Iṣe Awọn Apọsteli 18:1-22

Lesson 336 - Senior

Memory Verse
“Ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi” (1 Kọrinti 3:11).
Cross References

I Ijọ Kọrinti

1. Bi Paulu ti dé Kọrinti o ri Akuila ati Priskilla, awọn ẹni ti o bá gbé ti o si báṣiṣé̩ pọ, Iṣe Awọn Apọsteli 18:1-3; Romu 16:3, 4

2. Paulu n fi ọrọ wéọrọ pẹlu awọn Ju ati awọn Hellene ninu sinagọgu ni Ọjọ Isinmi, Iṣe Awọn Apọsteli 18:4; 1 Kọrinti 2:1-4

3. Sila oun Timoteu wá lati ran Paulu lọwọ ni Kọrinti, Iṣe Awọn Apọsteli 18:5; 1 Tẹssalonika 3:6-9

4. Awọn Ju kò gba ẹri ọrọ naa, eyi si mu ki Paulu lọ waasu fun awọn keferi, Iṣe Awọn Apọsteli 18:6, 7; 13:50-52; Matteu 10:14, 15

5. Olori sinagọgu gba Oluwa gbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 18:8

6. Niwọn bi Oluwa ti n ki Paulu laya loju iran, o duro ni Kọrinti ni oṣu mejidinlogun, Iṣe Awọn Apọsteli 18:9-11

II Niwaju Itẹ Idajọ Gallioni

1. Awọn Ju dide si Paulu, Iṣe Awọn Apọsteli 18:12, 13

2. Gallioni túẹjọ naa ká, Iṣe Awọn Apọsteli 18:14-16

3. Awon Hellene lu Sostene niwaju itẹ idajọ, Iṣe Awọn Apọsteli 18:17

III Ipadabọ si Jerusalẹmu

1. Paulu ati Akuila ati Priskilla fi Kọrinti silẹ, wọn kọja lọ si Siria ati si Efesu, Iṣe Awọn Apọsteli 18:18-20

2. Paulu si rekọja lọ si Kesarea ati Jerusalẹmu, Iṣe Awọn Apọsteli 18:21, 22

Notes
ALAYE

Iṣẹ Nigba Gbogbo

Bi Paulu ti kuro ni Atẹni, o lọ si Kọrinti ṣugbọn awọn alabaṣiṣẹ rẹ ko ba a lọ. Timoteu fi Berea silẹ wá si Atẹni ṣugbọn Paulu ran an pada lọ si Tẹssalonika: “Nigbati ara wa kò gba a mọ, awa rò pe o dara ki a fi awa nikan sẹyin ni Atẹni: awa si rán Timoteu, arakọnrin wa, ati iranṣẹỌlọrun ninu ihinrere Kristi, lati fi ẹsẹ yin mulẹ, ati tù yin ninu niti igbagbọ yin” (1 Tẹssalonika 3:1, 2). Bi Paulu ti n duro de awọn ẹlẹgbẹ rè̩ ni Kọrinti, o wọ sile Akuila ati Priskilla wọn si jumọ n ṣiṣẹ agọ pipa. O n fi ọrọ wéọrọ ninu sinagọgu ni ọjọọjọ Isinmi, o si n yi awọn Ju ati awọn Hellene ni ọkàn pada.

Paulu kò ka iṣẹọwọ si ohun itiju. Jesu wi pe “Ọfẹ li ẹnyin gbà, ọfẹ ni ki ẹ fi funni” (Matteu 10:8). Paulu ni igbagbọ ninu aṣẹ yii o si n ṣe e. Paulu kò fẹ jẹ ajigbese ẹnikẹni. Ọpọlọpọẹsin ode oni ni o ti di yẹpẹrẹ loju awọn eniyan paapaa ju lọ nitori pe wọn fi ajaga ti o wuwo bọ awọn eniyan lọrun. Lati maa ṣagbe fun owó ni orukọ Kristi jé̩àṣà ti o lodi si eto Ọlọrun. Ọlọrun fi ilana idamẹwaa lelẹ lati bojuto ọràn inawo laaarin Ijọ Rè̩, O si n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ ki o tẹle ilana yii, ani titi di ọjọ oni. Ọlọrun naani awọn eniyan ti o bá gbéẹkè̩ wọn le E patapata, O si n pese fun aini wọn. (Fun oye kikún, wo Ẹkọ 264; tabi “Idamẹwaa – Eto Ọlọrun fun Idawo” Iwe kekere Amulewọ ti Ijọ Apọstolic Faith No. 31.)

Awọn Anfaani

Nihin ni a kọ gbọ nipa Akuila ati Priskilla ninu Iwe Mimọ. A kò sọ fun ni pe Onigbagbọ ni wọn nigba ti Paulu wọ sọdọ wọn, ṣugbọn wọn di ọmọ-ogun Kristi tootọ. Lai si aniani itara Paulu ati apẹẹrẹ igbesi-ayé rè̩ṣe iranwọ lati sọ awọn eniyan wọnyi di akọni ninu Igbagbọ gẹgẹ bi a ti ri i ninu igbesi-ayé wọn nigbooṣe. Bi Paulu ti ri i pe oun ni lati fi ọwọ oun ṣiṣẹ, kò jẹ fi anfaani kankan ti o ba ni tafala, kò kuna lati maa kede Ihinrere ti o jẹẹ lọkan -- ibáàṣe nidi iṣé̩.

Akuila ati Priskilla kọè̩kọ gidigidi lọdọ Paulu, lai pẹ jọjọ awọn paapaa di olukọ ti o jafafa ninu ỌrọỌlọrun. Nigba ti Paulu kọja lọ si ibomiran lati ṣiṣẹ, Akuila ati Priskilla bẹrẹ si ba iṣẹ Ihinrere naa lọ nibi ti wọn wà.

Bakan na ni a gbọdọ fara mọẹkọ ti awọn alufaa ti o kún fún Ẹmi Ọlọrun n kọ wa ki a si maa ṣe e. Nigba ti awọn iṣẹ kan tabi anfaani kan ba ṣi silẹ, tabi nigba ti a ba pe awọn agbaagbà ninu awọn OjiṣẹỌlọrun lati lọ gba ère wọn, ẹni kan ni lati wà ti o ti ṣetan nipa ti ẹmi lati di aafo ti wọn fi silẹ. Ẹ jẹ ki a beere ibeere yii lọwọ ara wa, “Ki ni ṣe ti emi ki yoo fi jé̩ẹni naa?” Bi a ti fara mọẹkọ Ihinrere ti a ti n gbọ lati ọdun-mọdun yii wá ati bi a ti n ṣe wọn ni yoo fi hàn.

Iṣẹ Gbogbo Eniyan

Nigba ti Sila ati Timoteu si ti Makedonia wá lati bá Paulu ṣiṣẹ ni Kọrinti, ọrọ naa ká Paulu lara to bẹẹ ti o fi tọ awọn Ju lọ, o si n fi hàn fun wọn pe Jesu ni Kristi naa. Ẹri Paulu nipa ajinde Olugbala daju, o si mú ni lọkàn. Lai pẹ jọjọ awọn Ju gbe inunibini dide si Paulu to bẹẹ ti wọn n sọ blasfeme; nitori naa Paulu gbọn aṣọ rè̩, o si sọ fun wọn pe, “È̩jẹ nyin mbẹ lori ara nyin; ọrùn emi mọ: lati isisiyi lọ emi o tọ awọn Keferi lọ.”

Ọlọrun fi ọràn awọn eniyan ti awọn iranṣẹ Rè̩ ati awọn ti i ṣe ẹlẹri Rè̩ n ba gbe tabi ti wọn n ba ṣiṣẹ kọ wọn lọrun gidigidi de àyè kan. Ọlọrun sọ fun wolii nì pe: “Iwọọmọ enia, emi ti fi ọṣe oluṣọ fun ile Israẹli; nitorina iwọ o gbọọrọ li ẹnu mi, iwọ o si kilọ fun wọn lati ọdọ mi” (Esekiẹli 33:7). Ọlọrun n sọ ohun kan naa fun awọn Onigbagbọ lode oni: “Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda” (Marku 16:15). “Māṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ rẹ; mā duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọọrọ rẹ là” (1 Timoteu 4:16). Bi Onigbagbọ ba jẹ oloootọ lati kede ọrọ ireti ati igbala Ọlọrun, oun yoo gba ọkàn ara rè̩ là. Njẹ awa gẹgẹ bi Onigbagbọ, n ṣe ojuṣe wa ni kikun nipa sisọẹri igbala fun awọn eniyan? Njẹ a le sọ gẹgẹ bi Paulu ti wi pe “È̩jẹ nyin mbẹ lori ara nyin; ọrùn emi mọ.” Ọlọrun ma ṣai ran olukuluku Onigbagbọ lọwọ lati ṣe iṣẹ yii kárakára!

Lati tubọ ki Paulu laya ninu iṣẹ-iranṣẹ rẹ ni ilu Kọrinti, Oluwa ba a sọrọ ni oru ni ojuran pe: “Má bẹru, sá mā sọ, má si ṣe pa ẹnu rẹ mọ: nitoriti emi wà pẹlu rẹ, kò si si ẹniti yio dide si ọ lati pa ọ lara: nitori mo li enia pipọ ni ilu yi.” Paulu le ti maa rò pe awọn ọta oun pọ, wọn si lagbara, ṣugbọn Oluwa fun un ni idaniloju pe Oun yoo gba a kuro lọwọ gbogbo wọn. Ọrọ ikiya yii ti fi ọkàn Paulu balẹ pẹsẹ. Oun ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ wà ni Kọrinti fun ọdun kan ati oṣu mẹfa, wọn n kọ awọn ara ilu naa ni ỌrọỌlọrun.

Awọn Iwaasu Lile

Awọn eniyan lọkunrin ati lobinrin a saba maa na ika ariwisi si awọn ojiṣẹỌlọrun ti o ba n waasu ṣàkóṣàkó pẹlu agbára ati itara. Njẹẹnikan jẹ lero pe ohùn isalẹ tabi ohùn tinrin ni Paulu fi sọ fun awọn ara Kọrinti pe: “È̩jẹ nyin mbẹ lori ara nyin; ọrùn emi mọ: lati isisiyi lọ emi o tọawọn keferi lọ?” A ni idaniloju péọrọ yii ni imisi Ẹmi Mimọ ninu nitori pe Paulu n ṣe ohun ti Jesu palaṣẹ fun awọn ọmọlẹyin Rè̩ pe: “Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọọrọ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ile na tabi ni ilu na, ẹ gbọn ekuru ẹsẹ nyin silẹ” (Matteu 10:14). Iwaasu lile yii kò dùn mọ awọn Ju ti o wà ni Kọrinti ninu, sibẹ kò lọ lasan. Paulu ya ara rè̩ kuro ninu sinagọgu, o si wọ ile ọkunrin kan ti a n pe ni Justu ti ile rè̩ sun mọ sinagọgu lati maa waasu nibẹ. Lai pẹ jọjọ Krispu olori sinagọgu di Onigbagbọ, o si di ọmọlẹyin Oluwa. Bayii ni isọji ṣe bẹrẹ ni Kọrinti; nitori pe ọpọ eniyan yi pada nigba ti wọn gbọ pe Krispu ti di Onigbagbọ, a si baptisi wọn.

Oniwaasu ti o ba n sọọrọ didun-didun a saba maa ni ero lẹyin ju awọn ojiṣẹỌlọrun ti n waasu ỌrọỌlọrun laini abula, ṣugbọn ọrọ didun ki i sọ ni di Onigbagbọ atunbi. Onigbagbọ tootọ ni ẹni ti n ṣe gbogbo ỌrọỌlọrun; ki a to le jé̩ oluṣe Ọrọ naa, ọpọlọpọ awọn eniyan n fẹẹni ti yoo mu wọn lọkan le lati ṣe bẹẹ. Iwaasu lile ti n jade pẹlu agbára ati imisi Ẹmi Mimọ jé̩ ohun-elo iyanu lati ki awọn Onigbagbọ layà lati tubọ tè̩ siwaju ninu iṣẹ wọn fun Oluwa. Ijọ Onigbagbọ lode-oni n fé̩ awọn eniyan pupọ bi Paulu, ki i ṣe awọn ti n sọ aga iwaasu di ibi ti a ti n gbéọgbọn ayé kalẹ.

Aabò Paulu

O daju pe Paulu kò fa ọwọ iwaasu rè̩ sẹyin ni gbogbo akoko ti o fi wà ni Kọrinti. Bi o ba ṣe bẹẹ, awọn Ju i ba ti gbagbe Paulu ṣugbọn lẹyin igba diẹ si i, wọn tun gbiyanju lati pa akikanju Apọsteli awọn keferi yii lẹnu mọ. Wọn dide ọtè̩ si Paulu, wọn si mú un wá siwaju itẹ idajọ Gallioni. Ni imuṣẹ ileri ti Ọlọrun ṣe fun Paulu pe ki yoo ri ipalara rara ni Kọrinti, Ọlọrun mú ki Gallioni túẹjọ naa ká. Ẹsun èké ni wọn fi Paulu sùn, eyi kò jé̩ ki o ṣeeṣe fun awọn Ju lati le ṣe Paulu ni ohun kan. Paulu si duro “si i nibè̩ li ọjọ pipọ” ki o tó dagbere fun awọn arakunrin, o si báọkọ lọ si Siria.

Si Jerusalẹmu

Akuila ati Priskilla bá Paulu de Efesu. Paulu wọ inu sinagọgu ilu yii lọ, o si bẹrẹ si i fi ọrọ wéọrọ pẹlu awọn Ju. Dajudaju diẹ ninu awọn wọnyi yi pada nitori pe wọn bẹ Paulu pe ki o ba wọn joko diẹ si i. Akuila ati Priskilla duro ni Efesu boya lati kọ awọn ti o ṣẹṣẹ di ẹbi Ọlọrun ni è̩kọṣugbọn Paulu tè̩ siwaju ninu irin-ajo rè̩, o si ṣe ileri fun awọn ara Efesu pe bi Ọlọrun bá fé̩ oun yoo tun wá bè̩ wọn wò. Paulu báọkọ lọ si Kesarea lati ibi ti o ti goke lọ si Jerusalẹmu o si ki ijọ. Lẹyin naa o pada si Antiọku.

Bayii ni irin-ajo keji Paulu wá si òpin. Bi o tilẹ jẹ pe idanwo pupọ de ba a ni gbogbo ilu ati nibi gbogbo ti o gbe ti n waasu, sibẹ Paulu ni iṣẹgun ti o fẹsẹ mulẹ. O kere tán, ijọỌlọrun mẹrin ni a dá silẹ laaarin akoko kukuru yii; awọn ẹpisteli ti Paulu si kọ si awọn ijọỌlọrun wọnyi fun itọni, nipa imisi Ẹmi Mimọ, jé̩ẹkọ ti o wulo fun ire gbogbo awọn Onigbagbọ lati ayebaye. Bi Oluwa ba n tọni, ohun gbogbo yoo yọri si rere.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Darukọ awọn Ju meji ti Paulu ri ni Kọrinti ti wọn si wa di oluranlọwọ awọn Onigbagbọ ni ọjọ iwaju.
  2. Ki ni iṣẹ-ọwọ ti Paulu n ṣe?
  3. Ki ni ṣe ti Paulu fi ya ara rè̩ kuro ni sinagọgu?
  4. Ta ni Krispu? Ki ni o ṣe?
  5. Bawo ni Paulu ṣe ni ìkiyà lati tè̩ siwaju ninu iwaasu rè̩ ni Kọrinti?
  6. Bawo ni awọn Onigbagbọ wọnyii ti duro pé̩ tó ni Kọrinti?
  7. Ọna wo ni Gallioni fi ṣe iranwọ fun Paulu?
  8. Nibo ni Paulu lọ nigba ti o fi Kọrinti silẹ?