Lesson 318 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “A ṣe ilana ẹsẹ enia lati ọwọ OLUWA wá: o si ṣe inu didùn si ọna rè̩” (Orin Dafidi 37:23).Cross References
I Fifi Igbesi-ayé Elijah ati ti Eliṣa Wé Ara Wọn
1. Awọn wolii mejeeji lù omi Jọrdani lati là aarin rè̩ kọja, 2 Awọn Ọba 2:8, 14
2. Elijah ati Eliṣa jé̩ ohun-elo lati fi omi fun awọn ti o wà ninu ipọnju, 1 Awọn Ọba 18:41-45; 2 Awọn Ọba 3:9-20
3. Awọn opó meji ri iranwọ ati itunu gbà ni akoko aini wọn, nipasẹ iṣẹ-iranṣẹ Elijah ati Eliṣa, 1 Awọn Ọba 17:10-16; 2 Awọn Ọba 4:1-7
4. Elijah ati Eliṣa gbadura si Ọlọrun, O si ti ipasẹ wọn sọ okúọmọ di alaaye, 1 Awọn Ọba 17:17-24; 2 Awọn Ọba 4:18-35
5. Elijah ati Eliṣa pe iji-igbè̩san wá sori awọn alaigbagbọ, 2 Awọn Ọba 1:9-12; 2:23-25
6. Igbesi-aye Elijah pin nigba ti a fi aaja gbe e lọ si Ọrun, 2 Awọn Ọba 2:11, 12
7. Eliṣa kú sinu aisan, sibẹ agbara ajinde Ọlọrun lọna iyanu wà lara rè̩, 2 Awọn Ọba 13:14-21
Notes
ALAYEAwọn Wolii Ọlọrun
Awọn miiran ti o jé̩òpè ninu ỌrọỌlọrun a saba maa fi Elijah pe Eliṣa. Orukọ wọn jọ ara wọn, awọn mejeeji si jumọ jé̩ alabaṣiṣẹpọ ninu ọgba ajara Ọlọrun fun igba diẹ. Awọn ọkunrin mejeeji yii ni o ṣe iṣẹ-iyanu, okiki wọn si kàn ni Israẹli. S̩ugbọn sibẹ naa, Elijah ati Eliṣa yatọ si ara wọn ninu iwà ati iṣe.
Elijah, ara Tiṣbi
Ẹkọ pupọ wà ninu fifi igbesi-ayé Elijah wé ti Eliṣa arọpò rè̩. Elijah fara hàn ninu itan igbesi-ayé awọn Ọmọ Israẹli ti o dojuru lai jẹ pe ẹnikẹni kede bibọ rè̩. Iṣẹ kin-in-ni ti o rán si wọn bá wọn lojiji gẹgẹ bi wiwá rè̩ paapaa ti dé bá wọn lojiji. Iṣẹ ti a fi rán an jé̩ eyi ti o sọ ti igba wahala ti n bọ wá ba Israẹli. Ọrọ kin-in-ni ti Elijah sọ ti o si fi i hàn fún Israẹli gẹgẹ bi Wolii Ọlọrun ni pé, “Bi OLUWA Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, ki yio si iri tabi òjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọrọ mi.”
A kò mọ iru ọkàn itara ti Ahabu ọba fi gba iṣẹ yii ni àkọkọ ti o gbọọ, ṣugbọn ọdáòjo fihàn gbangba pé Wolii Ọlọrun ni Elijah i ṣe lotitọ ati lododo. Gbogbo ilẹ Israẹli ni a wá kiri lati mú Wolii alasọtẹlẹàjálu yii, ṣugbọn a kò ri i. Ohun-elo Ọlọrun ni oun i ṣe, Ọlọrun si daabo bo o.
Iṣẹ-iranṣẹ Elijah dojuja kọè̩ṣẹ ati iwa buburu ti o gba ọkàn Israẹli kan, awọn ayanfẹỌlọrun. Elijah duro bi ọwọn otitọ ninu ỌrọỌlọrun ati ojiṣẹ ibinu gbigbona Ọlọrun lori è̩ṣẹ. A saba maa n sọ pe bi Wolii Ọlọrun ba ti dide lati kede iṣẹỌlọrun fun awọn eniyan, idajọỌlọrun wà lẹyin ilẹkun. Igbesi-ayé Elijah fihàn bé̩è̩.
Ni igba pupọ, Elijah jé̩ẹni kan ti o n dágbé, ti o si n dárìn, nitori pé igba kọọkan ni o n fi ara hàn lati igba-de-igba lati ibi kàn ti o fara sin lati ké mọè̩ṣẹ. O dabi ẹni pé kò fi ara rora pẹlu awọn ọmọ Israẹli ninu igbesi-ayé wọn ojoojumọ, igba kọọkan ni o sì n fara hàn. Iṣẹ ti a fi rán Elijah ni lati rán awọn eniyan leti ni ọna ti o le péẹlẹṣẹ ki yoo lọ lai jiya; ati pé nigba pupọ ni idajọ gbigbona Ọlọrun i maa wa sori ẹlẹṣẹ lati kilọ fun awọn ẹlomiran.
Awọn wolii Baali ri agbára Ọlọrun Elijah; wọn sọẹmi wọn nù nitori ti wọn gboju-gboya lati dojukọỌlọrun Ọrun. Elijah bá Ahabu ati Jesebẹli wi nitori iwa buburu wọn, o si kede idajọỌlọrun lé wọn lori. Bi o tilẹ jé̩ pé Elijah ṣe ọpọlọpọ oore ati aanu fun awọn eniyan Israẹli, ipinnu pataki ti o leke lọkàn rè̩ ni lati pa ibọriṣa run.
Lati lè tako ibọriṣa ti o gbilẹ kan ni Israẹli, o ṣe danindanin péẹni ti yoo jé̩ ohun-elo lọwọỌlọrun fun iṣẹ ribiribi yii ni lati jé̩ẹni ti o ni itara fun iṣẹỌlọrun ati igbona ọkàn fun ododo Rè̩. Elijah káju ipe yii ni iwà ati iṣe. Sibẹsibẹ a mọ eyi pẹlu pe “Enia oniru iwa bi awa ni Elijah” (Jakọbu 5:17). Elijah fẹran Ọlọrun gidigidi, nitori ti o fẹran Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkàn rè̩, o ni lati jé̩ pé o fẹran awọn eniyan Israẹli pẹlu. Bi ẹni kan bá fẹran Ọlọrun, yoo ni ifẹ fun ọkàn awọn eniyan pẹlu, nitori ti ifẹỌlọrun kún fún aajo ọkàn eniyan.
Boya awọn ẹlomiran le maa rò pé Elijah kò le ni ifẹ awọn eniyan Israẹli tọkàntọkàn, sibẹ ki o maa pe ibinu Ọlọrun le wọn lori nigbakuugba. Idahun si ọran yii ni pe gbigba è̩ṣẹ laaye kọ ni a n pe ni ifẹ. “Ifẹ ni Ọlọrun” sibẹỌlọrun ni ọta ti o ga jù lọ si gbogbo aiṣododo.
Oore ti o ga ju lọ ti a kò lè fi ohun aye yii diwọn ni imukuro è̩ṣẹ lati ọwọỌlọrun. Ibọriṣa ti o gbilẹ kan ni ẹṣẹ ti o fa ibinu Ọlọrun wá sori orilẹ-ede yii. Ohun kan ṣoṣo ni o le mu ibi yii kuro, oun ni pipa isin ibọriṣa run patapata. Ifẹọkàn Elijah ni pé ki a mú isin Ọlọrun otitọ pada si Israẹli, o si ni itara ati igbona ọkàn fun iṣẹ yii. Ojo kò gbọdọ rọ ni Israẹli titi igba ti ọkàn awọn eniyan yoo yi pada sọdọỌlọrun. O dabi ohun ti o ya ni lẹnu péọwọ kan naa ti Oluwa n lo lati gbogun ti è̩ṣẹ ni ọna ti o le jù lọ kún fún ifẹ ati inu-rere fun ẹni ti a n gbogun ti nitori è̩ṣẹ yii. Eredi lilu yii a maa rúọmọ-eniyan loju ni igba pupọ a si le maa fi oju si ẹni ti o ni itara pupọ fun isin Ọlọrun lara bi a-yọ-gbogbo-ilu-lẹnu gẹgẹ bi wọn ti ṣe fun Elijah.
Elijah kòṣalai mọ gbogbo iyọṣutisi ati atako ti o dojukọọ lara, nitori pe igba iṣudẹdẹ wà ninu eyi ti ọkàn rè̩ poruuru lẹyin ti o ti ni iṣẹgun nla lori awọn wolii Baali. Sibẹ ki i ṣe ẹni ti o ṣe rere fun igbà diẹ ni a o gbala bi kòṣe ẹni ti o ba foriti i titi déòpin. Elijah bori gbogbo iṣoro rè̩, o si di aṣẹgun; awa paapaa le ṣe bẹẹ.
Wo bi Ọlọrun ti fi ibukun ati ọla fun ọkunrin ti o niye lori pupọ loju Rè̩ yii! Igbẹyin rè̩ jẹọkan ti o logo ti o si kun fun iṣẹgun ju lọ ti a ni akọsilẹ wọn ninu ỌrọỌlọrun. A fi kẹké̩ iná gbe e lọ soke lati lọ pade Oluwa rè̩, awọn ogun ọrun si yi i ka! “Kẹké̩ iná ati ẹṣin iná si làārin awọn ... Elijah si ba ājà gòke re ọrun.” Ta ni kò ni fé̩ lọ lọna bayii? Israẹli padanu akikanju nla kan nigba ti Oluwa rè̩ mu un lọ si Ile.
Eliṣa, ỌmọS̩afati
Oluwa yan Eliṣa lati jé̩ arọpo Elijah. A kò fifun ẹnikẹni lati dá nikan ṣe gbogbo iṣẹỌlọrun. Olukuluku wa ni a pè lati mú ipa kan ṣe ninu iṣẹỌlọrun bi a ba fé̩. Elijah sa ipa rè̩ gidigidi lati mu isin Ọlọrun pada si Israẹli, iṣẹ-iranṣẹ rè̩ si mú awọn eniyan lọkàn girigiri. O ti jà gidigidi fun Ọlọrun, ṣugbọn nisisiyi akoko tó lati fi òróró yan arọpo rè̩.
Ninu iṣẹ Oluwa, olukuluku ni o ni iṣẹ ti a pèé si. Elijah ti ṣe ipa ti rè̩ ninu iṣẹỌlọrun, iṣẹ ti rè̩ si ti dopin. Eliṣa rọpo Elijah lati maa ba iṣẹỌlọrun lọ ni ibi ti Elijah ṣe e de, ṣugbọn ni ọna ti o yatọ. “Njẹ onirru è̩bun li o wà, ṣugbọn Ẹmi kanna ni. Onirru iṣẹ-iranṣẹ li ó si wà, Oluwa kanna si ni. Onirru iṣẹ li o si wà, ṣugbọn Ọlọrun kanna ni ẹniti nṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn” (1 Kọrinti 12:4-6).
Awọn miiran n ṣe ariyanjiyan nigba miiran wi pe, ta ni ẹni ti o pọ jù ninu Elijah ati Eliṣa? Iru ibeere bayii kò múọgbọn ati ẹkọ lọwọ, eyi ni Paulu kilọ fun ni lati yẹra fun. (Wo 2 Timoteu 2:23; 1 Timoteu 1:4). Awọn mejeeji ni ẹni nla lọwọỌlọrun, olukuluku ninu ipe ti rè̩ ati lọna ti rè̩. Eniyan mimọỌlọrun ni lati lakaka lati ṣe afarawe wọn ninu ifọkansin ati iwà mimọ, ki i ṣe lati pọ jùẹnikeji rè̩ tabi lati jẹ gaba lori awọn arakunrin rè̩.
A mọ Eliṣa jù lọ bi ẹni kan ti o fẹ ni “iṣé̩po meji” Ẹmi Ọlọrun ju ohunkohun lọ. Eliṣa beere ohun nla lọwọỌlọrun, Ọlọrun si ṣe ohun nla fún un. Iṣẹ-iranṣẹ Eliṣa fara mọ akoko Ẹmi Mimọ ati Arọkuro Ojo yii, ju igbà ayé awọn woli. A le fi ibẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ rè̩ wé ti awọn wọnni ti wọn ṣafẹri ti wọn si ri agbára gbà lati òkè wá, nipa ifiwọni Ẹmi Mimọ.
Eliṣa gbé igbesi-ayé iṣẹgun patapata, a kò si ni akọsilẹ igbà kan ti ọkan rè̩ poruuru gẹgẹ bi o ti ri fun Elijah. O ṣe iṣẹ-iyanu gẹgẹ bi awọn ti Elijah ṣe, o tilẹṣe iṣẹ-iyanu pupọ ju woli ki woli lọ, afi Mose.
Agbára Ajinde
Ikú Eliṣa kò larinrin gẹgẹ bi eyi ti o fi oju rè̩ ri nigba ti a gba Elijah lọ soke Ọrun. Aisan ni o fi opin si igbesi-ayé rè̩; bi o tilẹ jé̩ pé ikú rè̩ kò ni okiki, sibẹ ohun ti a kò gbọ ri ṣẹlẹ lẹyin ikú rè̩. Nitori ibẹru awọn onisunmọmi, a gbéọkunrin kan ti a ti fé̩ sin sinu iboji kan jù sinu iboji Eliṣa. Nigba ti okúọkunrin naa fi ara kan egungun Eliṣa, ọkunrin naa sọji, o si di alaaye. Eyi ṣẹlẹ nipasẹ agbára ajinde ti o wa ninu eniyan Ọlọrun yii.
Jesu sọ fun Marta pe, “Emi ni ajinde, ati iye: ẹniti o ba gbà mi gbọ, bi o tilẹ kú, yio yè” (Johannu 11:25). A tun rii ka pe, “S̩ugbọn bi Ẹmi ẹniti o ji Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmi rè̩ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di āye pẹlu” (Romu 8:11).
Questions
AWỌN IBEERE- Sọ awọn iṣẹ-iyanu ti Elijah ati Eliṣa ṣe ti o bá ara wọn mu.
- Ni ọna wo ni iwà ati iṣe Elijah fi fara jọ ti Eliṣa?
- Bawo ni a ṣe mọ pe ẹni kan kò le nikan ṣe gbogbo iṣẹỌlọrun?
- Ọna wo ni ikú Eliṣa fi yatọ si ọna ti Elijah gbà fi ayé silẹ?
- Ẹkọ wo ni a ri kọ nipa okú ti o di alaaye nipa fifi ara kan egungun Eliṣa?
- Ọna wo ni iṣẹ-iranṣẹ Eliṣa fi fara jọ akoko Ẹmi Mimọ?