2 Awọn Ọba 9:1-37; 10:1-36

Lesson 317 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ikú li ère è̩ṣẹ; ṣugbọn è̩bun ọfẹỌlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 6:23).
Notes

Jehu

Ninu ọkan ninu awọn ogun ti o ṣẹlè̩ laaarin awọn ọmọ Israẹli ati awọn ara Siria, Joramu, ọba Israẹli, gbọgbé̩. O ni lati pada si Jesreeli titi ọgbé̩ rè̩ yoo fi sàn. O paṣẹ fun ẹgbé̩ ogun kan lati duro ni Ramọti-Gileadi lati daabo bo awọn Ọmọ Israẹli. Jehu jé̩ọkan ninu awọn olori-ogun ti o wà nibẹ. O dabi ẹni pe Jehu wà lọdọ Ahabu nigba ti Ọlọrun sọ idajọ ti o n bọ wá sori Ahabu ati ile rè̩ (1 Awọn Ọba 21:21, 27-29). Ọlọrun ti sọ fun Woli Elijah pé Jehu yoo jọba lori Israẹli ati pé yoo mu idajọỌlọrun ṣẹ.

Oniṣẹ Kan

Ni ọjọ kan gẹgẹ bi awọn olori-ogun ti pejọ pọ, oniṣẹ kan ti i ṣe ọdọmọkunri wolii fé̩ bá Jehu sọrọ. Wọn jùmọ lọ si iyara kan nibi ti ọdọmọkunrin wolii gbé sọ fun un pe Eliṣa ni o rán oun si i. O ta òroro si Jehu ni ori o si wi pe, “Bayi li OLUWA Ọlọrun Israẹli wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori enia OLUWA, lori Israẹli.” A paṣẹ fun Jehu lati mu idajọỌlọrun ṣẹ lori ile Ahabu. Ẹnikẹni kò gbọdọ salà: “gbogbo ile Ahabu” ni a ni lati fi idà pa lati gbẹsan è̩jè̩ awọn woli Oluwa ti ẹbi yii ti pa. Eyi ni iṣẹ ti Oluwa fi lé Jehu lọwọ.

Idajọ

“Idajọ OLUWA li otitọ, ododo ni gbogbo wọn” (Orin Dafidi 19:9). Iṣẹ Jehu yii le dabi iṣẹ alailaanu, ṣugbọn wo ibi ti Ahabu ti ṣe sẹyin. Oluwa ati awọn woli Rè̩ ti kilọ fun Ahabu nitori è̩ṣẹ rè̩. Ahabu kò naani gbogbo anfaani ti o ni lati ronupiwada. “S̩ugbọn ko si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rè̩ lati ṣiṣẹ buburu niwaju OLUWA” (1 Awọn Ọba 21:25). Ahabu bọriṣa o si mú ki awọn ẹlomiran ṣe bẹẹ pẹlu. O kùnà lati kọawọn ọmọ rè̩ ni ọna Oluwa, awọn ọmọ rè̩ si tẹle apẹẹrẹ buburu baba wọn. Gbogbo wọn ni o jẹbi niwaju Ọlọrun ti wọn si yẹ si ikú. Akoko ironupiwada wọn ti kọja, wọn si ni lati jiya è̩ṣẹ wọn. Abajọ ti Wolii Isaiah kilọ pe: “Ẹ wá OLUWA nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e, nigbati o wà nitosi” (Isaiah 55:6).

Ikú tabi Ìyè

Lọjọ oni, iwaasu Ihinrere yoo mu idajọ wá sori awọn ti wọn bá kọ lati ronupiwada. Nigba ti eniyan ba gbọ Ihinrere, a fun un ni imọlẹ. Lati rin ninu imọlẹ naa jasi iyè nipa ti ẹmi. Lati kọ imọlẹ yii yoo yọri si ikú nipa ti ẹmi. Nigba ti eniyan ba gbọ Ihinrere, ti o si gba ihin naa gbọ, ti o si gbọran, oun yoo ni iyè. Bi kò bá gbagbọ ki o si gbọran, oun ki yoo yè. Jesu sọ bayi pe: “Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba gbọọrọ mi, ti o ba si gbàẹniti o rán mi gbọ, o ni iyè ti kò nipẹkun, on ki yio si wá si idajọ; ṣugbọn o ti ré ikú kọja bọ si iyè” (Johannu 5:24). Jesu tun wi pe: “Ẹniti o ba gbà a gbọ, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọỌmọ bibi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ” (Johannu 3:18).

Ọkunrin ti Kò fi Iṣẹ Jafara

Lẹyin ti ọdọmọkunrin wolii nì ti fi òroro yan Jehu, ti o si ti fi iṣẹ ti Ọlọrun fi rán an le lọwọ tán, woli yii fi ibè̩ silè̩. Jehu pada tọ awọn iyoku lọ, awọn ẹni ti o sọrọ iwọsi si ọdọmọkunrin woli yii. Wọn fẹ mọ ohun ti o sọ fun Jehu. Nigba ti Jehu sọ fun wọn pe a ti fi òroro yan oun ni ọba, awọn ọmọ-ogun ẹlẹgbé̩ rè̩ yé̩ẹ si. Gẹgẹ bi ami ọlá, wọn té̩ aṣọ wọn sori oke àtè̩gùn lati fi ṣe aga igunwa. Wọn gbé Jehu ka ori rè̩, wọn si fun ipe lati kede pé Jehu jọba.

Jehu jé̩ẹni kan ti kò fi iṣẹ jafara. A ti fun un ni iṣẹ lati ṣe, o si bè̩rè̩ lọgan lati mú aṣẹ Oluwa ṣẹ. O paṣẹ fun awọn ọmọ-ogun ti o wà ni Ramọti-Gileadi pe ẹnikẹni kò gbọdọ sọrọ ohun ti o ṣè̩lẹ yii ni Jesreeli nibi ti Joramu gbé wà.

Ikilọ Oluṣọ

Ẹni kin-in-ni ti Jehu parun ni Joramu, ọmọ Ahabu. Nitori pé ara Joramu kò dá, Ahasiah ọba Juda lọ bè̩é̩ wò. Nigba ti o wà ni Jesreeli, oluṣọ ti o wà lori ile-iṣọ sọ fun wọn pe ẹni kan n bọ wa. Ayà Joramu já, o si rán oniṣẹ kan jade lọ lori ẹṣin lati beere bi alaafia ni. Nigba ti oniṣẹ yii kò pada, o tun rán omiran. Nigba ti oniṣẹ yii kò tun pada, Joramu paṣẹ pe ki a mu kè̩ké̩-ogun oun wá ki oun ba le lọ padé alejò naa.

Gigun Kẹkẹ Kikan-Kikan

Oluṣọ sọ pe oun wòye pe Jehu ni o n bọ wá, nitori pe o n gun kè̩ké̩ kikan-kikan. Oju n kán an gidigidi, o n bọ pẹlu iwara. O dabi ẹni pe a ti mọ Jehu si ẹni ti i maa fi itara ṣe nnkan. Lai si aniani ero rè̩ dọgba pẹlu ti Dafidi ti o wi pe, “Iṣẹọba na jé̩ iṣẹ ikanju” (1 Samuẹli 21:8).

Ọpọlọpọ eniyan ni kò ni itara tó fun iṣẹ Oluwa. Awọn miiran a maa lọra pupọ lati gbọran si aṣẹ Oluwa. Nigba ti Ọlọrun ba fun wa ni ohun kan lati ṣe fun Un, ẹ jẹ ki a fi imoore wa hàn fun anfaani ti O fun ni, nipa ṣiṣe iṣẹ naa lẹsè̩kẹsè̩ dipò ki a fi iṣẹ naa silẹ lai ṣe titi di igba miiran.

Kò si Alaafia

Joramu, tabi Jehoramu gẹgẹ bi a ti maa n pe e nigbà miiran, jé̩ọmọ Ahabu, o si jé̩ọba Israẹli. Ọkunrin kan wà ti o tun n jẹ orukọ yii kan naa. O jẹọmọ Jehoṣafati o si jẹọba Juda (2 Awọn Ọba 8:16). Joramu, ọmọ Ahabu, “si ṣe buburu li oju OLUWA” (2 Awọn Ọba 3:2). O huwa è̩ṣẹ kan naa gẹgẹ bi Jeroboamu, “ti o mu Israẹli dè̩ṣẹ” (2 Awọn Ọba 3:3). Joramu dabi awọn ẹlé̩ṣè̩ miiran: kò ni alaafia bẹẹ ni è̩rù n bà a nipa ohun ti ọjọọla yoo mú wá. A le ri i pe kò fọkàn tán olori-ogun rè̩, è̩ru si ba a nigba ti o ri i pe ẹni kan n bọ wà. A kà ninu Bibeli pe “Alafia kò si fun awọn enia buburu, li OLUWA wi” (Isaiah 48:22).

Ahasiah ati Joramu, olukuluku ninu kè̩ké̩ ti rè̩, jade lati pade Jehu. Nigba ti wọn pàdé, Joramu kigbe pe: “Jehu, alafia kọ?” Bawo ni o ṣe lè ni alafia nigba ti idajọ rọ dè̩dè̩ lori rè̩ nitori è̩ṣẹ rè̩? Bi o ti yi pada lati salọ, ọfa kan lati inu ọrun Jehu bà a. A si gbé okú rè̩ sori ilẹ nibi ti ọgbà Naboti gbé wà tẹlẹ ri. Eyi ni ilẹ naa ti Ahabu ti ṣe ojukòkòrò rè̩ to bẹẹ ti a fi pa ẹni ti o ni in, ki Ahabu ba lè fi ṣe ti rè̩. A beere ẹmi Joramu, ọmọ Ahabu ni ibi kan naa gan an lati gbẹsan è̩jè̩ Naboti ati awọn ọmọ rè̩.

Nigba ti Ahasiah ri ohun ti o ṣẹlẹ si Joramu, o sá, ṣugbọn kò sáàsálà. “Iparun Ahasiah lati ọwọỌlọrun wá ni, nipa wiwá sọdọ Jehoramu: nigbati o si de, o si ba Jehoramu jade tọ Jehu, ọmọ Nimṣi, ẹniti Oluwa fi ororo yàn lati ké ile Ahabu kuro” (2 Kronika 22:7). Ẹwẹ, ọmọbinrin Omri ẹni ti i ṣe baba Ahabu ni iya Ahasiah (2 Awọn Ọba 8:26; 1 Awọn Ọba 16:28). Ahasiah tun bá ile Ahabu tan nipasẹ igbeyawo (2 Awọn Ọba 8:27). Nipa igbesi-ayé ati ijọba Ahasiah a kà pe: “On pẹlu rin li ọna Ahabu: nitori iya rè̩ ni igbimọ rè̩ lati ṣe buburu. O si ṣe buburu loju OLUWA bi ile Ahabu: nitori awọn wọnyi li o nṣe igbimọ rè̩ lẹhin ikú baba rè̩ si iparun rè̩” (2 Kronika 22:3, 4).

Jẹsebẹli

Nigba ti iyawo Ahabu gbọ ohun ti o ṣẹlẹ ati pe Jehu wá si Jesreeli, o le tirõ o si kun atike, o si wé gèlè alarabara. Boya o lero lati fi eyi fa Jehu mọra tabi lati fi ti i siwaju. Bi Jehu si ti gba ẹnu-ọna wọle, obinrin yii yọju loju férèse o si n beere lọwọ rè̩ bi apaniyan kan wà ti o ni alaafia ri. O yẹ ki oun paapaa ti mọ eyi nitori pe o ti mu ki a pa awọn wolii Ọlọrun (1 Awọn Ọba 18:13). Jesebeli darukọ Simri, ẹni ti o ti huwàọdàlè̩ niti pe o ṣọtẹ si oluwa rè̩ o si pa a. O yan ara rè̩ lati mu iṣẹ idajọỌlọrun ṣẹ. Simri “ṣe buburu niwaju OLUWA” (1 Awọn Ọba 16:19).

Kò si Asala

Ọrọ ati iṣe Jẹsebẹli fi hàn pe kò gbàọrọ ti Ọlọrun sọ gbọ. O daba pe Jehu dabi Simri – ki i ṣe ẹni ti o gbọràn si aṣẹỌlọrun. Nipa ọrọ ati iṣe rè̩, o hàn gbangba pe o ni èro lati bọ kuro ninu idajọỌlọrun. Ọna kan ṣoṣo ti eniyan le gbà bọ lọwọ ikú nitori è̩ṣẹ rè̩ ni pe ki o ronupiwada ki a si fi Ẹjẹ Jesu wè̩è̩ṣẹ rè̩. A kà ninu iwaasu Peteru kan pe, “Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa è̩ṣẹ nyin ré̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 3:19). Nigba ti eniyan bá ronupiwada, è̩ṣẹ rè̩ yoo “han gbangba, a mā lọṣāju si idajọ” (1 Timoteu 5:24), ṣugbọn Jẹsebẹli kò jé̩ gbadura fun idariji è̩ṣẹ.

Asọtẹlẹṣẹ. A ti Jẹsebẹli silẹ lati oju ferese loke, awọn ẹṣin si fi ẹsẹ tẹẹ mọlẹ. Nigba ti wọn fẹ lọ sin in, wọn ri i pe apakan ara rè̩ ni o kù. Idajọ wá sori rè̩ gẹgẹ bi ỌrọỌlọrun.

Awọn ỌmọỌba

Aadọrin ọmọkunrin wa ni ilu Samaria ti a mọ ni ọmọ Ahabu. Lai si aniani a ka awọn ọmọ-ọmọ rè̩ ati awọn ọmọ rè̩ pọ ni. Jehu paṣẹ pe ki a bé̩ “awọn ọmọọba” lori. O wipe: “Njẹẹ mọ pe, kò si ohun kan ninu ọrọ OLUWA, ti OLUWA sọ niti ile Ahabu ti yio bọ silẹ, nitori ti OLUWA ti ṣe eyi ti o ti sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rè̩.” Jehu kò pa diẹ ninu idile Ahabu ki o si dawọ duro nitori pe Ọlọrun ti paṣẹ pe ki a pa gbogbo idile Ahabu. Kò fà sẹyin ninu iṣẹ ti o dabi ẹni pe o ṣoro yii. Kò dawọ duro titi o fi ri i pe ẹni kan kò kù ni ile Ahabu – gbogbo awọn eniyan nla rè̩, awọn ibátan rè̩, ati gbogbo awọn woli èké rè̩ ni a pa.

Awọn Olusin Baali

Jehu ri i pe o yẹ ki oun pa è̩sin èké Ahabu ati ile rè̩ paapaa run. Ahabu ni ẹni ti o mu ki awọn Ọmọ Israẹli sin Baali ni akoko yii. Ki i ṣe pe Ahabu fi apẹẹrẹ buburu lelè̩ nipa sisin Baali nikan, ṣugbọn o té̩“pẹpẹ kan fun Baali ninu ile Baali, ti o kọ ni Samaria” (1 Awọn Ọba 16:32). Lẹyin ikú Ahabu, awọn olusin Baali kò mọwọ kuro ninu isin Baali.

Jehu pe gbogbo awọn woli Baali jọ, gbogbo awọn iranṣẹ rè̩, ati gbogbo awọn alufaa rè̩. A kede pe a o pa awọn ti o ba kọ lati fi ara hàn niwaju Jehu. O dibọn bi ẹni pe o fẹṣe irubọ si Baali. S̩ugbọn Jehu fi è̩tàn ṣe e “nitori ki o le” pa awọn olusin Baali run.

O paṣẹ ki wọn yààpèjọ kan si mimọ fun Baali. O ranṣẹ jakejado gbogbo ilẹ Israẹli. Gbogbo awọn olusin Baali ni o wà nibẹ, bẹẹ ni ile Baali si kún fọfọ. Wọn wadii finnifinni lati ri i pe kò si ẹlomiran laaarin wọn bi kòṣe kiki awọn olusin Baali. Bi wọn ti n ba irubọ wọn lọ, Jehu yàn ọgọrin ọkunrin si ode o si paṣẹ fun wọn pe wọn kò gbọdọ jẹ ki ẹni kan ninu wọn sá asála.

Eyi ni ipade ikẹyin fun awọn olusin Baali wọnyi. Ki i ṣe Ọlọrun otitọ ati Ọlọrun alaayè ni wọn n sin. Wọn n rubọ si oriṣa ti kò le riran, ti kò le gbọran, ti kò si le ṣe iranwọ. Awọn eniyan wọnyi kò pa ofin meji ti o ṣaaju ninu ofin ti Ọlọrun fi fun awọn Ọmọ Israẹli lati ọwọ Mose mọ. Iwọ ha mọ ofin meji ti o ṣaaju ninu awọn Ofin Mẹwaa? O wà ninu Ẹksodu 20:1-6.

Nigba ti Jehu ju ọwọ si wọn, awọn oluṣọ ati awọn olori-ogun rọ wọle, wọn si pa gbogbo awọn olusin Baali. A fọ ere Baali a si wo ile Baali lulẹ. “Bayi ni Jehu pa Baali run kuro ni Israẹli.”

Ẹgbọrọ Malu Wura

Nitori pe Jehu ni itara o si ti gbọran si aṣẹỌlọrun, Oluwa ṣeleri fun un pe iran mẹrin ninu idile rè̩ yoo jọba ni Israẹli. Titi de ihin, Jehu ti ṣe eyi ti o dara, ṣugbọn a kọ akọsilẹ ti o ba ni ninu jẹ yii nipa rè̩: “Kòṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rè̩ rin ninu ofin OLUWA Ọlọrun Israẹli.” Kò tẹra mọọn lati maa sin Ọlọrun lai yẹsẹ ati lati maa gbọran si I lẹnu. Jehu tẹle è̩ṣẹ Jeroboamu, ẹni ti o ṣe ẹgbọrọ malu wura meji -- ère – fun awọn eniyan lati maa sin ni Bẹtẹli ati ni Dani (1 Awọn Ọba 12:28, 29). O tilẹ kede fun awọn eniyan pe awọn ẹgbọrọ malu wura wọnyi -- oriṣa – ni awọn ọlọrun ti o mu wọn jade kuro ninu oko-ẹru ni Egipti.

Jehu tẹle è̩ṣẹ Jeroboamu. Jehu pa ere Baali run ṣugbọn o n sin ẹgbọrọ malu wura wọnni. Eyi ki i ṣe ilana Ọlọrun, o si jé̩ ohun ti o burú bakan naa gẹgẹ bi ibọriṣa lọna miiran ti burú. Bi o ti wù ki iṣẹ rère eniyan tabi itara rè̩ pọ to, o ni lati gbọran si Ọlọrun ninu ohun gbogbo ki o si maa rin ninu ipa ọna ododo. Jesu sọ bayi pe, “Bi ẹnyin ba duro ninu ọrọ mi, nigbana li ẹnyin jẹọmọ-ẹhin mi nitõtọ” (Johannu 8:31), ati “Ẹniti o ba foriti i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà” (Matteu 10:22).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni Jehu iṣe?
  2. Ta ni ẹni ti o fi òróró yàn an ni ọba lori Israẹli?
  3. Iṣẹ wo ni Ọlọrun fun un lati ṣe?
  4. Bawo ni Jehu ṣe tẹra mọ iṣẹ rè̩ si?
  5. Ki ni ṣe ti a fi ni lati pa idile Ahabu run?
  6. Ta ni Jẹsebẹli i ṣe?
  7. Asọtẹlẹ wo ni a muṣẹ nigba ti o kú?
  8. Iru ẹsìn wo ni Ahabu gbé kalè̩ ni Israẹli?
  9. Ki ni ṣe ti a fi pa awọn olusin Baali ati oriṣa Baali run?
  10. Bawo ni eniyan ṣe le bọ lọwọ idajọỌlọrun?