Lesson 327 - Senior
Memory Verse
“Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn” (1 Kọrinti 15:20).Cross References
I Otitọ Ajinde Kristi
1. O ṣẹlẹ gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wi, 1 Kọrinti 15:1-4; Orin Dafidi 16:9, 10
2. A fi idi otitọ rè̩ mulẹ lati ọdọ awọn ẹlẹri, 1 Kọrinti 15:5-7; Iṣe Awọn Apọsteli 4:33; 10:40, 41
3. Paulu tikara rẹ jé̩ẹlẹri, 1 Kọrinti 15:8-11; Iṣe Awọn Apọsteli 9:4, 17; 22:14, 18
II Pataki Ajinde Kristi
1. O fi hàn pé ajinde okú wà, 1 Kọrinti 15:12-15; Iṣe Awọn Apọsteli 1:3
2. O jé̩ ipilẹ igbagbọ wa, 1 Kọrinti 15:16, 17; Romu 4:25; 10:9
3. On ni ireti iye ainipẹkun fun wa, 1 Kọrinti 15:18, 19; 1 Tẹssalonika 4:14
III Eto Ajinde
1. Kristi ni akọbi, 1 Kọrinti 15:20-22; Ẹksodu 22:29; Lefitiku 23:10; Owe 3:9
2. Lẹyin naa, ikojọpọ awọn eniyan mimọ ni igba Ipalarada yoo tẹle e, 1 Kọrinti 15:23; 1 Tẹssalonika 4:16, 17
3. Kristi yoo pa ikú run ni ajinde ikẹyin, 1 Kọrinti 15:24-28; Ifihan 20:14
4. Paulu sọ asọye lati fi idi otitọ ajinde mulẹ, 1 Kọrinti 15:29-34
IV Bi Ajinde yoo ti ri
1. A fi ohun ti ara wé ohun ti ẹmi, 1 Kọrinti 15:35-50; 2 Kọrinti 5:1-4
2. Lọgan, ni iṣẹju, a o pa awọn onigbagbọ ti ó wà laaye lara dà, nigba bibọ Kristi, 1 Kọrinti 15:51-53; Filippi 3:20, 21
3. A o gbé ikú mì ni iṣẹgun, 1 Kọrinti 15:54-58; Ifihan 21:4
Notes
ALAYEGẹgẹ bi Iwe Mimọ
“Ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si?” Paulu waasu Ihinrere ajinde okúṣugbọn diẹ ninu awọn ara Kọrinti kò gba otitọ naa gbọ. Nitori eyi Paulu tun ṣe atunwi Ihinrere ti o n waasu, o si wi pe ṣaaju ohun gbogbo –eyi ni pe, ohun ti o ṣe pataki jù lọ ni pé Kristi kú fun è̩ṣẹ wa, a sin In, O si jinde ni ọjọ kẹta. Kò jé̩ gbagbe lati fi hàn pé Jesu kú fun è̩ṣẹ wa gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wi. Lai si aniani ẹsẹ Iwe Mimọ yii leke ọkàn rẹ ninu gbogbo awọn ẹsẹỌrọỌlọrun miiran ti o jẹ mọọran yii. “A ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rè̩, ati nipa ìna rè̩ li a fi mu wa lara da ... a ti ke e kuro ni ilẹ alāye: nitori irekọja awọn enia mi li a ṣe lù u. O si ṣe iboji rè̩ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ ni ikú rè̩” (Isaiah 53:5-9). Paulu tọka si i pẹlu pe Jesu jinde kuro ninu okú gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wi – “Nitori iwọ ki yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú; bḝni iwọ ki yio jẹ ki Ẹni Mimọ rẹ ki o ri idibajẹ” (Orin Dafidi 16:10).
Ẹlẹri Ojukoju
Ẹri miiran ti o fi idi ajinde mulẹ ni awọn wọnni ti o mọ Jeṣu ṣaaju ikú Rẹ ti wọn si tun ri I lẹyin ikú Rẹ --awọn eniyan bi Kefa, awọn ọmọ-ẹyin mejila, awọn ẹẹdẹgbẹta arakunrin ti wọn jumọ ri I, Jakọbu, ati gbogbo awọn Apọsteli. Gbogbo awọn wọnyi jé̩ẹlẹri ajinde Rè̩, a ha le fi ọwọ rọ gbogbo awọn ẹlẹri wọnyi tì? Paulu le sọ daju pe, Emi ri I! Bi o tilẹ jé̩ pé Paulu gba ẹri awọn ẹlomiran ti o ri Kristi gbọ, sibẹẹri pataki ti oun paapaa ni nipa ajinde ni pipadé ti o ba Olugbala rè̩ ti o jinde, pade. A le ṣalai ti i fi oju ara ri I, ẹri ti o ṣe pataki ju lọ ti a ni nipa Olugbala ni idaniloju ti a ni pe a ti dari è̩ṣẹ wa ji, Kristi si n jọba lọkàn wa. Igbagbọ wa kò já si asán nitori ti a mọ pé Kristi kú fun è̩ṣẹ wa, O si “jinde nitori idalare wa” (Romu 4:25).
Ireti Wa
Ireti gbogbo awọn eniyan mimọ lati ijimiji titi de igba ti ayé yoo pin rọ mọ ajinde okú. “Bi o ba ṣe pe ni kiki aiye yi nikan li awa ni ireti ninu Kristi, awa jasi òtoṣi jùlọ ninu gbogbo enia.” Jobu ni idaniloju pe a o ji ara oun dide, o si fé̩ ki o di mimọ gbangba nigba ti o sọ bayii pé: “A! Ibaṣepe a le kọwe ọrọ mi nisisiyi, ibaṣepe a le dà a sinu iwe! Ki a fi kalamu irin ati ti ojé kọ wọn sinu apata fun lailai. Ati emi, emi mọ pe Oludande mi mbẹ li āyè, ati pe on bi Ẹni-ikẹhin ni yio dide soke lori erupẹ ilẹ. Ati lẹhin igba awọ ara mi, ti a ti ke e kuro bi iru eyi, ati laili ẹran ara mi li emi o ri Ọlọrun, Ẹniti emi o ri fun ara mi, ti oju mi o si wò, ki si iṣe ti ẹlomiran; ọkàn mi si dáku ni inu mi” (Jobu 19:23-27).
Akọso
Labẹ Ofin, awọn Ọmọ Israẹli ni lati mú akọso ikore oko wọn wá gẹgẹ bi ọrẹ fun Oluwa. Ọlọrun ṣeleri pe bi wọn ba ṣe eyi, aká wọn yoo kún fún ọpọlọpọ. “Fi ohun ini rẹ bọwọ fun OLUWA, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: Bḝni aká rẹ yio kún fun ọpọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun” (Owe 3:9, 10). Akọso wọnyi ti wọn mú wá gẹgẹ bi ọrẹ fun Oluwa jé̩ apẹẹrẹ ikore ti n bọ nigbooṣe. Bayii ni Kristi di “akọbi ninu awọn ti o sùn” nigba ti O jinde kuro ninu okú. Oun ni Ẹni kin-in-ni ti O jinde kuro ninu okú pẹlu ara ologo. Oun ni akọbi – ileri tabi apẹẹrẹ awọn ara ti a o ji dide ti yoo jade wá lati inu iboji nigba bibọ Rè̩. Ireti Onigbagbọ nipa ajinde jé̩ ireti aaye, nitori ti a ti kó awọn akọso jọ na, dajudaju ikore n bọ wá.
Eto Ajinde
Ki i ṣe gbogbo okú ni yoo ji dide nigba ti Kristi bá gba awọn aṣẹgun soke kuro ninu aye yii, ṣaaju akoko ipọnju nla. “S̩ugbọn olukuluku eniyan ni ipa tirè̩: Kristi akọbi; lẹyin eyi ni awọn ti i ṣe ti Kristi ni bibọ rè̩.” O da bi ẹni pe a o ji awọn eniyan mimọ ti o kú ikú ajẹrikú nigba ipọnju nla dide nigba ifarahan Kristi (Ifihan 20:4). “Nigbana ni opin yio de ...” Lẹyin ti Kristi bá ti jọba ẹgbẹrun ọdun lori ilẹ aye yii, a o ji okú awọn ẹlẹṣẹ dide. “A si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn. Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rè̩ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn. Ati ikú ati ipo-okú li a si sọ sinu adagun iná” (Ifihan 20:12-14). Eyi ni opin ati olubori iṣẹgun Kristi lori ikú, ọta Kristi ikẹyin. Ni Ọrun titun ati ayé titun “ki yio si si ikú mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bḝni ki yio si irora mọ: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ” (Ifihan 21:4).
Iribọmi
Lati tubọ fi ẹsẹ alaye rè̩ nipa ẹkọ ajinde kuro ninu okú mulẹ, Paulu tọka si ọna ti a fi n baptisi awọn Onigbagbọ nipa iribọmi. Eyi jé̩ apẹẹrẹ pe a sin wá pọ pẹlu Kristi sinu ikú Rẹ a si ji wa dide pẹlu ni afarawe ajinde Rè̩. “Bi a ti sin nyin pọ pẹlu rè̩ ninu baptismu, ninu eyiti a si ti ji nyin dide pẹlu rè̩ nipa igbagbọ ninu iṣẹỌlọrun, ẹniti o ji i dide kuro ninu okú” (Kolosse 2:12). “Njẹ kili awọn ti a baptisi nitori okú yio ha ṣe, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde rara? nitori kili a ha ṣe mbaptisi wọn nitori okú?” Ibeere yii fi hàn pé aṣiṣe ni lati ri awọn eniyan bọmi ati lati gbé wọn dide ni afarawe ajinde bi o ba ṣe pe ajinde kò si. “Tabi ẹ kò mọ pe, gbogbo wa ti a ti baptisi sinu Kristi Jesu, a ti baptisi wa sinu ikú rè̩? Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ pẹlu rè̩: pe gẹgẹ bi a ti ji Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba, bḝni ki awa pẹlu ki o mā rin li ọtun ìwa. Nitori bi a ba ti so wa pọ pẹlu rè̩ nipa afarawe ikú rè̩, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rè̩” (Romu 6:3-5).
Ara Kikú ati Ara Aikú
A lè beere bayii pe, “Bawo li a o ha ji awọn okú dide? iru ara wo ni nwọn o pada si?” Lati dahun ibeere yii, Paulu fi hóro alikama ti a gbin sinu ilẹṣe apẹẹrẹ. Hóro alikama naa yoo kú, ṣugbọn lati inu rè̩ wá ni eehu miiran yoo gbé jade wá ti yoo so eso bi iru eyi ti a gbin sinu ilẹ. “Ọlọrun fun u li ara bi o ti wù u, ati fun olukuluku irú ara tirè̩.” “A gbin i ni idibajẹ; a si ji i dide li aidibajẹ.” Ireti yii ti lárinrin tó! Ara iyara yii ti a n sin ni ailera, ni idibajẹ ati ni ainiyin, ni a gbé dide ni ara ẹmi ni ogo, agbára, aidibajẹ ati ni aworan ara eniyan ṣugbọn o gbéẹwa ti ọrun wọ! Irora, aisan ati ailera kò lagbara lori rè̩ mọ gẹgẹ bi igba ti o wa ni ara kikú, ṣugbọn gẹgẹ bi ara aikú, kò mọ ibanujẹ mọ. Gbogbo awọn eweko ati ewebẹ ti o n hù jade lati inu ilẹ lẹyin igba ẹẹrun awọn lili ati ogunlọgọ itanna oloorun didun ati awọn eweko ti o tutu yọyọ ti o n hù jade lẹyin ti o dabi ẹni pe wọn ti kú nigba ti ohun gbogbo gbẹ, jé̩ apẹẹrẹ ti o fi hàn pé ni ọjọ ajinde, gbogbo awọn eniyan mimọ ti o ti sùn ni yoo ji dide ti wọn yoo si gbé ara aikú wọ.
A o Pa Awọn ti o wa Laaye Lara dà
Ohun ijinlẹ miiran ti Apọsteli naa tun ṣipaya ni pe ki i ṣe gbogbo awọn Onigbagbọ ni yoo lọ sinu iboji ni idibajẹṣugbọn awọn Onigbagbọ diẹ yoo wà laayè sibẹ ni ọjọ ologo nì ti Jesu “yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipèỌlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ jinde: Nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lāyè ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma” (1 Tẹssalonika 4:16, 17). Ni akoko yii, a o pa awọn Onigbagbọ aṣẹgun ti o wà laayè larada kuro ninu ara kikú yii, wọn yoo si gbé ara ti ẹmi tabi ara ologo wọ. “Nitorina ẹnyin ará mi olufẹẹ mā duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ mā pọ si i ni iṣẹ Oluwa nigbagbogbo, niwọn bi ẹnyin ti mọ pe iṣẹ nyin ki iṣe asan ninu Oluwa.”
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti o fi ṣe pataki fun wa pe Kristi jinde kuro ninu okú?
- Ki ni ẹri ti a ni pé Kristi jinde?
- Ki ni ohun ti o ṣe pataki ninu pipè Kristi ni akọbi ninu awọn ti o sùn?
- Ta ni ọtá Kristi ikẹyin ti a o parun?
- Lọna wo ni iribọmi fi jé̩ apẹẹrẹ ajinde?
- Ẹkọ wo ni a ri kọ nipa ajinde ninu horo alikama?
- Darukọ diẹ ninu awọn ẹlẹri ajinde.
- Ki ni yoo ṣẹlẹ si ara awọn wọnni ti a gbà soke ni akoko Ipalarada?
- Ta ni “Adamu ikẹyin”?
- Ki ni oró ikú?