Lesson 322 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ si fà aiyà nyin ya, ki isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipadà si OLUWA Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ li ore-ọfẹ, o si kún fun ānu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ” (Joẹli 2:13).Cross References
I Ọrọ Oluwa Nipa Israẹli ati Awọn Keferi
1. A rán ikilọ lile si Israẹli nipa ti ituka wọn ati isọdahoro ti yoo dé bá ilẹ wọn, Joẹli 1:1-12; Deuteronomi 4:25-28; Lefitiku 26:14-39; Orin Dafidi 44:9-16; Esekiẹli 6:1-7, 11-14; 36:16-20
2. A fi ironupiwada lọ wọn, Joẹli 1:13, 14; Deuteronomi 4:29-31; Lefitiku 26:40-42
3. A sọ asọtẹlẹ nipa ọjọ Oluwa ati gbigbona idajọ Rè̩, Joẹli 1:15-20; 2:1-11; Esekiẹli 38:1-23; 39:1-29; Ifihan 9:1-21; 16:13, 14; 19:11-21
4. A ké si wọn lẹẹkan si i fun ironupiwada tootọ, Joẹli 2:12-17; Isaiah 1:1-20
5. A ṣeleri iranlọwọ fun orilẹ-ède naa bi wọn bá le ronupiwada, Joẹli 2:18-20; Esekiẹli 6:8-10; 36:28-38
6. A o tu ọpọ ibukun ti ẹmi nlá nlà jade, a o si fi ibukun ti ara fun wọn lakoko imupadabọ Israẹli, Joẹli 2:21-32; Esekiẹli 36:21-27; 37:1-28; Jeremiah 31:1-40; Iṣe Awọn Apọsteli 2:1-21
7. A sọ asọtẹlẹ nipa idajọ nla ti yoo wa sori ẹni ti a kò ba gba ọkàn rè̩ là, Joẹli 3:1-21; Ifihan 20:7-15; 21:8
Notes
ALAYEA kò mọ pupọ nipa Wolii Joẹli, ju pe ọmọ Petuẹli ni oun i ṣe ati pe o wà ni ayé ni nnkan bi ẹgbẹrin ọdun ṣaaju ibi Kristi. Lati inu awọn akọsilẹ ti o kọ, a le ri i pe eniyan Ọlọrun ni ọkunrin yii ati pe Ọlọrun fun un ni iṣipaya kikun nipa eto Ọlọrun fun Israẹli. Ohun afiyesi gidigidi ni pé orukọ ti a sọ woli Ọlọrun yii ni Joẹli, itumọ eyi ti i ṣe Jehofa ni Ọlọrun! Kokó asọtẹlẹ rè̩ ni ipè si ironupiwada ati ikilọ nipa ohun ti yoo tẹle e bi wọn bá kọ eti didi si ikilọ naa.
Orilẹ-ède Ti A Yàn Fé̩
Nigba ti a bi orilẹ-ède Israẹli ninu Abrahamu, Ọlọrun ba a dá majẹmu ti ibukun ati anfaani rè̩ kò lẹgbé̩. Nipasẹ majẹmu naa ni a o ti bukun fun gbogbo orilẹ-ède agbayé. Nitori pe Abrahamu gba Ọlọrun gbọ, a fun un ni ọmọ kan. Orilẹ-ède kan dide lati inu ọmọ ileri yii; ni aipẹ jọjọ, Ọlọrun daabo bo orilẹ-ède yii, O mu wọn lọ si ile-ẹkọ, O tọ wọn, nikẹyin O mú wọn lọ si ilẹ ileri. Bi wọn ti n lọ si ilẹ ileri, Mose sọ ohun ti yoo dé bá wọn bi wọn kò bá gbọran, ati ibukun ti yoo jé̩ ti wọn bi wọn bá gbọran si aṣẹỌlọrun. S̩ugbọn kò pé̩ ti Israẹli gbagbe Ọlọrun, ti wọn tè̩ si ifẹọkàn ara wọn lati dabi orilẹ-ède ti o yi wọn ká.
Lẹyin ti Ọlọrun ti fara da a fun Israẹli fun ọdun pupọ, ṣugbọn ti wọn n ṣubu sinu ibọriṣa lati igbà-de-igbà, nikẹyin, Ọlọrun ran wọn lọ sinu igbekun. A le sọ wi pe igbekun yii jé̩ìtọwò ituká ti a ti sọ asọtẹlẹ pe yoo de ba wọn bi wọn ba kọỌrọỌlọrun. Ninu igbekun wọn, wọn ké pe Oluwa, O gbọ, O gbà wọn, O si mú wọn pada si ilẹ wọn. Wọn tún Tẹmpili kọ; bi o tilẹ jé̩ pe ogo rè̩ kò tó ogo ti iṣaaju, sibẹ Ile Ọlọrun ni, wọn si n sin Ọlọrun nibẹ. Orilẹ-ède naa la akoko aidaniloju kọja titi di akoko ti awọn ara Romu fi ṣẹgun wọn.
S̩ugbọn orilẹ-ède Israẹli kọ aanu Ọlọrun jalẹ-jalẹ nigba ti wọn kan Kristi, Messiah wọn mọ agbelebu. Wọn sọ wi pe ki Ẹjẹ Rè̩ ki o wà lori wọn ati lori awọn ọmọ wọn; ki i ṣe pe Ọlọrun fi ibeere wọn fun wọn nikan ṣugbọn O mu gbogbo idajọ wa sori wọn fún kikọ ti wọn kọ iṣẹ ti O ti n rán si wọn lati è̩yin wá. A pa orilẹ-ède wọn run. A wó awọn ilu ati Tẹmpili wọn lulẹ. A ṣé̩ wọn niṣẹ a si tú wọn kaakiri gbogbo ayé. A kà wọn si ẹni itanu ninu ayé, a kẹgan wọn a si korira wọn ninu ayé. S̩ugbọn orukọ wọn kò parẹ, wọn kò nù mọ ayé lára, a si ti bukun wọn lọna miiran, ju gbogbo awọn orilẹ-ède iyoku lọ. Awọn Ju, gẹgẹ bi orilẹ-ède ti ni ọrọ ti o pọ jù lọ bẹẹ naa ni oṣi ti o pọ jù lọ. Gẹgẹ bi orilẹ-ède, wọn jé̩ẹlẹsin, ṣugbọn alafẹnujẹẹlẹsin ni wọn, nitori wọn ti kọẸni kan ṣoṣo naa ti O le fun wọn lọnà sọdọỌlọrun. S̩ugbọn Ọlọrun kò pa wọn tì patapata, nitori ti O ranti majẹmu Rè̩ pẹlu Abrahamu, baba wọn.
Ikilọ lati Ẹnu Awọn Wolii
Orilẹ-ède Israẹli jiya lọpọlọpọ nitori ti wọn kọỌmọỌlọrun, wọn si ṣọtẹ si ỌrọỌlọrun. S̩ugbọn wọn ko le sọ pe wọn kò mọ pe idajọ yii yoo de ba wọn. Ọpọlọpọ ikilọ ni o wa ninu Majẹmu Laelae nipa ọrọ yii eyi ti a ti ọwọẸmi Mimọ fi pamọ fun wa. Lai si aniani awọn woli wọnni sọọpọlọpọ ju eyi ti o wà ni ipamọ fun wa. Iwe Mimọ kún fun ikilọ wọnyi lati ibẹrẹ dé opin. A sọ fun Israẹli lemọlemọ pe bi wọn bá gbọran, wọn yoo jé̩ alabukun-fún; ṣugbọn bi wọn kò bá gbọran, iyà yoo jẹ wọn. Woli Joẹli jé̩ọkan ninu awọn ti Ọlọrun lò lati kede ọrọ nla yii leti wọn.
Lai si aniani, Joẹli jé̩ oniwaasu ododo ati olukọni ni ọna iwa mimọ ati iwa-bi-Ọlọrun, o si jé̩ ojiṣẹỌlọrun ni igbesi-ayé rè̩. S̩ugbọn Ẹmi Mimọ yàn lati ṣe itọju ẹyọ asọtẹlẹ kan yii lati ẹnu Joẹli fun wa nipa Israẹli, ati awọn Keferi. Asọtẹlẹ ti o jinlẹ ni eyi, ori iwe mẹta ọtọọtọ ti o sọ nipa awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lati igbà ifasẹyin Israẹli titi di akoko Itẹ Idajọ Nla Funfun. O yẹ ki a fi gbogbo ọkàn wa si asọtẹlẹ ti o gbamuṣe ti o si sọ asọye yekeyeke yii, ki a ba le ri ibukun gbà nipa rè̩, ki a máṣe dabi awọn wọnni ti Ọlọrun fé̩ bukun fún ṣugbọn ti wọn gba egun dipo.
Bi Asọtẹlẹ Naa Ti Gbòorò Tó
Apa kin-in-ni asọtẹlẹ naa sọ nipa ituka awọn ọmọ Israẹli kaakiri gbogbo agbaye ti yoo tẹle ifasẹyin wọn. Ninu ikilọ yii ni ipè si ironupiwada ati si isin ododo gbe wa ti ko rẹlẹ si eyikeyi ti n bẹ kaakiri ninu Bibeli. “Fà aiyà nyin ya, ki isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipada si Oluwa Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ li ore-ọfẹ, o si kún fun ānu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ,” jé̩ọkan ninu awọn è̩bẹ ti o ti Ọkàn Ọlọrun gan an jade wá si awọn eniyan Rè̩. Israẹli ni ilana isin, ṣugbọn ki i ṣe atọkanwa, nitori ti wọn n fi ète wọn pe orukọỌlọrun ṣugbọn ọkàn wọn jinna si I.
Isin ojú lasan kò ni ère kan afi bi ọkàn ba yi pada si Ọlọrun. Aawẹ nikan kò jamọ nnkankan afi bi adura ati è̩bẹ atọkanwa ti i ṣe itẹwọgbà lọdọỌlọrun bá gbèé lẹsẹ. Ki a maa jẹ ara wa niya lati fi wá ojurere Ọlọrun nigba ti a taku sinu ẹṣẹ ati aiṣedede, kò le mu ire kan wá sori ẹni ti o n ṣe afarawe ironupiwada yii bi kòṣe ibinu Ọlọrun. Afarawe iwabi-Ọlọrun ti o sé̩ agbára Rè̩ kò le gbéẹnikẹni déỌrun. A le fa aṣọ wa ya lati fi hàn pe a ronu piwada lai ni irobinujẹẹni iwa-bi-Ọlọrun ninu ọkàn wa. Iṣẹ ti Ọlọrun rán wolii yii si awọn ọmọ Israẹli ni pe ki wọn mú gbogbo ẹsin asan adabọwọ aṣehàn pé wọn jé̩ẹni mimọ, ati awọn aṣa atọwọdọwọ kuro, ki wọn si yi pada si Ọlọrun ni ironupiwada tootọ bi wọn bá fé̩ bọ kuro ninu ajalu nla ti yoo jalu wọn.
Israẹli kò feti si ọrọ Joẹli nitori ti wọn kò yi pada tọkàntọkàn. ỌrọỌlọrun ṣẹ si wọn lara nitori ti a tú wọn kaakiri gbogbo agbaye. S̩ugbọn Ọlọrun kò gbagbe Israẹli, ẹni ti O ti mọ tẹlẹ ti O si ṣe ni ayanfẹ. O n ba wọn lò lẹẹkan si i.
Iṣẹ ti o yẹ ki awọn ọmọ Israẹli ṣe ni awọn ẹlomiran ti o jẹ ipe Ọlọrun ti gbàṣe, ani lati waasu Ihinrere yi gbogbo ayé ká nipa Messia ti o wá lati gba awọn eniyan là kuro ninu è̩ṣẹ wọn – ati fun awọn Ju ti a tu kaakiri pẹlu. Ẹni kọọkan ninu awọn Ju ti jé̩ ipe yii, ṣugbọn gẹgẹ bi orilẹ-ède, awọn Ju wà ninu aigbagbọ. Ki i ṣe pe igba nì nikan ni wọn kọ Kristi; nitori pe ni igba Ipọnju Nla, ki ibinu gbigbona tó dé bá wọn ni kikun, wọn yoo bá Aṣodi-si-Kristi, ọta Kristi dá majẹmu. Gẹrẹ lẹyin eyi, Aṣodi-si-Kristi yoo da majẹmu yii, yoo si gbogun nla pẹlu agbára ti o ju ti ẹda lọ ti awọn Ju. Igba yii ni a n pè ni akoko ipọnju Jakọbu. Ipọnju yoo dé bá wọn ju ti atẹyinwa lọ, ninu ipọnju wọn, wọn yoo ke pe Ọlọrun fún idande. Ni akoko yii ti wọn fi gbogbo ọkàn wọn wá iranlọwọỌlọrun ni awọn nnkan pupọ yoo bẹrẹ si ṣẹlẹ.
Ijọ Kristi ki yoo si ni ayé ni akoko yii. Wọn yoo wà pẹlu Kristi yi ItẹỌlọrun ká ni ibi Ase Alẹ Igbeyawo Ọdọ-Agutan. Kò si ẹlomiran ti awọn Ju le ké pè fun itunu bi kòṣe Ọlọrun. Awọn ajihinrere lati inu iran keferi ti o le sọ fun wọn nipa Kristi ti o ti wá, ti wọn si ti kọ, ki yoo si mọ. Ogunlọgọ awọn Ju ni a o pa ni akoko yii, ṣugbọn yoo kù iwọn iba diẹ ninu awọn Ju ti yoo ké pe Messia lati wá gbà wọn. (Apẹẹrẹ ohun ti a n sọ yi fi ara hàn diẹ ni akoko Ogun Ajakaye keji nigba ti a n pọn awọn Ju loju kikankikan. Bi wọn ti n fa ọpọlọpọ wọn lọ si ibi ti a o gbé pa wọn, wọn bẹrẹ si ké pe Messia fun idande. Eyi ni wọn yoo ṣe lọpọlọpọ nigba ti ipọnju nla ti akoko iyọnu Jakọbu bá dé bá wọn!) Messia yoo wá; ni àbọ Rè̩, nigba ti awọn Ju bá yi pada kuro ninu aigbagbọ wọn lati fi tọkàntọkàn sin Ẹni ti wọn ti kọ nigba kan ri, a o bi orilẹ-ède Ju ni ọjọ kan. A o pa ijọba eyikeyi ti o wù ki wọn ni nigba naa tì, a o si gbé Ijọba ti Ọlọrun ti ṣe ilana rè̩ silẹ fun awọn ayanfẹ Rè̩ kalẹ. Kristi ni yoo ṣe Olu ni ijọba naa. Ipadabọ Kristi ni akoko yii ni a n pè ni Ifarahàn Rè̩.
Israẹli ni igbekalẹ ijọba ti ara rè̩ nisisiyii, ṣugbọn a le ri i pe eyi ki i ṣe irú ijọba ti Ọlọrun yàn fun wọn. Gẹgẹ bi a ti mọ, a kò le gbé ijọba tootọ naa kalẹ titi Ọba yoo fi dé lati jé̩ Olu rè̩, Oun ki yoo si dé titi awọn Ju yoo fi ni ifé̩ lati gbà A gẹgẹ bi Kristi wọn. Gẹgẹ bi a ti ri i, ipọnju ati ijiya nlá nlà ni yoo mú awọn Ju wá sabẹ itẹriba fun eto Ọlọrun yii.
A sọ asọtẹlẹ awọn ohun ijinlẹ ninu ori Iwe Mimọ yii ati ibomiran ninu ỌrọỌlọrun ti o jẹ mọẹkọ yii. A sọ awọn ohun wọnni fun wa ti yoo ṣẹlẹ ni akoko kukuru ti o wa laaarin igbà ti awọn Ju yoo ké pe Messia wọn ati igbà didéẸni Oloootọ nì. Nigba ti Kristi bá pada wá si ayé, Oun yoo wá pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọna ẹgbẹrun awọn eniyan mimọ Rè̩ -- awọn ogun Ọrun – yoo si bá ogun ti ayé yii jà, yoo si ṣẹgun rẹ. Oun yoo gbé ijọba ododo kalẹ, yoo si jọba fun ẹgbẹrun ọdún lori ilẹ ayé. Akoko ijọba yii ni a n pe ni Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún ti Kristi. Akoko kan wà ti a saba maa n pe ni Ọjọ Oluwa eyi ti bibọ Kristi nigba Ifarahàn Rè̩ jé̩ olubori rè̩, nigba ti yoo wá lati fi idajọ gbigbona bẹ awọn ti o tako O ti wọn si n pọn awọn eniyan Rè̩ loju. Lẹyin Ọjọ Oluwa yii ati laaarin ijọba Ẹgbẹrun Ọdún ti Kristi, Israẹli yoo di ti Kristi nipa yiyan lati ṣe bẹẹ tikara wọn; wọn yoo si jé̩ eniyan Rè̩, ki i ṣe nitori ileri ti Ọlọrun ṣe fun Abrahamu nikan, ṣugbọn nitori pe wọn o wo Ẹni ti wọn ti gún ni ọkọ, wọn yoo ronupiwada è̩ṣẹ wọn, a o si gbà wọn là.
Awọn Ohun Ti Yoo S̩ẹlẹS̩iwaju ati ni Akoko Ọjọ Oluwa
Bi a ti n wo awọn nnkan wọnni ti o n ṣẹlẹ lode oni, o ṣoro lati ri wọn nipasẹ oju ti ayeraye, ọna ti a gbà n ri wọn ko si le ṣalai fete nitori pe awọn nnkan wọnni ti o n ṣẹlẹ nisisiyi dabi ohun ti o tobi loju wa. Bi a ba fé̩ ni oye pipé nipa asọtẹlẹ, a kò ni lati gbé ara le awọn nnkan wọnni ti o n ṣẹlẹ lode oni nikan bi kòṣe ki a fi wọn wé awọn nnkan wọnni ti o ti ṣẹlẹ ati awọn nnkan wọnni ti o n bọ wáṣẹ.
Igbekalẹ Ijọba Kristi lotitọ jé̩ abayọri si wiwa Rè̩ ni akọkọ, ṣugbọn Kristi ki yoo wá gẹgẹ bi Ọba, ninu Ifarahàn Rè̩ titi yoo fi wá ni Ipalarada. A mọ pé Ijọba Israẹli (gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wi) ninu eyi ti Kristi yoo jé̩ Olú, kòṣalai fi ara kọ ijọba ti Israẹli ti gbekalẹ ati ipadabọ awọn Ju si ilẹ wọn eyi ti o n ṣẹlẹ lọwọlọwọ yii. Idande ti Ọjọ Oluwa ki yoo ṣẹlẹ titi awọn Ju yoo fi ké pe Ọlọrun fun idande. Wọn ki yoo si gbohun è̩bẹ soke si Ọlọrun titi a o fi pọn wọn loju ti a o si ṣe inunibini si wọn ni ilẹ wọn, lẹyin ti wọn ti pada si ilẹ wọn ninu aigbagbọ. Gẹgẹ bi awọn iṣẹlẹ yii ti pọ ti o si ṣe pataki tó o ni, sibẹsibẹ wọn le ṣẹlẹ ni iwọn iba akoko kukuru. Kò gbàẹgbẹrun ọdún lati mú un ṣẹ, bẹẹ ni kò gba ọgọrun ọdún lati mú un ṣẹ. Aarin ọjọ diẹ ni Iwe Mimọ fi i si, ki i ṣe ọdún diẹ tabi ọdún mẹwaa kan. S̩ugbọn awọn eniyan mimọỌlọrun ti wà ni imurasilẹ fún Ipalarada ti o le ṣẹlẹ nigbakigba ki Aṣodi-si-Kristi tó gbéìté̩ ijọba rè̩ kalẹ.
Ojo Arọkuro
Ohun pupọ ni yoo ṣẹlẹ ki a tó mú ohun gbogbo wá si opin. Ọpọlọpọ nnkan wọnyi ni o ti ṣẹlẹ, awọn miiran ni a kò i ti muṣẹ. S̩ugbọn gbogbo awọn iṣẹlẹ wọnyi ni a o bẹrẹ si i muṣẹ leralera tabi ki a kuku wi pe o duro lori iṣẹlẹ nla kan -- iṣẹlẹ ti o tobi pupọ nipa ti ẹmi. O ya ni lẹnu pé oju ọpọlọpọ awọn ẹlẹsin ti fọ si nnkan nla yii. Ogunlọgọ awọn ti a n pe ni ọmọlẹyin Kristi ni a kò jé̩ ki anfaani nla ti Ọlọrun fi fun awọn Onigbagbọ ti ode-oni di mimọ fún. Anfaani nla ti ohun pupọ rọ mọ yii ni itujade Arọkuro Ojo.
Gẹgẹ bi Joẹli ti sọtẹlẹ ati gẹgẹ bi Peteru ti ṣe alaye ni Ọjọ Pẹntikọsti, akọrọ ojo Ẹmi Ọlọrun ti rọ ninu eyi ti a gbé fi Ẹmi Mimọ baptisi awọn ọmọ-ẹgbé̩ Ijọ ti igba nì. Ẹmi Mimọ, nipasẹ Peteru, kò fi ẹnikẹni sinu iyemeji nipa ohun ti itumọ asotẹlẹ Joẹli i ṣe. O sọ bayii pe, “Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmi mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obirin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá: Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obirin li emi o tú ninu Ẹmi mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:17, 18). Iyemeji kò ni lati wà nipa iyoku asọtẹlẹ itujade ẹmi yii, nitori Peteru sọ wi pé a o fi Agbára kan naa fun gbogbo awọn ti Ọlọrun yoo pe nigbakigba ati ni ibikibi ninu ayé yii.
Ni akoko ti a n pe ni igbà okunkun biribiri nipa ti Igbagbọ, nigba ti imọlẹ Ihinrere di okunkun ni ayé, iṣẹẸmi Mimọ dasẹ ni akoko yii. Ni nnkan bi ọdun diẹ sẹyin ni a tun ri ifarahàn iṣẹẸmi Mimọ gẹgẹ bi ti iṣaaju ati pẹlu agbára kan naa. Martin Luther ni o múẹkọ idalare nipa igbagbọ pada bọ si ayé lẹyin ti awọn ti n pe ara wọn ni onigbagbọ nigba nì ti gboju fòó dá, ti o si ṣe pe awọn iba eniyan diẹ nihin ati lọhun kaakiri nikan ni o fara mọẹkọ yii ni akoko okunkun biribiri nipa Igbagbọ. Nipa titẹle imọlẹ ti o mọ si ipa ọna wọn ni ayé igba ti wọn, John ati Charles Wesley fi tọkantọkan wáỌlọrun, awọn ni Ọlọrun si lò lati múẹkọ isọdimimọ patapata pada bọ si ayé. Ni akoko ti ebi ẹmi n pa awọn eniyan, nigba diẹṣaaju ọjọ kẹsan oṣu kẹrin ọdun 1906, Ọlọrun pese awọn eniyan kan ti o wà ni ilu Los Angeles ni Amẹrika silẹ lati ri iriri iṣisẹ kẹta ti Onigbagbọ, ti i ṣe Ẹmi Mimọ, gbà. Gẹgẹ bi a ti n ka asọtẹlẹ Wolii Joẹli, a le ri i daju pé a fi itujade Ojo Arọkuro pamọ de igba ikẹyin, akoko ti o ṣaaju ti o si fara kọỌjọ nla Oluwa.
Nipasẹọrọ iwaasu Peteru ni Ọjọ Pẹntekọsti, o hàn gbangba pé awọn Keferi ni anfaani lati gba Ẹmi Mimọ gẹgẹ bi awọn Ju pẹlu. Ori iwe yii ati gbogbo Iwe Mimọ fi yé ni pẹlu pé gbigba agbara Ẹmi Mimọ kò pin sọdọ awọn Keferi nikan bẹẹ ni a kò si ni fi du awọn Ju pẹlu. Nipa imisi Ẹmi Mimọ, Esekiẹli sọ bayii pe:
“Nigbana ni emi o fi omi mimọ wọn nyin, ẹnyin o si mọ: emi o si wè̩ nyin mọ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin.
“Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin.
“Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rin ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si ma ṣe nwọn” (Esekiẹli 36:25-27).
A sọ fun ni pato pe akoko ti asọtẹlẹ yii ba n ṣẹ, ani ti o ṣe pataki fun anfaani awọn Ju, ni akoko ti a o mu awọn Ju pada bọ sipo – nigba ti a o sọ Kristi di mimọ ninu awọn Ju niwaju awọn keferi (Esekiẹli 36:23). Akoko yii ki i ṣe igbà miiran bi kòṣe ỌjọOluwa! Kò si akoko miiran ṣaaju igbà yii ti awọn Ju yoo mọ Kristi gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala wọn, ti wọn yoo si gba Ọlọrun gẹgẹ bi Ọlọrun wọn, ti wọn yoo si sin In ni otitọọkàn. A le beere pe, iṣẹẹmi wo ni a o ṣe fun wọn ni akoko yii? A o ri esi si ibeere yii bi a ti n ṣe aṣaro lori awọn ẹsẹ Bibeli ti a kọ soke yii.
“Omi mimọ” ni a o fi wọn awọn Ju, a o si wè̩ wọn mọ kuro ninu gbogbo ẹgbin ati oriṣa wọn. Eyi ki i ṣe ohun miiran bi kòṣe iriri idalare ati idariji è̩ṣẹ wọn. Nipa ọgbọn Ọlọrun ni a fi yan awọn ọrọ ti o wà ninu Iwe Mimọ ati ninu ọrọ asọtẹlẹ yii: nigba ti O sọ pe, “Emi o fi ọkàn titun fun nyin,” ọrọ ti o tẹle e ni eyi “pẹlu” lati fi hàn wi pe lẹyin ti a ti dari ẹṣẹ awọn Ju ji wọn, wọn yoo tun ni iriri miiran pẹlu eyi ti wọn ti ni tẹlẹ. Ninu iriri keji yii a o paarọọkàn wọn, a o si dáẹmi titun sinu wọn. Eyi pẹlu kò lodi si awọn ibomiran gbogbo ninu Bibeli, nitori pé eto Ọlọrun ni pé gbogbo awọn ti a ba gbalà kuro ninu è̩ṣẹ wọn ni lati tè̩ siwaju lati ni iriri iṣẹ oore-ọfẹ keji -- Isọdimimọ patapata. Nitori naa, a o sọ awọn Ju di mimọ lẹyin ti wọn bá ti báỌlọrun laja.
S̩ugbọn imupadabọ sinu ifẹỌlọrun kò le doju ami bi kòṣe pé wọn bá gba gbogbo ibukun ẹmi ti Ọlọrun n fi fun gbogbo ẹni ti o bá wá sọdọ Rè̩. Nitori naa, bi a ti n ka iyoku asọtẹlẹ ti a n ṣe aṣaro lé lori yii, a ri i pe awọn Ju pẹlu yoo ni anfaani lati gba Ẹmi Mimọ gẹgẹ bi awa ti a wà ni akoko Arọkuro Ojo yii. Ọlọrun wi pe, “Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin.”
A fẹ ki a ṣe akiyesi bi a ṣe lo awọn ọrọ meji ti tadawa ootẹ wọn dúdú rara wọnyi. “Si” ti a lo fi hàn pe iriri miiran pẹlu iriri meji ti wọn ti gbà tẹlẹ ni eyi, gẹgẹ bi “pẹlu” ti fi hàn pe gbigba isọdimimọ patapata yatọ si iriri idalare tabi idariji è̩ṣẹ wọn. Iriri kẹta ni fifi Ẹmi Mimọ ati ina wọ ni! “Ninu” pẹlu jé̩ọrọ ti o ni itumọ pataki nihin, nitori pé nigba ti Jesu ṣe ileri lati rán Ẹmi Mimọ, O wi pe, “Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mā ba nyin gbé titi lailai, Ani Ẹmi otitọ nì; ...nitoriti o mba nyin gbe, yio si wàninu nyin” (Johannu 14:16, 17). Ranti pẹlu pé awọn Ju ni Kristi n bá sọ awọn ọrọ wọnyi ati pé wọn kò mọ pé awọn Keferi ni awọn ọrọ naa tọka si bi kòṣe lẹyin Ọjọ Pẹntikọsti!
Nihin, ninu Majẹmu Laelae a n ri awọn ileri Majẹmu Titun ati asọtẹlẹ awọn ibukun ẹmi ti Majẹmu Titun. A kò fi awọn ibukun wọnyi pamọ fun awọn eniyan diẹ nikan bi kòṣe fún gbogbo eniyan “fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu: nitori ojusaju enia kò si lọdọỌlọrun” (Romu 2:10, 11).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni a mọ nipa Wolii Joẹli?
- Ki ni kókó asọtẹlẹ Joẹli? Ọjọ nla wo ni a mẹnu kàn ninu awọn ori iwe wọnyi?
- Awọn wolii Ọlọrun miiran wo ni o sọ asọtẹlẹ nipa ituka awọn Ọmọ Israẹli?
- Ninu Isaiah ori kin-in-ni a kà nipa isin ti kò té̩Ọlọrun lọrun. Sọ ohun ti o ṣe danindanin lati mú ki isin wa jé̩ itẹwọgbà lọdọỌlọrun.
- Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi ni ifẹ si awọn Ọmọ Israẹli pọ tó bẹẹ?
- Sọ awọn ibukun ti a o fi fun awọn Ọmọ Israẹli ni akoko imupadabọ sipo wọn ni kikun.
- Njẹ orilẹ-ède Israẹli ti o wà lakoko yii ni imuṣẹ kikun nipa awọn asọtẹlẹ ti a sọ nipa ifidimulẹ orilẹ-ède naa ni ayé? Bi eyi kò ba ri bẹẹ, sọ ohun ti o kù lati ṣe.
- Irú ipá wo ni Israẹli yoo kó ninu ijọba Ẹgbẹrun Ọdún ti Kristi?
- Awọn ta ni yoo duro niwaju Ité̩ Idajọ Funfun lati gba idajọ?
- Nibo ni a o dari awọn ti a bá dá lẹbi nibi itẹ Idajọ Funfun si?