Mika 4:1-7; 5:2; 6:1-8; 7:18-20

Lesson 330 - Junior

Memory Verse
“Iwọ o si sọ gbogbo è̩ṣẹ wọn sinu ọgbun okun” (Mika 7:19).
Notes

Awọn Wolii Agba ati Wolii Kekere

Wolii ni ẹni ti o jé̩ aṣoju Ọlọrun laaarin awọn eniyan, tabi ẹni ti n sọ ohun ti Ọlọrun fi hàn án pe o n bọ wa ṣẹlẹ lọjọ iwaju. Oniwaasu tootọ, ẹni ti i ṣe olododo ninu Ihinrere pẹlu jẹ wolii Ọlọrun, nitori pe o n sọ otitọỌrọỌlọrun gẹgẹ bi Ẹmi Mimọ ti fi hàn fun un. Ninu Majẹmu Lailai a ri awọn wolii agba mẹrin ti wọn sọ asọtẹle awọn ohun ti n bọ wáṣẹlẹ lọjọ iwaju, ati awọn wolii mejila kekere. A kò pe wọn ni wolii agba ati kekere nitori pe akọsilẹ awọn kan ṣe pataki ju akọsilẹ awọn miiran lọ, nitori “gbogbo iwe-mimọ li o ni imisi Ọlọrun” (2 Timoteu 3:16), ṣugbọn a pin wọn si ipa meji wọnyii nipa bi akọsilẹ ti ẹni kọọkan wọn ti pọ tó.

Ohun ti Ọlọrun sọ ninu Ọrọ Rè̩ Mimọ nipa imisi awọn iranṣẹ Rè̩ yoo ṣẹ, ẹnikẹni ti o wu ki o kọọ i baa ṣe Mose, Dafidi, Sọlomọni, Mika, ọkan ninu awọn Apọsteli tabi ẹnikẹni ti o wu ki o jẹ ninu awọn miiran ti o kọ akọsilẹ, tabi lati ọwọ awọn ti wọn kọ apa kan ninu Bibeli ti a kò tilè̩ darukọ wọn. “Asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia mimọỌlọrun nsọrọ lati ọdọỌlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọẸmi Mimọ wá” (2 Peteru 1:21).

Bibeli titun kan jade ni ède Gẹẹsi ti a ṣẹṣẹ tumọ. S̩ugbọn itumọ igbalode yii kò duro deedee lori ỌrọỌlọrun gẹgẹ bi o ti wa gan an ninu ède ti a fi kọ Bibeli ni ipilẹṣẹ. Bibeli ti a tumọ si ède Gẹẹsi (lati inu ède miiran) lakoko ijọba Ọba JAKỌBU lọ taara, o si peye. Awọn eniyan meji din laadọta ti wọn jé̩ ijimi ninu è̩kọ ti wọn si jé̩ ojiṣẹỌlọrun tootọ -- ti wọn kò ni ero meji lọkan ju pe ki wọn gbé ojulowo Bibeli ti itumọ apapọ rè̩ peye le awọn eniyan lọwọ ni o ṣe itumọ ti a mẹnu kàn yii. Ọlọrun ti fi ibukun Rè̩ si è̩da Bibeli yii ti ọkẹ aimoye eniyan ti ka fun itọni. Otitọ yii ti gbilẹ pe, “ire ati anfaani ti Bibeli ti a tumọ si ède Gẹsi nigba ijọba Ọba JAKỌBU ṣe ninu ẹsin wa ati awọn iwe kikà gbogbo ti a n tè̩ jade kòṣe fẹnu sọ.”

Iranti

Ninu ẹkọ yii a o ṣe ayẹwo akọsilẹ Mika, ọkan ninu awọn wolii kekere, ẹni ti itumọ orukọ rè̩ i ṣe “tani o dabi Jehofa.” Wolii Ọlọrun yii ṣe apejuwe ipò buburu ti Israẹli ati Juda wà. Bakan naa ni o tun sọ asọtẹlẹ nipa Ijọba ti n bọ ninu eyi ti ododo yoo gbilẹ. Awọn Ọmọ Israẹli ayanfẹỌlọrun, ti ṣaigbọran si Oluwa wọn si ti yi pada kuro ninu ofin Rè̩ nigba pupọ. Gẹgẹ bi ọpọlọpọ eniyan lọjọ oni, wọn korira ire, wọn fé̩ ibi, (Mika 3:2). S̩ugbọn Ọlọrun na ọwọ aanu si wọn bi wọn bá ronu piwada, Oun yoo dariji wọn. Ironu piwada ni pe ki a wá sọdọỌlọrun pẹlu ọkàn pe a ki yoo mu Ọlọrun binu mọ, ati pe a ki yoo mọọmọ tapa si ofin ifẹ ati ododo Rè̩. Wolii yii rán wọn leti pe Ọlọrun mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti ati pe O fi Mose fun wọn gẹgẹ bi afunni lofin, ati Aarọni Alufaa. O fi aanu ati ifẹ bá wọn lò. Njẹ wọn ranti igba ti Balaki pinnu lati pa wọn run nigba ti o fẹ ki Balaamu fi wọn ré? S̩ugbọn Ọlọrun yi ero Balaamu pada, o si sure fun awọn eniyan ti Ọlọrun fẹ bukun-fun. NitootọỌlọrun aanu ni Oun!

Otitọ -- Aanu -- Irẹlẹ

Ninu ori kẹfa, ẹsẹ kẹfa iwe ti a yan fun è̩kọ wa yii, o da bi ẹni pe ède ti o n lò yi pada, o da bi ẹni pe awọn eniyan yii n bi Oluwa leere pe, Ki ni emi i ba mu wá ki n si tẹriba niwaju Rè̩? Ki emi ha wá pẹlu ọmọ maluu fun ọrẹ-ẹbọ sisun? Tabi Iwọ ha ni inudidun si ẹbọ miiran -- ẹgbẹẹgbẹrun àgbo tabi ẹgbẹẹgbaarun iṣàn òroro? O dabi ẹni pe ki a maa beere wi pe, Ẹkún ha lè múè̩ṣẹ kuro? Itọrẹ-aanu ha lè múè̩ṣẹ atẹyinwa kuro?

Nigba naa ni Mika dahun wi pe, oun ti fi ohun ti wọn ni lati ṣe han fun wọn lati ọjọ pipẹ sẹyin; kò yẹ ki wọn tun ṣẹṣẹ maa beere bi ẹni pe wọn kò gbọ ri. “Ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹānu, ati ki o rìn ni irè̩lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?” (Mika 6:8).

Otitọ, aanu, irè̩lẹ -- Ọlọrun n beere nnkan wọnyii lọwọ wa lọjọ oni. Ki a ṣe ohun ti o tọ si ẹni keji; aanu, ipamọra, iyọnu, ati ifẹ lati huwa ẹtọ si ẹlomiran. Ki i ṣe pe a ni lati pa Ofin Wura nì ti o wi pe, “Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bḝ si wọn pẹlu” (Luku 6:31) mọ nikan, ṣugbọn a ni lati ranti aṣẹ yii pe, “Njẹ ki ẹnyin ki o li ānu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ānu” (Luku 6:36).

Lati “rìn ni irè̩lẹ pẹlu Ọlọrun” gba pe ki a maa gbadura lai simi ati iṣọra gbogbo, ki a si ṣọra gidigidi lati ri i pe igberaga kò wọ inu ọkàn wa. “Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye” (Matteu 5:5).

Etutu fun Ẹṣẹ

Ni orilẹ-ède wa yii ti anfaani wà fun wa lati kà Bibeli, kò yẹ ki a jé̩ópe nipa ohun ti Ọlọrun n beere lọwọ wa. Ohun kin-in-ni ti a ni lati ṣe ni pe ki a ronu piwada ki a si gbà wá là nipasẹ itoye Ẹjẹ Jesu. Kò ni si awawi fun ẹnikẹni lati fara hàn niwaju Ọlọrun ni ọjọ idajọ pẹlu ọkàn ti Ẹjẹ Jesu kò wẹnu. Owo, iṣẹ rere, ọpọ itọrẹ-aanu, tabi ẹkún kò le mu è̩ṣẹ kuro, ṣugbọn “è̩jẹ Jesu Kristi Ọmọ rè̩ ni nwè̩ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo” (1 Johannu 1:7).

Betlehemu

Ọkan ninu awọn asọtẹlẹ pataki Mika ni ibi ti a o gbé bi Jesu. Mika wi pe bi o tilẹ jẹ pe Betlehemu jé̩ ilu kekere ninu eyi ti eniyan kò pọ pupọ, boya ti kò tilẹ jọ ni loju nipa ti ara, sibẹ o jé̩ ilu pataki ju lọ nipa ti ẹmi, nitori pe ibẹ ni a yàn ni ibi ti a o gbé bi Messia. A le ranti pe ni akoko ti a bi Jesu ni Betlehemu, nigba ti awọn amoye wá lati Ila-oorun si Jerusalẹmu, Hẹrọdu ọba beere lọwọ awọn olori alufaa ati awọn akọwe ibi ti a o gbé bi Kristi. Idahun wọn ni pe, “ni Betlehemu,” wọn si rán an leti ọrọ ti Mika wolii ti sọ ni ọpọlọpọọdun sẹyin.

O ṣeeṣe ki ọpọ eniyan maa wo pe ohun rere kan kò le ti Betlehemu jade; ṣugbọn nigba miiran, Ọlọrun a maa yan ohun kekere lati ta ohun nla yọ. A kà nipa Filippi ti o sọ ni ọjọ kan fun ọkunrin kan ti a n pe ni Natanaẹli pe, “Awa ti ri ... Jesu ti Nasarẹti,” ṣugbọn Natanaẹli kò gbagbọ wi pe ohun rere kan le ti Nasarẹti ibi ti Jesu n gbé nigba ewe Rè̩ jade. S̩ugbọn nigba ti o ri Jesu ti o si gbọọrọ Rè̩, o wi pe, “Iwọ li ỌmọỌlọrun; iwọ li Ọba Israẹli” (Johannu 1:49). Ọba ti a bi ni Betlehemu ti o si gbé ni Nasarẹti! NitootọỌlọrun a maa saba yan “awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan” (1 Kọrinti 1:28). Hẹrọdu Ọba nla ni rò pe bi a ba bi ọba nitootọ o ni lati jẹ ni ilu Jerusalẹmu; ṣugbọn Mika wi pe “Bẹtlẹhẹmu ni.”

Ireti ti N bọ wa S̩ẹ

Ninu ori kẹrin, Mika sọ nipa Ijọba ododo ti a o gbé kalẹ lori ilẹ ayé, awa naa ti kẹkọọ nipa Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún Kristi lori ilẹ ayé -- ẹgbẹrun ọdun alaafia kuro ninu ogun nigba ti awọn eniyan yoo fi “idà wọn rọọbẹ-plau, ati ọkọ wọn rọ dojé” (Mika 4:3). Ni akoko yii ni Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa, bi o tilẹ jẹ pe ni ilu kekere ti Betlehemu ni a gbé bi I, yoo jọba ni Sioni lori awọn eniyan Rè̩.

“Tani Ọlọrun bi iwọ, ti o ndari aiṣedede ji, ... kò dá ibinu rè̩ duro titi lai, nitori on ni inudidun si ānu. Yio yipadà, yio ni iyọnú si wa; ... iwọ o si sọ gbogbo è̩ṣẹ wọn sinu ọgbun okun” (Mika 7:18, 19). Ileri Ọlọrun fun Abrahamu kò yè̩ sibẹ: “Emi si farahàn Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu, ... Emi si ti bá wọn da majẹmu mi pẹlu, lati fun wọn ni ilẹ Kenaani” (Ẹksodu 6:3, 4).

Bi o tilẹ jẹ pe ilẹ Kenaani ti bọ kuro lọwọ awọn Ọmọ Israẹli, Ọlọrun ti n gba a pada fun wọn ni akoko ikẹyin yii. Awọn Ju, ti i ṣe ayanfẹỌlọrun, ti bẹrẹ si pada si ilẹ wọn, asọtẹlẹ Mika nipa ikẹyin ọjọ si ti bẹrẹ si i ṣẹ: “Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o kó ... emi o si ṣàẹniti a le jade, ... emi o si dá ... emi o si sọẹniti a ta nù rére di orilẹ-ède alagbara: OLUWA yio si jọba lori wọn li oke-nla Sioni” (Mika 4:6, 7). Gbogbo ayé n reti ẹgbẹrun ọdún alaafia nì ti yoo wà lori ilẹ ayé. Iwọ ha n gbadura gẹgẹ bi Kristi ti kọ wa lati maa gbadura pe, “Ki ijọba rẹ de?” (Luku 11:2).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni a n pe ni wolii?
  2. Iwọ ha le darukọ awọn wolii miiran yatọ si Mika?
  3. Ni ilu wo ni a o gbé fi idi Ijọba kalẹ ni igba Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún Kristi?
  4. Njẹ ogun yoo wà lakoko naa?
  5. Ọna wo ni awọn Ọmọ Israẹli gba fi iwa aimoore hàn fun ore Ọlọrun si wọn?
  6. Ki ni asọtẹlẹ ti Mika sọ nipa Betlehemu?
  7. Nibo ninu Iwe Mimọ ni a gbé le ri imuṣẹ asọtẹlẹ yii?
  8. Ki ni Ọlọrun n beere lọwọ wa lọjọ oni?
  9. Ki ni ileri ti Oluwa ṣe fun Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu?