Mika 1:1-6; 2:1, 2, 8-11; 3:9-12; 4:1-13; 5:2; 6:1-8; 7:18-20

Lesson 330 - Senior

Memory Verse
“A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti OLUWA bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹānu, ati ki o rìn ni irè̩lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?” (Mika 6:8).
Cross References

I Ọlọrun bá Israẹli Wijọ

1. O sọ ti idajọ Rè̩, Mika 1:1-6

2. A kà iye è̩ṣẹ awọn eniyan naa, Mika 2:1, 2, 8-11

3. Ati wolii, ati alufaa, ati olori ni è̩sùn lati ọdọỌlọrun, Mika 3:9-12; Jeremiah 6:13, 14; Isaiah 1:23; Titu 1:10

II Iṣipaya awọn Eto Ọlọrun

1. A ṣe ileri Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, Mika 4:1-8; Isaiah 11:1-10; 35:1-10; Ifihan 20:1-4

2. A sọ asọtẹlẹ nipa ikolọ Juda si ilẹ igbekun ati iparun ti yoo dé bá awọn ọta Sioni, Mika 4:9-13

3. A o bi Ọba kan ni Bẹtlẹhẹmu, Mika 5:2; Matteu 2:5, 6

III Ipè si Ironupiwada

1. Ọlọrun n rọ Israẹli, Mika 6:1-8; Isaiah 1:18

2. O ni inudidun si aanu, Mika 7:18-20; Orin Dafidi 103:8-18

Notes
ALAYE

Ironupiwada

Nigba ti awọn alufaa ati awọn wolii èké gbimọ pọ lati pa Jeremiah nitori ti o sọ asọtẹle iparun Jerusalẹmu, awọn alagba diẹ dide fun iranlọwọ Jeremiah nipa titọka si asọtẹlẹ Mika ti o farajọ asọtẹlẹ Jeremiah. “Bayi li OLUWA awọn ọmọ-ogun wi: a o tulẹ Sioni fun oko, Jerusalẹmu yio di òkiti alapa, ati oke ile yi gẹgẹ bi ibi giga igbo.” Awọn alagba si beere pe: “Njẹ, Hesekiah, ọba Juda, ati gbogbo Juda ha pa a bi? È̩ru OLUWA kò ha bà a, kò ha bẹ OLUWA bi? OLUWA si yi ọkàn pada niti ibi ti o ti sọ si wọn?” (Jeremiah 26:18, 19).

Igba meloo ni Ọlọrun ti dawọ idajọ Rè̩ duro nigba ti awọn eniyan bá ronu piwada è̩ṣẹ wọn ti wọn si gbọkàn wọn soke si I! Nigba ti awọn eniyan buburu Ninefe ronu piwada Ọlọrun dá ilu wọn si. Bi o ti wù ki è̩ṣẹ eniyan didò tó, aanu Ọlọrun pọ tó bé̩è̩ ti yoo fi gbà a là bi o ba le ronu piwada è̩ṣẹ rè̩. Nigbakuugba ni Israẹli maa n mu Ọlọrun binu; ṣugbọn ninu ipọnju wọn bi wọn bá ké pe Ọlọrun, Oun a maa ṣaanu fun wọn. IdajọỌlọrun n rọ dè̩dè̩ lori ẹlẹṣẹ lọjọ oni, ṣugbọn a n fi aanu lọ awọn ti yoo bá ronu piwada è̩ṣẹ wọn ki o tó pé̩ jù.

A Kede Idajọ

Mika kede idajọ gbigbona Ọlọrun nitori è̩ṣẹ; o wi pé: “OLUWA jade lati ipò rè̩ wá, yio si sọkalẹ, yio si tè̩ awọn ibi giga aiye mọlẹ” (Mika 1:3). O tun tẹnu mọọ ni ọna ti o le yé ni nigba ti o tun sọ bayii pe: “Nitori irekọja Jakọbu ni gbogbo eyi, ati nitori è̩ṣẹ ile Israẹli. Kini irekọja Jakọbu? Samaria ha kọ? ki si ni awọn ibi giga Juda? Jerusalẹmu ha kọ?” Awọn olu-ilu orilẹ-ede yii ni ibi ti è̩ṣẹ ati ibọriṣa gbé gbilẹ si gidigidi. Awọn onigboya wolii Ọlọrun kò dẹkun nigba kan ri lati kede péè̩ṣẹ kò dara, bakan naa ni wọn kò kuna lati tọka si ibi ti ẹbi wa. Samuẹli bá Saulu wi, Elijah fi hàn pé Ahabu ni ẹni ti n yọ Israẹli lẹnu; nigba ti Dafidi dẹṣẹ, Natani wa nibẹ lati sọ fun un pe, “Iwọ li ọkunrin na.” Iwa buburu laaarin olu-ilu tabi laaarin awọn ẹni giga kò pamọ kuro loju Ọlọrun, bẹẹni ọmọde ti n dẹṣẹ ki yoo lọ laijiyà. Awọn ẹni ti n fi ojukòkoro gba ilè̩, ti n le alaini kuro ninu ile awọn baba rẹ, ti o si n le awọn obinrin ati awọn ọmọ wọn jade kuro ninu ile wọn; awọn ọmọ-ogun ti n fi agbara gba aṣọ awọn alaiṣẹ; awọn alufaa ti n ṣiṣẹỌlọrun nitori owó-ọyà; awọn wolii ti n sọtẹlẹ nitori owó -- gbogbo awọn wọnyi ni wolii naa mé̩nukàn, idajọỌlọrun kò si jinna si wọn. Bẹẹni awọn ọmọ-alade ti o ṣá idajọ tì, ti wọn si n ṣe ojusaju, ki yoo lọ laijiya.

Ipò Kan naa

Nitori iwa ẹṣẹ wọnyi, Samaria yoo di “òkiti”, a o “ṣe ro Sioni bi oko.” “Ẹ dide, ki ẹ si ma lọ; nitoripe eyi ki iṣe ibi isimi ... nitori nisisiyi ni iwọ o jade lọ kuro ninu ilu, iwọ o si ma gbe inu igbé̩, iwọ o si lọ si Babiloni” (Mika 2:10; 4:10). Bi o tilẹ jé̩ pé Babiloni kò ti i di alagbara, ti wọn kò si ni àyè ti Juda le fi mikàn nipa wọn, nipa imisi Ọlọrun, Mika sọ asọtẹlẹ wi pe a o kó wọn lẹru lọ si Babiloni ati Assiria. Ojukokoro, ibajẹ ati iwa ipá ti o mú idajọ wá sori Israẹli, kò yatọ si ohun ti n ṣẹlẹ laaarin ilẹ wa lọjọ oni. Awa o ṣe là bi awa ko ba naani etutu ti Ọlọrun ṣe lati mu è̩ṣẹ kuro? Gẹgẹ bi awọn Assiria ti sọ Samaria di ilẹ ti awọn ara Babiloni si pa Jerusalẹmu run, bakan naa ni ibinu Ọlọrun yoo sọ ilẹ wa yii di ahoro bi kòṣe pe awa, gẹgẹ bi orilẹ-ède bá ronu piwada iwa buburu wa.

Ipọnju ati Imubọ Sipo

Bi o tilẹ jé̩ pé Mika sọrọ pupọ nipa è̩ṣẹ ati idajọ, sibẹ asọtẹlẹ rè̩ kún fún ipè si ironu piwada ati ileri imubọ sipo. O sọ nipa ìgbà ti a o gba “ọmọbirin Sioni” kuro lọwọ awọn ara Babiloni, o si wi pe, “Nibè̩ ni Oluwa yio ràọ padà kuro lọwọ awọn ọta rẹ” (Mika 4:10). Awọn asọtẹlẹ rè̩ tayọìgbà ti wọn yoo pada bọ lati oko ẹrú lẹyin aadọrin ọdun, ani o tilẹ sọ nipa ọjọ iwaju nigba ti awọn orilẹ-ède yoo kó ara wọn jọ pọ si Sioni lati pa a run. “S̩ugbọn nwọn kò mọ erò OLUWA, bḝni oye imọ rè̩ kò ye wọn: nitori on o kó wọn jọ bi ití sinu ipaka” (Mika 4:12). Ninu asọtẹlẹ yii, Oluwa mú Sioni lọkan le: “Dide, si ma pakà, Iwọọmọbirin Sioni: nitori emi o sọ iwo rẹ di irin, emi o si sọ patakò rẹ di idẹ, iwọ o si run ọpọlọpọ enia womwom: emi o si yáère wọn sọtọ fun OLUWA, ati ini wọn si OLUWA gbogbo aiye” (Mika 4:13).

Apẹẹrẹ dída iti ọka sori ilẹ ipakà nigbaanì lati jé̩ ki awọn ẹranko fi patakòẹsẹ wọn tẹẹ mọlẹ lati yọ horo inu rè̩, n tọka si ọjọ wọnni ni igba ti Ipọnju Nla bá lọ sopin, nigba ti Ọlọrun yoo “kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifoji Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibè̩ nitori awọn enia mi, ati nitori Israẹli ini mi, ti nwọn ti fọn ka sārin awọn orilè̩-ede, nwọn si ti pin ilẹ mi” (Joẹli 3:2). Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa, pẹlu aṣọ ti a tè̩ bọ inu è̩jẹ, yoo maa gẹṣin lọ pẹlu awọn ogun Ọrun lori ẹṣin funfun, a o si pa awọn ọta Sioni run. (Wo Ifihan 19:14-21). Nipa gbigbe igbesi-ayé Onigbagbọ aṣẹgun lọjọ oni, iwọ le jé̩ọkan ninu awọn ọmọ-ogun ti a o wọ ni aṣọ funfun ti yoo si maa gun ẹṣin tẹle E lẹyin.

Ẹgbẹrun Ọdun

Iwọ le ni ipin ninu ijọba nì nigba ti Sioni yoo jé̩ olu-ilu gbogbo agbayé fun ẹgbẹrun ọdún bi iwọ ba le fi gbogbo ọkàn rẹ sin Ọlọrun ni ayé yii. Kò si ifarada tabi wahala isisiyii ti a le fi ṣe akawe igbadun ti yoo jé̩ tirẹ ni ọjọ wọnni nigba ti Oluwa yoo “ṣe idajọ lārin ọpọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọọbẹ-plau, ati ọkọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède ki yio gbe idà soke si orilẹ-ède, bḝni nwọn ki yio kọ ogun jijà mọ” (Mika 4:3). Eyi ni akoko naa ti “gbogbo ẹda jumọ nkerora” fún (Romu 8:22), akoko ti “oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi” (Isaiah 35:5), ti “ijù yio yọ, yio si tanna bi lili” (Isaiah 35:1). Iwọ ha n mura silẹ lati ni ipin ninu ijọba nì?

Bẹtlẹhẹmu

Mika sọ nipa ibi ti a o gbe bi Alakoso nla yii: “Ati iwọ Bẹtlehẹmu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lārin awọn ẹgbẹgbè̩run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israẹli yio ti jade tọ mi wá; ijade lọ rè̩ si jẹ lati igbāni, lati aiyeraiye.” Ki i ṣe pe Mika darukọ ilu ti a o gbé bi Jesu nikan, o tilẹ fi hàn péẹni ayeraye ni Jesu i ṣe. Nigba ti awọn amoye beere lọwọ wọn pé, “Nibo li ẹniti a bí ti iṣe ọba awọn Ju wà?” awọn olori alufaa ati awọn akọwe dahun pé, “Ni Bẹtlẹhẹmu ti Judea ni: nitori bḝli a kọwe rè̩ lati ọwọ woli nì wá” (Matteu 2:2, 5). A ti pa awọn asọtẹlẹ wọnyi mọ fun ni lati ọdún pupọ wọnyi wá, a si ti fi le wa lọwọ lẹyin ti a ti ṣe itumọ rẹ taarà lai si abula ninu è̩dà Bibeli ti Ọba Jakọbu tumọ si ède Gẹẹsi.

Aanu

Ọlọrun ti o yan Israẹli fé̩ ti o si n fé̩ ki wọn jẹ anfaani ti O nawọ rẹ si wọn n rọ wọn lati yi pada kuro ninu gbogbo ifasẹyin wọn. “Enia mi, kini mo fi ṣe ọ? ati ninu kini mo fi da ọ li agara?” (Mika 6:3). Bayi ni Ọlọrun ifẹ n rọ awọn ti o yi pada kuro ninu otitọ. Ki i ṣe ọrẹ wọn, ọrọ wọn tabi akọbi ọmọ wọn ni Oluwa n beere lọwọ wọn, bi kòṣe pe ki wọn “ki o ṣe otitọ, ki o si fẹānu, ati ki o rìn ni irè̩lẹ” pẹlu Rè̩. Ẹṣè̩ a maa yà eniyan nipa si Ọlọrun, a maa yọ orukọẹni kuro ninu Iwe Iyè a si maa ṣi eniyan nipò kuro ninu ijọba ayeraye ti Ọlọrun; ṣugbọn ironupiwada ni akoko ti o wọ yoo dá eyi ti a ti sọnu pada. “Tani Ọlọrun bi iwọ, ti o ndari aiṣedede jì, ti o nre iyokù ini rè̩ kọja? kò dá ibinu rè̩ duro titi lai, nitori on ni inudidun si ānu” (Mika 7:18).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni itumọ ibeere yii, “Kini irekọja Jakọbu? Samaria ha kọ?” (Mika 1:5).
  2. Darukọ diẹ ninu awọn ẹṣè̩ ti Wolii Mika takò.
  3. Fi ohun ti n ṣẹlẹ lode oni wé awọn ohun ti n ṣẹlẹ nigba ayé Mika.
  4. Igba ati akoko wo ni Wolii Mika n sọrọ nipa rè̩ ninu ori kẹrin, ẹsẹ keji?
  5. Ki ni itumọọrọ wọnyi, “Dide, si ma pakà, Iwọọmọbirin Sioni”?
  6. Bawo ni awọn akọwe igba ayé Jesu ṣe mọ ibi ti a o gbé bi Jesu?
  7. Ki ni Ọlọrun n beere lọwọ Israẹli? (Wo Ori Kẹfa).
  8. S̩e akajuwe ohun wọnni ti yoo wà nigba Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún.
  9. Iru àyè wo ni Israẹli yoo wà nigba Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún?