Lesson 324 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mā ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ māṣe iyọnú, ẹ ni ẹmi irẹlẹ” (1 Peteru 3:8).Notes
Ilu Nla
Ilu Antiọku jé̩ ilu nla ti o si ni ọrọṣugbọn ilu naa buru jai pẹlu. Ogunlọgọ awọn eniyan ti o wà nibẹ, ni o n bọriṣa dipo ki wọn sin Ọlọrun. Sibẹ, Ọlọrun ri i pe awọn kan wà nibẹ ti yoo ṣafẹri lati ni igbala bi wọn bá gbọ nipa Ihinrere, nitori naa O rán Paulu ati Barnaba lati lọ waasu fun wọn. Ni ọdun kejilelogoji lẹyin ti a bi Jesu, a dá ijọ kan silẹ ni ilu Antiọku, nibẹ ni a si ti kọ pe awọn ọmọ-ẹyin Jesu ni Kristiani.
Ijọ Antiọku gbèrú nipa ti ẹmi, ọpọlọpọ awọn Keferi ni o si wà sin Ọlọrun otitọ, ti wọn si gbagbọ pe Jesu ni ỌmọỌlọrun. Ki i ṣe wi pe a gbà wọn là nikan, ṣugbọn a sọ wọn di mimọ pẹlu, a si fi Ẹmi Mimọ wọ wọn. Lati ihin yii ni awọn Apọsteli gbé ti ṣiṣẹ lati tan Ihinrere kalẹ si ibi gbogbo ni ijọba Romu.
Asọtẹlẹ Nipa Iyan
Awọn woli wá lati Jerusalẹmu lati bẹ ijọ Antiọku wò, laaarin wọn ni a ri ẹni kan ti o sọtẹlẹ pe iyàn kan n bọ wá mu lori gbogbo ilẹ aye. Ọlọrun ni Olufunni ni agbára lati mọ ohun ti o n bọ wá, awọn Kristiani si gbagbọ wọn si bè̩rẹ si mura silẹ de akoko iṣoro yii. S̩ugbọn awọn Kristiani ti o wà ni Jerusalẹmu kò ni ohunkohun ti wọn le fi pamọ. Wọn ti fara gbá inunibini nlá nlà nitori igbagbọ wọn ninu Jesu, wọn si ti gba gbogbo ohun ini ọpọlọpọ ninu wọn. Awọn Keferi ti o di Kristiani ni Antiọku wà ni ipo ti o sàn jù ti awọn wọnyi lọ, wọn si fi ifẹ wọn hàn nipa fifi nnkan ranṣẹ lati ṣe iranlọwọ fun awọn ọré̩ wọn ti kò ni lọwọ tó bi ti wọn.
Ọrẹ ti ijọ Antiọku fi ranṣẹ ko ni ṣalai mú ki irẹpọ timọtimọ tubọ wà laaarin awọn ijọ Keferi ti o yipada wọnyi ati ijọ awọn Ju. A yan Barnaba ati Paulu lati múè̩bun wọnyi lọ si Jerusalẹmu.
KikọỌrọ ati Agbara Silẹ
Laaarin awọn alakoso ijọ Antiọku pẹlu Paulu ati Barnaba, ọkunrin kan wa ti a tọ pọ pẹlu Hẹrọdu, alaṣẹ ti o roro gidigidi si awọn Kristiani. Gẹgẹ bi Mose, Manaeni ṣe tan lati kọ aafin silẹ pẹlu gbogbo ọrọ ati ọlá rè̩, o si yàn lati ba awọn Onigbagbọ fara da iyà ati inunibini ti o de ba wọn ni akoko naa, jù lati jẹ “fāji è̩ṣẹ fun igba diẹ.” Ọlọrun bukún Manaeni, O si sọọ di alagbara ninu iṣẹ Oluwa. Lai si aniani, iduro irú eniyan bayii ninu ijọ, ẹni ti o ti ni ipo ọlá ni ayé, fun awọn ẹlomiran ni igboya lati dara pọ mọ ijọ.
ỌrọẸmi Mimọ
Bi awọn alakoso wọnyi ti n gbadura ti wọn si n gbaawè̩ ki iṣẹỌlọrun le di mimọ fun ọpọlọpọ eniyan, Ẹmi Mimọ wi pe, “Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si.” (Titi di igba yii Saulu ni a n pè Paulu Apọsteli). Akoko tó fun wọn wayii lati ṣe ohun ti a pè wọn lati ṣe. Nigba ti Saulu yi pada, Ọlọrun rán Anania si i pe yoo jé̩ ohun-elo aayo lati waasu Jesu fun awọn Keferi. O dabi ẹni pe a ti sọ fun Barnaba naa tẹlẹ pe a o rán a si awọn Keferi.
Ipe ti o le mú aṣeyọri wá ninu iṣẹ-iranṣẹ ati iṣẹ itankalẹ Ihinrere ni lati jé̩ eyi ti o jade lati Ọrun wa. Ni akoko yii, Ẹmi Mimọ fi hàn pé Oun dọgba pẹlu Ọlọrun nigba ti O sọrọ pẹlu aṣè̩ fun awọn eniyan wọnyi lati ṣiṣẹ Oluwa. O fi hàn pé Oun jé̩Ẹni kan nigba ti ẹsè̩ ti a kà yii wi pe O sọrọ.
Iṣẹ Paulu ati Barnaba ni Antiọku tẹlẹ kò tayọọdọ awọn Keferi, ṣugbọn nisisiyi iṣẹ wọn n pọ si i. Ọpọlọpọ awọn Keferi ni o wà ni ayika kaakiri ti wọn fẹ mọ nipa Jesu. Paulu ati Barnaba duro lẹnu iṣẹ ti wọn ti n ṣe tẹlẹ titi a fi sọ fun wọn pe ki wọn tè̩ siwaju. Ọlọrun bukun iṣẹ-iranṣẹ wọn, ọpọlọpọọkàn ni a si ti gbàlà. S̩ugbọn nisisiyi Ẹmi Mimọ paṣẹ pe ki wọn tè̩ si iwaju.
Awọn àgbà ijọ Antiọku pejọ pọ lati gbadura fun Paulu ati Barnaba, wọn si gbéọwọ lé wọn lati yà wọn sọtọ fun iṣẹ ti wọn ni lati ṣe. Awọn ijọ kọwọ ti iṣẹ awọn ajihinrere wọnyi lẹyin pẹlu adura ati aṣẹ wọn, ṣugbọn lati Ọrun ni ipè yii ti kọ jade wá. Jesu wi pe: “Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin” (Johannu 15:16).
Wọn Lọ si Kipru
Ipe Ẹmi Mimọ yii n gbé wọn lọ si apa keji okun. IranṣẹỌlọrun kekere kan ti a n pe ni Johannu Marku bá Paulu ati Barnaba lọ. Awọn ajihinrere mẹtẹẹta wọnyi lọ si ọna ti o jinna réré si ile, wọn lọ si erékùṣù Kipru.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn Keferi ni wọn jade lọ lati waasu fun, sibẹ ninu sinagọgu awọn Ju ni wọn ti i maa kọṣe ipade nigba gbogbo. Awọn Ju n rò ninu ara wọn pe wọn jé̩ẹni ti Ọlọrun fẹran jù awọn iyoku lọ sibẹ, nitori naa awọn ni a ni lati fun ni anfaani akọkọ lati gbàè̩kọ Jesu. Bi wọn ba gbà a, lẹsẹkẹsẹ wọn yoo ni idapọ Onigbagbọ pẹlu awọn Keferi ti a ti gbàlà; ṣugbọn bi wọn ba kọọ, wọn kò ni è̩tọ lati kùn. A ti fun wọn ni anfaani.
Wọn pade Alafọṣẹ
Ninu irin-ajo awọn ajihinrere wọnyi ni erékùṣù Kipru, wọn bá oṣo kan tabi alafọṣè̩ pade. Awọn eniyan ti o wà ni erekùṣù yii kún fún isin atọwọdọwọ asan, wọn si feti si ti ọkunrin yii nigba ti o ba n sọ itan rè̩. Iṣẹ-iyanu ti o n fi agbara ẹmi Eṣu ṣe tilè̩ kún baalẹ ti awọn ara Romu fi sibẹ loju. S̩ugbọn nigba ti baalẹ yii, ẹni ti a npe ni Sergiu Paulu, gbọ nipa Paulu ati Barnaba, ọkàn rè̩ fà si wọn pupọpupọ. Ọkàn rè̩ n fẹ otitọ. Oun a ti maa feti si ti oṣo yii nitori pe kò mọọna miiran. Nigba ti o gbọ pe awọn Ajihinrere wọnyi ni imọỌrọỌlọrun ati pe wọn n waasu otitọ, o fẹ gbọ ohun ti wọn n sọ.
S̩ugbọn Elima, oṣó, kò fẹ ki ọrẹ rè̩ ti o wà ni ipo ọlá yii fi oun silẹ. O mọ pe kò si idọgba laaarin è̩kọ rè̩ ti i ṣe ti èṣù, ati è̩kọ Paulu on Barnaba. Bi Sergiu Paulu ba di Kristiani, ọrẹ wọn yoo bajẹ. Oṣó yii bè̩rè̩ si tako iwaasu otitọ.
Nigbakigba ti a ba n waasu ỌrọỌlọrun ninu Ẹmi, Satani a maa sa ipa rè̩ lati dena awọn ti wọn n gbọ. Bi ẹni kan ba fẹ di Kristiani, awọn eniyan a saba maa sọ fun un pe “Bi o ba di Kristiani, iwọ ki yoo le gbadun ayé mọ.” Nigba miiran Satani le sọ kẹlẹkẹlẹ wipe, “Iwọ kò ni le ṣe awọn atunṣe wọnni.” “Bi o tilẹ bè̩rẹ, iwọ ki yoo le gbé igbesi-ayé Onigbagbọ.” “Igbesi-ayé Onigbagbọṣoro.”
Irọ ti èṣu n pa ni gbogbo eyi jé̩. Kò si ẹni ti o ni ayọ bi Onigbagbọ. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe, “Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki ayọ mi ki o le wà ninu nyin, ati ki ayọ nyin ki o le kún” (Johannu 15:11). Woli Isaiah sọ pẹlu wi pe: “Ẹnyin o si fi ayọ fà omi jade lati inu kanga igbsla wá” (Isaiah 12:3).
Ihinrere Mimọ
A le fi iṣẹ-iranṣẹ Elima wé ti awọn ẹlẹsin èké, awọn ti o kún fun ọpọlọpọ adabọwọ aṣerege. Awọn ẹlomiran a maa lọ sinu iṣipaya nigba ti wọn ba n lù tabi ti wọn n jó ti wọn si n patẹwọ, wọn a si wi pe Ẹmi Ọlọrun ni. Awọn miiran a maa jó ijo ẹmi wọn a si bẹrẹ si riran. Gbogbo jijà pàtipàti wọnyi ki i ṣe ti Ọlọrun.
Ihinrere ti Paulu ati Barnaba n waasu jé̩ eyi ti o n mu ki a gbé igbesi-ayé iwa-mimọ. Wọn n ṣe isin wọn letoleto. Paulu Apọsteli sọ fun wa pe: “Nitori Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia, gẹgẹ bi o ti jẹ ninu gbogbo ijọ enia mimọ” (1 Kọrinti 14:33).
Ẹru kò ba Paulu lati sọ fun Elima oṣó pe ọmọèṣu ni Elima i ṣe. Paulu kún fun Ẹmi Mimọ, ọrọ ti o sọ si ṣẹ. O sọ idajọ ti yoo dé ba Elima – yoo fọjú ni saa kan – o si ri bẹẹ lẹsẹkẹsẹ. Idajọ le falẹ nigba pupọ, ṣugbọn bi ẹlẹṣè̩ kò bá ronupiwada, idajọ ti o daju mbọ wá nigbooṣe.
Nigba ti Sergiu Paulu ri i bi Ọlọrun ti n ṣiṣẹ lati ọwọ Paulu, ti o si gbọẹkọ ti Paulu n waasu rè̩, o gba Jesu gbọ. Ẹkọ yii jẹọtun loju rè̩. Boya kò tilẹ gbọ nipa Jesu ri. S̩ugbọn o mọ otitọ yatọ nigba ti o gbọ iwaasu otitọ lẹnu Paulu ti o kún fún ifororoyan Ẹmi Mimọ.
Ẹni kan ni yii ti o jé̩ẹni nla nipa ti ara, ti o rẹ ara rè̩ silẹ lati di ayanfẹỌlọrun. Paulu Apọsteli sọ nigba kan pe: “Ki iṣe ọpọ awọn ọlọgbọn enia nipa ti ara, ki iṣe ọpọ awọn alagbara, ki iṣe ọpọ awọn ọlọlá li a pè” (1 Kọrinti 1:26). Obinrin kan ti a bi ni ile ọlá ti o si wa di Onigbagbọ, sọ bayii nigba kan pe, “Mo dupẹ lọwọỌlọrun fun Ọrọ Rè̩.” Inu mi dùn nitoriti O wi pe, “ki iṣe ọpọọlọgbọn” ti kò si wi pe “kò si ninu awọn ọlọgbọn.”
Iwaasu Paulu ati Barnaba yọri si rere bi o tilẹ jé̩ pé Satani gbogun; ṣugbọn a jere ọpọlọpọọkàn awọn Keferi fun Ijọba Ọrun.
Questions
AWỌN IBEERE- Ọdun wo ni a dá ijọ silẹ ni Antiọku?
- Awọn ta ni ojiṣẹỌlọrun akọkọ nibẹ?
- Ọkunrin ọlọlá wo ni a gbàlà nibẹ?
- Iṣe nla wo ni o bẹrẹ si i gbèrú lati ijọ Antiọku?
- Ọdọmọkunrin wo ni o bá Paulu ati Barnaba lọ ni irin-ajo itankalẹ Ihinrere ti akọkọ?
- Nibo ni wọn lọ?
- Ta ni awọn ajihinrere bá pade ni erekùṣù nì?
- Eniyan pataki wo ni o yi pada nibẹ?
- Itọni wo ni Paulu fun ni nipa ọna ti a le gbàṣe eto isin?