1 Kọrinti 15:1-58

Lesson 327 - Junior

Memory Verse
“Ọpé̩ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi” (1 Kọrinti 15:57).
Notes

Iṣẹ ti Paulu ran si Kọrinti

Kọrinti ekinni ati ekeji ti a n pe ni Episteli, jé̩ awọn iwe ti a ti ọwọ Paulu Apọsteli kọ si ijọ ti o wà ni ilu Kọrinti, orilẹ-ède Griki. Paulu ti wà ni ilu yii fun nnkan bi ọdun kan ati oṣu mẹfa, o n waasu, fun Ju ṣaaju lẹyin eyini, fun awọn Keferi, nigba ti a dá ijọ ibè̩ silẹ.

Kọrinti jé̩ olu-ilu ẹkùn kan ati ẹka kan ninu ibujoko ijọba Romu. Ilu yii buru lọpọlọpọ, awọn eniyan ibẹ a si maa dẹṣẹ lọpọlọpọ. Bi ẹnipe iku li opin ohun gbogbo, wọn ti tẹwọ gba ọrọ akọmọna awọn Epikurei, “Ẹ jẹ ki a mā jẹ, ẹ jẹ ki a mā mu; ọla li awa o sá kú” (1 Kọrinti 15:32).

O hàn gbangba pe bi o bá dá eniyan loju wi pe oun yoo kú bi ẹranko ṣe n kú, lai pẹ jọjọ wọn yoo maa huwa bi ẹranko. A ni lati fi yé awọn ara Kọrinti pe ikú ki i ṣe opin ohun gbogbo, Paulu si ni ẹni ti Ọlọrun yàn lati mu ihin pataki yii tọ wọn lọ. Ihin yii ki i ṣe fun awọn wọnni nikan, o n lọ jakejado sibẹ nipa ỌrọỌlọrun. Ọpọlọpọ eniyan lọjọ oni ni o wà ninu è̩ṣẹ lai bẹru ibinu Ọlọrun ti yoo wá sori awọn oluṣe-buburu nigbooṣe. “Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ikọkọ, ibāṣe rere, ibāṣe buburu” (Oniwasu 12:14). Ikú ki i ṣe opin ohun gbogbo, nitori “a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lḝkanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ” (Heberu 9:27).

“Awọn ti Iṣe ti Kristi”

Paulu fi hàn pe Kristi ni o kọ jinde kuro ninu okú pẹlu ara ologo; nitori naa li a ṣe n pe E ni “akọbi lati inu okú wá” (Kolosse 1:18). Ni ọjọ kan awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun ti o kú ninu Kristi yoo ji dide kuro ninu oku, nigba naa a o si gba awọn wọnni ti wọn wa laaye ti wọn si jẹ aṣẹgun “soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun” (1 Tẹssalonika 4:16, 17). Awọn “agbo” Kristi yoo jé̩ alabapin ogo Rè̩ li akoko ipadabọ Rè̩, ṣugbọn a ko gbọdọ rò pe eyi ni “opin” ayé, tabi idajọ ikẹyin. (Wo Ifihan 20:11-15). Gbogbo eniyan ni yoo ji dide, ṣugbọn a kò gbọdọ ni èro pe gbogbo eniyan ni a o gbala, nitori awọn miiran yoo jinde “si iye ainipẹkun, ati awọn miran si itiju ati è̩gan ainipẹkun” (Daniẹli 12:2). Awọn alaiwa-bi-Ọlọrun yoo jinde nikẹyin: ṣugbọn lori iwe yii a kò sọ nipa ajinde ikẹyin tabi opin ayé. S̩ugbọn a sọ nipa rè̩ ninu awọn ọrọ yii pe: “Nigbana ni opin yio de” (1 Kọrinti 15:24).

Bakan naa ni a kò sọ nipa awọn wọnni ti wọn kú pẹlu ero yii ninu ọkan wọn pe wọn yoo bọ kuro ninu idajọỌlọrun lai di atunbi. Paulu n sọrọ nihin yii nipa ajinde ologo awọn “ti iṣe ti Kristi.” Kristi kú nitori è̩ṣẹ wa, a sin In, O si jinde ni ọjọ kẹta (1 Kọrinti 15:3, 4); kò si orukọ miiran labẹỌrun ti a fi funni nipa eyi ti a le fi gba wa la, bikoṣe orukọ Jesu (Iṣe Awọn Apọsteli 4:12). Ki ẹnikẹni ki o maṣe ni ero pe iṣẹ rere nikan yoo fun oun ni ipin ninu iye ainipẹkun; ki ẹnikẹni ki o maṣe ni ireti lati jé̩ alabapin ninu ogo ti o wà li Ọrun lai jé̩ pé o ronu piwada è̩ṣẹ rè̩ ki Ẹjẹ Jesu wè̩é̩ nù.

“A gbin i li ailera”

Nigba ti Ọlọrun dá Adamu O dá a lati inu erupẹ ilẹ -- itumọ orukọ Adamu ni erupẹ pupa. Ọlọrun sọ fun un pe, “Erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ” (Gẹnẹsisi 3:19). Ninu ori kẹẹdogun iwe yii, Paulu n fi hàn fun awọn eniyan mimọ ati awọn ẹlẹṣẹ pé Kristi jinde kuro ninu okú ati pe ni ọjọ kan, a o ji gbogbo awọn ti a ti sin sinu iboji ti ara wọn si ti pada di erupẹ dide kuro ninu okú.

Paulu fi otitọ nla yii wé irugbin ti a gbin sinu ilẹ. Wo bi eyi ti dara jù pe ki a sọ pe a sin in! Gẹgẹ bi irugbin ti a gbin sinu ilẹ ti n kú ti eehu titun si n hù jade lati inu irugbin naa, bẹẹ gẹgẹ ni o ri nigba ti a ba té̩ eniyan mimọỌlọrun sinu iboji. Ara rè̩ yoo pada di erupẹ, ṣugbọn nigba ti ipe ikẹyin bá dún, ara titun, ara-aikú, ara ologo yoo jade lati inu iboji wá. Wo irú ireti ologo ti awọn Onigbagbọ ni! Ara titun yii kò le kú mọ bẹẹni kò le ṣaisan tabi ailera mọ. “A gbin i ni idibajẹ... li ainiyin... li ailera... li ara iyara;” ṣugbọn “a si ji i dide li aidibajẹ... li ogo... li agbara... li ara ẹmi” (1 Kọrinti 15:42-44).

Akọso ati Ikore

Ni akoko Ofin, awọn eniyan ni lati mú akọso ohun-ini wọn wá fun Oluwa: akọmalu, agutan, akọso ọkà, ọti-waini, oróro, ati akọrẹ irun agutan (Deuteronomi 18:3, 4). Akọso jé̩ apẹẹrẹ tabi iwọn iba diẹ ninu eso ti yoo jade lakoko ikore ni ọjọ iwaju. Bakan naa ni Kristi, olufunni ni iye, jé̩ Akọso ninu awọn okú ti o ji dide. Gẹgẹ bi Adamu ti jé̩ okunfa ikú, bẹẹ gẹgẹ ni Kristi jé̩ olufunni ni iye. “Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bḝni a ó si sọ gbogbo enia di alāye ninu Kristi” (1 Kọrinti 15:22).

Paulu sọ wi pe, “Kristi ti kú nitori è̩ṣẹ wa gẹgẹ bi iwe mimọ ti wi; ati pe a sìnkú rè̩, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe-mimọ ti wi” (1 Kọrinti 15:3, 4). Gbogbo akọsilẹ lati ọwọ awọn wolii igbaanì nipa Jesu ni a múṣẹ pérépéré. ỌrọỌlọrun daju to bẹẹ ti kò gbọdọ si iyemeji nipa otitọ ti ikú, isinkú ati ajinde Kristi, ipadabọ Rè̩ lẹẹkeji, tabi eyikeyi ninu Iwe Mimọ. Ni afikun akọsilẹ nipa ajinde lati ọwọ awọn ti o kọ awọn Ihinrere mẹrẹẹrin, a darukọ awọn ẹlẹri ti ọran ajinde ṣoju wọn kòrókòró ninu Bibeli, ninu awọn ẹni ti Paulu jé̩ọkan, bi o tilẹ wi pe, “Emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Apọsteli ... mo ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun” (1 Kọrinti 15:9). O fẹrẹ le ma dariji ara rè̩ nigba ti o ba ranti awọn è̩ṣẹ ti o ti da sẹyin.

Aigbagbọ

“S̩ugbọn ẹnikan yio wipe, Bawo li a o ha ji awọn okú dide? iru ara wo ni nwọn o pada si?” (1 Kọrinti 15:35).

Paulu dahun ibeere yii nipa pipe ìru ẹni bẹẹ ni alaimoye; lotitọ, iwa omugọ ni fun ẹnikẹni lati sé̩ ohun kan nitori pe ẹni naa kò mọ idi ti ohun naa fi ri bẹẹ. Awọn ẹlomiran n fi agbára Ọlọrun diwọn ọgbọn kukuru tabi agbára ti wọn, wọn kò si ni jé̩ gba ohunkohun ti wọn kò le ṣe alaye rẹ gbọ. Ẹ jẹ ki a pinnu lati jé̩ọkan ninu awọn wọnni ti wọn kò ri ṣugbọn ti wọn gbagbọ (Johannu 20:29).

Nigba kan Ẹmi Oluwa gbé Wolii Esekiẹli lọ sinu afonifoji ti o kún fún egungun gbigbẹ. Ẹmi Oluwa si bi i leere pe, “Egungun wọnyi le yè?” (Esekiẹli 37:3). Esekiẹli dahun pe, “Oluwa ỌLỌRUN, iwọ li o le mọ.” Bi a ba lọ ka itàn yii, a o ri i bi Ọlọrun ṣe fi iṣan ati ẹran-ara ati àwọ bo awọn egungun naa, afẹfẹ fé̩ si wọn, eemi si wọ inu wọn, wọn si yè – “ogun nlanla.” A fi iran yii hàn lati jé̩ ki o di mimọ fun Esekiẹli ati awa naa pẹlu pé agbára Ọlọrun le ṣe ohun ti kòṣeeṣe loju ẹda.

Ireti Wa

Ohùn ariwo iro ipè ni a gbọṣiwaju ohùn Ọlọrun nigba ti Ọlọrun fi Ofin fun awọn eniyan ni Oke Sinai. “Ohùn ipè si dún, ti o si mulẹ kijikiji,” ẹru si ba gbogbo awọn ti o gbọ iro ipè na gidigidi (Ẹksodu 19:16-19). Ipè ikẹyin yoo dún ni ọjọ kan, nigba ti ohun ipè na ba si dún, awọn okú olododo yoo ji dide kuro ninu iboji, a o si pa awọn eniyan mimọ ti o wa laaye sibẹ lara dà, wọn yoo si gbé ara aiku, ara ologo wọ (1 Kọrinti 15:52, 53).

Awọn ọkunrin, obinrin, ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin ti wọn ti ni igbala, isọdimimọ, ati Agbára Ẹmi Mimọ ati ina ti wọn si n gbé igbesi-ayé ti o wu Ọlọrun n fi oju sọna pẹlu ayọ fun akoko naa ti Jesu yoo pada wá. Kò si ibẹru ninu ọkàn awọn wọnni ti wọn ti mura silẹ “lati pade Oluwa li oju ọrun,” pẹlu awọn eniyan mimọ ti wọn ti ji dide kuro ninu okú, yoo “wà titi lai lọdọ Oluwa” (1 Tẹssalonika 4:17). Bi Jesu ba fa bibọ Rè̩ sẹyin, ti awọn miiran ninu awọn ti o wa laaye loni ba si fi ayé silẹ, eyi ki i ṣe ohun ti o le ba awọn aṣẹgun lẹru rara, nitori pe ikú kò ni “oró” mọ. Wọn yoo jinde kuro ninu okú ni ọjọ ajinde. Nitori naa “bi a ba ji, tabi bi a ba sùn, ki a le jùmọ wà lāye pẹlu rè̩” (1 Tẹssalonika 5:10). Ireti ologo, ireti ti n mu ọkan yọ!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Awọn wo ni o ri Kristi lẹyin ti O ti jinde kuro ninu okú?
  2. Awọn ẹri miiran wo ni a ni lati fi mọ pe O jinde kuro ninu okú?
  3. Ki ni itumọ “akọso”?
  4. Ọna wo ni ikú fi fara jọ irugbin ti a gbin sinu ilẹ?
  5. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ẹni irapada nigba ti ipe bá dún?
  6. Ki ni ohun ti a n pè ni “oró ikú”? S̩e alaye.
  7. Ki ni ohun ti o wà fun awọn Onigbagbọ lẹyin ikú? Ki ni ohun ti o wà fun awọn ẹlẹṣè̩?
  8. Ki ni o rò pé yoo jé̩ ipin wa bi Kristi kò ba jinde kuro ninu okú?
  9. Ki ni ohun ti o jé̩ ohun danindanin fun wa lati ṣe?