Iṣe Awọn Apọsteli 15:1-41; Romu 14:1-6

Lesson 333 - Senior

Memory Verse
“Nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá” (Johannu 1:17).
Cross References

I Ofin tabi Oore-ọfẹ

1. Awọn Onigbagbọ ti Ikọla fé̩ fi ipá mu awọn Keferi lati pa ofin ti a tipasẹ Mose fun ni mọ, Iṣe Awọn Apọsteli 15:1; Galatia 1:6, 7

2. Paulu ati Barnaba kò jé̩ kuro ninu ilana oore-ọfẹ ti awọn Onigbagbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 15:2; Romu 10:4; Galatia 1:8-12

3. A rán awọn ikọ kan lọ si Jerusalẹmu nitori ọrọ yii, Iṣe Awọn Apọsteli 15:2-5

II Ipade Igbimọ ni Jerusalẹmu

1. Awọn Apọsteli ati awọn alagba pejọ pọ lati dàọrọ naa rò, Iṣe awọn Apọsteli 15:6

2. Peteru sọ inu tirè̩ gẹgẹ bi iṣipaya ifẹỌlọrun ti o ti ri ṣiwaju akoko yii, Iṣe Awọn Apọsteli 15:7-11; 10:44-48

3. Paulu ati Barnaba sọ ti awọn iṣẹ-iyanu ti Ọlọrun ṣe laaarin awọn Keferi, Iṣe Awọn Apọsteli 15:12

4. Jakọbu fi ọrọ tirè̩ kún un, o si sọ ni kukuru imọran awọn igbimọ, Iṣe Awọn Apọsteli 15:13-21; Romu 14:1-6

III Oore-ọfẹ ti n S̩ẹgun

1. Igbimọ pari ọrọ naa pé awọn Keferi ti o gbagbọ ti di ominira kuro lọwọ ofin Mose, Iṣe Awọn Apọsteli 15:22-29; Galatia 2:14-16

2. A kọ eyi sinu iwe a si fi rán awọn arakunrin, Iṣe Awọn Apọsteli 15:23-33

IV Irin-ajo Keji fun Itankalẹ Ihinrere

1. Paulu pinnu lati fi Antiọku silẹ lati lọ si ilu gbogbo ti o ti bè̩wò tẹlẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 15:34-36

2. Barnaba yàn lati mú Johannu ti a n pe ni Marku dani, wọn si lọ si Kipru, Iṣe Awọn Apọsteli 15:37-39

3. Paulu yàn Sila, wọn si lọ si Siria ati Kilikia, Iṣe Awọn Apọsteli 15:40, 41

Notes
ALAYE

“Ẹnyin nsin ohun ti ẹnyin kò mọ: awa nsin ohun ti awa mọ: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá” (Johannu 4:22). Jesu sọ ohun ti gbogbo awọn Ju fi tọkantọkan gbagbọ, nitori ni ọpọlọpọọdun sẹyin ni Oluwa ti ṣe ileri fun Abrahamu olododo wi pe, “Ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye” (Gẹnẹsisi 12:3).

Majẹmu ni Sinai

Orilẹ-ède Israẹli jé̩ abajade ati apakan imuṣẹ ileri ti Ọlọrun ṣe fun Abrahamu. Ni ori Oke Sinai, Ọlọrun to Majẹmu Rè̩ pẹlu awọn Ọmọ Israẹli lẹsẹẹsẹ; awọn pẹlu fohun-ṣọkan lati pa Majẹmu naa mọ gẹgẹ bi Mose ti sọọ fun wọn. Lọna kukuru, eredi ipè nla ti Ọlọrun pe awọn Ọmọ Israẹli ni pe Ọlọrun n fẹ ki Israẹli ki o di orilẹ-ède mimọ ati ijọba alufaa -- iṣura ọtọ fun Ọlọrun. Wọn ni lati jé̩ iranṣẹ Majẹmu Ọlọrun lati kede ihin naa fun araye, ati lati mú awọn eniyan wá sinu Majẹmu Ọlọrun. Ọlọrun fi ara rè̩ hàn fun awọn Ọmọ Israẹli lọna ti o daju ti a kò si le gbagbe. O fun wọn ni Ofin Mẹwaa, ti a ti ọwọỌlọrun kọ sara wàláà okuta ati awọn ofin miiran ti Mose kọ sinu iwe. Ọlọrun fi awọn Ọmọ Israẹli ṣe olupamọ ati olutọju ỌrọỌlọrun, O si yan awọn ỌmọIsraẹli gẹgẹ bi idile ati ohun-elo nipasẹẹni ti a o gbé mú Ileri Majẹmu ti O bá Abrahamu dá, ṣẹ fun gbogbo ayé nipasẹ ibi Messia.

Gbogbo Ofin ti Ọlọrun fi fun awọn Ọmọ Israẹli ni Oke Sinai ni a n pe ni Ofin Mose nitori pe Mose ni ẹni ti Ọlọrun lo lati fi Ofin naa lé Israẹli lọwọ, ṣugbọn lai si aniani, ti Ọlọrun ni Ofin naa i ṣe. Bi a ti n kẹkọọ ti a si n ṣe ayẹwo Ofin ati akoko ti a fi fun awọn Ọmọ Israẹli, a o ri i péỌlọrun nikan ni o le jé̩ Olulana irú awọn ofin bẹẹ lati ṣe akoso igbesi-ayé ati lati kọọmọ-eniyan bi a ṣe le huwa rere ati iwa è̩tọ. Ofin yii ṣe ilana akoso igbesi-ayé ati isin Ọlọrun silẹ fun awọn Ọmọ Israẹli irú eyi ti o jinna si orilẹ-ède miiran patapata. Ofin yii jẹ iṣipaya nla Ọlọrun ti o tayọ ti atẹyinwa; nipasẹ Ofin, awọn Ọmọ Israẹli mọ ohun ti Ọlọrun n beere lọwọ wọn nipa isin ti o ṣe itẹwọgba niwaju Rè̩.

Eredi Ofin

Ofin dara, o si logo, nitori pe o tọka si Ẹbọ pipe nì ti n bọọ wá ani Oluwa wa Jesu Kristi. IfẹỌlọrun ni pe ki Ofin ki o jé̩ olukọni fun awọn Ọmọ Israẹli – ki i ṣe pe Ofin tikara rè̩ le mú igbala wá. “Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ” (Galatia 3:24). “Nitori ofin bi o ti ni ojiji awọn ohun rere ti mbọ laijẹ aworan pāpā awọn nkan na, nwọn kò le fi ẹbọ kanna ti nwọn nru nigbagbogbo li ọdọdún mu awọn ti nwá sibẹ di pipé ... Nitori ko ṣe iṣe fun è̩jẹ akọ malu ati ti ewurẹ lati mu è̩ṣẹ kuro” (Heberu 10:1, 4).

Nitootọ a ri awọn eniyan kan ti wọn jé̩ olododo labẹ Ofin -- awọn ẹni ti o ri igbala, ti a si sọọkàn wọn di mimọ; ṣugbọn ododo wọn kò ti ipa iṣẹ Ofin wá bi ko ṣe lati inu igbagbọ wọn ninu Ọlọrun ati ìgbọràn si Ọrọ Rè̩. “Igba yio kùna fun mi lati sọ ti Gideoni, ati Baraku ati Samsoni, ati Jẹfta; ti Dafidi, ati Samuẹli, ati ti awọn woli: awọn ẹni nipasẹ igbagbọ ti nwọn ṣẹgun ilẹọba, ti nwọn ṣiṣẹ ododo, ti nwọn gbà ileri, ti nwọn di awọn kiniun li ẹnu ... Gbogbo awọn wọnyi ti a jẹri rere si nipa igbagbọ, nwọn kò si ri ileri na gbà: Nitori Ọlọrun ti pèse ohun ti o dara jù silẹ fun wa, pe li aisi wa, ki a máṣe wọn pé” (Heberu 11:32, 33, 39, 40).

Igba Oore-ọfẹ

“Ohun ti o dara jù” ti Ọlọrun pèse fun wa ni Ihinrere Jesu Kristi. Lati igba de igba ni ỌrọỌlọrun maa n sọ asọtẹlẹọjọ nì ti Oluwa yoo ṣi ilẹkun oore-ọfẹ silẹ fun gbogbo aye. “Kiyesi i, iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ, ati orilẹ-ède ti kò mọọ yio sare wá sọdọ rẹ, nitori OLUWA Ọlọrun rẹ, ati nitori Ẹni-Mimọ Israẹli; nitori on ti ṣe ọ li ogo” (Isaiah 55:5).

Ibí Jesu Kristi, ti i ṣe Messia, jé̩ ipilẹṣẹ akoko titun ninu ibalo Ọlọrun pẹlu eniyan – Igba Oore-ọfẹ. Akoko naa dé ti a mu gbogbo ohun idiwọ kuro ti a si wó gbogbo ohun idabu ti o paala saarin awọn orilẹ-ède lulè̩, a si mu oore-ọfẹỌlọrun tọ gbogbo eniyan lọ. Jesu sọ fun obinrin ara Samaria nì pe: “Wakati na mbọ, nigbati ki yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalẹmu, li ẹnyin o ma sin Baba ... S̩ugbọn wakati mbọ, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sin Baba li ẹmi ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sin on” (Johannu 4:21, 23). Iṣẹ alufaa ti i ṣe ti ọmọ Lefi ti dopin, isin ti i ṣe itẹwọgba niwaju Ọlọrun ti tayọ irubọ ti a n ṣe ni Tẹmpili ti a fi sọjọ sibi kan pato; irubọ ti a n fi ẹran ṣe lati wá ojurere Ọlọrun fun idariji è̩ṣẹ ti dopin. Ẹnikẹni ti oungbẹ n gbẹ nibikibi ni orilẹ ati ède ni anfaani lati tọỌlọrun lọ pẹlu igbagbọ ninu Jesu Kristi ati ironupiwada tootọ fun è̩ṣẹ ki o si ri ẹri gbà ninu ọkàn rẹ pé adura oun jé̩ itẹwọgba ati pe a dari è̩ṣẹ oun ji.

Majẹmu Titun

Ọlọrun gbé Majẹmu Titun kalẹ lati mu Majẹmu Laelae ṣẹ nitori ti O ti ṣe eto Majẹmu Titun lati ipilẹṣẹ ayé. Gbese nla ti Majẹmu Titun beere ni o sún Jesu Oluwa lọ si Kalfari ti o si mu ki a fi I kọ sori igi agbelebu, pé nipa Ẹjẹ Rè̩ ti a ta silẹ ati Ẹmi Rè̩ ti O fi lelẹ, ki O le dá Majẹmu kan – ki i ṣe pẹlu awọn Ju nikan bí ko ṣe pẹlu gbogbo agbaye gẹgẹ bi ẹni kọọkan – nipa eyi ti wọn le báỌlọrun laja.

Ohun ti Majẹmu yii wà fun ni lati di ọgbun ti è̩ṣẹ fi ya ọmọ-eniyan nipá si Ọlọrun. Ohun kan ṣoṣo ti o le di ọgbun yii ni gbese ti Jesu san, Ẹjẹ ti O ta silẹ, ẹbọ ti O fi ara Rè̩ rú, Etutu ti O ṣe nipasẹ eyi ti gbogbo araye le báỌlọrun laja. Ohun rere ni péỌlọrun pèse ọna ti eniyan le gbà fi bori è̩ṣẹ ki o si báỌlọrun laja; leke gbogbo rè̩, ki a gbin ifẹ sinu ọkàn rè̩ -- ifẹ si Ọlọrun ati ifẹ si eniyan. Ofin ifẹ ni ofin titun ti ayé Oore-ọfẹ.

Ofin ati Oore-ọfẹ

Ọna ti Ofin fi beere igbọran kànnpá. “Ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mọ, ti o si rúọkan, o jẹbi gbogbo rẹ” (Jakọbu 2:10). “Iwọ kò gbọdọ” ni aṣẹ Ofin duro lori; awọn Ọmọ Israẹli ké̩kọọ nipa awọn aṣẹ wọnyi péè̩ẹṣẹ buru jai (Romu 7:13) S̩e e tabi ki o kú ni ẹmi ofin.

“Bi Mose si ti gbé ejò soke li aginjù, gẹgẹ bḝli a kò le ṣe alaigbéỌmọ-enia soke pẹlu: ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ, ki o má ba ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun” (Johannu 3:14, 15). Awọn Ọmọ Israẹli ti n kú lọ ni aginjù wo ejò idẹ, wọn si yè. Bakan naa ni awọn ẹlẹṣẹ ti n kú lọ le wo ỌmọỌlọrun ti a fi kọ sori igi agbelebu ki wọn si ri iye; nitori naa wo o ki o si ye ni ọrọ akọmọna Ihinrere. “Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kóè̩ṣẹ aiye lọ!” (Johannu 1:29).

Ọpọlọpọ ninu ilana Ofin, bi wọn ti ga to o nì, kò dé odiwọn ti Jesu fi lelẹ. Ofin jé̩ ojiji nnkan rere ti n bọ, nigba ti è̩kún imọlẹ Ihinrere Jesu Kristi bé̩ yọ, ojiji para dà. Ofin wi pe, “Oju fun oju, ati ehin fun ehin” ṣugbọn Jesu paṣẹ pe, “Ẹnikẹni ti o ba gbáọ li ẹrẹkẹọtún, yi ti òsi si i pẹlu” (Matteu 5:39). Ofin wi pe, “Iwọ ko gbọdọṣe panṣaga” ṣugbọn Jesu beere ohun ti o ju eyi lọ: “Emi wi fun nyin, ẹnikẹni ti o ba wò obirin kan lati ṣe ifẹkufẹ si i, o ti bá a ṣe panṣaga tan li ọkàn rè̩” (Matteu 5:28). “Ẹnyin ti gbọ bi a ti wi fun awọn ará igbāni pe, Iwọ ko gbọdọ pania; ẹnikẹni ti o ba pania yio wà li ewu idajọ. S̩ugbọn emi wi fun nyin, ẹnikẹni ti o binu si arakunrin rè̩ lasan, yio wà li ewu idajọ; ati ẹnikẹni ti o ba wi fun arakunrin rè̩ pe, Raka, yio wà li ewu ajọ awọn igbimọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba wipe, Iwọ aṣiwere, yio wà li ewu ináọrun apadi” (Matteu 5:21, 22).

Ayẹwo ẹkọỌrọỌlọrun yoo fi hàn fun ni pe a fi ẹsẹ awọn Ofin Mẹwaa ti Majẹmu Laelae mulẹ ninu Majẹmu Titun ni ọna ti o ga ju ti Majẹmu Laelae lọ, afi Ofin Kẹrin nikan. A kò le ri ibi kan ninu Majẹmu Titun ti a gbé fi idi ofin nipa Ọjọ Isinmi awọn Ju mulẹ.

Ariyanjiyan

O ṣoro fun awọn Ọmọ Israẹli lati gbagbọ pe Ọlọrun wọn ki i ṣe ojuṣaaju eniyan. Pupọ ninu awọn Farisi ati diẹ ninu awọn ti o di Onigbagbọ ni igba ayé awọn Apọsteli, ni ero pe igbala wá lati ọdọ awọn Ju o si wa fun awọn Ju nikan. Wọn n wo awọn eniyan ti ki i ṣe Ju bi keferi, ti kò ni ireti ninu ayé yii tabi ninu ayé ti n bọ, a fi bi wọn ba di Ju ki wọn si pa Ofin Israẹli mọ. “Awọn kan ti ẹya awọn Farisi ti nwọn gbagbọ dide, nwọn nwipe, a ni lati kọ wọn ni ilà, ati lati paṣẹ fun wọn pe ki nwọn ki o mā pa ofin Mose mọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 15:5).

Paulu ati Barnaba ti i ṣe ikọ Ihinrere si awọn Keferi kò fara mọ irúẹkọ bẹẹ rara, nitori ti wọn ti ri ogunlọgọ awọn Keferi ti n fi tọkàntọkàn tọỌlọrun wá ni ironupiwada tootọ ti wọn si ti ni iyipada ọkàn ni idahun si adura wọn. A mu ọrọ yii lọ si Jerusalẹmu ki awọn alagba ati awọn Apọsteli le yanju rè̩.

Ẹmi ti n Tọni

Nipasẹ itọni Ẹmi Mimọ, awọn Apọsteli ati awọn alagba ri i pe a ti mu Ofin ṣẹ ninu Kristi, nitori naa Ofin ti ká kuro. “Awa ti gbọ pe, awọn kan ti o ti ọdọ wa jade lọ fi ọrọ yọ nyin li ẹnu, ti nwọn nyi nyin li ọkàn po, wipe, Ẹnyin kò gbọdọṣaima kọ ilà, ati ṣaima pa ofin Mose mọ: ẹniti awa kò fun li aṣẹ: ... Nitorina awa rán Juda on Sila, awọn ti yio si fi ọrọẹnu sọ ohun kanna fun nyin. Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ, ati loju wa, ki a máṣe di ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ; ki ẹnyin ki o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu è̩jẹ ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere” (Iṣe Awọn Apọsteli 15:24, 27-29). Wọn fi ohùn ṣọkan pe ikọlà ki i ṣe ọranyan. Wọn kò sọrọ nipa yiya awọn ọjọ ase si mimọ, tabi pipa oṣu titun mọ, tabi Ọjọ Isinmi, wọn kò tilẹ sọrọ kan ẹran jijẹ tabi wiwà lai jẹẹran yatọ si pe ki wọn máṣe jẹẹran ti a pa bọ oriṣa.

“Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni māṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi: Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ: ṣugbọn ti Kristi li ara” (Kolosse 2:16, 17).

“Ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ kan jù omiran lọ: ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ gbogbo bakanna. Ki olukuluku ki o da ara rè̩ loju ni inu ara rè̩. Ẹniti o ba nkiyesi ọjọ, o nkiyesi i fun Oluwa; ẹniti kò ba si kiyesi ọjọ, fun Oluwa ni kò kiyesi i. Ẹniti njẹun, o njẹun fun Oluwa, nitori o ndupẹ lọwọỌlọrun; ẹniti kò ba si jẹun, fun Oluwa ni kò jẹun, o si ndupẹ lọwọỌlọrun” (Romu 14:5, 6). “Nisisiyi a fi wa silẹ kuro ninu ofin, nitori a ti kú si eyiti a ti dè wa sinu rè̩: ki awa ki o le mā sìn li ọtun Ẹmi, ki o máṣe ni ode ara ti atijọ” (Romu 7:6). Eyi jé̩ diẹ ninu awọn ẹsẹỌrọỌlọrun ti o fi hàn wá bi Otitọ ninu Jesu Kristi ti kò le yi pada ti dipo Ofin Mose.

Ta ni yanju ọrọ naa? “O dara loju Ẹmi Mimọ, ati loju wa.” Ẹmi Ọlọrun dari awọn ti o wà ni igbimọ -- wọn wà ni ọkàn kan – O si mí si wọn lati ṣe ipinnu gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe ilana rè̩ lati ipilẹṣẹ ayé.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Awọn wo ni ẹlẹsin lọna ti awọn Ju gba gbé e kalẹ? Ki ni ẹkọ wọn?
  2. Ki ni ṣe ti Paulu ati Barnaba fi lodi si wọn?
  3. Ẹkọ wo ni Paulu ati Barnaba n waasu rè̩?
  4. Bawo ni a ṣe yanju ọrọ naa?
  5. Ki ni Peteru sọ si ọrọ naa?
  6. Iranwọ wo ni Paulu ati Barnaba ṣe lati mu ki ọrọ naa ki o ni iyanju?
  7. Ta ni o kasẹọrọ awọn Igbimọ nilẹ?
  8. Ki ni abayọrisi awọn Igbimọ naa?