Hosea 11:1-12; 14:1-9

Lesson 331 - Senior

Memory Verse
“Tali o gbọn, ti o lè moye nkan wọnyi? tali o li oye, ti o le mọ wọn? nitori ọna Oluwa tọ, awọn olododo yio si ma rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn” (Hosea 14:9).
Cross References

I Ọlọrun Mú Igbala Israẹli Kuro ni Ilẹ Egipti Wá si Iranti Wọn

1. IfẹỌlọrun ni o mú Israẹli jade kuro ni oko-ẹrú, Hosea 11:1

2. Israẹli pada si isin Baali, Hosea 11:2; 1 Awọn Ọba 18:18, 21

3. A fi è̩sọ kọ wọn lẹkọọ ni ibẹrẹ igbesi-ayé orilẹ-ède wọn, Hosea 11:3, 4; Deuteronomi 32:9-12; 1:31

II Ọlọrun Rán Israẹli Leti pé Ikolọ Wọn si Oko-ẹrú Sunmọ Etile

1. Assiria ni yoo maa jọba lori wọn bi wọn kò ba pada sọdọ Oluwa, Hosea 11:5; 2 Awọn Ọba 17:22, 23

2. Idà yoo wa sori wọn nitori ifasẹyin wọn, Hosea 11:6, 7

3. A ṣe apejuwe iyọnú ati aanu Ọlọrun si Israẹli ti o ti fasẹyin, Hosea 11:8; Orin Dafidi 103:13, 14

4. Bi gbigbona ibinu Ọlọrun ti pọ tó, sibẹ O tun fi aanu bá Israẹli lò, Hosea 11:9; Orin Dafidi 103:8, 9

5. O tun ṣe ileri ipadabọ wọn nikẹyin, Hosea 11:10, 11; Deuteronomi 30:4, 5

6. A fi iyatọ ti o wà laaarin Israẹli ati Juda lakoko naa hàn, Hosea 11:12

III Ipe Ọlọrun si Ironupiwada

1. Ọlọrun fi ifẹ ati itara pe Israẹli, Hosea 14:1, 2; Matteu 23:37

2. Israẹli ni lati ṣe ijẹwọẹṣẹ rè̩ tọkàntọkàn, Hosea 14:3; Owe 28:13

3. Imupada-bọ-sipo Israẹli duro lori bi wọn ba le ronupiwada, Hosea 14:4-8

4. A fi ọgbọn ti ó wà ninu ironupiwada atọkànwá hàn, Hosea 14:9

Notes
ALAYE

Wolii Hosea

Wolii Hosea jé̩ ojugbà Wolii Isaiah ti o kọ akọsilẹ pupọ nipa Ijọba Messia. Pupọ ninu asọtẹlẹ Hosea ni o jẹ ti Ijọba Israẹli, nigba ti pupọ ninu asọtẹlẹ ti Isaiah jẹ ti Ijọba Juda. A mọ Hosea bi wolii ti n pohun réréẹkún lori Israẹli, è̩wẹ, Jeremiah ni wolii ti n sọkun lori Juda. Ọpọlọpọ ninu ọna ti wolii Hosea fi gbéọrọ rè̩ kalè̩ ni o gbamuṣe gẹge bi eyikeyi ti a le ri ninu awon iwe kika asiko. Gẹgẹ bi ọrọ rè̩ ti muna to lati tako è̩ṣẹ awọn Ọmọ Israẹli, bẹẹ gẹgẹ ni o tun fi iyọnu ati ifẹ pè wọn si ironupiwada. Hosea ni è̩bun lati maa sọrọ ni ọna ti o mu ni lọkan ṣinṣin, ọpọlọpọ ninu awọn akọsilẹ rẹ ninu Bibeli si ni ọlá lọpọlọpọ. Efraimu ni orukọ anijẹ ti a saba maa n fi pe ẹya mẹwaa Israẹli. Orukọ yii ni Hosea n lo nigba pupọ ti o ba fẹ mé̩nukàn wọn.

Kuro ni Oko-ẹrú

IfẹỌlọrun si Israẹli dabi ifẹ obi si ọmọ rè̩. Ifẹ ati iyọnúỌlọrun si Israẹli pọ lọpọlọpọ to bẹẹ ti O fi mu wọn jade kuro ni oko-ẹrú Egipti. Iru ifẹ iṣaaju ti o n gba ọkàn ẹlẹṣẹ ti o ronu piwada kan, nigba ti a da a nide kuro lọwọọta jé̩ diẹ kinun nipa irú ifẹ ti Ọlọrun ni si awọn ọmọ Rè̩, eyi ni O si fihàn fun Israẹli.

Ọlọrun fé̩ Israẹli, O si gbà wọn kuro ni oko-ẹrú. O fé̩ẹlẹṣẹ, O si n pèé si ironupiwada. Gẹgẹ bi awọn Ọmọ Israẹli ti wà labẹ awọn oluwa ònrorò ni Egipti, bẹẹ gẹgẹ ni ẹlẹṣẹ kọọkan wà labẹ oluwa ònrorò -- èṣu. Ọlọrun nikan ni o le já idèè̩ṣẹ, ki o si sọẹlẹṣẹ di ominira.

Ni oru ọjọ kan ni Ọlọrun mú awọn Ọmọ Israẹli jade kuro ni ilẹ Egipti. O gbà wọn kuro lọwọ Farao onroro. Ni iṣẹju kan, Jesu le pa agbara Satani run ni igbesi-ayéẹlẹṣẹ ki o si da a nide kuro ninu gbogbo iwa buburu ti o ti de e ni igbekun. Iyọnú, ifẹ ati aanu Ọlọrun ni o n mu ki ẹlẹṣẹ, ẹlẹbi ati ẹni irira di ẹni ti Ọlọrun fi ojurere ati iṣeun ifẹ Rè̩ hàn fún to bẹẹ ti a fi n pe e ni ọmọ Rè̩. Ọrọ nì ti o wi pe, “Ni Egipti ni mo ti pèọmọ mi jade wa” jé̩ otitọ fun Israẹli, o si tun jé̩ asọtẹlẹ ti o daju ti a si múṣẹ pere-pere ninu Kristi.

A kọỌ lati Rin

Jakọbu lọ si Egipti lati gba ẹmi ara rè̩ ati ti awọn ara ile rè̩ la. A gbé Jesu lọ si Egipti lati gba ẹmi Rẹ là kuro lọwọỌba Hẹrọdu. S̩ugbọn Oluwa kò fi Israẹli tabi Kristi silẹ nibi ti i ṣe oko-ẹrú yii. O pè wọn jade! Ki i ṣe pe Oluwa mu Israẹli jade kuro ni ilẹ Egipti nikan, ṣugbọn O gba oriṣiriṣi ọna lati kọ wọn lati rin ni ọna kanṣoṣo ti i ṣe ọna otitọati ailewu. Ẹmi Mimọ wà ninu ayé lode oni, O n pe gbogbo ọkàn jade kuro ninu okunkun wá sinu imọlẹ Ihinrere. Ọlọrun kilọ fun Israẹli nipa ewu ati jamba ti ó wà loju ọna, O si fi oju Rè̩ tọ wọn la gbogbo ilẹ ti wọn kò rin ri já. O fi ounjẹ bọ wọn nigba ti ebi n pa wọn. O fi manna bọ wọn -- ounjẹ angẹli -- ṣugbọn Efraimu “sanra tán, o si tapa.”

Ifasẹyin

Nigbakuugba ni wolii Hosea n bá Israẹli wi nitori ifasẹyin rè̩. Ọrọ rẹ si wọn ni yii, “Israẹli ṣe agidi bi ọmọ malu alagidi;” “Efraimu dapọ mọòriṣa: jọwọ rè̩ si;” “Nitori nwọn ti gbin ẹfufu, nwọn o si ka ājà.” Awọn ọrọ wọnyi n fi irú ipò ti Israẹli wà nipa ti ẹmi hàn fun ni. Bi gbogbo ibukun ti Ọlọrun fifun wọn ti pọ tó o nì, sibẹ wọn jingiri sinu ifasẹyin.

Lati igba ti Aarọni ti yá ere ẹgbọrọ maluu fun awọn ọmọ Israẹli titi di igba ti a fi kó wọn lẹrú lọ si ilẹ Assiria ati Babiloni, igbesi-ayé wọn jẹ kiki ifasẹyin, ironupiwada ati ifasẹyin si i. Nigba ti wọn bá di ọlọrọ, ọkàn wọn a gbe gá soke ninu iwa asán. Nigba naa Oluwa a jẹ ki ọtá wọn bori wọn, ninu ipọnju wọn, wọn a si tun kigbe pe Oluwa. Ọlọrun a rán aanu Rè̩ si wọn nigba ti wọn ba ke pe E, lẹyin eyi ibukun Rè̩ a si tun jẹ ti wọn. Nipa bayii a fi Israẹli wé agbere obinrin, awọn eniyan ti o kọỌlọrun otitọ ati alaayè silẹ ti wọn si n sin oriṣa. Bibeli sọ fun ni pe, “Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rè̩” (1 Johannu 2:15).

Ipè si Ironupiwada

“Israẹli, yipadà si OLUWA Ọlọrun rẹ, nitori iwọ ti ṣubu ninu aiṣedẽde rẹ. Mu ọrọ pẹlu nyin, ẹ si yipadà si OLUWA: ẹ wi fun u pe, Mu aiṣedẽde gbogbo kuro, si fi ore-ọfẹ gbà wa.” Bayii ni Oluwa ṣe n rọ orilẹ-ède ọlọtẹ. Bakan naa ni Ọlọrun n rọ olukuluku ọkàn aṣako lọjọ oni. Boya ọta ni o ti mu ki o ṣina, ṣugbọn Oluwa wi pe, “Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ nyin.” “Bi è̩ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo didì; bi nwọn pọn bi àlāri, nwọn o dabi irun-agutan” (Isaiah 1:18). Jesu n pe gbogbo eniyan bayii pe, “Ẹniti o ba si tọ mi wá, emi ki yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri” (Johannu 6:37). Bi o tilẹ jẹ pe idajọỌlọrun wà lori ọkàn ti o takú sinu è̩ṣẹ, sibẹ O na ọwọ aanu Rè̩ si awọn ti o bá gbà lati ronu piwada.

Ninu ẹkọ yii, Ọlọrun n sọ fun Israẹli pe, “Mu ọrọ pẹlu nyin, ẹ si yipadà si OLUWA; ẹ wi fun u pe, Mu aiṣedẽde gbogbo kuro, si fi ore-ọfẹ gbà wa.” Ẹ fi tẹduntẹdun bẹỌlọrun ki O mú gbogbo è̩ṣẹ yin kuro! Ẹ ti sọnù laini iranwọ, ẹ si n ṣegbe lọ ni yiyà ara yin kuro lọdọỌlọrun.

Awọn Ọmọ Israẹli ki yoo tún iwa wọn ṣe lati yi pada si Ọlọrun. Ki i ṣe pe wọn kọ lati rin ni ọna Ọlọrun nikan, ṣugbọn wọn n yangàn ninu iwa buburu wọn. Ọlọrun sọ lati ẹnu woli Isaiah pe, “Dawọ duro lati ṣe buburu; kọ lati ṣe rere.” Oju Ọlọrun ri ọkàn ti o fé̩ yi pada kuro ninu è̩ṣẹ lotitọ ati lododo, Oun yoo si ran irúọkàn bẹẹ lọwọ.

IyọnúỌlọrun si awọn Eniyan Rẹ

“Emi o ha ṣe jọwọ rẹ lọwọ, Efraimu? emi o ha ṣe gbàọ silẹ Israẹli?” Ọrọ wọnyi jade lati inu ọkàn afẹrí, ọkàn ifẹ ati aanu Ọlọrun. Jesu sọ bayii bi O ti n sọkun lé Jerusalẹmu lori: “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, iwọ ti o pa awọn woli, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ ti ìradọ bò awọn ọmọ rẹ labẹ apá rè̩, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!” (Matteu 23:37).

Ọlọrun tikara Rè̩ n rọọmọ-eniyan, O ta ẹjẹ Rè̩ silẹ fun wọn, O si nawọ ifẹ Rè̩ lati gba wọn pada sọdọ ara Rè̩. Ifẹ alailẹgbé̩! Wọn o ha ṣe kọ eti didi si ipè ti Ẹmi n pe wọn yii?

“Sa jẹwọè̩ṣẹ rẹ” (Jeremiah 3:13). Ọna rẹ tabi ero rẹ ha ti di ọlọrun rẹ bi? Wọn ha ti ṣu ọ loju to bẹẹ ti iwọ kò le ri ọna ti Ọlọrun? Eniyan ni lati gbà péọna ayé oun, yala gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ paraku ti n dẹṣẹ ti o buru jù tabi gẹgẹ bi alaimọkan ti n dẹṣẹ ninu ifọju ọkàn ati lile àyà, kò mu alaafia ati ìfayàbalẹ ti oun n fé̩ wá, o si ni lati bẹỌlọrun ki O fi ọna Rè̩ hàn oun. Oun yoo ri ọna Ọlọrun nigba ti o ba n ka Bibeli ti o ba si fara balẹ gbọ iwaasu ỌrọỌlọrun lati inu Bibeli pẹlu ọkàn ti o ṣipaya ti o si pa gbogbo ohun ti o ti ni lọkàn tì. Ọlọrun yoo fi ọna ifẹ, ayọ, alaafia ati suuru Rè̩ hàn án; bi eniyan ba si ti fa ọkàn rẹ ya niwaju Ọlọrun, nitori aiṣedeedee rè̩, ti o si tọrọ idariji lọdọỌlọrun, Ọlọrun yoo sọkalẹ sinu ọkan rẹ lati maa ba a gbé. “Bayi li Ẹni-giga, ati ẹniti agbega soke sọ, ẹniti ngbe aiyeraiye, orukọ eniti ijẹ Mimọ; emi ngbe ibi giga ati mimọ, ati inu ẹniti o li ẹmi irobinujẹ on irẹlẹ pẹlu, lati mu ẹmi awọn onirẹlẹ sọji, ati lati mu ọkàn awọn oniròbinujẹ sọji” (Isaiah 57:15). Tun wo Orin Dafidi 34:18.

Ironupiwada Efraimu

Hosea ṣe apejuwe ohun ti Efraimu yoo wi nigba ti ọkàn ọtẹ ati agidi rè̩ bá kaanu. Efraimu yoo sọ bayi pe, “Kili emi ni fi òriṣa ṣe mọ?” Nikẹyin o ti tuubá! O wolẹ lẹsẹ Agbelebu pẹlu irobinujẹọkàn!

Hosea n fi oju ẹmi isọtẹlẹ ri igbà ti Israẹli ki yoo bọriṣa mọ. O fi oju ẹmi ri akoko ologo nì ti orilẹ-ède naa yoo ṣiwọè̩ṣẹ didá. Ọlọrun yoo jé̩Ọlọrun wọn titi lae, wọn yoo si jé̩ eniyan Rè̩. Wọn yoo maa rúẹbọọpọ si Ọlọrun pẹlu “ọmọ malu” ètè wọn nitori pe irubọ ewurẹ ati agbo ki yoo si mọ. Oju wọn yoo ti ri Ẹbọ nì -- Kristi ti wọn ti kọ nigba kan ri. Wọn yoo ma a rú “ẹbọ iyin si Ọlọrun nigbagbogbo, ... ti njẹwọ orukọ rè̩” (Heberu 13:15).

Ailoṣuwọn IfẹỌlọrun

Gbọ idahun Ọlọrun alaanu ati onifẹ: “Emi o wo ifàsẹhìn wọn sàn, emi o fẹ wọn lọfẹ: nitori ibinu mi yi kuro lọdọ rẹ. Emi o dabi ìri si Israẹli: on o tanná bi eweko lili; yio si ta gbòngbo rè̩ bi Lẹbanoni.” Eyi ti dara tó! Olukuluku ọkàn ni anfaani yii wà fún. Igbesi-ayé bẹẹ ti dara tó, ti oluwarẹ yoo maa tàn bi lili, ti adun igbesi-ayé ti o n gbé lọjọọjọ yoo maa ta sánsán bi òróro ikunra oloorun didun!

Hosea ba Israẹli ti n dakú-dáji wi, o si gbà a niyanju pẹlu; o pari asọtẹlẹ rè̩ pẹlu ọrọ giga wọnyi: “Tali o gbọn, ti o lè moye nkan wọnyi? tali o li oye, ti o le mọ wọn? nitori ọna Oluwa tọ, awọn olododo yio si ma rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Darukọ wolii nla kan ti i ṣe ojugba Hosea.
  2. Orukọọwọn wo ni a saba maa n fi pe Israẹli?
  3. Ki ni è̩ṣẹ ti Israẹli n ṣubu si nigbakuugba?
  4. Nigba wo ni a gbé Israẹli ga gẹgẹ bi orilẹ-ède?
  5. S̩e alayé bi aniyàn Ọlọrun ti ri lori Israẹli apẹyinda.
  6. Njẹ o le kàá lori awọn ọrọ ti Oluwa sọ lati rọ Israẹli lati yi pada?
  7. Sọ diẹ ninu awọn ọrọ kukuru kukuru ti Hosea sọ.