Iṣe Awọn Apọsteli 19:1-20

Lesson 338 - Senior

Memory Verse
“Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọju mi lọ mbọ lẹyin mi, bàta ẹni ti emi ko to gbé; on ni yoo fi Ẹmi Mimọ ati iná baptisi yin” (Matteu 3:11).
Cross References

I Paulu ni ilu Efesu

1. Paulu beere lọwọ awọn ọmọ-ẹyin kan ni Efesu bi wọn ba ti gba Ẹmi Mimọ lẹyin ti wọn ti gbagbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 19:1, 2

2. A baptisi awọn ọmọ-ẹyin wọnyii gẹgẹ bi baptisimu Kristi, Iṣe Awọn Apọsteli 19:3-5; 8:16; 18:25

3. Awọn ọmọ-ẹyin naa gba Ẹmi Mimọ lẹyin ti Paulu ti gbéọwọ le wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 19:6, 7; 8:17; 1 Timoteu 4:14; 2 Timoteu 1:6

4. Paulu waasu ninu sinagọgu fun oṣu mẹta, ati fun ọdun meji ni ile-ẹkọ ti Tirannu, Iṣe Awọn Apọsteli 19:8-10

5. Paulu ṣe ọpọ iṣẹ iyanu pataki, Iṣe Awọn Apọsteli 19:11, 12; Marku 16:17, 18; 1 Kọrinti 12:7-11, 29-31

6. Ohun iyanu kan ṣẹlẹ ni Efesu ti o mú ki a gbé orukọ Oluwa ga gidigidi, Iṣe Awọn Apọsteli 19:13-17

7. Abayọrisi rè̩ ni péọpọlọpọ eniyan jẹwọè̩ṣẹ wọn ni gbangba, wọn si yi pada si Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 19:18-20; 2:43; 5:5, 11; Ẹksodu 15:16; 2 Kronika 17:10; Luku 1:65; 7:16

Notes
ALAYE

Si gbogbo aye

“Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda” ni aṣẹ ti Jesu fi fun awọn ọmọlẹyin Rè̩ (Marku 16:15). Aṣẹ yii ni Paulu n mu ṣẹ nigba ti o lọ lati Kọrinti si Efesu. Efesu jé̩ ibi ti o dara pupọ lati waasu Ihinrere nitori pe o wà ni oju ọna ti awọn oniṣowo n gbà, ati ọna ti o lọ taarà si Romu lati awọn ilu Ilà--oorun. Ibi ti a yan ninu Bibeli fun ẹkọ yii sọ fun ni pe Paulu wà ni Efesu ju ọdun meji lọ, o n waasu Ihinrere Jesu Kristi.

Ibi ti a yan ninu Bibeli sọ fun ni pẹlu pé gbogbo awọn ti ó wà ni Aṣia (Aṣia kekere) gbọỌrọ Jesu Oluwa, Ju ati Hellene pẹlu. Nitori pe ẹnikan ṣoṣo ni Paulu i ṣe, kòṣe e ṣe fun un lati mú Ihinrere déọdọọpọlọpọ eniyan. Efesu ti o wà mú ki o ni anfaani lati báọpọlọpọ eniyan ti o wá lati oriṣiriṣi ilu ti ó wà ni Aṣia pade. Otitọ ni pe Oluwa rán Filippi lọ si aṣalẹ lati dara pọ mọ iwẹfa nì ati lati fi Ihinrere lọọ, bakan naa ni o jẹ ohun afiye si pe Oluwa wa rekọja si odi keji okun Galili lati tọẹlẹmi èṣu ara Gadara nì lọ. S̩ugbọn lẹyin eyi Jesu ati Filippi pada si aarin ilu ibi ti awọn eniyan pupọ gbé wà nigba ti wọn pari iṣẹ kan pato ti wọn lọṣe.

Ki i ṣe ifẹỌlọrun pe ki awọn eniyan Rè̩ ta kete lọ si ibi adado kan kuro lọdọ awọn eniyan ti ó wà ninu ayéṣugbọn O fẹ ki wọn wà ni ibi iṣẹ Oluwa wọn lati maa sọ itan Ihinrere ti igbala fun awọn ọkàn ti n ṣegbe. Awa ti ode oni ti o n lakaka lati mú Ihinrere Jesu Kristi tọ awọn eniyan lọ le kọẹkọ lara awọn ọmọ-ẹyin wọnyi gẹgẹ bi wọn ti n lọ si gbogbo ayé lati waasu Ihinrere. A ni lati mú Ihinrere tọ awọn eniyan lọ lọna kan tabi lọna miiran ṣugbọn ki i ṣe dandan pe a ni lati tikara wa lọ si ibi ti eniyan wà lati mu Ihinrere tọ wọn lọ. Paulu wà ni Efesu fun ọdun meji, o n kọ ni ni ojoojumọ ni ile iwe Tirannu, gbogbo awọn ti o wà ni Aṣia gbọỌrọ Jesu Oluwa.

Awọn Ọmọ-ẹyin ti a Baptisi si Ironupiwada

Paulu bá awọn ọmọ-ẹyin mejila kan pade ni Efesu ti wọn kò mọ nipa baptisimu Kristi. Wọn jé̩ eniyan Ọlọrun nitori pe nigba ti wọn gbọ nipa iwaasu Johannu Baptisi, wọn jẹwọè̩ṣẹ wọn a si baptisi wọn gẹgẹ bi o ti pa a laṣẹ. Nigba ti wọn gbọ pe Ẹni ti Johannu sọ nipa Rè̩ ti dé, wọn fi tayọtayọ gba ẹkọ Paulu nipa Kristi a si baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ ati ni ti Ẹmi Mimọ. A ri kà ninu ẹkọ wa pe, “a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa.” Itumọ eyi ni pe a baptisi wọn gẹgẹ bi Jesu ti pa a laṣẹ nigba ti O sọ pe, “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19). ỌrọỌlọrun ki i tako ara rẹ, ohun ti o ba sọ ni ibi kan wà ni idọgba pẹlu eyi ti o sọ nibomiran.

GbigbaẸmi Mimọ

Ibeere Paulu pe, “Ẹnyin ha gbàẸmi Mimọ na nigbati ẹnyin gbagbọ?” ṣe pataki lọpọlọpọ. Idahun awọn ara Efesu ti o gbagbọ pé awọn kò gbọ rara bi Ẹmi Mimọ kan wà mu ki Paulu wadii siwaju si i nipa igbagbọ wọn. Ibeere Paulu fara hàn kedere, ọna ti o gbà beere lọwọ awọn eniyan wọnyii si yanju, ani pe bi wọn ba i ṣe ọmọ lẹyin Jesu Kristi ti a ti baptisi wọn ni orukọ Baba ati ni ti Ọmọ ati ni ti Ẹmi Mimọ, wọn i ba ti mọ nipa Ẹmi Mimọ ati pe o ṣe e ṣe ki wọn tilẹ ti gbàÁ. Gbogbo awọn ọmọ-ẹyin Jesu ni igba ti Ijọṣẹṣẹ bẹrẹ ni igba aye awọn Apọsteli ni o mọ pé gbogbo eniyan ti o bá gba Kristi gbọ ti a si ti sọ di mimọ ni o ni lati gba Ẹmi Mimọ, ati pe wọn yoo ri Ẹmi Mimọ gbà.

Oye otitọ yii yé Johannu Baptisi o si jẹọkan ninu awọn ohun ti o tẹnu mọ ninu iṣẹ-iranṣẹ rè̩. Ikede rè̩ nipa Kristi ni pe, “Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọju mi lọ mbọ lẹyin mi, bàta ẹni ti emi kò to gbé; on ni yoo fi Ẹmi Mimọ ati iná baptisi yin” (Matteu 3:11).

Igba pupọ ni Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe Oun yoo rán Olutunu, ani Ẹmi Mimọ si wọn nigba ti Oun ba goke lọ sọdọ Baba. (Wo Johannu 14:16-26; 15:7-15). Awọn ọrọ ikẹyin Rè̩ si awọn Apọsteli Rè̩ṣaaju Igoke-re-Ọrun Rè̩, ni aṣẹ yii pe, “Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalẹmu, titi a o fi fi agbara wọ nyin, lati oke ọrun wá” (Luku 24:49). A tun kà ninu Iṣe Awọn Apọsteli pe: “Nigbati o si ba wọn pejọ, o (Jesu) paṣẹ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe kuro ni Jerusalẹmu, ṣugbọn ki nwọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe, ẹnyin ti gbọ li ẹnu mi. Nitori nitotọ ni Johannu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmi Mimọ baptisi nyin, ki iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:4, 5). Awọn wọnyi jé̩ diẹ ninu ẹsẹ Iwe Mimọ ti o fi otitọ naa hàn pe gbogbo Onigbagbọ ni o ni lati gbàẸmi Mimọ.

“Ẹnyin ha gbàẸmi Mimọ na nigbati ẹnyin gbagbọ?” jẹ ibeere ti gbogbo Onigbagbọ lode oni ni lati le dahun rè̩ wi pe, “bẹẹni.” Bi agbara yii kò ba fara hàn ninu Ijọ tabi ti ẹnikẹni ba wà ti kò ni agbara yii ni igbesi-ayé rè̩, eredi rè̩ ni pe kò gbọran ni kikun si aṣẹ Jesu ti o wi pe, “Ẹ joko ... titi a o fi fi agbara wọ nyin, lati oke ọrun wá.” Nigba ti Paulu gbéọwọ rè̩ lé awọn ọmọ-ẹyin ara Efesu wọnyi, ti o si gbadura, wọn gba Ẹmi Mimọ, wọn si fi ède miiran sọrọ gẹgẹ bi Ẹmi ti fun wọn li ohùn; gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ si awọn wọnni ti o wà ni yara oke ni Ọjọ Pẹntekọsti. Lọjọ oni, awa ti a ti sọ di mimọ yoo fi ède miiran sọrọ gẹgẹ bi Ẹmi bá ti fun wa ni ohùn nigba ti a ba gba Ẹmi Mimọ. A si gbọdọ bè̩rẹ si rin ninu imọlẹỌrọỌlọrun, a si ni lati gbọran si aṣẹ Rè̩ bi a kò ba fẹ ki ifororo yan Ọlọrun ti a ri gbà nigba ti a baptisi wa pẹlu Ẹmi Mimọ fi wa silẹ.

Iṣẹ-Ami ati Iṣẹ-iyanu

Ko si tabi tabi ni ti pe iṣẹ-iranṣẹ Paulu jé̩ akanṣe. Ẹkọ wa sọ fun wa pe Ọlọrun ti ọwọ Paulu ṣe awọn iṣẹ iyanu akanṣe. S̩ugbọn akoko iṣẹ-iyanu ko i ti kọja! Jesu Kristi ọkan naa ni ana, ati ni oni, ati titi lae; ohun ti Ọlọrun ṣe ni igbaanì, O le ṣe e, O si tun fẹ lati ṣe e ni ọjọ oni. Ileri Oluwa fun gbogbo awọn eniyan Rè̩ ni pe, “Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ lọ; Li orukọ mi ni wọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọrọ; Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, ki yio pa wọn lara rara: nwọn o gbéọwọ le awọn olokunrun, ara wọn ó da” (Marku 16:17, 18). Iṣura iyebiye ni awọn ileri wọnyi jé̩ fun Ijọ Jesu Kristi, Ọlọrun pẹlu si jẹ oloootọ si Ọrọ Rè̩ ni gbogbo igba. Ni ode-oni, awọn eniyan n ri iwosan, iṣẹ-iyanu si n ṣe nipa agbára iyanu Ọlọrun.

Ni Iya Ijọ Apostolic Faith, a n ri iwe gbà kaakiri gbogbo agbaye fun è̩bẹ adura, nigba miiran fun idiku kekere ti a ti gbadura si fun iwosan awọn alaisan. Ohun ti Ọlọrun ṣe fun ẹnikan, O ṣetan lati ṣe e fun ẹlomiran. Iṣe Awọn Apọsteli 19:12 ni a gun le lori lati maa fi idiku wọnyi ranṣẹ si awọn alaisan ati awọn ti ara n ni. Lẹyin ti a ba ti ta ororo si idiku kan, a o fi sori Bibeli ti a ṣi silẹ, awọn alufaa yoo si gbéọwọ wọn le e, wọn yoo si gbadura pe ki Ọlọrun ki o wo alaisan ti a ba fi ranṣẹ si sàn. Iyanu ni ọna ti Ọlọrun gbà n dahun adura awọn eniyan ti n kọ iwe è̩bẹ fun adura ati idiku ti a gbadura si wọnyi! Ogunlọgọẹri ti o dani loju ni a ti ri gbà lati ọdọ awọn eniyan lọkunrin ati lobinrin ti o ti ri iwosan gbà nipa adura ati awọn idiku ti a gbadura si, ti a si fi ranṣẹ si wọn.

Gbigbeọwọ le ni lori

Lati igba Arọkuro Ojo ni ọdun 1906 ni ogunlọgọẹsin èké ati aṣerege ẹsin ti dide lati fi ọgbọn è̩tan fa ọkàn awọn eniyan kuro ni ọọa otitọ iṣẹỌlọrun. “Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni” (Isaiah 8:20). Gẹgẹ bi ỌrọỌlọrun, a ni lati fi ỌrọỌlọrun dán ohun gbogbo ati ẹni gbogbo wò, bi wọn kò ba duro lori “Bayi li Oluwa wi,” ayederu ati èké ni wọn i ṣe. Awọn kan ti wà, wọn si tun wà ni akoko yii, awọn ti n wi pe wọn ni è̩bun ati agbára ti ki i ṣe gẹgẹ bi ỌrọỌlọrun. Pupọ ninu awọn ẹlẹtàn yii n sọ wi pe wọn ni “è̩bun” gbigbéọwọ lé ni, ati pe wọn ni agbára lati fun awọn eniyan ni Ẹmi Mimọ nipa gbigbe ọwọ wọn le awọn wọnni ti n ṣafẹri Ẹmi Mimọ ni igbesi-ayé wọn. O ṣe ni laanu pe ogunlọgọ eniyan ni awọn woli èké wọnyi ti tànjẹ. Bi ẹnikẹni ba wà ti o ri ohunkohun gbà lati ọdọ awọn ẹlẹtàn wọnyi, dajudaju ki i ṣe Ẹmi Mimọ.

Kò si ibikibi ninu ỌrọỌlọrun ti a ti sọ fun ni pe “gbigbe ọwọ le ni” jé̩ọkan ninu awọn è̩bun Ẹmi. ỌrọỌlọrun kò sọ pato pe Peteru tabi Paulu tabi ẹnikẹni ninu awọn Aposteli ni irúè̩bun bẹẹ. Otitọ ni pe awọn eniyan ri Ẹmi Mimọ gbà nigba ti awọn Apọsteli gbéọwọ le wọn. S̩ugbọn gbigbe ọwọ le ni ni lati tọrọ ibukun Ọlọrun sori ẹni ti a gbéọwọ lé. Ọlọrun ti yan igbe-ọwọ le ni lori gẹgẹ bi ọna ti a gbà n ya awọn eniyan sọtọ fun iṣẹ-isin Ọlọrun. Titi di ọjọ oni ni awọn alagba ati awọn alufaa ninu Ijọ maa n gbéọwọ le ori awọn alaisan lati gbadura fun iwosan wọn, wọn a si maa ṣe bẹẹ gẹgẹ nigba ti a ba fẹ yà eniyan sọtọ fun iṣe alufaa; nigba pupọè̩wẹ, awọn alufaa ati awọn oṣiṣẹ a maa gbe ọwọ le awọn wọnni ti n wa igbala tabi iṣẹ oore-ọfẹ ti o jinlẹ lati bá wọn gbadura. Ko si eniyan Ọlọrun tootọ kan ti o jẹ sọ fun ni pe oun ni agbára lati fi Ẹmi Mimọ fun ẹnikẹni. Ẹmi Mimọ jẹẸni Kẹta Mẹtalọkan, akoso Rè̩ kò sí lọwọẹdá alaaye kan. Awọn eniyan a maa ri Ẹmi Mimọ gbà nitori ti wọn gbadura, wọn si jọwọ igbesi-ayé wọn fun Ọlọrun, wọn si pese ara wọn silẹ fun Un bi ohun-elo ti Ọlọrun ti sọ di mimọ. Ẹmi Mimọ a maa sọkalẹ sinu ọkàn funfun ti a ti wè̩ mọ, Oun ki i sọkalẹ sori eniyan nitori pe ẹnikan gbéọwọ lé e.

Ni Orukọ Jesu

Ohun iyanu kan ṣẹlẹ ni Efesu ti o gbé ogo Jesu ga ti o si fa ọpọlọpọọkàn wa sọdọỌlọrun. Awọn Ju meje, alẹmi-èṣu-jade dawọ le e lati léẹmi èṣu jade ni orukọ Jesu ti Paulu n waasu rẹ. Ẹmi buburu yii jẹwọ orukọ Jesu Kristi ati Paulu ṣugbọn o beere lọwọ awọn alarinkiri Ju wọnyi pe, “Tali ẹnyin?” Ọkunrin ti ẹmi èṣu naa wa lara rè̩ fo mọ awọn Ju naa, o lu wọn to bẹẹ ti wọn fi salọ pẹlu ifarapa. Eyi di mimọ ni gbogbo Efesu, è̩ru nla si ba gbogbo wọn, a si gbé orukọ Jesu ga to bẹẹ ti eniyan pupọ fi wá lati jẹwọè̩ṣẹ wọn ti wọn si gba Ihinrere. Ogunlọgọ awọn ti n ṣe oṣó ni o kó iwe wọn wá, wọn si dana sun wọn ni gbangba, iye rè̩ tóẹgbaa mẹẹdọgbọn iwọn fadaka.

“Bḝli ọrọ Oluwa si gbilẹ si i gidigidi, o si gbilẹ.” Nigba ti a ba waasu ỌrọỌlọrun pẹlu agbára ati imisi Ẹmi Mimọ, awọn eniyan a maa ri Igbala, alaisan ati awọn olokunrun a maa ri imularada, awọn ti ẹmi èṣu n dá loro a maa ri idande lode oni nitori pe Jesu Kristi (Ọrọ naa), “ọkanna ni li aná ati li oni ati titi lai.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Efesu fi jé̩ ibi ti o dara fun iwaasu Ihinrere?
  2. Ọdun meloo ni Paulu gbé ni Efesu?
  3. Bawo ni a ṣe mọ pé awọn ọmọ-ẹyin ti o wà ni Efesu kò mọ ohunkohun nipa iribọmi Kristi?
  4. Ki ni ṣe ti Paulu fi baptisi wọn lẹẹkeji lẹyin ti wọn ti ṣe iribọmi lọna ti Johannu Baptisi fi lelẹ?
  5. Ki ni ṣe ti Paulu beere lọwọ wọn bi wọn ti gba Ẹmi Mimọ?
  6. Ki ni ṣe ti a fi ni èro pe Ọlọrun n fẹ ki gbogbo awọn Onigbagbọ ki o gba Ẹmi Mimọ?
  7. ẸsẹỌrọỌlọrun wo ni Ijọ Apostolic Faith gùn lé lati maa fi idiku ti a ta ororo si ranṣẹ si awọn alaisan?
  8. Ki ni ṣe ti awọn alufaa fi n gbéọwọ le ni lori?
  9. Ki ni ṣe ti awọn alarinkiri Ju wọnni kò fi lè léẹmi èṣu jade ni orukọ Jesu?
  10. Ki ni o ṣẹlẹ si wọn nigba ti wọn kò lè léẹmi èṣu naa jade?