2 Awọn Ọba 13:1-25; 14:9-16

Lesson 328 - Junior

Memory Verse
“Ibaṣepe nwọn gbọn, ki oyé eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn!” (Deuteronomi 32:29).
Notes

Apẹẹrẹ Buburu

Jehoahasi si ṣe eyi ti o “buru li oju OLUWA.” O jọba lori Israẹli fun ọdun mẹtadinlogun ṣugbọn ọdun wọnyi kò mu irọrun wá. Nigba ti eniyan kò ba gbọran si Ọlọrun oun kò le ni ayọ tootọ. Ki i ṣe kiki pe o kó ara rè̩ sinu ipọnju nikan ṣugbọn o kó awọn Ọmọ Israẹli ti o n jọba le lori sinu wahala pẹlu. Igbesi-ayé ti ẹni kọọkan n gbé jé̩ apẹẹrẹ fun awọn ti o wà ni ayika rè̩. Ni ile-iwe, ọmọ buburu a maa kó awọn ẹlẹgbẹ rè̩ sinu iyọnu, ṣugbọn ọmọ rere a maa mú inu awọn eniyan dùn.

Awokọ

Nigba miiran eniyan a saba maa fi igbesi-ayéẹlomiran ṣe àwòkọ. Oun yoo wo ẹni kan ti o fẹ fi iwa jọ. Awọn ọmọde a saba maa ṣe afarawe awọn agbalagba, wọn a si maa ṣe bi wọn ti n ṣe. Lai si aniani iwọ ti ri awọn ọmọ kekere ti wọn n sọọrọ ti kò dara nitori pe wọn gbọ iru ọrọ buburu bẹẹ lẹnu awọn ẹgbọn wọn ọkunrin tabi ẹgbọn wọn obinrin. Awọn ọmọde miiran ti wọn ti ri i bi awọn eniyan jagidi-jagan ti n huwa ninu aworan tẹlifiṣọn, tabi sinima, tabi ti wọn kà nipa wọn ninu awọn iwe iroyin, tabi ti wọn tilẹ fi oju ara wọn ri igbesi-ayé awọn ẹlomiran ti o n huwa jagidi-jagan, a maa ṣe afarawe iwa buburu wọn. Nipa ṣiṣe bẹẹ wọn ti ṣe ara wọn ati awọn ẹlomiran ni jamba wọn si ti ba ọpọlọpọ ohun ini jé̩.

Bibeli sọ fun wa pe, “ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wòẹni diduro ṣinṣin” (Orin Dafidi 37:37). Eyi ni pe ki a ṣe awòkọ igbesi-ayé awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun. S̩ugbọn ju gbogbo rè̩ lọ, a ni lati ṣe afarawe Kristi tikara Rẹ, nitori pe Oun ni Awokọ wa, o si yẹ ki a tọ ipasẹ rè̩ (Ka 1 Peteru 2:21).

Dipo ki Jehoahasi ṣe afarawe awọn ọba ti i ṣe ẹni iwa-bi-Ọlọrun, o tẹle è̩ṣẹ Jeroboamu ẹni ti o mu Israẹli dẹṣè̩. Igba mọkan dinlogun ọtọọtọ ni a kọ akọsilẹ ninu Bibeli nipa Jeroboamu pe: “Ẹniti o mu Israẹli ṣè̩.” Iru eniyan bayii ni Jehoahasi tè̩ lé.

Apẹẹrẹ ti kò Nilaari

Jehu, ẹni ti o pa awọn olusin Baali run gẹgẹ bi aṣẹỌlọrun, ni baba Jehoahasi. Bi o tilẹ jẹ pe Jehu gbọran si Ọlọrun lẹnu lẹẹkan ṣoṣo yii, sibẹ oun kò “ṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rè̩ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israẹli” (2 Awọn Ọba 10:31). Baba Jehoahasi tẹle apẹẹrẹ buburu Jeroboamu. Nitori pe Jehu kò yà kuro ninu sinsin ere ẹgbọrọ maluu, Ọlọrun fi aye silẹ fun Hasaeli, ọba Siria, lati ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli. A le lero pe Jehoahasi yoo kọẹkọ lara iriri ti baba rè̩ ri yii. A le maa ro pe yoo ṣe akoso ijọba rè̩ lọna ti yoo mu ibukun Ọlọrun wá dipo idajọỌlọrun. Jehoahasi dá iru è̩ṣẹ kan naa ti baba rè̩ dá – o tẹle è̩ṣẹ Jeroboamu. Iru ijiya kan naa ti o wá sori baba rè̩ lati ọwọỌlọrun ni o wa sori oun naa -- nigba gbogbo ni awọn ara Siria n ni in lara.

Titaku sinu È̩ṣẹ

Bibeli kọ ni pe idajọỌlọrun wa lori awọn ti n dẹṣẹ. Bibeli sọ fun ni bakan naa pe “nigbati enia buburu ba yipada kuro ninu iwa buburu rè̩ ti o ti ṣe, ti o si ṣe eyiti o tọ, ati eyiti o yẹ, on o gba ọkàn rè̩ là lāye” (Esekiẹli 18:27). S̩ugbọn Jehoahasi kò yi pada kuro ninu ọna buburu rè̩. Nitori è̩ṣẹ Jehoahasi oju Ọlọrun kan si awọn Ọmọ Israẹli. Jehoahasi ati awọn eniyan rè̩ jiya è̩ṣẹ wọn.

Bakan naa ni o ri lọjọ oni. Bi awọn eniyan kò bá yi pada kuro ninu è̩ṣẹ wọn, idajọỌlọrun yoo wá sori wọn. Bi wọn bá gbadura si Ọlọrun ti wọn si tọrọ idariji, Oun yoo gbà wọn là, yoo si mu idajọ kuro. Wọn yoo ri aanu nigba ti wọn ba jẹwọè̩ṣẹ wọn ti wọn si kọọ silẹ (Owe 28:13). Bi wọn ba taku sinu è̩ṣẹ wọn sibẹ, wọn kò le ni igbala, ijiya ayeraye si ni ipin wọn. Ki wọn tilẹ to fi ayé silẹ wọn yoo maa jiya è̩ṣẹ wọn.

Idajọ

Eyi ni apa kan ninu idajọỌlọrun lori Jehoahasi ati awọn Ọmọ Israẹli: “OLUWA ... si fi wọn le ọwọ Hasaeli ọba Siria, ati le ọwọ Bẹnhadadi ọmọ Hasaeli.” Ni gbogbo ọjọ ayé wọn, awọn ọba Siria mejeeji wọnyi pọn awọn Ọmọ Israẹli loju. Wọn pa ọpọlọpọẹlé̩ṣin wọn, wọn ba awọn kè̩ké̩ wọn jé̩. Wọn kò fi àye silẹ fun awọn ọmọ-ogun Israẹli lati pọ ni iye. Wọn pa awọn ọmọ-ogun, wọn si “ti lọ wọn mọlẹ bi ẽkuru”; ọrọ wọnyi fi hàn pe a fẹrẹ pa awọn ọmọ-ogun Israẹli run tán. A fi ye wa pe ni igba atijọ, ilẹ ipaka jé̩ ibi ti o le to bẹẹ ti ekuru kò ni pọ nibẹ, bẹẹ ni erupẹ ki yoo pọ to bẹẹ ninu ọkà ti a pa nibẹ. Lati lọ wọn “mọlẹ bi ekuru” fi hàn pe awọn ọmọ-ogun wọn kò pọ to bẹẹ, wọn ko jamọ nnkankan. Awọn ọta ti sọ wọn di ranpẹ, awọn ti o kù kò si lagbara. Irú awọn ọmọ-ogun bẹẹ kò le ko ọta loju bẹẹ ni wọn kò fun Israẹli ni iṣẹgun.

Wiwa Ọlọrun

Ni akoko inira, Jehoahasi wáỌlọrun fun iranwọ. Oun kò tọrọ idariji è̩ṣẹ rẹ bẹẹ ni kò si kọ wọn silẹ. Jehoahasi beere iranlọwọ nitori pe oun ati awọn eniyan rè̩ di ijẹ fun awọn ara Siria. Oluwa boju wo awọn Ọmọ Israẹli ti a ni lara, pẹlu aanu. Nitori pe Ọlọrun ranti majẹmu Rè̩ pẹlu Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu, O dahun adura Jehoahasi. O ti ṣeleri lati jẹỌlọrun wọn ati Ọlọrun awọn ọmọ wọn. O ti ṣeleri wi pe Oun yoo fi ilẹ Kenaani fun wọn ni “iní titi lailai.” O ti pinnu lati bukun wọn niwọn igba ti wọn ba pa majè̩mu Rè̩ mọ ti wọn si gbọran. (Ka Gẹnẹsisi 17:1-9).

Adura Gba

Bawo ni Ọlọrun ṣe dahun adura Jehoahasi? O rán iranwọ si awọn Ọmọ Israẹli. Ki i ṣe akọni kan ni a gbé dide bẹẹ ni ki i ṣe nipa ogun kan gbọn ọn. Idasilẹ dé lẹyin ọdun diẹ ani lati ọwọ Jehoaṣi ẹni ti o gba awọn ilu Israẹli wọnni ti awọn ara Siria ti kó, pada; ati lati ọwọọmọ rè̩ Jeroboamu, ẹni ti o gba aala awọn Ọmọ Israẹli pada. Ọlọrun kò “pa orukọ Israẹli ré̩ labẹọrun: ṣugbọn o gbà wọn nipa ọwọ Jeroboamu” (2 Awọn Ọba 14:27).

Ki ni ṣe ti Jehoahasi fi wá iranwọỌlọrun? Eniyan le maa rò pe oun yoo wá iranwọ lọ sọdọ awọn ere ẹgbọrọ maluu ti o n bọ. S̩ugbọn ere lasan ni wọn i ṣe, wọn kò le ran an lọwọ rara. Nipa wiwáỌlọrun, a dá awọn eniyan rè̩ si, wọn si bọ lọwọ iparun ti a ba fi pa wọn run patapata. Ọlọrun tun fun wọn ni aafo kan si i lati ronu piwada ati lati yi pada lati sin Ọlọrun tootọ ti i ṣe Ọlọrun alaaye.

Aabo ati Iranwọ

Nigba pupọ lọjọ oni ni awọn eniyan n bọ lọwọ jamba ati ikú ojiji nipasẹ adura awọn eniyan wọn ti o jé̩ Onigbagbọ. Ọlọrun dá wọn si fun idi kan pataki – ki wọn le ronu piwada, ki wọn le ni igbala, ati ki wọn le sin In. Nigba pupọ ni Ọlọrun n dahun adura awọn ti kò ni igbala. Idahun si adura ẹni yẹ ki o fun ni ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun ki o si fi hàn fun ẹni naa pe o jẹỌlọrun nigbese lati sin In ati lati dupẹ fun Un.

A ri kà péỌlọrun yoo sunmọ wa nigba ti a ba tọỌ lọ ninu adura. “Ẹ sunmọỌlọrun, on o si sunmọ nyin” (Jakọbu 4:8). Onipsalmu wipe: “O dara fun mi lati sunmọỌlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa ỌLỌRUN, ki emi ki o le ma sọrọ iṣẹ rẹ gbogbo” (Orin Dafidi 73:28).

S̩ugbọn Jehoahasi n dẹṣẹ niwaju Ọlọrun nipa titaku sinu ibọriṣa. Ọmọ rè̩, ẹni ti o jọba lẹyin rè̩ pẹlu ṣe eyi ti o buru niwaju Ọlọrun. “On kò lọ kuro ninu gbogbo è̩ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israẹli ṣè̩: ṣugbọn o rin ninu wọn.”

Ọmọ Jehoahasi, ẹni ti o jọba ni Israẹli lẹyin rè̩ ni a n pe ni Jehoaṣi, a si tun maa n pe e ni Joaṣi. Ẹni kan si tun wa ti o tun n jẹ Joaṣi. Oun jẹọmọ Ahasiah ọba Juda. A ti kẹkọọ nipa Joaṣi ọmọdekunrin ti i ṣe ọba Juda (Ẹkọ 319). Jehoaṣi ni a o maa pe ọmọ Jehoahasi ninu ẹkọ wa yii.

Eliṣa

Ni ọjọ wọnni, Eliṣa ni wolii Oluwa. Ni igbẹyin aye rè̩ o ṣaisan. Jehoaṣi ọba Israẹli si lọ lati bẹẹ wò. Ọba yii lọ ki Woli Ọlọrun yii, o si ba a kẹdun nipa aisan ti o n ṣe e. Jehoaṣi ṣe atunwi awọn ọrọ ti Eliṣa ti fi ẹnu ara rẹ sọ nigba kan ri. Eliṣa sọọrọ naa nigba ti a fi aajà gbé Elijah lọ si Ọrun (2 Awọn Ọba 2:11, 12). “Baba mi, baba mi! kẹké̩Israẹli, ati awọn ẹlẹṣin rè̩.” Lai si aniani awọn ọrọ wọnyi fi hàn pe wolii yii ti ṣe ohun pupọ fun awọn Ọmọ Israẹli nipa adura ati imọran rè̩ ju ohun ti gbogbo awọn ọmọ ogun wọn ti ṣe. Gẹgẹ bi Eliṣa ti bu ọlá yii fun Elijah, bakan naa ni Jehoaṣi bu ọlá kan naa fun Eliṣa. Bi o tilẹ jẹ pe Jehoaṣi n bọriṣa, o jẹwọ pé Eliṣa, wolii Oluwa, ni ẹni ti o múọpọ iṣẹgun bá Israẹli. Ọba yii fi hàn pe oun ni igbagbọ ninu adura ati ọrọ Eliṣa.

Ọrun ati ọfà

Eliṣa sure kan fun Jehoaṣi ki o to kú. O ṣẹlẹ lọna bayii: Eliṣa sọ fun Jehoaṣi pe ki o ta ọfà lati oju ferese ti o kọju si ila oorun. Eliṣa gbéọwọ rè̩ le ọwọọba nigba ti ọba n fa ọrun. Ọwọ Eliṣa kò lagbara rara nitori aisan ti o ṣe e ṣugbọn Oluwa mu ọwọ rè̩ le. Eliṣa paṣẹ fun ọba ki o ta ọfà naa. Nigba ti ọfà naa n kùn lọ ninu afẹfẹ, Eliṣa wipe “ọfà igbala OLUWA.”

Lai ni Itara

Eliṣa sọ fun Jehoaṣi pẹlu pe ki o ta iyoku ọfà naa silẹ. Jehoaṣi ta ọfà na silẹ nigba mẹta pere lai ni itara. Eliṣa ba a wi nitori iwa aini itara rè̩. O sọ fun Jehoaṣi pe oun i ba ṣẹgun awọn ara Siria patapata bi o ba jẹ pe o ta ọfà naa silẹ nigba marun un tabi mẹfa. S̩ugbọn nisisiyii igba mẹta pere ni yoo ni iṣẹgun lori awọn ara Siria. Lẹyin ikú Eliṣa, asọtẹlẹ naa ṣẹ. Igba pupọ ni Jehoaṣi bá Bẹnhadadi, ọmọ Hasaeli, ọba Siria jagun. S̩ugbọn igba mẹta pere ni Jehoaṣi ṣẹgun gẹgẹ bi ọrọ Wolii Oluwa.

Jehoaṣi kò ni itara ati iforiti lati fi àya rán iṣoro ati ogun ayé titi yoo fi bori. O dabi awọn miiran ti n gbadura fun ibukun kan pato tabi lati ri iriri kan gbà lati ọdọỌlọrun lọjọ oni, ṣugbọn wọn dẹkun adura ígbà lẹyin igba diẹ. Wọn kuna lati gbadura titi wọn yoo fi ri idahun si adura wọn. Ẹwẹ, wọn dabi awọn wọnni ti o joko sile tabi ti o n fi akoko wọn tafala nipa tita okúọrọ sọ pẹlu awọn ọmọbinrin tabi ọmọkunrin ẹlẹgbẹ wọn lakoko ti o yẹ ki wọn bẹrẹ si mú ohun kan ṣe ti yoo mu ki wọn le wulo ninu Ihinrere lẹyin ọla, boya nipa lilo ohun-elo orin, orin kikọ, tabi nipa sisọẹri, nipa adura gbigba, riran awọn alaisan ati awọn alaini lọwọ, tabi nipa kikọ iṣẹọwọ kan ti o le wulo ninu iṣẹ ijọ.

Ọkan rè̩ gbé soke

Ohun kan tun ṣẹlẹ lakoko ijọba Jehoaṣi, nigba ti Ọlọrun lo o lati mu idajọ wa sori Amasiah, ọba Juda. Amasiah “ṣe eyi ti o tọ li oju OLUWA, ṣugbọn ki iṣe pẹlu 6ile, o kó awọn oriṣa ọmọ Seiri dani. Kò kó wọn wa si ile gẹgẹ bi ohun iranti. O gbé wọn kalẹ gẹgẹ bi ọlọrun rè̩. O fori balẹ fun wọn, o si sun turari si awọn oriṣa wọnni ti kò lagbara lati gba awọn ti n sin wọn silẹ kuro lọwọ Amasiah.

Ọkan Amasiah gbé ga soke, o tilẹ n fọnnu. O dabi ẹni pe o ti gbagbe ọrọ eniyan Ọlọrun ti o sọ fun un lati “mu ara le fun ogun na: ... Ọlọrun sa li agbara lati ṣe iranlọwọ, ati lati bì ni ṣubu” (2 Kronika 25:8).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Jehoahasi ati Jehoaṣi ti jé̩ si ara wọn?
  2. Ta ni wọn fi ṣe awokọ lati tẹle?
  3. Ki ni ṣe ti Jehoahasi fi wáỌlọrun?
  4. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi dahun adura rẹ?
  5. Ta ni ẹni ti o ṣe ohun pupọ fun awọn Ọmọ Israẹli ju ohun ti awọn kẹké̩ ati ẹlẹṣin wọn ṣe?
  6. Ki ni ṣe ti Jehoaṣi lọ bẹ Eliṣa wò?
  7. Ki ni asọtẹlẹ ti Eliṣa sọ fun Jehoaṣi?
  8. Sọ ohun ti o ṣẹlẹ si ọkunrin ti a sọ oku rè̩ sinu iboji Eliṣa?
  9. Nigba wo ni ọkàn Amasiah gbe ga soke ti o si n fọnnu?
  10. Ki ni ṣe ti Jehoaṣi fi bori Amasiah?