2 Awọn Ọba 11:1-21; 2 Kronika 24:1-27

Lesson 319 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Mo fẹ awọn ti o fẹ mi; awọn ti o si wá mi ni kutukutu yio ri mi” (Owe 8:17).
Notes

Awọn Onroro Alaṣẹ

Ọba buburu kan ti o kún fun owú, ti a n pe orukọ rè̩ ni Farao paṣẹ nigba kan pe ki a pa gbogbo awọn ọmọ-ọwọ ti i ṣe ọkunrin ni Egipti. A ranti itàn ọmọ-ọwọ nì ti a n pè ni Mose ẹni ti iya rè̩ fi pamọ sinu apóti eeṣú ti o si gbé e sinu koriko lẹba odò (Ẹksodu 2:3). Ọlọrun ni iṣẹ fun Mose lati ṣe, kò si jé̩ ki ipinnu ọba buburu nìṣẹ. Ọba Hẹrọdu, alaiwàbi-Ọlọrun ọba miiran, n bẹru pe a o gba ijọba lọwọ oun, nitori naa o paṣẹ pé ki a pa awọn ọmọkunrin lati ọmọọdun meji silẹ. Eyi ṣẹlẹ ni Bẹtlẹhẹmu lẹyin ti a bi Jesu (Matteu 2:16). A mọ pe Ọlọrun ni Ọrun n ṣọè̩ṣọ lori Ọmọ Rè̩.

Nisisiyi a fẹ kè̩kọọ nipa ayaba buburu kan ti a n pe ni Ataliah, ẹni ti o fẹ lati jọba ti o si n bè̩ru péẹlomiran le fẹ gba ijọba lọwọ oun. Nitori naa o mú ki a pa gbogbo idile ọba run. S̩ugbọn arabirin Ahasiah ti o ti jé̩ọba tẹlẹ gbéọmọkunrin kekere ọmọ-ọba, ẹni ti i ṣe ọmọọdun kan pere, o si fi ọmọ naa ati olutọju rè̩ pamọ si iyè̩wu kekere kan ninu Tẹmpili. Ni ilẹ ilà-oorun, iyẹwu kekere yii jé̩ ibi ti a maa n kó timtim ti a n sun le ati awọn ẹni ti a n tẹ silẹ ni gbọngan ti a gbe n ṣe faaji si. Lai si aniani ọmọde naa ati olutọju rè̩ a maa sun nibẹ wọn a si wà laaarin agbala Tẹmpili ni gbogbo akoko naa. Ataliah ki i saba lọ si Ile Oluwa nigba gbogbo bi bẹẹ kọ oun i ba ti ri ọmọde yii. A pa Joaṣi mọ fun ọdun mẹfa gbako, ni akoko yii, Ataliah n jọba ni ilẹ Juda. Iwọ ha rò pé obinrin apaniyan lé jé̩ọba-binrin rere?

Ọba Gbade

Lọjọ kan, Jehoiada alufaa tootọ pe awọn olori-ogun ati awọn ọkunrin alagbara jọ si Tẹmpili. Lẹyin eyi ó gbéọmọde naa, ẹni ti o ti di ọmọọdun meje ni akoko yii jade nibi ti a gbé e pamọ si. O sọ ohun ti o fẹṣe fun awọn akọni ọkunrin wọnyi: ni ọjọ Isinmi, ki wọn ki o pín ara wọn si ẹgbé̩ mẹta ki wọn si maa ṣọ Ile Oluwa ati ọmọde naa -- Joaṣi. Nigba ti o di ọjọ Isinmi, awọn ọkunrin wọnyi ṣe ohun ti a ti sọ fun wọn. Nigba naa ni Jehoiada alufaa gbéọmọ-ọba naa jade, ani Joaṣi, o si fi adé dé e ni ori. A ta òróró si i ni ori, ayọ pupọ si wà ni Tẹmpili ni ọjọ naa, bi awọn eniyan ti n pàté̩wọ ti wọn n kigbe ni ohun rara pe: “Ki ọba ki o pẹ.” Wọn si fun ipè kikan-kikan. Ọba ti gbade!

Ataliah ki i wá si Ile Ọlọrun, nitori pé ninu tẹmpili Baali ni o gbé n jọsin. A kò pè e lati wá si ibi aṣeyẹ dídéọba lade yii, ṣugbọn nigba ti o gbọ ohùn ìpè, hiho ati atẹwọ, o tara ṣaṣa lọ si Tẹmpili -- ṣugbọn o ti pé̩ jù ki ó tó wá si Ile Ọlọrun! Inu gbogbo awọn ti o wà nibẹ dun; ṣugbọn ọba obinrin yii binu o si fa aṣọ rè̩ ya o n kigbe pe, “Ọtè̩! Ọtè̩!” A mu un gbàọna ti awọn ẹṣin n gbà jade; ni è̩bá ile ọba ni a pa obinrin buburu yii ẹni ti o ti mu ki a pa gbogbo idile ọba run. Gbogbo ète buburu ti di asán, o si jiya è̩ṣẹ rè̩. Ẹlẹṣẹ ki i lọ lai jiya, i baa ṣe ọmọ-ọdọ tabi alaṣẹ lori ìté̩.

Ijọba Joaṣi

Ọdọmọkunrin, ọba titun yii, ti i jẹ Joaṣi, ni anfaani lati ni ẹni iwa-bi-Ọlọrun, apẹẹrẹẹni ti o lè tẹle. A ka a wi pe “Jehoiada si da majẹmu lārin OLUWA ati ọba ati awọn enia, pe, ki nwọn ki o māṣe enia OLUWA; ati lārin ọba pẹlu awọn enia” (2 Awọn Ọba 11:17). Eyi ṣẹlẹ gé̩ré̩ ti ọba titun yii jọba ati lẹyin ikúọba obinrin buburu nì. Nigba naa ni awọn eniyan wó pẹpẹ Baali, ọlọrun èké nì lulé̩, “awọn ere rè̩ ni nwọn fọ tútu patapata.” A ti bẹrẹ iṣẹ rere daradara.

Joaṣi kún fún itara fun Ọlọrun: a ni lati tún Ile Ọlọrun ṣe a si ni lati náọpọlọpọ owó si iṣẹ yii. O sọ fun awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi lati kó owó jọ lati fi tun ile Ọlọrun ṣe, o si wi pe, “Ẹ mu ọran na yá kankan.” Nigba ti wọn n fi ọran naa falè̩, o pe Jehoiada o si beerè lọwọ rè̩ ki ni ṣe ti owó kò fi wọlé. Nitori naa ọba paṣẹ pe ki a gbé apoti kan si ẹnu-ọna Ile Oluwa. Eyi dùn mọ gbogbo eniyan, wọn mú owó wá, wọn si sọọ sinu apoti naa. A n ṣi apoti naa lojoojumọ, a si n gbe e pada si ayè rè̩ lẹyin ti a ba ti kó owó ti o wà ninu rè̩ kuro. Owo ti o wọle tó lati gba awọn ọmọlé, gbé̩nàgbé̩nà, ati awọn oṣiṣẹ ti irin ati ti idẹ lati tun Ile Ọlọrun ṣe. Bawo ni o ti dùn lati ri i pe a ti tun gbé Tẹmpili ró fun isin Ọlọrun, ani Tẹmpili ti awọn ọmọọba-binrin buburu nì ti wó lulẹ.

Nigba ti Jehoiada di ẹni aadoje (130) ọdun, o kú, a ṣe isinkú rè̩ tè̩yẹtè̩yẹ ni ilu Dafidi, nitoriti “o ṣe rere ni Israẹli, ati si Ọlọrun, ati si ile rè̩” (2 Kronika 24:16). Lati fi aadoje (130) ọdun sin Ọlọrun tọkàntọkan ati lati ṣe rere fun eniyan pẹlu! S̩ugbọn ọmọdekunrin ọba yii n kọ -- o ha ni akọsilẹ ti o dara bi eyi? Ẹ jẹ ki a wòó.

A kà wi pe Joaṣi, ọba, ṣe eyi ti o tọ ni oju Oluwa ni gbogbo ọjọ Jehoiada alufaa, ṣugbọn nisisiyi ti Jehoiada kú, ohun gbogbo yi pada. Ko si itọni Ọlọrun mọ; adura eniyan mimọ yii ti o n goke tọỌlọrun lọ ti dẹkun pẹlu.

Joaṣi, iwọ tikara rẹ ni lati gbadura fun ara rẹ nisisiyi; iwọ ki i ṣe ọmọde mọ. Iwọ kò le fi gbogbo ọjọ ayé gbé ara le ẹni ti o de ọ lade ti o si fi òroro yàn ọ fun iṣẹỌlọrun. Joaṣi, ọkàn rẹ ha n fẹ ipọnni awọn ọmọ-alade Juda ti o n wá lati wolẹ fun ọ? Iwọ ha rò pe awọn wọnyi gbọn ju woli Ọlọrun lọ? Imọran wọn ha nilaari ju ti awọn eniyan Ọlọrun lọ? Iwọ ha le fi aake kọri ki o si kẹyin si ohun ti o tọ ti o si dara lati té̩ awọn ọmọ-alade wọnyi lọrun?

S̩ugbọn eyi gan an ni ohun ti Joaṣi ṣe. O tun gbà fun awọn eniyan lati maa bọriṣa; o gbagbe aanu ti Jehoiada fi hàn fun un; o si mu ki a pa Sẹkariah ọmọ alufaa yii nitori pe o bá Joaṣi wi nitori pe o yi pada kuro lọdọỌlọrun.

Wò o bi o ti fara jọ Saulu, ọdọmọkunrin ti a yàn lati jé̩ọba! Oun pẹlu, bẹrẹ daradara, nigba ti o kere loju ara rè̩ Oluwa wà pẹlu rè̩ (1 Samuẹli 15:17). S̩ugbọn nigba ti o ṣe aigbọran si Ọlọrun ti o si kọ aṣẹ Samuẹli, woli Ọlọrun silẹ, Oluwa pẹlu kọọ silẹ. Iṣubu Saulu fi ara jọ ti Joaṣi pupọ. “Nitoripe iwọ kọọrọ OLUWA, on si kọọ li ọba,” li ọrọ ti a sọ fun Saulu (1 Samuẹli 15:23). Woli Sẹkariah sọ fun Joaṣi pe, “Nitoriti ẹnyin ti kọ OLUWA silẹ, on pẹlu si ti kọ nyin” (2 Kronika 24:20). Igbẹyin Joaṣi buru nitori pe o kọọna titọ silẹ o si yi pada kuro lọdọỌlọrun, dipo ti i ba fi tẹle apẹẹrẹ rere Jehoiada.

Wo iyatọ ti o wa laaarin Joaṣi ati Jehoiada! Jehoiada gbé aadoje ọdun laye o si ni akọsilẹ rere niwaju Ọlọrun ati eniyan. Boya Joaṣi kò tilẹ to ẹni aadọta ọdun nigba ti awọn ọmọ-ọdọ rè̩ṣọtẹ si i ti wọn si pa a. Joaṣi ṣe gẹgẹ bi Rehoboamu ti ṣe. “O kọ imọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti nwọn dagba pẹlu rè̩, ti nwọn si duro niwaju rè̩ gbimọ” (1 Awọn Ọba 12:8). ỌrọỌlọrun n kilọ fun awọn ti o yi pada kuro lọdọ Rè̩: “Ẹnyin ti ṣá gbogbo igbimọ mi ti, ẹnyin kò si fẹ ibawi mi: Emi pẹlu o rẹrin idāmu nyin; emi o ṣe è̩fẹ nigbati ibè̩ru nyin ba de” (Owe 1:25, 26).

Iforiti titi Dopin

Ẹ jẹ ki a kọè̩kọ ninu akọsilẹ igbesi-ayéọmọdekunrin ọba yii, ẹ si jẹ ki a gbadura pe ki Ọlọrun ràn wá lọwọ lati ni eti igbọ ati àyà lati kọè̩kọ nigba ti Ọlọrun bá n bá wa sọrọ lati inu Ọrọ Mimọ Rè̩, tabi nipasẹ awọn iranṣẹ Rè̩, awọn olùkọ ati awọn òṣiṣé̩. Ọlọrun lo Joaṣi nigba ti o tilẹ jé̩ọmọde kekere, bẹẹ ni Ọlọrun le lo ẹni ti o kere ju lọ paapaa lode oni bi wọn o ba jé̩ jọwọọkàn ati ayé wọn patapata fun Ẹmi Mimọ. S̩ugbọn nigba ti wọn ba tó tán ni oju ara wọn ti wọn si rò pé wọn gbọn ju awọn wọnni ti wọn ti lo ọpọlọpọọdun ninu Ihinrere ti wọn si ti ni ọpọlọpọ iriri, o yẹ ki wọn mọ pe wọn wà ninu ewu.

A ka a ninu Bibeli pe, “Bi awọn ẹlẹṣè̩ ba tàn ọ, iwọ máṣe gbà” (Owe 1:10). Ẹ jẹ ki a bẹỌlọrun ki o ràn wá lọwọ lati mọ iyatọ laaarin imọran rere ati buburu ti awọn eniyan n fi fun wa. A ri i nipa igbesi-ayé Joaṣi pe o ṣe e ṣe fun eniyan lati pada lẹyin Ọlọrun, ṣugbọn wò bi ọpẹ wa ti pọ tó pe o ṣe e ṣe fun eniyan lati bè̩rẹ si sin Ọlọrun lati igba èwe rè̩ ki o si jé̩ olododo ati oloootọ jalè̩ gbogbo ọjọ ayé rè̩. “Ẹniti o ba foriti i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà” (Matteu 10:22).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ fun ni bi a ṣe dáẹmi Joaṣi si.
  2. Nibo ni a fi i pamọ si?
  3. Sọ bi a ṣe de ọba ni ade.
  4. Ọmọọdun meloo ni Joaṣi nigba ti o jọba?
  5. Ta ni ẹni ti o wá si Ile Oluwa ni akoko yii?
  6. Awọn iṣẹ rere wo ni Joaṣi ṣe?
  7. Ki ni ṣẹlẹ lẹyin ikú alufaa naa?
  8. Ọna wo ni asọtẹlẹ Sẹkariah fi ṣẹ?
  9. Wá awọn ẹsẹỌrọỌlọrun ti o kọ wa pe Ọlọrun a maa jẹ awọn ẹlẹṣẹ niya.