1 Awọn Ọba 17:1; 2 Awọn Ọba 4:8, 13, 35, 42-44; 1 Awọn Ọba 18:12-18; 2 Awọn Ọba 3:16, 17; 1 Awọn Ọba 19:9-14, 18-21; 2 Awọn Ọba 2:21

Lesson 318 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wòẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkunrin na” (Orin Dafidi 37:37).
Notes

Ipe Elijah

A pe Elijah lati jé̩ woli Ọlọrun nigba ti ọkàn awọn Ọmọ Israẹli yi pada kuro lọdọỌlọrun awọn baba wọn. Ahabu, ọba wọn, ti gbé obinrin keferi kan ni iyawo; bẹẹ ni obinrin buburu ti a n pe ni Jesebeli yii ti yi i lọkàn pada lati maa sin awọn ọlọrun keferi. Awọn eniyan wọnyi si tẹle alakoso wọn, bẹẹ ni ọkàn gbogbo Israẹli si dibajẹ.

A kò sọ ohunkohun fun wa nipa ile tabi ẹbi Elijah. Ninu aginju ni o gbe lo pupọ ninu ibẹrẹ igbesi-ayé rè̩. O jé̩ ogboju, akọni ọkunrin, ti o bè̩ru Ọlọrun nikan ṣoṣo.

Elijah ni iṣẹ ti o ṣoro lati ṣe, ṣugbọn o kaju iṣẹ naa. Iṣẹ ti Elijah yoo ṣe ni gbogbo igbesi-ayé rè̩ ni lati fi hàn fun awọn Ọmọ Israẹli pe Ọlọrun kan ṣoṣo ni o wà, Ọlọrun ti o sọ wọn di orilẹ-ède nigba ti O fi Ofin fun Mose lori Oke Sinai. Iṣẹ rè̩ kò rọrùn nitori pe awọn eniyan kò fẹ ki a sọ fun wọn nipa è̩ṣẹ wọn tabi ki a kilọ fun wọn nipa idajọ. Wọn kò ni fẹ lati gbọ ti rè̩. O ni lati lọ siwaju ọba ati awọn eniyan lati sọ fun wọn pe gbogbo wọn ti ṣina ninu ẹsin ati iwa ayé wọn; kò si si ẹni ti yoo fi ojurere wo o nitori eyi.

Elijah ki i saba lọ saarin ilu. Nigba ti o ba si lọ, o wá lati kede idajọỌlọrun ni. Lẹyin eyi, yoo tun tara ṣaṣa pada sinu aginju. Awọn eniyan kan gbagbọ pe Ẹmi Ọlọrun ni o maa n gbe e lati ibi kan de ibi keji (1 Awọn Ọba 18:12) ti o si n pa a mọ nigba ti awọn ọtá rè̩ ba fẹ pa a run.

Idajọ

Ohun wọnni ti Elijah ṣe tobi o si wú ni lori. O le duro niwaju awọn eniyan ki o si sọ pẹlu idaniloju pe, “Bi OLUWA Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, ki yio si iri tabi òjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọrọ mi” (1 Awọn Ọba 17:1). Eyi jé̩ idajọ lori awọn Ọmọ Israẹli nitori ipadasẹyin wọn kuro lọdọỌlọrun, eyi si fi hàn dajudaju nigba ti imuṣẹ rè̩ dé péỌlọrun kan wà ni Israẹli ti o n dahùn adura. Fun ọdun mẹta ati oṣu mẹfa ni ọdá omi fi dá awọn eniyan. Wọn kò si fi ojurere wo Elijah nitori ipa ti rè̩ ninu idajọ yii (1 Awọn Ọba 18:17).

Lẹyin ti iná ti sọkalẹ ti o si sun ẹbọ Elijah lori Oke Karmẹli, o pa awọn aadọtale-nirinwó woli Baali. Elijah ṣe ohun ti o wu Ọlọrun nipa igbọran rè̩ si aṣẹỌlọrun, ṣugbọn ayaba bura lati gbẹsan nipa ṣiṣe ẹmi rè̩ gẹgẹ bi ọkan ninu awọn woli ti o kú wọnni ki ilẹọjọ naa tóṣú. Elijah fi ara pamọ lati gbàẹmi rè̩ là.

Nigba miiran è̩wẹ, Elijah pe ina sọkalẹ lati Ọrun wá lati jóẹgbé̩ọmọ-ogun araadọta meji ti o wá lati mu un run. Ọlọrun fi agbara yii fun Elijah lati fi wè̩ Israẹli ti o kun fun ibọriṣa mọ.

Ohùn Jé̩jé̩, Kẹlẹkẹlẹ Nì

Ni ọjọ kan Ọlọrun fi hàn fun Elijah pe isin ti Oun yàn fun Israẹli ki i ṣe kiki iná ati idajọ. Elijah dá nikan wà ninu iho apata nibi ti o gbé sá pamọ si kuro lọdọ ayaba buburu nì. O rò pe iṣẹ oun kò mu ire pupọ wá. Awọn eniyan naa n sin oriṣa sibẹ lẹyin gbogbo aapọn ti o ti ṣe lati mu wọn yi pada si Ọlọrun. O rò pé oun nikan ṣoṣo ni o kù ti o fé̩Ọlọrun ni gbogbo Israẹli.

Ọlọrun sọ fun Elijah pe ki o lọ duro lori oke naa ati pe Oun yoo kọja nibẹ. Iji nla jà, iji naa le to bẹẹ ti o fọ apata tuutu nipa ipa rè̩. S̩ugbọn Oluwa kò si ninu iji naa. Lẹyin eyi isẹlẹ kan sè̩. Boya Elijah ranti isẹlẹ nla ti o sè̩ ti o mu ki Oke Sinai mì tìtì nigba ti Ọlọrun fi Ofin fun Mose. S̩ugbọn lakoko yii, Ọlọrun kò si ninu isè̩lè̩ naa, bẹẹ ni kò si si ninu iná ti o tun wá tẹle eyi. Lẹyin naa Elijah gbọ ohun jé̩jé̩, kẹlẹkẹlẹ kan, ohun ifẹ, aanu ati itura. Eyi ni ohun Ọlọrun ti o n fọ si oloootọ woli yii lati mu un ni ọkàn le. Bi o tilẹ jẹ pe Elijah kò le ri iṣẹỌlọrun, sibẹ iṣẹ naa n tẹ siwaju lọnà jé̩jé̩. Ẹẹdé̩gbaarin eniyan wà ni Israẹli ti kò tẹ eekun wọn ba fun Baali, ti kò si fi ẹnu ko ere rè̩ lẹnu.

Atẹle Elijah

Eliṣa ẹni ti o rọpò Elijah fi idi iṣẹ ti Elijah bé̩rẹ mulẹ. Bawo ni o yẹ ki ọpẹ awọn Ọmọ Israẹli si Ọlọrun pọ tó fun irú eniyan bi Elijah ẹni ti o sé̩ ara bẹẹ ti o si ṣetan lati dide fun iranlọwọ Oluwa bi o tilẹ jẹ pe o ni lati gbé igbesi-ayé ti kò rọgbọ ti a kò si kà si! Ọlọrun ni iṣẹ pupọ fun eniyan lati ṣe, a kò si gbọdọ fé̩ awọn eniyan kù ti yoo mura tan lati ja ija ajaku-akátá ki awọn eniyan ba le ni otitọỌrọỌlọrun ninu ọkàn wọn.

Ki Elijah to pari iṣẹ rè̩, Ọlọrun rán an lati fi òróró yan Eliṣa lati jé̩ woli lẹyin rè̩. Eliṣa jé̩ẹni ti o yatọ patapata. O n gbe laaarin ẹbi rè̩ gẹgẹ bi bọrọkini eniyan ati agbẹ ti o gbamuṣe. S̩ugbọn lati ọjọ ti Elijah ti n kọja lọ ti o si ti da agbádá rè̩ bò o, itumọ eyi ti i ṣe pe o n fé̩ ki Eliṣa jẹ “ọmọ” tabi olùrọpò rè̩. Eliṣa bè̩rè̩ si i murasilẹ lati tè̩le ifẹỌlọrun.

Lai si aniani, yoo ṣoro fun Eliṣa lati fi ẹbi ati iṣè̩ rè̩ silẹ, ṣugbọn o mọ pe ipè lati Ọrun wá ni, iṣẹỌlọrun si wá jọọ loju ju ohunkohun lọ. Fun iwọn ọdun diẹ o n ba Elijah rin o si n ṣe iranṣẹ fun un, ni gbogbo akoko yii o n kọè̩kọ ohun wọnni ti o n bọwa jé̩ ohun iyebiye fun un nigba ti akoko ti rè̩ bá tó lati maa bá iṣẹ nla ti Elijah ti bè̩rẹ lọ.

Eliṣa beerè ilọpo meji Ẹmi ti o wà lara Elijah. Nitori ijolootọ rè̩, a mu ibeere rè̩ṣẹ. Gẹgẹ bi awọn iṣẹ-iyanu ti a kọ akọsilẹ rè̩ ninu Iwe Mimọ, Eliṣa ṣe ilọpo meji iṣẹ-iyanu ti Elijah ṣe.

Ifiwera Iṣẹ-iranṣẹ Elijah ati Eliṣa

Iṣẹ Eliṣa jé̩ eyi ti yoo yatọ lọpọlọpọ si ti Elijah. Elijah lo ọpọlọpọ ninu ọjọ ayé rè̩ ninu ijù nikan ṣoṣo, lati fi ara pamọ kuro lọdọ awọn eniyan ati ijọba, a si maa fi ara hàn lẹẹkọọkan lati kede ỌrọỌlọrun. Eliṣa n gbé aarin ilu pẹlu awọn eniyan (2 Awọn Ọba 4:8), o si jé̩ẹni ti ọba mọ dunju-dunju ti o si fẹran(2 Awọn Ọba 4:13).

Ọpọlọpọ ninu iṣẹ-iranṣẹ Elijah jé̩ iṣẹ idajọ, Eliṣa n lọ kaakiri o si n ṣe iṣẹ oore ati aanú -- awọn ohun ti yoo mu ki ọkàn awọn eniyan fa mọọn. Iṣẹ kin-in-ni ti Elijah ṣe ni lati sọ asọtẹlẹ nipa iyàn; iṣẹ kin-in-ni ti Eliṣa ṣe ni pe o ṣe awotan omi ti o korò. Iṣẹ-iyanu Eliṣa fara jọ iṣẹ-iranṣẹ Kristi nigba ti O wà láyé laaarin awọn eniyan, ti O n wò alaisàn sàn, O n fun alaarè̩ ni isinmi, O sọ ounjẹ diẹ di pupọ fun awọn ti ebi n pa, O si n ṣe iranlọwọ ni oriṣiriṣi ọna gbogbo.

Akoko Aanu

Akoko idajọ wà -- Ọlọrun si ti lo diẹ ninu awọn woli Rè̩ lati kede rè̩ -- ṣugbọn Jesu sọ bayi nigba ti O wà ni ayé: “O ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ” (Luku 4:18).

Ni ọjọ kan ti awọn ara Samaria ṣe iwọsi si Jesu, awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ wi pe: “Oluwa, iwọ ko jẹ ki awa pè iná lati ọrun wá, ki a sun wọn lúlu, bi Elijah ti ṣe?” (Luku 9:54). Jesu fi ọrọ wọnyi báa wọn wi pe: “Ọmọ enia ko wá lati pa ẹmi enia run, bikoṣe lati gbà a là” (Luku 9:56). Akoko idajọ kò i ti i tó.

Iṣẹ-iranṣẹ Eliṣa kún fun iṣẹ aanu: o sọòróró opó nì di pupọ ki oun ati ọmọ rè̩ le ri nnkan gbọ bukata wọn (2 Awọn Ọba 4:1-7); o ṣe awotan omi ti o korò ni Jẹriko (2 Awọn Ọba 2:21); o pese ounjẹ fun awọn ọmọ ile-è̩kọ awọn woli nigba ọdá (2 Awọn Ọba 4:42-44); o ji ọmọ opó kan dide kuro ninu okú (2 Awọn 4:35); o pese omi fun awọn ọmọ-ogun Israẹli ati Juda ti oungbẹ n gbẹ (2 Awọn Ọba 3:16, 17). Nigba kan, nigba ti o mu odindi ẹgbẹọmọ-ogun Siria, o fun wọn ni omi ati ounjẹ, o si rán wọn pada lọ si ile wọn. Ani lẹyin ti o tilẹ ti kú, agbára wà ninu egungun rè̩ ti o sọ okú jagun-jagun kan ti a gbé sọ sinu iboji rè̩ di alaaye (2 Awọn Ọba 13:21).

Bayi ni igbesi-ayé awọn eniyan Ọlọrun meji nla wọnyii ri, olukuluku pẹlu iṣẹ ti rè̩ lati ṣe ni ọnà ti rè̩, ṣugbọn awọn mejeeji mú ifẹỌlọrun ṣẹ ni orilẹ-ède Israẹli.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni a mọ nipa ibè̩rẹ igbesi-ayé Elijah ati iwà ayé rè̩?
  2. Ki ni iyatọ ti o wà ninu igbesi-ayé ati iwa ayé Eliṣa ati ti Elijah?
  3. Irú iṣẹ-iyanu wo ni o pọ ju lọ ninu iṣẹ-iyanu ti Elijah ṣe?
  4. Ọna wo ni awọn iṣẹ-iyanu Eliṣa fi fara jọ iṣẹ-iyanu ti Jesu?
  5. Ki ni iṣẹ-iyanu ti Elijah kọkọṣe?
  6. Ki ni iṣẹ-iyanu kin-in-ni ti Eliṣa ṣe lẹyin ti ó ti ré Odò Jọrdani kọja?
  7. Ki ni ṣe ti Elijah ni lati ṣe awọn irú iṣẹ ti o ṣe wọnyii?
  8. Fi iye iṣẹ-iyanu ti Eliṣa ṣe wé iye iṣẹ-iyanu ti Elijah ṣe.
  9. Ki ni ohun ti Eliṣa beerè kẹyin lọwọ Elijah?
  10. Ki ni iṣẹ-iyanu ikẹyin ti a ka mọ iṣẹ Eliṣa?