Lesson 335 - Senior
Memory Verse
“Wère li ọrọ agbelebu si awọn ti o nṣegbé; ṣugbọn si awa ti a ngbalà, agbara Ọlọrun ni” (1 Kọrinti 1:18).Cross References
I Ni Tẹssalonika
1. Ẹgbé̩ awọn ajihinrere gba ilu kékèké meji kọja lọ si Tẹssalonika ati sinagọgu kan, Iṣe Awọn Apọsteli 17:1
2. Paulu waasu ninu sinagọgu pe Jesu ni Kristi naa, Iṣe Awọn Apọsteli 17:2, 3; 9:20
3. Diẹ ninu awọn Ju ati ọpọ awọn Helleni gbàgbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 17:4; 1 Tẹssalonika 2:13, 14
4. Awọn Ju ti o kún fún owú dá rúkèrúdò silẹ ni ilú, Iṣe Awọn Apọsteli 17:5-9
II A Té̩wọ Gbà Wọn ni Berea
1. A rán Paulu ati Sila jade kuro ni Tẹssalonika loru, wọn si wá si Berea, Iṣe Awọn Apọsteli 17:10; 9:23-25; Matteu 10:23
2. Awọn ara Berea fi tayọtayọ gba ỌrọỌlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 17:11, 12; Matteu 13:16; Jakọbu 1:19
3. Awọn Ju lati Tẹssalonika wá si Berea lati rú awọn eniyan soke, Iṣe Awọn Apọsteli 17:13, 14
III Paulu ni Atẹni
1. Ọkan Paulu dàru nitori ibọriṣa ni Atẹni o si bá awọn eniyan naa fi ọrọ wéọrọ, Iṣe Awọn Apọsteli 17:15-17
2. Awọn ọjọgbọn kan mú Paulu lọ si iléẹjọ, Iṣe Awọn Apọsteli 17:18-21
3. Paulu sọ otitọ pataki nipa ti Ọlọrun pe Oun nikan ni Ọlọrun alaaye ati otitọ, Iṣe Awọn Apọsteli 17:22, 23
4. Awọn ti o ba n sin Ọlọrun ni lati sin In ni ẹmi ati ni otitọ, Iṣe Awọn Apọsteli 17:24-29; Johannu 4:23, 24
5. Ọlọrun paṣẹ fun gbogbo eniyan lati ronupiwada, Iṣe Awọn Apọsteli 17:30, 31; Johannu 12:46-48; 2 Timoteu 4:1
6. Iṣẹ-iranṣẹ Paulu múèso diẹ jade ni Atẹni, Iṣe Awọn Apọsteli 17:32-34
Notes
ALAYEAwọn OjiṣẹỌlọrun
Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe, “Nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yii, ẹ sá lọ si omiran” (Matteu 10:23). Dajudaju, Paulu Apọsteli tẹle aṣẹ yii. Ni irin-ajo keji yii, Paulu ati Sila lọ si Makedonia nitori pe Ẹmi Ọlọrun dari wọn lọ sibẹ. Ni Filippi ti i ṣe olu-ilu Makedonia, awọn ọkàn ti ebi n pa fi ayọ gba ỌrọỌlọrun, ṣugbọn awọn onidajọ ati pupọ ninu awọn eniyan ibẹ n fé̩ ki awọn eniyan Ọlọrun wọnyi jade kuro ni ilu wọn. Bi o tilẹ jẹ pé Paulu ati Sila ti bá inunibini pupọ pade ni Filippi, Paulu mọ pé ohun kan wà ti o mú ki Ọlọrun pé wọn lọ sibẹ.
Lẹyin ti wọn ti kuro ni Filippi, awọn iranṣẹỌlọrun wọnyi gba Amfipoli ati Apollonia kọja, ki wọn ba le de Tẹssalonika nitori pe sinagọgu awọn Ju wà nibẹ. Gẹgẹ bi iṣe rè̩, nigbakuugba ti o ba wọ ilu bẹẹ, Paulu a maa lọ si sinagọgu a si maa ba wọn fi ọrọ wéọrọ lati inu Iwe Mimọ. Koko iwaasu Paulu duro lori Kristi, tabi Messia, Ẹni ti gbogbo awọn Ju ti n reti. Paulu fi han lati inu Iwe Mimọ pe Kristi kò le ṣaima jiya, ki O si kú lori agbelebu nitori è̩ṣẹ gbogbo agbaye, ki O si jinde fun idalare awọn ti o gba A gbọ. Diẹ ninu awọn Ju ti o wà ni Tẹssalonika gba Ọrọ ti Paulu sọ gbọ, ṣugbọn pupọ ninu awọn olufọkànsin Hellene ati awọn obinrin ọlọlá gbọọrọ wọn.
Ijọ Tẹssalonika
Bi o tilẹ jẹ pe ọsẹ mẹta pere ni a gba Paulu ati Sila laaye lati sọỌrọỌlọrun lai si idena ni ilu Tẹssalonika, sibẹỌrọỌlọrun fidi mulẹ ninu ọkàn awọn ti o gbagbọ. Nigbooṣe nigba ti Paulu n kọwe si awọn eniyan wọnyi ati ijọ ti a da silẹ lati ọwọ wọn, Paulu rán wọn leti bi wọn ti yi pada kuro ninu ibọriṣa lati maa sin Ọlọrun alaaye ati otitọ ati bi wọn ti n fojusọna fun ipadabọ Jesu lẹẹkeji. Paulu sọ bi ỌrọỌlọrun ti dún jade lati ọdọ awọn eniyan wọnyi, ki i ṣe ni kiki Makedonia ati Akaia nikan, ṣugbọn ni “ibi gbogbo ni ihin igbagbọ nyin si Ọlọrun tàn kalẹ” (Wo 1 Tẹssalonika 1:8-10).
“Satani si wá pẹlu.” Lati atetekọṣe ni èṣu ti maa n fara hàn nigbakugba ati nibikibi ti a ba gbé n tan Ihinrere kalẹ ti a si n sọrọ ododo Ọlọrun. Eyi ri bẹẹ nipa isin Igbagbọ nitori pe eṣu a maa fi gbogbo agbara rè̩ jà lati dojukọ Ijọba Kristi lati igba ti o ti bẹrẹ. Eṣu mọ pé Kristi ati Ijọba Rè̩ ni yoo bori Satani ati awọn ẹmẹwa rè̩ titi ayeraye. Jesu sọ pe, “Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi” (Matteu 28:18). Bi o tilẹ jẹ pe iṣẹ Kristi ni idojukọ lainidi nigba miiran, Ọlọrun ri i, O si mọ. Ni akoko ti Rè̩ ati ni ọna ti Rè̩, Oun yoo fi opin si idojukọ, iṣẹ Rè̩ yoo si maa gbèrú bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.
Inunibini
Ni Tẹssalonika, awọn Ju ti kò fé̩ gba otitọỌrọỌlọrun gbọ bẹrẹ si jowu aṣeyọri Paulu ati Sila laaarin awọn eniyan naa. Awọn Ju wọnyi fa awọn jagidijagan ati ijajẹ eniyan mọra, wọn dá rúkèrúdò silẹ, wọn si da ilu rú. Wọn wá Paulu ati Sila ni ile Jasoni; ṣugbọn nigba ti ọwọ wọn kò tẹ awọn ojiṣẹỌlọrun wọnyi nibẹ, wọn wọ Jasoni ati awọn arakunrin kan tọ awọn olori-ilu lọ. Ẹsun wọn: “Awọn wọnyi ti o ti yi aiye po wá si ihinyi pẹlu” (Iṣe Awọn Apọsteli 17:6). Eṣu paapaa ni o ti dori aye kodo ni ọdun pupọṣaaju nigba ti o sún eniyan lati dẹṣẹ; ṣugbọn nisisiyii o fẹ di ẹbi naa le ẹlomiran lori. Nitootọ awọn Apọsteli n yi ayé po; ṣugbọn ohun ti wọn n ṣe nipa agbára Ọlọrun ni pe wọn n gbé ori ayé ti eṣu ti dà kodò soke gẹgẹ bi o ti wà tẹlẹ ri. Lati atetekoṣe ni Ihinrere ti maa n fi ayọ sinu ọkàn ti o ti daru – a si maa mú ki idakẹrọrọ dé si ọkàn ti ijì ayé n gbá kiri; o n fi isinmi fun awọn ti n ṣíṣẹ ti è̩ṣẹ si di ẹrù wuwo le lori; o ti fi ilera fun ara ati ọkàn ti è̩ṣẹ n pa kú lọ nigba ti wọn ba wá sọdọ Olugbala pẹlu ijọwọ ara ẹni lọwọ lọ.
Awọn Ju ti o wà ni Tẹssalonika dá irukerudo silẹ jakejado gbogbo ilu, wọn si di ẹbi rè̩ ru awọn iranṣẹỌlọrun wi pe, awọn ni o da ilu rú ti wọn si n dori ayé kodò. Wọn jẹwọ pe awọn n fi ọla fun ijọba Kesari wọn si kọwọ ti i, ṣugbọn ni otitọ gan an, gbogbo awọn Ju ni o korira lati wà labẹ akoso ajeji. Ẹbi ati idalẹbi è̩ṣẹ jé̩ọmọìyá rikiṣi ti o maa n pa ọtá meji pọ ti wọn si n di ọré̩ apapandodo. Iwa ati iṣe eniyan kò ti i yi pada pupọ si ti igba awọn ara Tẹssalonika yii, nitori pe awọn eniyan kò ti i ṣiwọ lati maa ṣe awawi eredi rè̩ ti wọn kò fi sin Jesu Kristi. Eṣu ati awọn alaigbagbọ ti o wà ninu ayé n sa gbogbo ipá wọn lati fi hàn pe Onigbagbọ ati igbagbọ rẹ kò lẹsẹ nilẹ; ṣugbọn bi wọn ti n ṣe inunibini si awọn Onigbagbọ tó, bẹẹ ni imọlẹ Ihinrere n tàn siwaju ati siwaju ti ẹwa Ihinrere si n fi ara hàn jù bẹẹ lọ. Ẹsun èké pupọ ni a ti fi sun ẹsin Igbagbọ, ṣugbọn kò si ọkan ninu awọn ẹsun naa ti o ti fidi mulẹ. Awọn olori-ilu gbàògò lọwọ Jasoni ati awọn iyoku, wọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nitori ti kò si è̩ṣẹ irufin kan ti a ká mọ wọn lọwọ.
Wiwá Inu Iwe Mimọ
Lọgan, ni òru, awọn arakunrin rán Paulu ati Sila lọ si Berea nibi ti sinagọgu miiran gbé wà. Awọn ara Berea yatọ lọpọlọpọ si awọn ará Tẹssalonika ti o ṣe inunibini si awọn iranṣẹỌlọrun. Iru awọn ará Berea ṣọwọn ni ayé titi di onioloni. Awọn eniyan wọnyi fi tọkàntọkàn gba ỌrọỌlọrun, wọn si n wá inu Iwe Mimọ lojoojumọ lati mọ bi nnkan ti Paulu ati Sila n waasu rè̩ ri bẹẹ tabi bẹẹkọ. Fifi ara balẹ kẹkọọ lati inu Bibeli lọnà bayii kò le ṣai mú ire wá, nitori pe Ihinrere Jesu Kristi yeje kò si ni aṣiiri ikọkọ ninu. Lai pẹ jọjọ, pupọ ninu awọn Ju ati Hellene, lọkunrin ati lobinrin, gba ihin otitọ naa gbọ pé Jesu ni Kristi naa. Kò si ẹnikan ni Berea ti o tako Ihinrere lọnàkọnà; ṣugbọn inu eṣu kò dùn si iru aṣeyọri nla ti o dé bá wọn ni Berea. Iroyin isọji ti o bé̩ silẹ ni Berea tàn dé Tẹssalonika, awọn eniyan buburu ilu naa si wá si Berea lati rú awọn eniyan sókè si awọn Apọsteli. Paulu ti i ṣe agbọrọsọ ati alakoso ẹgbé̩ awọn Onigbagbọ, ni wọn doju ija kọ; nitori eyi awọn arakunrin rán Paulu jade kuro ni ilu naa ṣugbọn Sila ati Timoteu duro lẹyin lati tubọ fi otitọẹkọ igbagbọ yé awọn ti o ṣẹṣẹ di Onigbagbọ wọnyii.
Ni Atẹni
Wọn fi Berea silẹ, wọn si sin Paulu dé Atẹni nibi ti o gbé ranṣẹ pe Sila ati Timoteu lẹsẹkẹsẹ. Bi Paulu ti n duro de awọn ẹlẹgbẹ rè̩ ni Atẹni, ọkàn rè̩ rú ninu rè̩ nigba ti o ri i pe ilu naa kún fún ibọriṣa. A sọ fun wa ninu awọn iwe itàn pe awọn oriṣa ti o wà ni Atẹni nikanṣoṣo pọ ju gbogbo oriṣa ti o wà ni ilẹ Hellene ni àpapọ -- è̩wè̩, o fẹrẹ jé̩ pé iye awọn oriṣa ti o wà ni Atẹni tó iye awọn ti o wà nibẹ. Eyi tayọ ohun ti Paulu le gboju fò dá; bi o si ti n duro de Sila ati Timoteu, o lọ sinu sinagọgu awọn Ju o si n ba wọn fi ọrọ wéọrọ nibẹ lojoojumọ ati pẹlu awọn ti n ba pade lọja lojoojumọ.
Ẹni ti n Ba Ẹni kọọkan Sọrọ
Ki i ṣe pé Paulu jé̩ ojiṣẹỌlọrun ati Ajihinrere nikan, o jé̩ẹni ti o n ba ọkàn kọọkan jiroro pẹlu – eyi si jé̩ọkan ninu ipè ti o ga julọ ati eyi ti o lere julọ ninu iṣẹỌlọrun. Biba ọkàn kọọkan jiroro jé̩ iṣẹ ti o mú ki Ijọ Kristi gbèrú pupọ, o si ṣe pataki gidigidi ni akoko ikẹyin ti okunkun bolẹ yii. Nigba kan ri ni o jé̩ wi pe ogunlọgọọkàn ni o n gba iriri atunbi nibi pẹpẹ adura ni akoko isọji ati ikede Ihinrere, ṣugbọn ni akoko yii, o fẹrẹ jé̩ pé gbogbo awọn ti o n wá sọdọ Kristi ni o wá nipasẹ awọn wọnni ti o bá wọn sọrọ nikọkọ. Paulu n lọ si ọja lojoojumọ lati sọỌrọỌlọrun fun gbogbo awọn ti o bá fé̩ gbọọrọ rè̩.
Oluwa Ase Alẹ Nla nì rán awọn iranṣẹ Rè̩ lọ si opopo ati abuja ọna lati pe awọn talaka, awọn alabuku àrùn, awọn amọkun ati awọn afọju; ati si gbangba ati kọrọ lati rọ awọn eniyan ki wọn ki o le wá sibi àse (Luku 14:16-23). Oluwa Ogo fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ Rè̩ lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ki wọn ki o maa pe awọn eniyan wá si ibi ase nla ti O ti pese silẹ. Adura wa ni pe ki Oluwa ki o le là wá loju lati mọ bi iṣẹ yii ti ṣe pataki ati bi o ti lere tó ninu ọgba ajara Rè̩. Ẹni ti o n ba tirè̩ lọ laaarin igboro, ọtaja, ọga ati awọn ọmọ-ọdọ nibi iṣẹ, aladugbo ati olukọni -- ẹnikọọkan ninu awọn wọnyi le fi tayọtayọ gba Ihinrere gẹgẹ bi ẹnikan ninu awọn iranṣẹỌlọrun ti n sọ ti ireti ati ayọ ti Ihinrere n fun ni fun awọn wọnyi.
Awujọ awọn Keferi
Lai pẹ iṣẹ ti Paulu bẹrẹ wẹrẹ yii ṣi anfaani ti o tobi silẹ fun un. Awọn olumọran kan ninu awọn Ẹpikurei ati Stoiki kó ti Paulu, wọn si fa a lọ si Oke Areopagu ti i ṣe ibi ijiyan ti o ga julọ ni Atẹni. Ni ibi ijiyan yii ni wọn yoo ti gbọẹkọ Jesu Kristi ti wọn o si ti pinnu boya wọn yoo gbàẹkọ naa láye ni ilu Atẹni tabi bẹẹkọ, nitori awọn ara Areopagu a maa sọ ohun ti ero wọn jẹ nipa olukuluku ẹsin titun ti a ba mu wọ ilu Atẹni.
Imọ awọn Ẹpikurei ati awọn Stoiki dọgba lori nnkan diẹ, ṣugbọn lori nnkan pupọ ni wọn lodi si ara wọn gidigidi. Awọn ẹgbẹ mejeeji wọnyi kò ni igbagbọ si ajinde lẹyin ikú; lai si aniani, iwaasu Paulu nipa ajinde Jesu ati ireti IjọỌlọrun mú ki awọn ẹlẹgan wọnyi kó ti Paulu. Ohun rere kan ti a ri lara awọn ara Atẹni ni pe wọn n fẹ lati gbọỌrọỌlọrun ṣaaju ki wọn to ṣe idajọ le e lori. Pupọ ninu awọn eniyan ti ode-oni ni n sọ ohun ti wọn fẹ nipa Ihinrere ti wọn si n ṣe idajọèké nipa ihinrere lai mọ ohunkohun nipa agbára rè̩ lati yi igbesi-ayéẹlẹṣẹ pada, ati lai mọ alafia, ayọ ati ireti ti Ihinrere n fun ọkàn ẹdá.
Iṣẹ ti Ọlọrun Rán
Nigba ti Paulu bá waasu fun awọn Ju nipa Kristi, a saba maa sọ itan bi Ọlọrun ṣe ba awọn Ọmọ Israẹli lò lati ibẹrẹ dé opin. Oun a maa sọ fun wọn nipa irubọ, awọn asọtẹlẹ ati ireti olukuluku Ju ninu Messia; gbogbo wọn ni ọrọ rè̩ si yé yálà wọn fara mọ ohun ti o n sọ tabi bẹẹkọ. S̩ugbọn lori Oke Arepaogu, nibi ti ibọriṣa gbé yọyẹ si, ki ni Paulu le sọ lati mu ki ọrọ rè̩ yé wọn? Jesu wi pe: “Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna” (Matteu 10:19). Ni wakati naa gan an, Ẹmi Mimọ fi ọrọ si Paulu lẹnu nitori pe gbogbo ọrọ ti o sọ ni o kún fún imọlẹ ti o si yé awọn eniyan ti o kún fún oniruuru isin wọnyii. Awọn Ẹpikurei ati Stoiki gbọ péỌlọrun ni Ẹlẹda gbogbo agbaye ati Alaṣẹ lori ẹda gbogbo -- wọn kò gba a gbọ. Iwaasu Paulu ti o tako ibọriṣa ati irubọ lati tu awọn irunmọlẹ loju, gún awọn ara Atẹni lọkàn – gbogbo wọn ni ẹlẹbi. Awọn ara Atẹni gbà pe wọn yatọ si awọn ẹlomiran, ṣugbọn Paulu sọ fun wọn pe ẹjẹ kanna ni Ọlọrun fi dá gbogbo orilẹ-ède ati pe iṣẹọwọỌlọrun ati Ọmọ Rè̩ ni gbogbo eniyan i ṣe. Nitori pe a dá eniyan ni aworan Ọlọrun, a kò gbọdọ ni ero pe Iwa-Ọlọrun dabi wura tabi fadaka tabi okuta ti a fi ọgbọn ati ihumọ eniyan ṣe li ọnà. Bi eniyan ba fẹ sin Ọlọrun, wọn ni lati wa Oluwa ki “ọkàn wọn si fa si I,” nitori O wa nitosi olukuluku ọkàn. Awọn ti n sin Ọlọrun ni lati sin In ni ẹmi ati ni otitọ.
Ọlọrun gboju fo igba aimọ ati ibọriṣa ti o ti kọja sẹyin dá, ṣugbọn nisisiyi o paṣẹ fun gbogbo eniyan nibi gbogbo lati ronu piwada. “Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye” (Johannu 1:9), n tàn pẹlu gbogbo agbára rè̩, nitori naa kò si awawi fun ẹnikẹni lati wà ninu okunkun. Paulu sọ fun awọn ara Atẹni pe ọjọ idajọ n bọ fun awọn ti o kọ lati ronupiwada – pe Ọlọrun ti dáọjọ kan O si ti yan Onidajọ. O si ti fun gbogbo eniyan ni idaniloju idajọ ni ti pe O ji Onidajọ naa dide kuro ninu òkú. O ṣe pataki lati gba Ihinrere gbọ!
Kò Jasi Asán
Paulu lu ponpó mọè̩ṣẹ ati ibọriṣa awọn ara Atẹni, ṣugbọn o dabi ẹni pe kò tu irun lara wọn. Nigba ti awọn eniyan ti o pe jọ si ori Oke Areopagu wọnyi gbọ nipa ajinde, awọn miiran n ṣẹfẹ: bẹẹni awọn miiran fi ọjọ ipinnu wọn dọla, wọn fẹ gbọ nnkan wọnyi lẹnu Paulu lẹẹkan si i, ṣugbọn boya kò si ọjọ ti wọn dé ojú imọ otitọ Kristi. Paulu fi ilu Atẹni silẹ nigba ti o ri i pe awọn Hellene ka iwaasu Kristi si were nibi ti wọn gbé n wáọgbọn kiri, ṣugbọn eyi kò mu ki aarẹ múọkàn Apọsteli onigboya yii. Paulu báọna rè̩ lọ lati lọ furugbin nibomiran ati lati wá awọn wọnni ti yoo jé̩ ipè Ihinrere lọ. Sibẹsibẹ iṣẹ Paulu ni Atẹni kò jasi asán; nitori pe awọn ọkunrin kan gbagbọ, wọn si “fi ara mọọ” ninu awọn ẹni ti Dionisiu ọkan ninu awọn onidajọ ara Areopagu wà. Iwe itan sọ fun ni pe Paulu fi otitọỌrọỌlọrun yéọkunrin yii to bẹẹ ti o fi di biṣọpu kin-in-ni ni ilu Atẹni. Ọkàn kanṣoṣo ti o ronupiwada niyelori loju Ọlọrun ju gbogbo ayé yii lọ; nitori naa kò yani lẹnu pe Ọlọrun rán Paulu si Atẹni lati yi awọn eniyan diẹ wọnyi lọkàn pada.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Paulu fi gba Amfipoli ati Apollonia kọja lai waasu fun wọn?
- Bawo ni awọn ara Tẹssalonika ṣe tẹwọ gba Paulu oun Sila?
- Ki ni ṣe ti awọn iranṣẹỌlọrun wọnyi ṣe ni lati fi Tẹssalonika silẹ?
- Lọna wo ni awọn ara Berea fi yatọ si awọn eniyan Tẹssalonika?
- Oniruuru eniyan wo ni o gba itàn Ihinrere gbọ ni Berea?
- Ki ni ṣe ti Paulu fi ni lati fi Berea silẹ?
- Ki ni o rúọkàn Paulu soke nigba ti o de ilu Atẹni?
- Ki ni o ṣẹlẹ ni oke Areopagu?
- Bawo ni Ọlọrun ṣe fun gbogbo eniyan ni idaniloju péọjọ idajọ n bọ?
- Eniyan meloo ni o gba è̩kọ Paulu ni ilu Atẹni?