Amosi 1:1-5; 2:4-8; 4:11-13; 5:18-20; 7:10-17; 8:4-13; 9:11-15

Lesson 329 - Junior

Memory Verse
“È̩ru Oluwa mọ, pipẹ ni titi lai; idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn” (Orin Dafidi 19:9).
Notes

Oluṣọ-agutan di Wolii

Nigba pupọ ninu itàn Israẹli, Ọlọrun rán awọn wolii lati sọ fun awọn ayanfẹ Rè̩ ni ti awọn ohun ti n bọ wáṣẹlẹ. Nitori ti awọn Ọmọ Israẹli a maa digba pada sinu ibọriṣa, ọrọ ti o saba ma a n ti ẹnu awọn wolii wọnyi jade ni ikilọ nipa idajọỌlọrun.

Ọkan ninu awọn woli naa ni Amosi, oluṣọ-agutan kan lati Tekoa, ileto kan ti o wa ni nnkan bi mile mẹwaa ni iha guusu Jerusalẹmu. Oun kò lọ si ile-ẹkọ awọn woli tẹlẹ ri, bẹẹni ki i ṣe lati inu idile nla ni a gbe bi i, ṣugbọn Ọlọrun ri ọkàn rè̩ O si ri i wi pe Oun le fi ọkan tán an, Oun si le ràn an niṣẹ si Israẹli lati Ọrun wá.

Kò dùn mọ Amosi lati sọ fun awon Ọmọ Israẹli pe ibi n bọ wá bá wọn, ṣugbọn ki ni o le ṣe nigba ti ọwọỌlọrun wa lara rè̩? “Oluwa ỌLỌRUN ti sọrọ, tani lèṣe aisọtẹlẹ?” (Amosi 3:8). Ogoji igbà ni a kà ninu asọtẹlẹ rè̩ pe: “Bayi li OLUWA wi.” Ohun ti Ọlọrun sọ fun Amosi ni o ni lati sọ.

Nitori Awọn Irekọja Mẹta

Awọn orilẹ-ède ti Amosi sọtẹlẹ si ni akọkọ ni awọn orilẹ-ède ti o ti huwa ikà si Israẹli. Nigba ti Ọlọrun pe Abramu lati jé̩ baba orilẹ-ède iran Ju, O ti sọ bayii pe, “Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré” (Gẹnẹsisi 12:3). Ọpọlọpọ orilẹ-ède keferi ni o ti huwa buburu si Israẹli, gbogbo è̩ṣẹ wọn ni o si wá ni iranti. Nisisiyi a o jẹ wọn niya nitori è̩ṣẹ wọn. “Nitori irekọja mẹta ti Damasku, ati nitori mẹrin, emi ki o yi iyà rè̩ kuro.” Nigba pupọ ni Amosi tẹnu mọọrọ kan naa: “Nitori irekọja mẹta ..., ati nitori mẹrin,” itumọ eyi ni pe ki i ṣe nitori è̩ṣẹ kan tabi meji ni wọn yoo ṣe jiya, ṣugbọn nitori ti wọn ti huwa buburu nigba pupọ ti o yẹ ki wọn jiya nitori rè̩. S̩ugbọn ẹyọè̩ṣẹ kan ṣoṣo tó lati fa idajọ wá sori ẹlẹṣẹ. Meloo meloo ni awọn wọnyi ti wọn ti dẹṣẹ pupọ.

Inu awọn Ọmọ Israẹli dùn lati gbọ nipa idajọ ti yoo wá sori awọn keferi, sugbọn wọn ka ara wọn si ayanfẹỌlọrun pataki ati pe okun ifẹ naa kò lè já. Wọn gba pe dandan gbọn, Ọlọrun ni lati ran wọn lọwọ bi wọn tilẹ n dẹṣẹ.

Awọn miiran wà lọjọ oni ti wọn rò pé wọn jé̩ ayanfẹỌlọrun, ati pe bi o ti wu ki wọn ti maa dẹṣẹ tó, wọn gba pe ọmọỌlọrun ni wọn sibẹsibẹ wọn yoo si lọ si Ọrun. S̩ugbọn Bibeli sọ fun ni wi pe: “Ọkàn ti o báṣè̩, on o kú” (Esekiẹli 18:4), ẹnikẹni ti o wu ki o le jé̩.

Awọn Ọlọrọ Aninilara

Lẹyin awọn ọrọ idajọ ti Amosi sọ si awọn keferi, o yi pada si Israẹli lati sọ ohun wọnni ti Ọlọrun ni ninu si wọn. Ni akoko yii, Israẹli jé̩ orilẹ-ède ti n ṣẹgun awọn ọta rè̩, ọkan rè̩ si gbega nitori agbára rè̩. Ọpọlọpọọlọrọ wà ni ilẹ naa, wọn n jẹ ayé ijẹkujẹ, wọn si n ni awọn talaka lara. Awọn Ọmọ Israẹli wọnyii tilẹ n ta awọn eniyan si oko ẹrú.

Ododo Ọlọrun ni iwaasu Amosi duro le lori. Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan Rè̩ ki o fẹran ara wọn ki wọn si maa ṣaanu fun awọn talaka, ki wọn ran awọn alaini lọwọ, leke gbogbo rè̩, ki wọn ṣe idajọ otitọ lai ṣe egbè. Amosi tẹnu mọọn fun awọn eniyan wọnyi gidigidi pe wọn ni lati huwa rere si ọmọnikeji wọn ki wọn si fẹ aanu bi wọn ba fẹ gbadun ayé wọn, ki wọn jumọ gbé ni irẹpọ, ki wọn si ri ojurere Ọlọrun.

Awọn anikan jọpọn ti wọn mọ ti ara wọn ati ti awọn ẹbi wọn nikan, ti wọn n fi gbogbo akoko ṣe akojọ fun ara wọn nikan, kò ni ayọ. Awọn eniyan ti o layọ ni awọn wọnni ti wọn n fi fun ẹlomiran ti wọn si n sa ipa wọn lati ṣe iranwọ fun awọn alaini.

Ibukun Lori Adéhun

Ọlọrun sọ nitootọ pe ayanfẹ Oun ni Israẹli i ṣe. “Enia mimọ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ: OLUWA Ọlọrun rẹ ti yàn ọ lati jé̩ enia ọtọ fun ara rè̩, jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ” (Deuteronomi 7:6). S̩ugbọn ileri ibukun yii duro lori igbọran wọn si gbogbo àṣẹỌlọrun.

Nisisiyii, Amosi ni lati sọ fun wọn pe wọn kò pa àṣẹ wọnni mọ, nitori naa wọn kò lẹtọ si awọn ibukun ti wọn rò pe o jẹ ti wọn.

Nigba ti Mose sọ pe Ọlọrun yoo pa majẹmu Rè̩ mọ pẹlu awọn wọnni ti wọn fẹẸ, ani titi de ẹgbẹrun iran, o ṣe afi kun yii pe, “Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rè̩ li oju wọn, lati run wọn” (Deuteronomi 7:9, 10).

IdajọỌlọrun daju. Ohunkohun ti Ọlọrun sọ yoo ṣẹ. Awọn obi le halẹ nigba miiran lati jẹ awọn ọmọ wọn niya bi wọn ba ṣaigbọran, ṣugbọn nigba ti ọmọ naa báṣaigbọran, wọn le gbagbe lati jẹẹ niya. Eyi kò ri bẹẹ pẹlu Ọlọrun. Ọrọ ti Ọlọrun ba sọ yoo ṣẹ dandan. A ni lati ri i daju pe a gbọran si ilana ti Ọlọrun fi lelẹ fun wa ninu Bibeli ki a ba le gbadun awọn ibukun ti O ti ṣeleri, dipo pe ki a jé̩ alabapin ninu idajọ ti n bọ wá sori awọn alaigbọran.

Kikọ Eti didi

Awọn Ọmọ Israẹli kò fẹ irúọrọ ti Amosi sọ, wọn si sọ fun un pe ki o ma ṣe sọrọ bẹẹ si wọn mọ. Ọpọlọpọ eniyan lọjọ oni ni kò fé̩ gbọ nipa idajọỌlọrun, ṣugbọn idajọỌlọrun n bọ wá, bi wọn fé̩ tabi wọn kò fé̩ gbọ. Kò ha sàn lati mọ ewu ti o wa niwaju, ki iwọ ki o le sá asala? Bi ile rẹ ba n jona iwọ yoo ha fẹ ki awọn eniyan fi otitọ yii pamọ fun ọ nitori pe ki i ṣe ihin ayọ? Iwọ ki yoo ha kuku fẹ mọ ki iwọ baa le tete ké si awọn panapana ki ile rẹ tó jona tán?

Amosi n fé̩ lati ran awọn Ọmọ Israẹli lọwọ. Kò fẹ ki wọn jiya. S̩ugbọn wọn kò naani gbogbo itara rè̩, ani ati awọn ẹlẹsin paapaa. Olori alufaa ranṣẹ si ọba wi pe ọlọtẹ eniyan ni Amosi jé̩ si orilẹ-ède rè̩. Amosi sọtẹlẹ pe ọba yoo kú, ati pe awọn ọta yoo kò Israẹli lẹrú. Otitọ ni Amosi sọ ki i si ṣe ẹbi rè̩. Ọlọrun n ran idajọ sori Israẹli nitori è̩ṣẹ rè̩.

Nigba ti Jesu wà ni aye, O kilọ fun awọn eniyan lati ronu piwada bi bẹẹkọ wọn yoo ṣegbe. Wọn kò gbọ ti Rè̩, ṣugbọn wọn wi pe, “Mu u kuro.” Wọn pa A gẹgẹ bi wọn ti pa awọn wolii ti o wàṣiwaju Rè̩. S̩ugbọn ọrọ ti O sọ bẹrẹ si ṣẹ lai pẹ jọjọ; laaarin ogoji ọdún lẹyin eyi, awọn Ju ti o kú le ni aadọta ọkẹ, aimoye ọkẹ si ni awọn ti wọn bọ sinu wahala ati inira. Ẹ maṣe jẹ ki a gbagbe pé awọn nnkan ti Ọlọrun ba ti sọ yoo ṣẹ.

Wọn Ri Aanu Gbà

Awọn idajọ ti Ọlọrun ti ẹnu Amosi sọ fun awọn Ọmọ Israẹli ba ni lẹru to bẹẹ ti Amosi bẹrẹ si gbadura fun wọn. “Oluwa ỌLỌRUN, dawọ duro, emi bè̩ọ: Jakọbu yoo ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on.” Amosi n bẹbẹ fun aan u fun awọn Ọmọ Israẹli. Ọlọrun gbọ adura naa. O si dawọ idajọ naa duro. S̩ugbọn sibẹ Israẹli kò ronu piwada.

A ti fa ọwọ idajọỌlọrun sẹyin kuro lori orilẹ-ède wa nitori pe awọn eniyan pupọ wà ti n gbadura si Ọlọrun fun aanu. Awọn eniyan wà sibẹ ti a o gbala. S̩ugbọn bi a o ti dawọ idajọ naa duro pé̩ tó ni a kò mọ. Ọjọkọjọ ni Ọlọrun le sọ pe, “O to.” Oun yoo kó awọn eniyan Rè̩ olododo kuro ninu ayé, gbogbo ibinu akoko Ipọnju Nla yoo si wá sori awọn wọnni ti wọn kọ lati gbọ ikilọ.

Iran

Ọrọẹnu ni Ọlọrun kọ fi sọ fun Amosi nipa idajọ ti n bọwa. S̩ugbọn bi akoko ti n lọ, iṣipaya naa tubọ n tobi si i, Ọlọrun si fi awọn ohun ti n bọ wá hàn fun Amosi ninu iran. Nikẹyin gbogbo rè̩, Amosi ri iran bi Oluwa ti duro nibi pẹpẹ ti o si wipe gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ni yoo kú. “Bi nwọn tilẹ wà ilẹ lọ si ọrun-apadi, lati ibè̩ li ọwọ mi yio ti tè̩ wọn; bi nwọn tilẹ gùn okèọrun lọ; lati ibè̩ li emi o ti mu wọn sọkalè̩: ...ati bi a tilẹ fi wọn pamọ kuro niwaju mi ni isàlẹ okun; lati ibè̩ na li emi o ti paṣẹ fun ejò ni, on o si bù wọn jẹ” (Amosi 9:1-3).

Ọjọ Oluwa

Awọn Ọmọ Israẹli n foju sọna fun ọjọ Oluwa. Wọn rò pe Ọlọrun yoo rán idajọ sori awọn keferi, yoo si mu ki Israẹli jọba lori gbogbo ayé. S̩ugbọn Amosi kilọ bayii pe: “Mura lati pade Ọlọrun rẹ.” O sọ fun wọn pe ọjọ Oluwa ki yoo jé̩ọjọ imọlẹ bi kòṣe ọjọ okunkun biribiri. Bi wọn ba rò pe wọn yoo ri iranlọwọ lọjọ naa wọn yoo dabi ẹni ti o n sa fun beari ti o bá kiniun pade, tabi ẹni ti o sa wọ inu ile rè̩ fun aabo ti ejò si bu ṣán nibẹ. Oró ejò buru ju ki beari bu ni jẹ lọ. Ọna kan ṣoṣo ni o wà lati bọ kuro ninu ibinu Ọlọrun, ọna kan ṣoṣo naa ni lati ronu piwada ati lati kuro ninu è̩ṣẹ.

Bi ẹnikan kò ba di atunbi, kò si ireti fun un lati bọ kuro ninu idajọỌlọrun bi o ti wu ki ẹni naa maa jẹọrọ Bibeli lẹnu tó, ki o si maa ni ireti pe oun jé̩ Onigbagbọ

Iyàn ỌrọỌlọrun

Amosi sọ ni ti akoko kan nigba ti iyàn ti yoo tayọ iyàn ounjẹ yoo mú. Inira pupọ maa n wa fun eniyan nigba ti eniyan kò ba ri ounjẹ jẹ; ṣugbọn wọn lero pe wọn le maa ba ayé wọn lọ bẹẹ lai si Bibeli. S̩ugbọn akoko n bọ wá nigba ti awọn eniyan yoo lọ lati okun de okun, wọn yoo tilẹ sare, ki wọn ba le lọ gbọỌrọỌlọrun. Awọn ti kò naani lati pa ofin Ọlọrun mọ ni ọkàn wọn, awọn wọnni ti wọn ti fi ẹkọ Jesu ṣẹfẹ, ti wọn si sọ wi pe “Mu u kuro” gẹgẹ bi awọn Ju ti sọ nigba ti wọn, yoo fẹ gbọ Otitọ, ṣugbọn wọn ki yoo ri i. Ireti kan ṣoṣo ti wọn ni ti bọ.

O yẹ ki a fi ọwọ danindanin mu ỌrọỌlọrun! Ọrọ naa ni Imọlẹ wa lati ṣamọna wa ninu aye buburu yii, ati lati mu wa lọ sinu Ogo. Oun ni itunu wa nihin. Oun ni ounjẹ wa lati Ọrun, ilera fun ara wa, agbára fun iṣé̩ gbogbo.

Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún

Sibẹ Amosi fi hàn pe ireti wa fun Israẹli. Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun yoo mu idajọ wọnyi wá sori Israẹli, sibẹ Oun yoo gba awọn diẹ là. Awọn eniyan diẹ yoo yi pada si Ọlọrun wọn yoo jẹ igbadun ibukun Kenaani nigba ti a bá mú egun kuro. “Emi o si tun mu igbèkun Israẹli enia mi padà bọ, nwọn o si kọ ahoro ilu wọnni, nwọn o si ma gbe inu wọn; nwọn o si gbin ọgbà-àjara, nwọn o si mu ọti-waini wọn; nwọn o ṣe ọgbà pẹlu, nwọn o si jẹ eso inu wọn. Emi o si gbìn wọn si ori ilẹ wọn, a kì yio si fà wọn tu mọ kuro ninu ilẹ wọn, ti mo ti fi fun wọn, li OLUWA Ọlọrun rẹ wi.”

Amosi ṣe oloootọ ni sisọ gbogbo idajọ gbigbona ti yoo de ba Israẹli fun wọn, Ọlọrun si fun un ni ayọ ninu ireti Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, ti gbogbo awọn ti n gbé igbesi-ayé iwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu yoo ṣe alabapin rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni Amosi?
  2. Ki ni awọn ẹri rere ti o ni ti o fi di wolii?
  3. Ta ni Amosi kọkọ sọrọ si?
  4. Ki ni ṣe ti idajọ fi n bọ wá sori awọn orilẹ-ède wọnni?
  5. Ki ni ṣe ti Israẹli fi rò pé wọn kò ni jiya?
  6. Ki ni igbagbọ awọn Ọmọ Israẹli nipa Ọjọ Oluwa?
  7. Ki ni Amosi sọ nipa iyàn ỌrọỌlọrun?
  8. Ki ni Ọlọrun yoo ṣe fun awọn Ju ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun ọdún?