2 Awọn Ọba 6:1-7

Lesson 314 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ranti ibiti iwọ gbé ti ṣubu, ki o si ronupiwada, ki o si ṣe iṣẹ iṣaju” (Ifihan 2:5).
Notes

Ile-ẹkọ awọn Woli

Woli Eliṣa fi gbogbo akoko rè̩ṣiṣẹ fun Ọlọrun. A sọ fun ni pe ọkan ninu awọn iṣẹ ti o ṣe ni pe o jé̩ olukọni-agba ninu ile-è̩kọ awọn woli. Awọn ọdọmọkunrin ti o fẹ ni imọ si i nipa Ọlọrun ati isin ti O gbekalẹ fun awọn ọmọ Israẹli a maa lọ si ile-è̩kọ yi.

Eliṣa gan an ni ẹni ti o tọ lati di ipo yii mú, nitori pe o ni agbára Ọlọrun ninu igbesi-ayé rè̩. O ni anfaani lati kọ awọn ọdọmọkunrin bi wọn ṣe lè fi ayé wọn fun Ọlọrun ati bi wọn ṣe lè sọ fún awọn ẹlomiran nipa isin tòotọ. Eliṣa sin Ọlọrun ni ọnà ti o tọ bẹẹ ti Ọlọrun fi gbọ ti O si dahun awọn adura rè̩.

Ọjọ Iṣipopada

Ni ọjọ kan awọn ọmọ woli pinnu pé wọn n fẹ lati kó lọ si ibi ti àye yoo gbé gbà wọn ju ibi ti wọn ti wà lọ. Eliṣa gbà fun wọn lati ṣe bẹẹ; ṣugbọn wọn kò fẹ fi i silẹ. Eliṣa ti gbadura fun wọn nigba ti wọn wà ninu wahala. Laisi aniani iwà ayé rè̩ jé̩ apẹẹrẹ rere fun wọn; è̩wẹ, nipasẹ agbára Ọlọrun ti o wà ni igbesi-ayé rè̩, o ti pese ounjẹ fun wọn nigba ti wọn kò ni ohun ti wọn o jẹ. Wọn n fé̩ ki o wà pẹlu wọn lati ràn wọn lọwọ nipa ti ẹmi ati nipa ti ara.

Eliṣa yọọda lati lọ, ọjọ kò ti olukuluku awọn ti o wà ni ile-è̩kọ na palè̩ẹru wọn mọ, ti wọn si kó lọ si ebute Odò Jọrdani. Kò si ile ti wọn yoo wọ si, nitori naa olukuluku wọn nila ti lọ gé igi ki wọn si là pakó ti wọn yoo fi kọ ile-ẹkọ ati ibugbe wọn.

Aake sọnu

Ọdọmọkunrin kan bẹrẹ si fi gbogbo agbára rè̩ gé igi, lojiji aaké rè̩ yọ sinu Odò Jọrdani o si rì si isalẹ odo, o yẹ ki o ti mọ pe aaké naa ti n mì lara eeku rè̩. Aake naa ki yoo yọ bi o ba ti wọ inu eeku rè̩ṣinṣin, ṣugbọn oun kò kàn án mọ nigba ti o ni anfaani lati ṣe bẹẹ nitori naa ni o fi yọ kuro. Ki ni yoo fi eeku aake nikan ṣe? Eyi ti o wa buru julọ ni pé wọn tọrọ aake naa ni. Pagidari, igi dá! Wahala bà a, ṣugbọn ó mọ ibi ti oun yoo wa iranwọ si.

Bawo ni inu ọdọmọkunrin naa yoo ti dùn tó pé Eliṣa bá wọn wá! O saré lọ sọdọ woli lati sọ fun un nipa idaamu ti o de bá a. O sọ pé oun ti sọọmọ-aaké naa nù, ati pé oun n fé̩ iranwọ.

Njẹ bi awọn wolii wọnyi kò bá ti bẹ Eliṣa lati bá wọn lọ n kọ? Boya igbagbọ awọn ọmọ woli le ṣe alaito lati ri iranwọ gbà lọdọỌlọrun. Iwọ ha ti rò bi yoo ti buru to bi iwọ bá mọọmọ sá kuro lọdọ awọn enia Ọlọrun, lẹyin eyi ti aisan tabi idaamu si dé báọ, ti kò si si ẹnikẹni nitosi lati gbadura fun ọ?

Kikọ Ile Ọlọrun silẹ

Awọn miiran a maa sin ni Ile Oluwa tọkàntọkàn fun iwọn igba diẹ, wọn a si ri ibukún Rè̩ gbà. S̩ugbọn lẹyin igba diẹ, awọn è̩bun rere ti Ọlọrun n fi fun wọn yoo di ara fun wọn, wọn a si fi oju tinrin awọn ibukun wọnyi. Wọn gbagbe pe lati ọdọỌlọrun ni gbogbo è̩bun rere wọnyi ti wá, wọn si ni lati fi imoore hàn nipa iṣẹ-isin wọn si Ọlọrun. Wọn lè sá kurò lọdọ awọn eniyan Ọlọrun nitori idi kan ti kò nilaari bii pé wọn fẹ lọṣiṣẹ ti o mú owo wá ju eyi ti wọn n ṣe lọ.

Ki ni n ṣẹlè̩ nigba ti wọn bá bọ sinu wàhalà? Kò si ẹnikẹni ni tosi lati gbadura fun wọn. Adanu ti wàhalà yii yoo mú bá wọn tilẹ le tayọère ti wọn yoo ri gbà nibi iṣẹ titun ti wọn lọṣe. È̩wẹ, nitori pe wọn kò ni idapọ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun ati nitori pe kò si anfaani lati maa ba wọn sọrọ nipa ohun ti i ṣe ti Ọlọrun, wọn le sọ ifẹỌlọrun nù kuro ninu ọkàn wọn.

Bibeli sọ fun wa pé ki a máṣe kọ ipejọpọ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran (Heberu 10:25). A maa n di alagbara, a si maa n ni ikiya nipa idapọ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun, ati nipa biba wọn gbadura ati jijọsin pọ.

Iranlọwọ nigba Ipọnju

Nigba ti ọdọmọkunrin akẹkọọ ti o sọ aake rè̩ nù sọ fun Eliṣa nipa ohun ti o ṣẹlè̩, Eliṣa ṣetan lati dide fun iranlọwọ rè̩ lẹsẹkẹsẹ. O beerè pé, “Nibo li o bọ si?” Nigba ti a fi ibè̩ hàn an, o gé igi kan, o jù u sinu omi nibi ti aakè naa bọ si, bẹẹ ni irin naa si fó sori omi.

Irin naa kò le fó sori omi bi kòṣe nipa agbára Ọlọrun; ṣugbọn Ọlọrun yoo ṣe ohun ti o ṣoro fun awọn ọmọ Rè̩ bi o ba gbẹkè̩le E. Gbogbo è̩dá ni o wà lábé̩ákóso Ọlọrun wọn a si maa gbọ ti Rè̩.

ỌrọỌlọrun kò sọ fun wa pe Eliṣa gbadura ni akoko yii, ṣugbọn a ti kọè̩kọ pe o fara mọ Elijah titi di igbà ti a fi gbà a lọ si Ọrun, ki o ba lè ni ilọpo meji agbára Elijah. O ti ri ohun ti o n fẹ gbà, agbara naa si ti ọdọỌlọrun wá. Ọkàn rè̩ wà ni idapọ pẹlu Ọlọrun nigba gbogbo. Agbára yii ni o fi n ṣe iṣẹ-iyanu.

Aanu Ọlọrun

Ohun ti o ṣẹlẹ yii fi aanu Ọlọrun si awọn ti o bá ke pe E nigba ti wọn wà ninu idaamu hàn. Boya ẹni kan wà ti o ti fẹran Oluwa nigba kan ri, ṣugbọn o ti fà sẹyin. Boya o tilẹ n jọsin bi ti atẹyinwa, bi o ti ṣe e ṣe fun agegi yii lati tẹra mọ a ti fi eeku aake lu igi. S̩ugbọn a mọ pe fifi eeku aake lasan lù igi kò lè gé igi lulè̩. Bakan naa ni iṣẹ-isin wa fun Oluwa kò lè mú ire kan jade lai si Ẹmi Ọlọrun ni igbesi-ayé wa. Jesu wi pe: “Nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan” (Johannu 15:5). Oluwa ni lati wà pẹlu wa ki O ba lè lò wá ninu iṣẹ wa si I.

S̩ugbọn ireti wà sibẹ fun ẹni ti o ti sọẸmi Ọlọrun nù. Lakọkọ o ni lati gbá pe oun kò ni Ẹmi Ọlọrun mọ, lai ṣe awawi tabi ki o ma ṣe apamọ-apabo. Bi o bá si ke pe Ọlọrun fun aanu ati idariji, a o dá ifẹỌlọrun pada fún un. Ọkunrin ti o n gé igi nì jẹwọ lẹsẹkẹsẹ pe oun ti sọ aake oun nù, lai si aniani, inu rè̩ bajẹ o si kaanu pe ó yọ bọ, nitori o wi pe, “Yẽ! oluwa mi, a tọrọ rè̩ ni.”

Oluwa yá wa ni ohunkohun ti a ba fi fun wa lò ni. A fi wa ṣe olutọju awọn ibukun wọnni ti a ri gba ni. Iriju ni awa i ṣe lati maa boju to iṣẹ Oluwa ninu aye yii. O yẹ ki a mọ riri ohun ti Ọlọrun fi fun wa ki a si fi ọwọ danindanin mú un! Bi ohunkohun bá si gbọn ọn bọ lọwọ wa, o yẹ ki a tete fi itara beere pe, ki Ọlọrun dariji wá ki O si tún jé̩ ki a ri ojurere Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ipo wo ni Eliṣa wà ni ile-è̩kọ awọn wolii?
  2. Ki ni awọn ọmọ wolii fẹṣe?
  3. Nibo ni Eliṣa lọ?
  4. Ki ni ṣẹlè̩ nigba ti awọn aké̩kọọ wọnyi n kọlé?
  5. Ki ni ọdọmọkunrin nì ti ibanujẹ dé báṣe nigba ti idaamu de ba a?
  6. Bawo li Eliṣa ṣe ràn án lọwọ?
  7. Ki ni iṣẹ wa fun Oluwa ni aye yii?
  8. Ki ni a gbọdọ ni ki a tó lèṣiṣé̩ fún Oluwa?
  9. Bawo ni a ṣe le fi ẹsẹ ara wa mulè̩ ki a si maa mu ara wa ni ọkàn le ninu igbagbọ?
  10. Ki ni apẹyindà le ṣe lati ri ojurere Ọlọrun gbà padà?