Iṣe Awọn Apọsteli 12:1-23

Lesson 323 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ” (Jakọbu 5:16).
Notes

Hẹrọdu Agrippa

Ọba Romu ni o fi Ọba Hẹrọdu ṣe alaṣẹ ni Palẹstini. Oun ki i ṣe ọkan ninu awọn Ju; ṣugbọn laaarin ọdun diẹ ti o jé̩ alaṣẹ o wáọna lati ri ojurere wọn. Ọna kan ti o le gbà lati mú inu awọn Ju dun ni lati maa jẹ awọn ọmọ-ẹyin Jesu Kristi niya. Hẹrọdu bè̩rè̩ si i na ọwọ rè̩ lati mu wọn. O to iwọn ọdun mẹwaa ti a ti pa Stefanu (Ẹkọ 289). Ni akoko naa, awọn ọmọ-ẹyin ti tukaakiri gbogbo ilẹ naa, wọn si n tan Ihinrere kálè̩ nibikibi ti wọn bá dé (Iṣe Awọn Apọsteli 8:1). A dá ijọ silẹ ni Samaria ati Antiọku, nibi ti a kọ pe awọn ọmọ-ẹyin ni “Kristiani” (Iṣe Awọn Apọsteli 11:26). Saulu ara Tarsu ti yi pada (Ẹkọ 301). A ti rán Peteru lọ si ile Kọrneliu, o si ti waasu Jesu, awọn Keferi si ti gba Ihinrere (Iṣe Awọn Apọsteli 11:1).

Lai si aniani awọn oloye awọn Ju ro pe wọn yoo fi inunibini ati ọrọ ihalẹ dẹru ba awọn ọmọlẹyin Kristi (Iṣe Awọn Apọsteli 5:40). S̩ugbọn kaka ki wọn le dá iṣẹ awọn ọmọlẹyin Kristi duro, wọn mu ki iṣẹ Ihinrere tubọ tàn kalẹ ju bẹẹ lọ.

Jakọbu

Ẹkọ wa oni sọ fun wa nipa Apọsteli kin-in-ni ti o kú ikú ajé̩rikú. Ajé̩rikú ni ẹni ti o fi ẹmi rè̩ lelẹ nitori ijẹwọ igbagbọ rè̩ ti o si kọ lati sé̩ igbagbọ rè̩ ninu Jesu. Jakọbu ni Apọsteli kin-in-ni ti a pa gẹgẹ bi ajé̩rikú. Arakunrin Johannu, ọmọ Sebede ni oun i ṣe (Marku 1:19). Apẹja ni oun i ṣe nigba ti Jesu pè e. Oun ati arakunrin rè̩ fi baba wọn ati ọkọ wọn silẹ lati tẹle Jesu (Matteu 4:22). Lẹyin eyi a yan Jakọbu gẹgẹ bi ọkan ninu awọn Apọsteli mejila (Matteu 10:2). O jé̩ọkan ninu awọn mẹta ti o fara mọ Jesu timọtimọ. Jakọbu wà lọdọ Jesu ni akoko ipalarada Rè̩ (Ẹkọ 114). Jakọbu wà ninu Ọgba Gẹtsemane pẹlu Jesu bi o ti n fi irora nla gbadura. O jé̩ọkan ninu awọn mẹta ti Jesu sọ fun pe, “Ẹ si mā ba mi ṣọna” (Matteu 26:38). Lẹyin ti Jesu ti goke re Ọrun, Jakọbu gbọràn si aṣẹ Jesu lati duro de ileri Baba (Iṣe Awọn Apọsteli 1:4). O bá awọn iyoku lọ si yàráòkè ni Jerusalẹmu lati lọ gbadúrà (Iṣe Awọn Apọsteli 1:13). Nibẹ ni wọn gba agbára lati jẹẹlẹri fun Jesu (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8).

Inunibini

Eyi naa ni Jakọbu ẹni ti Hẹrọdu fi idà pa. A sọ fun wa pe ohun itiju ni o jé̩ fun eniyan pe ki a fi idà bẹẹ li ori, ọna ti a si gbà fi pa Jakọbu ni eyi. Lai si aniani, Hẹrọdu ti rò pe nipa pipa Apọsteli ti o fara mọ Jesu timọtimọ yii lọna itiju ati ẹsin, awọn iyoku ki yoo tun ni igboya lati waasu mọ. Ẹwè̩, ohun ti Hẹrọdu ṣe yii yoo dùn mọ awọn Ju, wọn yoo si fi ojurere wo o. Fun Jakọbu, ikú ojiji yii jasi iṣẹgun ojiji, oun yoo si wà pẹlu Jesu, ẹni ti o fẹran pupọ to bẹẹ.

Peteru

Nigba ti Hẹrọdu ri i pe ikú Jakọbu dun mọ awọn Ju, o tubọ n ṣe inunibini si i. Ni akoko yii, o mu Peteru o si fi sinu tubú. Akoko ajọ aiwúkàrà ni, ti o n ṣe Ajọ Irekọja, ni akoko ti a n ṣe Ajinde lode oni. Wọn n ṣọ Peteru tọwọ tẹsẹ ninu túbú, Hẹrọdu si pinnu lati pa a mọ titi di ẹyin Ajinde.

Eyi ki i ṣe igbà kin-inni ti a fi Peteru sinu tubu nitori pe o n waasu Ihinrere. Ni akoko kan awọn alaṣẹ da a silẹ, pẹlu Johannu nitori pe wọn kò ri “nkan ti nwọn iba fi jẹ nwọn ni iya” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:21). Wọn paṣẹ fun awọn Apọsteli pe ki wọn máṣe waasu ni orukọ Jesu mọ (Ẹkọ 283). Nigba miiran è̩wẹ, angẹli Oluwa ṣilẹkun túbú o si dá awọn Apọsteli silẹ (Iṣe Awọn Apọsteli 5:19). A fi wọn sinu túbú nitori ti wọn tẹra mọọn lati maa waasu Jesu. A mu wọn wá siwaju Ajọ Igbimọ Nla. Peteru ati awọn iyoku wi pe, “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun jù ti enia lọ.” Ni akoko yii, wọn lù wọn, wọn si jọwọ wọn lọwọ lọ (Iṣe Awọn Apọsteli 5:40).

Boya Hẹrọdu ranti igba kan ti Peteru jade kuro ninu tubu bi o tilẹ jẹ pe “ile tubu o sé pinpin, ati awọn oluṣọ duro lode niwaju ilẹkun” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:23). Ni akoko yii, Hẹrọdu paṣẹ pe ki a fi Peteru sinu tubu ti inu ki awọn ọmọ-ogun mẹrindinlogun si maa ṣọọ.

Adura

Peteru wà ninu iṣoro gidigidi. Kò si iranlọwọ fun un nipa ti ẹda. Kò si ofin ti a fi le gbà a silẹ, bẹẹ ni kò si si agbẹjọrò lati gba ọràn rè̩ rò. S̩ugbọn awọn ọré̩ rè̩ kan n gbadura. Awọn ọmọ-ẹyin pejọ si ile Maria, iya Johannu Marku. Nibẹ ni wọn gbe n gbadura lai sinmi fun Peteru. Lai si aniani, lọsan ati loru, ni gbogbo igba ti o wà ninu tubu ni wọn fi n gbadura fun un.

Nigba ti ọràn kan ba le ti o si dabi ẹni pe kò si ireti mọ, awọn ẹlomiran rò pé kòṣanfaani lati gbadura. Awọn ẹlomiran a maa sọ ireti nù nigba ti wọn ba ti gbadura lẹẹkan tabi lẹẹmeji. A ba jẹ le kọè̩kọ ninu eyi pe “ohun gbogbo ni ṣiṣe fun Ọlọrun” (Marku 10:27).

Ọjọ n gori ọjọ, Peteru wà ninu tubu sibẹ. Nikẹyin o wá ku ọjọ kan ṣoṣo pere ki a mu Peteru jade wá fun idajọ. Peteru kò bè̩rù bẹẹ ni ko daamu nipa ohun ti yoo ṣẹlẹ si i. O mọ pe awọn eniyan Ọlọrun n gbadura fun oun. Lai si aniani, oun paapaa ti n gbadura. Awọn eniyan Ọlọrun saba maa n gbadura bi Jesu ti gbadura pe “Baba mi ... ifẹ tirẹ ni ki a ṣe” (Matteu 26:42). Boya Peteru ni ọkàn kan naa pẹlu Paulu ti o wi pe “Nitori, niti emi, lati wà lāye jẹ Kristi, lati kú jẹ ere” (Filippi 1:21). Peteru ṣetan lati kú tabi lati wà laaye fun Kristi.

Idande

Ni alẹọjọ yii, ohun gbogbo ṣokunkun biribiri bi Peteru ti lọ sùn, laaarin awọn ọmọ-ogun meji ti a fi ẹwọn de e mọ. Lojiji imọlẹ kan wọ inu tubu, angẹli Oluwa si yọ si i. Peteru rò pé oun ri iran ni, ṣugbọn o ṣe ohun ti angẹli Oluwa sọ fun un. Bi o ti dide ẹwọn bọ silẹ kùro ni ọwọ rè̩. Peteru wọ bata ati ẹwu rè̩, o si tẹle angẹli naa. Wọn kọja iṣọ kin-in-ni ati ekeji. Bi wọn ti déẹnu-ọna ilẹkun ti ode, o ṣi tikara rè̩. Lẹyin ti wọn ti kọja ẹnu-ọna ilẹkun irin, ti o lọ si ilú, angẹli naa fi Peteru silẹ. Nigba naa li o mọ pe ki iṣe ìran. A ti dá a silẹ kuro ninu tubu. Kò si ẹnikan ti o fun fèrè, bẹẹ ni awọn oluṣọ kò kigbe pe ẹni kan salọ. Ohun gbogbo parọrọ, nitori pe Ọlọrun ti rán angẹli Rè̩ lati ṣe iṣẹ-iyanu yii. Peteru wi pe, “Nigbayi ni mo to mọ nitõtọ pe, Oluwa rán angẹli rè̩, o si gbà mi li ọwọ Hẹrọdu, ati gbogbo ireti awọn enia Ju.”

Igbagbọ

Peteru pinnu lati lọ si ile Maria, iya Johannu Marku, nibi ti o mọ pé awọn eniyan Ọlọrun gbé n gbadura fun oun. O fé̩ wà pẹlu awọn ti o ti n gbadura fun un. O fé̩ sọ fun wọn bi Ọlọrun ti gbà oun silẹ ni idahun si adura wọn. Nigba ti Peteru kan ilẹkun, ọmọbinrin kekere kan ti a n pe ni Roda beere ẹni ti o wà nibẹ. Nigbati o gbọ ohùn Peteru, inu rè̩ dun o si kun fun ayọ to bẹẹ ti o fi gbagbe lati ṣilẹkun fun Peteru lati wọle.

Roda sure lọ sọ fun awọn iyoku. Wọn ti n gbadura fun Peteru fun ọpọlọpọọjọ lai sinmi. Nigba ti Ọlọrun gbọ adura wọn ti O si da a silẹ, o dabi àlá loju wọn. Wọn fẹrẹ ma le gbagbọ pe Peteru ni ẹni ti o n kan ilẹkun sibẹ. Nigba ti wọn ri i, ẹnu yà wọn. Ọlọrun ti ṣiṣẹ iyanu! Peteru juwọ si wọn ki wọn ki o dakẹ, o si royin fun wọn bi Ọlọrun ṣe da a silẹ.

Peteru fi ibẹ silẹ o si lọ si ibomiran, lẹyin ti o ti sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe ki wọn sọ fun Jakọbu. Lai si aniani eyi ni Jakọbu ti i ṣe alabojuto Ijọ ni Jerusalẹmu. (Wo Iṣe Awọn Apọsteli 21:17, 18). Nigba ti awọn eniyan Ọlọrun bá gbadura fun wa, ti Ọlọrun si gbà wa, o yẹ ki a jé̩ ki wọn mọ ohun ti Oluwa ṣe. Peteru n fẹ ki Jakọbu ati awọn arakunrin iyoku mọ pe oun wà ni alaafia nitori pe Ọlọrun da a silẹ.

Kò ha jọ wá loju pe ẹnu ya awọn eniyan ti o ti n gbadura wọnyii nigba ti angẹli da Peteru silẹ? Boya Ọlọrun mu è̩kọ yii wá gẹgẹ bi apẹẹrẹ fun wa. A ha gbagbọ nigba gbogbo pe adura wa gbà? A kà ninu Bibeli pe, “Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ pe, ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bḝ fun nyin” (Marku 11:24). Jesu sọ fun baba kan ti o mu ọmọ rè̩ ti ẹmi èṣù ndá loro wá fun iwosan pe, “Bi iwọ ba le gbagbọ, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ” (Marku 9:23). Gbọ ohun ti Johannu eniyan Ọlọrun sọ: “Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rè̩, pe bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rè̩, o ngbọ ti wa: bi awa ba si mọ pe o ngbọ ti wa, ohunkohun ti awa ba bère, awa mọ pe awa ri ibere ti awa ti bère lọdọ rè̩ gbà” (1 Johannu 5:14, 15). Ọlọrun ma ṣalai jé̩ ki è̩kọ yii ràn wa lọwọ lati tubọ tẹra mọ adura i gbà, ki a si ni igbagbọ gbigbona nigba ti a ba n gbadura.

Ko si Aanu

Ni owurọọjọ keji, idaamu dé bá wọn ni ile tubu. A fé̩ Peteru kù. Lai si aniani, awọn ọmọ-ogun sùn nigba ti angẹli tú Peteru silẹ. Bẹẹ naa ni, ilẹkun irin naa tun tì pada tikara rè̩ bi o ti ṣe ṣi ni ọna iyanu. Wọn kò ri Peteru. A pe awọn onitubu bi leere niwaju Hẹrọdu. Kò si ẹni kan ninu wọn ti o mọọna ti Peteru gbà yọ. Nigba ti wọn kò ri alaye kan ṣe nipa Peteru, Hẹrọdu paṣẹ pe ki a pa wọn.

Ọjọ ikúọkunrin ti o ti pète lati pa Peteru kù si dẹdẹ. Hẹrọdu kò ni ifẹ si awọn ọmọ-ẹyin rara. Ni ṣiṣe inunibini si wọn, Hẹrọdu n ba Ọlọrun jà. S̩ugbọn nigbooṣe, Ọlọrun dide si Hẹrọdu.

Ọlọrun LùÚ Pa

Fun idi kan ti a kò mọ, Hẹrọdu binu si awọn ara Tire ati Sidoni. Wọn ti bá Blastu ẹni ti iṣe igbakeji Hẹrọdu ṣọrẹ. Wọn fẹ wà ni alaafia pẹlu Hẹrọdu, nitori naa wọn ṣètò pe ki o bá wọn sọrọ. Wọn dá akoko ti Hẹrọdu yoo ba wọn sọrọ. O wọ aṣọ igunwa rè̩ bi o ti joko tori itẹ rè̩ niwaju awọn eniyan. Lai si aniani, ọrọ rè̩ dun leti wọn nitori pe wọn hó gee, wi pe, “Ohùn ọlọrun ni, ki si iṣe ti enia.” Inu Hẹrọdu dùn si ọrọ ipọnni wọnyii, kò si kọ lati fara mọọn. O fé̩ọlá fun ara rè̩ṣugbọn kò fi ògo fun Ọlọrun. S̩ugbọn ògo Hẹrọdu kò pé̩ lọ titi. Bi o ti joko sibẹ niwaju awọn eniyan naa, Ọlọrun lù u pa. Arun ti o kọlù buru jai, a si sọ fun wa pé o wà ninu irora nla. Lai pẹ, o kú ninu irora rè̩.

Awọn eniyan meji ti a ri ninu è̩kọ wa yii duro fun àpẹẹrẹ irú eniyan meji ti o wà ninu ayé. Awọn eniyan bi Hẹrọdu ti kò naani Ọlọrun ti wọn si n ṣe inunibini si awọn eniyan Rè̩, kò ni ṣalai fi ara gbá idàjọỌlọrun. Bi Hẹrọdu bà gbadura, igbesi-ayé rè̩ i bá ti yi padà. Awọn eniyan bi Peteru, ti o ni ifẹ si Ọlọrun ati iṣẹ Rè̩, ni a gbàlà nipa adura. “Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a fi pa Jakọbu?
  2. Ta ni pa a?
  3. Ta ni a fi sinu túbú?
  4. Ki ni ṣe ti a fi i sinu túbú?
  5. Ki ni Hẹrọdu pete lati ṣe si Peteru?
  6. Bawo ni a ṣe da Peteru silẹ?
  7. Ta ni gbadura fun Peteru?
  8. Ki ni ṣẹlẹ nigba ti wọn gbadura?
  9. Iru aláṣẹ wo ni Hẹrọdu i ṣe?
  10. Ki ni ṣe ti idájọỌlọrun wá sori Hẹrọdu?