede, àánú Oluwa si ẹlẹṣẹ kaakiri gbogbo agbaye, ṣugbọn gbogbo awọn ti o ba kọàánu yii ti o ba si ṣọtẹ si aṣẹỌlọrun ni a o mu wa si idajọ fun è̩ṣẹ wọn. Aanu ti a kẹgan, ni aanú ti a kọ. “S̩ugbọn kò si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rè̩ lati ṣiṣẹ buburu niwaju OLUWA, ẹniti Jesebeli aya rè̩ nti” (1 Awọn Ọba 21:25). Ọlọrun mimọ ati Olododo kò le gboju fo è̩ṣẹ ibọriṣa ati iṣọtẹ Ahabu ati awọn ara ile rè̩, nitori naa Ọlọrun dojukọ ile Ahabu lati pa a run patapata. A paṣẹ fun Elijah lati fi òroro yan Hasaeli ni ọba lori Siria, ki o si yan Jehu ni ọba lori Israẹli ati Eliṣa gẹgẹ bi woli: “Yio si ṣe, ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Hasaeli ni Jehu yio pa, ati ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Jehu ni Eliṣa yio pa” (1 Awọn Ọba 19:17).

Kò Ronupiwada Tọkantọkan

A fun ile Ahabu ni anfaani lati ronupiwada. Aafo ogun ọdun tabi ju bẹẹ lọ ni o wa laaarin igba ti a fi aṣẹ yii lé Elijah lọwọ ati akoko imuṣẹ idajọ naa. Ahabu rẹ ara rè̩ silẹ o si n ṣe jẹjẹ fun igba diẹ lẹyin ti o sọ Naboti ni okuta pa, ṣugbọn irẹlẹ naa kò jinlẹ tó ninu ọkàn rè̩ lati mu idajọ kuro – ó kàn sún ọjọ idajọ siwaju sii ni (1 Awọn Ọba 21:27-29). I ba ṣe pe Ahabu ronupiwada tọkàntọkàn, lati inu odo ọkàn rè̩ wá, tó bẹẹ ti o mu ki o yipada patapata kuro ninu ọna buburu rẹ, laisi aniani, ohun ti o wà ni akọsilẹ nipa ile Ahabu loni i ba yatọ. Tori tọrun ni awọn ọmọ Ahabu lọkunrin ati lobinrin fi tẹle apẹẹrẹ igbesi-ayé itiju ti Ahabu baba wọn gbé lai fi ọkan pe meji.

Ipa ti awọn obi ni lori awọn ọmọ wọn kò kere. Aṣẹ ati ifẹỌlọrun ni pe ki awọn obi ki o tọ awọn ọmọ wọn “inu ẹkọ ati ikilọ Oluwa.” Apẹẹrẹ rere awọn obi ati igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun wọn yoo mu ki awọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin tọọna iwa-bi-Ọlọrun (Owe 22:6).

Bi a bá taku sinu è̩ṣẹ, aanu Ọlọrun ki yoo wa lori wa lọ bẹẹ titi. Ọjọẹsan fun è̩ṣẹ idile Ahabu dé lojiji gẹgẹ bi yoo ti ri fun olukuluku ẹlẹṣẹ ti o ba kọ lati ronupiwada iwa buburu rè̩.

Ipè Jehu ati Iṣẹ ti A fi Ran an

Jehu ni a fi “Ida Oluwa” ti a fi gbẹsan ẹṣè̩ idile Ahabu lé lọwọ. Eliṣa rán ọkan ninu awọn ọmọ woli lati fi ororo yan Jehu ni ọba ati lati sọ fún un wi pe oun ni ẹni ti yoo jé̩ ohun-elo ti a o lò lati pa awọn eniyan buburu run. Ọdọmọkunrin naa ri Jehu ni Ramoti-Gileadi bi o ti pejọ pẹlu awọn olori-ogun. O pe Jehu kuro lọdọ awọn ọmọ-ogun, o jiṣẹ naa fun un, o si ta ororo si i lori. Lẹyin ti ọdọmọkunrin naa ti jiṣẹ ti a rán an tán, o salọ, o si fi Jehu silẹ ninu ironu nipa iṣẹ nla ti o wà fún un lati ṣe.

Boya Jehu ti mọ tẹlẹ pe eyi ni iṣẹ ti a o pe oun si, a kò le sọ. Lai fi eyi pe, lati ọdọỌlọrun ni iṣẹ naa ti wa, yoo si ni lati ni iranlọwọ ati agbara Ọlọrun lati lèṣe iṣẹ naa ni aṣeyọri.

Boya iwuwo iṣẹ naa ba Jehu lẹru to bẹẹ ti o fi n ṣe aṣaro bi oun yoo ti ṣe mu iṣẹ naa ṣe; ṣugbọn lai pẹ, Ọlọrun dahun ibeere-ki-beere, O si ṣi ọna lati mu aṣẹ Rè̩ṣẹ. Jehu ti ni lati gbadura bi o ti tọ ati bi o ti yẹ ki o ṣe. Ogunlọgọ eniyan ni o si ti jé̩ ipe Ọlọrun lẹyin ti Jehu – ki i ṣe lati pa ẹmi run – bi kòṣe lati waasu Ihinrere ti o n fun ni ni igbala. Ọlọrun kò i ti i dẹkun lati maa pe ọkunrin tabi obinrin ti yoo yọọda ara wọn lati jé̩ọmọ-ogun Rè̩ ati lati ṣiṣẹ ti Oun yoo fi lé wọn lọwọ. Awọn ọmọ-ogun ti o n ṣe aṣeyọri tootọ ni awọn wọnni ti o n duro tiiri ninu adura.

S̩iṣe Jehu Lọba

Awọn olori-ogun kò lọra ni gbigba Jehu ni ọba. Olukuluku wọn yara mu aṣọ rẹ sabẹ Jehu lori awọn àtè̩gùn ti o wa ni Ramoti-Gileadi, wọn si fun ipe lati ṣe e lọba. Jehu pe awọn olori-ogun sọdọ rè̩ lati fi inu hàn wọn nipa ohun ti o fẹṣe, ati lati ṣeto ọna ti wọn yoo gbàṣe iṣẹ naa. Wọn pinnu pé, wọn kò gbọdọ fi ayè silẹ fun ẹnikẹni lati sa lọ kuro ni ilu lati royin ni Jesreeli ni ibi ti Joramu, ọmọ Ahabu, ti i ṣe ọba Israẹli gbe wà ti o n wo ọgbé̩ ti o gbà lati ọwọ awọn ara Siria.

Jehu fẹ yọ si Joramu lojiji, nitori naa o kóẹgbẹ ogun ẹlẹṣin jọ lẹsẹkẹsẹ. Oluṣọ kan ti o duro lori odi ni Jesreeli ri awọn ẹgbẹ Jehu ti o n bọ wá, ṣugbọn wọn jinna pupọ si i to bẹẹ ti kò fi mọ wọn. A ran ẹlẹṣin kan lati lọ pade ẹgbẹ naa lati wadi boya ẹni mimọ ni wọn ati eredi rè̩ ti wọn fi n bọ wá. Jehu paṣẹ fun iranṣẹ naa lati yi pada sẹyin oun. Oluṣọ naa royin ohun gbogbo ti o ri fun ọba, o si tún rán ẹlẹṣin miiran jade. Ohun kan naa ni o tun ṣẹlẹ si ẹlẹṣin keji, ṣugbọn lakoko yii, oluṣọ naa ti mọ daju pe Jehu ni i ṣe olori ẹgbẹ yii nitori ti “o nwọ bọ kikankikan.” (Ogunlọgọ Jehu ni o wa lode oni laye ti kò si kẹkẹẹlẹṣin mọ, ṣugbọn ọkọ iwàkuwà pẹlu ere sisa kikankikan kò gbéẹnikẹni niyi ri, bẹẹ ni ki yoo si gbéẹnikẹni niyi lae).

Igbẹyin Eniyan Buburu

Joramu mú ki a pese kẹkẹ ti yoo fi lọ pade Jehu silẹ. Ahasiah, ọba Juda ati ibatan idile Ahabu jade lọ pẹlu Joramu. Olukuluku ninu kẹkẹ rè̩ pade Jehu ni ilẹ biiri nì ti i ṣe ti Naboti. Joramu beere pe, “Jehu, Alafia kọ?” Jehu dahun pe, “Alafia kini, niwọnbi iwà-agbère Jesebeli iya rẹ ati iṣe ajé̩ rè̩ ti pọ tobḝ?” (2 Awọn Ọba 9:22). Joramu mọ péọjọ ibẹwo oun dé, o yi pada, lati sá; ṣugbọn Oluwa dari ọfa ti Jehu ta, o si ba Joramu laaarin apa rè̩ mejeeji, ọfa naa si gba ọkàn rè̩ jade. Jehu paṣẹ pe ki a gbé oku rè̩ si aarin oko naa, nibi ti o kú si, ki a lè gbẹsan è̩jẹ Naboti alaiṣẹ ati è̩jẹ awọn ọmọ rè̩.

Ahasiah ri i pe Joramu kú, oun paapaa gbiyanju lati salọ; ṣugbọn Jehu ati awọn eniyan rè̩ lepa rè̩ wọn si pa a ninu kẹkẹ rè̩. O kú ni Megiddo, ṣugbọn awọn iranṣẹ rè̩ gbé e lọ si Jerusalẹmu wọn si sin in nibẹ. I ba ṣe pe Ahasiah ti duro ni Jerusalẹmu lati maa sin Ọlọrun awọn baba rè̩ nibẹ, opin buburu yii ki ba ti de ba a. Otitọ yii kò i ti i yi pada: ẹgbé̩ buburu a maa ba iwà rere, ati awọn eniyan jé̩. Bi a ba pinnu lati wà fun Ọlọrun, a ni lati ya ọkàn wa ati ifẹ wa kuro ninu ifé̩ ayé ati è̩ṣẹ.

Jesebẹli ni ẹni ti o kàn wayii lati fi ara gba ẹsan lati ọwọ Oluwa Ọlọrun Ọrun. O ti kẹgàn Ofin Ọlọrun, o si ṣọtẹ si Ọlọrun titi dopin ẹmi rè̩. A ba lero pe yoo wa ibi isadi fun ara rè̩ nigba ti Jehu dé Jesreeli; ṣugbọn kaka bẹẹ, o lọ le tiroo, o si ta ori rè̩ lati fi igboya rè̩ hàn fun Jehu ati lati ki i ni iki è̩gàn. Lai si aniani, o fé̩ daya fo Jehu ki o ba le bọ kuro ninu wahala yii gẹgẹ bi o ti maa n fi ọgbọn kó ara rè̩ yọ ni igba pupọ tẹlẹ ri. Eṣu gan an ni o gbé Jesebẹli wọ. Ọlọrun fun un ni akoko lati ronupiwada, ṣugbọn kò ronupiwada. Awọn ohun ti Ọlọrun korira: “oju igberaga, ète eke ati ọwọ ti nta è̩jẹ alaiṣẹ silẹ, aiya ti nhumọ buburu, ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si iwa-ika, ẹlẹri eke ti nsọ eke jade, ati ẹniti ndá ija silẹ larin awọn arakunrin” (Owe 6:17-19), gbogbo wọn ni o pe si ọwọ Jesebẹli. Bi è̩ṣẹ kan ba tayọ ninu è̩ṣẹ ti Jesebẹli n dá, oun ni è̩ṣẹ tita ẹjè̩ alaiṣẹ silẹ; nitori pe a ri ọrọẹsùn wọnyi kà nipa rè̩. “Iwọ o si kọlù ile Ahabu oluwa rẹ, ki emi o le gbẹsan ẹjẹ awọn woli iranṣẹ mi, ati è̩jẹ gbogbo awọn iranṣẹ Oluwa lọwọ Jesebeli” (2 Awọn Ọba 9:7). Igberaga pẹlu ti ba ayé Jesebẹli jé̩. “Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu” (Owe 16:18). Jesebẹli ṣubu. Awọn iwẹfa meji tabi mẹta ti i lulẹ lati oju ferese, awọn ẹṣin ẹlẹṣin Jehu si tè̩é̩ mọlẹ.

Erè Jehu

Jehu jiṣẹ ti Ọlọrun rán an pé perepere. Itara Jehu kò dinku titi o fi pa gbogbo awọn ẹni buburu ile Ahabu run. Jehu tilẹ tun ṣe ju eyi ti a fi ran an nitori nipa ẹtan o pa isin Baali run -- è̩ṣẹ ti o leke ni Israẹli. Baali ni o fa iṣubu ile Ahabu, ṣugbọn Jehu pinnu pe oun ki yoo jé̩ ki o ṣe okunfa iṣubu ile ti oun.

Ọlọrun san ẹsan gbogbo iṣẹ yii fun Jehu. O ṣeleri fun un pe iran rè̩ kẹrin yoo joko lori itẹ Israẹli. “S̩ugbọn Jehu kòṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rè̩ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israẹli: nitoriti kò yà kuro ninu è̩ṣẹ Jeroboamu, ti o mu Israẹli ṣè̩” (2 Awọn Ọba 10:31). Jehu jé̩ onitara eniyan, ṣugbọn ọrọ ti a sọ nipa rè̩ yii fi hàn pé itara rè̩ dinku nigba ti ỌrọỌlọrun lodi si ilana rè̩ ati ilepa rè̩. O le gun ẹṣin kikankikan lati mú aṣẹỌlọrun ti o lere fún un ṣẹ, ṣugbọn o kuna lati ṣe gbogbo ifẹỌlọrun. O pa diẹ ninu isin ibọriṣa Jeroboamu mọ, eyi ni o si fa iṣubu ile Jehu. Itara Jehu fun Ọlọrun duro lori awọn nnkan ti ara, o kuna lati ṣe ojuṣe rè̩ nipa ti è̩mi, nitori naa èrè ohun ti ayé yii ni o gbà.

Gbogbo IfẹỌlọrun

Ogunlọgọ Onigbagbọ alafẹnujé̩ ni o fara mọ ibikibi ninu ỌrọỌlọrun ti o bá ifẹ wọn mu, ṣugbọn wọn a maa ṣe awawi lati yẹ apakan ỌrọỌlọrun ti o n tọka si ikuna ati è̩ṣẹ wọn silẹ. Tifẹtifẹ ni wọn fi n kọè̩ṣẹ wọnni ti wọn korira silẹ, ṣugbọn è̩ṣẹ kékèké wọnni ti o dùn mọ wọn lẹnu ni wọn n jẹ lẹnu bi ohun adidun. Iṣẹ-isin kò lé jé̩ itẹwọgba lọdọOluwa bi ko ṣe pe a ba pa gbogbo aṣẹ Rè̩ mọ. Lati le ṣe aṣeyọri tootọ, ẹni ti o n wa Ọlọrun ni lati gba gbogbo ỌrọỌlọrun gbọ, ki o si jade fún Un patapata, bi bẹẹ kọ oun yoo kuna erèọrun ni ikẹyin.

Nigba ti a ba n ṣiṣẹ ninu ọgba ajara Oluwa, ewu wà ninu ki a maa fi itara ṣe awọn nnkan wọnni ti o ba dùn mọ wa, tabi ti o té̩ ifẹọkàn wa lọrun, ṣugbọn ki a maa yẹ awọn iṣẹ wọnni ti ko larinrin tabi ti kò jọ ni loju silẹ. Ẹnikẹni ti o ba fi ara rè̩ rubọ ni tootọ, ti o si jé̩ ohun-elo lọwọ Oluwa, yoo maa wulo siwaju ati siwaju ninu gbogbo iṣẹ Ihinrere. Ogunlọgọ eniyan ni o ni ailera lọna kan tabi lọna miiran ti wọn si n fi eyi kẹwọ lati má jade fun iṣẹ Oluwa; ṣugbọn Oluwa ni agbara lati mú awọn ohun idiwọ wọnyi kuro ki O si sọ awọn eniyan wọnyi di ohun-elo tootọ ni ọwọ Rè̩. Ọlọrun le sọ Onigbagbọ onitalẹnti kan di onitalẹnti pupọ. Gẹgẹ bi itanṣan oorùn ti n tan si ara awojiji didan to bẹẹ ti oriṣiriṣi awọ pataki mẹjẹẹjọ n fi ara hàn, bakan naa ni itanṣan ImọlẹỌlọrun ninu igbesi-ayé Onigbagbọ yoo fi ọpọ oore-ọfé̩Ọlọrun hàn fun ayé ti è̩ṣẹ ti fọ loju yii.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ipò wo ni Ọlọrun pe Jehu si?

  2. 2 Iṣẹ wo ni a fi rán Jehu? Bawo ni a si ṣe sọ iṣẹ naa di mimọ fun un?

  3. 3 Awọn wo ni o fara mọ Jehu lé̩sè̩kẹsè̩?

  4. 4 Awọn wo ni o kọṣubu si ọwọ “ida igbẹsan OLUWA?.”

  5. 5 Ki ni ṣẹlẹ si Jesebẹli ninu iparun ile Ahabu?

  6. 6 Darukọ wolii ti o sọ asọtẹlẹ igbẹyin Jesebẹli ati ibi ti a ti sọọ ninu ỌrọỌlọrun?

  7. 7 Ki ni Jehu ṣe si awọn olusin Baali?

  8. 8 Ki ni ere ti Jehu gbà fun iṣẹ ti o ṣe fun Ọlọrun yii?

  9. 9 Ki ni ṣe ti Jehu kò fi gba èrè ti è̩mi? Èrè wo ni o ṣe pataki ju lọ?