Iṣe Awọn Apọsteli 11:27-30;12:24, 25; 13:1-12

Lesson 324 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹniti o ṣānu fun talaka OLUWA li o win; ati iṣeun rè̩, yio san a pada fun u” (Owe 19:17).
Cross References

I Isin Otitọ

1. Wolii Agabu sọ fun awọn ará ti o wà ni Antioku pe iyan nla kan n bọ wáa sori ayé, Iṣe Awọn Apọsteli 11:27, 28; 21:10, 11; 20:23

2. Awọn ọmọ-ẹyin gẹgẹ bi agbára wọn fi è̩bùn fun awọn ará ti o wà ni Judea nitori aini wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 11:29, 30; Isaiah 58:7; Iṣe Awọn Apọsteli 20:35; Jakọbu 2:15, 16; 2 Kọrinti 9:12

3. Barnaba ati Saulu múè̩bun Ijọ Antiọku lọ si Jerusalẹmu, Iṣe Awọn Apọsteli 11:30; 1 Kọrinti 16:3, 4

4. O jé̩ẹkọ Bibeli lati pese fun aini awọn ẹni ti a ti ipasẹ rè̩ ni ibukun ti ẹmi, Romu 15:25-28; 1 Kọrinti 16:1-4; 2 Kọrinti 8:1-24; 9:1-15; Galatia 2:10; Iṣe Awọn Apọsteli 24:17

5. Barnaba ati Saulu pada bọ lati Jerusalẹmu, wọn mu Johannu Marku lọwọ wá, Iṣe Awọn Apọsteli 12:24, 25

II Awọn ti Ọlọrun Yàn

1. Ni Antioku, Ẹmi Mimọ yan Barnaba ati Saulu sọtọ fun iṣẹỌlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 13:1-3; 10:19, 20; 16:6; 22:21

2. Bi a ti rán wọn lọ lati ọwọẸmi Mimọ Barnaba ati Saulu ati awọn iyoku lọ si Saleukia, lẹyin naa si Kipru wọn n waasu ni sinagọgu ni Salami, Iṣe Awọn Apọsteli 13:4, 5

3. Awọn ọmọ-ẹyin fi Salami silẹ, wọn kọja lọ si Pafo nibi ti wọn gbé waasu Ihinrere, Iṣe Awọn Apọsteli 13:6

III A Kọjuja Si Ihinrere

1. Sergiu Paulu, baalẹ ilu naa fé̩ ki awọn ọmọ-ẹyin waasu Ihinrere fun oun, Iṣe Awọn Apọsteli 13:6, 7; Marku 6:20; Luku 23:8; Iṣe Awọn Apọsteli 25:22

2. Elima oṣó tako iwaasu awọn ọmọ-ẹyin, o si gbiyanju lati yi Sergiu Paulu lọkan pada kuro ni ti igbagbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 13:8; 2 Timoteu 3:8, 9; 4:14, 15; Jeremiah 28:15-17

3. Paulu bá Elima wi fun itanjẹ rè̩, Elima si di afọju, Iṣe Awọn Apọsteli 13:9-11; Ẹksodu 9:3; 1 Samuẹli 5:6-9

4. Ẹnu ya baalẹ si ohun ti o ṣẹlẹ, o si gba Oluwa gbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 13:12; 19:17, 20; Matteu 27:54; Luku 7:16

Notes
ALAYE

Pipese fun Awọn Ará

Ni Antioku, nibi ti a ti kọ pe awọn ọmọ-lẹyin Jesu Kristi ni Kristiani, wolii Oluwa kan ti a n pe orukọ rè̩ ni Agabu sọ asọtẹlẹ nipa iyan nla ti o n bọ wá mú. O sọ asọtẹlẹ pé iyan naa yoo mú ká gbogbo ayé ati pe yoo mú dé Jerusalẹmu pẹlu. Dajudaju awọn ọmọlẹyin Jesu ti o wà nibẹ yoo ri ipọnju nipa iyan naa pẹlu. Wọn kò ni ọrọ gẹgẹ bi Ijọ, eyi yoo si mú ki wọn fara gba ninu iyan naa nitori pe wọn kò ni lagbara lati ra ounjẹ. Asọtẹlẹ Agabu nipa ipọnju ti o n bọ wá bá ayé rú ifẹọkàn awọn ọmọ-ẹyin ti ó wà ni Antioku soke lati mú ohun kan ṣe. Eredi rè̩ ti Ọlọrun fi rán asọtẹlẹ naa jade ni eyi, ọna yii ni o si fé̩ lò lati pese fun aini awọn arakunrin ti o wà ni Jerusalẹmu. Olukuluku awọn ọmọ-ẹyin si pinnu lati ṣe iranwọ gẹgẹ bi agbára rè̩ ti tó.

Ki iṣe ohun titun ni pe ki awọn eniyan mimọỌlọrun pese fun aini awọn ará ninu Oluwa, ki wọn si fi ohun-ini wọn pese fun ẹnikẹni ti o ṣe alaini. Nigba gbogbo ni Jesu n tọka si ojuṣe awọn ọlọrọ si awọn alaini. O fi ara Rè̩ṣe apẹẹrẹ ninu iṣẹ aanu nitori ti O sọ ara Rè̩ di alaini ki awa ki o le di ọlọrọ (2 Kọrinti 8:9).

Jesu sọ fun ijoye ọlọrọ kan nigba kan pe, bi o ba fé̩ jogun iye ainipẹkun, o ni lati ta ohun gbogbo ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talaka, ki o wá, ki o si maa tọ Oun lẹyin (Wo Matteu 19:21). Ohun ti Jesu n fẹ lọwọọdọmọkunrin yii ni pé ki o ni ọkàn aanu ati iṣoore nipa fifun awọn alaini ninu ọpọọrọ rè̩. Idanwo yii wá siwaju rè̩ lati mọ bi ẹsin ti jẹé̩ lọkàn tó, ṣugbọn o ṣe ni laanu pe o kunà, eyi si fi hàn pé isin rè̩ kò nilaari. (Ka 1 Johannu 3:16-18 ati Jakọbu 2:15, 16). Eyi yii ati awọn ẹsẹ miiran lati inu Iwe Mimọ fihàn fun ni pe ki a lawọ si talaka ati alaini, pàápàá jù lọ awọn ti i ṣe ti agbole igbagbọ, jé̩ ohun ti awọn eniyan Ọlọrun gbọdọṣe.

Ipinnu awọn eniyan mimọ ni Antioku lati rán iranlọwọ si awọn arakunrin ti o wà ni Jerusalẹmu jé̩ ipilẹ ilana ti gbogbo Ijọ Kristi n tẹle lọjọ oni. Eto ati ilana ti Ọlọrun dá silẹ ti O si fi ọwọ si ni i ṣe. Awọn opitan sọ fun wa pe laaarin ogun ọdún lẹyin naa, igba mẹrin ọtọọtọ ni iyàn mú gidigidi. Opitan kan sọ fun ni pé, ọkan ninu awọn ìyan naa pọ to bẹẹ ti wọn gbà péỌlọrun ni o rán idajọ Rè̩ sori awọn eniyan. Ibi pupọ ni a ti sọ nipa awọn iyan wọnyi ninu Majẹmu Titun. Ni ọdun diẹ lẹyin eyi, Paulu Apọsteli sọrọ pupọ lori ẹkọ ati ilana ṣiṣe iranwọ fun aini awọn eniyan mimọ lati ọwọ awọn wọnni ti o ni lọwọ.

Paulu sọ wi pe awọn ti o ti ri iranwọ nipa ti ẹmi gbà lati ọwọ awọn ẹlomiran jé̩ ajigbese si wọn, bi o ba si ṣe e ṣe, wọn ni lati pese fun aini wọn nipa ti ara. O sọ pe, “Nitori bi o ba ṣepe a fi awọn keferi ṣe alajọni ninu ohun ẹmi wọn, ajigbese si ni wọn lati fi nkan ti ara ta wọn lọrẹ” (Romu 15:27). Awọn ohun ti ẹmi ṣe pataki ju ohun ti ara nitori pe awọn ohun ti ẹmi duro titi lae, ṣugbọn awọn ohun ti a ni nipa ti ara kò wulo mọ lẹyin ikú.

A ni lati ka ori kẹjọ ati ori kẹsan Kọrinti keji ni akatunka fun oye kikún nipa ẹkọ yii. IjọỌlọrun ti o wà ni Kọrinti ti ṣeleri ṣaaju akoko yii lati fi ọrẹ ranṣẹ fun iranlọwọ awọn eniyan mimọ ti o wà ni ilu miiran. Awọn eniyan mimọ ti o wà ni Makedonia ti múọrẹ ti wọn wá. Wọn ṣe alaini pupọ sibẹ wọn ṣe iranlọwọ ju bi a ti lero lọ. Inu rere ati ifẹ wọn si awọn arakunrin wọn nipa ti ẹmi ga pupọ nitori pe ifẹ Kristi n gbé inu ọkàn wọn; wọn si fi tifẹtifẹ múọrẹ wá lati inu ohun ini wọn.

Kọrinti jé̩ ilu nla, awọn eniyan mimọ ti o wà nibẹ si ni ibukun lọpọlọpọ ju ti awọn eniyan mimọ ti o wa ni awọn ijọ iyoku lọ. Paulu sọ bi ijọ ti ó wà ni Makedonia ti lawọ tó bi o tilẹ jé̩ pé wọn jé̩ alaini, ni ireti lati rú ifẹ lati ṣe ohun kan naa soke lọkàn awọn eniyan mimọ ti o wà ni Kọrinti. Ki i ṣe pe Paulu gba awọn eniyan mimọ niyanju lati múọrẹ wọn wa tọkantọkan nikan, fun imoore ati ifẹ nla Ọlọrun ati ipese Rè̩ fun wọn, ṣugbọn o fi hàn fun wọn pe iṣẹ wọn ni lati ṣe. Ni kukuru, Paulu sọ asọye ọrọ naa lọna bayi pe, “Nitori emi kò fẹ ki awọn ẹlomiran wà ni irọrun, ki o si jẹ ipọnju fun nyin, ṣugbọn nipa idọgba, pe ki ọpọlọpọ ini nyin li akoko yi le ṣe ẹkún aini wọn, ki ọpọlọpọ ini wọn pẹlu le ṣe ẹkún aini nyin: ki idọgba ki o le wà: Gẹgẹ bi a ti kọọ pe, Ẹniti o kó pọju, kò ni nkan le; ẹniti o si kó kere ju, kòṣe alainito” (2 Kọrinti 8:13-15).

Ilana Ọlọrun ni pe ki ọmọỌlọrun ti Oun ti pese fun lọpọlọpọ ki o jẹ iranwọ fun awọn arakunrin rè̩ ti kò ni lọwọ tó bẹẹ, bi Ọlọrun bá ti jé̩ ki aini yii di mimọ fún un. Ki Onigbagbọ fawọ iranwọ sẹyin fun arakunrin rè̩ ti o ṣe alaini nigba ti o wa ni agbára rè̩ lati ṣe iranwọ, ki i ṣe ohun miiran bi kòṣe pe o ja arakunrin rè̩ ni ole. (Ka Owe 3:27, 28). IfẹỌlọrun ni pe ki eyi ki o jé̩ọna kan ti a o fi maa pese fun aini awọn ará. Arakunrin tabi arabinrin ti o ni lọwọ lọpọlọpọ ni lati pese fun aini awọn ara ninu Oluwa, nitori pe nigba ti oun naa ba ṣe alaini, awọn ti o ti jé̩ alaini tẹlẹ ri, ṣugbọn ti wọn ti di ẹni ti o ni lọwọ lọpọlọpọ nisisiyi yoo pese fun aini ti oun naa.

Ọlọrun ki yoo fi ojurere wo Onigbagbọ nì ti o ni lọwọ lọpọlọpọṣugbọn ti o kọ lati mú ninu ohun ti Ọlọrun pese fun un lati ṣe iranwọ fun awọn ará. Awọn anikanjọpọn yoo ṣe rere bi wọn ko ba gbagbe ọrọ ti Ọlọrun sọ fun Israẹli pe, “Ma kiyesara rẹ ki iwọ ki o máṣe gbagbéOLUWAỌlọrun rẹ, li aipa ofin rè̩, ati idajọ rè̩, ati ilana rè̩ mọ, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni: Ki iwọ ki o má ba jẹ yó tán, ki o kọ ile daradara, ki o si ma gbé inu rè̩; ati ki ọwọ-ẹran rẹ ati agbo-ẹran rẹ, ki o ma ba pọ si i tán, ki fadakà rẹ ati wurà rẹ pọsi i, ati ki ohun gbogbo ti iwọ ni pọsi i, nigbana ni ki ọkàn rẹ wa gbé soke, iwọ a si gbagbéOLUWA Ọlọrun rẹ ... Iwọ a si wi li ọkàn rẹ pe, Agbara mi ati ipa ọwọ mi li o fun mi li ọrọ yi. S̩ugbọn ki iwọ ki o ranti OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe, on li o fun ọ li agbara lati li ọrọ, ki on ki o le fi idi majẹmu rè̩ ti o bura fun awọn baba rẹ kalẹ, bi o ti ri li oni yi” (Deuteronomi 8:11-14, 17, 18).

Bi o ti ri nipa ipinfunni nipa ti ara, bakan naa ni o ri nipa ti ẹmi. A kò le fi tọkàntọkàn ka Kọrinti keji ori kẹjọ ati ori kẹsan lai jé̩ pe o di mimọ fun ni daju pe kokó ohun ti Paulu n sọ nipa ipinfunni jẹ mọ ipinfunni nipa ti ẹmi pẹlu. Ọrọ naa ti o lọ bayi pe, “Ẹniti o ba fọnrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si fọnrugbin pipọ, pipọ ni yio ká” ni itumọ ti o tobi ti o si dara lọpọlọpọ bi a bá tumọ rè̩ nipa imisi ẹmi Ọlọrun. (Ka Isaiah 55:8-13, ki o si fi ẹkọ yii sọkan nigba ti o ba n ka a).

Ipe Si Iṣẹ

Paulu ati Barnaba ti a ti ọwọ wọn mu ọrẹ ijọ Antioku lọ si Jerusalẹmu, mú Johannu Marku pẹlu wọn nigba ti wọn n pada bọ si Antioku. Lẹyin ipadabọ wọn, wọn n jọsin fun Oluwa pẹlu adura ati aawẹ. Laaarin ijọsin yii, Ẹmi Mimọ sọ bayi pé, “Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si.” Lẹyin aawẹ ati adura, awọn ọmọ-ẹyin yan Barnaba ati Saulu nipa gbigbéọwọ lé wọn, wọn si rán wọn lọ fun iṣẹỌlọrun pẹlu adura, wọn si sure fun wọn.

O yẹ ki a ṣe akiyesi pe nigba ti Oluwa pe Barnaba ati Paulu si iṣẹỌlọrun, o di mimọ fun awọn alakoso ati awọn eniyan mimọ ti o wa ni Antioku. Ọlọrun ki i yan oṣiṣẹ ati awọn iranṣẹ Rè̩ si iṣẹ lai jé̩ ki ifẹ Rè̩ki o di mimọ fun awọn alabojuto tabi awọn alakoso ti o wa lori Ijọ. Bi Ọlọrun kò bá jé̩ ki ifẹ Rè̩ ki o di mimọ fun awọn ti o jẹ alaṣẹ lori IjọỌlọrun, yoo mú rudurudu lọwọ. “Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun ohun rudurudu” (1 Kọrinti 14:33). Bi ipe naa bá ti ọdọỌlọrun wa, Oun yoo jẹ ki ipè na di mimọ fun alakoso ati awọn olori. Li ọna bayi, nigba ti ẹni ti o jẹ ipe naa ba lọ si ibi iṣẹ ti a pe e si, yoo ni itilẹyin adura awọn eniyan mimọ ati ti IjọỌlọrun. Bi ẹni kan bá wà ti kò ni itilẹyin alakoso, o yẹ ki o fi ara balẹ lati kiyesi ipe rè̩ lati mọ daju pé lati ọdọỌlọrun ni.

Nigba ti Ọlọrun bá pe ẹni kan ti O si rán an lọ lati ṣiṣẹ fun Oun, oṣiṣẹ naa le lọ lai bẹru ohunkohun ti o le de nitori ti o wa ni ọgangan ifẹỌlọrun. Bi o tilẹ jé̩ pé eṣu yoo gbogun, dajudaju iṣẹgun daju nitori ti Ọlọrun yoo tẹlẹ dèé.

Jesu, nigba ti O n sọ nipa awọn eniyan ti Rẹ wi pe: “O si pè awọn agutan tirè̩ li orukọ, o si ṣe amọna wọn jade. Nigbati o si mu awọn agutan tirè̩ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ ohùn rè̩” (Johannu 10:3, 4). Ko le ṣai ya ni lẹnu ọpọlọpọ iṣẹ ati akitiyan ti awọn eniyan ti fi ṣofo nipa igbekalẹẹsin nitori pe ilana eniyan ni ki i ṣe eto Ọlọrun. Ti Ọlọrun ni iṣẹ igbala ọkàn; gẹgẹ bi Balogun Igbala wa, Oun yoo mu awọn eniyan Rè̩ dé iṣẹgun ayeraye. Lati fi iwarapapa dawọ le ohunkohun lai si itilẹyin Ọlọrun yoo mu ijatilẹ wa.

Bi Jọṣua ti n mu awọn ọmọ-ogun Israẹli lọ si ilẹ Kenaani, Ọkunrin kan ti o fa ida yọ pade rè̩. Ọkunrin yii sọ fun Jọṣua pe Oun wá gẹgẹ bi Olori-ogun Oluwa. Ọlọrun kò fi Jọṣua silẹ lati fi ọgbọn ati agbára rè̩ṣé̩ ogun naa ṣugbọn Oluwa wà nibẹ lati lọṣaaju rẹ lati fún un ni iṣẹgun. Gbogbo ẹnu ni a le fi sọ bi o ti ṣe danindanin tó fún awọn eniyan Ọlọrun lati duro de Ọlọrun lati mú ifẹ Rè̩ṣẹ ni igbesi-ayé wọn.

Idojukọ Satani

Paulu ati Barnaba, ti Ẹmi Mimọ pè lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun kòṣaigbọràn si ipe naa. Sergiu Paulu, alaṣẹ ilu ti wọn wà, ranṣẹ pèe wọn ki o ba le gbọ nipa Kristi ni ẹnu wọn. Ire ọkàn rè̩ mu un lọkan gidigidi to bẹẹ ti o fi n poungbẹ lati gbọ itan Ihinrere lati ẹnu awọn ti o n kede rè̩.

Eṣu kò ni fi Sergiu Paulu silẹ, gẹgẹ bi kò ti fi awọn ti iṣaaju ati awọn ti o n bọ lẹyin silẹ lai ṣe idena wọn nigba ti wọn bá fé̩ gbọ nipa Ihinrere. Elima oṣo, ẹni ti i ṣe oludamọran Sergiu Paulu, gbiyanju lati yi i lọkan pada kuro ninu igbagbọ. ỌrọỌlọrun kò sọọna ti Elima gba lati ṣe iṣẹ ibi yii, boya o lo è̩tàn ati èké, ni ireti lati mú ki ọkàn baalẹ naa tako Ihinrere, nipa bayi ki o máṣe lè gba otitọ. O lè jẹ pé Elima n jẹ anfaani kan pataki lọdọ Sergiu Paulu eyi ti kò ni bọ si i lọwọ mọ bi baalẹ naa ba di Onigbagbọ. O dabi ẹni pe kò si ẹnikẹni ti o bá fé̩ kọ iṣẹ Eṣu silẹ lati di ero Ijọba Ọlọrun, ti Eṣu ki yoo gbiyanju lati gbogun ti lọnakọna lati mu ki aarẹ ati irẹwẹsi dé ba a nipa igbona ọkan ti o ni lati fi báỌlọrun laja.

Paulu kò duro ki o maa wò, ki o si jé̩ ki ọkàn kan ṣegbe nitori ti eṣu n fé̩ lati ṣe idena igbala ọkàn Sergiu Paulu. O bá Elima wi ni orukọ Oluwa, oju Elima si fọ nitori iwa buburu rè̩. Bi Eṣu bá n ṣe idena iwaasu Ihinrere, gẹgẹ bi Elima ti ṣe, a ni lati bẹỌlọrun ki O sọ idojukọọta di asán, gẹgẹ bi O ti ṣe nigba ti O dide fun iranlọwọ Paulu ati Barnaba. Ija wa ki i ṣe ti ara, bi kòṣe ti ẹmi, awọn ohun ija Onigbagbọ si ni agbára lati wó ibi giga palẹ.

Iru nnkan bayii ṣẹlẹ nigba ti Sennakeribu, ọba Assiria, fi iwe rán awọn ounṣẹ si Hesekiah ọba Israẹli, pe ki Hesekiah ki o fi ilu rè̩ lé oun lọwọ. Sennakeribu gan Ọlọrun Israẹli wi pe Oun yoo dabi ọkan ninu awọn oriṣa orilẹ-ède ti kò le gba ni kuro lọwọ oun. Hesekiah té̩ iwe ipenija yii siwaju Ọlọrun, o si gbadura fún iranwọ. Ọlọrun dahun adura Hesekiah, o si rán angẹli lati ṣe iparun ni ibudo awọn Assiria. Angẹli naa pa ọkẹ mẹsan o le ẹgbẹẹdọgbọn eniyan. Sennakeribu ati ẹgbé̩ ogun rè̩ yi pada lai ta ọfa ati lai wọ aarin ilu. Nigba ti o pada sile, awọn ọmọ rè̩ fi ida paa ni ile oriṣa rè̩.

Idajọ ti o wá sori Elima ya Sergiu Paulu lẹnu lọpọlọpọ, eyi si mú ki o gba Oluwa gbọ. Nigba ti awọn ọmọỌlọrun bá mu iduro wọn fun Oluwa, Ọlọrun yoo fun wọn ni agbára, yoo si fi hàn pe iduro wọn jé̩ iduro otitọ, a o si jere ọkàn fun Kristi.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni awọn ọmọ-ẹyin ṣe mọ pe iyàn nla yoo mú?
  2. Ki ni awọn ọmọ-ẹyin ti o wa ni Antioku pinnu lati ṣe?
  3. Bawo ni a ṣe mọ pe iṣẹ olukuluku Onigbagbọ ni lati ran awọn alaini lọwọ?
  4. Ki ni ṣe ti Paulu ati Barnaba fi Antioku silẹ?
  5. Ọna wo ni Elima gbà lati dena Ihinrere?
  6. Bawo ni Paulu ṣe bori atakò Elima?
  7. Ki ni abayọrisi ibeere Sergiu Paulu lati gbọ nipa Ihinrere?