Iṣe Awọn Apọsteli 13:13-52

Lesson 325 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nwọn si jade lọ, nwọn si nwasu nibigbogbo, OLUWA si mba wọn ṣiṣẹ, o si nfi idi ọrọ na kalẹ, nipa àmi ti ntè̩le e” (Marku 16:20).
Notes

Awọn Iṣoro

Ohun iṣiri ni lati fi oju ẹmi bá Paulu lọ ni awọn irin-ajo rè̩ fun itankalẹ Ihinrere. A kò gbọdọ gbagbe pe irin-ajo kò rọrun ni akoko Paulu gẹgẹ bi o ti rọrun lọjọ oni. O sọ diẹ nipa iriri rè̩ ninu irin-ajo rè̩ lati waasu Kristi. O sọ fun ni pe ewu wà lori ilẹ ati loju omi; ewu awọn olè ati awọn keferi; ewu awọn ara ilu rè̩; ewu ni ilu ati ewu ni aginju. Igba pupọ ni o rè̩ẹ ti o si n ni irora. Nigba miiran ebi pa a oungbẹ si gbẹẹ. Nigba miiran ẹwè̩, otutu mu un aṣọ kò si pọ tó lọwọ rè̩. (Ka 2 Kọrinti 11:7-27). A kò ri i kà wi pe Paulu kùn nitori gbogbo iṣoro ti o de ba a nitori Jesu Kristi, ṣugbọn o wi pe: “Emi kò kàẹmi mi si nkan rara bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o ba le fi ayọ pari ire-ije mi” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:24).

Paulu ti gbọ ipèỌlọrun lati ṣiṣẹ o si ti pinnu lati ṣe iṣe naa ni aṣepari. Lẹyin ti a gba ọkàn rè̩ là, Oluwa sọ nipa rè̩ pe: “Ohun elo àyo li on jẹ fun mi, lati gbe orukọ mi lọ si iwaju awọn Keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Israẹli” (Iṣe Awọn Apọsteli 9:15). Paulu yoo jé̩ imọlẹ fun awọn Keferi a o si lo o lati tan Ihinrere ká gbogbo ayé (Iṣe Awọn Apọsteli 13:47).

Barnaba

Barnaba ti i ṣe oluranlọwọ Paulu ti fi ara rè̩ rubọ fun Ọlọrun patapata. Nigba kan ri o ni ilẹ kan, ṣugbọn o ta a o si gbé owó rè̩ wá si ọdọ awọn Apọsteli, ki a ba le ṣe ipinfunni fun awọn ti o ṣe alaini (Iṣe Awọn Apọsteli 4:34-37). Nigba ti Paulu ṣẹṣẹ ri igbala, Barnaba mú Paulu lọrẹ o si fi ifẹ hàn fun un (Iṣe Awọn Apọsteli 9:27). Paulu ṣe ori ire lati ni Barnaba ni oluranlọwọ, ẹni rere ti o ni igbagbọ ti o si kún fun Ẹmi Mimọ (Iṣe Awọn Apọsteli 11:24).

Johannu Marku

Ọdọmọkunrin kan ti a n pe ni Johannu Marku wà pẹlu Paulu ninu irin-ajo rè̩ fun Itankalẹ Ihinrere, awọn mẹtẹẹta si jumọ fi erekuṣu Kipru silẹ. Wọn wọọkọ gbàọna Okun Mẹditareniani lọ si Aṣia wọn si gunlẹ ni ibi kan ti a n pe ni Perga. Boya ninu irin-ajo yii ni wọn gbé bọ sinu ewu ti Paulu sọ nipa rè̩ lẹyin eyi.

Nigba ti wọn gunlẹ, Marku pinnu lati fi awọn iyoku silẹ lati pada si Jerusalẹmu. Eyi dabi ijatilẹ fun Paulu ni akoko yii; ṣugbọn lẹyin eyi o sọ fun ni pe Marku jé̩ oluranlọwọ ti o “wulo” ninu iṣẹ-iranṣẹ, o si sọrọ rere nipa rè̩ (2 Timoteu 4:11; Filemoni 24).

Titi de Opin

Nigba ti eniyan bá n wá idariji è̩ṣẹ, yoo pinnu lati fi ayé rè̩ sin Ọlọrun. Gẹgẹ bi o bá si ti n sún mọỌlọrun si i ti o si ni imọ si i nipa ifi-ara-ẹni-rubọ, yoo wá iriri ologo ti isọdimimọ ati agbára Ẹmi Mimọ, oun yoo si ri wọn gbà. S̩ugbọn o ni lati mu è̩jé̩ rè̩ṣẹ. Ọpọlọpọ ni o ti sọ pe “Oluwa, mo fi ayé mi fun Ọ,” lai mọ itumọọrọ ti wọn sọ yii ni kikún. Kò si èrè ti a lè ri gbà ninu ipadasẹyin – bi o ba ti bè̩rè̩, tẹra mọọn titi de opin.

Wọn gba pàlàpáláọna oke wọnni lọ si Antiọku ti Pisidia. Anfaani lati mú Ihinrere tọọpọlọpọ eniyan lọ ni ilú yii yoo ṣi silẹ fun wọn lai pẹ jọjọ. Boya kò yẹ ki o pada sẹyin, Marku; iwọ i ba ni anfaani gẹgẹ bi Barnaba, lati gbọ bi Paulu ti waasu agbaayanu ni Antiọku.

Ninu Sinagọgu

Ni ọjọ Isinmi kan, wọn lọ si sinagọgu awọn Ju. Sinagọgu wọnyi jẹ ibi ti awọn Ju ti n pade lati ka Iwe Ofin. A sọ fun ni pe sinagọgu ti o wà ni ilu Jerusalẹmu to nnkan bi ọtà-le-nirinwó (460) tabi ọrin-le-nirinwó (480); ṣugbọn Antiọku kò tobi tó Jerusalẹmu.

Lẹyin kika Iwe Ofin ati awọn wolii, olori sinagọgu ran ẹni kan lati beere lọwọ awọn alejo meji wọnyi bi wọn ni ohunkohun lati sọ fun awọn eniyan. Wò anfaani ti o ṣi silẹ fun Paulu – anfaani ti o ti n wá!

Lẹsẹkanna Paulu dide o si ba awọn Ju sọrọ, wipe, “Ẹnyin enia Israẹli, ati ẹnyin ti o bè̩ru Ọlọrun, ẹ fi eti silẹ.” Nigba naa li o sọ bi Ọlọrun ṣe bá awọn Ju lò lati ibè̩rè̩ orilẹ-ède yii titi de akoko Jesu. Paulu ti kè̩kọọ nipa Ofin ati awọn woli labẹ olukọ pataki kan ti a npe ni Gamaliẹli, Paulu le kà Ofin lati ori wá o si le ṣe alaye bi a ṣe mu asọtẹle nipa Jesu ṣẹ. O sọ fun wọn pe, “Awa li a rán ọrọ igbala yi si” (Iṣe Awọn Apọsteli 13:26). O sọ fun wọn pe awọn ti o wà ni Jerusalẹmu ti a nka Iwe Ofin fun ni Ọjọjọ Isinmi ni o dá Jesu lẹbi ikú. Paulu tọka si Orin Dafidi 16:10 nigba ti o wipe, “Iwọ ki yio jẹ ki Ẹni Mimọ rẹ ri idibajẹ” (Iṣe Awọn Aposteli 13:35). Eredi rẹ niyii ti ọkàn awọn Ju fi kún fún aigbagbọ fọfọ: wọn kò gbagbọ pe Jesu jinde kuro ninu okú. Paulu sọ fun wọn pe a ti sin Dafidi sinu iboju rè̩, ara rè̩ si ti pada di erupẹ, ṣugbọn Jesu jinde ni ọjọ kẹta.

Paulu sọ fun wọn bi o ti dara pupọ tó lati tọ Jesu lọ fun idariji è̩ṣẹ ju pe ki a wà labẹ Ofin. O kilọ fun wọn kikankikan pe ki wọn máṣe ké̩gàn “ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù.” Ni kukuru, Paulu rọ awọn Ju ki wọn máṣe kọ ifẹ Jesu silẹ ki wọn má ba ṣegbe titi lai.

Ni ipari iwaasu yii, awọn Keferi sọ pe ki Paulu wá waasu fun wọn ni Ọjọ Isinmi ti mbọ. Inu rè̩ dùn lọpọlọpọ, ni Ọjọ Isinmi ti o tẹle e, o fẹrẹ jé̩ pé gbogbo ilu patapata li o wá lati gbọỌrọỌlọrun. Eyi yii mu ki awọn Ju kún fun owú, wọn si n sọrọ lodi si ọrọ Paulu. S̩ugbọn oun mọ ohun ti yio fi da wọn lohun: Ọlọrun ti lana rè̩ silẹ pe ki a waasu Ihinrere fun “Ju ṣaju” (Romu 1:16); eredi ti Paulu fi waasu fun awọn eniyan ni yii. “S̩ugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ si kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun, wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi” (Iṣe awọn Apọsteli 13:46).

Lilé Jade

Diẹ ninu awọn Ju ati ọpọlọpọ Keferi gbagbọ, a si gbà wọn là ninu isọji nla ti o pari lojiji yii. Awọn Ju dá rúkèrúdò silẹ wọn si mú ki a lé Paulu ati Barnaba kuro nibẹ. Paulu ati Barnaba gbọn ekuru ẹsẹ wọn silẹ bi ẹni pe wọn n fẹ ki o di mimọ fun awọn Ju ti o wà ni Antiọku pe, “Anfani ti nyin ti kan nyin lara ṣugbọn ẹ ti kọọ, awa n tọ awọn ti o ṣetan lati gba Ihinrere lọ”. Wọn si lọ si Ikonioni, ti o nnkan bi mile marundinlaadọta ni iha isalẹ ila-oorun Antiọku.”

Si orilẹ-ède gbogbo

Ọlọrun fun olukuluku ọkàn ni anfaani lati gba Oun gbọ ati lati ri igbala. Jesu wipe: “A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de” (Matteu 24:14). Paulu ati Barnaba wà lara awọn ti a kọkọ rán jade lati waasu Ihinrere nigbati Ijọṣẹṣẹ bè̩rẹ. Lati igbani ni a ti n kede ihin igbalà kakiri gbogbo ayé. Awọn eniyan diẹ li o nwáỌlọrun nitootọ ti wọn si n ri igbala, ti wọn si n gbé igbesi-ayé ti o báỌrọỌlọrun mu. S̩ugbọn a ti waasu Ihinrere ká gbogbo ayé, opin si kù si dè̩dè̩.

Gbogbo wa kọ ni yoo jade bi ajihinrere si ilu òkeerè, ṣugbọn ẹ jé̩ ki a sa gbogbo ipa wa lati mu ki ọkàn pupọ yipada si Oluwa ki o tó pé̩ jù. Awọn ẹlomiran kò ni anfaani lati lọ si oke-okun lati lọṣiṣẹ gẹgẹbi ajihinrere, ṣugbọn wọn le ṣiṣẹ fun Jesu ni ile nihin. Awọn ẹlomiran le fi owó wọn ṣe iranwọ lati pese fun aini awọn ti iṣe ajihinrere ni ilu òkeerè; tabi ki wọn pin iwe ihinrere fun awon aladugbo wọn ki wọn si pe awọn eniyan wá si ile Ọlọrun. Iwọ ha n tiju Ihinrere? Paulu kò tiju Ihinrere (Romu 1:16). Ọna miiran ti a le gbà lọwọ ninu itankalẹ Ihinrere ni pe ki a maa gbadura ki ibukun Ọlọrun le wà lori gbogbo ipade iwaasu ode, isin ti a nṣe ni ile-tubú ati gbogbo ibẹwo ti a nṣe ni ile-alárùn. Olukuluku wa lọkunrin, lobinrin, ati lọmọde le ni ipin ninu jijeere ọkàn fun Kristi nipasẹ adura. “Awọn ọlọgbọn yio si ma tàn bi imọlẹ ofurufu: awọn ti o si nyi ọpọlọpọ pada si ododo yio si ma tàn bi ìrawọ lai ati lailai” (Daniẹli 12:3).

Imọlẹ ninu Okunkun

Paulu ti iṣe Ju ti a pe lati jé̩ “imọlẹ awọn Keferi” (Iṣe wọn Apọsteli 13:47), di Aposteli nla ati imọlẹ nla pẹlu. Kò kuna ipè giga rè̩. Olukuluku ẹni ti Ọlọrun ba pè lode oni – Ju tabi keferi – a pè e lati jé̩ imọlẹ nitori pe Jesu kọ wa pe, “Ẹnyin ni imọlẹ aiye” (Matteu 5:14). Awa o ha jé̩ oloootọ si ipè giga wa, bi ti Paulu, ki a si jé̩ imọlẹ fun araye nipa ẹri wa ati igbesi-ayé ti a n gbé?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta li o wà pẹlu Paulu ni irin-ajo yii?
  2. Sọ bi a ṣe fun Paulu ni anfaani lati waasu ni Antiọku.
  3. Ki ni kókó iwaasu rè̩?
  4. Ihà wo ni awọn Keferi kọ si iwaasu Paulu?
  5. Ki ni o ṣẹlẹ ni Ọjọ Isinmi ti o tẹle e?
  6. Sọ ohun ti awọn Ju ṣe ni akoko yii.
  7. Ihinrere ha i ṣe ti awọn Ju tabi ti awọn Keferi?
  8. Ta ni a rán Paulu si gan an?
  9. Lọ wá awọn ẹsẹỌrọỌlọrun ti o kọ wa pe Ọlọrun ki i ṣe ojuṣaaju eniyan.