Iṣe Awon Apọsteli 12:1-23

Lesson 323 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi ti nri enia buburu, ẹni iwa-ika, o si fi ara rè̩ gbilẹ bi igi tutu nla. S̩ugbọn o kọja lọ, si kiyesi i, kò si mọ: lõtọ emi wá a kiri, ṣugbọn a kò le ri i” (Orin Dafidi 37:35, 36).
Cross References

I Inunibini Hẹrọdu si Awọn Apọsteli

1. Jakọbu ni Apọsteli kin-in-ni ti o kú ikú ajẹriku, Iṣe Awọn Apọsteli 12:1, 2; 8:1

2. Peteru ni Hẹrọdu si tún nawọ mu lati té̩ awọn Ju lọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 12:3; Galatia 1:10

3. Herọdu fi Peteru sinu tubu, o n gbero lati pa á lẹyin Ajinde, Iṣe Awọn Apọsteli 12:4; Marku 14:2

II Idasilẹ Peteru jé̩ Idahun si Adura

1. A gbadura lai sinmi fun Peteru, Iṣe Awọn Apọsteli 12:5; Luku 18:1; Romu 1:9; 1 Tẹssalonika 5:17; 2 Timoteu 1:3

2. Angẹli Oluwa ji Peteru loju oorun, ninu ide ati labẹ awọn ẹṣọ, Iṣe Awọn Apọsteli 12:6, 7

3. Peteru bọ kuro ninu ẹwọn a si paṣẹ fún un lati tẹle angẹli naa, Iṣe Awọn Apọsteli 12:8

III IpadabọPeteru si Ile Adura

1. Bi o ti n lọ si igboro, oye rẹṣi, o si mọ pé angẹli ni o wá dá oun silẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 12:9-11

2. Bi o ti de ile nibi ti ọpọ eniyan n gbadura, o kan ilẹkun, Iṣe Awọn Apọsteli 12:12, 13; 10:30

3. Roda fi hàn pé oun ni igbagbọ ju awọn iyoku lọ, Iṣe Awọn Apọsteli 12:14-17; Luku 18:17

IV Hẹrọdu Kú IkúẸsin

1. A pa awọn oluṣọ nitori ọna àrà ti Peteru gbà jade, Iṣe Awọn Apọsteli 12:18, 19

2. Hẹrọdu sọọrọ didun fun awọn eniyan ni Kesarea, Iṣe Awọn Apọsteli 12:20-22

3. Idin jẹọba, nitori kò fi ogo fun Ọlọrun Ọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 12:23; Jobu 24:20

Notes
ALAYE

Aláṣewu Eniyan

Hẹrọdu ti o pa Jakọbu (Jakọbu ni ẹni kin-in-ni ti o kú ikú ajẹriku ninu awọn Apọsteli) jé̩ọmọọmọ Hẹrọdu ti o paṣẹ pe ki a pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ ni Bẹtlẹhẹmu ni ireti ati pa Jesu. “O si fi idà pa Jakọbu arakunrin Johannu. Nigbati o si ri pe, o dùnmọ awọn Ju, o si nawọ mu Peteru pẹlu.” Iranṣẹ Eṣu ni ẹnikẹni ti o ya òṣonu to bẹẹ ti yoo maa pa eniyan lati le té̩ awọn eniyan lọrun! Hẹrọdu Antipa pa Johannu Baptisti ki o ba le té̩ọmọbinrin Hẹrọdia lọrun. Pilatu fi Jesu lé awọn eniyan lọwọ lati kan An mọ agbelebu ki o ba le té̩ awọn olori alufaa ati awọn alaṣẹ lọrun. Fẹliksi fi Paulu sinu ide lati té̩ awọn Ju lọrun; o yá Fẹstu pẹlu lara lati té̩ awọn Ju lọrun ju ati ṣe idajọ ododo lọ.

Gbogbo awọn ti n du u lati wu eniyan a saba maa mu Ọlọrun binu. Ohun ti awọn Apọsteli duro le lori ni pe, “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun jù ti enia lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:29). Awọn oṣiṣẹ ti a gbà si ibi iṣẹ ni lati ranti ỌrọỌlọrun ti o sọ fun ni wi pe ki a maa gbọran “ki iṣe ni arojuṣe, bi awọn alaṣewù enia; ṣugbọn ni otitọ inu, ni ibè̩ru Ọlọrun: Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mā fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, ki si iṣe fun enia; ki ẹ mọ pe lọwọ Oluwa li ẹnyin ó gbàère ogun: nitori ẹnyin nsin Oluwa Kristi” (Kolosse 3:22-24).

Ifẹ Oluwa ni pe ki oṣiṣẹ ki o ṣiṣẹ kárakára ni ibi iṣẹ lai si imẹlẹ, ọga iṣẹ i ba wà ni tosi tabi bẹẹ kọ. Iwa ti awọn oṣiṣẹ n hù ni pé ki wọn tẹ apa mọ iṣẹ diẹ si i nigba ti ọga agba bá wà ni tosi. Oju Oluwa n wo wa ni gbogbo igbà; ohunkohun ti o wù ki ọmọỌlọrun le maa ṣe, o ni lati ṣe e gẹgẹ bi si Oluwa ki i ṣe lati wu eniyan. Bi o tilẹ jẹ pe ọdọ eniyan ni a ti n gba owo-ọya, bi a ba ṣiṣẹ “gẹgẹ bi awọn ẹrú Kristi, ẹ māṣe ifẹỌlọrun lati inu wá; ẹ mā fi inurere sin bi si Oluwa, ki si iṣe si enia.” Ọlọrun ṣe ileri pe, “ohun rere kohun rere ti olukuluku ba ṣe, on na ni yio si gbà pada lọwọ Oluwa” (Efesu 6:6-8).

Nigba miiran ninu iṣẹ Oluwa, awọn ẹlomiran a maa ni ifẹ lati ṣe awọn iṣẹ wọnni ti awọn eniyan le ri, ṣugbọn wọn a maa ṣá iṣẹ wọnni ti o wà ni ikọkọ tì. Jesu sọ fun ni pe a ki yoo ri èrè gbà lọdọ Baba wa ti n bẹ ni ọrun fun iṣẹ wọnni ti a ṣe fun àṣehàn eniyan. Oṣiṣẹ nì ti o n ba iṣẹ rẹ lọ wẹrẹ-wẹrẹ lai fi àṣehàn eniyan si i, yoo ni èrè ti o pọ ju ti ẹni ti o n ṣiṣẹ nitori ki a ba le ri i.

Inunibini

Ni akoko Ajinde tabi igbà Ajọ Irekọja, ni Hẹrọdu gbogun dide lati pọn Ijọ loju. O di ọdun mẹwaa geere lẹyin inunibini kin-in-ni ninu eyi ti a sọ Stefanu ni okuta pa ti IjọỌlọrun, afi awọn Apọsteli si tuka. Nisisiyi ọta fi aake le gbongbo IjọỌlọrun ani lati pa awọn Apọsteli mejila. O ti bẹrẹ si ṣe eyi nitori ninu awọn Apọsteli mẹta ti o fara mọ Kristi timọtimọ, a ti pa Jakọbu a si ti fi Peteru sinu tubu lati pa á. Awọn eniyan Ọlọrun a maa fi ara gbá inunibini. “Gbogbo awọn ti o fẹ mā gbé igbé iwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini” (2 Timoteu 3:12). Nigba ti Paulu n sọ nipa awọn inunibini ti o faradà, o fi ọrọ yii kun un wi pe: “Oluwa si gbà mi kuro ninu gbogbo wọn” (2 Timoteu 3:11).

Idande

“Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rè̩ si ṣi si igbe wọn” (Orin Dafidi 34:15). Ijọ fi itara gbadura nigba ti Peteru wà ninu tubu ti a fi ẹwọn meji de e laaarin awọn ọmọ-ogun meji. Eyi jé̩ iṣọra ilọpo meji, nitori pe tẹlẹ ri ọmọ-ogun kan pere ni wọn n de onde pọ mọ. Ọmọ-ogun mẹrindinlogun ni o n ṣọ Peteru bi ọjọ ti a o pa a ti n sunmọ etile. S̩ugbọn Ọlọrun gbọ adura awọn olododo, O si rán angẹli Rè̩ lati dá Peteru silẹ. Igba melomelo ni Oluwa ti lo awọn è̩dáọrun wọnyi lati da eto awọn eniyan buburu rú!

Awọn Angẹli

Nigba kan ṣaaju eyi, nigba ti Peteru wà ninu tubu pẹlu awọn Apọsteli miiran, angẹli Oluwa ṣi ilẹkun ile tubu o si mú awọn Apọsteli naa jade lai jẹ ki o di mimọ fun awọn oluṣọ pé wọn ti lọ. Wo bi ipaya awọn oluṣọ naa yoo ti pọ tó nigba ti awọn oniṣẹ dé ti wọn si ri i pe tubu ofifo ni wọn n ṣọ. Angẹli Oluwa yi okuta kuro nigba ti Jesu jade kuro ninu iboji. “Nitori è̩ru rè̩ awọn oluṣọ wariri, nwọn si dabi okú” (Matteu 28:4). Ọlọrun ran angẹli Rè̩ lati gba Daniẹli kuro ni ẹnu awọn kiniun. Paulu beere nipa awọn angẹli bayi pe, “Ẹmi ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mā jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?” (Heberu 1:14).

Igbẹkẹle Wa ninu Ọlọrun

Nigba miiran Ọlọrun a maa fi aye silẹ ki a dán wa wo, ṣugbọn ki yoo jẹ ki o ju bi a ti le gbà lọ. O fi aye silẹ ki a gbé Daniẹli sinu iho kiniun, ṣugbọn o di kiniun ni ẹnu. A gbé awọn ọmọ Heberu mẹta sinu ina ileru ṣugbọn ina kò ni agbára lori ara wọn. A fi Peteru pamọ sinu tubu titi akoko ti wọn fẹ pa a fi kù fẹẹfẹẹ, ṣugbọn Ọlọrun rán angẹli Rè̩ lati gba a. Nipa awọn apẹẹrẹ wọnyi, Ọlọrun n kọ awọn ọmọ Rè̩ lati gbe ẹkẹ wọn le E. A le mu wa lọ si bebe iku ṣugbọn bi a ba rọ mọỌlọrun, Oun yoo ko wa yọ pẹlu ayọ iṣẹgun.

Aigbagbọ

O ṣoro fun ọpọlọpọ ninu wa lati mọ bi itọju Ọlọrun lori awọn ti Rẹ ti pọ tó. Nigba ti angẹli ni lu è̩gbé̩ Peteru pé̩pé̩ ti o si mu un jade kuro ninu tubu, Peteru rò pé ala ni oun n la. Nigba ti Roda sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pé Peteru wa ni ẹnu-ọna wọn wi pe, “Angẹli rè̩ ni.” Eredi ti wọn fi pejọ pọ ni lati gbadura fun idasilẹ Peteru, ṣugbọn nigba ti Ọlọrun dá Peteru silẹ, ẹnu yà wọn. Iyalẹnu ni ọna ti Ọlọrun n gba fi dahun adura ti O si fi n ṣe iṣẹ iyanu. Nigba ti a ba ri bi Ọlọrun ti n ṣiṣẹ ribiribi bi o tilẹ jẹ pe igbagbọ awọn eniyan Rè̩ kere, bawo ni iṣẹ iyanu i ba ti pọ tó bi igbagbọ wa ba pọ ju bayi lọ ti a si fi gbogbo ọkan gba ileri Rè̩ gbọ?

Jesu wi pe, “Lõtọ ni mo wi fun nyin, bi ẹnyin ba ni igbagbọ ti ẹ kò ba si ṣiyemeji, ẹnyin ki yio ṣe kiki eyi ti a ṣe si igi ọpọtọ yi, ṣugbọn bi ẹnyin ba tilẹ wi fun òke yi pe, S̩idi, ki o si bọ sinu okun, yio ṣẹ. Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bère ninu adura pẹlu igbagbọ, ẹnyin o ri gbà” (Matteu 21:21, 22). Nigba miiran Jesu wi fun ọkunrin kan pe, “Bi iwọ ba le gbagbọ, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ” (Marku 9:23). Awa i ba le ni iru ọkan ti ó wà ni ookan àya ọkunrin nì ti o fi omije wi pe, “Oluwa, mo gbagbọ; ràn aigbagbọ mi lọwọ” (Marku 9:24). Ẹ jẹ ki a ṣe bi Apọsteli ni ti o wi fun Oluwa pe, “Busi igbagbọ wa” (Luku 17:5).

Igberaga

Hẹrọdu wọ aṣọ igunwa o si joko lori itẹ rè̩, ọkan rè̩ gbega soke nitori ọrọ didun ti o ti sọ. O ka ara rè̩ si ju bi o ti yẹ lọ nigba ti o gbọ bi awọn eniyan ti n kokiki rè̩ ti wọn n wi pe “Ohùn ọlọrun ni, ki si iṣe ti enia.” Angẹli Oluwa ni o lu Peteru pẹpẹ ti o si yọọ jade kuro ninu tubu; ṣugbọn nigba ti angẹli Oluwa lu Hẹrọdu, idin jẹẹ, o si kú. “Enia lasan a sa ma fẹ iṣe ọlọgbọn, bi a tilẹ ti bi enia bi ọmọ kẹtẹkẹtẹ” (Jobu 11:12). Ki ni eniyan ti yoo fi maa gbé ara rè̩ ga nigba ti oun kò le ni ohun kan bi kòṣe ohun ti Ọlọrun ba fi fun un tabi ti O mu ki o ṣe e ṣe fun un lati ni? Ọlọrun wipe, “Irera, ati igberaga ... ni mo korira” (Owe 8:13). “Irera aiya rẹ ti tàn ọ jẹ, iwọ ti ngbe inu pàlapála apáta, ibugbe ẹniti o ga: ti o nwi li ọkàn rè̩ pe, Tani yio mu mi sọkalẹ? Bi iwọ tilẹ gbe ara rẹ ga bi idi, ati bi iwọ tilẹ té̩ itẹ rẹ sārin awọn irawọ, lati ibẹ li emi o ti sọọ kalẹ, ni OLUWA wi” (Obadiah 3:4).

Igberaga lé Nebukadnessari kuro laarin eniyan lati báẹranko gbé ninu igbé̩. Igberaga ni o gba ijọba Saulu kuro lọwọ rè̩ ti o mu ki o tikalara rè̩ pa ara rè̩. Igberaga ni o le Hamani kuro ni aafin ọba ti a si fi ori rè̩ kọ sori igi. Igberaga ni o le Lusiferi agberaga lati Ọrun Rere lọ si ọrun apaadi. Igberaga ni o mu ki Hẹrọdu ba ikú buburu pade lori itẹ rè̩. “Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rè̩ (Ọlọrun) (1 Kọrinti 1:29). Ki Ọlọrun ràn wa lọwọ lati le rẹ ara wa silẹ niwaju Rè̩! “Alailere ọmọ-ọdọ ni wa” (Luku 17:10).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ bi awọn Hẹrọdu ti o wà ninu Bibeli ti jé̩ si ara wọn.
  2. Ki ni ṣe ti Hẹrọdu fi Peteru sinu tubu?
  3. Ọmọ-ogun meloo ni a fi ṣọ Peteru?
  4. Ọna miiran wo ni a gbà lati ri i daju pe Peteru kò lè salọ?
  5. Bawo ni angẹli naa ti duro ti Peteru pé̩ tó?
  6. Ki ni awọn ohun ti o ya ni lẹnu ninu idasilẹ Peteru?
  7. Nibo ni Peteru kọ lọ lẹyin ti a ti dá a silẹ?
  8. Nibo ni a gbé tun ri Peteru lẹyin naa, gẹgẹ bi ohun ti a sọ fun ni nipa rè̩?
  9. Ki ni fi hàn pé aigbagbọ wà lọkan awọn ti o n gbadura yii?
  10. Ki ni ṣe ti angẹli fi lu Hẹrọdu?