Joẹli 1:1-20; 2:1-32

Lesson 322 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Má bè̩ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ: nitori OLUWA yio ṣe ohun nla” (Joẹli 2:21).
Notes

Ọrọ Itùnu

“Má bè̩ru. iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ: nitori OLUWA yio ṣe ohun nla” (Joẹli 2:21). Wo ọrọ itunu ti o jade si Israẹli ti o ti wà ni ipo ibanujẹ! Wo bi ọrọ yii yoo ti dùn mọ awọn eniyan ti o wa ni igbekun ti wọn si n jiya è̩ṣẹ wọn. Lai pẹ ni wọn gbọ asọtẹlẹ Joẹli nipa idajọ ti o n bọ wá bá wọn -- ọrọ ti o mú ki ọkàn wọn wà ni ipo ainireti. S̩ugbọn itanṣan imọlẹ yii bé̩ yọ jade lati inu okunkun yii pe: “Má bè̩ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ.”

Idajọ ti Joẹli sọ nipa rè̩ ki i ṣe fun Israẹli nikan. O sọrọ pẹlu nipa “ọjọ OLUWA,” ti yoo de ni igbà Ipọnju Nla. Yoo jẹ “ọjọòkunkun ati òkudu ... kò ti isi iru rè̩ ri, bḝni iru rè̩ ki yio si mọ lẹhin rè̩, titi de ọdun iran de iran.” “Aiye yio mi niwaju wọn; awọn ọrun yio wariri: õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun; awọn iràwọ yio si fà imọlẹ wọn sẹhin. Oluwa yio si fọ ohùn rè̩ jade niwaju ogun rè̩: nitori ibùdo rè̩ tobi gidigidi: nitori alagbara li on ti nmu ọrọ rè̩ṣẹ; nitori ọjọ OLUWA tobi o si li è̩ru gidigidi; ara tali o le gbà a” (Joẹli 2:10, 11).

Bi o ba jé̩ pe iru ipin bayii ni yoo dé bá eniyan ni ọjọ iwaju, è̩rù ki yoo ha ba oluwarè̩? Ọlọrun sọ fun Joẹli lati kọọrọ wọnyi silẹ ki Israẹli le mọ pe ẹlẹṣẹ ni wọn i ṣe, ki wọn si mọ iru iya ti yoo jẹ wọn bi wọn kò bà ronupiwada ki wọn si yi pada si Ọlọrun.

Ireti

Ọlọrun kò fi igbà kan fi eniyan silẹ lai ni ireti. O sọ fun awọn Ọmọ Israẹli ọna ti wọn le gbà lati bọ ninu idajọ wọnyi. “Ẹ fi gbogbo ọkàn nyin yipada si mi, ati pẹlu āwè̩, ati pẹlu ẹkún, ati pẹlu ọfọ. Ẹ si fà aiyà nyin ya, ki isi iṣe aṣọ nyin, ẹ si yipada si OLUWA Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ li ore-ọfẹ, o si kún fun ānu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ati ṣe buburu” (Joẹli 2:12, 13). Ninu ọrọ wọnni o n kọ awọn eniyan ti o n gbé ori ilẹ ayé pe wọn ni lati ronupiwada è̩ṣẹ wọn, ki wọn si kaanu fun è̩ṣẹ wọn, ki wọn ba le ri igbalà.

Ọlọrun sọ pẹlu pe: “Wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ: bi è̩ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didì; bi nwọn pọn bi àlāri, nwọn o dabi irun-agutan” (Isaiah 1:18). Nipa eyi olukuluku ni anfaani lati bọ kuro ninu idajọ ti ipọnju nla. Gbogbo wa ni anfaani lati ri igbalà bi a ba ronupiwada ti a si kọè̩ṣẹ wa silẹ, ti a si gba Jesu ni Olugbala wa.

Idalare jé̩ ibè̩rè̩ ibukun ti yoo jé̩ ti wa nigba ti a bá n tẹle Oluwa. Iṣisẹ keji ni isọdimimọ, nipa eyi ti a o fà gbòngbo è̩ṣẹ tu kuro ninu ọkàn. A nri iriri yii gbà nigba ti a bá gbadura ti a si fi ara wa rubọ si i fun Oluwa.

Iṣisẹ kẹta ni fifi Ẹmi Mimọ wọ ni. Eyi ni Wolii Joẹli n sọ nipa rè̩ nigba ti o wi pe: “Njẹ jẹ ki inu nyin dùn, ẹnyin ọmọ Sioni, ẹ si yọ ninu OLUWA Ọlọrun nyin; nitoriti o ti fi akọrọ ojò fun nyin bi o ti tọ, on o si mu ki ojò rọ silẹ fun nyin, akọrọ ati arọkuro ojò ni oṣù ikini” (Joẹli 2:23).

Akoko Ẹmi Mimọ

Gbogbo ọrọ wọnyi jé̩ asọtẹlẹ, wọn n tọka si akoko Ẹmi Mimọ, nigba ti Ẹmi Mimọ yoo pe Iyawo Ọdọ-agutan ti yoo si maa pese rè̩ silẹ fun ipadabọ Kristi. Peteru Apọsteli sọ fun ni pe awọn woli ti sọ asọtẹlẹ nipa akoko ti o logo ti itujade Ẹmi Mimọ yii, ati pe awọn angẹli paapaa n fẹ lati mọ nipa rè̩ (1 Peteru 1:10-12).

Igba ati akoko kin-in-ni ninu itan Bibeli ni a mọ gẹgẹ bi “akoko ti o ṣàju ikún omi” eyi ni akoko ti o ṣaaju igba ti a fi omi pa aye ré̩. Akoko ti awọn baba nla bè̩rè̩ lati igba ayé Noa titi dé akoko ti awọn Ọmọ Israẹli dé ilẹ Kenaani. Lẹyin eyi ni akoko awọn onidajọ, ati lẹyin eyi, awọn woli. Lẹyin eyi ni akoko naa ti Joẹli pe ni akoko “akọrọ ojò.” Eyi bè̩rẹ ni Ọjọ Pẹntekọsti nigba ti Ẹmi Mimọ sọkalẹ ti o si bà le awọn ọgọfa ni iyara òke.

Jesu wi pe, “Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ... titi de opin ilẹ aye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Eyi ni eredi ti a fi fun ni ni Ẹmi Mimọ: lati fun awọn ọmọỌlọrun ni agbára ati pe ki wọn le jé̩ẹlẹri Rè̩ ki a ba le jerèọpọlọpọọkàn fun Ijọba Ọlọrun.

Fun iwọn ọdun diẹ lẹyin Ọjọ Pẹntekọsti, awọn eniyan n ri Ẹmi Mimọ gbà. S̩ugbọn inunibini nla dide nitori wiwaasu Ihinrere, nikẹyin ogunlọgọ awọn ti wọn n kede, ti wọn si n gbé igbesi-ayé Ihinrere ni lati lọ fi ara pamọ. A fẹrẹ pa iná Ijọ ni akoko naa. Awọn ara Romu pa Jerusalẹmu run, a si tú awọn Ju kaakiri gbogbo ayé. Eyi jé̩ apa kan ninu idajọ ti Joẹli sọ asọtẹlẹ rè̩. Ilẹ Mimọ nì di ahoro; òjo kò si rọ, a si ké awọn igi lulẹ. Ilẹ ti o ti jẹ ilẹọgba ẹlẹwa daradara di aṣálè̩. S̩ugbọn eyi ki i ṣe opin itan awọn Ọmọ Israẹli.

OjòArọkuro

Joẹli sọ asọtẹlẹ nipa igba miiran kan ti o n bọ ni ọjọ iwaju, akoko yii ni a n pe ni igba “arọkuro ojò.” “On o si mu ki ojò rọ silẹ fun nyin, akọrọ ati arọkuro ojò ni oṣù ikini.” Akoko Ẹmi Mimọ kò pari si igba ti awọn ọmọ-ẹyin ati awọn Apọsteli iṣaaju kú. Jakọbu Apọsteli ẹni ti o wà laye ni akoko Akọrọ Ojò, sọ nipa akoko miiran nigba ti o wi pe: “Kiyesi i, àgbẹ a mā reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sru de e, titi di igbà akọrọ ati arọkuro òjo” (Jakọbu 5:7).

Eso ilẹ ti o n sọ nipa rè̩ ni Iyawo Kristi, ti a n pese silẹ fun bibọ Oluwa. Ijọ ti ṣe alabapin Akọrọ Ojo, eyi ti o bè̩rẹ lati Ọjọ Pẹntekọsti; ṣugbọn Jesu kò ti i de lati wá mú Iyawo Rè̩ lọ. Akoko kan n bọ nigba ti a o túẸmi Mimọ jade lọpọlọpọ; lẹyin eyi, nigba ti Iyawo Ọdọ-agutan ba si ti mura silẹ tán, Jesu yoo dé. Eyi n sọ nipa akoko ti wa yii.

Bawo ni a ṣe mọ pé itujade Ẹmi Mimọ ni Joẹli n sọrọ rè̩ nigba ti o n sọ nipa akọrọ ati arọkuro òjò? Peteru ṣe alaye kikun ni Ọjọ Pẹntekọsti nigba ti o wi pe: “Eyi li ọrọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joẹli wá pe; Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmi mi jade sara enia gbogbo” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:16, 17), o si tè̩ siwaju lati sọ nipa iṣẹ ti awọn Onigbagbọ ti o bá gba agbára yii yoo ṣe fun Oluwa.

Ojo Rọ si Palẹstini

Lẹyin ti Palẹstini ti wà ni aṣalẹ fun ọpọlọpọọdún, òjò tun bè̩rẹ si rọ, ilẹ si bẹrẹ si i mu eso jade. Ni iwọn bi ọgọta ọdun sẹyin ni ilẹ aṣálè̩ yii bè̩rẹ si i so èso, a si bè̩rẹ si dako si ilẹ ti a ti fi silẹ to bẹẹ ti o fi jẹ pe ni ọjọ oni, a le ri diẹ ninu awọn ohun ọgbin ti o dara ju lọ ni ayé ni Ilẹ Mimọ (Palẹstini).

Joẹli ṣeleri pe: “Awọn ilẹ ipakà yio kún fun ọkà, ati ọpọn wọnni yio ṣàn jade fun ọti-waini ati ororo. Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miiran ti fi jẹ, awọn ogun nla mi ti mo rán sārin nyin. Ẹnyin o si jẹun li ọpọlọpọ, ẹ o si yó, ẹ o si yin orukọ OLUWA Ọlọrun nyin, ẹniti o fi iyanu ba nyin lò; oju ki o si ti awọn enia mi lai” (Joẹli 2:24-26).

Awọn Ju jiya kaakiri ayé fun nnkan bi ẹẹdẹgbẹwa (1900) ọdun, ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun n mu wọn pada si ilẹ wọn. Wọn n pada ninu aigbagbọ, ṣugbọn akoko n bọ ti wọn yoo gba Jesu ni Messia wọn. Gbogbo ibukun ti awọn woli sọtẹlẹ wi pe yoo wà ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun-ọdun ni yoo jẹ ti awọn ti o gba Jesu gbọ.

Itujade Nlanla

Ohun miiran ti o tobi ju ibukun ti ara lọṣẹlẹ nigba ti òjò bẹrẹ si rọ si Palẹstini. Itujade nlá nlà ti Ẹmi Mimọṣẹlẹ ni akoko Arọkuro Ojò, gẹgẹ bi Ọlọrun ti sọ wipe yoo ri. O ṣẹlẹ ni oṣu kin-in-ni gẹgẹ bi iṣiro ọdun ti ẹsin awọn Ju, gẹgẹ bi Joẹli ti sọ tẹlẹ. Awọn eniyan diẹ kòṣalai ri Ẹmi Mimọ gbà laaarin ọpọlọpọọdún ti o ti rekọja; ṣugbọn ibè̩rẹ itujade nlá nlà yii bẹrẹ ni Oṣu Kẹrin ọdun 1906.

Ni akoko yii ebi ti ẹmi wà ninu ijọ kaakiri ati laaarin awọn Onigbagbọ jakejadò ayé. Isọji nlá nlà ti bé̩ silẹ nigba ayé Luther ati Wesley, ati nipasẹ iwaasu awọn eniyan Ọlọrun gẹgẹ bi Charles Finney, Charles Spurgeon, Jonathan Edwards, ati D. L. Moody. Lẹin eyi ni isọji bé̩ silẹ ni Wales nipasẹ eyi ti Ẹmi Mimọ múẹgbẹgbẹrun ọkàn wá sinu Ijọba Ọlọrun.

Ni ilu Los Angeles, ni California, awọn eniyan ninu ọpọlọpọ ijọ bè̩rẹ si gbadura fun isọji. Ẹgbé̩ awọn ọdọmọkunrin oniṣowo kan n gba adura àgbà-mọju. Awọn eniyan a maa pejọ pọ lati gbadura agboole. Gbogbo wọn n poungbẹ fun itujade Ẹmi Ọlọrun ju ti atẹyinwa lọ. Iroyin ti ọkunrin kan mú wá nipa Isọji ti ilu Wales tubọ rú oungbẹ yii soke.

Ọkan ninu awọn ti wọn n poungbẹ fun agbára Ọlọrun ninu igbesi-ayé wọn ni ẹni ti o dá ijọ Apọstolic Faith ti Portland, Oregon silẹ, iyaafin Florence L. Crawford. Ninu ile alaigbagbọ ni a gbé bi i; ṣugbọn ni iwọn nnkan bi ọdun mẹẹdogun ṣaaju akoko itujade ti Arọkuro Ojò yii ni Ọlọrun ti bá a sọrọ ninu ile-ijó, wi pe, “Ọmọ, fi ọkàn rẹ fun mi.” Nipasẹ iranlọwọ obinrin kan ti i ṣe aladugbo rè̩, ẹni ti oun ti mọ ni onigbagbọ tootọ, o gba adura agbayọri, o si ni idaniloju pe a ti dari awọn è̩ṣẹ rè̩ ji i.

Abayọrisi iyipada ti o ṣẹlẹ ninu igbesi-ayé rè̩ jé̩ eyi ti yoo mú ire bá awọn eniyan kaakiri ayé ni ọjọ iwaju. Gbogbo ilepa rè̩ yi pada kuro ninu ilepa ohun afé̩ aye yii o si di ẹni ti o jọwọ ayé rè̩ lati ṣe iranwọ fun awọn ẹlomiran. O fun awọn alaini ni aṣọ ati ounjẹ. O ṣiṣẹ ni isowọpọ pẹlu awọn ẹlomiran lati kọ ile fun awọn ọmọdekunrin ati ọmọdebinrin ti kò ni itọju tó. Iṣẹ rè̩ ninu ile túbú, lati dana ireti si ọkàn awọn wọnni ti o wà ninu ahamọ, jé̩ iṣẹ ifẹ lati ṣe iranwọ fun awọn ọmọẹlomiran ti o n fẹ iranwọ.

O gbọ nipa isọdimimọ, bi o tilẹ jé̩ péọkàn rè̩ n poungbẹ lati ni in, kò ri ẹni kan ti o le fi ye e bi yoo ṣe ni idaniloju pe a ti sọ oun di mimọ. Ni ọjọ kan, ọrẹ rè̩ kan sọ fun un pe a n ṣe awọn ipade kan ni apakan ilu nibi ti wọn kii saba maa lọ. O gbagbọ pe awọn eniyan wọnyi ni ohun ti ọkàn rè̩ n poungbẹ lati ni. Ni ipade akọkọ ti o lọ, alufaa dide duro o wi pe, “Mo gbagbọ pe ẹnikan wa nihin yii ti o n fẹ ki a sọ oun di mimọ.” Ni alẹọjọ naa gan an ni o ri iriri yii gbà.

Laaarin awọn ẹni irẹlẹ wọnni ti o wà ni opopo Bonnie Brae ni Los Angeles, ni itujade Ẹmi Mimọ ti gbé bè̩rẹ. Ọpọlọpọ agbára bi igbi nla sọkalẹ sori awọn eniyan wọnyi. Bi ihin naa si ti n tàn kalẹ wi pe Arọkuro Ojo n rọ ni Los Angeles, ihin si tun dé lati India, ati awọn ilu Scandinavia pe agbára Ọlọrun n sọkalẹ lọhun pẹlu. Ni ibi pupọ kaakiri ayé ni òjo ẹmi yii rọ dé. Akoko Arọkurò Ojo dé, a si mu ọkàn awọn ti ebi n pa fun agbára Ọlọrun yó.

Jakọbu wi pe Agbè̩ (Oluwa) a maa mu suuru de eso ti ilẹ “titi di igba akọrọ ati arọkuro òjo.” Nisisiyi Arọkuro Òjo ti dé lati pese Iyawo Kristi silẹ fun bibọ Rè̩.

Lode oni “Ijọ akọbi” (Heberu 12:23), awọn wọnni ti wọn ti gba ỌrọỌlọrun gbọ ti wọn si ti ri awọn iriri ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wọn gbà, n reti bibọ Oluwa nigbakigba. Wọn n duro lati gbọ: “Ẹ jẹ ki a yọ, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rè̩ si ti mura tan” (Ifihan 19:7).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nipa idajọ ti o ba ni lẹru wo ni Joẹli sọ fun Israẹli?
  2. Ireti wo ni o fun wọn?
  3. Darukọ awọn iṣisẹ mẹta ti o daju ti Onigbagbọ ni lati ni?
  4. Ki ni a n pe ni “akọrọòjo” nipa ti ẹmi?
  5. Nigba wo ni o de?
  6. Sọ diẹ ninu awọn idajọ ti o dé bá Israẹli lai pẹ ti Kristi ti lọ si Ọrun.
  7. Awọn ileri wo ni Ọlọrun ṣe fun Ilẹ Palẹstini fun ọjọ iwaju?
  8. Nigba wo ni Arọkuro Òjo bè̩rẹ si i rọ? Nibo?
  9. Awọn Ju ha n mu asọtẹlẹṣẹ ni ode-oni?
  10. Ki ni “Ijọ akọbi” n reti?