Iṣe Awọn Apọsteli 13:13-52

Lesson 325 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sārin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọn bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba” (Matteu 10:16).
Cross References

I Si Awọn Ju S̩aaju

1. Awọn ọmọ-ẹyin dé Perga nibi ti Johannu ti fi wọn silẹ; wọn si tun lọ si Antioku ti Pisidia, Iṣe Awọn Apọsteli 13:13, 14

2. Paulu waasu fun awọn Ju ninu sinagọgu ni Ọjọ Isinmi, Iṣe Awọn Apọsteli 13:15; 17:2; Luku 4:16

3. Paulu waasu Jesu Kristi fun awọn Ju, o n fi hàn lati inu Iwe Mimọ pe Oun ni Messia wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 13:16-41; 2:22-36; 3:13-26; 4:11, 12; 5:29, 32

4. Ọpọlọpọ ni otitọ iwaasu Paulu wọ lọkàn, wọn si gba Oluwa gbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 13:42-44

II Ati Si Awọn Hellene

1. Awọn Ju jowu nitori ogunlọgọ eniyan ti o wá gbọ iwaasu Paulu, wọn si sọrọ odi si Ihinrere ati si Paulu, Iṣe Awọn Apọsteli 13:45; 14:2; 17:5, 13, 17, 18

2. Paulu ri i pe awọn Ju kò gba Kristi, o si yi pada si ọdọ awọn Keferi, Iṣe Awọn Apọsteli 13:46-52; 28:25-28; Isaiah 42:6, 7; 49:6; Luku 2:32

3. O jé̩ ohun aigbọdọ máṣe lati kọkọ waasu Ihinrere fun awọn Ju, Iṣe Awọn Apọsteli 13:46; Matteu 10:5, 6; Iṣe Awọn Apọsteli 3:26; Romu 1:16

4. Paulu ati Barnaba gbọn ekuru ẹsẹ wọn si awọn Ju, wọn si lọ waasu Ihinrere fun awọn Keferi, Iṣe Awọn Apọsteli 13:51, 52; 18:6; Matteu 10:14; Marku 6:11

Notes
ALAYE

Iwaasu Ihinrere fun Awọn Keferi

A le ri koko ẹkọ wa ninu ọrọ Paulu ti o lọ bayi pe, “Mo mura tan lati wasu Ihinrere ... nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu” (Romu 1:15, 16). Gẹgẹ bi eto Ọlọrun, Ọlọrun ṣe ilana pe ki awọn Ju tete kọ gbọ Ihinrere Jesu Kristi ṣaaju nitori ti wọn ni “isọdọmọ iṣe, ati ogo, ati majẹmu, ati ifunnilofin, ati isin Ọlọrun, ati awọn ileri; ti ẹniti awọn baba iṣe, ati lati ọdọ awọn ẹniti Kristi ti wá nipa ti ara, ẹniti o bori ohun gbogbo” (Romu 9:4, 5). Eyi kò fi hàn pé awọn Ju nikan ni Ọlọrun ṣe eto pe ki o ri igbala, ki a si ṣá awọn Keferi tì. Igbala wà fun awọn Keferi gẹgẹ bi o ti wà fun awọn Ju; ṣugbọn awọn Ju ni Ọlọrun yàn gẹgẹ bi ohun-elo lati tan ihin igbala kálè̩ ni akọbẹrẹ.

Lati akoko Abrahamu, nigba ti Ọlọrun ṣeleri fun un nipa majẹmu ti O ba a dá wi pe ninu rẹ ni a o ti bukun fun gbogbo idile ayé, Ọlọrun n ba Israẹli lò gẹgẹ bi ẹni kọọkan ati gẹgẹ bi orilẹ-ède. (Wo Galatia 3:8, 9). Ọlọrun n fẹ lò wọn fun ogo Rè̩ ati fun itankalẹ Ihinrere. Gẹgẹ bi orilẹ-ède, wọn jé̩ọlọrùn-lile ati alagidi, wọn kò gba Ẹmi Ọlọrun layè ninu wọn. Ni opin gbogbo rè̩, ni akoko iṣẹ iranṣẹ Kristi, O sọọrọ wọnyi nigba ti O ri i pe awọn Ju, gẹgẹ bi orilẹ-ède, kọ Oun ni àkọtán patapata: “Sawõ, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro: lõtọ ni mo si wi fun nyin, Ẹnyin ki yio ri mi, titi yio fi di akoko ti ẹnyin o wipe, Olubukun li ẹniti o mbọ wá li orukọ Oluwa” (Luku 13:35). Ọrọ wọnyi fi hàn pe igba kan fẹrẹ dopin ati pe lai pẹ jọjọỌlọrun yoo yi pada si awọn Keferi pẹlu ọrọ ilajà, wọn yoo si di igi òroro igbẹ ti a lọ sinu igi òroro rere (Ka Romu 11:17-24). A n mú asọtẹlẹ ti a ti sọ lati ọpọlọpọọdún ṣẹ. Lati igba ayé Mose ni Ọlọrun ti kilọ fun Israẹli nipa ifasẹyin wọn, O si sọ asọtẹlẹ pe, a o waasu Ihinrere fun awọn Keferi, wọn yoo si tẹwọgba a. A kọwe rẹ pe: “Nwọn ti fi ohun ti ki iṣe Ọlọrun mu mi jowú; nwọn si fi ohun asan wọn mu mi binu: emi o si fi awọn ti ki iṣe enia mu wọn jowú; emi o si fi aṣiwere orilẹ-ède mu wọn binu” (Deuteronomi 32:21). Paulu sọ bayii lati inu iwe Isaiah: “Awọn ti kò wá mi ri mi; awọn ti kò bère mi li a fi mi hàn fun” (Romu 10:20).

OtitọỌrọỌlọrun wọnyi ni pe igba pupọ ni Israẹli ti múỌlọrun binu nipa titaku sinu ẹsin ibọriṣa. Ọlọrun sọ wi pe Oun pẹlu yoo mú wọn jowú ni ti pe Oun yoo yi pada si awọn eniyan ti awọn Ju kò fi pe nnkan. Awọn Ju fi ori kunkun taku sinu ero pe anfaani Ihinrere ti Ọlọrun fi fun wọn jé̩ ogún wọn ti Ọlọrun paapaa kò le gbà kuro lọwọ wọn. S̩ugbọn Ọlọrun gba awọn anfaani naa kuro lọwọ wọn; O si gba awọn ibukun miiran lọwọ wọn pẹlu nitori aiṣedeedee wọn. Bakan naa ni Ọlọrun yoo gba ayọ igbala kuro lọwọ Onigbagbọ ti kò bá rin deedee. Siwaju si i, Oun yoo pa orukọẹnikẹni ti o bá dẹṣẹ ré̩ kuro ninu Iwe Iye.

Kò si aniani pe awọn Ju binu gidigidi nitori pe a waasu Ihinrere fun awọn Keferi, gẹgẹ bi ẹkọ wa ati awọn ẹkọ miiran gbogbo ti fi hàn gbangba. Iwaasu Ihinrere fun awọn Keferi ti bẹrẹ, ki yoo si dẹkun titi di igba Ipalarada IjọỌlọrun; ni akoko yii ni Ọlọrun yoo tun yi pada si awọn Ju gẹgẹ bi orilẹ-ède, lati bá wọn lò nipa Messia wọn.

Awọn Keferi Gba Ihinrere

Bi a ti n kẹkọọ ninu Iṣe Awọn Apọsteli, a o ri i bi awọn Ju ti n tako iwaasu Ihinrere Jesu Kristi, ati bi wọn ti kún fún owú tó nitori ti awọn Keferi gbà Ihinrere lọgan. O hàn gbangba pé anfaani awọn Ju ti bọ lọwọ wọn, imọlẹ igbala si ti mọ kedere fún awọn Keferi.

Gẹgẹ bi iṣe awọn Apọsteli yoku, Paulu pẹlu ṣe e ni ọranyan lati kọ tete lọ si sinagọgu tabi ibomiran ti o bá wọ, lati waasu Ihinrere Jesu Kristi fun awọn Ju. Ọlọrun pe Paulu lati jé̩ Apọsteli awọn Keferi, o jẹri si eyi tikara rè̩ bayi pe “Ẹnyin ti iṣe Keferi li emi sa mba sọrọ, niwọnbi emi ti jẹ apọsteli awọn Keferi” (Romu 11:13). Sibẹsibẹ Paulu a maa tọ awọn Ju lọṣaaju lati sọ fun wọn nipa idariji è̩ṣẹ ati pe kò si orukọ miiran ti a fi fun ni labẹỌrun ti a fi le gba eniyan là bi kòṣe orukọ Jesu Kristi. Ilana Ọlọrun ni pe ki a waasu Ihinrere fun awọn Ju ṣaaju, Paulu si tẹle aṣẹ yii patapata. Nigba pupọ ni iwaasu Ihinrere fun awọn Ju kò leso o si n dá rogbodiyan silẹ, ṣugbọn gẹgẹ bi aṣẹỌlọrun, awọn ni a ni lati waasu fun ṣaaju.

Bi o tilẹ jé̩ pe Ọlọrun ti fi Israẹli silẹ gẹgẹ bi orilẹ-ède, sibẹ olukuluku Ju ti o bá ronupiwada è̩ṣẹ rè̩ ti o si yi pada si Kristi le ri igbala ati ibukun gbà lọdọỌlọrun. Pupọ ninu wọn ti yi pada si Kristi ṣugbọn o ṣe ni laanu pe ọpọlọpọ wọn ni kò yi pada. Paulu ati awọn Apọsteli miiran waasu fun awọn Ju lati inu Majẹmu Laelae, wọn si n fi hàn fun wọn gbangba pe Kristi ni Messia ti awọn Ju ti n reti lati ọjọ pipẹ.

Gẹgẹ bi Oluwa ti sọtẹlẹ, awọn Ju kún fún owú gidigidi nitori ti awọn Keferi gba iwaasu Paulu gbọ. Wọn bẹrẹ si sọrọ odi, wọn si n ṣe atako iwaasu Paulu. Paulu ati Barnaba bá awọn Ju wi fun atako ti kò nilaari ti wọn n ṣe, pẹlu ọrọ wọnyi pe: “Ẹnyin li o tọ ki a kọ sọọrọỌlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ si kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun, wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi. Bḝli Oluwa sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbéọ kalẹ fun imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le jẹ fun igbala titi de opin aiye.”

Nigba ti awọn Keferi gbọ pé a o waasu ỌrọỌlọrun fun wọn, wọn yọ, wọn si yin Ọrọ Oluwa logo. Pupọ si gbagbọ si iye ainipẹkun. “A si tàn ọrọ Oluwa ka gbogbo ẹkún na.”

A ka a ninu ẹkọ wa pe Paulu ati Barnaba “gbọn ekuru ẹsẹ wọn si wọn.” Wo ewu nla ti o wà ninu awọn ọrọ kukuru yii! Wọn dọgba pẹlu ọrọ Jesu ti o lọ bayii pe: “Ilu-kilu tabi iletò-kileto ti ẹnyin ba wọ, ẹ wáẹniti o ba yẹ nibẹ ri, nibè̩ ni ki ẹ si gbé titi ẹnyin o fi kuro nibè̩. Nigbati ẹnyin ba si wọ ile kan, ẹ ki i. Bi ile na ba si yẹ, ki alafia nyin ki o bà sori rè̩; ṣugbọn bi ko ba yẹ, ki alafia nyin ki o pada sọdọ nyin. Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọọrọ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ile na tabi ni ilu na, ẹ gbọn ekuru ẹsẹ nyin silẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun ilẹ Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu na lọ” (Matteu 10:11-15).

Ẹ jé̩ ki a fi aigbagbọ orilẹ-ède Israẹli ṣe arikọgbọn. Bi o ti wù ki a mọ nipa eto isin Ọlọrun tó, imọ wa yii ki yoo jamọ nnkan, afi bi a ba fi gbogbo ọkàn wa gbagbọ si ododo, ki a si gbagbọ pe lootọ ati lododo, Ọlọrun ji Kristi dide kuro ninu okú.

Akoko iwaasu Ihinrere fun awọn Keferi fẹrẹ dopin. Nisisiyi awọn Ju n pada lọ si Palẹstini, ilu wọn. Anfaani awọn Keferi fẹrẹ dopin, gẹgẹ bi o ti kọja lọ fun awọn Ju. Jẹ ki a ranti ỌrọỌlọrun ti o wi pe, “Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ ki o máṣe wà ninu ẹnikẹni ninu nyin, ni lilọ kuro lọdọỌlọrun alāye. S̩ugbọn ẹ mā gbà ara nyin ni iyanju li ojojumọ, niwọn igbati a ba n pé e ni Oni, ki a má bā séọkàn ẹnikẹni ninu nyin le nipa è̩tan è̩ṣẹ. Nitori awa di alabapin pẹlu Kristi, bi awa ba di ipilẹṣẹ igbẹkẹle wa mu ṣinṣin titi de opin” (Heberu 3:12-14).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni itumọọrọ yii “Fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu”?
  2. Ki ni ṣe ti Paulu fi n waasu fun awọn Ju ṣaaju?
  3. Ki ni ṣe ti Paulu fi wi pe Apọsteli awọn Keferi ni oun i ṣe?
  4. Awọn ta ni Keferi?
  5. Ki ni ṣe ti Paulu fi gbọn ekuru ẹsè̩ rè̩ silẹ si awọn Ju?
  6. Ki ni ṣe ti awọn Ju fi n jowu Paulu?