Jona 1:1-17; 2:1-10; 3:1-10; 4:1-11

Lesson 320 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi ọrọ ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran si gbàẹsan ti o tọ; awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bè̩rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ” (Heberu 2:2, 3).
Cross References

I Tarṣiṣi Dipo Ninefe

1. Oluwa paṣẹ fun Jona lati waasu fun awọn ara Ninefe, Jona 1:1, 2

2. Jona dojukọọna Tarṣiṣi o n gbiyanju lati sa kuro niwaju Oluwa, Jona 1:3

3. Ẹfuufu nla bẹrẹ si jà loju òkun, Jona 1:4-6

4. Nipa imọran oun tikalara rè̩ a gbé Jona sọ sinu òkun, Jona 1:7-16

5. Oluwa ti pese ẹja nla kan lati gbé Jona mì, Jona 1:17

II È̩jé̩ Jona

1. Ipọnju Jona mú ki o gbadura, Jona 2:1-7

2. Nigba ti Jona ṣeleri lati san è̩jé̩ rè̩, Oluwa jé̩ ki ẹja naa pọ Jona sori ilẹ gbigbẹ, Jona 2:8-10

III Iwaasu Ti O S̩iṣẹ

1. Ọrọ Oluwa tọ Jona wá lẹẹkeji, Jona 3:1, 2

2. Jona dide, o si lọ si Ninefe, Jona 3:3

3. “Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bi Ninefe wo,” Jona 3:4

4. Awọn ara Ninefe gba Ọlọrun gbọ, wọn ronupiwada iwa buburu wọn, Jona 3:5-9

5. Ọlọrun ri iṣẹ wọn, O si yi idajọ ti O ti ṣe tẹlẹ pada, Jona 3:10

IV Oniwaasu Ti O Fajuro

1. Jona fé̩ idajọ lẹsẹkẹsẹ lori Ninefe, Jona 4:1-3

2. Ọlọrun kọ Jona ni ẹkọ aanu, Jona 4:4-11

Notes
ALAYE

Woli Jona, ọmọ Amittai, jé̩ ara Gat-heferi, ilu kan ni Sebuloni. Oun ni woli nigba ti idile Jehu n jọba lori awọn ọmọ Israẹli. Asọtẹlẹ Jona kò le ṣalai di mimọ ni gbogbo ilẹ Israẹli nitori ti wọn jé̩ asọtẹlẹ idande kuro lọwọọtá awọn Ọmọ Israẹli ati idapada awọn agbegbe ti a ti gba lọwọ wọn. (Wo 2 Awọn Ọba 14:25-28).

Iṣẹ Titun

Ni ọjọ kan Ọrọ Oluwa tọ Jona wá, ṣugbọn awọn eniyan orilẹ-ède miiran ni a rán an si. Jona mọ ohùn Oluwa, ỌrọỌlọrun kò si le ru u loju, ṣugbọn ki ni iṣẹ naa ti a fi rán an? “Dide, lọ si Ninefe, ilunla nì, ki o si kigbe si i; nitori iwa buburu wọn goke wá iwaju mi.” Ninefe jé̩ olu ilu Assiria.

Nigba ti Ọlọrun sọ fun Abrahamu nipa iwa è̩ṣẹ awọn ara Sodomu ati ipinnu Rè̩ lati pa ilu buburu naa run, Abrahamu bẹrẹ si gbadura pe ki a le dá ilu naa si, ṣugbọn ọkàn ti Jona ni yatọ si eyi. Dipo ki Jona gbadura fún ilu Ninefe tabi ki o mu ọna ajo rè̩ pọn lati lọ waasu fun awọn ara ilu naa, o dide lọgan lati salọ si ọna jijin réré si iha keji ti o dojukọ ilu naa. Bi o ba waasu ỌrọỌlọrun fun awọn ara Ninefe, eyi yoo ṣilẹkun anfaani igbala silẹ fun wọn bi o tilẹ jé̩ pe wọn jé̩ ajeji si anfaani awọn ọlọtọ Israẹli ati alejo si awọn majẹmu ileri. Fun idi kan ṣá, Jona kò ni ifẹ lati ri i pe a gba Ninefe là tabi ki a dá a si.

Woli ti o ba ṣe lodi si ifẹ ati ỌrọỌlọrun ki i ṣe woli tootọ mọ. Ọkunrin tabi obinrin ti o ba kọ lati tẹle ifẹ tabi ilana Ọlọrun kò si ninu ẹbi Ọlọrun mọ, bi o tilẹ jẹ pe o ti di atunbi nigba kan ri. Ẹnikẹni ti o ba mọọmọ kọọna otitọ ati ododo silẹ, ki i ṣe Onigbagbọ mọ. Gbogbo aigbọran ni è̩ṣẹ, è̩ṣẹ a si maa ya eniyan ya Ọlọrun.

Awawi

Ki ni ṣe ti eniyan bi woli Jona, ti Oluwa lo lọpọlọpọ, ti o ti ri iyọrisi iṣẹ rè̩, fi ni lati pinnu lojiji lati yẹ iṣẹ rè̩ silẹ ati lati sá kuro niwaju Oluwa? Lai si aniani, Jona ni idi kan ninu ọkàn rè̩ fun ohun ti o ṣe. Jona ni awawi kan lati fi kẹwọ lati gbe ara rè̩ lẹsè̩ fun ojuṣe ti o n yẹra fún.

Ogunlọgọ eniyan ni o n ṣe awawi dipo ki wọn ṣe gbogbo ifẹỌlọrun. Ọlọrun n pe awọn oṣiṣẹ lati lọ waasu Ihinrere fun awọn ẹlomiran, ṣugbọn ọpọlọpọ ni o n ṣe awawi ti wọn si n fi iṣẹ ti wọn n ṣe lọwọlọwọ kẹwọ pé on ni kò jé̩ ki wọn jọwọ ara wọn fun Ọlọrun. O fé̩ rán awọn ẹlomiran sinu ọgbà ajara Rè̩ kaakiri lati lọ kede Ihinrere, ṣugbọn awọn ẹlomiran n ṣe awawi pe wọn kò ni imọ tó. Ọlọrun n fẹ awọn ẹni ti yoo lọ si ile itọju awọn alaisan ati ile tubu lati sọọrọ itunu Rè̩ fun awọn eniyan, ṣugbọn ọpọ ni o wa iṣẹ oojọ wọn mọra tó bẹẹ ti wọn kò ni ayè lati ṣiṣẹ fun Oluwa. Jesu wi pe, “Ọkọnrin kan se àse-alẹ nla, o si pè enia pipọ: o si rán ọmọ-ọdọ rè̩ ni wakati àse-alẹ lati sọ fun awọṅ ti a ti pè wipe, Ẹ wá; nitori ohun gbogbo ṣe tan. Gbogbo wọn si bè̩rẹ, li ohùn kan lati ṣe awawi ... Mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ninu awọn enia wọnyi ti a ti pè, ki yio tọwò ninu àse-alẹ mi” (Luku 14:16-18, 24).

Jona le maa rò lọkan rè̩ pe oun kò ni lọ waasu fun awọn ara Ninefe nitori pe o n woye pé orilẹ-ède Assiria ti i ṣe alagbara le gbogun tì, ki wọn si ṣẹgun ilẹ Israẹli lai pé̩. Asọtẹlẹ Jona jẹmọ idapada awọn ilẹ Israẹli ti a ti gbà lọwọ wọn: niwọn bi o si ti jẹẹni kan ti o ni itara pupọ fun Israẹli, orilẹ-ède rè̩, o jowú, kò si fé̩ ki ohunkohun yẹ aala ilẹ orilẹ-ède yii. Agbára Assiria yoo dinku gidigidi bi Ọlọrun ba pa olu-ilu rè̩ run nitori iwà buburu awọn eniyan ibẹ. O dabi ẹni pe ohun ti Jona n fẹ ni eyi, nitori naa kò fẹ lọ waasu fun awọn ara Ninefe. O wi pe: “Emi mọ pe, Ọlọrun olore-ọfẹ ni iwọ, ati alānu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ibi na” (Jona 4:2). O kọ lati waasu, ki Ninefe má ba ronupiwada ki a si dá wọn si. S̩ugbọn ero Ọlọrun ki i ṣe erò eniyan, bẹẹ ni ọnà eniyan ki i ṣe ọnàỌlọrun. Asan ni erò eniyan niwaju Ọlọrun; nitori naa, nigba ti Ọlọrun bá sọrọ, eniyan ni lati feti silẹ ki o si ṣe ohun ti Ọlọrun wi, ni aifi erò ti o ti ni lọkan tẹlẹ pè.

Ókun Riró

Bi Jona ti n salọ kuro niwaju Oluwa, o lọ si Joppa, ebute kan pataki ju lọ ni ilẹ Israẹli. Lai pẹ jọjọ o ri ọkọ ti o n lọ si Tarṣiṣi, o san owóọkọ o si wọ inu rè̩ ni ireti lati yẹ iṣẹ ti Ọlọrun rán an silẹ. O dabi ẹni pe eṣu saba maa n pese oriṣiriṣi ọnà miiran fun awọn ti o ba fẹ yẹ iṣẹ ti Ọlọrun fun wọn silẹ lai ṣe. Ọkẹ ainiye eniyan ni o ti sanwo ọkọ ti yoo gbe wọn lọ kuro niwaju Ọlọrun, ṣugbọn wọn bá ijatilẹ pade, nitori pe ko si ẹni ti o le fara pamọ kuro niwaju Ọlọrun. “Emi ha iṣe Ọlọrun itosi? li OLUWA wi, ki iṣe Ọlọrun lati okere pẹlu? Ẹnikẹni le fi ara rè̩ pamọ ni ibi ikọkọ, ti emi ki yio ri i, li OLUWA wi. Emi kò ha kún ọrun on aiye, li OLUWA wi?” (Jeremiah 23:23, 24). Kòṣe e ṣe lati sá kuro niwaju Oluwa.

Ọkọ Jona gbera irin ajo rè̩ lọ si ilu Tarṣiṣi ṣugbọn lai pẹ awọn atukọ rè̩ kó si wahala. Oluwa rán iji lile ti o si lagbara si wọn. Ọkọ wọn wa ninu ewu ati fọ si wé̩wé̩. Awọn atukọ naa mọ iru ewu ti wọn wà, nitori naa wọn bẹrẹ si ké pe awọn ọlọrun wọn, ṣugbọn Jona ti lọ si isalẹọkọ, o si ti sun fọnfọn lai mọ wahala ati ewu ti o dá silẹ.

“Ọna awọn olurekọja ṣoro” (Owe 13:15). Oluwa fi eniyan buburu wé rirú omi òkun nigba ti kò le simi, ti n túẹrẹ ati eeri jade. “Alafia kò si fun awọn enia buburu ni, Ọlọrun mi wi” (Isaiah 57:21). Ibinu Ọlọrun, bi igbi ayé, yoo bi lu ọkàn kọọkan ti o kọ lati jé̩ ipe Ọlọrun ati lati ṣe ifẹ Rè̩. Jona fé̩ sá kuro niwaju Ọlọrun, ṣugbọn ó bá ara rè̩ pade laaarin igbi òkun, nibi ti ireti ati là kò si fún un. Wahala ni ẹni ti o bá sá kuro niwaju Ọlọrun n bọ si nigba gbogbo, nikẹyin yoo jihin fun Ọlọrun, bi o ti wù ki o ri. Bawo ni o ti dara tó lati gbagbọ ati lati bu ọla fun Ọlọrun, ki a ba le fi ayọ iṣẹgun rin aye yii ja!

Ọwọ Tè̩é̩

Awọn atukọ ji Jona kuro loju orun bi o ti sùn fọnfọn ti kò si bikita, wọn sọ fun un ki o ke pe Ọlọrun rè̩ fun iranwọ. Lai pẹ jọjọ, awọn ọlọkọ naa mọ pé Jona ni o kó bà wọn, wọn si bi i leere ohun ti wọn le ṣe ki òkun le dakẹ jẹjẹ fun wọn. Jona sọ fun wọn pe afi bi wọn ba gbé oun sọ sinu òkun. Awọn atukọ naa kò fẹṣe bẹẹ; ṣugbọn lẹyin ti wọn ti sa gbogbo ipa wọn lati gba ẹmi ara wọn là lọna ti ara wọn, wọn ṣe ohun ti Jona ni ki wọn ṣe. Lootọ, lootọ gẹgẹ bi ọrọ Jona, riru okun dakẹ jẹjẹ.

“S̩ugbọn OLUWA ti pese ẹja nla kan lati gbe Jona mì. Jona si wà ninu ẹja na li ọsan mẹta ati oru mẹta.” Nigba miiran, Ọlọrun ni lati lo ọwọ lile lati mú awọn aṣe tinu ẹni wá sinu ironupiwada, eyi a si maa mú ki ọlọtè̩ naa jiya pupọ.

Adura Jona

Jona rò pé oun ti dé isalẹọrun apaadi nigba ti o wà ninu ẹja. Bi ipin rè̩ ti buru to yii, Jona mọ pé ohun ti o buru ju eyi lọ wà niwaju fun oun bi kòṣe pe oun ba gbadura. Awọn miiran rò pe ọrun apaadi kò tayọìṣé̩ ati ibanujẹ ti o n dé bá wọn ni aye yii; ṣugbọn kò si ẹni ti o ti i wà ni ipò ti o buru ju ti Jona lọ. Jona mọ pé wahala ati irora ti oun wà ko jamọ nnkankan lara pagidari iya ti yoo jẹ oun bi oun kò ba ronupiwada è̩ṣẹ oun. Jona gbadura! Ninu ipò ainireti, nibi ti koriko odò ti wé mọọn lori, ti ọkàn rè̩ si n dakú ninu rè̩, Jona gbadura. O ṣe ileri lati san è̩jé̩ rè̩. Adura iwaya-ija rè̩ tọỌlọrun lọ. Ọlọrun gbọ, O si mú ki ẹja naa gbé Jona lọ sori iyangbẹ ilẹ.

O ṣoro fun awọn ẹlomiran lati gba itan Jona gbọ, ṣugbọn igbagbọ ninu Ọlọrun ati ninu Ọrọ Rè̩ yoo mu gbogbo iṣoro ati aigbagbọ kuro. “OLUWA ti pese ẹja nla kan lati gbe Jona mì.” Ọlọrun ti o da ohun gbogbo ti a n ri, ati eyi ti awa mọ, ki ni ṣe ti a o fi ni ero wi pe Oun kò lagbara lati le dáẹja ti yoo gbé Jona mì? Jesu jẹri si otitọ yii pe Jona wà ninu tubu ninu ẹja nigba ti O wi pe: “Nitori bi Jona ti gbéọsan mẹta ati oru mẹta ninu ẹja; bḝli Ọmọ-enia yio gbéọsán mẹta on oru mẹta ni inu ilẹ” (Matteu 12:40). Agbára Ọlọrun kan naa ti o mú ki ẹja gbé Jona wá si iyangbẹ ilẹ, ki o ba le waasu fun awọn ara Ninefe, ni o mu ki ỌmọỌlọrun jinde kuro ninu okú ki a le waasu ironupiwada ati idariji è̩ṣẹ ni Orukọ Rè̩. “Awọn ara Ninefe yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, nwọn, o si da a lẹbi: nitori nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si wò o, ẹniti o pọ ju Jona lọ nbẹ nihinyi” (Matteu 12:41).

Ogoji Ọjọ

Ipe Ọlọrun tọ Jona wa lẹẹkeji, o tun fi iṣẹ kan naa le e lọwọ pe ki o lọ waasu fun awọn ara Ninefe. Ọlọrun ma ṣalai jẹ ki gbogbo onigbagbọ le kọẹkọ ninu eyi pé ipèỌlọrun kòṣe e fi ọwọ yẹpẹrẹ mú ati pe bi a ba tete gbọran si i lẹsẹkẹsẹ irọrun ni yoo jé̩ fun wa. Ọwọ lile ni Jona fi kọẹkọ ti rè̩. Bi o ba ṣe pe o ti lọ si Ninefe taara ni iṣaaju nigba ti Ọlọrun ti pe e, wo iyọnu nla ti i ba ti fòó dá!

“Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bi Ninefe wo.” Ikede Jona kò gùn, ṣugbọn o yéẹnikẹni yekeyeke. Awọn ara Ninefe kò ja Jona ni koro bẹẹ ni wọn kò beere aṣẹ ti o fi n sọrọ; lai si aniani Ẹmi Ọlọrun báọkàn wọn sọrọ ju ohun ti wọn gbọ lẹnu Jona ni igboro Ninefe. Gbogbo awọn ara Ninefe tara ṣàṣà -- lati ọba, ti o sọkalẹ kuro lori itẹ rè̩ ti o si bọ aṣọ igunwa rè̩, titi dé iranṣẹ ti o rẹlẹ jù lọ. Gbogbo wọn fi aṣọọfọ bora. Aṣẹ jade lati aafin ọba pe ki eniyan tabi ẹranko ki o máṣe tọ ohunkohun wò, i ba ṣe ounjẹ tabi omi. “Jẹ ki enia ati ẹranko fi aṣọọfọ bora, ki nwọn si kigbe kikan si Ọlọrun: si jẹ ki nwọn yipada, olukuluku kuro li ọna ibi rè̩, ati kuro ni iwa agbara ti o wà lọwọ wọn. Tani le mọ bi Ọlọrun yio yipada ki o si ronupiwada, ki o si yipada kuro ni ibinu gbigbona rè̩, ki awa máṣegbe?” (Jona 3:8, 9). Ọlọrun ronupiwada ibi ti O ti pinnu lati mú wá sori awọn ara Ninefe. Ibinujẹẹni iwa-bi-Ọlọrun a maa mú ni ri ojurere Ọlọrun ni gbogbo ọna.

Tete WáỌlọrun

Awọn ara Ninefe wá aanu Ọlọrun pẹlu aawẹ ati adura lẹsẹkẹsẹ ti wọn gbọ iwaasu Jona. Ọlọrun wi pe, “Niwọn ogoji ọjọ si i,” ṣugbọn awọn eniyan wọnyi kò fi ọjọ ironupiwada wọn dọla. Ọrọ iparun kan naa ti awọn ara Ninefe gbọ ni awọn eniyan ayéòde isisiyi n gbọ, ṣugbọn a kò fi hàn fun ni ọjọ ti iparun naa yoo dé: “Ọrun on aiye yio rekọja, ṣugbọn ọrọ mi ki yio rekọja. S̩ugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo” (Matteu 24:35, 36). Nitori ti Oluwa fa bibọ Rè̩ sẹyin, ọpọlọpọ eniyan n fa ọwọ imurasilẹ wọn sẹyin de ọjọ yii.

I ba ṣe pe pupọ ninu awọn eniyan òde-oni wà ni ilu Ninefe nigba nì, ki wọn si gbọ iwaasu Jona, wọn i ba duro de opin ogoji ọjọ ki wọn tó bẹrẹ si gbadura. Awọn miiran ti n fi ero yii tu ara wọn ninu pé awọn yoo gbadura nigba ti wọn ba wà leti bebè ikú tabi nigba ti o ba kù diẹ ti aye yii yoo dopin. Wò bi o ti lewu tó fun eniyan lati kùgbu kẹgan, kọ, tabi ṣe ainaani ifẹ ati aanu Ọlọrun ni ireti pe Ọlọrun yoo dari igbesi-ayéè̩ṣẹ ati ayé ijẹkujẹ ji ni idahunsi adura raurau kan ti a gbà lopin igbesi-ayé ti kò ni laari! O tilẹ le ṣalai ni anfaani ati gbadura rara. Ọna bayii ki i ṣe eyi ti o ni idaniloju, o si lewu pẹlu.

Lọna keji è̩wẹ, Ọlọrun a maa fun awọn iranṣẹ Rè̩ ti i ṣe oloootọ ni èrè pupọ. Onigbagbọ ki i bẹbẹ fun inu-didùn, itẹlọrun tabi alaafia ki o tó ni wọn. Gbogbo ọjọ ayé Onigbagbọ ni o fi n ṣe afẹri bibọ Jesu lẹẹkeji. Bi o tilẹ ni lati lọ laaarin afonifoji ojiji ikú, idaniloju iye ainipẹkun ati ireti iye lẹyin ikú yoo wà ninu ọkàn rè̩. Ọlọrun wà pẹlu rè̩ pẹlu gbogbo itura Ọrun. Fun Onigbagbọ, ọna igbesi-aye kan ṣoṣo ni o wà, oun naa ni ọna ti Jesu là silẹ loke Kalfari -- ọna Ihinrere.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi rán Jona lọ si Ninefe?
  2. Ki ni ṣe ti Jona fi gba Tarṣiṣi lọ?
  3. Bawo ni a ṣe de Jona lọna ninu irin-ajo rè̩ lọ si Tarṣiṣi?
  4. Ki ni Oluwa lò ti kò jé̩ ki Jona ri sinu omi?
  5. Ki ni ṣe ti ẹja naa fi pọ Jona silẹ lori iyangbẹ ilẹ?
  6. Ki ni ọrọ ti Jona fi kede fun awọn ara Ninefe?
  7. Ọkàn wo ni awọn ara Ninefe fi gba ikilọỌlọrun?
  8. Bawo ni a ṣe mọ pé otitọ ni itan Jona?