Lesson 329 - Senior
Memory Verse
“Nitori asọtẹlẹkan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia mimọỌlọrun nsọrọ lati ọdọỌlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọẸmi Mimọ wá” (2 Peteru 1:21).Cross References
I A Pe e kuro lẹnu Iṣẹ oojọ rè̩
1. Amosi jé̩ darandaran ni Tekoa ati ẹni ti n ká eso ọpọtọ, Amosi 7:14; 1:1
2. Ibẹrẹ igbesi-ayé rẹ jẹ iru eyi ti o ri mu lo lati fi ṣe apejuwe daradara ninu awọn asọtẹlẹ rè̩, Amosi 2:13; 3:8, 12; 6:1
3. Amosi ka a kun ohun pataki lati jé̩ ipèỌlọrun, Amosi 3:8; 7:15
II Aṣẹ ti a fi fun Amosi ati Iṣẹ-iranṣẹ r
1. “Bayi li OLUWA wi” ati ọrọ bawọnni fara hàn ni igba ogoji ninu iwe yii, Amosi 1:3, 6, 9; 3:11 ati bẹẹ bẹẹ lọ
2. A rán ọrọ idajọ ti n bọ wá si awọn orilẹ-ède ti o wà yika, Amosi 1:3-15; 2:1-3
3. A rán Ọrọ Oluwa lati kọjuja si Juda, Amosi 2:4, 5
4. Pupọ ninu ọrọ Amosi ni a rán si Israẹli, Amosi 2:6-16; 3:1-15; 4:1-13; 6:7-14
5. Ọlọrun pe awọn Ọmọ Israẹli si ironupiwada tootọ, Amosi 5:1-27
6. Amosi ké rara mọè̩ṣẹ ati imọ-ti-ara-ẹni-nikan, Amosi 6:1-6; 8:4-6
III Adura-è̩bẹ ati Inunibini
1. Nipa adura Amosi, pupọ ninu idajọ ti Ọlọrun n mú bọ ni a dá duro, Amosi 7:1-9
2. Amasiah ṣe inunibini si Amosi, o fi sun ẹsun pe o ditè̩, o si gbiyanju lati le e kuro ni ilẹ Israẹli, Amosi 7:10-13
3. IdajọỌlọrun sọkalẹ sori Amasiah, Amosi 7:16, 17
4. Ipari ọrọ Amosi sọ ti otitọ isọdahoro Israẹli, Amosi 8:1-3, 7-14; 9:1-10
5. Ọlọrun ṣe ileri ti o kún fún imọlẹ ati ireti, Amosi 9:11-15
Notes
ALAYEKoṣee-mani Wolii
Ijọba Jeroboamu, ọmọ Joaṣi (ti a saba maa n pe ni Jehoaṣi), ọba Israẹli kún fun ọpọlọpọ iṣẹgun ninu ogun, ṣugbọn ijọba yii kún fun iwa ibajẹ ti o tubọ gbilẹ si i. A ti gba ilẹ pupọ pada fun awọn Ọmọ Israẹli, nipa agbára ogun jija ọba yii; lai si aniani, ọpọlọpọ ikogun ati ọrọ ni wọn ti ni nipa iṣẹgun wọnyi, to bẹẹ ti awọn Ọmọ Israẹli di ọlọrọ, ọlẹ ati ẹni ti igbesi-ayé rè̩ kún fun è̩ṣẹ. Awọn woli Ọlọrun ké rara nipa iwa è̩ṣẹ wọnyi, ṣugbọn o hàn gbangba pé awọn Ọmọ Israẹli kò bikita. Awọn eniyan naa tilẹ sa gbogbo ipa wọn lati pa awọn iranṣẹỌlọrun lẹnu mọ (Amosi 2:11, 12).
Jesu wi pe, “Kò si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu ati ni ile on tikararè̩” (Matteu 13:57). Njẹ awọn ara Samaria ati awọn Ọmọ Israẹli yoo gbọ bi wolii ti o ti ilu miiran wa ju ti awọn woli ti a ti ran si wọn lọ? Ọlọrun rán Amosi, oluṣọ-agutan lati Tekoa, ati lati inu ẹya Juda gẹgẹ bi ojiṣẹỌlọrun si awọn alaiwa-bi-Ọlọrun wọnyi. Ohùn Amosi ti o kún fun ipá ati agbára Ẹmi Ọlọrun, n dún bi agogo bi o ti n ké rara nipa iwa buburu ti awọn Ọmọ Israẹli n hù. ỌrọỌlọrun jade si awọn orilẹ-ède ti o yi Israẹli ka pẹlu. S̩ugbọn awọn Ọmọ Israẹli ni asọtẹlẹ yii doju kọ gidi. Ọkàn oluṣọ-agutan yii gbina o si gbọgbẹ nitori ifasẹyin ti o ri laaarin awọn eniyan ti wọn ti n sin Ọlọrun Ọrun nigba kan ri.
Kò si Awawi
Ọlọrun ṣe rere fun Israẹli, O si mu suuru fun wọn lọpọlọpọ: “Ẹnyin nikan ni mo mọ ninu gbogbo idile aiye” (Amosi 3:2). Ọlọrun mú awọn eniyan wọnyi jade kuro ni oko-ẹrú Egipti, O si mu wọn la aginju já ni ogoji ọdun, ki O ba le mu wọn wa si Ilẹ Ileri. Ọlọrun pa awọn Amori run niwaju wọn. O sọ bayi pe, “giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rè̩ run lati oke wá, ati egbò rè̩ lati isalẹ wá” (Amosi 2:9).
Ọlọrun bukun awọn eniyan wọnyi lọpọlọpọ; ibukun ni ilu wọn ati ni oko wọn, ibukun ohun ọgbin ati ibisi malu, ibukun agbọn ati àká, ṣugbọn lori gbogbo ibukun wọnyi, awọn Ọmọ Israẹli bẹrẹ si dáè̩ṣẹ buburu ni adale-adale eyi ti o tabuku si orukọ mimọỌlọrun ti o si n rú ibinu Rè̩ soke.
Ipo è̩ṣẹ ti awọn Ọmọ Israẹli wà tubọ buru si i nitori pe wọn tun n jẹwọ pe awọn n sin Ọlọrun; ṣugbọn Ọlọrun wi pe: “Ẹni meji lè rìn pọ, bikòṣepe nwọn ré̩?” (Amosi 3:3). Awọn Ọmọ Israẹli ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun ṣugbọn wọn kọ lati fi gbogbo ọlá fun Ọlọrun Baba wọn, wọn si du U ni isin ti o tọ si I. Ọlọrun pa a laṣẹ pe: “Iwọ kò gbọdọ li ọlọrun miran pẹlu mi. Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, ... Iwọ kò gbọdọ tè̩ ori ara rẹ ba fun wọn, bḝni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi” (Ẹksodu 20:3-5). Awọn ère wura ati pẹpẹ ti awọn Ọmọ Israẹli gbé kalẹ ni Bẹtẹli ati Dani jé̩è̩gan ati iwa ti o buru jai si isìn Ọlọrun otitọ ti o wà ni Jerusalẹmu. Wọn n rubọ ojoojumọ -- pẹlu iwukara aiyẹ; wọn n mu idamẹwaa ati ọrẹ atinuwa wọn wa si ibi pẹpẹ alaimọ pẹlu ariwo; ṣugbọn Ọlọrun kò kà a si.
Ọna iwa mimọ ni o lọ si Ọrun taara, ṣugbọn ọna ti o lodi si eyi ni awọn Ọmọ Israẹli n gbà. Oriṣiriṣi ipọnju ni Ọlọrun rán si awọn Ọmọ Israẹli lati mu ki wọn ronu piwada ṣugbọn wọn kọ lati yi pada. Iṣẹ ti o n jẹ fun awọn eniyan wọnyi jé̩ọran ẹdun lọkàn Amosi. Gẹgẹ bi o ti n sọ asọtẹlẹ ifasẹyin awọn eniyan wọnyi kuro lọdọỌlọrun ati idajọ ti yoo tẹle e, ọrọ wọnyi jade si wọn pẹlu igbona ọkàn: “Nitorina, bayi li emi o ṣe si ọ, iwọ Israẹli: ati nitoriti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ, iwọ Israẹli” (Amosi 4:12).
Akoko ti o ga
Iṣẹ kan naa ti Ọlọrun ti ẹnu Amosi rán si awọn Ọmọ Israẹli ni Ọlọrun n rán si ayé loni. Ni akoko Oore-ọfẹ yii, ibalo Ọlọrun kò pin si ọdọ orilẹ-ède kan, ṣugbọn Ọlọrun n ba gbogbo eniyan ti o wà laye lò. “Nitori ore-ọfẹỌlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan, O nkọ wa pe, ki a sé̩ aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mā wà li airekọja, li ododo, ati ni iwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi” (Titu 2:11, 12). Ọlọrun rọòjo ibukun sori eniyan gbogbo, akanṣe ibukun ti o tayọ gbogbo ibukun ni Ọmọ Rè̩ ti O fi ta ayé lọrẹ. “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobḝ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rè̩ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ má bàṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun” (Johannu 3:16).
Njẹ awọn ọmọ-eniyan tẹwọ gba è̩bun Ọlọrun ti o tobi julọ yii ki wọn si karamasiki rè̩? Rara o. Ni apapọ, awọn eniyan kọ Jesu Oluwa. NjẹỌlọrun jẹ oloootọ si awọn eniyan ati orilẹ-ède ninu ibalo rẹ bi o tilẹ jé̩ pé wọn kọỌ ati Ẹbun Rè̩ iyebiye? Bẹẹni. Fun nnkan bi ẹgbaa ọdun, ni oriṣiriṣi ọkẹ aimoye ọna ni Ọlọrun gbà n bá awọn ọmọ eniyan jiròrò ti O si n sa ipa Rè̩ lati yi wọn lọkàn pada kuro ninu è̩ṣẹ ati lati fi ojuṣe wọn hàn wọn. Ọlọrun yoo ha dá awọn eniyan wọnyi ti o kọ Kristi silẹ lare? Agbẹdọ! È̩bi olukuluku ẹni ti o kọỌlugbala yoo sọọ di odi niwaju itẹ idajọỌlọrun fun ainaani rè̩. Ki Ọlọrun ma ṣalai jé̩ ki olukuluku eniyan yi pada si Olugbala nigba ti O n fi aanu bẹbẹ wi pe “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣíṣẹ, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin. Ẹ gbààjaga mi si ọrùn nyin, ki ẹ si mā kọẹkọ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Nitori àjaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ” (Matteu 11:28-30).
Ọna Ọlọrun
Nigba miiran, awọn eniyan a maa fa tìkọ lati fi iṣẹ oojọ wọn silẹ lati jé̩ ipè giga Ọlọrun, nitori pe wọn ka ara wọn si alaiyẹ fun ipe ti o ga bẹẹ; ṣugbọn bi o ba jẹ pe ni tootọ ni a ri ipèỌlọrun gbà, a kò gbọdọ bè̩ru. Amosi jé̩ẹni ti o rẹlẹ gẹgẹ bi oluṣọ-agutan, ṣugbọn Ọlọrun lo ọgbọn ati iriri ti Amosi ri nibi ti o ti n da ẹran lati jé̩ apẹẹrẹ nlanlà fun iṣẹ ti o n jé̩ fún Israẹli. “Kiniun yio ké ramùramù ninu igbo, bi kò ni ohun ọdẹ? ... Kiniun ti ké ramùramù, tani ki yio bè̩ru? Oluwa Ọlọrun ti sọrọ, tani lèṣe aisọtẹlẹ?” (Amosi 3:4, 8). Amosi kòṣalai ti ni iriri bi kiniun ṣe n gbé agutan nigba ti o n ṣọ agbo agutan rè̩ ni papa, o si mọ pe kiniun ki i bú a fi igba ti o ba gbaradi lati sare lọ fa ohun ọdẹ rè̩ ya pẹrẹpẹrẹ. Agbo ti Amosi n tọju nisisiyii yatọ -- awọn agutan Israẹli. O gbọ ohùn titun ti idajọ -- ani ohùn Ọlọrun. Bi agbo agutan kò ba ni ṣegbe, o di dandan lati mu ohun kan ṣe ni kiakia. Amosi si mọ pe iṣẹ ti oun gbọdọṣe ni lati kilọ fun agbo naa ati lati sa ipa oun lati gbà wọn kuro ninu ibinu Ọlọrun.
Bakan naa ni Ọlọrun le lo ẹnikẹni ti o ba jẹ ipè Rẹ ni kikun, iṣẹkiṣẹ ti o wu ki o ti maa ṣe. Gbogbo Onigbagbọ atunbi ni o ni ifẹ lati tan Ihinrere igbala kalẹ, yala o le fi gbogbo akoko rẹṣe e, tabi bẹẹkọ. Igbesi-ayéẹnikẹni ti o jẹwọ pe oun mọ Olugbala ti o si n sin Olugbala ti a ji dide jé̩ iwe ti a n kà, gbogbo iṣẹ ati iwa rè̩ ni awọn araye n kà bi iwe. Ohunkohun ti wọn ba ri kà ni igbesi-ayé awọn Onigbagbọ afẹnujẹ ni awọn ẹlẹṣẹ i maa sába fi ṣe odiwọn gbogbo Igbagbọ, dipo ỌrọỌlọrun. “Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobḝ niwaju enia, ki nwọn ki o le mā ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yin Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo” (Matteu 5:16).
Amosi ṣe ohun pataki kan ninu iṣẹ-iranṣẹ rè̩ ti awọn woli ode oni n gboju fò dá. Amosi jé̩ iṣẹ ti Ọlọrun rán an, o si n gbé igbesi-ayé ti o ṣe deedee pẹlu ỌrọỌlọrun. Ninu iwe kekere yii, ogoji igbà ni a ka a wi pe, “Bayi li OLUWA wi,” tabi awọn ọrọ miiran ti o fara jọ eyi. Amosi kò bẹru lati ké mọè̩ṣẹ nitori ti o mọ agbara Ọlọrun ti n gba ni là ti o si le pa ni mọ kuro ninu è̩ṣẹ. Nigba ti Amosi kigbe wi pe, “Egbe ni fun ẹniti ara rọ ni Sioni, ati awọn ti o gbẹkè̩le oke nla Samaria” (Amosi 6:1), a kò le ri Amosi ki o joko lati jẹ faaji ayé ati è̩ṣẹ, bẹẹni Amosi kò si ni igbẹkẹle ninu ara. Iṣẹ ti Ọlọrun rán wọ Amosi lọkàn titi dé ookan àyà rè̩, to bẹẹ ti kò le fi ojurere wo ẹnikẹni ti kò tara ṣaṣa lati ronu piwada lẹyin ti o ti gbọ pé idajọỌlọrun n bọ wá. Gbogbo Onigbagbọ tootọ ni o gbọdọ ni irú itara kan naa ti Amosi ni fun Israẹli fun awọn ọkàn ti n ṣegbe.
Inunibini
Iru iduro ti o ga bayii kò le ṣalai fa iyọṣuti si ati inunibini. Lai pẹ wọn bẹrẹ si ṣe inunibini si Amosi. Amasiah alufaa ranṣẹ si ọba Israẹli wi pe, Amosi n ditẹ si ọba ati pe ilẹ naa kò lè gba gbogbo ọrọ Amosi mọ. Alufaa naa gba Amosi niyanju lati salọ kuro ni Israẹli ki o si lọ si Juda lati maa sọtẹlẹ nibẹ bi o ba fẹ sọtẹlẹ. Amosi jé̩ onirẹlẹ (eyi pẹlu jé̩ọkan ninu iwa rere ti iranṣẹỌlọrun tootọ gbọdọ ni). Amosi kò lọra lati sọ fun Amasiah pe oun ki i ṣe woli tẹlẹ ki o to di igbà ti Oluwa pe oun kuro nibi iṣẹ oluṣọ-agutan ti o si rán oun si awọn Ọmọ Israẹli. Gbogbo ihalẹ Amasiah kò le dá iṣẹỌlọrun duro. Ọlọrun pa ète buburu Amasiah ti si è̩gbé̩ kan, O si ti ẹnu woli Rẹ sọ wi pe ibi yoo wa sori èké alufaa alaiwa-bi-Ọlọrun yii. Amasiah i ba ṣe rere bi o bá fara balẹ tẹti lelẹ ti o si tẹle ọrọ woli yii dipo ti o fi n wáọna lati lé woli naa lọ.
Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe, “Ko le ṣe ki ohun ikọsè̩ má de: ṣugbọn egbé ni fun ẹniti o ti ipasẹ rè̩ de. Iba san fun u ki a so ọlọ nla mọọ li ọrùn, ki a si gbé e jù sinu okun, ju ki o mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi kọsè̩” (Luku 17:1, 2). Inunibini kò dá Ijọ tootọ lọwọ kọ ri, kaka bẹẹ a maa sọọ di alagbara ninu Oluwa ati ninu igbagbọ.
Ifẹ Tootọ
Amosi ni ifẹ atọkànwa si awọn ti n ṣe iṣẹ iranṣẹ fún, eyi si fara hàn gbangba nipa ọna ti o gbà n fi taratara ké mọ iwa anikànjọpọn, ọlẹ, ibọriṣa, ati iwa è̩ṣẹ miiran ti wọn n hù. Ẹwè̩, o tó igba meji ti Oluwa fi iparun nla ti n bọ wá sori awọn Ọmọ Israẹli hàn Amosi ninu iran, ṣugbọn nipa adura è̩bẹ rè̩, Ọlọrun dawọ idajọ naa duro.
Bakan naa ni ayé ode-oni n fẹ adura gidigidi. IdajọỌlọrun rọ dè̩dẹ sori ọmọ araye bi òjo ti o ṣú dùdù loju ọrun. Adura awọn eniyan Ọlọrun ni o duro bi odi ti kò ti i jé̩ ki idajọỌlọrun sọkalẹ sori ayé yii ni kikun. S̩ugbọn ni ọjọ kan, a o mú ohun idena yii kuro, a o si da ibinu gbigbona Ọlọrun sori ilẹ ni ẹkunrẹrẹ. Oluwa ti pe araye lati yi pada si Oun, ṣugbọn wọn kọ lati yi pada. O tun n sọ ohun kan naa ti O sọ fun Israẹli fun awọn orilẹ-ède loni pẹlu. Nitori naa, bayi li emi o ṣe si ọ, ẹyin orilẹ-ède ati nitori ti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ.
Questions
AWỌN IBEERE- Lati inu è̩ya wo ni Amosi ti jade wa?
- Ki ni iṣẹ ti Amosi n ṣe ki Oluwa to pèé lati maa sọtẹlẹ?
- Ki ni ṣe ti è̩ṣẹ awọn Ọmọ Israẹli fi buru jai to bẹẹ niwaju Ọlọrun?
- Ki ni awọn ohun ti Amosi fi ṣe apẹẹrẹ ninu asọtẹlẹ rè̩?
- Ki ni ọrọ ti Amosi sọ fun awọn Ọmọ Israẹli duro le lori?
- Ọna wo ni Amosi gbà lati yi diẹ ninu idajọỌlọrun kuro lori ilẹ Israẹli?
- Ki ni ṣe ti wọn fi ṣe inunibini si Wolii Amosi ni ilẹ Israẹli?
- Iru ihà wo ni Amosi kọ si inunibini lati ọdọ Amasiah?
- Ki ni Oluwa sọ nipa awọn ti “ara rọ ni Sioni”?