2 Awọn Ọba 6:24-33; 7:1-20; 8:1-16

Lesson 316 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ olododo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rè̩ ki o ma ṣagbe onjẹ” (Orin Dafidi 37:25).
Notes

Samaria

Jehoramu, Ọba Israẹli, n gbé ni ilu Samaria. Oun ni i ṣe ọba è̩yà mẹwaa ti ó wà ni iha ariwa ni Israẹli. Ori oke ni a tè̩ Samaria ti iṣe olu-ilu Israẹli dó si (1 Awọn Ọba 16:23, 24). Bi a ṣe tè̩ ilu yii dó yoo jẹ anfaani fun wọn lori ọta nitori pe awọn oluṣọ yoo ni anfaani lati tete ri ẹnikẹni lati okeere réré.

Nigba aye Ahabu, Bẹnhadadi, ọba Siria, gbáọmọ-ogun rè̩ jọ lati gbogun ti Samaria (1 Awọn Ọba 20:1). Ọba meji-le-lọgbọn ni o ran Bẹnhadadi lọwọ. Ọlọrun ran awọn ọmọ Israẹli lọwọ nigba ti wọn jade lati báọtá wọn jà. Ọpọlọpọ ninu awọn ara Siria ni a fi idà pa, ṣugbọn Bẹnhadadi ọba sá asálà.

Ahabu ni anfaani lati pa Bẹnhadadi ẹni ti i ṣe ọtáỌlọrun ati awọn eniyan Rè̩. Kàkà bẹẹ, Ahabu ába Bẹnhadadi dá majẹmu o si jé̩ ki o pada si ile rè̩. Inu Ọlọrun kò dùn pe Ahabu fi àye silẹ fun ọtá lati sáàsálà. A sọ fun Ahabu pe oun ati awọn eniyan rè̩ yoo jiyà nitori ikuna rè̩ yii. (Wo Ẹkọ 299).

Iyàn

Ọba Siria tún dide ogun si awọn Ọmọ Israẹli. Ninu ọkan ninu awọn è̩kọ ti a ti ṣe kọja, a ri bi Ọlọrun ṣe daabò bò wolii Rè̩ ti O si gbà a nigba ti ẹgbé̩ ogun Siria yi ilu ti Eliṣa gbé wà ká. Ọwọ wọn kò lè tẹ Eliṣa nitori péỌlọrun wà pẹlu rè̩.

Bẹnhadadi, Ọba Siria, pinnu lẹẹkan si i lati kó ilu Samaria lẹru. O ṣeto lati jé̩ ki awọn ọmọ-ogun yi oke naa ka, lati séọna ti ounjẹ n gbà wọ inu ilu ki iyàn ki o le mú. Ni ọjọ wọnni, gbogbo eniyan a maa gbe inu ilu, wọn a si maa mu ounjẹ wá si ilé lati oko. Nigba ti kòṣe e ṣe fun ẹnikẹni lati jade tabi lati wọ inu ilu nitori awọn ọtá, ounjẹ bẹrẹ si tán diẹdiẹ. Ni ikẹyin iyàn mú ni Samaria. Kò si ounjẹ bi kòṣe awọn nnkan wọnni ti a kà si alaimọ fun jijẹ, iye owo ti a si n ta wọn ga ju eyi ti apa awọn eniyan ká. Awọn Ọmọ Israẹli n fẹ ounjẹ lọnakọna, o si dabi ẹni pe ebi ni yoo pa wọn kú.

Ileri

Jehoramu, ọba Israẹli, di ẹbi wahala yii le Ọlọrun lori. A kò gbọ ki Jehoramu sọ fun wolii lati gbadura tabi ki o sọ fun gbogbo eniyan lati gbadura. Lai si aniani, Ọlọrun i ba ti ràn wọn lọwọ bi wọn ba ti ke pe E ki wọn si gbadura. Jehoramu pinnu lati gbé igbesẹ miiran dipo ki o duro de Ọlọrun lati gbà wọn. O halè̩ wi pe oun yoo pa woli Ọlọrun, ṣugbọn eyi kò ba Eliṣa lẹrù. O sọtẹlẹ pé, “Ni iwòyi ọla li a o ta oṣùwọn iyè̩fun kikuna kan ni ṣekeli kan ni ẹnu bode Samaria.” Laaarin ọjọ kan ṣoṣo iyipada yoo wà -- wọn yoo bọ lọwọ ebi sinu ọpọlọpọ ounjẹ! Lati rirà ounjẹ aimọ ni ọwọn owo sinu rira ounjẹ ti o dara ni ọpọkúyọkù! Bawo ni eyi yoo ṣe ri bẹẹ?

Iyemeji

Ọkàn awọn eniyan lode oni ki i saba balẹ wọn a maa wara papa dipo ki wọn gbadura ki wọn si gbẹkẹle Ọlọrun. Wọn n kunà lati ri ibukun Ọlọrun gbà nitori pe wọn a tete maa sọ ireti nù. Dafidi Onipsalmu wi pe, “Fi ọna rẹ le OLUWA lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ” (Orin Dafidi 37:5). Awọn ẹlomiran ki i ri ibukun Ọlọrun gbà nitori pe wọn n ṣiyemeji gẹgẹ bi oluranlọwọọba nì. Kò gbà Eliṣa gbọ nigba ti o sọ pe Ọlọrun ti ṣeleri pe wọn yoo ni ọpọ ounjẹ ni ọjọ keji. Ijoye nàa beere pe, “Kiyesi i, bi OLUWA tilẹṣe ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bḝ?” Nitori aigbagbọ rè̩, a sọ fun un pe yoo fi oju rè̩ ri ounjẹ naa ṣugbọn ki yoo jẹ ninu rè̩. Ọlọrun le ṣe fèrèsé ni ọrun lati gbà ibẹ tú ounjẹ dà silẹ. S̩ugbọn ọna yii kọ ni Ọlọrun gbà pese fun awọn eniyan Rè̩ ni akoko yii.

Igba Aini

Awọn adẹtẹ mẹrin kan wà ti wọn n gbé lẹyin odi ilu, gẹgẹ bi Ofin (Lefitiku 13:46). Awọn ti o n kó ounjẹ lọ saarin ilu ni i maa fun wọn ni ounjẹ. Niwọn igba ti a ti sé ilẹkun ibodè ilu ti ẹnikẹni kò le wọle tabi ki o jade, awọn adẹtẹ wọnyi kò ni ounjẹ. Wọn gbèrò ohun ti wọn yoo ṣe. Bi wọn bá duro si ibi ti wọn wà wọn yoo kú. Bi wọn ba wọ inu ilu lọ nibi ti iyàn gbé wà, wọn yoo kú pẹlu. Bi wọn ba lọ si ibudo awọn ara Siria wọn le pa wọn, ṣugbọn wọn ni ireti kan -- awọn ara Siria le dá wọn si. Wọn pinnu lati lọ si ibudo awọn ara Siria.

Ireti Kan

Ni afè̩mọjumọ, bi awọn adẹtẹ wọnyi ti n sún mọ ibudo awọn ọtá, wọn kò ri ẹnikẹni, ko tilẹ si oluṣọ ti n ṣọ ibudo. Wọn wọ inu agọ kan lọ. Sibẹ wọn kò ri ẹnikẹni, nitori naa awọn adẹtè̩ wọnyi jẹ ounjẹ ti wọn ri nibẹ nitori pe ebi n pa wọn. Wọn n lọ lati inu àgọ kan de ekeji ṣugbọn awọn àgọ naa ṣofo; kiki ounjẹ ati awọn ohun alumọni nikan ni o wà nibẹ.

Ọna Ọlọrun

Ọna ti Ọlọrun gba lati pese ounjẹ fun awọn ara Samaria ni eyi. Oluwa mu ki awọn ọmọ-ogun ara Siria ki o gbọ ariwo ti o dabi ẹni wi pe ẹgbẹ-ogun pupọ n bọ wá. Wọn rò pé wọn gbọ iro ọpọlọpọ kè̩ké̩ ogun, ọpọlọpọẹṣin, ati ẹgbẹ ogun nla. Awọn ọmọ-ogun Siria wọnyi gba pe ọba Israẹli ti bẹẹgbẹ ogun pupọ lọwé̩ lati bá wọn jà. Ẹrù ba wọn, wọn si sa àsálà fun ẹmi wọn. Ilẹ kò ni pẹṣú mọ nitori naa wọn kò jẹ daba lati duro kó awọn ohun-ini wọn mọ. Gbogbo wọn sá kuro ni ibudó, wọn si fi àgọ wọn, ẹṣin, ounjẹ ati awọn nnkan olowo iyebiye silẹ. Wọn sá lọ, wọn si fi ibudó wọn silẹ bi o ti wà. Awọn adé̩tè̩ mẹrin wọnyi ri i pe awọn eniyan ti sá lọ kuro ni ibudo.

Ọpọ

Nigba ti wọn ti jẹun tán, ti wọn si ti kó ipaarọ aṣọ ati owo diẹ pamọ fun ara wọn, wọn ranti awọn ti ebi n pa ninu ilu. Awọn adé̩tè̩ naa sọ pe: “Awa kòṣe rere: oni yi, ọjọ ihinrere ni, awa si dakẹ.” Wọn lọ si ẹnubode ilu lati royin ohun ti wọn ri.

È̩tẹ ati È̩ṣẹ

Nigba ti a ké̩kọọ nipa è̩tè̩ tẹlẹ, a sọ fun ni pe a saba maa n fi è̩tẹṣe apẹẹrẹè̩ṣẹ. Lọna wo ni awọn adẹtẹ mẹrin ti è̩kọ wa yii gbà fara jọẹlẹṣẹ? Awọn adẹtẹ wọnyi mọ pe wọn wà ninu aini ati pe wọn yoo kú bi wọn ba wà bẹẹ. Wọn wi pe, “Ẽṣe ti awa fi joko nihinyi titi awa o fi kú?” Wọn ni ireti kan -- awọn ara Siria le dá wọn si. Awọn adẹtẹ wọnyi kò duro ti ọrọ sisọ nikan ṣugbọn wọn mú ohun kan ṣe. Ẹlẹṣẹ ni lati mọ ipo oṣi ati ègbé ti oun wà niwaju Ọlọrun. O ni lati mọ pe oun wà ninu aini, ati pe bi oun ba wà ni ipo yii yoo yọri si ikú. Ireti kan ṣoṣo ni o wà fun ẹlẹṣẹ -- Ẹjẹ Jesu ti o le wẹè̩ṣẹ rè̩ nù. Lati mọ otitọ yii nikan kò tó. Eniyan ni lati mú ohun kan ṣe. O ni lati sun mọỌlọrun ki o si wá oju Rè̩. Ọpọlọpọ eniyan ni o wà ti wọn mọ péọna wọn kòṣe deedee pẹlu Ọlọrun, wọn si mọ nipa ọna igbala pẹlu. Bi wọn ba wà ninu iru ipo yii, wọn ki yoo ri igbala.

Irú eniyan wo ni iwọ i ṣe? A ha ti gbàọ là? tabi iwọ ha ṣe alai ni oore-ọfẹỌlọrun ti n gba ni là? Bi iwọ ba dabi awọn adé̩tè̩ mẹrin ti inu è̩kọ wa yii, ki ni ṣe ti iwọ ki yoo fi sọọrọ kan naa pẹlu wọn pé, “Ẽṣe ti awa fi joko nihinyi titi awa o fi kú?” Ki ni ṣe ti iwọ ki yoo fi lọ sọdọ ireti rẹ kan ṣoṣo, ani Jesu?

Titan Ihinrere Kalẹ

Nigba ti ẹni kan bá ri igbala, ti o si ti jẹ ounjẹẹmi, yoo ni ifẹ lati sọ fun awọn ẹlomiran. O n fẹ ki awọn ẹlomiran ti o ṣe alaini nipa ti ẹmi ṣe alabapin ọpọlọpọ ibukun ti oun ni. Ọna pupọ ni eniyan le gbà lati tan Ihinrere kalè̩. Oun yoo fé̩ lati sọè̩ri rè̩, lati sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun un. Oun yoo fé̩ mu awọn eniyan wá si ile-ìsin ati Ile-è̩kọỌjọ Isinmi. O si tun le tan Ihinrere kalè̩ nipa pípín iwe itankalẹ Ihinrere fun ni. Lai si aniani, iwọ paapaa mọ awọn ọna miiran ti eniyan le gbà lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa Jesu. Iwọ ha n ṣe ohunkohun lọna bayi lati mú awọn ẹlomiran mọ Oluwa? Oju gbà mi tì fun awọn wọnni ti wọn ni lati jẹwọ bi awọn adé̩tè̩ wọnni pe: “Awa kòṣe rere: oni yi, ọjọ Ihinrere ni, awa si dákẹ”!

Iṣiyemeji

A mú ihin awọn adẹtè̩ wọnyi tọọba lọ. O dide ni oru naa o si bá awọn iranṣẹ rè̩ sọrọ. O rò péọgbọn alumọ-kọrọyi awọn ọtà ni eyi, ki wọn ba le ba dè wọn. Nigba kan, iru ete bayi ni wọn ṣe. S̩ugbọn ọba ha ti gbagbe ọrọ Eliṣa ni? Lai si aniani oun kò ni igbagbọ péọpọ ounjẹ n bọ wá. Ọkan ninu awọn iranṣẹ rè̩ dába pe ki a ran awọn ọmọ-ogun si ibudo awọn ọtá lati wo ohun ti yoo ṣẹlẹ. Nitori naa, ọba ran awọn diẹ lọ wi pe, “Ẹ lọ iwò.”

Nigba miiran ti awọn eniyan ba gbọ nipa Ihinrere a maa jọ bi ẹni pe ohun ti a n sọ kò le ri bẹẹ. Wọn a maa ṣe tikọ bi o tilẹ jẹ péỌlọrun ti ṣe ileri ninu Bibeli. Nigba ti wọn bá dán Ọlọrun wò tikara wọn, wọn a ri ire ọpọlọpọ ati iṣẹgun lori ọtà wọn ẹmi pẹlu.

Ihin tootọ

Awọn iranṣẹọba pada lati sọ fun un pe wọn ri i pe gbogbo ọna “kún fun agbáda ati ohun-elò ti awọn ara Siria gbé sọnù ni iyára wọn.” Nigba naa ni awọn eniyan lọ sinu ibudò awọn ara Siria. Nibẹ ni wọn gbé ri ounjẹ, aṣọ ati owó gẹgẹ bi a ti royin tẹlẹ. Nisisiyi ọpọlọpọ ounjẹ wa ni Samaria. A si ta ounjẹ ni ọpọkúyọkú “gẹgẹ bi ọrọ OLUWA.”

Igbagbọ ati Iyemeji

A fi ijoye, oluranlọwọọba si ẹnubodè. Bi awọn eniyan naa ti n rọ lu ara wọn bi wọn ti n wọẹnubodè, wọn tẹẹ mọlẹ, o si kú. Ọkunrin ti kò gba ileri Ọlọrun gbọ yii kú. Awọn iyoku gbadùn ibukún Oluwa, nitori pe Oun a maa ṣe itọju awọn ti Rè̩. Ọlọrun ki i fi igbà gbogbo pèsè fun awọn eniyan Rè̩ lọna bayi. Nigba miiran a rán wọn lọ si ibòmiràn, gẹgẹ bi a ti rán Elijah si odò nì ni igba ọdá (Wo Ẹkọ 296). A ji ọmọ obinrin ara S̩unemu nì dide kuro ninu okú nipasẹ adura Eliṣa (Wo Ẹkọ 310). Lẹyin eyi, ni akoko iyàn ọdun meje, a rán an lọ si ilẹ awọn Filistini. Ki i ṣe kiki péỌlọrun pèsè fun un ni ọna bayi nikan ṣugbọn Ọlọrun gba gbogbo ohun ini ti o ti fi silẹ pada fun un. Ju gbogbo rè̩ lọ, a dá “gbogbo erè oko lati ọjọ ti o ti fi ilẹ naa silẹ” pada fun un.

Awọn Ileri Tootọ

Ọlọrun a maa pèsè fun awọn eniyan Rè̩. Dafidi Onipsalmu sọ bayi pe, “Tọọ wò, ki o si ri pe, rere ni OLUWA: ... awọn ti nwá Oluwa, ki yio ṣe alaini ohun ti o dara” (Orin Dafidi 34:8-10). Bi ileri ibukun Ọlọrun ṣe daju, bẹẹ gẹgẹ ni ileri idajọ Rè̩ daju.

O ha ti joko ki o si ṣe aṣàrò nipa ohun ti o ṣẹlè̩ si Bẹnhadadi, ọba Siria, ẹni ti i ṣe ọtáỌlọrun ati awọn eniyan Rè̩? Ẹni kan ti o n fẹ gbà ijọba lọwọ rè̩ ni o pa a. Ọré̩ ti o gbẹkẹle ni o fi i hàn. Ninu Iwe Owe a kà pe, “Ibè̩ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rè̩ le OLUWA li a o gbe leke. Ọpọlọpọ enia li o nwá ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ enia li o nti ọdọ Oluwa wá” (Owe 29:25, 26). Olukuluku eniyan ni o le yàn eyi ti o wùú - yálà ki o gbé̩kè̩léỌlọrun tabi ki o gbé̩kè̩lé eniyan. Ninu ta ni igbé̩kè̩lé rẹ wà?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Awọn wo ni o n gbé ni ilu Samaria?
  2. Ta ni Bẹnhadadi?
  3. Bawo ni o ṣe fẹ gba Samaria?
  4. Bawo ni iyàn naa ti mú to?
  5. Ki ni ṣe ti ọkunrin nì fi beerè bi Ọlọrun yoo ba ṣi awọn fèrèséỌrun?
  6. Ki ni ṣe ti awọn adé̩tè̩ mẹrin wọnni fi lọ si ibùdó awọn ara Siria?
  7. Ọna wo ni a lè gbà fi awọn adé̩tè̩ wọnyi wéẹlẹṣẹ?
  8. Bawo ni Ọlọrun ṣe pèsè fun awọn eniyan Rè̩?
  9. Ki ni ṣẹlẹ si ọkunrin ti kò gba ọrọ Eliṣa gbọ?
  10. Ki ni ṣe ti a pa Bẹnhadadi?