Lesson 326 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Tani yio ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi? Ipọnju ni, tabi wahalà, tabi inunibini, tabi iyan, tabi ihoho, tabi ewu, tabi idà?” (Romu 8:35).Cross References
I Paulu On Barnaba, Meji Ninu Awọn Ajihinrere Ọlọrun Ti Wọn Jẹ Oloootọ
1. Paulu ati Barnaba fi igboya waasu Ihinrere fun ọpọ eniyan ni Ikonioni ninu sinagọgu awọn Ju, Iṣe Awọn Apọsteli 14:1; 13:5; 18:19; Johannu 6:59; 18:20; Romu 1:16; 2:9, 10
2. Paulu ati Barnaba n bá iṣẹ wọn lọ fun igba pipẹ ni Ikonioni, nina apáỌlọrun si n bá wọn lọ, O si n jẹri si iṣẹ wọn nibè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 14:3; 4:13, 31; 19:8; Marku 16:17
3. Inunibini ti o ti bẹrẹ lákọkọ mú awọn meji naa rekọja lọ si Listra nikẹyin, Iṣe Awọn Apọsteli 14:2, 4-6; Matteu 10:5-33; 1 Kọrinti 4:10-13; 2 Kọrinti 4:8-10
4. Ni Listra, wọn waasu Ihinrere, wọn si ri iṣẹ iyanu ti a ti ọwọ wọn ṣe, Iṣe Awọn Apọsteli 14:7-10; 3:6-8
5. Gẹgẹ bi eniyan Ọlọrun tootọ, Paulu ati Barnaba kọ fun awọn eniyan lati bọ wọn, wọn tọka wọn si ati maa sin Ọlọrun nikan ṣoṣo, Iṣe Awọn Apọsteli 14:11-18; 12:21-23; 28:6; Matteu 4:10
6. Awọn alaigbagbọ Ju, ninu irunu wọn, mú ki a sọ Paulu ni okuta, Iṣe Awọn Apọsteli 14:19, 20; 2 Kọrinti 11:24-27;
7. 2 Timoteu 3:10-12
8. A da ẹmi Paulu si, oun pẹlu Barnaba si lọ si Derbe lati waasu Ihinrere nibẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 14:20, 21; 5:18, 19; 12:7; 16:26; 1 Samuẹli 17:37; Daniẹli 3:27; 6:22
9. Ni ipadabọ awọn ajihinrere si Antioku, itẹsiwaju pupọ ló wà ninu è̩kọ, pẹlu ifẹsẹmulẹ ati igbagbọ ati imulọkanle ati eto gbogbo laaarin awọn ti o ṣẹṣẹ gbagbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 14:21-28; 1 Timoteu 4:1-5
Notes
ALAYEIrin-Ajo Naa
“Awọn woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ... ati Saulu ... Ẹmi Mimọ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si. Nigbati nwọn si ti gbàwẹ, ti nwọn si ti gbadura, ti nwọn si ti gbe ọwọ le wọn, nwọn si rán wọn lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 13:1-3). Eyi ni ekinni ninu ọpọlọpọ irin ajo Paulu Apọsteli gẹgẹ bi ajihinrere. Ẹkọ yii sọ diẹ ninu awọn ohun ti o ṣẹlẹ ni irin-ajo kin-in-ni yii -- awọn iṣẹlẹ ti Paulu tọka si ninu awọn Episteli ti o kọ lẹyin naa. O wú ni lori lati ka ohun ti a kọ silẹ nipa opin irin-ajo yii. Ọrọ naa lọ bayi pé “nwọn ba ti ọkọ lọ si Antioku, lati ibiti a gbé ti fi wọn le õre-ọfẹỌlọrun lọwọ, fun iṣẹ ti nwọn ṣe pari.”
Awọn eniyan Ọlọrun akọni ọkunrin meji niwọnyi ti o fi ori la ikú ati iṣoro ti irin-ajo igbà nì mú lọwọ, wọn si mú Ihinrere ti Ijọba Ọrun lọ si awọn ilẹ ajeji, ati si awọn ajeji eniyan. Awọn ọkunrin meji ni wọnyi ti Ẹmi Mimọ ti yà sọtọ fun iṣẹỌlọrun, ki i ṣe pe wọn bẹrẹ iṣẹ naa nikan, ṣugbọn wọn kò yi pada kuro ninu ipèỌlọrun bi o tilẹ múẹgàn ati ọpọ iṣoro lọwọ. Ki i ṣe pe a “fi wọn le õre-ọfẹỌlọrun lọwọ fun iṣẹ nā” nikan, ṣugbọn wọn ṣe iṣẹ naa ni aṣeyọri. O yẹ ki a tẹle apẹẹrẹ wọn. O yẹ ki a ṣe akiyesi bi wọn ṣe lo igbesi-ayé wọn ninu iṣẹ pataki yii. O yẹ ki a wò bi wọn ṣe n bá iṣẹỌlọrun lọ, ki awa ba le tẹle apẹẹrẹ wọn ninu iṣẹ ti a fi le awa naa lọwọ lọjọ oni.
“Fun Awọn Ju S̩aju”
S̩aaju ohun gbogbo, a ni lati ṣe akiyesi otitọ yii péỌlọrun ni eto ti o yanju kedere fun iṣẹ Rè̩. Oun ki i fi opin iré ije ti a gbọdọ dé lelẹ fun wa ki O si fi wa silẹ lati tikara wa wáọna ti a o gbà lati fi dé ibè̩. Bi o ba sọ fun wa lati tè̩ siwaju, Oun yoo la ọna silẹ. Bi O ba si sọ fun wa lati maa n ṣó, Oun yoo fi ọna hàn wá. Ọna ki i pe meji bi a ba n tọọna ifẹ Rè̩. Ọna kan ṣoṣo ni o wa ninu eyi ti kò si iṣina. Bi a ba kuna lati tọọna ti Ọlọrun là silẹ, dajudaju Oun yoo ṣe ohun ti O tọ, ninu aanu Rè̩, lati mú wa pada bọ si ojúọna ti Rè̩, bi o bá leke ifẹọkàn wa lati ṣe ifẹ Rè̩ ati lati rin ni ọna Rè̩.
Suuru Ọlọrun si wa pọ nipa oye kukuru ti a ni nipa ifé̩ pipé Rè̩ si wa; bi a bá kùnà, Oun a maa ba wa lò bi ọmọ. S̩ugbọn bi awa bá mọọmọ yi pada kuro ninu ọna Rè̩, ti ọgbọn wa, ilana wa ati ipinnu wa si jọ wa loju, lai pẹ a o ri i pe a kò si labẹ itọju Rè̩ mọ.
Awọn ojiṣẹỌlọrun mejeeji ti o jé̩ péàpò awọn tikara wọn ni wọn ti n ṣe inawo ara wọn yii tẹle ifé̩ ati ilana Ọlọrun patapata. (Ka 1 Kọrinti 8:1-15). Ọlọrun ti mú ki ifẹ Rè̩ di mimọ pe awọn Ju ni a ni lati mú Ihinrere tọ lọṣaaju. Lẹyin naa O tun jé̩ ki o di mimọ pe a ni lati mu un tọ awọn Keferi lọ pẹlu. Awọn kan ninu awọn Ju ti ni anfaani iyebiye lati gba Kristi ni Messia wọn ati lati maa tọỌ lẹyin, awọn diẹ si ti ṣe bẹẹ. S̩ugbọn ọpọlọpọ ni kòṣe bẹẹ, dipo eyi, wọn yàn lati ru ẹbi ikú Rè̩.
Ilana Ọlọrun ni pe awọn Ju ni o ni lati kọ gba anfaani igbala Rè̩ ki wọn ba le tan Ihinrere ká gbogbo ayé. Nigba ti Ọlọrun rán awọn ojiṣẹ Rẹ jade ni akọbẹrẹ lati waasu Ihinrere, a mu ilana yii ṣẹ, nitori pe Ju ni awọn meji wọnyi; bi wọn si ti jade lọ, wọn lọ taara si ọdọ awọn Ju ti o n gbé ni awọn ilu ti o jinna ti wọn kò si ti i gbọ nipa Ihinrere. O tọ ki Ihinrere déọdọ wọn gẹgẹ bi o ti déọdọ awọn ti wọn fi oju ara wọn ri awọn iṣẹ iyanu ati iṣẹ Kristi. Lọna bayi, gbogbo awọn Ju ni o ni anfaani lati ronupiwada ati lati mú ifẹỌlọrun nipa wọn ṣẹ.
Irin ajo wọn kin-in-ni yii fẹrẹ tóẹẹdẹgbẹjọ (1500) mile. Lai fi gbogbo iṣoro ti wọn bá pade pè, wọn n tẹ siwaju titi dé ibi ti a gbé lè sọ nipa ti wọn pé, wọn pari iṣẹ ti Ọlọrun fi lé wọn lọwọ. Irúọkọ oju-omi kékèké ti wọn n lò nigba nì fi kún wahala irin-ajo wọn loju omi. Pupọ irin-ajo naa ni wọn ni lati fi ẹsẹ rin; sibẹ iṣoro ati inunibini ti o wà loju ọna wọn kò fò wọn laya. Wọn fori ti i wọn si tẹra mọ iṣẹỌlọrun ti a fi fun wọn lati ṣe titi wọn fi ṣe e ni aṣeyọri.
Iru Iṣẹ-Iranṣẹ Wọn
Ohun pupọ ni a ni lati kiyesi ninu ẹkọ yi. Lọna kin-in-ni, a kọọ pe, “Nwọn si sọrọ tobḝ, ti ọpọlọpọ ... gbagbọ.” Ninu ọrọ ikẹyin ti Kristi sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ O wi pé, “Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi.” Agbara yii jé̩ọkan ninu ohun ti ẹnikẹni ti o bá fé̩ jé̩ oṣiṣẹ fun Ọlọrun ni lati ni.
NipasẹẸmi Mimọ ni a gbà n jere ọkàn fún Ọlọrun. Lati jé̩ ojulowo oṣiṣẹ fun Ọlọrun a ni lati ni Ẹmi Ọlọrun. Awọn oṣiṣẹ meji wọnyi ni agbara yii. Bi wọn ti n sọrọ, ọpọlọpọ eniyan ni o n yi pada si Ọlọrun. Wọn lo laakaye. Wọn lo ọgbọn ti Ọlọrun fi fun wọn. Wọn sa gbogbo ipa wọn lati rọ awọn eniyan si ipa ti Ọlọrun. Wọn lo gbogbo talẹnti ati ẹbun ti Ọlọrun fi fun wọn. Wọn lo gbogbo nnkan wọnyi pẹlu igbona ọkàn ati itara Apọsteli; pẹlupẹlu, agbara Ọlọrun wà ni igbesi-ayé wọn. Agbára yii ni o n rú awọn ọkàn soke.
Agbara yii kan naa wà fun wa pẹlu. A ni lati lepa rè̩, a ni lati ṣafẹri rè̩, bẹẹ ni a si gbọdọ jé̩ ki o jọ wá loju ju ohunkohun lọ. Ohunkohun ti o wu ki a ni, i baa ṣe è̩bun, ọgbọn, talẹnti tabi agbára, a ni lati mọ pé ohun kan ni o ṣe pataki ju lọ fun ẹnikẹni – ani fun gbogbo wa – ni lati ni ifòroroyan Ọlọrun ni igbesi-ayé wa, iwaasu wa ati iṣẹ wa. Ọlọrun, jọwọ fi fun ni wi pe ki awọn eniyan lé maa gbagbọ bi a ti n sọrọ!
Awọn ajihinrere wọnyi duro pé̩ ni Ikonioni, wọn n fi igboya sọrọ ninu Oluwa. Ọlọrun fi ọwọ si ọna ti wọn n gbàṣiṣẹ fun Un, O mu ki awọn ami ti O ti ṣeleri ki o maa tẹle iṣẹ-iranṣẹ wọn.
OjiṣẹỌlọrun ti a rán jade jé̩ ajihinrere. Ajihinrere è̩wẹ ni ojiṣẹỌlọrun i ṣe. Iṣẹ ajihinrere gidi wà ninu fifi ẹsè̩ọkàn kan mulẹ ninu Ijọba Ọlọrun gẹgẹ bi o ti jé̩ iṣẹ nla pataki lati jere ọkàn fun Ijọba Ọlọrun. Ọkàn ti a mú duro ninu Ijọba Ọlọrun nikan ni ọkàn ti a jere fun Ijọba Ọlọrun. Awọn eniyan Ọlọrun wọnyi a maa duro titi yoo fi di mimọ fun wọn pé ifẹỌlọrun ni fun wọn lati tè̩ siwaju ninu irin ajo wọn, tabi nigba ti a ba ti ilẹkun ọna ati tè̩ siwaju ninu iṣẹ iranṣẹ wọn. Wọn yoo tun lọ si awọn ibomiran, lẹyin naa ni wọn yoo tun pada lati da awọn ará lé̩kọọ siwaju sii, lati fi idi ọrọ wọn mulẹ, lati gbà wọn niyanju ati lati mú wọn lọkan le. Nigba ti o ba si ṣe dandan lati tè̩ siwaju, wọn a maa ṣe etò nipa itẹsiwaju Ijọ fun ọjọ iwaju nipa yiyan awọn eniyan ti ọwọỌlọrun wà lara wọn gẹgẹ bi alakoso ti o jáfafa lati bojuto IjọỌlọrun, ki iṣẹ ti wọn ti ṣe ki o ma baa jasi asan.
O ya ni lẹnu wi pe Paulu paṣẹ fun Timoteu pé ki o ṣe iṣẹẸfangẹlisti, nitori pe awọn aṣẹ ti a fi le Timoteu lọwọ yii kún fún ọpọ iṣẹ ti i ṣe ti oluṣọ agutan nikan. Eyi fi hàn nigba naa pé gbogbo wa ni lati sa gbogbo ipa wa lati jere ọkàn fun Oluwa, lẹyin naa è̩wè̩, a ni lati tún sa ipá wa lati ṣe iranlọwọ fun awọn ọkàn naa lati di ọkunrin ninu iwa-bi-Ọlọrun.
Ohun miiran ti a tun ni lati ṣe akiyesi ni iha ti awọn ojiṣẹỌlọrun meji wọnyi kọ si awọn ti o fé̩ bu ọlá fun wọn lọna pataki.
Awọn ara Listra ri iṣẹ-iyanu ti a ṣe, wọn si ni idaniloju iṣẹ iyanu yii nitori ti wọn ri ọkunrin ti o ti yarọ lati inu iya rè̩ wá ti o n fo ti o si n rin niwaju wọn. Ẹran ati iṣan ti kòṣee lò tẹlẹ ri, ti kò ni idagbasoke, ti kò rin nigba kan ri, ni Ọlọrun jé̩ ki o pada bọ si ipo ti o si lokun ninu loju kan naa. O gba ọsẹ pupọ lati kọ bi a ti n rin, bi ẹni naa kò ba rin tẹlẹ ri lati igba èwe rè̩ wá. S̩ugbọn nihin yii, ki i ṣe péọgbẹni yii bẹrẹ si rin lẹsẹkẹsẹ nikan, o bẹrẹ si fò pẹlu. Kò si aniani pé iṣẹ-iyanu ni eyi i ṣe. Eyi tayọ ipá tabi agbára eniyan. S̩ugbọn awọn eniyan naa bẹrẹ si bọ awọn eniyan Ọlọrun dipo Ọlọrun tikara Rè̩.
Kò si eniyan Ọlọrun tootọ kan ti o jé̩ gba ọlá ati ògo ti i ṣe ti Ọlọrun fun ara rè̩. Awọn iranṣẹỌlọrun tootọ ki i fẹ ki a juba wọn bẹẹ ni wọn ki i fẹ gba ògo fun ara wọn fun iṣẹỌlọrun. Onirẹlẹ ni awọn iranṣẹỌlọrun. Ọlọrun ni o fun wọn ni agbára, ọgbọn, okun ati ipá ti wọn ni. Nitori naa, Oun ni o gbọdọ gba iyin iṣẹ-iyanu tabi ohunkohun ti wọn ba ṣe. Ibi pupọ ni o wà ninu ỌrọỌlọrun nibi ti awọn eniyan ti gba idajọ gbigbona nitori ti wọn fé̩ gba ọlá ati iyin ti i ṣe ti Ọlọrun nikan fun ara wọn.
Ni ọna miiran è̩wè̩, a tun le wi pé nigba ti a bá kuna lati mọ pe alailera ni awa i ṣe, ati bi o ti ṣe danindanin fun ni tó lati gbé ara léỌlọrun fun iranwọ, ọgbọn, ipá ati agbára ti ẹmi ninu ohunkohun ti a ba ni lati ṣe fun Un, a o kuna ninu ohun ti a ba dawọ lé lati ṣe nitori pe a kò fi ògo ti o tọ si Ọlọrun fun Un. Bi a ba bẹrẹ si yọ nitori iṣẹọwọ wa, ti a kò si mọ péỌlọrun ni o mú ki a ṣe aṣeyọri ni gbogbo ọna, ohun ti a n ṣe ni pe a n múẸmi Ọlọrun binu. Ifororoyàn tabi agbára Ẹmi wo ni a fẹ ri gbà tabi ti a le ni ireti wi pe yoo wà ni igbesi-ayé wa bi a bá kuna lati fi ọla fun Ọlọrun nipa gbigba ọlá ti i ṣe ti Rè̩ fun ara wa – i baa tilẹṣe lọna ti o kere jù lọ? ỌrọỌlọrun yanju ketekete lori ọran yii – o tilẹ dani lẹbi – nitori o mú iyemeji wá nipa pe a ti gbà wá là kuro ninu è̩ṣẹ wa bi a ba n lepa ti a si n gba iyin eniyan. A ka a ninu Bibeli pe: “Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ, ẹnyin ti ngbà ogo lọdọ ara nyin, ti kò wá ogo ti o ti ọdọỌlọrun nikan wá” (Johannu 5:44). Onipsalmu sọ bayi pe, “Enia ti o wà ninu ọlá kò duro pẹ: o dabi ẹranko ti o ṣegbe” (Orin Dafidi 49:12). Nigba ti Eṣu dán Jesu wò, ti o n fẹ ki ỌmọỌlọrun foribalẹ fun un, Jesu dahun pe, “Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ ki o mā sin” (Matteu 4:10).
Yoo ṣe wa ni ire bi a báṣe afiyesi iwa awọn ara Listra. A sọỌrọỌlọrun fun wọn. Wọn bọè̩dá dipo Ẹlẹda, ṣugbọn awọn eniyan Ọlọrun dá wọn lẹkun. O hàn gbangba péọkàn awọn eniyan wọnyi kò yi pada lati sin Ọlọrun tootọ; nitori pe nigba ti awọn alaigbagbọ Ju ti Ikonioni ati Antioku wá, lẹsẹkẹsẹ ni ọkàn awọn ara Listra yii pada kuro ninu nnkan wọnni ti wọn ti ri. Awọn ti o ri iṣẹ-iyanu Ọlọrun ni aipẹ jọjọ yii wá kẹyin si Ọlọrun ati awọn iranṣẹ Rè̩. Wọn sọ Paulu ni okuta, wọn si fi i silẹ bi ẹni ti ó kú.
Iṣẹgun Nigba ti O Dabi Ẹnipe Ọta Bori
Ẹ jé̩ ki a mú aworan nnkan ti o ṣẹlẹ wa si iwaaju wa: awọn iranṣẹỌlọrun tootọ meji ti awọn onigbagbọ yika, awọn wọnni ti o n yọ nipa agbára Ọlọrun ti o gbé arọ dide duro ṣanṣan. Ainiye ero iworan ti wọn n fi iyin wọn hàn li ohùn rara niwọn-igba ti anfaani wà fun wọn lati tẹle ifẹkufẹọkàn wọn; awọn ẹni ti eniyan Ọlọrun dálẹkun kánkán. Ni tosi awọn eniyan wọnyi ni awọn jagidijagan eniyan ati ogbogi ninu ìwa ọdaran ati kikọỌlọrun silẹ dimọlù lati ṣe ibi si awọn eniyan ti o mú ihin Kristi ti o jinde kuro ninu okú tọ wọn wá. Lẹyin ọrọ diẹ, awọn eniyan ti gbagbe iṣẹ-iyanu, wọn si ti di alaigbagbọ ninu agbára Ọlọrun. Ẹni kan ju okuta kin-in-ni -- lẹyin eyi ti olukuluku bẹrẹ si sọ okuta lu iranṣẹỌlọrun ti kòṣe ohunkohun lati gbe ara rè̩ nija. Lọgán awọn onigbagbọ ti a ti tuka kó ara wọn jọ kánkán, wọn ṣù bo alakoso wọn ti o ti ṣubu lulẹ.
Wo Barnaba, alabaṣiṣẹpọ pẹlu Paulu. Barnaba jé̩ọmọ Lefi, o ti ri i bi ipè Ihinrere ti ga tó ati bi ojuṣe ti akoko Ihinrere ti pọ tó, o ti ta awọn ohun ini rè̩ ti o wa ni Kipru o si ti fi owo rè̩ lelẹ ni ẹsè̩ awọn Apọsteli – ki i ṣe fun awọn alaṣẹ Tẹmpili – o si ti bẹrẹ si ṣe iṣẹọmọ-ẹyin loju mejeeji apẹẹrẹ eyi ti kò le parẹ rara ninu aye yii. Oun ni o mu Paulu wá sọdọ awọn arakunrin ni Jerusalẹmu nigba ti wọn n bẹru rè̩ nitori inunibini ti o ṣe si IjọỌlọrun. Bi Barnaba bá jé̩ alafẹnujẹ Onigbagbọ lasan ti o n wa ohun ti ara nì, o yẹ ki o lero péọlá ati iyi ti o pọ jù tọ si oun nitori pe oun ti wà pẹlu awọn Apọsteli ṣaaju Paulu. S̩ugbọn gbogbo iṣẹ ara bawọnni kò si ninu ọkàn ati igbesi-ayé Barnaba nitori ti o daju pe Barnaba gba Paulu ni aṣaaju rè̩. O ri i pe ọwọ agbára Ọlọrun wà lara Paulu. Aṣaaju naa ni o wà nilẹ gbalaja yii, okuta ti ṣe e lọṣẹ, è̩jẹ wè̩é̩ kanlẹ, o dakẹ jẹjẹ bi ẹni ti ó ti kú.
S̩ugbọn lojiji o sọji! O rá pálá! O dide! Eniyan Ọlọrun yii tun duro lori ẹsè̩ rè̩ lẹẹkan si; awọn Onigbagbọ ti yi i ká lati ṣe itọju ọkunrin onirẹlẹ, iranṣẹỌlọrun yii, gẹgẹ bi o ti tọ ati bi o ti yẹ. Paulu bẹrẹ si rin! Iṣẹ-iyanu kan ti tun ṣe! O sì bẹrẹ si sọ ti agbára Ihinrere Jesu Kristi lẹẹkan si.
Ibi ti wọn wa yii kò ti i tó idaji ibi ti wọn gbé waasu dé ninu irin-ajo kin-in-ni ti Paulu, ṣugbọn ihin Ijọba Ọlọrun ti fi ẹsè̩ mulẹ nibẹ, o si ti rú ibinu awọn ọmọlẹyin Satani soke, ṣugbọn o ku ilẹ pupọ lati gbà. Paulu ati Barnaba kò lọra lati ṣiṣẹ Baba wọn. Wọn jé̩ akikanju ninu Ọlọrun, Ọlọrun si yé̩ iṣẹ ti wọn n ṣe fun Un si.
Nigba ti wọn ti pari irin-ajo wọn, awọn eniyan Ọlọrun wọnyi yọ pupọ lati ni idapọ pẹlu awọn arakunrin ti o wà ni Antioku. Nibẹ ni wọn gbé royin ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe, bi ọkàn pupọṣe yipada ti wọn si ri ibukun ti ẹmi gbà, awọn alaisan ri iwosan ati bi ọtá ti gbogun dide lati ṣe idena iṣẹ wọn fun Ọlọrun. Wọn si tun royin bi agbára Ọlọrun ti pọ tó lati ko ni yọ ati lati fun ni ni iṣẹgun.
Bi o tilẹ jé̩ pé Paulu ati Barnaba ri itilẹyin ati ọwọ ifẹỌlọrun lori ọna ti wọn gbàṣe iṣẹ iranṣẹ wọn, sibẹ awọn ojiṣẹỌlọrun meji wọnyi kò gboju fo dá, ojuṣe wọn si awọn ti Ọlọrun fi le lọwọ lati rán wọn jade. Wọn kò ni ọkàn adáṣe tabi ki wọn ni ọkàn mo-tó-tán, ṣugbọn wọn lọ taara si Antioku nigba ti wọn pari irin-ajo wọn. “Ki iṣe igba diẹ ni nwọn ba awọn ọmọ-ẹhin gbé,” wọn n gba agbára Ẹmi ati okun fún ara wọn lẹyin irin-ajo pipẹ ti o kún fun wahala, bakan naa ni wọn si tun ni anfaani lati fi ẹsè̩ awọn ara ti o n gbọ wọn mulẹ ati lati gbà wọn niyanju.
Questions
AWỌN IBEERE- Lori awọn apejuwe ayé (mapu), tọka si ọna ti Paulu gbà nigba irin-ajo rè̩ kin-in-ni.
- Sọdọ awọn wo, ati nibi ipejọpọ wo ni awọn ajihinrere naa lọṣaaju?
- Sọ ohun ti a mọ nipa Barnaba, orilẹ-ède rè̩, iru ipa ti o ni ninu isin gẹgẹ bi idile ti a gbé bi i, ohun pataki kan ti o ṣe nipa ohun ini rè̩ ni Kipru, ati iru ihà ti o kọ si Paulu ni iṣaaju ati nigba irin-ajo yii.
- Ọna wo ni Paulu ati Barnaba fi pa aṣẹ Jesu mọ nigba ti inunibini dide si wọn?
- Iṣẹ-iyanu wo ni a ṣe ni Listra? S̩e alayé iha ti awọn ara ilu naa kọ si i ki o si sọ ohun ti Paulu fi fesi fun wọn ni ède ara rẹ.
- Ki ni ṣẹlẹ si Paulu ni Listra? Awọn ta ni da wahala naa silẹ?
- Ki ni a sọ nipa igbala wa kuro ninu è̩ṣẹ bi a ba n wa iyin lati ọdọ eniyan dipo Ọlọrun?
- Sọ oriṣiriṣi iṣẹ-iranṣẹ ti Paulu ati Barnaba ṣe gẹgẹ bi ojiṣẹỌlọrun ti a rán jade?
- Bi a ba fi apẹẹrẹ yii ṣe odiwọn, ki ni iṣẹ awọn ojiṣẹỌlọrun ti a ran jade?
- Ki ni ohun ti o wú ni lori nipa ipadabọ Paulu ati Barnaba si Antioku?