Iṣe Awọn Apọsteli 16:9-40

Lesson 334 - Senior

Memory Verse
“Awa si mọ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹỌlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rè̩” (Romu 8:28).
Cross References

I Ipè Paulu si Makedonia

1. Ni oju iran, Paulu ri ọkunrin kan ti o wi pe: “Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ,” Iṣe Awọn Apọsteli 16:9

2. Paulu ati Sila wọọkọ lọ si Makedonia, wọn si ṣe isin kan lẹba odò kan, Iṣe Awọn Apọsteli 16:10-13

3. Lidia ṣe aajo Paulu ati Sila, Iṣe Awọn Apọsteli 16:14, 15; I Timoteu 5:10; Heberu 6:10

II Obinrin Ẹlẹmi Eṣu kan Mu Ki Paulu Kẹdun

1. O múère pupọ wá fun oluwa rè̩ nipa afọṣẹ rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 16:16

2. O tẹle Paulu o si kigbe pe, “Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹỌlọrun Ọgá-ogo”, Iṣe Awọn Apọsteli 16:17

3. Paulu léẹmi eṣu naa jade kuro ninu rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 16:18

4. Awọn oluwa rè̩ binu nitori igbẹkẹle èrè wọn pin, wọn si dawọle Paulu ati Sila lati mú wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 16:19

III A Lu Wọn a si Fi Wọn si Tubu nipa Aṣẹ Awọn Onidajọ

1. A múẹsùn Paulu ati Sila wa si iwaju awọn onidajọ, Iṣe Awọn Apọsteli 16:20, 21

2. Awọn onidajọ fa aṣọ Paulu ati Sila ya wọn si paṣẹ pe ki a lù wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 16:22, 23

3. A sọ wọn sinu tubu ti inu lọhun, Iṣe Awọn Apọsteli 16:24

IV Adura, Iyin, ati Isẹlẹ nla

1. Isin adura ati orin-iyin bẹrẹ bi o tilẹ jẹ pe a kan àbà mọ wọn ni ẹsè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 16:25

2. Isẹlẹ nla kan sè̩, awọn ilẹkun tubu ṣi, ìde awọn onde si tú, Iṣe Awọn Apọsteli 16:26

3. Onitubu gbiyanju lati pa ara rè̩ṣugbọn Paulu dá a lẹkun, Iṣe Awọn Apọsteli 16:27, 28

4. Onitubu ati ara ile rè̩ ri igbala, a si ṣe itọju awọn onde naa, Iṣe Awọn Apọsteli 16:29-40

Notes
ALAYE

Irin-Ajo Paulu Ẹẹkeji

Ni akoko ẹkọ wa yii, Paulu wà lori irin-ajo rè̩ keji. O ti bẹọpọlọpọ ilu wò nibi ti oun ati Barnaba ti waasu Ihinrere ti wọn si ti dá ijọ silẹ ni irin-ajo wọn ekinni. Barnaba kò bá Paulu lọ ni igba keji yii, ṣugbọn o lọ si Kipru ilu rè̩. Paulu mú Sila lọ gẹgẹ bi alabaṣiṣẹpọ rè̩. Lẹyin ti o si ti bẹ awọn ilu ti wọn dé ni iṣaaju wò tán, o lọ si Siria ati Kilikia o n fi ẹsè̩ ijọ mulẹ. Lẹyin naa awọn mejeeji lọ si iha ariwa ati iwọ-oorun si Galatia ati Misia. Paulu ti pinnu lati lọ si iha oke si ilu Bitinia, ṣugbọn Ẹmi Oluwa kọ fún un, nitori naa wọn lọ si Troasi, nibẹ ni Paulu ti ri iran ti o dari rè̩ kuro ni Asia lọ si Europe.

Ipè Lati Makedonia

Nigba meji ọtọọtọ ni Ẹmi Ọlọrun kọ fun Paulu lati tè̩ siwaju lọ si Asia, boya o wá si Troasi ti o si n woye ninu ọkan rè̩ ibi gan an ti Oluwa fé̩ ki oun lọ. S̩ugbọn Ọlọrun kò fi i silẹ ninu iyemeji pé̩ titi. O ri iran kan ni oru; ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si n bè̩ẹ wi pe, “Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ.” Oluwa mọ péọpọlọpọọkàn ni o wa ni ilu Griki ti wọn ṣe tán lati gba Ihinrere. Lati igbaani titi di isisiyi ni ipe “Makedonia” ti n dún ni eti igbọọpọlọpọ awọn iranṣẹỌlọrun lati rú ifẹ wọn soke.

O daju pe Ẹmi Mimọ ni o n tọ iṣisẹ awọn ojiṣẹỌlọrun wọnyi lọ si Europe. Eyi ṣẹlẹ ni nnkan bi ẹgbaa ọdun sẹyin, sibẹsibẹẸmi Mimọ kò tii dẹkun lati maa tọ iṣisẹ awọn iranṣẹỌlọrun tootọ ati awọn alakoso lode oni.

Saa miiran fẹrẹ bẹrẹ ninu iṣẹ-iranṣẹ Paulu. Ipè ti o jade lati Makedonia wá yii fi hàn pe ogunlọgọọkàn ni ilu naa ni oungbẹỌrọỌlọrun n gbẹ, ọkàn wọn si ṣe tán lati gba Ihinrere.

Awọn Onigbagbọ Kin-in-ni ni Ilẹ Awọn Alawọ funfun

Awọn iranṣẹỌlọrun kin-in-ni si ilẹ awọn alawọ funfun mú irin-ajo wọn pọn lọ si ilu Filippi ti i ṣe olu-ilu awọn ilu ti ó wà ni iha ihin yii. Lai si aniani, awọn Ju kò pọ nibẹ. S̩ugbọṅ ni Ọjọ Isinmi kin-in-ni, Paulu ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ wà lẹyin odi ilu lẹba odo kan nibi ti awọn eniyan ti maa n gbadura. Nibẹ ni awọn obinrin diẹ pejọ pọ si; diẹ ninu wọn jé̩ Ju awọn diẹ si jé̩ alawọṣe Ju.

Paulu ati Sila joko wọn si bá awọn obinrin naa sọrọ. Gẹgẹ bi ibi ti wọn gbe wà yii ti ri, o daju pe isin ránpẹ lasan ni wọn ṣe, ṣugbọn obinrin kan wà nibẹ ti ebi ỌrọỌlọrun n pa. O ṣi ọkàn rè̩ payá si otitọ. Oun ni ẹni kin-in-ni ti o kọ gba Ihinrere lẹyin ti Paulu gbọ ipè ti o jade si i ni Makedonia. Oun ati awọn ara ile rẹ tẹwọ gba Ihinrere Majẹmu Titun. O ni lati jé̩ pé Paulu mẹnu ba ẹkọ iribọmi ninu iwaasu rè̩ ni owurọọjọ naa nitori ti a ṣe iribọmi fun Lidia ati awọn ara ile rè̩. Lẹsẹkẹsẹ ni Lidia pinnu pé awọn iranṣẹỌlọrun wọnyi ni lati wọ si inu ile oun. O rọ wọn to bẹẹ ti wọn fi gbà lati wọ sibẹ. O fi tọkàntọkàn gba Ihinrere, o si n mu ofin ifẹ ti Jesu kede rè̩ṣẹ -- ifẹ si awọn iranṣẹỌlọrun ati awọn eniyan Rè̩ -- o si n to iṣura ipilẹ rere jọ fun ara rè̩ di igbà ti n bọ (1 Timoteu 6:19). Bibeli sọ bayii pé: “Ẹ máṣe gbagbé lati māṣe alejò; nitoripe nipa bḝ li awọn ẹlomiran ṣe awọn angẹli li alejò laimọ” (Heberu 13:2).

Awọn Inunibini

Iṣẹ awọn iranṣẹỌlọrun yii kò le maa lọ geere bẹẹ lai si idojukọ. Eṣu gbọn ninu ọgbọn arekereke rè̩ bi o ti n sa ipa rè̩ lati bi iṣẹ Oluwa wó. Nigba pupọ a maa fi èké pamọ sabẹ otitọ lati fi tan ọmọ-eniyan jẹ. Ọdọmọbinrin kan bẹrẹ si i tẹle Paulu ati Sila, o si n kigbe wi pe, “Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹỌlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọna igbala fun nyin” (Iṣe Awọn Apọsteli 16:17). Otitọ ni o n sọ, ṣugbọn ẹri ẹlẹmi eṣu kò le mu ẹnikẹni duro. Eṣu ni o n gba ẹnu rè̩ sọrọ, lai si aniani, ohun ti o fẹṣe ni pe ki o pokiki Apọsteli Paulu ati ẹlẹgbẹ rè̩ lati gbé wọn lé ayé lọwọ ki o ba le gba ọna yii ṣe idena iṣẹ ti Ọlọrun n ti ọwọ wọn ṣe. Ọna ti o gbà sọọ ni o mu ki inu Paulu bajẹ. Iru ẹmi kan naa ni o wà ninu ẹlẹmi eṣu ara Gadara nì nigba ti o ri Jesu.

Ofin paṣẹ pe: “Máṣe yipada tọ awọn ti o ni imọ afọṣẹ, bḝni ki o má si ṣe wá ajé̩ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jé̩: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin” (Lefitiku 19:31). Ọlọrun kọ fun ni lati ni ohunkohun lati ṣe pẹlu awọn ti n bá iwin gbimọ pọ, ẹmi abokulo, tabi awọn alafọṣẹ. Ọlọrun korira rè̩, nitori pe lati ọdọ eṣu ni o ti wá. Ẹṣè̩ ni fun ẹnikẹni lati lọ wadii ohun wọnni ti Ọlọrun kò fi aṣiiri rè̩ hàn fun ni, lọdọ awọn alafọṣẹ tabi abokulo; iwa bẹẹ jé̩ abuku si ọgbọn Ọlọrun. Ninu aanu nla Rè̩, Ọlọrun fi pupọ ninu ohun ti yoo ṣẹlẹ ni ọjọọla pamọ fun ẹda, O si fi ireti dipo rè̩.

Paulu léẹmi aimọ naa jade kuro lara obinrin naa, eyi si fa ibinu awọn oluwa rè̩. Ọna lati maa mu u lo lati ri owó gbà nipa afọṣẹ rè̩ dopin. Nitori naa wọn mú Paulu ati Sila lọ siwaju awọn onidajọ. Awọn onidajọ gbọẹsun ti a kà si Paulu ati Sila lọrun, ṣugbọn wọn kòṣe iwadii ọrọ lẹnu wọn -- eyi lodi si àṣà ilẹ Romu. Lẹyin ti wọn ti lù wọn pupọ, wọn sọ wọn sinu tubu, wọn si tẹẹ mọ awọn onitubu leti lati pa wọn mọ daradara; onitubu pẹlu si sọ awọn eniyan Ọlọrun wọnyi sinu tubu ti inu lọhun, o si kan àbà mọ wọn li ẹsè̩.

Adura ati Isin Ọpẹ

Ki i ṣe ohun ti o rọrun lati maa kọrin nigba ti idanwo wa bá dé ogogoro. Nigba pupọ a da bi ẹnipe ẹrù naa wuwo ju eyi ti ẹnikan le rù lọ. S̩ugbọn Jesu ti ṣeleri pe Oun yoo bá wa gbéẹrù wúwo wa. Paulu ati Sila gbadura, wọn si kó aniyan wọn le Ọlọrun lọwọ nitori ti O wi pe, “Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọọ silẹ.” Bi wọn ti n gbadura, ayọ kun ọkàn wọn to bẹẹ ti wọn bẹrẹ si kọ orin iyin si Ọlọrun.

Awọn onde iyoku gbọ orin ayọ wọn. Wò bi ẹnu yoo ti ya awọn onde tó nigba ti wọn taji ti wọn si n gbọ adura ati orin lẹnu awọn ti a fi abà si lẹsẹ lẹyin ti a ti lú wọn ni ilukilu ti ara wọn si n ṣẹjẹ. Kò ni jé̩ ohun iyanu fun awọn onde bi wọn ba gbọ iro gbingbin ati èpè kikankikan, ṣugbọn adura ati orin kikọ jé̩ ohun ti wọn kò ni ìreti lati gbọ. Adura ati orin iyin mú ki Ọrun paapaa boju wolẹ, ki O si tẹti si wọn. Lojiji isẹlẹ nla sè̩, ipilẹ ile tubu naa si mì tìtì. Lọgan gbogbo ilẹkun ṣi silẹ, ide olukuluku onde si tú. Irú eyi kòṣẹlẹ ri ni ile tubu ni ilu Filippi. Agbára Ọlọrun pọ to bẹẹ ti kò si ọkan ninu awọn onde ti o gbiyanju lati salọ.

Igbala Onitubu

Isẹlẹ naa ta onitubu ji, lẹsẹkẹsẹó fò dide lori akete rè̩, o ri i pe awọn ilẹkun ile tubu ṣi silẹ. “Gẹgẹ bi ofin ilẹ Romu, onitubu ti arufin ba sa mọ lọwọ nipa ilọra, yoo ru iya ti awọn arufin naa ni lati jẹ.” Nigba pupọ ni awọn onitubu yoo pa ara wọn kaka ki a pa wọn lati ọwọ awọn alaṣẹ. Ni ireti pe awọn onde wọnyi ti salọ, onitubu yii fa idà yọ lati pa ara rẹ. Bi o tilẹ jé̩òru ọganjọ ni, ti okunkun si bolẹ, imọlẹ diẹdiẹ ti n wọle lati ẹnu ọna ti o ṣi silẹ mú ki Paulu ri ohun ti onitubu naa fẹṣe, o si kọ kàrá si i wi pe, “Máṣe pa ara rẹ lara: nitori gbogbo wa mbẹ nihinyi.”

Idalẹbi wọ inu ọkàn onitubu. Ọkàn rè̩ n fé̩ irú igbala ti Paulu ati Sila ni. O beere iná, pẹlu iwariri o wolẹ niwaju awọn eniyan Ọlọrun. Nigba naa ni o mú Paulu ati Sila jade o si wi pe, “Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le là?” Paulu kò ni ṣalai ranti wàyii igba ti oun paapaa n ṣe inunibini si awọn Onigbagbọ. Oluwa mú Paulu ni ọna ajo rè̩ si Damasku o si kigbe wi pe, “Oluwa, kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe?” (Iṣe Awọn Apọsteli 9:6).

Idahun Paulu si ibeere onitubu naa kò le: “Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ, a o si gbàọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu.” Ọkan onitubu yii gbọgbẹ gidigidi nitori è̩ṣẹ ti o ti n dá, ọkàn rè̩ si wà ni ipò ti o fi le gbagbọ lati odo ọkàn rè̩. Igbagbọ atọkànwa -- igbagbọ ti o lọ pẹlu igbọran si gbogbo aṣẹỌlọrun – eyi ni o n fun ni ni iriri atunbi. Ogunlọgọ eniyan ni o n fi ọgbọn ori gba otitọỌrọỌlọrun gbọ ti wọn si n lero pe wọn ti ri igbala, ṣugbọn eyi nikan kò le mu ìbí titun wa. ỌrọỌlọrun sọ pe, “Bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun ji i dide kuro ninu okú, a o gbàọ là. Nitori ọkàn li a fi igbagbọ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala “ (Romu 10:9, 10).

Alẹọjọ yii kòṣee gbagbe! Lakọkọ ipade adura, lẹyin naa orin, isẹlẹ, igbala onitubu ati awọn ara ile rẹ, wiwẹọgbé̩ Paulu ati Sila, isin iribọmi, lopin rè̩, àse nla nibi ti olukuluku n yọ ti wọn si n yin Ọlọrun logo fun igbala nla Rè̩.

Eyi ni ogun kin-in-ni nipa ti ẹmi ati iṣẹgun kin-in-ni ti awọn ojiṣẹỌlọrun meji, ti ijọ akọkọbè̩rẹ wọnyi ni fun Ọlọrun lori ilẹ awọn alawọ funfun. Ilẹ awọn alawọ funfun di papa ogun laaarin agbára Satani ati agbára Kristi. Ogun naa si n lọ lọwọlọwọ, ṣugbọn ọjọ kan n bọ nigba ti gbogbo awọn ajẹriku yoo duro ni iṣẹgun lori ilẹ yii lati gbé asia Jesu Kristi ọba wọn soke. Ọjọ Ologo!

Ni ọdun mẹwaa lẹyin eyi, Paulu kọ Episteli si awọn ara Filippi, nibi ti o gbé sọ nipa irú ifẹ nla ti o ni si Lidia ati awọn ará ile rè̩, ati fun onitubu nì ati awọn ara ile rè̩ ati fun gbogbo awọn ti a gbala ni Filippi. Ohun ti o sọ ni eyi:

“Mo dupẹ lọwọỌlọrun mi fun gbogbo iranti nyin ti mo nṣe,

Nigbagbogbo ninu gbogbo adura mi fun nyin li emi nfi ayọ bè̩bẹ,

Nitori idapọ nyin ninu ihinrere lati ọjọ ekini wá titi fi di isisiyi;

Ohun kan yi sa da mi loju, pe ẹniti o ti bè̩rẹ iṣẹ rere ninu nyin, yio ṣe aṣepe rè̩ titi fi di ọjọ Jesu Kristi:

Gẹgẹ bi o ti tọ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere.

Nitori Ọlọrun li ẹlẹri mi, bi mo ti nṣafẹri nyin to gidigidi ninu iyọnu Jesu Kristi.”

“Nitorina, ẹnyin ará mi olufẹ, ti mo si nṣafẹri gidigidi, ayọ ati ade mi, ẹ duro ṣinṣin bḝ ninu Oluwa, ẹnyin olufẹ mi” (Filippi 1:3-8; 4:1).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni a n pè ni ipè Makedonia?
  2. Nibo ni a ti kọ waasu Ihinrere ni ilẹ awọn alawọ funfun?
  3. Ta ni alawọ funfun kin-in-ni ti o di Onigbagbọ?
  4. Ki ni ṣe ti wọn fi gbé Paulu ati Sila jù sinu tubu?
  5. Ki ni Bibeli sọ nipa afọṣẹ?
  6. Ta ni o fun awọn abokulo ni agbára wọn?
  7. Sọ bi onitubu nìṣe ri igbala.
  8. Ki ni iṣẹ ti awọn onidajọ rán si Paulu ati Sila ni ọjọ keji?
  9. Ki ni idahun Paulu si iṣẹ onidajọ?
  10. Darukọ nnkan mẹjọ pataki ti o ṣẹlẹ loru nigba ti Paulu ati Sila wa ninu tubu.