2 Kronika 29:1-36

Lesson 339 - Senior

Memory Verse
“Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitori ti Oluwa ti yàn nyin lati duro niwaju rè̩, lati sin i, ati ki ẹnyin ki o māṣe iranṣẹ fun u” (2 Kronika 29:11).
Cross References

I Hesekiah, Ọba Juda

1. Baba rẹ jé̩ọba buburu, 2 Kronika 28:1-4; 2 Awọn Ọba 16:1-4

2. Iya rẹ jé̩ọmọ wolii, 2 Kronika 29:1; 26:1, 5; 2 Awọn Ọba 18:2

3. Oun jé̩ọba ti o ṣe ododo, bi o tilẹ jẹ pe baba rè̩ fi apẹẹrẹ buburu lelẹ, 2 Kronika 29:2; 2 Awọn Ọba 18:3-7

II Hesekiah Bẹrẹ Lati fi Idi Isin Otitọ Mulẹ

1. Ohun kin-in-ni ti Hesekiah kọkọṣe gẹgẹ bi àyè rè̩ ni pe o tun ṣi Ile Ọlọrun silẹ, 2 Kronika 29:3; 28:21, 24; 2 Awọn Ọba 16:8, 14-18

2. O gba awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi niyanju lati ya ara wọn si mimọ lọtun, 2 Kronika 29:4, 5

3. Hesekiah sọ ti iṣe buburu ti awọn iran ti o ti kọja, o si sọ ti idajọỌlọrun lori wọn, 2 Kronika 29:6-9; 28:5-8; 2 Awọn Ọba 17:13-20

4. Ifẹ Hesekiah ni pe ki wọn yi pada si Ọlọrun patapata lati ni idapọ pẹlu Rè̩ gẹgẹ bi o ti ri tẹlẹ, 2 Kronika 29:10, 11; 6:24, 25; 7:12; 1 Awọn Ọba 8:23, 28-30, 33, 34

III Awọn Alufaa ati awọn ọmọ Lefi jé̩ Ipe Naa Kánkán

1. Awọn ọmọ Lefi gbọran si aṣẹ Hesekiah, wọn si ya ara wọn si mimọ lẹsẹ kan naa, 2 Kronika 29:12-15

2. Gẹgẹ bi ètò Ofin, awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa ya Tẹmpili si mimọ, olukuluku mú ipa tirè̩ ninu iṣẹ isin naa, 2 Kronika 29:16, 17; 23:1-11; Numeri 1:50-53; 3:5-10; 8:5-26; 18:1-7, 20-23

3. A mu iroyin rere wá fun ọba nipa gbogbo iṣẹ naa, 2 Kronika 29:18, 19

IV Hesekiah fi Ipilẹ Isin OtitọMulẹLọtun

1. A ṣe ẹbọẹṣẹ fun ijọba naa, ati fun ibi mimọ ati orilẹ-ède naa, 2 Kronika 29:20-24; Heberu 7:26, 27

2. Lẹyin ti a ṣe etutu tán ati lẹyin ẹbọ sisun lori pẹpẹ, isin ati orin iyin bẹrẹ, 2 Kronika 29:25-30; 23:18; Orin Dafidi 40:1-3; 51:12; 81:1-5; 95:1-7; Isaiah 30:29; 1 Kọrinti 14:15; Efesu 5:19, 20; Kolosse 3:16; Jakọbu 5:13

3. A gba awọn eniyan niyanju lati mu ọrẹ atọkànwa wá lati mu isin Ọlọrun pé, 2 Kronika 29:31-35; Deuteronomi 12:5-7; 16:10, 11; Ẹsra 3:4, 5

4. A ṣe ohun gbogbo kánkán ki ifẹsẹ mulẹ isin maṣe ni idaduro, 2 Kronika 29:36; 1 Awọn Ọba 19:20; Marku 1:18; Sekariah 8:21; Efesu 5:15, 16; Oniwasu 9:10

Notes
ALAYE

Awọn Aṣayan ẸsẹỌrọỌlọrun ninu Ẹkọ yii

Bi a ti n ka ẹkọ nipa igbesi-ayé Hesekiah, ọba Juda, lati inu ori Iwe Mimọ ti a yàn fun ẹkọ wa yii, a o ri awọn aṣayan ẹsẹỌrọỌlọrun ti o dá yatọ si awọn ti o kù ni ọna ti n fẹ akiyesi. Bi a si ti n ṣe aṣaro lori awọn ẹsẹỌrọỌlọrun wọnyi, a o ri i pe ohun pupọ ni a le ri kọ ninu wọn nipa iwa Hesekiah ọba.

Hesekiah “ṣe eyiti o tọ li oju OLUWA, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi baba rè̩, ti ṣe. O ṣí ilẹkun ile OLUWA, o si tun wọn ṣe. O si mu awọn alufa wá ati awọn ọmọ Lefi ... o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ temi, ẹnyin ọmọ Lefi; ẹ yà ara nyin si mimọ nisisiyi, ki ẹ si yà ile OLUWA Ọlọrun awọn baba nyin si mimọ.” A si tun kọ akọsilẹ pe o sọ bayii pe, “O wà li ọkàn mi lati ba OLUWA Ọlọrun Israẹli dá majẹmu,” ati pe o gba awọn ọmọ Lefi niyanju pe, “Ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitoriti OLUWA ti yàn nyin lati duro niwaju rè̩.” Nigba naa ni awọn ọmọ Lefi “kó awọn arakunrin wọn jọ, nwọn si yà ara wọn si mimọ, nwọn si wá.” “Nigbati ẹbọ sisun na si bè̩rẹ, orin OLUWA bè̩rẹ pẹlu ... Gbogbo ijọ enia na si wolẹ sìn, awọn akọrin, kọrin, ati awọn afunpè fun: gbogbo wọnyi si wà bḝ titi ẹbọ sisun na fi pari tan.” “Hesekiah si yọ, ati gbogbo enia pe, Ọlọrun ti mura awọn enia na silẹ: nitori li ojiji li a ṣe nkan na.”

ẸsẹỌrọỌlọrun wọnyi fi itara ati otitọọkàn ọba ati awọn eniyan hàn, paapaa ju lọ awọn ẹya ti Ọlọrun ti yàn lati ṣiṣẹ isin Rè̩. Wọn fi hàn pe eti Ọlọrun ṣi silẹ nigbakuugba si igbe awọn ọkàn ti o ronu piwada ati pe Ọlọrun ṣe tán nigba gbogbo lati tú ibukun Rè̩ dà sori awọn ti n ṣafẹri ibukun Rè̩. Wọn fi hàn pe Ọlọrun fé̩ awọn wọnni ti o fi gbogbo ọkàn wọn ṣiṣẹ fun Un, awọn wọnni ti isin Rè̩ṣe pataki ninu igbesi-ayé wọn ju ohunkohun ti o jasi ère fun wọn.

Ọdọmọde Ọba Onitara

Hesekiah kò wá lati inu ẹbi rere. Baba rè̩ jé̩ abọriṣa, ẹni ti o fi awọn ọmọ bibi inu rè̩ rubọ si oriṣa ti o si kọ awọn pẹpẹ oriṣa kaakiri ni Jerusalẹmu. Baba Hesekiah bá awọn ọba alaiwa-bi-Ọlọrun ati awọn orilẹ-ède Keferi dá majẹmu a si maa kó awọn ohun-elo fadaka ati wura ti o wà ni Tẹmpili fun awọn ọba keferi. O sọ pẹpẹ idẹ di alaimọ o si mu ki ohun ẹgbin ati eeri wà ninu Tẹmpili.

S̩ugbọn nigba ti Hesekiah jọba ni ọmọọdun mẹẹdọgbọn, o ṣe eto lati mú gbogbo ohun eeri kuro o si bẹrẹ ni ibi ti o tọ. O yẹ ki awọn ọdọ ti ode oni kọẹkọ lara Hesekiah. Pẹlu bi ohun gbogbo ti ṣọwọòdi si too nì, ọdọmọkunrin yii mú iduro fun Ọlọrun ati Ile Ọlọrun. O ti ri ibi ti o wà ninu ibọriṣa, o si ti fi oju ara rè̩ ri ijiya gbigbona ti isin èké n kó ba ni ni aarin ẹbi oun tikara rè̩. O ri i bi awọn ọtá ti o ṣẹgun orilẹ-ède rè̩ ti fi iya jẹ wọn. Ohun ti o si mu ki eyi ri bẹẹ ni pe orilẹ-ède rè̩ ti pada kuro lọdọỌlọrun otitọ. Bi o tilẹ jẹ pe ọmọde ni oun i ṣe, sibẹ o mú iduro gidigidi fun Ọlọrun.

Nṣe ni o dabi ẹni pe Hesekiah ti gba imọran kan naa ti Paulu Apọsteli fun ọdọmọkunrin ni, Timoteu ni ọjọ iwaju. Paulu kọwe si Timoteu bayii pe, “Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ, ninu ọrọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmi, ninu igbagbọ, ninu iwa mimọ” (1 Timoteu 4:12). Ọjọ ori Hesekiah kere, ṣugbọn kò jẹ ki eyi di oun lọwọ ninu iṣẹ ti o wà ni iwaju rè̩. O jade fun Ọlọrun, Ọlọrun si ti i lẹyin; nitori eyi, nigba ti iṣoro dé bá a ni igbesi-ayé rè̩, o le wi fun Ọlọrun pe, “Nisisiyi, OLUWA, mo bè̩ọ, ranti bi mo ti rin niwaju rẹ li otitọ ati pẹlu aiya pipé, ati bi mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ” (Isaiah 38:3). Aníọjọ ori rè̩ tilẹ kere nigba ti iṣoro dé bá a; wo bi o ti ṣe pataki tó nigba naa pe ki a le lo igba ewe wa ni ọna ti o ṣe pe bi ajalu kan ba de ti a o le boju wo igbesi-ayé wa atẹyinwa pẹlu idaniloju pe Ọlọrun yoo ranti wọn, yoo si dahun adura ti a gba si I.

Oṣe Pataki lati Ni Àya Pípe

Ni akoko yii, awọn ẹlomiran ti wọn ri itara Hesekiah ati bi o ti n boju to Ile Ọlọrun le wi pe ọgbọn ẹwé̩ awọn òṣelu ni o fé̩ lò lati le jeere ọkàn awọn eniyan ti a ko naani bi o ti tọ ati bi o ti yẹ labẹ ijọba baba rè̩. Wọn tun le wi pe ifẹ ile alarabara ni o wà ni ọkàn rè̩ to bẹẹ ti ko fi fẹ ki Tẹmpili daradara nì di ohun aṣáti ti o kun fun okiti-àlapa. A le fi awọn eniyan ti o le sọ iru ọrọ bawọnni wé awọn wọnni ti n lọ si ile Ọlọrun lọjọ oni lati le pade awọn eniyan ti yoo mu ki iṣẹ oojọ wọn ma lọ deedee tabi ki wọn le jé̩ gbajumọ laaarin ilu. Awọn miiran è̩wẹ n ka Bibeli bi iwe ti o larinrin ṣá, wọn tilẹ gba a gẹgẹ bi ọba iwe ṣugbọn wọn kuna lati ri i gẹgẹ bi ỌrọỌlọrun ti o wà titi lai ti o si yè. S̩ugbọn lai pẹ jọjọ awọn wọnni ti i ba fi ẹsun èké bawọnni sun Hesekiah yoo gbà pe Hesekiah kò ni èro kọlọfin bẹẹ lọkàn.

Hesekiah sọ pe, “O wà li ọkàn mi lati ba OLUWA Ọlọrun Israẹli dá majẹmu.” Ipa ọna ti Hesekiah fi ẹsẹ le ni igbesi-ayé rè̩ tọna. Ọkàn rè̩ pé! Awọn ohun ti o dawọ le ni ibẹrẹ ijọba rẹ ki i ṣe fun ògo ayé, tabi lati gba iyin eniyan tabi lati sọọ di alagbara oṣelu. Fun ogo Ọlọrun ni awọn ohun ti o n ṣe (1 Kọrinti 10:31). O fé̩ ni ọkàn ti o ṣe deedee pẹlu Ọlọrun, o si n fẹ ki awọn eniyan rè̩ ki o pada sọdọỌlọrun. O le ri ibinu Ọlọrun ti o rọ dè̩dè̩ sori orilẹ-ède rẹ. O ri i pe ọna kan ṣoṣo ti wọn le gbà bọ lọwọ idajọ yii ni lati ni igbala Ọlọrun, ati pẹlu pe ohun kin-in-ni ti oun le ṣe lati mu ki awọn eniyan yii pada sọdọỌlọrun ni lati mu isin Ọlọrun otitọ pada. Nitori naa, ohun ti o kọṣe ni lati palẹ Ile Ọlọrun mọ ati lati tún un ṣe, awọn ti o si le ṣe iṣẹ yii bi o ti tọ ati bi o ti yẹ ni awọn wọnni ti Ọlọrun ti yà sọtọ fun iṣẹ naa -- awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi.

Ninu gbogbo eyi, a le ri i pe Hesekiah huwa ọlọgbọn. Kò si anfaani kan ninu ile isin ti a wẹnu kuro ninu eeri ati ẹgbin atọdun mọdun bi awọn alakoso isin kò ba ya aye awọn paapaa sọtọ fun isin, ki wọn si maa fi ojoojumọ pa gbogbo ilana iṣẹ wọn mọọ. A kò le ni ireti pe agbára ati ojúrere Ọlọrun yoo fara hàn ni Ile Ọlọrun bi awọn oṣiṣẹ ati awọn ti n boju to Ile Ọlọrun ba jé̩ alaiwa-bi-Ọlọrun, ti wọn kò si fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ-isin wọn. Nitori naa Hesekiah hu iwa ọlọgbọn nitori awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ni o kọ bá sọrọ.

A ri i ka wi pe oriṣiriṣi ọna ni awọn eniyan Ọlọrun wọnyi gbà fi itara wọn hàn gẹgẹ bi ọkàn olukuluku wọn ti ri. A kò le fi agbára mu ẹnikẹni lati sin Ọlọrun; a kò le fi ofin de ẹnikẹni lati jé̩ olododo. Ibẹru-bojo nikan kò to lati sọ eniyan di oloootọ iriju ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. Oluwa rè̩ ni lati ni ifẹ atinuwa lati gbe agbelebu rè̩ ki o si maa tẹle Jesu. Awọn ọmọ Lefi jẹ ipè naa wọn si ya ara wọn si mimọ gẹgẹ bi aṣẹỌlọrun.

Bi a ti n kọè̩kọ nipa eto nla ti igbala, a ri i pe ipa meji ni o wa ninu iriri Onigbagbọ nla keji ti a n fi fun ẹnikẹni ti o ba de odiwọn ti Ọlọrun là silẹ lẹyin ti o ti ri idalare gbà nipa igbagbọ. Ipa kin-in-ni ninu iriri isọdimimọ patapata yii ni ipa ti awa paapaa ni lati ṣe. Ipa keji ni eyi ti Ọlọrun n ṣe. Ipa kin-in-ni ni lati ya ara wa sọtọ ki a si fi ara wa rubọ patapata fun Ọlọrun. Ifi-ara-ẹni-rubọ wa a maa jinlẹ ni akoko yii ju ti atẹyinwa lọ ati ju bi awa paapaa tilẹ ti lero lọ. Nigba miiran a maa n pe ifi-ara-ẹni-rubọ tabi ifi-ara-ẹni jì yii ni isọdimimọ ti òde ara – yiya-ara-ẹni si mimọ. Apa keji ni iṣẹ ti Ọlọrun n ṣe -- iwẹnumọ nipa Ẹjẹ nì lati tu gbongbo ikoro ati lati mu ibajẹ ti a jogun bá kuro ninu eyi ti a o da aworan Ẹlẹda pada sinu wa; eyi ni a n pe ni isọdimimọ patapata. Jesu gbadura bayi pe: “Emi si yà ara mi si mimọ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ ninu otitọ” (Johannu 17:19). Jesu ti i ṣe Etutu fun è̩ṣẹ ati aimọ wa, yà ara Rè̩ sọtọ, lọna miiran, O ya ara Rè̩ si mimọ ki a le wè̩ wá mọ kuro ninu ipo è̩ṣẹ ti a jogun bá – ki a ba le sọ wa di mimọ.

Bi a ti n báè̩kọ wa lọ, a o ri bi awọn ọmọ Lefi ti dide lẹsẹkẹsẹ lati ṣiṣẹ lẹyin ti wọn ti ya ara wọn si mimọ -- wọn fi ara wọn rubọ -- gẹgẹ bi Hesekiah ti paṣẹ fun wọn lati ṣe. Bakan naa ni o ri pẹlu awọn alufaa, ṣugbọn a ka nipa awọn diẹ ninu iran Aarọni yii pe awọn kan ninu wọn kò “yà ara wọn si mimọ: nitori awọn ọmọ Lefi ṣe olõtọ li ọkàn jù awọn alufa lọ lati yà ara wọn si mimọ.” Awọn alufaa ti kò fi itara dide lati ṣe ara wọn yẹ fun isin Ọlọrun, kò le ṣiṣẹ isin wọn nigba ti wọn pa ẹran ẹbọ. Awọn ọmọ Lefi ti o ti palẹọkàn wọn mọ ti wọn si jé̩ oloootọ si ipe wọn ni o rọpo wọn ninu iṣẹ-isin yii.

Adura fun Idariji ati Idahun Ọlọrun

Niwọn bi o ti jẹ pe ọkan ninu iṣẹ ti olukuluku ọba ti o ba jẹ lori awọn eniyan Ọlọrun ni ilẹ Israẹli ní lati kọṣe ni lati Kọ Ofin Ọlọrun, ki o si fi ọwọ ara rẹṣe ẹdà ofin naa ki Ofin naa le di ara fun un, a le gbà pe Hesekiah pẹlu ti ṣe bẹẹ. S̩e akiyesi pe Hesekiah paṣẹ pe ki a ru ẹbọè̩ṣẹ fun “ijọba na, ati fun ibi mimọ na, ati fun Juda.” Eyi fi hàn pe oun fẹ ki Ọlọrun dari gbogbo irekọja atẹyinwa ji. Eyi kan awọn ara ile ọba ati idile ọba pẹlu. Bẹẹni kò yẹ awọn ti n ṣe iṣẹ-isin fun Oluwa silẹ pẹlu. A ko si gboju fo gbogbo eniyan orilẹ-ède naa dá.

S̩e akiyesi pe ki i ṣe iwọn iba ẹbọ ti Ofin beere ni Hesekiah mú wá; o mú meje-meje wá ni iru ẹran kọọkan, boya o ṣe eyi ni èro pe iwa ti o buru jai ti awọn eniyan ti hù gba pe ki o mu un wa ni ilọpo. Ọran iye ainipẹkun niye lori loju Hesekiah ju ohunkohun ninu ayé yii. Awọn ẹlomiran a maa tọỌlọrun wá lati beere è̩bun iye ainipẹkun ṣugbọn wọn a maa ṣe aṣaro lori awọn nnkan wọnni ti yoo gbà wọn lati ri ibukun Ọlọrun yii gbà.

Ohunkohun ha ga jù fun wa lati fi lelẹ bi a ba fé̩ ri ojúrere lọdọỌlọrun? Lati bọ ninu ijiya ọrun apaadi nikan ti tó fun ohunkohun ti o wu ki a padanu ninu aye yii, i baa ṣe anfaani ipò, itura tabi ọrọ. S̩ugbọn Ọlọrun a tilẹ maa fun wa ni idaniloju ti o tayọ pe a ki yoo jiya ayeraye bi a ba tọỌ wa pẹlu ironu piwada. Ọlọrun a maa fun wa ni ireti iye ainipẹkun pẹlu anfaani lati gba ère ati ayọ ainipẹkun ti a ko lè fẹnu sọ.

Awọn ẹlomiran lero pe ohun ọṣọ kekere nì tabi aṣọ igbalode ti kò ba ỌrọỌlọrun mu, adùn è̩ṣẹ fun igba diẹ, ojúrere ẹdá ti oun paapaa yoo duro niwaju itẹ idajọỌlọrun, tabi jijọwọ ifẹ wọn, niyelori ju ibukun Ọrun ti Ọlọrun fi lọ wọn. Nigba miiran awọn eniyan a maa mọọmọ gbé ireti Ọrun ti Ọlọrun na ọwọ rè̩ si wọn sọnu nitori ohun kan ti kò ni pẹ sú wọn lẹyin ọjọ diẹ, ti wọn yoo si gbé sọnu fun ọṣọ titun, tabi faaji ti kò ni pẹ sú wọn, ti wọn yoo si tun gbe sọnu lai pẹ jọjọ bi ohun ti kò nilaari. S̩ugbọn ẹni ti ọkàn rè̩ṣe deedee yoo mọ bi ohun ayé ti jẹ alainilaari tó lẹgbẹ ohun ti Ọrun, yoo si mu ipa ti o tọna, yoo yọnda ohunkohun ti o le gba a ni kikun ki oun ba le ni ojúrere ati ibukun Ọlọrun.

O daju pe Ọlọrun gbọ adura awọn eniyan wọnyi ati ọba wọn. “Nigbati ẹbọ sisun na si bè̩rẹ, orin OLUWA bè̩rẹ pẹlu ... Gbogbo ijọ enia na si wolẹ sìn, awọn akọrin, kọrin, ati awọn afunpè fun: gbogbo wọnyi si wà bḝ titi ẹbọ sisun na fi pari tan.”

Kò si ohun ti o le fun ni layọ ti o pọ tó bayii bi kòṣe pe ki a mọ pe a ti dari gbogbo aiṣe deedee atẹyinwa ji, idalẹbi è̩ṣẹ kò si mọ, o si ni agbára lati gbé igbesi-ayé ti kò lé̩ṣè̩ gẹgẹ bi ilana Ọlọrun ati gẹgẹ bi oungbẹọkàn ara rè̩. Eniyan le wolẹ lati gbadura pẹlu imi ẹdun nitori pe Satani de e ni igbekun, ṣugbọn pẹlu adura igba kan ṣoṣo ti o ti inu ọkàn irobinujẹ wá, idèè̩ṣẹ ati agbára èṣu ti o ti de e nigbekun yoo já. Nigba naa ni orin iyin bẹrẹ. Nigba naa a gbin ayọọrun sinu ọkàn. Nigba naa ni yoo ri ireti ọtun gbà. Lati igba naa lọ, o di ẹda titun, ọmọỌba -- ọmọỌlọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Olododo eniyan ni baba Hesekiah i ṣe tabi eniyan buburu?
  2. Iya Hesekiah jé̩ọmọ wolii Ọlọrun. Ọba miiran wo ni o ri itọni gbà nipa eniyan Ọlọrun yii?
  3. Ọmọọdun meloo ni Hesekiah nigba ti o bẹrẹ si jọba? Ka 1 Timoteu 4:12 ki o si sọọna wo ni ỌrọỌlọrun yii gbàṣẹ ni igbesi-ayé Hesekiah.
  4. Ki ni ohun kin-in-ni ti Hesekiah ṣe nipa isin Ọlọrun?
  5. Ki ni Hesekiah sọ fun awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi lati ṣe?
  6. Awọn alufaa kan kòṣe ohun ti a sọ pe ki wọn ṣe bi o ti tọ ati bi o ti yẹ. Anfaani wo ni wọn padanu nipa isin Ọlọrun? Awọn wo ni a fi rọpo wọn ki iṣẹ-isin Ọlọrun le maa lọ lai si idaduro?
  7. Ki ni Hesekiah sọ pe o wà lọkàn oun lati ṣe?
  8. Ki ni imọran ti Hesekiah fun awọn ọmọ Lefi nipa yiyàn ti Ọlọrun yàn wọn si isin Rè̩?
  9. Nitori awọn wo ni a ṣe ṣe irubọè̩ṣẹ?
  10. Sọ bi awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ti tun gbogbo Tẹmpili ṣe; ati bi wọn ti tẹle Ofin Ọlọrun ni ṣiṣe bẹẹ.
  11. Ki ni iyatọ ti o wà ninu isọdimimọ ti òde ara ati iriri isọdimimọ patapata? Ki ni ipa ti a ni lati sa? Ewo ni ti Ọlọrun?
  12. Iru ipa wo ni orin ati ohun-elo orin kó ninu isin Ọlọrun ni akoko yii? Nigba wo ni orin kikọ bẹrẹ?