Lesson 319 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ranti ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ, nigbati ọjọ ibi kò ti ide, ati ti ọdun kò ti isunmọ etile, nigbati iwọ o wipe, emi kò ni inudidùn ninu wọn” (Oniwasu 12:1).Cross References
I A DéỌdọmọkunrin Kan Lade
1. Ataliah pa gbogbo irúọmọọba Juda run o si jọba lori ilẹ naa, 2 Awọn Ọba 11:1, 3
2. Jehoṣeba fi Joaṣi pamọ ninu Tẹmpili fún ọdún mẹfa, 2 Awọn Ọba 11:2
3. Jehoiada pe awọn olori si ikọkọ ninu Tẹmpili, o fi ọmọọba hàn wọn, o fi ihamọra ogun wọ wọn, o si fi awọn oluṣọ yi Tẹmpili ka, 2 Awọn Ọba 11:4-11
4. Wọn fi òróro yan ọm ni ọba, wọn si dé e ni ade, awọn eniyan naa patẹwọ, wọn si yọ, 2 Awọn Ọba 11:12
5. Ataliah gbọ ariwo, o wá sinu Tẹmpili, a mú un a si pa á, 2 Awọn Ọba 11:13-16
6. Jehoiada mú ki awọn eniyan bá Oluwa dá majẹmu; a wo ile Baali lulè̩, a si mú Joaṣi wá sinu ile ọba, 2 Awọn Ọba 11:17-21
II Titún Ile Oluwa S̩e
1. Joaṣi bẹrẹ si jọba lati ọmọọdun meje o si ṣe rere ni gbogbo ọjọ Jehoiada, 2 Kronika 24:1-3
2. Joaṣi pinnu lati tún Ile Oluwa ṣe o si sọ fun awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi lati gba owó lọwọ awọn eniyan, 2 Kronika 24:4, 5
3. Awọn eniyan lọra lati ṣe eyi, a si gbé apoti kan si ẹnu-ọna Tẹmpili, 2 Kronika 24:6-9
4. Wọn dá owó lọpọlọpọ a si tún Tẹmpili ṣe, 2 Kronika 24:10-14
III Ifasẹyin Ọba
1. Jehoiada kú a si sin in laaarin awọn ọba, 2 Kronika 24:15, 16
2. Awọn ijoye ti wọn jé̩ olufẹ ayé mú Joaṣi pada bọ sinu ibọriṣa, 2 Kronika 24:17, 18
3. A rán awọn woli lati kilọ fun awọn eniyan, 2 Kronika 24:19, 20
4. Nipa aṣẹọba, a sọ Sakariah lokuta pa, 2 Kronika 24:21, 22
5. Oluwa jé̩ ki awọn ogun Siria mu idajọ wá sori Joaṣi ati awọn ijoye naa, 2 Kronika 24:23, 24
6. A pa Joaṣi lati ọwọ awọn iranṣẹ rè̩, 2 Kronika 24:25-27
Notes
ALAYEIpadasẹyin Israẹli kuro ninu Igbagbọ tàn kalẹ dé ilẹ Juda. Idi kan pataki ti o fa iṣubu kuro ninu Igbagbọ yii ni pé awọn ọba wọn gbé awọn obinrin orilẹ-ède abọriṣa ni iyawo. Ofin Ọlọrun, nipasẹ Mose, kò fi ayè silẹ fún iru igbeyawo bẹẹ nitori ti Ọlọrun mọ pé awọn obinrin abọriṣa wọnyi yoo gbé oriṣa wọn kalẹ, wọn yoo si dá igbó-oriṣa silẹ ni ilẹ ti Ọlọrun fi fun awọn eniyan Rè̩. O dabi ẹni pe awọn obinrin buburu wọnyi ni ọna ti wọn n gbà fi è̩tàn múọkọ wọn lati maa bá wọn bọriṣa. Lati igbà ti Efa ti tan Adamu lati jẹ eso ti Ọlọrun kọ fun wọn lati jẹ ni awọn obinrin alaiwa-bi-Ọlọrun ti di ohun-elo ikà lati tan awọn ọkọ wọn lati ṣe ohun ti o lodi si ofin Ọlọrun. Pẹlupẹlu, iwà iwọra lati di alagbara ti wọ awọn ẹlomiran lẹwu lọna ti o ya ni lẹnu. O dabi ẹni pe kò si ohun ti ẹlomiran kò le ṣe lati tẹ ifẹkufẹọkàn wọn lọrun bi o ti wù ki o buru tó. Nihin ni a sọ fun ni nipa iyá-àgbà kan ti o pa awọn ọmọ-ọmọ rè̩ ki o ba le ni anfaani lati jọba.
Orukọ iya agba buburu yii ni Ataliah. Ọmọ Ahabu ati iyawo rẹ Jesebẹli abọriṣa ni obinrin yii i ṣe. Ataliah fé̩ Jehoramu, ọba Juda. Ipilẹ igbesi-ayé Ataliah kò dara; oun paapaa tẹle iwà ikà ati iwàọdaran awọn obi rè̩. Inu bi i nitori ti Jehu n pa idile Ahabu run ni Israẹli, oun naa pẹlu si pinnu lati pa idile Dafidi run ni Juda. O fẹrẹ mu ipinnu rè̩ṣẹ. S̩ugbọn Oluwa ti ṣeleri fun Dafidi pé a ki yoo fé̩ọkan kù ninu ọmọ rè̩ ti yoo joko lori ité̩, Ọlọrun kò si jẹ ki irú Dafidi parun patapata.
Nigba ti Ataliah bẹrẹ si pa awọn ọmọ idile ọba, Jehoṣeba iyawo Jehoiada alufaa ati ẹgbọn-binrin ọmọ Ahasiah, ji ọmọọba ti o wà ni ọmọ-ọwọ, ó si gbé e pamọ sinu Tẹmpili, lọna bayii, a kò pa Joaṣi ọmọ-ọwọ naa pẹlu awọn iyoku. O rọrun lati fi ọmọ-ọwọ yii pamọ sinu Tẹmpili nitori pe Tẹmpili wà ni ikawọ awọn alufaa, paapaa ju lọ obinrin buburu ajinnilẹsẹ yii kò ni saba maa wá si Tẹmpili nigba gbogbo.
Eto Jehoiada
Jehoiada, Olori Alufaa, jé̩ oloootọ eniyan o si ni ifẹ lati mu awọn eniyan naa pada lati maa sin Ọlọrun otitọ. Isin ibọriṣa ti dé ilẹ Juda lati ijọba Israẹli, wọn si ti kọ tẹmpili kan fun Baali. Wọn tilẹ ti kó awọn ohun-elo ti a yà si mimọ ninu Ile Ọlọrun lọ si tẹmpili Baalimu.
Bọya ọdun mẹfa ti Jehoiada gbéọmọ kekere naa pamọ sinu tẹmpili ni o fi n ṣe eto lati gba ijọba naa pada fun ẹni ti o tọ si. Lai si aniani, oun kò ni ṣalai bá awọn balogun ati awọn agbaagba sọrọ lati mọ awọn ti o jé̩ oloootọ si Ọlọrun. Amí kò si laaarin wọn ti o le mú iroyin lọ ba Ataliah, obinrin buburu nì.
Lakotán, Jehoiada mú awọn balogun ati awọn agbaagba wá sinu Ile Oluwa. O fun wọn ni ohun ijà, o si fi wọn ṣe oluṣọ ati ẹlẹri. Nigba naa ni o mu Joaṣi ọmọdekunrin naa jade, o si fihàn wọn. Wo bi ayọ ati iyalẹnu yoo ti pọ tó fún awọn oloootọ wọnyi lati ri ọmọọba! Wọn yọ! Awa yọ pẹlu nigba ti ỌmọỌlọrun – Jesu Kristi, Ẹni ti yoo jẹỌba awọn ọba – fi ara hàn ni ookan àya wa.
Ọba Kekere Jojolo Dade
Awọn balogun fara mọ aṣẹ Jehoiada, Olori Alufaa. Ọlọrun wà pẹlu wọn, eto wọn si yọri si rere. Bi awa bá wà ni iha otitọ, ti Oluwa si wà pẹlu wa, iṣẹgun daju. Lai si aniani, ọjọ ajọ kan ninu eyi ti awọn eniyan a maa pejọ si Jerusalẹmu, ni a déọba lade. A mú Joaṣi wá sinu Tẹmpili lẹba ọwọn kan ti awọn ọba maa n joko si nigba ti a ba fẹ dé wọn ni ade.
Adé, ẹri ati òroro jé̩ ohun mẹta pataki ti a ni lati lo nigba ti a ba fẹ fi ọba joyè. Adé ni ibori rè̩. Ẹri ni Ofin Ọlọrun ti a mu un bura pe oun yoo pamọ, òroro ti a ta si i lori ni lati yàá sọtọ fun iṣẹỌlọrun ti a pe e si. Eyi ni akọsilẹ kin-in-ni ti a gbé ri i ka pe a fi ọmọ kekere jọba.
Majẹmu
Jehoiada dá majẹmu laaarin Oluwa ati Ọba ati awọn eniyan pé wọn yoo jé̩ ti Oluwa. Isọji nla ni eyi! Lẹsẹkẹsẹ awọn eniyan lọ si ile oriṣa Baali wọn si bi i wó, wọn wó pẹpẹ oriṣa, wọn si fọ awọn ère tuutuu, wọn si pa alufaa Baali.
Nigba ti Jesu bá wọ inu ọkàn kan, a o ti eṣu ati itẹ rè̩ jade. Bi Oluwa ba n jọba ninu ọkàn kan, ki yoo si ibọriṣa nibẹ. Nigba ti awọn ọmọ Israẹli ba pa ofin Ọlọrun mọ, alaafia yoo wà fun wọn. Ni akoko yii, wọn yin Oluwa logo, wọn si ṣapé̩ fun ayọ nitori ti ilẹ naa bọ lọwọ Ataliah abọriṣa ati onroro.
Titún Ile Oluwa S̩e
Bi ọba ti n dagba o ri i pe Ile Oluwa n fé̩ atunṣe. Bọya o ti mọ awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi lara lati maa ri ogiri ti o sán tabi ti o ya to bẹẹ ti kò buru loju wọn mọ. O ṣe e ṣe lati maa ba iṣẹ wa ojoojumọ lọ lai bikita to bẹẹ ti a kò ni le ri awọn nnkan wọnni ti o n fẹ abojuto ninu ọkàn wa ati fun Oluwa. Wọn kò naani ohun ti ọba sọ ni akọkọṣugbọn nigba ti o pe wọn bi leere, wọn bẹrẹ iṣẹṣiṣe. Nigba pupọ ni Oluwa ni lati mú awọn eniyan Rè̩ wá sabẹ ibawi lọna kan tabi lọna miiran ki O si fi oju wọn raná nitori ijafara wọn. Bibeli sọ fun ni pe Onigbagbọ “ki iṣe ọlẹ ni ibi iṣẹ” ṣugbọn “a mā ni igbona ọkàn; ẹ mā sin Oluwa” (Romu 12:11).
Jehoiada mu apoti kan o si dá ideri rè̩ lu, o si fi sabẹ pẹpẹ. Titi di oni ni a maa n wi pe apoti Jehoiada. O dabi ẹni pé eto gbigbe apoti iṣura tabi ọrẹ si itosi ilẹkun ninu Ile Ọlọrun kò kasẹ nilẹ lati igba nì titi di isisiyi.
Nigba ti Jesu wà ni ayé a gbé apoti iṣura si ẹba ẹnu ọna Tẹmpili. Lọjọ kan, O n ṣe akiyesi bi awọn ọlọrọ ti n fi ẹbun wọn sinu apoti iṣura; bi O ti duro nibẹ, O ri obinrin opó kan ti n fi owò idẹ wé̩wé̩ meji sinu rè̩. O pe awọn ọmọ-ẹyin Rè̩, O si wi pe, “Lõtọ ni mo wi fun nyin, talakà opó yi fi si i jù gbogbo wọn lọ: nitori gbogbo awọn wọnyi fi sinu è̩bun Ọlọrun lati ọpọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aini rè̩ o sọ gbogbo ohun ini rè̩ ti o ni sinu rè̩” (Luku 21:3, 4).
Lati igbà ti a ti dá Ijọ Igbagbọ Apọsteli (Apostolic Faith Church) silẹ, iru eto kan na ni a n lo nipa gbigbe apoti kekere kan si ẹba ẹnu ọna àbáwọ Ile Ọlọrun fun idamẹwaa ati ọrẹ. A ki i ṣe ikojọ owó ni awujọ. A ki i si gbé awo kiri lati gba owo-igbá. A ki i ṣi Bibeli silẹ lori pẹpẹ pe ki awọn eniyan maa kọja lati fi ọrẹ wọn si i, lati ṣe aṣehàn orẹ ti wọn mu wá. Jesu wi pe, “Nigbati iwọ ba nṣe itọrẹānu rẹ, máṣe jẹ ki ọwọ osi rẹ ki o mọ ohun ti ọwọọtun rẹ nṣe; ki itọrẹānu rẹ ki o le wà ni ikọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ikọkọ, on tikararè̩ yio san a fun ọ ni gbangba” (Matteu 6:3, 4).
Nigba ti Jehoiada gbé apoti iṣura si ẹba ẹnu ọna Tẹmpili, ifé̩ awọn eniyan naa ru soke lati mu ọrẹ wa, owó si wọle lọpọlọpọ lati tun Ile Oluwa ṣe. “Ẹniti o ba fọnrugbin kiun, kiun ni yio ká, ẹniti o ba si fọnrugbin pipọ, pipọ ni yio ká. Ki olukuluku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rè̩; ki iṣe àfèkunṣe, tabi ti alaigbọdọ máṣe nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ” (2 Kọrinti 9:6, 7). Awọn ọkọle naa ṣe oloootọ tó bẹẹ ti a kò fi ba wọn ṣiro owó ti a fi lé wọn lọwọ. A kò si gbọ iyọnu kankan lati ọdọ awọn oṣiṣẹ.
Ifasẹyin Ọba
Ninu ẹkọ yii a ri ọwọ itọni ati iranlọwọẹni iwabi-Ọlọrun. Niwọn igbà ti Jehoiada wa laaye, o mú ki ilu ati ijọỌlọrun ki o sin Ọlọrun alaaye. O pa ibọriṣa run ni Juda; akoso ti o ni lori ọba mú ki ọba rin ni ọna rere. Jehoiada n ṣe akoso ilu ni orukọọba, nigba ti o kú, a sin okú rè̩ si iboji awọn ọba. Eyi fihàn bi o ti ṣe pataki tó lọwọ awọn eniyan.
Lẹyin ikú Jehoiada, o hàn gbangba pé eniyan alailagbara ni Joaṣi ọba i ṣe. Eṣu ati awọn ọmọ-ogun rè̩ yọ wọle ṣugbọn ọba kò ni igboya ati ẹmi iduro-ṣinṣin. O dabi ẹni pe oun kò mọ bi a ti ṣe n kọ ohun ti kò tọ. Awọn ọmọ-alade fi ète ipọnni wọn tàn án jẹ. “Ète ipọnni ati ọkàn meji ni nwọn fi nsọ” (Orin Dafidi 12:2). Nitori naa a ri i pe nigba ti a múọwọ itọni Jehoiada ẹgbọn rè̩ kuro, Joaṣi kò ni ọkàn ti o duro ṣinṣin ninu ara rè̩, lai pẹ jọjọ o ṣubu sọwọ awọn ẹlẹtan. “Ẹniti o ba foriti i titi fi de opin, on na li a o gbalà” (Marku 13:13). Dafidi Onipsalmu sọ bayii pé: “Gbà-ni OLUWA; nitori awọn ẹni iwabi-ọlọrun dasè̩; nitori awọn olõtọ dasè̩ kuro ninu awọn ọmọ-enia” (Orin Dafidi 12:1).
Ikilọ lati Ọdọ Woli
Oluwa kò fi Joaṣi ati awọn eniyan rè̩ silẹ lati ṣubu sọwọọta lai fun wọn ni ọpọlọpọ ikilọ. “Sibẹ o rán awọn woli si wọn, lati mu wọn pada tọ OLUWA wá; nwọn si jẹri gbè wọn; ṣugbọn nwọn kò fi eti si i.” Lopin gbogbo rè̩, gẹgẹ bi ikilọ ikẹyin, Ẹmi Ọlọrun si ba le Sakariah ọmọ Jehoiada alufaa, o si wi fun wọn pe, “Ẽṣe ti ẹnyin fi ru ofin OLUWA, ẹnyin ki yio ri ire? nitoriti ẹnyin ti kọ OLUWA silẹ, on pẹlu si ti kọ nyin.” Nipa aṣẹọba, nwọn sọ wolii yii ni okuta pa. Awọn ọba le gbagbé, ṣugbọn Oluwa ki i gbagbe! Baba ati iya wolii yii ni o fi ọba yii pamọ ti kò jé̩ ki apaniyan nì pa á nigba ti o wà ni ọmọ-ọwọ. O ti gbagbe oore ti wọn ṣe fun un, ṣugbọn Oluwa kò gbagbe. Ọdun kan lẹyin eyi ni ogun awọn ara Siria wá dó ti Juda ati Jerusalẹmu. Wọn pa gbogbo awọn ọmọ-ọba, wọn si rán gbogbo ikogun wọn si Damasku, wọn fi ọba silẹ ninu àrun nla lai si oluranlọwọ. Awọn iranṣẹ rè̩ si pa a. Bayi ni opin buburu dé báẹni ti o kọỌlọrun otitọ ati isin Jehofa silẹ.
Questions
AWỌN IBEERE- Ọna wo ni a fi pa ọmọ-ọba mọ kuro lọwọ awọn apaniyan. Ta ni o pa a mọ?
- Ta ni n jọba lori ilẹ naa nigba naa?
- Ọmọọdun meloo ni Joaṣi nigba ti a fi jọba?
- Eto wo ni Jehoiada ṣe lati fi Joaṣi jọba?
- Ohun mẹta wo ni o ṣe pataki nigba ti a ba fẹ fi ọba jẹ?
- Ki ni Joaṣi ṣe akiyesi nipa Tẹmpili?
- Ki ni o sọ fun awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi lati ṣe?
- Ki ni ṣẹlẹ si ọba lẹyin ikú Jehoiada?
- Njẹ igbẹyin ọjọ ayé Joaṣi dara?