Iṣe Awọn Apọsteli 14:1-28

Lesson 326 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye” (Johannu 16:33).
Notes

Lati Ikonioni lọ si Listra

A lé Paulu ati Barnaba kuro ni Antiọku ti Pisidia lẹyin ti wọn ti waasu kan ti o kún fún agbára Ọlọrun nibẹ. Nigba ti Ijọṣẹṣẹ bẹrẹ ati ni oni-oloni yii, nibikibi ti a bá ti n waasu otitọ, èṣu wà nitosi lati dáìyapa tabi irukerudo silẹ lọna kan tabi lọna miiran. Ni akoko yii, ni Ikonioni, eṣu gbé ogun dide, nigba ti awọn ajihinrere meji wọnyi ri i pe awọn eniyan naa n pète lati sọ wọn li okuta, wọn fi ibẹ silẹ, wọn si lọ si ilu miiran.

Ninu awọn Episteli ti Paulu kọ lẹyin naa, o fi igbesi-ayé Onigbagbọ wé igbesi-ayéọmọ-ogun, awọn ohun ti a kà ninu iwe wọnni tó lati fi hàn fún wa eredi rè̩ ti Paulu fi rò bẹẹ. Igbesi-ayéọmọ-ogun ki i ṣe igbesi-ayé faaji, Paulu kò si reti pé ki ohun gbogbo maa lọ deedee fun oun. Ewu pupọ ni o n dojukọọmọ-ogun, oun kò si gbọdọ huwa ojo ki o si sá kuro loju ogun; ṣugbọn nigba miiran o ṣanfaani lati yẹra bi bẹẹkọ yoo sọẹmi rè̩ nù. Ni akoko Ogun Ajakaye Keji, ewu a maa wa fun awọn ọdọmọkunrin ti i ṣe Onigbagbọ, ti o wà loju ogun, igba pupọ ni Ọlọrun n fọhun si wọn lati sọ fun wọn pe ki wọn kuro nibi ti ewu wà. A gbagbọ pe ohùn Ọlọrun ni o kilọ fun awọn ọmọ-ogun Kristi wọnyi lati kuro ni ilu Ikonioni lọ si Listra li akoko ti o wọ.

A sọọ li Okuta

S̩ugbọn awọn ikà Ju ti o wà ni Antiọku ati Ikonioni pinnu sibẹ lati dá iṣẹ Paulu duro. Wọn tẹle e lọ si Listra. Laisi aniani wọn gbọ pe iṣẹ yii nlọ deedee, nitori pe ni Listra li a ti múọkunrin arọ kan laradá nipa agbára Ọlọrun. Boya wọn ri i bi o ti n fò sókè-sódò, ohun ti kòṣe ri. Nikẹyin wọn fi ọrọ yi awọn eniyan naa lọkàn pada wọn si sọ Paulu li okuta.

Nisisiyi wọn ti mú ifẹ inu wọn ṣẹ; nisisiyi wọn rò pé wọn ti ṣi i lọwọ iwaasù rè̩ nipa ajinde Jesu. Wọn fẹ pada sinu àṣa ati ilana isin wọn atijọ. Ọkàn ibi wọn kò tilẹ fẹ bikità pé a mú alaisan kan laradá nipa ọrọ Paulu. Wọn kò fẹ ki a fun ọkàn awọn onirobinujẹ layọ, gẹgẹ bi o ti ri nibi ti Paulu gbé waasu (Iṣe Awọn Apọsteli 13:48).

Ọrọ Ayeraye

Lati atetekọṣe ni awọn ti o kọjuja si Ihinrere Jesu Kristi ti n gbiyanju lati pa iná otitọỌrọỌlọrun ki wọn si dá itankalẹ Ihinrere duro. Nigba kan ni ilẹ Gẹẹsi, awọn alaṣẹ ilu bẹrẹ si ṣọ gbogbo ibode wọn, wọn si gba ẹgbẹẹgbẹrun Majẹmu Titun, wọn si fi ina sun wọn ni ikorita kan ti a n pe ni Saint Paul; ṣugbọn a tun tè̩ awọn miiran jade. Nigba ti wọn ri i pe kòṣeeṣe pe ki a má kó awọn iwe wọnyi wa si ilẹ Gẹẹsi, Biṣọbu London sọ fun oniṣòwò kan pe ki o ra gbogbo iwe yii tan patapata lati ibi ti a gbé ti n ko wọn wá ni oke okun. S̩ugbọn oniṣowo yii jẹọrẹ Tyndale, ti i ṣe ẹni kin-in-ni ti o túmọ gbogbo Bibeli si ede Gẹẹsi. Oniṣowo yii dahùn lọgan pe “Mo fẹ ki o mọ daju pe gbogbo iwe yii ti a kò ti tà ni yoo tẹọ lọwọ.” Biṣọbu yii lero pe “ọwọ on ti tè̩Ọlọrun ni aimọ wi pe ọrun ọwọ eṣu ni o dimu,” o si ṣeleri lati san iyekiye ti owo iwe wọnyi bá jé̩ nitori ti o wi pe, “awọn iwe naa kò dara, mo si ti pinnu pe ki yoo ku ẹyọ kan, nitori emi o fi ina sun wọn ni Ikorita Paulu.” Lọgan ni oniṣowo yii ra gbogbo iwe ti o kù lọwọ Tyndale, ni ero pe laisi aniani Biṣọbu yii yoo fi ina sun wọn nitootọ. Nisisiyi o wá ni owó ti o tó lati fi tè̩ eyi ti o pọṣua, lẹyin ti o ti tẹẹ tan, ọpọlọpọ iwe yii si tun n wọ ilẹ Gẹẹsi.

Nigba ti awọn ti wọn dojuja kọ Iwe yii ri i nikẹyin pe wọn kò lagbara lati pa iwe yii run, ọkan ninu wọn ṣe iwaasu nla kan ni Ikorita Paulu, o n tọka si “ohun buburu” ati aṣiṣe ti o wà ninu Iwe naa. Ni ipari iwaasu rè̩ o ju iwe naa sinu ina nla kan ti o wà nitosi. Bi idojukọ kikoro yii ti pọ tó, Iwe yii di ohun ti a n kà kaakiri a si n royin rè̩ ju ti atẹyinwa lọ, titi o fi di ọjọ kan, ti Biṣọbu kan wi pe, “O tayọ agbara mi, tabi ẹnikẹni ti o wà fun ohun ti ẹmi, lati ṣe idènà rè̩ nisisiyi.” Ọna wá là silẹ kedere fun Bibeli bayii; kò si ọba tabi ijoye kan ti o le dènà itẹsiwaju rè̩, nitori Ọlọrun wi pe, “ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà!”

Lode oni, Bibeli ni Iwe ti o pọ julọ ninu awọn iwe ti a n tè̩ fun tita; a ti tumọ gbogbo rè̩ tabi apakan ninu rè̩ si oriṣiriṣi ède ti o tóọgọfa le ni ẹgbè̩rún o din meji, a si le ri i ra ni owó pọọku. Ogbogi kan ninu awọn ti kò gbà péỌlọrun wa ti a n pe ni Ingersoll, gbéẹyọ Bibeli kan soke, o si wipe, “Laaarin ọdun mẹẹdogun, emi o mú ki a sọ Iwe yii si ibi ti wọn n gbéòkú si (mortuary).” Laaarin ọdun mẹẹdogun, a ti gbé Ingersoll gbin, ṣugbọn Bibeli wà sibè̩. Voltaire, alaigbagbọ miiran sọ pe ni iwọn ọgọrun ọdun si i, a o ti gbagbe Bibeli si ibi ti a gbe E tì si. Ni opin ọgọrun ọdun yii, ile rè̩ di ti awọn ẹgbé̩ kan ni Geneva ti o n tẹ Bibeli jade.

Jijiya fun Kristi

Nigba kan ri, Paulu ni ohùn si sisọ ti a sọ Stefanu li okuta, oun li o tilẹ kó aṣọ awọn ti o ṣè̩è̩ṣẹ buburu yii lọwọ (Iṣe Awọn Apọsteli 22:20). Lẹyin naa Paulu jẹ iru iyà kan naa fun Kristi lati ọwọ awọn ẹlẹṣè̩. S̩ugbọn Ọlọrun mọ pé iṣẹ Paulu kò i ti pari, O si gbe e dide. O pada si idi iṣẹ iwaasu, laisi aniani a ti mu u laradá. Paulu ati awọn Apọsteli ti o wà pẹlu rè̩ kò ni ṣalai yin Ọlọrun logo bi o ti dide lori è̩ṣẹ rè̩ ti o si tun pada lọ sidi iṣẹ rè̩.

Nigbati Paulu yipada, Ọlọrun sọ fun Anania pe, “Emi o fi gbogbo iyà ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a” (Iṣe Awọn Apọsteli 9:16). Nisisiyi Paulu ti fi ara gbá diẹ ninu ijiyà yii, kò si ti dopin.

Nigba miiran, Ọlọrun a maa fi ayè silẹ fun wahala ti o le lati dé ba awọn ayanfẹ Rè̩, nigba miiran ọna na le kun fun “pàlapála” ṣugbọn niwọn igba ti o jé̩ pé eyi ṣẹlẹ nipa ifẹỌlọrun, fun ire wa ni. Ẹ máṣe jẹ ki a gbagbe eyi nigba ti iṣoro tabi idanwo ba dé bá wa. Bi a kò ba ti i jiyà fun Kristi titi di isisiyi, a le ri diẹ ninu nnkan wọnyi ki ọjọ ayé wa to buṣe, nitori pe ọgọrigọri ibi n bọ lori ayé ti o n darugbo lọ yii. Ẹ jẹ ki a pinnu lọkàn wa lati duro ṣinṣin ki a má si jẹ ki igbagbọ wa ninu Ọlọrun ki o yè̩.

Ipadabọ sile

Irin-ajo Paulu gẹgẹ bi ajihinrere n lọ sopin gẹgẹ bi ọkọ rè̩ ti n sunmọ Siria lẹẹkan si; lẹyin eyi wọn lọ si Antiọku nibi ti wọn gbé ti bè̩rẹ irin-ajo wọn. Wò bi ipadabọ wọn sile ti dara tó! Olukuluku eniyan wá si ile-isin lati gbọ iroyin ohun ti Ọlọrun ṣe, lẹnu Paulu. Ihin ti o dara julọ ti wọn mu bọ ni pe Ọlọrun ti ṣilẹkun Ihinrere silẹ fun awọn Keferi (Iṣe Awọn Apọsteli 14:27). Wò bi ayọ yoo ti bé̩ jade loju Paulu bi o ti n sọ fun wọn pe awọn Keferi pe oun lati waasu fun wọn, ati pe o fẹrẹ jé̩ pé gbogbo ilu li o pejọ lati gbọỌrọỌlọrun. A mọ daju pe o mu ihin daradara bọ nipa irin-ajo rè̩ kin-in-ni yii, bi o tilẹ jẹ pe gbogbo ajo na kọ ni o rọrùn jalè̩. Bi o ba sọ nipa ewu, iṣoro, sisọ ti a sọọ li okuta, a mọ pe lati fi hàn bi ọwọ aabòỌlọrun ti pọ tó ni, agbára ipamọ Rè̩, ati oore-ọfẹ Rè̩ ti o n ba a lọ ninu iṣisẹ kọkan ti o gbé ni gbogbo irin-ajo yii. A gbagbọ pe kò ni ṣalai fẹ ki o di mimọ pe ayọ ti o wà ninu iṣẹ-isin tayọ gbogbo iṣoro ati wahala ti wọn bá pade lọna. Gbogbo Onigbagbọ li o ni irúọkàn bẹẹ nipa iṣẹ-isin wa si Ọlọrun.

Ọna Agbelebu

Bi o ba jé̩ọmọkunrin tabi ọmọbinrin ti a ti gbàọkàn rè̩ là niwọn igba diẹ sẹyin, boya yoo ti di mimọ fun ọ wi pe nipa gbigbe igbesi-ayé Onigbagbọ iwọ ti bá idanwo ati iyiriwo diẹ pade. S̩ugbọn o ti di mimọ fun ọ pẹlu pe eyi li ọna ti o dara julọ, nitori pe ayọ Oluwa wà li ọkan rẹ, ohunkohun ti o wù ki o dé. Bi o ba jé̩ọdọmọkunrin tabi ọdọmọbinrin ti a ṣè̩ṣè̩ gba ọkàn rè̩ là laipẹ jọjọ, iwọ le bá iṣoro diẹ pade loju ọna rẹ; ṣugbọn a maa saba n sọ bayii pe akoko ti o buru julọ fun Onigbagbọ sàn ju akoko ti o dara julọ fun ẹlé̩ṣè̩. Bi iwọ ba jé̩ọdọmọkunrin tabi ọdọmọbinrin ti a kò i ti gba ọkàn rè̩ là, bi o ba si fẹ fi Ọrun ṣe ile rẹ, máṣe jé̩ ki ọna Agbelebu dabi eyi ti o ṣoro li oju rẹ, ranti pe oun li ọna ti o lọ si Ile. Ohunkohun ti o wù ki o dé, ranti ileri yii pe, “Ore-ọfẹ mi to fun ọ” (2 Kọrinti 12:9). Nipasẹ Kristi iwọ le ja ajaṣẹ ninu gbogbo ogun ti o ba dide si ọ.

Onigbagbọ ni anfaani lati bá Jesu rin ati lati ba A sọrọ; lati sọ gbogbo iṣoro rè̩ fun Un. Jesu mọ gbogbo rè̩ ju obi ti i ṣe oninuure ati onifẹ. Lojoojumọ li O n fi ohun rere gbogbo dé igbesi-ayé Onigbagbọ lade, O si ti pese ile daradara kan silẹ li Ọrun fun gbogbo awọn ti wọn ba ṣe oloootọ titi dé opin. Paulu wi pe: “Nitori mo ṣiro rè̩ pe, ìya igba isisiyi kò yẹ lati fi ṣe akawe ogo ti a o fihàn ninu wa” (Romu 8:18).

Iwọ ha le sọ ohun ti olorin nì sọ --

“Nko gbadura fun okiki,

Tabi afé̩ aye yii;

Layọ, ngo ṣiṣẹ ngo jiya

Ki nsa le mā ba Ọ rin.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni o ṣẹlẹ ni Listra lẹyin ti a ti wo ọkunrin arọ nì sàn?
  2. Awọn tali o yi awọn eniyan lọkàn pada lati sọ Paulu ni okuta?
  3. Awọn ilu wo ni Paulu ati Barnaba bẹwo nigba ti wọn n pada bọ sile?
  4. Nibo ni wọn pada si?
  5. Irú ipade wo ni iwọ rò pe wọn ni nigba ti Paulu pada bọ sile?
  6. Njẹ irin-ajo Paulu akọkọ lati waasu Ihinrere yọri si rere bi?
  7. Wo awọn ẹsẹỌrọỌlọrun ninu Bibeli eyi ti o n sọ fun wa nipa èrè ti o wà fun igbesi-ayé ti a lo fun iṣẹ-isin Ọlọrun.