Lesson 315 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Angẹli OLUWA yi awọn ti o bè̩ru rè̩ ká, o si gbà wọn” (Orin Dafidi 34:7).Notes
Ogun Oluwa
Lẹẹkan si i, orilẹ-ède Israẹli n sin Ọlọrun otitọ; awọn eniyan ati ọba Israẹli paapaa, n gbọ ti Eliṣa, wolii Ọlọrun. Eliṣa jé̩ ibùkún fun awọn eniyan naa, o n lọ kaakiri o si n ṣe rere: o n wo alaisan sàn, o n ran awọn onirobinujẹọkàn lọwọ, o tilẹ n ji okú dide.
Nigba kan, Bẹnhadadi, ọba Siria, gbiyanju lati tún ṣẹgun Israẹli. Nigba kan ri, Ọlọrun ti fi awọn Ọmọ Israẹli le awọn ara Siria lọwọ nigba ti wọn n bọ oriṣa: ṣugbọn ni akoko yii, ti wọn gbọran si woli Ọlọrun, Ọlọrun ṣetan lati jà fún wọn.
Ọba Siria gbiyanju lati fi ara pamọ si ibi ti awọn ọmọ-ogun Israẹli kò ni le ri wọn, ṣugbọn awọn Ọmọ Israẹli kò lọ si tosi ibi ti awọn ara Siria fi ara pamọ si. Wọn n fi ara pamọ lati ibi kan si ibi keji ṣugbọn awọn Ọmọ Israẹli kò lọ si ibùba wọnyi. Bẹnhadadi rò pé olofofó kan wà ni ibudo rè̩ ti o lọ n tú aṣiiri ètò rè̩ fun awọn Ọmọ Israẹli.
Ẹni kan wà ti o n sọ eto ati ète Bẹnhadadi fun Ọba Israẹli, ṣugbọn ẹni naa kò si laaarin awọn ara Siria. Ọlọrun ni o n fi hàn fun Eliṣa ti Eliṣa si n sọ fun ọba. Ọkan ninu awọn iranṣẹ Bẹnhadadi sọ fun un pé: “Eliṣa, woli ti mbẹ ni Israẹli, ni nsọ fun Ọba Israẹli gbogbo ọrọ ti iwọ nsọ ni iyè̩wu rẹ.” Ọlọrun lè tu aṣiiri ohun ti awa rò wi pe ẹnikẹni kò mọ. Jesu wi pe: “Ko si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ” (Matteu 10:26).
Nipasẹ ogun yii, Bẹnhadadi n bọ wá mọ péỌlọrun n jà fun Israẹli, ati pe kòṣanfaani fun wọn lati báỌlọrun jà. Bi Ọlọrun ba wà fun wa, ta ni yoo kọ oju ijà si wa?
Ẹgbẹ Ogun Dó Ti Wolii Kan
Ohun kin-in-ni ti awọn ara Siria gbiyanju lati ṣe ni lati pa woli Ọlọrun ti o n tú aṣiiri wọn. Ọpọlọpọ eniyan ni o ti gbiyanjù lati pa isin Jesu Kristi Oluwa wa run ati lati pa awọn agbatẹru isin naa. Nwọn ti gbé inunibini kikorò dide lati mú ki awọn eniyan sé̩ igbagbọ wọn. S̩ugbọn Ihinrere n lọ lati ipa de ipa o si n gbilẹ si i. O dabi ẹni pe awọn ti a ṣe inunibini kikoro si jù lọ ni o tilẹ fi gbogbo agbára wọn di otitọỌrọỌlọrun mu ṣinṣin ju lọ. Bẹẹ ni ọpọlọpọ awọn onigbagbọ ni o ti fi tọkàntọkàn tẹle awọn oniwaasu otitọ ti a ti kẹgan ti a kò si naani.
Awọn ajihinrere miiran ti o kọkọ mu Ihinrere lọ si ilẹ awọn keferi ti padanu ẹmi wọn ninu igbiyanju wọn lati waasù Kristi, ṣugbọn a sọ ni tòotọ pe, “È̩jẹ awọn ajẹrikú ni irugbin Ijọ.” Ni ibi ti awọn ẹlomiran gbé kú si, awọn miiran dide wọn si tọ ipasẹ wọn lati fi idi otitọ Bibeli mulẹ.
Bẹnhadadi ran odindi ẹgbẹ ogun kan si Dotani lati wá Eliṣa – odindi ẹgbé̩ ogun kan lati múẹyọẹni kan ṣoṣo. Ni tootọ o dabi ẹni pe ija naa kò dọgba. S̩ugbọn Ọlọrun ti ṣeleri pe: “Ọkunrin kan ninu nyin yio léẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin” (Joṣua 23:10). Ogun Oluwa ni eyi bẹẹ ni yoo si fi iṣẹgun naa fun ẹni kan ṣoṣo.
Ọmọ-ọdọti Ẹru n Bà
Ni òwúrọ kùtu ọjọ kan, iranṣẹ Eliṣa jade lati inu ile wọn, è̩rù si ba a gidigidi lati ri pe gbogbo ogun Siria ti yi ilu naa ká. Ẹṣin ati kè̩ké̩-ogun awọn ọtá wà nibi gbogbo. Ẹgbé̩ ogun nlá yii wá lati mú Eliṣa. Iranṣẹ yii kigbe pẹlu ifoya wi pe, “Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe?”
Njẹè̩rù bà Eliṣa bi? Oun ha bè̩ru ki ni eniyan lèṣe si i? Ọkàn Eliṣa balẹ pè̩sè̩ ninu Ọlọrun ti o n sin. Ọlọrun rè̩ kò ha kapa ohunkohun ti o wu ki o le de? Ọlọrun ti oun n sin jé̩Ọlọrun okè ati afonifoji pẹlu.
Eliṣa ti mọ pe “Angẹli Oluwa yi awọn ti o bè̩ru rè̩ ká, o si gbà wọn” (Orin Dafidi 34:7). O mọ péỌlọrun ti ri awọn ọmọ-ogun Siria ti o wá si Dotani nitori pe “oju OLUWA nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pipe si ọdọ rè̩” (2 Kronika 16:9). Eliṣa ti gbé igbesi-ayé ti o wu Ọlọrun, nitori naa ni wakati ti o n fẹ iranlọwọ yii, ọkàn rè̩ balẹ pe Ọlọrun yoo ran oun lọwọ. Lai si aniani, Eliṣa fi ara mọỌlọrun to bẹẹ ti oju ẹmi rè̩ fi lè ri kè̩ké̩-ina awọn angẹli ti o yi i ká. O gbadura pe ki Ọlọrun la iranṣẹ rè̩ loju ki o lè riran. Wo o bi iyalẹnu ọdọmọkunrin yii yoo ti pọ tó nigba ti Ọlọrun fi hàn án pe awọn oke naa kún fun ẹṣin ati kè̩ké̩-ina, kè̩ké̩ awọn angẹli, ti wọn duro lati gbèjà eniyan Ọlọrun naa.
Ọpọlọpọ igbà ni Dafidi ti sọ pé Oluwa li o n ja ogun rè̩ fún un. Ki ni ṣe ti yoo fi daamu niwọn igba ti ogun naa jẹ ti Oluwa? Nigba kan o wi pe: “Ki nwọn ki o dāmu, ki a si ti awọn ti nwáọkàn mi loju: ... ki nwọn ki o dabi iyangbo niwáju afẹfẹ: ki angẹli OLUWA ki o ma le wọn” (Orin Dafidi 35:4, 5).
Bawo ni wahala ati aibalẹ aya yoo ti jinna si wa tó bi a ba jẹ jọwọ gbogbo iṣoro wa lọwọ fun Oluwa ki Oun tikara Rè̩ ba wa yanju rè̩? S̩ugbọn a ni lati jẹ ki Ọlọrun ṣe e ni ọna ti Rè̩. O mọ ohun ti a ṣe alai ni ati ohun wọnni ti o dara fun wa jù awa tikara wa lọ. Wò bi inu wa yoo ti dùn tó bi a ba jẹ le gbà A laaye lati mú ifẹ ti Rè̩ṣẹ! Bi a ba ti jọwọ ara wa lọwọ fun Un pọ tó ni iṣẹgun wa yoo ti pọ tó.
Kẹkẹ Oriṣi Meji
Ronu lori oriṣi kè̩ké̩ ogun meji wọnyi. A le fi oju ara ri kè̩ké̩ awọn ara Siria. Awọn ohun ti o lagbara gẹgẹ bi irin ati igi ni a fi ṣe wọn. Ẹṣin awọn ara Siria lagbara o si lé̩wà pupọ. Awọn wọnyi ni o maa n mu ki eniyan léro pe oun lagbara. Awọn ẹṣin ati kè̩ké̩ ogun Ọlọrun ko ṣee fi oju ara ri. S̩ugbọn ewo ni o lagbara ju lọ ninu awọn mejeeji? Ewo ni iwọ fẹ lati gbẹkẹle, kè̩ké̩ ti eniyan ti a le fi oju ri, tabi kè̩ké̩Ọlọrun ti a ko le fi oju ri?
Ọpọlọpọ eniyan ni ode oni ni è̩rù n bà lati gbẹkẹle Ọlọrun nitori pe nwọn kò ri I. “Ohun ti a nri ni ti igba isisiyi; ṣugbọn ohun ti a kò ri ni ti aiyeraiye” (2 Kọrinti 4:18). Awọn ile ti a n gbé, awọn igboro wa, ounjẹ ti a n jẹ, ara wa paapaa ti i ṣe agọ ti ẹmi wa gbé wọ, yoo rekọja. Awọn wọnyi ni ohun ti a n ri: ṣugbọn wọn kò duro pẹ titi.
Ronu nigba naa nipa ireti iye ainipẹkun ti a ni. A kò fi oju ri i bi a ṣe gba ọkan wa làṣugbọn a mọ dajudaju nigba ti iṣẹ naa ṣe. A di è̩dá titun ninu Kristi, a si mọ pe iye ainipẹkun wọ inu wa. Itumọ iye ainipẹkun ni pe a o wà laayè titi lae, niwọn igba ti Ọlọrun ba wà laaye. Ki yoo nipẹkun. Njẹ eyi ni kò ha daju ju awọn ohun ti a n ri ti yoo parun ni aipẹ jọjọ? “Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rè̩: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹỌlọrun ni yio duro lailai” (1 Johannu 2:17).
Gigun Awọsanma Lẹṣin
Nigba ti ayà wa ba n já ti a si n rò pe o ha ṣe e ṣe fun wa lati ṣẹgun ọtá wa ẹmi, jẹ ki a ranti pe “kò si ẹniti o dabi Ọlọrun, iwọ Jeṣuruni, ti ngùn ọrun fun iranlọwọ rẹ, ati ninu ọlanla rè̩ li oju-ọrun” (Deuteronomi 33:26). Ọmọ iké̩ Rè̩ ni a jé̩. O fé̩ ki a ba Oun gẹṣin pọ. Isaiah wi pe: “OLUWA ngùn awọsanma ti o yara” (Isaiah 19:1). Ni tootọ, è̩dàọrọ ti o lọ bi owe ni apejuwe wọnyi jé̩, ṣugbọn Ọlọrun n fẹ fi hàn wa pe ohun ayé yii kòṣe pataki lọ titi. Bi a ba n ba Ọlọrun rìn ti a si n ba A sọrọ, ti a si kó gbogbo aniyan wa le E, a ki yoo fi àyè silẹ fun ẹrù aniyan ohun ayé yii ki o wọ wá lọrun. “Idi ti o n fò loju ọrun ki i ṣaniyan bi oun yoo ṣe ré iṣan omi kọja.”
Igbesi-ayé ijọwọ ara ẹni lọwọ fun ifẹỌlọrun jé̩ eyi ti o ni alaafia pupọ. Dafidi gbadura pe, “Iwọ o fi ipa ọna iye hàn mi; ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ wà: li ọwọọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai” (Orin Dafidi 16:11).
Fifé̩ awọn Ọta Wa
Nigba ti awọn ọmọ-ogun Siria de ọdọ Eliṣa, o ti mura silẹ dè wọn. Kò fi idà bá wọn jà; kò si ké pe awọn onikè̩ké̩-ina lati ọdọỌlọrun lati pa awọn ara Siria run. Eliṣa ki i ṣe woli ti o n pe idajọ wá sori awọn eniyan. O fi aanu hàn fun awọn ọtá rè̩ paapaa. A saba maa n sọ pe apẹẹrẹ Kristi ni oun i ṣe. Jesu sọ nigba ti O wà ni ayé pé akoko idajọ kò i tii de, nitori eyi Oun a maa yẹra kuro lọdọ awọn ti o ba doju jà kọỌ. O kọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe: “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin” (Matteu 5:44).
Eliṣa gbadura pe ki Ọlọrun bu ifọju lu awọn ọmọ-ogun Siria; lẹyin eyi ni o mú wọn lọ si Samaria, ti iṣe olu-ilu, o si tun bẹỌlọrun pé ki o là wọn loju. O duro niwaju wọn, bẹẹ ni oun ni ọkunrin naa gan an ti awọn eniyan wọnyi n wa. S̩ugbọn nisisiyi wọn wà ni ikawọ rè̩, wọn wa laaarin awọn Ọmọ Israẹli. Ọba Israẹli fé̩ pa wọn ni kiakia, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ ni Eliṣa dahun pe: “Iwọ kò gbọdọ pa wọn: iwọ jẹ pa awọn ti iwọ fi idà rẹ ati ọrun rẹ kó ni igbèkun? Gbe onjẹ ati omi kalẹ niwaju wọn, ki nwọn ki o jẹ ki nwọn ki o si mu, ki nwọn ki o si tọ oluwa wọn lọ.” Wò iru ifẹ ti o fi hàn fun awọn ọtà rè̩! Ni ayéọlàjú yii, o wa ninu ofin ti gbogbo orilẹ-ède fara mọ pé ki a máṣe huwa ika si awọn ti a kó lẹrú ni ogun; ṣugbọn Eliṣa tilẹṣe ju bẹẹ lọ, o ran awọn ọmọ-ogun Siria wọnyi pada si ìlu wọn.
Oore yii kún awọn ara Siria loju, fun igba diẹ wọn dé̩kun ogun ti wọn i maa gbe ti Israẹli.
Questions
AWỌN IBEERE- Ta ni gbogun ti Israẹli?
- Bawo ni wọn ṣe pète lati ja ija naa?
- Ki ni ṣe ti eto wọn kuna?
- Ta ni Ẹni ti o njà fun Israẹli?
- Ta ni a rán lati mú Eliṣa?
- Ki ni ṣe ti Eliṣa kò bè̩ru?
- Ki ni ileri ti Ọlọrun ṣe fun aabo wa ni igba ipọnju?
- Bawo ni a ni lati ṣe si awọn ọtà wa?