2 Awọn Ọba 13:1-25; 14:9-16

Lesson 328 - Senior

Memory Verse
“Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹṣe e” (Oniwasu 9:10).
Cross References

I Jehoahasi, Ọba Israẹli

1 Jehoahasi jọba ọdun mẹtadinlogun lori Israẹli, o si ṣe buburu niwaju Oluwa, 2 Awọn Ọba 13:1-3

2 Ọlọrun gba Israẹli là kuro lọwọ awọn ara Siria nitori pe Jehoahasi wá iranwọỌlọrun, 2 Awọn Ọba 13:4-9

II Ijọba Jehoaṣi

1. Ijọba Jehoaṣi jọ ti baba rẹ nipa pe oun naa ṣe eyi ti o buru niwaju Oluwa, 2 Awọn Ọba 13:10-13

2. Eliṣa sọ fun Jehoaṣi pe Ọlọrun yoo gba Israẹli là kuro lọwọ awọn ara Siria, 2 Awọn Ọba 13:14-21

3. Ọlọrun gba Israẹli là nitori majẹmu Rè̩ pẹlu awọn baba wọn, 2 Awọn Ọba 13:22-25

4. Ogun wà laaarin Juda ati Israẹli, Israẹli si ṣẹgun, 2 Awọn Ọba 14:9-16

Notes
ALAYE

Ile ti o Yapa

Bi awọn ẹkọ Ile-ẹkọỌjọ Isinmi wa ti n mu wa lọ sinu ikẹkọọ ninu Iwe Awọn Ọba ati Kronika, a ni lati mọ pé kò si ohun kan ti kò nilaari ninu ỌrọỌlọrun. Ọlọrun n bá eto Rè̩ lọ lati iran kan de ekeji lai fi ti ète eniyan ti kò fé̩ ki eto Ọlọrun ṣẹ pè. Ọlọrun a maa mú ifẹ Rè̩ṣẹ nigba ti ọkàn eniyan ba yọnda lati ṣe ifẹ Rè̩ tabi nigba ti kò tilẹ yọnda lati ṣe e. Pupọ ninu ẹkọ wa ninu Iwe Awọn Ọba ati Kronika jé̩ akọsilẹ nipa awọn eniyan ti kò sin Ọlọrun, ti igbesi-ayé wọn buru, ṣugbọn ti wọn fara kọ eto igbalàỌlọrun lọna kan tabi lọna miiran.

Nipa akọsilẹ Iwe wọnyii, a mọ igba pupọ ti awọn Ọmọ Israẹli n pàfọ ninu iwa buburu ati è̩ṣẹ gẹgẹ bi orilẹ-ède ti o si jé̩ pé iba awọn oloootọ eniyan diẹ ni o mú ki isin otitọỌlọrun wa laayè. Ọlọrun ti fa ijọba apapọẹya Israẹli mejila ya si meji nitori ti wọn kọỌlọrun silẹ (Wo 1 Awọn Ọba 11:30-40). Awọn ẹya mẹwaa ninu ẹya mejila Israẹli ṣọtẹ si ijọba Rehoboamu ọmọ Sọlomọni. Nipa bayii ẹya Juda ati Bẹnjamini nikan pere ni o kù fun un lati maa jọba lé lori. Lati igba naa lọ ni Israẹli ti di ile ti o yapa si ara rẹ. Ni ọpọlọpọọdún lẹyin eyi, nigba ti Jesu wà layé, O kilọ fun Israẹli nipa ewu ti o wà ninu è̩ṣẹ dida ati ibi ti o wà ninu iyapa, ikorira ati owú laaarin ẹya kan si ekeji. O sọ bayii pé, “Ijọba ki ijọba ti o ba yapa si ara rè̩, a sọọ di ahoro; ilukilu tabi ilekile ti o ba yapa si ara rè̩ ki yio duro. Bi Satani ba si nlé Satani jade, o yàpa si ara rè̩; ijọba rè̩ yio ha ṣe le duro?” (Matteu 12:25, 26).

Gẹrẹ ti Israẹli ti di orilẹ-ède ni o ti jé̩ ipinnu Ọlọrun wi pe ki wọn ki o jé̩ imọlẹ fun awọn Keferi. Bi a ti n ka akọsilẹ ti a ti ọwọỌlọrun kọ nipa Israẹli, a ri i pe aanu Ọlọrun a maa dá awọn diẹ si nigba ti idajọ bá dé bá orilẹ-ède naa. Ọlọrun sọ ninu Iwe Jeremiah 30:11 wi pe, “Bi emi tilẹṣe ipari patapata ni gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi ti tu ọ ka si, sibẹ emi ki yio ṣe ọ pari patapata: ṣugbọn emi o ba ọ wi ni iwọn, emi ki o j rẹ lọwọ li alaijiya.” S̩ugbọn ileri ti Ọlọrun ṣe wi pe Oun ki yoo pa orilẹ-ède Israẹli run patapata kò fi hàn wi pe ọkàn kọọkan awọn Ju ni a o gbà là. Olukuluku ọkàn ni lati ronupiwada ki a le gbàá là. Ọlọrun fé̩ lo Israẹli gidigidi ninu èto igbalà Rè̩. Ọlọrun fé̩ ki Israẹli jé̩ alabaṣiṣẹpọ pẹlu Oun ninu iṣẹ irapada, nipa wiwaasu Ihinrere fun ayé iṣé̩ yii. Eredi rẹ ni eyi ti oore Ọlọrun fi pọ tobẹẹ lori Israẹli lati irandiran bi o tilẹ jé̩ pe wọn ni ikuna ati ifasẹyin pupọ kuro ninu isin Ọlọrun gẹgẹ bi orilẹ-ède.

Jehoahasi ati Jehoaṣi

Ninu Majẹmu Titun, ohun ti Ọlọrun n fé̩ lọwọ awọn alagbà Ijọ ati awọn miiran ti i ṣe alakoso ni pe ki wọn ki o ni ẹri rere. (Wo Filippi 4:8; 1 Timoteu 3:7). Ni akoko Jehoahasi ati Jehoaṣi, Ijọ ati ijọba ilu jé̩ọkan naa. Ọlọrun si n fé̩ ki awọn ọba Israẹli jé̩ apẹẹrẹ rere fun awọn eniyan ni pipa Ofin Mose mọ. S̩ugbọn o hàn gbangba pe wọn kòṣe bẹẹ. Ọrọ Jehoahasi ati Jehoaṣi da bi owe nì ti o sọ fun ni pe, “Ẹni ti o bi ni ni a n jọ.” ỌrọỌlọrun sọ ohun kan naa nipa awọn mejeeji. “On si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, o si tè̩le è̩ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israẹli ṣè̩: on kò si lọ kuro ninu rè̩” (2 Awọn Ọba 13:2, 11). Ootọ ni ỌrọỌlọrun, Ọrọ wọnyi ti Ẹmi Oluwa kọ silẹ tun fi idi rè̩ mulẹ: “Irira ni fun awọn ọba lati ṣe buburu: nitoripe nipa ododo li ati fi idi ité̩ kalẹ” (Owe 16:12).

Bi Ọlọrun ba ti fi Israẹli silẹ lati tè̩le ọna ara rè̩ ati awọn ọna ọba wọn, Israẹli i bá ti di itẹmọlẹ labẹẹsè̩Ọba Siria. Ẹsẹ kan ninu ẹkọ wa yii fi hàn gbangba bẹẹ, “S̩ugbọn Hasaeli ọba Siria ni Israẹli lara ni gbogbo ọjọ Jehoahasi.”

Majẹmu pẹlu Ọlọrun

Ohun afiyesi nla kan fara hàn ninu ẹsẹỌrọỌlọrun kan ninu ẹkọ wa yii ti o jé̩ ki o di mimọ fun ni, eredi pataki ti Ọlọrun fi n bá Israẹli lò bẹẹ bi o tilẹ jẹ pe wọn n dẹṣẹ si I. A kà bayii pe “OLUWA si ṣe oju-rere si wọn, o si ṣānu fun wọn, o si ṣe akiyesi wọn, nitoriti majẹmu rè̩ pẹlu Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu kò si fẹ run wọn, bḝni kò si ta wọn nù kuro niwaju rè̩ titi di isisiyi.”

Eredi rè̩ ti Ọlọrun fi n gba awọn Ọmọ Israẹli silẹ kuro lọwọ awọn ọtá wọn ni titori majẹmu nla Rè̩ ti O dá pẹlu awọn baba wọn. Ki i ṣe nitori awọn ọba wọn, nitori igbesi-ayé wọn buru jai. Ki i ṣe nitori ti pupọ ninu awọn eniyan orilẹ-ède naa, nitori ni apapọ, ipasẹọba wọn ni wọn n tẹle. Nitori awọn eniyan diẹ ti o jé̩ oloootọ -- awọn iba diẹ ti o ṣẹku ti wọn n pa ilana Ọlọrun mọ -- ati nitori majẹmu Rè̩, eyi ni o mú ki Ọlọrun gba Israẹli silẹ kuro lọwọ awọn ọta wọn.

Awọn ọmọỌlọrun tootọ mọ awọn nnkan wọnyi. Nigba kan ti Woli Isaiah n pohùnrere ẹkun fun è̩ṣẹ Israẹli, o sọ bayii pe “Bikòṣe bi OLUWA awọn ọmọ-ogun ti fi iyokù diẹ kiun silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, awa iba si ti dabi Gomorra” (Isaiah 1:9). Ni akoko miiran kan, bi woli Israẹli yii ti n sọ inu Ọlọrun, o tun sọ bayii pe: “Gẹgẹ bi a ti iri ọti-waini titun ninu idi eso àjara, ti a si nwipe, Máṣe bà a jẹ nitori ibukun mbẹ ninu rè̩: bḝli emi o ṣe nitori awọn iranṣẹ mi, ki emi ki o má ba pa gbogbo wọn run” (Isaiah 65:8).

Igba pupọ ni a kò le fé̩ kù ni igbesi-ayé awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ti o tilẹ buru ju ti o ṣe pe wọn n ke pe Ọlọrun. Pẹlu gbogbo bi Jehoahasi ti lo igbesi-ayé rẹ ni ilokìlo to nì, akoko kan wà ti o ke pe Ọlọrun, Ọlọrun si dahun adura rẹ (Wo 2 Awọn Ọba 13:4). O ṣeni laanu pe awọn eniyan buburu bi ti Jehoahasi ki i pẹ gbagbe irú adura ti a gba ni igba pajawiri bẹẹ. A ko ni akọsilẹ pé Jehoaṣi, ọmọ rè̩, ké pe Ọlọrun. S̩ugbọn o dabi ẹni pe Jehoaṣi ri iṣẹ agbára Ọlọrun ninu Eliṣa, ati pe aisan ati ikú Eliṣa jé̩ ohun ti o gún un lọkàn gidigidi.

A kò mọ bi ibalo ti o wà laaarin Eliṣa ati Jehoaṣi ti pọ tó. Kò daju pe o pọ to bẹẹ nitori Jehoaṣi jé̩ eniyan buburu ni gbogbo ọjọ ayé rè̩. O mọ Eliṣa daradara, o si daju pe oun ki yoo ṣalai maa bu ọla fun woli Ọlọrun yii. Lai si aniani, Eliṣa gbadura ni igba pupọ fun igbalàọkàn Jehoaṣi, ṣugbọn Jehoaṣi kò yi pada. O lè jé̩ péọkàn Jehoaṣi kò balẹ nipa ohun ti o le de ba oun ni ọjọ iwaju nigba ti adura ti Eliṣa n gba fún un ba dẹkun. Ohun ti o wọpọ ni lati ri awon ẹlẹṣẹ ti o mọ riri ti wọn si n ṣafẹri adura awọn eniyan Ọlọrun bi o tilẹ jẹ pe awọn paapaa kò fẹ lati sin Ọlọrun.

Bi Eliṣa ti sọ fun Jehoaṣi pe Ọlọrun yoo pa awọn ara Siria run, a sọ fun un pe ki o ta ọfà kan o si ṣe bẹẹ. Eliṣa sọ fun un pe, eyi ni ọfà igbalà kuro lọwọ awọn ara Siria. S̩ugbọn nigba ti a sọ fun un pe ki o ta ọfà naa silẹ, o ta a silẹ nigba mẹta pere. Eliṣa binu si i nitori pe o ta ọfà na silẹ ni ẹmẹta pere, nipa bayii a fun un ni anfaani lati ṣẹgun awọn ara Siria ni igba mẹta dipo igba pupọ.

Aini itara Jehoaṣi lati ta ọfà igbalàỌlọrun si ilẹ buru pupọ. Ero wa ni pe oun yoo korira awọn ọta rẹ to bẹẹ ti eyi yoo fi fara hàn ninu iwa ati itara rẹ. A le fi aini itara rẹ yii wé awọn ti n fi ilọwọwọ beere nnkan lọdọỌlọrun. Wọn le gbadura nigba pupọ, ṣugbọn wọn ki i pẹ rẹwẹsi. IfẹỌlọrun ni pe ki gbogbo awọn ti n tọ Oun wá ki wọn wá pẹlu igbona ọkàn. Awọn ẹni ti o ba farabalẹ wa A nikan ni yoo ri gba lọwọỌlọrun. Aabọ iṣẹgun ni yoo jé̩ ti wa gẹgẹ bi ti Jehoaṣi, bi a kò ba fi gbogbo ọkàn mu ibeere wa lọ siwaju Oluwa.

Bakan naa, iṣẹ-isin ti a kòṣe tọkantọkan kò le fun wa ni iṣẹgun nipa ti Ọlọrun. Iṣẹ wa ni laye lati pa ọkan wa mọ “jù gbogbo ohun ipamọ” ati lati ran awọn ẹlẹgbẹ wa lọwọ. Yala ninu iṣẹ-isin orin kikọ tabi lilo ohun-elo orin, ninu adura è̩bẹ fun alaafia awọn ẹlomiran, tabi nipa wiwaasu Ọrọ naa tabi riran awọn alaisan tabi awọn alaini lọwọ, tabi ohunkohun ti o wù ki o jé̩ a maa “fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa” (Kolosse 3:23). Ọlọrun rán Ọrọ Rè̩ lati ẹnu Jeremiah pe “Ifibu li ẹniti o ṣe iṣẹ Oluwa ni imẹlẹ.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. IrúỌba wo ni Jehoahasi ati Jehoaṣi i ṣe?
  2. Ki ni ṣe ti a fi pin Israẹli si ipa meji?
  3. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi ran Israẹli lọwọ lati bá awọn ara Siria jà?
  4. Bawo ni a ṣe mọ pé Jehoahasi gbadura si Ọlọrun rára?
  5. Njẹ Jehoaṣi gba Ọlọrun gbọ?
  6. Ki ni ṣe ti inu Jehoaṣi fi bajẹ nigba ti Eliṣa ṣe aisan dé oju ikú?
  7. Njẹ o rò pé Jehoaṣi fé̩ Eliṣa kù lẹyin ikú rè̩? Ki ni ṣe?
  8. Njẹ iwọ rò pé Jehoahasi tabi Jehoaṣi ni iye ainipẹkun? Ki ni ṣe?