Lesson 332 - Senior
Memory Verse
“Nitorina ni ibinu OLUWA ṣe ràn si awọn enia rè̩, o si korira awọn enia ini rè̩. O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn” (Orin Dafidi 106:40, 41).Cross References
I È̩ṣẹ Wà ni Israẹli
1. Hoṣea jé̩ọba buburu, o si jọba lori Israẹli fun ọdun mẹsan, 2 Awọn Ọba 17:1, 2
2. S̩alamaneseri, ọba Assiria goke tọ Hoṣea wá, Hoṣea si di iranṣẹ rẹ, 2 Awọn Ọba 17:3
3. A há Hoṣea mọ inu tubu nitori ọtè̩ ti o ṣe si S̩alamaneseri, 2 Awọn Ọba 17:4
4. Awọn Assiria dó ti Israẹli, wọn si kó wọn li ẹrú, 2 Awọn Ọba 17:5, 6
II IdajọỌlọrun
1. Israẹli ti kọ isin Ọlọrun silẹ, wọn si pada di abọriṣa, 2 Awọn Ọba 17:7-12
2. Ọlọrun rán awọn wolii ati ariran si Israẹli lati rọ wọn ati lati kilọ fun wọn nitori ibọriṣa wọn, 2 Awọn Ọba 17:13-17; Jeremiah 7:25; 25:4; 11:7
3. Ọlọrun kọẹya Israẹli mẹwaa silẹ, O si pọn wọn loju, O si fi wọn le awọn akoni lọwọ, titi O si fi tá wọn nù kuro niwaju Rẹ, 2 Awọn Ọba 17:18-24
4. Ọlọrun rán awọn kiniun si ilẹ naa lati pa pupọ ninu awọn eniyan naa ki wọn baa le kọ lati bẹru Oluwa, 2 Awọn Ọba 17:25-28
5. Awọn eniyan ilẹ naa ni ibẹru Oluwa, sibẹ wọn sin ọlọrun ati oriṣa ti awọn tikara wọn gbé kalẹ, 2 Awọn Ọba 17:29-41
Notes
ALAYEIbinu si Israẹli
Hoṣea, ọba Israẹli jọba fun ọdún mẹsan-an, ijọba rè̩ si burú jọjọ. Eyi ni ohun ti Hoṣea fi silẹ nipa ijọba rè̩. Oun ni ọba ti o jẹ kẹyin ni Israẹli ni akoko ijọba rè̩ ni awọn ara Assiria pa ijọba ati orilẹ-ède Israẹli run. È̩ṣẹ ti gbilẹ o si ti seso laaarin ẹya Israẹli mẹwaa, eso rè̩ si ti pọn fún ikore. (Wo Jakọbu 1:15). Ọlọrun ti fara da iṣọtẹ, ibọriṣa ati ẹsin keferi ti o wa laaarin Israẹli tó. Lati nnkan bi igba ọdún ti Juda ati Israẹli ti pinya ni wọn ti n fi agidi tẹle ọna ara wọn labẹ akoso awọn ọba wọn alaiwa-bi-ọlọrun ti n tẹle ifẹkufẹ ati ilana buburu ara wọn. S̩ugbọn idajọỌlọrun kò jinna si wọn.
Hoṣea sún ọjọ ibi siwaju fun igba diẹ, ni ti pe o sọ ara rè̩ di iranṣẹS̩alamaneseri. S̩ugbọn kò pé̩ lọ ti o fi di mimọ fun S̩alamaneseri, ọba Assiria pe Hoṣea n di ọtẹ si oun, nitori naa o há Hoṣea mọ inu tubu, o si dó ti Samaria. Awọn ọmọ Israẹli kò pada kuro ni oko-ẹrú ijọba onroro awọn ara Assiria. Ifarada Ọlọrun nitori è̩ṣẹ Israẹli ti dopin, awọn ara Assiria ni Ọlọrun si fi ṣe ohun-èlo lati mú ki wọn mọ ibinu Rè̩.
Awọn asọtẹlẹ Wolii Isaiah fi idi otitọ yii mulẹ péỌlọrun a maa lo awọn orilẹ-ède keferi lati jẹ Israẹli niya. A kọọ bayii pé: “Egbe ni fun Assuri, ọgọ ibinu mi, ati ọpa ọwọ wọn ni irúnu mi. Emi o ran a si orilẹ-ède agabàgebe, ati fun awọn enia ibinu mi li emi o paṣẹ kan, lati ko ikogun, ati lati mu ohun ọdẹ, ati lati tè̩ wọn mọlẹ bi ẹrè̩ ni igboro” (Isaiah 10:5, 6). Eyi ni o ṣẹlè̩ lọpọlọpọ igba si Israẹli ati Juda. A tè̩ wọn mọlẹ bi ẹrè̩ ni igboro, nigba ti o ṣe pe, nipa oore-ọfẹỌlọrun wọn i ba lé ogun awọn ara Assiria sá, ṣugbọn dipo eyi, iṣubu ati ajalu ni o jé̩ ipin wọn.
Lati igba Mose ni a ti n kilọ fun wọn pe ègún Ọlọrun yoo wá sori wọn bi wọn ba yi pada kuro ninu isin Ọlọrun otitọ lati maa bọriṣa. Ikilọ naa ni eyi: “OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọna jijin, lati opin ilẹ wa bi idì ti ifò; orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọède rè̩; orilẹ-ède ọdaju, ti ki yio ṣe ojusaju arugbo, ti ki yio si ṣe ojurere fun ewe” (Deuteronomi 28:49, 50).
A le wi pe awọn Assiria jé̩ apẹẹrẹ Eṣu. A mọ awọn ara Assiria ni ayé igbaani bi ikà ati onrorò eniyan. Eyi paapaa jẹ apẹẹrẹ Satani, ọta-iyọta ọmọ-eniyan. Nigbakuugba ti Ọlọrun ninu ọgbọn awamaridi Rè̩ ba fi àye silẹ, Eṣu yoo gbogun ti awọn eniyan Ọlọrun pẹlu inunibini kikoro. Ohun ti o ṣẹlẹ si Jobu jé̩ apẹẹrẹ ikọlu Satani. Ọlọrun a tun maa gba Eṣu láyè lati ṣe ibi gẹgẹ bi idajọ ododo nitori è̩ṣẹ. Eyi ni ohun ti o ṣẹlẹ si Israẹli. Awọn ara Assiria ni ero lati pa orilẹ-ède Israẹli run, Ọlọrun si gba fun wọn lati ṣe bẹẹ nitori pe Israẹli ti jingiri sinu è̩ṣẹ lati ọjọ pipé̩, wọn kò si naani Ọlọrun. Awọn alaṣẹ ti o wà, lati ọdọỌlọrun li a ti ṣe ilana rẹ wá (Ka Romu 13:1-6). Oluwa sọ ninu Ọrọ Rè̩ pé: “Kiye si i, emi li ẹniti o ti dá alagbẹdẹ ti nfé̩ ináẹyín, ti o si mu ohun-elò jade fun iṣẹ rè̩; emi li o si ti dá apanirun lati panirun” (Isaiah 54:16). Ẹsẹ Iwe Mimọ yii fi hàn pé Eṣu, olori apanirun gbogbo ẹda, kò kọja akoso ti o bá tọ loju Ọlọrun lati fi i si. Bakan naa ni Ọlọrun le lo ibajẹ ati iṣẹ buburu Satani lati mú ilana ati idajọ Rè̩ṣẹ gẹgẹ bi o ti ri nipa awọn ara Assiria ti a fún làaye lati ṣẹgun Israẹli.
Nigba ti idajọ tilẹ sún mọle gbọngbọn, Ọlọrun le gba Israẹli là kuro lọwọ iparun Assiria ati ikolọ ti o tẹle e bi wọn bá ronu piwada è̩ṣẹ wọn ti wọn si ké pe Ọlọrun fún aanu. S̩ugbọn wọn kò yi pada bi o tilẹ jé̩ pé Oluwa rán awọn woli Rè̩ lati kilọ fun wọn. “Sibẹ OLUWA jẹri si Israẹli, ati si Juda, nipa ọwọ gbogbo awọn woli, ati gbogbo awọn ariran, wipe, Ẹ yipada kuro ninu ọna buburu nyin, ki ẹ si pa ofin mi ati ilana mi mọ, gẹgẹ bi gbogbo ofin ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, ti mo rán si nyin nipa ọwọ awọn woli iranṣẹ mi.” Wọn kò naani ikilọ, idajọỌlọrun si wá sori wọn. “Nitorina ni OLUWA ṣe binu si Israẹli gidigidi, o si mu wọn kuro niwaju rè̩: ọkan kò kù bikòṣe è̩ya Juda nikanṣoṣo” (2 Awọn Ọba 17:13, 18).
È̩ṣẹ Ikọkọ
Eredi rẹ ti Ọlọrun fi binu si Israẹli han ninu ẹsẹỌrọỌlọrun yii: “Awọn ọmọ Israẹli si ṣe ohun ikọkọ ti kò tọ si OLUWA Ọlọrun wọn, nwọn si kọ ibi giga fun ara wọn ni gbogbo ilu wọn, lati ile-iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.” Dajudaju è̩ṣẹ ti fọ oju inu awọn Ọmọ Israẹli ti wọn kò fi mọ péỌlọrun wà nibi-gbogbo. Arinu-rode ati olumọọkàn ni Ọlọrun. È̩ṣẹ kò pamọ loju Ọlọrun; Ọlọrun mọ nipa è̩ṣẹ ti a dá nikọkọ bi ẹni pe a da a ni gbangba. Onipsalmu sọ bayii pé, “Bi o ba ṣepe awa gbagbe orukọỌlọrun wa, tabi bi awa ba nàọwọ wa si ọlọrun ajeji; NjẹỌlọrun ki yio ri idi rè̩? nitori o mọ ohun ikọkọ aiya” (Orin Dafidi 44:20, 21). Jesu sọ fun awọn eniyan Israẹli pe: “Nitori kò si ohun ti o lumọ bikoṣe ki a le fi i hàn; bḝni kò si ohun ti o wà ni ikọkọ, bikoṣepe ki o le yọ si gbangba” (Marku 4:22).
Ayé yii fẹran okunkun, Jesu si sọ bayii nipa ayé pé: “Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹòkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru” (Johannu 3:19). Awọn eniyan rò pé bi è̩ṣẹ wọn ti pamọ kuro loju ẹlẹgbẹ wọn, bẹẹni o pamọ fun Ọlọrun.
Bi idajọỌlọrun lori Israẹli bá dà bi ẹni pe o wuwo loju wa, ẹ jé̩ ki a ranti pe Ọlọrun bukun Israẹli ati Juda ju gbogbo awọn ẹlomiran lọ, ni ti pe Ọlọrun yàn wọn fé̩ lati jé̩ eniyan ọtọ fún Un. Imọlẹ OtitọỌlọrun mọ si wọn, wọn mọ isin Ọlọrun otitọ ati alaaye, Ọlọrun si ti lana pe wọn yoo jé̩ẹni ibukun ju gbogbo ẹlomiran lọ, ki awọn naa paapaa le jé̩ ibukun fun awọn ẹlomiran. Wọn ṣá gbogbo ohun ti o tọ, ti o dara ti o si yẹ tì, wọn si tẹle ọna ibi, iwa buburu ati àṣa awọn orilẹ-ède keferi ti o yi wọn ká.
Iwa buburu wọn ti o ga ju lọ ni pé, lẹyin ti wọn ti mọỌlọrun ti i ṣe orisun iye ati ododo, wọn yi pada kuro lọdọ Rè̩. Ọrọ Peteru fi iru iwa ti ẹya mẹwaa Israẹli hu yé ni, ani awọn ẹni ti ibinu Ọlọrun sọkalẹ le lori: “Nitori lẹhin ti nwọn ba ti yọ tan kuro ninu ẽri aiye, nipa mimọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi, bi nwọn ba si tun fi ara kó o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹhin wọn a buru jù ti iṣaju lọ. Nitori iba san fun wọn, ki nwọn ki o má mọọna ododo, jù lẹhin ti nwọn mọọ tan, ki nwọn ki o yipada kuro ninu ofin mimọ ti a fifun wọn. Owe otitọ nìṣẹ si wọn lara, Ajá tún pada si ẽbi ara rè̩; ati ẹlẹdẹ ti a ti wè̩ mọ sinu àfọ ninu è̩rẹ” (2 Peteru 2:20-22).
Ẹ jé̩ ki awa ti o mọ otitọỌlọrun tẹle ọrọ Johannu ayanfẹ ti o sọ bayii pe: “Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kikún gbà” (2 Johannu 8).
Questions
AWỌN IBEERE- Ta ni ọba ikẹyin ni Israẹli?
- Ki ni ṣe ti awọn Assiria fi kọlu Israẹli?
- Ki ni ṣe ti Ọlọrun kò fi ja fun Israẹli gẹgẹ bi Oun ti maa n ṣe tẹlẹ ri?
- Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi binu si Israẹli?
- Ki ni ọpa ibinu Ọlọrun?
- Ta ni apanirun nla?
- NjẹỌlọrun a maa ṣe akoso Satani?
- Njẹè̩ṣẹ le pamọ kuro loju Ọlọrun?
- Ki ni è̩ṣẹ ikọkọ?