2 Kronika 26:1-23

Lesson 321 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ẹniti o ba rò pe on duro, ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu” (1 Kọrinti 10:12).
Notes

Ọdọmọde Ọba

Ọkan ninu awọn ọba Juda Ussiah, oun kan naa ni a n pè ni Asariah (2 Awọn Ọba 14:21). Ọmọọdun mẹrindinlogun pere ni i ṣe nigba ti a pa Amasiah, baba rè̩, ti a si fi oun jọba. Lai si aniani gbogbo awọn eniyan naa ni yoo maa woye bi ọdọmọkunrin yii yoo ṣe le ṣakoso. Yoo ha gba amọràn lẹnu awọn ti o ti ni iriri nipa biba awọn alaṣẹ damọran bi? Yoo ha kọ awọn àgbà silẹ ki o si gba amọran buburu bi Rehoboamu, ọmọ Sọlomọni? (Wo Ẹkọ 287). Ọmọ kekere yii ha le ṣakoso daradara bi?

Apẹẹrẹ Rere

Ussiah fi hàn pé a le fi iṣẹ patakì le ọdọ lọwọ ki o si ṣe e daradara. Nigba ti o bẹrẹ si jọba, o wáỌlọrun ati ọgbọn Ọlọrun, awọn eniyan si fi ọkàn tán an. Boya Ussiah wòye pe oun kere lati jọba, ati pe Ọlọrun ni lati ran oun lọwọ ki oun ba le ṣe aṣeyọri. O tẹle apẹẹrẹ baba rè̩ lati ṣe eyi ti o tọ ni oju Oluwa. Lai si aniani baba Ussiah kọọ nipa Oluwa ati ofin Rè̩. Bibeli kọ wa pe ileri ire wa fun awọn ti wọn bọwọ fun awọn obi wọn. Imọran Sọlomọni fun awọn ọmọde ni pe ki wọn gbọè̩kọ baba wọn ki wọn má si ṣe kọ ofin iya wọn silẹ (Owe 1:8). O sọ fun ni pe igbọran wọn yoo mu ki wọn ni “ọjọ gigùn, ati ẹmi gigun ati alafia” (Owe 3:1, 2).

Niwọn igba ti Ussiah n ṣe afẹẹri Oluwa, Ọlọrun mu ki o ṣe rere. Bi o ti yẹ ki o ri ni yii nitori pe Ọlọrun ti ṣeleri fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn o ṣe rere bi wọn bá gbọran si aṣẹ Oun (Deuteronomi 29:9). Ni ti awọn ti o gbé igbesi ayé iwa-bi-Ọlọrun, Onipsalmu sọ bayi pe, “Ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede” (Orin Dafidi 1:3).

Ibukun

Oriṣiriṣi ibukun ni o wà. Itumọ pe ki a ni ọrọ ni pe ki a ṣe aṣeyọri. Awọn ẹlomiran a maa ni ọrọ nipa ti ara. Wọn le ni owó ati dukia, ki wọn ṣe aṣeyọri ninu ohun ti aye yii. S̩ugbọn awọn eniyan Ọlọrun a maa lepa lati ni ọrọ ti ẹmi. Wọn n fẹ lati maa dàgbà ninu Ọrọ Oluwa, ki wọn si ni oore-ọfẹỌlọrun ati ifẹ lọpọlọpọ. Wọn n fé̩ lati ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ wọn fun Oluwa. Ọlọrun a si maa bukun awọn eniyan Rè̩ nipa ti ẹmi ati nipa ti ara, ṣugbọn ibukun nipa ti ẹmi ni o ṣe pataki jù lọ.

Wiwa Ọlọrun

Ni ti Ussiah, Ọba Juda, “Niwọn ọjọ ti o wá Oluwa, Ọlọrun si mu u ṣe rere.” O wáỌlọrun nigba ayé Sẹkariah, ẹni ti o ni imọ nipa awọn nnkan ti ẹmi. Lai si aniani, Ussiah a maa tọọ lọ fun imọran ati iranlọwọ. Ninu awọn wolii ti o wà nigba ayé Ussiah ni Isaiah (Isaiah 1:1), Hosea (Hosea 1:1), ati Amosi (Amosi 1:1). Anfaani nlanla ni o jé̩ fun Ussiah lati le maa tọ awọn eniyan Ọlọrun wọnyi lọ lati gbọọrọ wọn ati lati mu un ṣe.

Kikọ Ile

Bi Ussiah ti n ni ibukun si i, bẹẹni o kọ ilu fun awọn eniyan Juda. Ọkan ninu ilu wọnyi ni Eloti tabi Elati, ti o wa ni eti Okun Pupa ni ilẹ Edomu (2 Kronika 8:17). Eyi jé̩ọkan ninu awọn ebute ti Sọlomọni n lò fun awọn ọkọ oju-omi rè̩ (1 Awọn Ọba 9:26). Ussiah gbà a pada fun Juda, boya o si tun n ṣowo ni ebute yii pẹlu awọn orilẹ-ède ti ila-oorùn.

Ki i ṣe kiki ilu nikan ni Ussiah kọ, o kọ ile iṣọ pẹlu fun aabò. Ni Jerusalẹmu, a le daabo bo ẹnu-bode nipasẹ awọn ile-iṣọ ti o kọ wọnyi. Ni ilẹ aṣálè̩, lai si aniani a le lo awọn ile-iṣọ wọnyi fun aabo, ibi iṣọna, ati ibi ti a le wọ si. Ussiah pẹlu n fẹ tun ilẹṣe pẹlu. O fẹran iṣẹ agbè̩ṣiṣe ati sisin ohun-ọsìn. O mu ki a wa ọpọlọpọ kanga ki omi ba le wà. Ọgba-ajara wà ni gẹrẹgẹrẹ oke. Awọn ẹran ọsin wà ni afonifoji. Ni ọjọ wọnnì, ilẹ Juda ṣe rere, wọn ni ọrọ, wọn si lokiki.

O Dide si Awọn Ọta

Ọlọrun ran Ussiah lọwọ lati bori awọn ọta rè̩. O lọ lati ba awọn ara Filistini ja, awọn wọnni ti o ti jé̩ọta fun awọn Ọmọ Israẹli lati igba atijọ. Awọn Filistini ti mọ odi si aarin ilẹ wọn ati ilẹ Juda. Ussiah wo gbogbo odi wọnyi lulẹ nigba ti o ba gbogbo ibi ti awọn ọta fi ṣe odi-agbara jé̩.

Ussiah bori ninu ogun ti o bá awọn ara Arabia ati awọn aladugbo rè̩ jà. Awọn ara Amori fi ọrẹ ranṣẹ si i, lati mu ki wọn wà ni alafia pẹlu Ussiah. Ọlọrun ràn án lọwọ lati bori awọn ọta rè̩ titi okiki Ussiah fi kàn jake-jado, ani titi dé Egipti.

Ussiah ni ẹgbé̩ọmọ-ogun ti o ni ihamọra ti o gbamuṣe ju ti gbogbo awọn ẹgbẹọmọ-ogun ti igba nì lọ. O ni apata, aṣibori, ati ẹwu irin lati fi daabo bo awọn ọmọ-ogun. Awọn ọmọ ogun Ussiah ni imọ ati ọgbọn lati jagun. Wọn ṣe awari “ẹrọ” ti o le tafà ti o si le fi awọn okuta nla sọko. Eyi ni akọsilẹ kin-in-ni ti a ri nipa lilo è̩rọ lati fi ṣe ọṣé̩ ninu ogun jija.

Agbara nipa ti Ẹmi

Ohun daradara ni lati wó ibi giga ọta lulẹ nipa ti ẹmi pẹlu. Bi Ọlọrun ti ran Ussiah lọwọ bakan naa ni yoo ran wa lọwọ lode oni, lati bori Satani ọta wa ẹmi. Ọlọrun fé̩ ki awọn eniyan Rè̩ léọta sẹyin dipo ki wọn jọwọ ara wọn lọwọ fun Eṣu. A sọ fun wa pe ki a “kọ oju ìja si Eṣu on o si sá kuro lọdọ nyin” (Jakọbu 4:7). Iwọ ha fẹ mọ bi a ti ṣe le kọjuja si ọta? A sọ fun wa pe ki a “gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ” ki awa ki o ba le duro (Efesu 6:11). Ninu ihamọra yii ni “apata igbagbọ” wà ati “idàẸmi, ti iṣe ọrọỌlọrun” (Efesu 6:13-17).

Jesu tikara Rè̩ fi ỌrọỌlọrun ṣẹgun Satani. Nigba ti Eṣu dán Jesu wò, O mu ỌrọỌlọrun lo bayi pé, “A ti kọwe rè̩ pe,” Satani “si fi i silẹ lọ” (Luku 4:4-13). Bi a ba fẹ mọỌrọỌlọrun, a ni lati fara mọ Bibeli kika gidigidi. O ṣe pataki fun wa bi “idàẹmi.” ỌrọỌlọrun le sọ igbagbọ wa di lile nitori pe “nipa gbigbọ ni igbagbọ ti iwá, ati gbigbọ nipa ọrọỌlọrun” (Romu 10:17).

Adura ṣe pataki fun idagbasoke nipa ti ẹmi ati lati jé̩ alagbara ninu Oluwa. A ka a pe “o yẹ ki a mā gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣārè̩” (Luku 18:1). O ṣanfani fun ni lati maa sọrọ nipa Oluwa, lati maa ṣe aṣaro nipa Rè̩, ati lati maa sọrọ nipa ohun ti Ọlọrun ti ṣe (Malaki 3:16; Orin Dafidi 1:1, 2). Ninu Iwe ti o kẹyin ninu Bibeli a kà nipa awọn kan ti wọn yoo ti ṣẹgun ọta wọn ẹmi “nitori è̩jẹỌdọ-Agutan na, ati nitori ọrọẹri wọn” (Ifihan 12:11).

Igberaga

Ussiah di olokiki, alagbara, ati ẹni ti o ni ọpọlọpọ ibukun nitori pe Oluwa ràn an lọwọ. O ṣe daradara lori oye fun ọpọlọpọọdun. Lẹyin eyi ohun kan ṣẹlẹ. O bẹrẹ si jọ ara rè̩ loju. Dipo ti i ba fi ogo ati ọpẹ fun Ọlọrun, o rò wi pe oun ti ṣe daradara. O bẹrẹ si yin ara rè̩ fun aṣeyọri ti o ti ṣe. O bẹrẹ si gberaga, o si bẹrẹ si rò pé oun jamọ nnkan ni oju ara rè̩. A kà ninu Bibeli pe ewu wà ninu igberaga ati jijọ-ara-ẹni-loju. Ẹsẹ diẹ wọnyi lati inu ỌrọỌlọrun sọ nipa igberaga: “Bi igberaga ba de, nigbana ni itiju de” (Owe 11:2); “Gangan oju, ati igberaga aiya, ... è̩ṣẹ ni” (Owe 21:4); “Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu” (Owe 16:18).

Iwe Mimọ sọ fun ni nipa jijọ-ara-ẹni-loju : “Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rè̩ ga, li a o rè̩ silẹ” (Matteu 23:12); “Lati ma wadi ọran wuwo, o wuwo” (Owe 25:27); “Nitorina ẹniti o ba rò pe on duro, ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu” (1 Kọrinti 10:12); “Ẹniti o kọẹnu-ọna rè̩ ga, o nwá iparun” (Owe 17:19).

Kekere ati Nla

Boya Ussiah ti gbọ nipa Saulu ẹni ti o ti jẹọba lori awọn Ọmọ Israẹli. Nigba ti Saulu “kere” loju ara rè̩, Ọlọrun fi i jọba (1 Samuẹli 15:17). Nigba ti Saulu jọ ara rè̩ loju to bẹẹ ti o fi ṣaigbọran ti o si kọ ofin Oluwa silẹ, Oluwa kọ Saulu ni ọba (1 Samuẹli 15:23). Eyi yẹ ki o jé̩è̩kọ fun gbogbo eniyan ti wọn n gbọ tabi ti wọn n kà akọsilẹ igbesi-ayé Saulu.

Ni ọjọ kan, Ussiah pinnu lati fi turari jona si Oluwa. Pẹpẹ turari tabi pẹpẹ wura (Ẹksodu 40:5) wà ni Ibi Mimọ, “niwaju aṣọ ikele” ninu Tẹmpili (Ẹksodu 30:6). Ni orowurọ nigba ti a ba tún awọn fitila ṣe ati ni aṣaalẹ nigba ti a ba tàn wọn, a o gbe turari sori pẹpẹ ki o le maa jo nigba gbogbo gẹgẹ bi isin si OLUWA (Ẹksodu 30:7, 8). Awọn alufaa nikan ni o ni ẹtọ lati lọ si Ibi Mimọ, awọn alufaa nikan ni o ni anfaani lati fi turari jona lori pẹpẹ wura (Numeri 16:40).

Ki i ṣe Iṣẹ Rè̩

A lè rò pe boya Ussiah jé̩ olufọkànsin pupọ ni o ṣe fẹ fi turari jona si Oluwa. S̩ugbọn nipa ṣiṣe bẹẹ, o n ti ara rè̩ lati ṣe ohun ti Ọlọrun kò fi le e lọwọ lati ṣe. Eyi fi hàn pe o fẹ gba ipo ti Ọlọrun kò fi fun ẹnikẹni bi kòṣe kiki awọn alufaa. Bi o tilẹ jé̩ péỌlọrun ti bukun Ussiah O si ti mú ki o ṣe rere, sibẹỌlọrun kò ti i pa Ofin ti o fi iṣẹ sisun turari le awọn ọmọ Aarọni nikan ṣoṣo lọwọ tì. Olukuluku ni lati duro ni àyè ti Ọlọrun fi i si. Bi eniyan bá jé̩ oloootọ ti o rè̩ ara rè̩ silè̩, Ọlọrun yio fun un ni anfaani miiran pẹlu. Eniyan le ni itara gidigidi lati ṣiṣẹ fun Oluwa, sibẹsibẹ o ni lati ṣe ohun ti o tọ ti o si té̩Ọlọrun lọrun. Wolii Samuẹli sọ pe, “Kiye si i, igbọran sàn jùẹbọ lọ, ifetisilè̩ si sàn jùọra àgbo lọ” (1 Samuẹli 15:22).

S̩iṣe Aigbọran

Kò si ẹni ti o le rú ofin Ọlọrun ki o si lọ lai jiya, i ba ṣe ọba. Nigba ti Ussiah wọ Ibi Mimọ lọ, o ṣaigbọran, ki i ṣe nitori pe itara rè̩ pọ pupọ lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun bẹẹni ki i ṣe pe oun kò mọ ohun ti Ofin wi. S̩ugbọn Ussiah gbé ara rè̩ ga to bẹẹ ti o fẹ gba ipo awọn alufaa. Asariah, alufaa, pẹlu awọn ọgọrin alufaa miiran, kilọ fun Ussiah, wọn sa ipa wọn lati da a lẹkun. Awọn alufaa wi fun un pe, “Jade kuro ni ibi mimọ; nitoriti iwọ ti dẹṣẹ.”

Ọlọrun Lu U

A le ni ero pe Ussiah yoo sare jade kuro ni ibi mimọ yii lati lọ gbadura fun idariji è̩ṣẹ. S̩ugbọn Ussiah gberaga o si kọ eti didi si awọn alufaa ati Ọlọrun. Bi o ti duro nibẹ pẹlu awo turari lọwọ rè̩, ti inu si n bi i si awọn alufaa, ti o si taku pe oun yoo fi turari jona, è̩tè̩ bẹrẹ si yọ niwaju rè̩, Oluwa lu u, eyi si ni opin titobi rè̩.

Nitori è̩tè̩, ti i ṣe ijiya fun è̩ṣẹ Ussiah, “a ké e kuro ninu ile OLUWA.” A ti i jade kuro ninu Tẹmpili kò si tun pada wá jọsin nibẹ mọ. Ki è̩tè̩ ma ba ran awọn ẹbi rè̩, o ni lati lọ kuro lọdọ awọn ẹbi rè̩, ki o si maa dagbe, o si “ngbe nibi ọtọ” gẹgẹ bi Ofin (Lefitiku 13:46). Ussiah kò le wà lori oye mọ -- ọmọ rè̩ọkunrin Jotamu, si n ṣe idajọ awọn eniyan ilẹ naa. Ẹtẹ wà lara Ussiah ni gbogbo ọjọ ayé rè̩. Nigba ti ó kú, a sin in si ilẹ kan ti i ṣe ti awọn ọba. O dabi ẹnipe iboji rè̩ wà lọtọ kete si ti awọn ọba iyoku, nitori ti wọn wi pe, “Adẹtẹ li on.”

Irẹlẹ

Akọsilẹ wà ninu Bibeli wi pe a wò awọn adẹtè̩ sàn. A ti kè̩kọọ nipà Naamani ti a wòsàn kuro ninu è̩tè̩ rè̩ nigba ti o rẹ ara rè̩ silẹ ti o si gbọran si Ọlọrun (Ẹkọ 311). Ẹtè̩ bo Miriamu, arabinrin Mose (Numeri 12:10). Ọlọrun wò o san nigba ti o jẹwọè̩ṣẹ yii ti Mose si gbadura fun un. Boya Ussiah i ba ri iwosan gbà. S̩ugbọn a kò tilẹ ri i kà wi pe o ronupiwada tabi ki o beerè pe ki a gbadura fun oun ki o ba le ri iwosan gbà. Ẹṣẹ kan ṣoṣo yii ni a gbọ pe Ussiah dá (2 Kronika 27:2). Igbesi-ayé rè̩ fi hàn fun ni pe è̩ṣẹ kan ṣoṣo yoo ya eniyan kuro lọdọỌlọrun. Wo ibi ti è̩ṣẹ kan ṣoṣo ṣe – gbigbé ara rè̩ ga! Wo o bi o ti buru to lati pari igbesi-ayé rè̩ lọna bayi lẹyin ti o ti jọba ọdun meji le laadọta, paapaa ju lọ lẹyin ti o ti bè̩rè̩ daradara! Wo o bi o ti dara tó lati “fi irẹlẹ wọ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ” (1 Peteru 5:5). Ọkan ninu awọn ohun ti Ọlọrun n beere lọwọ eniyan ni pe ki o “rìn ni irè̩lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ” (Mika 6:8). Igbesi-ayé Ussiah fi otitọọrọ ti o wà ninu Iwe Owe mulẹ: “Igberaga enia ni yio rè̩ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹọkàn ni yio gbàọlá” (Owe 29:23).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Ussiah ti dagbà to nigba ti o bè̩rè̩ si i jọba?
  2. Ki ni ṣe ti ilu Eloti ṣe pataki?
  3. Bawo ni ile-iṣọṣe le jẹ ibi ti o niyelori?
  4. Ta ni ẹni ti o ran Ussiah lọwọ lati bori awọn aladugbo rè̩?
  5. Awọn wolii wo ni o wà laye ni ìgbà Ussiah?
  6. Ki ni èrè wíwá ti o wáỌlọrun?
  7. Ki ni ṣe ti Ussiah fé̩ fi turari jóná?
  8. Ki ni ṣe ti kò fi tọna fun Ussiah lati sun turari?
  9. Ki ni ìyà ti o jẹ?
  10. Ki ni ohun ti o fàè̩ṣè̩ Ussiah?