2 Kronika 26:1-23

Lesson 321 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi enia kan ba nrò ara rè̩ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rè̩ jẹ” (Galatia 6:3).
Cross References

I Iwa-rere Ussiah ati Ọrọ Rè̩

1. Nigba ti a fi jọba nigba èwe, Ussiah tabi Asariah bá eniyan Ọlọrun rin timọtimọ, 2 Kronika 26:1-5; 2 Awọn Ọba 15:1-4; 1 Awọn Ọba 2:4

2. Ọlọrun bukun fun Ussiah ati Juda niwọn igbà ti Ussiah tẹle Oluwa ti o si gbọran si ofin Rè̩, 2 Kronika 26:5-15; 31:21; 1 Samuẹli 12:13-15; Deuteronomi 29:9; 1 Kronika 22:11-13; Orin Dafidi 1:3

II Igberaga ati Ijiya Ussiah

1. Nigba ti Ussiah di alagbara tán, o gbagbe aṣẹỌlọrun, 2 Kronika 26:15, 16; Deuteronomi 6:10-12; 8:10-20; Orin Dafidi 62:10; Owe 1:32; 30:7-9

2. Igberaga ati jijọ-ara-ẹni loju jé̩è̩ṣẹ ti o n rán ni lọ si ọrun-egbe, 2 Kronika 26:16; Daniẹli 4:30-32; 5:17-24; Hosea 13:1-8; Luku 12:16-21; Owe 16:18; 1 Johannu 2:16

3. Ni rirò pe oun ti lagbara, oun si ti tó tán ninu ohun gbogbo, Ussiah ṣe iṣẹ awọn alufaa, 2 Kronika 26:16-18; Owe 25:14; Numeri 16:1-35; Lefitiku 10:1-11; Numeri 3:5-10; 18:1-7

4. Ussiah binu nigba ti iranṣẹỌlọrun ba a wi – eyi jé̩ ifarahàn igberaga rè̩ lẹẹkan si i, Ọlọrun si lùú, 2 Kronika 26:19; 2 Awọn Ọba 15:5; Orin Dafidi 141:5; Heberu 12:5; 1 Peteru 2:20; Efesu 5:21; 1 Peteru 5:5, 6

5. A ti Ussiah jade kuro ninu Tẹmpili, 2 Kronika 26:20

6. Ussiah lọ sinu iboji pẹlu ibinu ati idajọỌlọrun; a ko sọ ohun kan nipa rè̩ pe o ni ironupiwada, 2 Kronika 26:21-23;

7. 2 Awọn Ọba 15:5-7

Notes
ALAYE

Ussiah, ọba Juda bẹrẹ daradara; igbẹyin rẹ i ba si dara bi o bá tẹle ọna ti o mú ibukun wá sori rè̩ ni ibẹrẹ ijọba rè̩ titi dopin. S̩ugbọn Ussiah jáỌlọrun rè̩ tilẹ, o si yi pada kuro ni ọna ododo ati iwa mimọ si ọna igberaga ati ijọ-ara-ẹni-loju. Igbẹyin aye rè̩ buru o si kú labẹ idajọỌlọrun nitori è̩ṣẹ rè̩. A kò sọ fún wa bi ironupiwada rè̩ ti jinlẹ tó, tabi pé o tilẹ ronupiwada rara, ṣugbọn nitori arun è̩tè̩ ti o kọlu u, oun kò le lọ si Ile Oluwa mọ, o si kú lai si itunu.

O yẹ ki a kaanu fun ẹnikẹni ti o ni anfaani nipa ti ẹmi lọnakọna ṣugbọn ti o fi ọna otitọ yii silẹ lati yan ọna iṣina! “Ododo olododo ki yio gbà a là li ọjọ irekọja rè̩: ... bḝni olododo ki yio là nipa ododo rè̩ li ọjọ ti o dẹṣẹ” (Esekiẹli 33:12). A o nùè̩ṣẹẹni ti i ṣe ẹlẹṣẹ nù kuro nigba ti a ba dá a lare lọfẹ nipa oore-ọfẹỌlọrun; bakan naa ni iṣẹ rere olododo ki yoo gbà a là bi o bá yi pada kuro lọna ododo si ọna è̩ṣẹ. Bi olododo “ba gbẹkẹle ododo ara rè̩, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rè̩ ni a ki yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rè̩ kú” (Esekiẹli 33:13). O yẹ ki a gba ọrọ wọnyi rò. Wọn fi hàn fun ni bi o ti ṣe danindanin tó lati bè̩rẹ ni ọna otitọ ati bi o ti ṣe dandan fun ni tó lati maa rin ni ọna ododo naa titi déòpin.

Ussiah Olorire Ọba Juda

Ussiah ni anfaani ti ọpọlọpọ kò ni. Ọba ni, o si ni anfaani si ohun pupọ ti i ṣe ire tabi ibi; ni ibẹrẹ igbesi-aye rè̩, o huwa ọlọgbọn ni ti pe o tẹle imọran eniyan Ọlọrun. “O si ṣe eyiti o tọ li oju OLUWA, ... O si wáỌlọrun li ọjọS̩ekariah, ẹniti o li oye ninu iran Ọlọrun: niwọn ọjọ ti o wáOLUWA,Ọlọrun si mu u ṣe rere.” O ṣe iṣẹ rere pupọ. Ibukun ti Juda ri gbà ni akoko yii kò kere. A sọ fun ni pé Ussiah ni o kọṣe ẹrọ ogun ti o le wó ilu olodi palẹ ni akoko kukuru. Gẹgẹ bi ẹni ti o fẹran iṣẹ agbè̩ṣiṣe paapaa nipa awọn ẹran ọsìn, Juda ṣe rere labẹ akoso rè̩.

Yatọ si S̩ekariah ẹni ti a kò le sọ pupọ nipa rè̩, Ussiah ni anfaani lati mọ pupọ ninu awọn eniyan Ọlọrun pataki-pataki. Isaiah jé̩ Woli ni akoko ijọba Ussiah. Ni ọdun ti Ussiah kú ni Isaiah ri iran Ọlọrun Mẹtalọkan nipasẹ eyi ti o fi mọ daju pé oun ni lati ni isọdimimọ patapata. Amọsi ati Hosea sọtẹlẹ ni akoko ijọba Ussiah. Lai si aniani, awọn eniyan Ọlọrun miiran wà ni orilẹ-ede yii ti a mú mọỌlọrun lati ọwọ awọn iranṣẹỌlọrun mẹta wọnyi, awọn ẹni ti igbagbọ ati oore-ọfẹ wọn nipa ti ẹmi ni lati jé̩ anfaani ati ibukun fun ọba ati ijọba rè̩.

S̩ugbọn orilẹ-ède naa kò fi gbogbo ara tẹle apẹẹrẹọba wọn tabi ọrọ awọn woli wọn nitori ti awọn eniyan naa n sun turari, wọn si n rubọ ni ibi giga ti Ussiah kò mu kuro. Orilẹ-ède yii pin si meji ninu ọran isin, eyi si yatọ si ilana ati ipinnu Ọlọrun ni ọna ti O n fé̩ ki a fi sin Oun. Diẹ ninu awọn eniyan yii n lọ si Ile Ọlọrun, awọn miiran si n tọọna ti o rọrun -- wọn n lọ si ile isin ti o wà ni tosi wọn eyi ti kò gbà wọn ni wahala bi ati maa lọ si Jerusalẹmu ni igba mẹta lọdọọdun. Boya awọn miiran tilẹ n lọ si Ile Ọlọrun ati ibi giga wọnni pẹlu ni ireti pé apapọ mejeeji yoo tun dara ju ọkan ṣoṣo lọ. Dajudaju awọn miiran n lọ si Ile Ọlọrun nitori ti wọn ri i pe o dara lati ṣe bẹẹ, ki i ṣe nitori pe wọn ni ẹmi isin tootọ ni ọkàn wọn. S̩ugbọn awọn oloootọ diẹ ranpẹ wà ti o n sin Ọlọrun nikan ṣoṣo, nitori ti wọn fẹran Rè̩ ati nitori ti wọn fẹọna Rè̩ ju ohunkohun lọ.

A kò fé̩ọmọlẹyin iru awọn eniyan wọnyi kù ninu isin Igbagbọ lode oni, bakan naa ni kò si igbà kan ti iru wọn ṣọwọn lati igba ti Ijọ ti bẹrẹ. S̩ugbọn ọna kan ṣoṣo ni o wà. Ọlọrun kan ni n bẹ. Igbala kan ṣoṣo ni o wà pẹlu. Isin kan ṣoṣo ni o wà, eyi si ni isin Ọlọrun tootọ, ni ẹmi ati ni otitọ. Ẹgbé̩ kan ṣoṣo ni yoo pejọ sọdọ Oluwa nigba ti O ba pada, awọn ọmọẹgbé̩ yii ni awọn wọnni ti wọn ti fi ẹbọ ba A da majẹmu.

“A ṣe iranlọwọ iyanu fun Ussiah, titi o fi li agbara.” Apọsteli nì sọ fun ni wi pe, “Nitorina tayọtayọ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mā gbe inu mi. Nitorina emi ni inu didun ninu ailera gbogbo, ninu è̩gan gbogbo, ninu aini gbogbo, ninu inunibini gbogbo, ninu wahalà gbogbo nitori Kristi: nitori nigbati mo ba jẹ alailera, nigbana ni mo di alagbara” (2 Kọrinti 12:9, 10). Niwọn-igbà ti Ussiah gbẹkẹle Ọlọrun, Ọlọrun jé̩ Oluranlọwọ rè̩. Niwọn-igbà ti Ọlọrun si ràn án lọwọ, ó lagbara gidigidi.

S̩ugbọn nigba pupọ ni awọn ẹlomiran i maa ṣe bi Ussiah ti ṣe. Lẹyin ti Ọlọrun bá ti ràn wa lọwọ tán, ti O si ti fun wa ni agbára lọna kan tabi lọna miiran, o rọrun lati mú ojú wa kuro lara Ẹni ti o fun ni ni nnkan wọnyi, ki a si bẹrẹ si wo agbára wa, tabi ohun ti a ti ṣe tabi awọn ibukun ti a ti ri gbà. A kò gbọdọṣe bẹẹ bi a ba fé̩ wà ninu ifẹỌlọrun ti a si fé̩ ki ibukun ti a ri gbà ki o mọ wa lọwọ. A ni lati tẹju mọ Olufunni-lẹbun. A kò gbọdọ wo iṣẹọwọ wa, aṣeyọri ti a ṣe, tabi nnkan wọnni ti ọwọ wa ti tè̩, tabi awọn ẹbun ti a ni. Ki i ṣe pe awọn ẹlomiran gbé ojú le nnkan wọnyi nikan, ṣugbọn wọn n fi ọwọ sọ aya nipa wọn, eyi ti o buru ju pé ki a gbé oju lé wọn. Awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun kò tilẹ ni fi ojú si nnkan wọnyi afi lati fi gbé ogo Ọlọrun ga nikan.

Jesu wi pe, “Nigbati ẹ ba ti ṣe ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun nyin tan, ẹ wipe, Alailere ọmọ-ọdọ ni wa: eyi ti iṣe iṣẹ wa lati ṣe, li awa ti ṣe” (Luku 17:10). Paulu Apọsteli kọ akọsilẹ pe, “lati ọdọỌlọrun ni tito wa” (2 Kọrinti 3:5). A si tun kọọ pe, “Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rè̩ ga, li a o rè̩ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rè̩ ara rè̩ silẹ li a o gbé ga” (Matteu 23:12); a tun le fi ibeere yii gbèé lẹsẹ lati inu Iwe Mimọ wá wi pe, “Tali o mu ọ yàtọ? kini iwọ si ni ti iwọ kò ti gbà? njẹ bi iwọ ba si ti gbà a, éhatiṣe ti iwọ fi nhalẹ, bi ẹnipe iwọ kò gbà a?” (1 Kọrinti 4:7).

ÈrèÈ̩ṣẹ

Igbésè̩ ti Ussiah gbé jé̩ eyi ti oun kò ni jé̩ daba lati gbé nigba ti ọkàn rè̩ rẹlẹ niwaju Ọlọrun. Ẹṣè̩ ki i fara hàn bi ohun ti o buru jai ni akọbẹrẹ. Ni ibẹrẹ, o le fi ara hàn bi ohun ti kò buru. Bọya ẹnikẹni kò tilẹṣe akiyesi ti Ussiah rara. Bibeli sọ fun ni pe, “Ọkàn rè̩ gbega soke.” Boya bi o ti n ṣe tẹlẹ ni o n ṣe, ninu ihuwasi, ninu iṣọwọṣe isin ti kò yipada, ẹgbé̩ ati ọgbà rè̩ pẹlu ko yipada si ti atẹyinwa. S̩ugbọn ohun kan yipada “Ọkàn rè̩ gbé ga soke.”

Wo bi arekereke ti Eṣu n lò lati pa awọn iranṣẹỌlọrun run ti pọ tó. Oró ejò kòṣe fi oju ri nigba ti o ba bu eniyan ṣán, ṣugbọn oró naa wà ninu ara, o si n ṣiṣẹ jamba nlá nlà nikọkọ; bakan naa ni iṣẹ Eṣu ri ninu ọkàn. Ipọnni kan ti a fara mọ ti a si tò jọ bi iṣura, fifi kẹlẹkẹlẹọkàn yin ara ẹni, igberò pe kò si ẹlomiran ti o le ṣe iṣẹ kan bi ti wa; fifi oju tinrin agbára tabi iṣẹ awọn ẹlomiran; eyikeyi ninu awọn irin-iṣẹ Eṣu yii, bi a ba jọwọ lọwọ lọ, le da owusuwusu bo ọkàn ki o si ṣe ikú pa ọkàn ti o ti n ṣe rere ti o si kún fún alaafia tẹlẹ ri. O tọ, o si yẹ ki olukuluku Onigbagbọ maa yẹọkàn ara rè̩ wò lati igbà-de-igbà lati ri i pe gbongbo ibi kan tabi ohun ti o fara jọ ibi kò hu nibẹ. Ju gbogbo rè̩ lọ, ọkàn Onigbagbọ kò gbọdọ gbé ga soke. O ni lati rẹ ara rè̩ silẹ ni gbogbo ọna paapaa jù lọ, o ni lati jé̩ onirẹlẹ ninu ọkàn rè̩. Irẹlẹ adabọwọ ti òde ara kò lere kan bi ọkàn bá gbé ga soke. Iwa wa lode yoo dara bi irẹlẹ tootọ bá wà ninu ọkàn wa.

Ẹṣẹ Ikugbu ni Abayọrisi Igberaga

Ussiah wọ Tẹmpili Ọlọrun lọ lati sun turari lori pẹpẹỌlọrun lai naani gbogbo ilana Ọlọrun ati awọn eniyan ti Ọlọrun ti yàn lati ṣe iru iṣẹ bẹẹ. È̩ṣẹ yii buru jai. Ofin Mose beere pe ki a pa ẹni ti o ba ṣe bẹẹ, ṣugbọn niwọn bi o ti jé̩ pé Ussiah ni ọba Juda, kò si ẹni ti o le paṣẹ pe ki a pa á.

S̩ugbọn alufaa Ọlọrun tako ọba yii gẹgẹ bi aṣẹ ti Ọlọrun fi le e lọwọ; nigba ti idajọỌlọrun sọkalẹ, o fi hàn pe iduro ti eniyan Ọlọrun yii mú ni o tọnà, gbogbo awọn alufaa si ti Ussiah jade kuro ni ibi mimọ. Nigba ti Ussiah paapaa ri è̩tè̩ ti Ọlọrun da bòó, inu rè̩ dùn lati sá jade kuro ni Ile Ọlọrun. Arun è̩tè̩ yii jade si i lara, ki i ṣe bi akọbẹrẹè̩tè̩ bi kòṣe bi igbà ti arun è̩tẹ dé ogogoro. Ussiah mọ pé kò si adẹtẹ ti o ni è̩tọ ninu Tẹmpili. O si mọ pé kò si ẹni ti a kò yàn ti o ni ẹtọ lati wà nibẹ, paapaa lati sun turari. O ti rú ofin Ọlọrun, o si ti ré aṣẹ Rè̩ kọja, o si ti mọọn lara, idajọ ojiji ti o dé bá a. O sá jade nitori o bẹru ki idajọ ti o gbona ju eyi lọ má ba tún dé bá a.

Ni igba miiran gbogbo ti eniyan tẹ ofin Ọlọrun leti ninu ọran yii, Ọlọrun rán idajọ lẹsẹkẹsẹ. Eniyan kòṣè̩ṣẹ lè maa gbeja Ọlọrun ninu ọran yii. Ohun ti eniyan le ṣe ni pé ki o sọ ofin ati ifẹỌlọrun. Ilẹ gbé Kora, Datani, ati Abiramu mì laaye nitori ti wọn fé̩ fi ọwọ rọ ofin ati ilana Ọlọrun ati iranṣẹ Rè̩ ti o yàn tì si apakan. Awọn ọmọ Aarọni meji ti a tilẹ yàn si ipo alufaa ṣe alainaani ilana Ọlọrun, iná si ti ọdọ Oluwa wá, o si run wọn (Lefitiku 10:1).

Awọn ohun ti o ṣẹlẹ wọnyi fi hàn fún ni bi o ti buru tó pé ki a má rin deedee ninu gbogbo ofin Ọlọrun ati pe ki a ṣá ilana Ọlọrun tì lati yan ọna ti o té̩ọkàn igberaga wa lọrun. Ọlọrun lè rán idajọ ojiji si ẹnikẹni ti o bá rú ofin Rè̩. Pẹlupẹlu a tun le ri i nihin yii bi ohun ti awọn eniyan n pe ni è̩ṣẹ kékèké ti buru jai to, bi a bá gbàá laye lati lùmọ ninu ọkàn, yoo di ohun ti ọwọ kò ká, nikẹyin yoo mu ki ẹni naa ṣọtẹ si Ọlọrun patapata.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Darukọ awọn wolii Ọlọrun mẹta, ti wọn pẹlu awọn ti o kọ akọsilẹ ninu Bibeli, ti o wà nigba ijọba Ussiah.
  2. Ohun pataki wo ni o ṣẹlẹ ni ọdun ti Ussiah kú ti a kọ akọsilẹ rè̩ sinu Iwe Isaiah?
  3. Abé̩ iranwọ rere awọn ta ni ẹkọ wa yii sọ fún wa pé Ussiah wà ni igbà kan ni akoko ijọba rè̩?
  4. Njẹ Ussiah ṣe rere tabi buburu ni ibẹrẹ igbesi-ayé rè̩?
  5. Ki ni mú ki Ussiah yi pada ki o si ṣe eyi ti kò tọ nikẹyin igbesi-ayé rè̩?
  6. Ussiah di adẹtẹ. È̩ṣẹ wo ni o ṣè̩ ti o mú ki arun yii dé bá a?
  7. Ki ni ìyà ati idajọ ti o dé bá Ussiah nitori iwa è̩ṣẹ yatọ si arùn è̩tè̩ ti o kọlu u?
  8. Ki ni ṣe ti igberaga fi jé̩è̩ṣẹ?
  9. Ki ni a n pe ni titó-tán-loju ara-ẹni? Ki ni ṣe ti o fi jé̩è̩ṣẹ ti o buru jai?
  10. Ọna “mo-tó-tán” ni ayé n tọ lode oni. Darukọ awọn nnkan diẹ ti o n sún awọn eniyan lati tè̩ sí iru ọna bẹẹ. Sọ fun ni pẹlu, ki ni ṣe ti ifaramọèrò bẹẹ fi lodi si Ihinrere Kristi?