Jona 1:1-17; 2:1-10; 3:1-10; 4:1-11

Lesson 320 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi o fi ohùn idupẹ rubọ si ọ; emi o san ẹjé̩ ti mo ti jẹ. Ti OLUWA ni igbala” (Jona 2:9).
Notes

Ipe Woli Naa

Ni akoko awọn Ọmọ Israẹli ni ọpọlọpọọdun sẹyin, wolii kan wà ti a n pe ni Jona ẹni ti Ọlọrun yàn lati sọ fun awọn Eniyan AyanfẹỌlọrun ohun wọnni ti o n bọwáṣẹlẹ si wọn ni ọjọ iwaju. A kò sọ pupọ fun ni nipa iṣẹ rè̩ ni Israẹli, tabi ohun ti o sọ nipa awọn Ọmọ Israẹli (2 Awọn Ọba 14:25) ṣugbọn ohun iyanu kan ṣẹlẹ ni igbesi-ayé rè̩, akọsilẹ eyi ti o gba odindi iwe kan ninu Bibeli.

Ọlọrun pe Jona lati lọ waasu fun ilu keferi kan. Ilu yii jẹ ilu nlá, awọn eniyan ibẹ si buru jai. Ọlọrun ri iwa buburu wọn, O si pinnu pe akoko tó lati rán idajọ sori wọn bi wọn kò ba ronupiwada. Ọlọrun ninu aanu Rè̩ fun wọn ni anfaani kan si i.

Ẹniti o ba Fẹ

Jona le rò pe ko ṣanfaani lati lọ si Ninefe. Wọn ki i ṣe Eniyan AyanfẹỌlọrun, ki ni ṣe ti oun ni lati lọ waasu fun wọn? Boya kò tilẹ fé̩ ki wọn ronupiwada ki wọn si ri igbala. O le jẹ pe o fẹ ki gbogbo ibukun Ọlọrun wá sori Israẹli nikan ṣoṣo.

Awọn eniyan kan wà lode oni ti wọn rò pe awọn diẹ ti a yàn ni a o gbalà, lẹyin eyini kò si ẹni ti o tun yẹ si igbalà. S̩ugbọn ọrọ Jesu mú inu wa dùn: “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobḝ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rè̩ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ má bàṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun” (Johannu 3:16). Isaiah, ọkan ninu awọn woli Majẹmu Laelae kigbe pe: “Njẹ gbogbo ẹniti ongbẹ ngbẹ, ẹ wá sibi omi, ati ẹniti kò li owo; ẹ wá, ẹ rà, ki ẹ si jẹ” (Isaiah 55:1). A fi anfaani igbala lọ gbogbo eniyan nipa ọrọ wọnyii. Ẹnikẹni ti o ba fẹ lè wá ki a si gbà a là.

Ajihinrere ni Ilu Okeere

Anfaani ṣi silẹ fun Jona lati jé̩ ajihinrere ni ilu okeere, ṣugbọn o kọ lati ṣe bẹẹ. O yi pada o si sá fun ipèỌlọrun. Ni Joppa o ri ọkọ kan ti o n lọ si Tarṣiṣi, o sanwo ọkọ ki o ba le salọ jinna rére si Ninefe ki o si fi ara pamọ kuro niwaju Ọlọrun. S̩ugbọn kòṣe e ṣe fun un lati sá kuro niwaju Ọlọrun. Ọlọrun wà nibi gbogbo, bẹẹ ni O si ri Jona bi o ti n wọọkọ ti o n lọ sinu agbami òkun. O yẹ ki a maa ranti nigba gbogbo pe kò si ohun ti a ṣe ti o pamọ kuro loju Ọlọrun.

Ọlọrun fun Jona ni iṣẹ lati ṣe, ipè naa wà sibẹ. Awọn ohun kan yoo ṣẹlẹ si Jona ti yoo mu ki o fẹ lọ si Ninefe.

Jona ti rò pé kò si ẹni kan ti o mọ ibi ti oun wà, o lọ si isalẹọkọ o si sùn fọnfọn. Ọkan rè̩ wá balẹ pẹsẹ pe oun ki yoo lọ si Ninefe mọ! S̩ugbọn isinmi rè̩ yii ki yoo pẹ lọ titi. Lai pẹìjì lile bè̩rè̩; idaamú nla de ba awọn ti o wà ninu ọkọ. Awọn atukọ bè̩rè̩ si i sáre sihin-sọhun wọn si n kóẹrù dà sinu omi lati mú ki ọkọ fúyé̩ ki o má ba fọ wé̩wé̩. Bi wọn ti n ṣe gbogbo wahala yii, wọn n ke pe ọlọrun wọn lati gbà wọn là kuro lọwọ ikú. Sibẹ Jona sùn!

OrunẸmi

Wo bi Jona ti fara jọ awọn ti o fa sẹyin kuro lọdọỌlọrun! Wọn a maa gbé igbesi-ayéè̩ṣẹ ni ireti pe wọn n gbadun aye wọn. Eṣu ti ré̩ wọn jẹ nipa ti ẹmi, è̩ṣẹ ati è̩rù idajọ ti o rọ dẹdẹ sori wọn kò bà wọn lè̩rù mọ. Bi wọn ko ba ji giri lakoko, idájọ yoo de ba wọn, wọn a si ṣègbé patapata.

Ọga-ọkọ ti i ṣe è̩lè̩ṣẹ, wá ji Jona lati gbà a lọwọ ikú. O sọ fun un pe ki o gbàdúrà si Ọlọrun rè̩, Ọlọrun Israẹli, ki o si beerè pe ki O ṣaanu fun wọn ki gbogbo wọn má ba ṣegbé.

Wiwa fun Ẹlomiran

Ọlọrun ni o ran ẹfuufu lile yii lati jẹ Jona niyà, gbogbo awọn eniyan ti o wà ninu ọkọ si pin ninu iya yii pẹlu. Kò si ẹni ti o wà fun ara rè̩ nikan. Ẹni ti o n gbé igbesi-ayéẹni iwa-bi-Ọlọrun a maa mú ki ibukun dé ba awọn ẹlomiran nipa ṣiṣe rere. Bakan naa ni eniyan buburu a maa kó ibanujẹ bá awọn ẹlomiran nipa iwa ti o n hù. Iwọ sa wo gbogbo wahala ti Jona kó bá awọn atukọ nitori aigbọran rè̩ bi o ti n lọ si Tarṣiṣi.

Ìjì lile naa pọ tó bẹẹ ti awọn atukọ fi woye pe ẹni kan ni o fa wahala yii. Wọn ṣé̩ kèké lati mọẹni naa. Ọlọrun jé̩ ki kèké naa mu Jona . Nigba ti a mọ pe Jona ni, o sọ fun awọn eniyan naa pe Ọlọrun pe oun lati lọ si Ninefe ṣugbọn oun sá, oun kò si fé̩ lọ.

S̩ugbọn ohun rere kan wà ninu Jona sibẹ. O sọ fun awọn atukọ ki wọn gbé oun sọ sinu okun ki ẹfuufu lile naa ba le dawọ duro ki a ba lè dáẹmi awọn eniyan ti o wà ninu ọkọ si. S̩ugbọn wọn kò fẹ gbé e ju sinu omi, wọn si wa ọkọ kikankikan lati múọkọ gunlẹ; ṣugbọn nikẹyin wọn dawọ ati mu ọkọ gunlẹ duro, wọn si gbe Jona ju sinu omi. Lẹsẹkẹsẹìjì naa dakẹ jẹẹ.

S̩ugbọn eyi kọ ni opin ọrọ naa. Jona kò ri gẹgẹ bi eniyan i ba ti rò pé yoo ṣe. Eniyan ti o tayọọké̩ mẹfa wà sibè̩ ni ilu Ninefe ti wọn ni lati gbọỌrọỌlọrun, Ọlọrun si n fẹ ki Jona lọ waasu fun wọn sibẹ.

Ẹja ti a ti Pese Silẹ

Ọlọrun ti pese ẹja kan silẹ lati gbé Jona mì ki o má baa rì sinu omi. Ọpọlọpọ eniyan ni kò fé̩ gbagbọ pe ẹja nla kan le gbé eniyan mì, ati pe eniyan le wà laayè ninu rè̩. Jesu fi idi rè̩ mulẹ pe o ṣẹlè̩ (Matteu 12:40). Yatọ si eyi, akọsilẹ wà ni ode oni ti o sọ nipa ọkunrin kan ti ẹja-nla gbé mì ati pe a mu ẹja-nla naa, a si gbéọkunrin naa kuro ninu rè̩ laayè. O ṣeeṣe fun ẹja-nla lati gbé eniyan mì ki oluwarè̩ si wà laayè. S̩ugbọn ni ti Jona, a pese ẹja yii silẹ ni pataki lati gbé Jona mì nigba ti a gbé e jù sinu okun lati inu ọkọ. Jona gbadura ninu ẹja naa.

Adura Jona

Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi adura Jona. O gbadura gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ ti o ti sọnu ti o si wà ninu wahala, Ọlọrun si gbohùn rè̩. Adura rè̩ dabi adura Dafidi, eyi ti Jona ti le kà rí: “Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, OLUWA si gbohùn rè̩, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rè̩” (Orin Dafidi 34:6). Wo o bi aanu Ọlọrun ti pọ to! Nigba ti o tilẹ jé̩ pe ọwọ ara wa ni a fi fa wahala wa sori ara wa, bi a ba ronupiwada, ti a si képèỌlọrun, Oun yoo gbọ adura wa, yoo si gbà wá.

Nisisiyi Jona ṣetan lati ṣe ohunkohun ti Ọlọrun ba fẹ ki o ṣe. Bẹẹni kò si ti i pé̩ jù. O gbadura lati inu ẹja, Ọlọrun gbọ ni Oke Ọrun giga lọhun. Ibikibi ti o wu ki a wà, a kò jina jù ti Ọlọrun ki yoo fi gbọ adura wa. S̩ugbọn a ni lati sọ otitọ. A ni lati pinnu pe awa yoo mu ileri ti a ṣe fun Ọlọrun ṣẹ pe awa yoo lọ si ibikibi ti O bá rán wa.

Iwọ ha kiyesi i pe Jona ṣọpẹ ninu adura rè̩? Apọsteli nì wipe: “Pẹlu idupẹ, ẹ mā fi iberè nyin hàn fun Ọlọrun” (Filippi 4:6). Ọkàn Jona ti ṣipaya tán patapata, o n fẹ ri idahun si adura rè̩; nitori naa o dupẹ fun aanu Ọlọrun, o si mura tán lati san è̩jé̩ rè̩. Ẹwẹ, a ri i bi adura Jona ti fara jọ adura Onipsalmu, ẹni ti o gbadura pe: “Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjé̩ rẹ fun Ọga-ogo. Ki o si kepè mi li ọjọ ipọnju: emi o gbàọ, iwọ o si ma yin mi logo” (Orin Dafidi 50:14, 15). Lakọkọ a ni lati dupẹ lọwọỌlọrun fun aanu Rè̩, ati awọn ibukun ti a ti ri gbà, lẹyin eyi, a o san ẹjé̩ ti a ti jé̩ fun Ọlọrun; nigba naa ni a o ri ibukun gbà.

Si Iṣẹ Naa

Jona ti gbadura, Ọlọrun si ti gbọ, O si mú ki ẹja pọọ sori ilẹ. Wo bi inu Jona yoo ti dùn tó nigba ti o tun ri ilẹ, awọsanma, igi ati eweko! Fun odindi ọjọ mẹta ni o ti wà ninu òkùnkùn biribiri ninu ẹja, ti koriko odò wé e lori, ṣugbọn lẹẹkan si i o tun ri imọlẹ. Kò tilè̩ si akoko fun un lati sinmi tabi lati maa ṣe aṣaro nitori pe lẹsẹkẹsẹ ni ipè naa tun kan an lara pe: “Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kede si i ikede ti mo ti sọ fun ọ.” ỌrọỌlọrun kò yi pada. A ti fi ọwọ agbára ṣe akoso Jona lati ṣe e yẹ fun iṣẹ naa, ṣugbọn iṣẹỌlọrun wà bakan naa.

Jona dide kankan ni akoko yii, o si múọna Ninefe pọn. Ohun ti Ọlọrun paṣẹ fun un gan an ni o lọ fi waasu: “Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bi Ninefe wo.”

Isọji Naa

Abajade iwaasu yii jé̩ iru eyi ti olukuluku ajihinrere n fé̩ lati maa ri. Gbogbo ilu ronupiwada. Nigba ti ọba gbọ iwaasu Jona, o bọ aṣọ-igunwa rè̩ o si wọ aṣọọfọ. O ranṣẹ kaakiri gbogbo ijọba rè̩ pe ki olukuluku eniyan rè̩ ara rè̩ silè̩ ki wọn gbadura, ki wọn si gbaawè̩. Ẹnikẹni, ani awọn ẹranko pẹlu kò gbọdọ jẹun bẹẹni wọn kò gbọdọ mu omi bi wọn ti n ke pe Ọlọrun pe ki O dariji wọn. O pàṣẹ fun wọn lati kigbe kikan si Ọlọrun. Wọn ni lati gbadura titi wọn o fi ri idahun. Wọn ni lati gbadura lọna ti yoo fi han gbangba pe wọn n sọ ohun wọnni lati inu ọkàn wọn wá. Eyi ni ironupiwada tootọ ti n mu igbalà wá.

Ki i ṣe pe ki wọn ronupiwada è̩ṣẹ ti wọn ti n dá nikan, ṣugbọn wọn kò tun gbọdọ dẹṣè̩ mọ. “Jẹ ki enia buburu kọọna rè̩ silẹ, ki è̩lẹṣẹ si kọ ironu rè̩ silẹ; si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣanu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi ji i lọpọlọpọ” (Isaiah 55:7). Ọba Ninefe ti i ṣe keferi mọ pe ohun danindanin ni fun eniyan lati kọè̩ṣẹ rè̩ silẹ ki o ba le ri igbalà.

Wò bi o ti yẹ ki inu Jona ti dun to pe gbogbo awọn ara ilu naa yi pada si Ọlọrun! Wò bi ayọ wa ti n pọ to nigba ti ọkàn kan ba gbadura agbayọri si igbalà. Wò bi o ti yẹ ki ayọ naa pọ tó nigba ti ọké̩ mẹfa eniyan fi ọkàn wọn fun Ọlọrun! Iyanu ni -- iṣẹ iyanu ti o tobi ju pe Jona jade laaye kuro ninu ẹja lẹyin ọjọ mẹta ni pe ọpọlọpọ eniyan bayii yi pada lẹsẹ kan naa!

S̩ugbọn inu Jona kò dun. O ti waasu pe a o pa ilu naa run ni iwọn ogoji ọjọ, ṣugbọn nisisiyi eyi ki yoo ri bẹẹ mọ. Nitori eyi Jona binu. O jade kuro laaarin ilu naa o si pa àgọ o si joko labẹ rè̩ o n fé̩ lati kú. Ọlọrun si kọ Jona ni è̩kọ kan. Ọlọrun pese itakun kan ti o hù jade ni òru o si ṣiji bo Jona bi o ti joko ninu àgọ rè̩. Eyi dun mọ Jona. S̩ugbọn ni oru ọjọ keji kòkòrò jẹ itakun naa o si rọ. Lẹẹkan si i Jona si tun joko ninu oorun lai si ohun ti o le ṣiji bo o, inu rè̩ si bajẹ.

Ọlọrun sọ fun Jona pe ki o ronu. Jona kòṣe ohun kan lati mú ki itakun naa hu jade. Ki ni ṣe ti inu fi n bi i wayii pé itakun naa kú? Ọna wo ni a le gbà fi eweko lasan yii wé awọn eniyan Ninefe? Kò ha tọ fun Ọlọrun lati ṣaanu fun awọn ẹlẹṣẹ wọnyi ti wọn jẹ alaimọkan?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Iru eniyan wo ni awọn ara Ninefe i ṣe?
  2. Ki ni Jona nila ti sọ fun wọn ninu iwaasu rè̩?
  3. Ki ni Jona ṣe dipo ti i ba fi lọ si Ninefe? Ki ni ṣe?
  4. Ibi wo ni Ọlọrun mú wa sori Jona ati awọn eniyan ti o wà pẹlu rè̩?
  5. Bawo ni a ṣe mu rògbòdiyàn naa wá si opin?
  6. Ki ni Jona ṣe ninu ẹja?
  7. Nibo ni Jona lọ nigba ti o jade ninu ẹja?
  8. Ki ni awọn eniyan naa ṣe nigba ti wọn gbọ iwaasu Jona?
  9. Ki ni inu Jona ti ri nipa abayọrisi iwaasu rè̩?
  10. Ki ni ohun iyanu ti o tobi ju lọ ninu è̩kọ wa yii?