Lesson 337 - Senior
Memory Verse
“Ẹniti ngbin, ati ẹniti mbomirin, ọkan ni nwọn jasi: olukuluku yio si gba ère tirè̩ gẹgẹ bi iṣẹ tirè̩. Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbàỌlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin” (1 Kọrinti 3:8, 9).Cross References
I Iwa-bi-Ọlọrun Apollo, Ẹni ti o jé̩ Ajihinrere ni Akọkọ Bẹrẹ Ijọ
1. A ti kọ Apollo ni Iwe Mimọ tẹlẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 18:24, 25; Kolosse 1:10; 2 Timoteu 2:15
2. O jé̩ọkunrin ti o ni è̩bun ọrọ sisọ, o si lo gbogbo è̩bun rè̩ wọnyi fun ogo Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 18:24, 25; Efesu 4:8, 11-13; Romu 12:5-8
3. Nitori ó jé̩ onirẹlẹọkàn, óṣe tán lati gba è̩kọ, Iṣe Awọn Apọsteli 18:26; Romu 12:10, 16; Jakọbu 3:13-17
4. O jé̩ẹni ti o ni itara si ohun ti Ẹmi, o n fi aapọn sọrọ, o si n kọ ni pẹlu igboya, Iṣe Awọn Apọsteli 18:25, 26; Oniwasu 9:10; Romu 12:11; Galatia 4:18; Isaiah 62:1; 2 Kọrinti 9:2
5. Ọlọrun bukun iṣẹ-iranṣẹ rè̩, ọpọlọpọ si ti ipasẹ rè̩ gbagbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 18:27, 28; 1 Kọrinti 3:5
6. Paulu fi Apollo ati Peteru ṣe apẹẹrẹ pẹlu ara rè̩ lati kọ ni lẹkọọ ewu ti o wà ninu ariyànjiyàn lori ọran awọn alakoso nipa ohun ti Ẹmi, ati lati fi èro ọkàn awọn ti wọn n fi aigbọn gbé awọn olori wọn ga ju bi o ti yẹ lọ hàn, 1 Kọrinti 1:10-13; 3:4-9, 21-23; 4:6
Notes
ALAYEApollo jé̩ẹni kan ti Ọlọrun fi ibukun si iṣẹ-iranṣẹ rè̩ lọpọlọpọ. O jé̩ alabaṣiṣẹ pọ pẹlu Paulu ati awọn Apọsteli miiran ti n ṣe laalaa lati mu ki ọna igbala di mimọ ni Aṣia ati Europe ati ni gbogbo ibi ti wọn mọ gẹgẹ bi agbaye nigbaanì. Bi a ba ṣe akiyesi iwà ati ẹri eniyan Ọlọrun yii, ẹni ti awọn Apọsteli yé̩ si lọpọlọpọ, eyi yoo ràn awa naa lọwọ lati mu ki igbesi-ayé wa tubọ wulo lọpọlọpọ fun iṣẹỌlọrun.
A kọỌ ni Ọna Ọlọrun
Ju ni Apollo i ṣe, lai si aniani o ni imọ Iwe Mimọ nitori ẹkọ ti a n kọ olukuluku ọmọ ti a bi ni ile awọn Ju. Iru ọdọmọde bẹẹ yoo kọ pupọ ninu ọrọ Mose ati ọpọlọpọ ninu awọn Psalmu sori. Wọn o maa bu ọlá fun Ọlọrun ninu ile wọn ninu ọpọlọpọ adura ti wọn maa n gbà ni oriṣiriṣi igbà ninu igbesi-ayé wọn ojoojumọ. Wọn a maa pa ọjọàsè mọ, wọn a si maa jẹọdọ-agutan irekọja.
Yoo dara pupọ bi awọn obi lode oni ba le tẹle apẹẹrẹ yii ki wọn kọ awọn ọmọ wọn gidigidi ni Ọrọ ati ifẹỌlọrun. Nitori ti awọn obi ṣáẹkọ yii tì ni iwa ibajẹ fi pọ tò bẹẹ laaarin awọn ọdọmọde.
A ti fi “ọna Oluwa” kọ Apollo. O ṣeeṣe ki o jé̩ nipa ifẹ aiṣẹtan ti o ni si Iwe Mimọ tabi nipa itọni Ẹmi Mimọ ni o gbé ti ni imọỌmọỌlọrun. Kò si ẹri ti o ṣe pataki ju lọ fun ẹnikẹni ti n ṣafẹri lati di oṣiṣẹ ninu iṣẹỌlọrun bi pe ki o jé̩ ki Ọrọ naa ki o ṣiṣẹ ninu igbesi-ayé oun, ki o si jé̩ẹni ti a kọ daradara ni ọna Oluwa. O ni lati jé̩ alagbara ninu awọn ohun ti i ṣe ti Oluwa, oun yoo si ri agbára yii gbà nipa jijẹ ounjẹ lile lati inu ỌrọỌlọrun. Bi o ba ṣe n jọwọ ara rè̩ lọwọ fun Ọlọrun to bẹẹ ni Ẹmi Ọlọrun ati otitọỌrọỌlọrun yoo maa mu un yẹ fun iṣẹ ti Ọlọrun fi fun un lati ṣe. Nigba naa, ani nigba naa nikan ni oun yoo di oṣiṣẹ “ti kò ni lati tiju.” Dajudaju ìmọỌrọỌlọrun jé̩ọkan ninu ohun ti o mu ki ọrọ yọ ni ẹnu Apollo bi o ti n sọ ti oore-ọfẹ igbala ti Kristi fun awọn ẹlomiran.
Irẹlẹ
Niwọn bi o ti jẹ pe ìmọ Apollo kò tayọ “kiki baptismu ti Johannu” o tọ ki a kọọ lẹkọọ giga ti Jesu gbé kalẹ. Nipasẹ inunibini ti a n ṣe si awọn Ju ni Romu, a le awọn olufọkansin meji ti i ṣe ọmọlẹyin Jesu Kristi Oluwa jade kuro ni Romu (Iṣe Awọn Apọsteli 18:1, 2). Awọn pẹlu, gẹgẹ bi Paulu jé̩ẹni ti n pa agọ. Nitori ti Paulu jẹ “oniṣẹọnà kanna,” o bá Akuila ati Priskilla joko ni Kọrinti. Paulu jé̩ olukọni àtàtà fun wọn. Lai si aniani, o kọ wọn lẹkọọ daradara nipa Ihinrere. Nigba ti Akuila ati Priskilla gbọ bi Apollo ti fi igboya sọrọ ninu sinagọgu ni Efesu “nwọn mu u si ọdọ nwọn si tubọ sọ idi ọna Ọlọrun fun u dajudaju” (Iṣe Awọn Apọsteli 18:26). Iṣe rè̩ ni lati jé̩ eyi ti o wu ni lori pupọ, nitori pe nigba ti o n lọ si Kọrinti, awọn arakunrin ti o wà ni Efesu fun un ni itilẹyin ti ẹmi ati iwe ẹri rere fun awọn arakunrin ti o wà ni Akaia (Iṣe Awọn Apọsteli 18:27).
Ọpọlọpọ awọn eniyan ni kò fé̩ gba è̩kọ. Wọn lero pe wọn ti tó tán ati pe kòṣanfaani lati gba ẹkọ ti Ọlọrun le fẹ kọ wọn nipasẹọkan ninu awọn iranṣẹ Rè̩. S̩ugbọn Apollo gba ẹkọ, eredi rẹ niyii ti Ọlọrun fi lòó gẹgẹ bi ajihinrere.
IgbonaỌkàn ati Itara
Apollo jé̩ẹni ti o ni igbona ọkàn – ninu Ẹmi -- gẹgẹ bi ti Paulu ti i ṣe alabaṣiṣẹ pọ pẹlu rè̩, a si sọ fun ni pe o n sọrọ, o si n fi aapọn sọrọ. Dajudaju ẹbun meji ti o ni papọ yii mú ki iṣẹ rè̩ yọrisi rere. Nigba pupọ ni a n ri awọn ti o ni itara ṣugbọn ti wọn ki i ṣe iṣẹ wọn ni ẹkun rẹrẹ pẹlu ifarabalẹ -- ẹkunrẹrẹ ati ifarabalẹ ti i ṣe apakan iṣẹẸmi Mimọ ninu igbala ọkàn. Eyi mu ki wọn kuna lati ni iyọrisi rere ti o yẹ ki o tẹle itara wọn. Gbogbo wa ni lati làkaka lati jé̩ onitara ati alaapọn. A ni lati ni igbona ọkàn ninu ohun gbogbo ti a ba n ṣe, a si ni lati ni ọkàn lati ṣe iṣẹ ti a ba dawọle ni aṣeyọri, bi o tilẹ jẹ pe irú ipinnu bẹẹ yoo mu ki a ṣe wahala ati aapọn ti ko bara dé.
O “nfi āyan nsọrọ, o si nkọni ni nkan ti Oluwa.” Ifẹọkàn rè̩ ni lati mú ki o di mimọ pe Jesu kú, O si tun jinde; pe Oun ni Ọmọ bibi Ọlọrun nitootọ, ki i kan i ṣe “ọmọ kan” fun Ọlọrun gẹgẹ bi awọn igbalode olutumọ Bibeli ti tumọ Bibeli ti wọn. A fi bi O ba jẹỌmọỌlọrun naa, bi bẹẹ kọìbí Rẹ, ikú Rẹ lori agbelebu, ajinde Rè̩ kuro ninu okú ati awọn ẹkọ Rè̩ jé̩ asan. Ọlọrun di eniyan nikan ni O lè dariji ti O si lè múè̩ṣẹ kuro ninu ọkàn è̩dá.
Igboya
Apollo ni igboya ti o dara pupọ. Ọkàn rẹ kò mì lati lọ si ibi ti igbekalẹẹsin awọn Ju ti gbilẹ lati waasu awọn ẹkọ Kristi. Lẹyin ti o ti gba ẹkọ lati ọdọ Akuila ati Priskilla, o n sọ fun awọn Ju pe Kristi wá si ayé gẹgẹ bi Olugbala araye ati pe Oun ni Messia wọn. O fi igboya sọ asọye Iwe Mimọ; o si yi ọpọ lọkàn pada si Otitọ. Oun kò kè̩rè̩ ninu ikede orukọẸni naa ti ọkàn rè̩ fé̩ lọpọlọpọ. Nitori eyi, ogunlọgọ eniyan ti wọn kò ba ti ni anfaani lati gbọ ihin mimọ naa ni o gbọọ nitori pe igboya rè̩ ninu Ọlọrun gbamuṣe.
Iṣọkan
Nigbooṣe, ni akoko irin-ajo kẹta Paulu, o kọwe si awọn ara ti o wà ni Kọrinti. Ẹmi Mimọ pa iwe yii mọ fun wa lati kà ni ọjọ oni. A kò gbọdọ gbagbe bi a ti n kà iwe kin-in-ni ti Paulu kọ si awọn ara Kọrinti pe eredi ti Paulu fi kọ iwe naa ni lati tọ wọn si ọna ati lati mu awọn igbekalẹ kan ti o n lọ laaarin ijọ Kọrinti kuro. Diẹ ninu awọn ohun ti o takò jé̩è̩ṣẹ gidi -- è̩ṣẹ ti awọn wọnni ti o ti ri igbala ti wọn si ti jé̩ẹbi Ọlọrun tun pada si, ti wọn si tun n fi ara hàn gẹgẹ bi ọmọỌlọrun bi o ti lẹ jé̩ pé wọn ti sọ igbala wọn nù nipa è̩ṣẹ ti wọn mọọmọ dá. Awọn alaiwa-bi-Ọlọrun wọnyii n dá rudurudu silẹ laaarin ijọ.
Awọn ohun miiran ti Paulu kọ iwe nipa rè̩ ki i ṣe è̩ṣẹ gidi ti irekọja, ṣugbọn wọn jé̩ iwa ati iṣe ti o le sún eniyan sinu è̩ṣẹ tabi ti o le gbé ara ga, tabi ti o le dá rudurudu silẹ lati yẹ oju awọn eniyan kuro lọdọỌlọrun. Paulu tun sọ nipa iṣẹ ara ti o wà ninu ọkàn awọn diẹ ninu wọn eyi ti Ẹjẹ Kristi ni lati wè̩ kuro, paapaa ju lọ o tún jé̩ ki o di mimọ ewu ti ọkan ninu awọn nnkan wọnyii le jé̩ fun awọn ti kò tilẹ tii lọwọ ninu rẹ.
Paulu ri bi awọn kan ti n fi ọlá fun awọn kan ninu awọn alakoso wọn ti wọn si fi oju yẹpẹrẹ wo awọn miiran. Awọn kan n wi pe, “Emi ni ti Paulu;” awọn miiran n wi pe “Emi ni ti Apollo” tabi “Emi ni ti Kefa;” awọn miiran pẹlu tilẹ n wi pe “Emi ni ti Kristi.” Paulu nígbà ayé rè̩ ri ewu ti o wà ninu iru àṣa yii. Ni ọna kin-in-ni, o fi hàn pé iṣé̩ ara ni. Ija ati asọ ni o si n dá silẹ. Ohun ti eyi jé̩ loju Paulu ni pé ipinya wà laaarin awujọ awọn Onigbagbọ, nipa bẹẹ wọn n díẸmi Ọlọrun lọwọ lati ṣiṣẹ laaarin wọn.
Awọn kan wà lọjọ oni ti o jé̩ pé awọn oniwaasu kan ni wọn n fẹ ki o waasu fun wọn, wọn ni awọn kan ti wọn fẹ ki o gbadura iwosan fun wọn, ati awọn kan ti wọn fẹ ki o ba wọn gbadura fun igbala ati pẹlu wọn ni awọn kan ti wọn n fẹ ki o fun wọn ni imọran. Bi Paulu ati Apollo ba wà laaarin wa nihin, wọn yoo pe awọn eniyan bẹẹ ni ẹni “ti ara.” Paulu sọ bayii pe, “A ha pin Kristi bi? iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si” (1 Kọrinti 1:13). “Nitori nigbati ẹnikan nwipe, Emi ni ti Paulu; ti ẹlomiran si nwipe, Emi ni ti Apollo; ẹnyin kò ha iṣe enia bi? Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹẹniti ẹnyin ti gbagbọ, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun. Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá ... Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbàỌlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin” (1 Kọrinti 3:4-6, 9).
Awa mọ pe a ni lati gba awọn iranṣẹỌlọrun ti Ọlọrun fi sori ijọ pẹlu “ayọ pupọ ... nipa ti Oluwa” a si ni lati “búọlá fun wọn” (Filippi 2:29) ki a si maa “bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn” (1 Tẹssalonika 5:13), “ki a kà yẹ si ọlá ilọpo meji” (1 Timoteu 5:17), a ni lati gbọnran si wọn lẹnu ki a si tẹriba fun wọn bi awọn ti “nṣọẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣiro” (Heberu 13:17). S̩ugbọn awọn eniyan Ọlọrun kò gbọdọ fi iyatọ si awọn iranṣẹỌlọrun wọnyii lọna ti ipinya ati ija yoo fi bé̩ silẹ laaarin ijọ Onigbagbọ. Bẹẹ ni awọn ọmọ ijọ kò gbọdọ gba ọrọ iwaasu awọn ojiṣẹỌlọrun wọnyi gẹgẹ bi ọrọ awọn ojiṣẹỌlọrun tikara wọn bi kòṣe gẹgẹ bi ỌrọỌlọrun ti a rán si wọn lati ọdọỌlọrun wá.
Questions
AWỌN IBEERE- Ọmọ ilu wo ni Apollo? Nibo ni a gbé bi i?
- Ẹbun pataki wo ni a fi fun eniyan Ọlọrun yii -- ẹbun ti ó lò fun anfaani iṣẹỌlọrun?
- Ki ni a ti mọọrọ ti o wi pe “a kọ Apollo ni ọna ti Oluwa” si?
- A sọ fun ni pe, “Apollo gboná li ọkàn.” Ẹbun miiran wo ni o ni ti o tún kún itara rè̩ fún Ọlọrun?
- Awọn wo ni o gbọọrọ Apollo ni Efesu? Ki ni awọn eniyan wọnyi ṣe fun un? Iru iwa-bi-Ọlọrun wo ni o fara hàn ninu Apollo nigba ti awọn ọmọ-ẹyin wọnyii tọọ wá?
- Paulu sọ nipa ti ara rè̩ pe oun ti gbìn ati pe oun jé̩ọlọgbọn ọmọle. Ipa wo ni o fun Apollo ninu awọn ẹdàọrọ ti o sọ yii?
- Ki ni ọkan ninu awọn ohun ti o n dá iyapa ati ija silẹ laaarin awọn awujọ Onigbagbọ?