Lesson 331 - Junior
Memory Verse
“OLUWA mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là” (Orin Dafidi 34:18).Notes
Wolii Kekere
Hosea, ọmọ Beeri, ni iṣẹ lati jé̩ fun awọn Ọmọ Israẹli. O jé̩ wolii Oluwa ni akoko kan naa pẹlu Isaiah, Amosi, ati Mika. Bi o tilẹ jẹ pe a mọ Hosea gẹgẹ bi wolii ti ijọba iha guusu Israẹli, ṣugbọn gbogbo awọn Ọmọ Israẹli ni a kó pọ ninu ọrọ rè̩. Hosea jé̩ wolii fun iwọn nnkan bi i ọgọta ọdun. Ni akoko yii, Jeroboamu, ọmọ Joaṣi (ti a saba n pe ni Jehoaṣi) ni o n jọba ni Israẹli; Ussiah, Jotamu, Ahasi ati Hesekiah si jọba tẹle ara wọn ni Juda ni akoko kan naa.
Iṣẹ Wolii
A kò le ṣalaini awọn wolii. O tọ ki a ni awọn eniyan ti Ọlọrun pè lati jiṣẹỌlọrun fun awọn eniyan. Ọlọrun fi ọkàn tán awọn wolii lati sọ ohun ti O n fẹ fun awọn Ọmọ Israẹli. Awọn wolii n sọ fun wọn nipa idajọỌlọrun. Wọn n ba wọn wi nitori è̩ṣẹ wọn, wọn si n tọka si ọna ibọriṣa ti wọn n tọ. Wọn sọ fun wọn pẹlu nipa ileri ibukun ti Oluwa ṣe fun wọn bi wọn ba yi pada ti wọn si n sin Ọlọrun. Eyi ni iṣẹ wolii. Hosea jé̩ oloootọ si Ọlọrun, bakan naa ni o si jé̩ oloootọ si awọn Ọmọ Israẹli.
Ọna Buburu
Gẹgẹ bi a ti n kẹkọọ nipa awọn Ọmọ Israẹli ati awọn ọba ti o wà ni akoko Hosea, a ri i bi Ọlọrun ati awọn wolii Rè̩ ti jé̩ oloootọ lati maa kilọ fun wọn. Jeroboamu, Ọba Israẹli ṣe buburu niwaju Oluwa nipa pe kò yà kuro ninu ọna è̩ṣẹ Jeroboamu (olorukọ rè̩) ẹni ti o mu Israẹli dè̩ṣẹ (2 Awọn Ọba 14:24). Ni akoko yii ipọnju Israẹli “korò gidigidi: nitori kò si ọmọ-ọdọ, tabi ominira tabi olurànlọwọ kan fun Israẹli” (2 Awọn Ọba 14:26). Ọlọrun ti ṣeleri pe orukọ Israẹli ki yoo parun patapata, nitori naa O lo Jeroboamu lati gba awọn Ọmọ Israẹli silẹ kuro lọwọ awọn ọta wọn.
È̩tè̩
A mọ Ussiah gẹgẹ bi ọba ti o di adẹtẹ nigba ti o lọ sinu Tẹmpili lati sun turari. Nipa ṣiṣe eyi, o dẹṣẹ si Ọlọrun. Turari sisun ninu Tẹmpili jẹ iṣẹ ati ẹtọ awọn alufa nikan. Ọlọrun ran Ussiah lọwọ gidigidi, ṣugbọn nigba ti o di alagbara tán ọkàn rè̩ gbega soke (2 Kronika 26:15, 16). È̩tẹ Ussiah mu ki o padanu gbogbo awọn ohun rere ti i ba gbadun ni aye rè̩ -- ẹbi ati ile rè̩, iṣẹ ati ijọba rè̩, ati isin rè̩ pẹlu, nitori “a ké e kuro ninu ile OLUWA.” Gẹgẹ bi o ti ri fun Ussiah nigba ti o di adẹtẹ, è̩ṣẹ a maa mu ki eniyan padanu awọn ohun rere ti ẹni naa i ba gbadun ni aye rè̩. A kò dá Ussiah lẹjọ lasan. O ni lati gbọọrọ ti Ọlọrun ti ẹnu Hosea sọ, sibẹ kò ronu piwada.
Iwa Buburu
Nigba ti è̩tẹ bo Ussiah, ọmọ rè̩ Jotamu, di ọba. O “di alagbara, nitoriti o tun ọna rè̩ṣe niwaju Oluwa Ọlọrun rè̩” (2 Kronika 27:6). Jotamu ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa ṣugbọn awọn eniyan n ṣe “ibi” (2 Kronika 27:2). Eyi ni lati jẹ ohun ti awọn eniyan yii yàn fun ara wọn. Hosea jé̩ oloootọ nipa fifi è̩ṣẹ wọn hàn wọn, o jé̩ ki ijiya ti n tẹle è̩ṣẹ di mimọ fun wọn.
Ahasi jọba ni Juda lẹyin ikú Jotamu. Ijọba rè̩ kun fun iwa buburu, iwa ikà, ati ibọriṣa (2 Awọn Ọba 16:3, 4). “Li akokò ipọnju rè̩, o tun ṣe irekọja si i si Oluwa” (2 Kronika 28:22). Ahasi ba ile Oluwa jé̩, o tì ilẹkun ile Oluwa, o si té̩ pẹpẹ ni gbogbo igun Jerusalẹmu (2 Kronika 28:24). Lẹyin ikú Ahasi, Hesekiah jọba ni Juda. Oun ni ọkunrin naa ti a sọ fun pe ki o palẹ ile rè̩ mọ nitori ti oun yoo kú. Hesekiah gbadura. Ọlọrun wo o sàn, a si fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ ayé rè̩. O gbẹkẹle Ọlọrun kò si yi pada kuro ni titọỌ lẹyin: “S̩ugbọn Hesekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u: nitoriti ọkàn rè̩ gbega” (2 Kronika 32:25).
Iṣe ti a rán Hosea
Ki ni iṣẹ ti a rán Hosea si awọn ọba wọnyii ati si awọn eniyan wọn? A rán an si wọn pe wọn ni lati ronu piwada. Itumọ ironu piwada ni pe ki a kọè̩ṣẹ silẹ. Nigba ti eniyan bá ronu piwada, yoo ni igbọgbẹọkàn, yoo si kaanu fun è̩ṣẹ rè̩ atẹyinwa: yoo ni ipinnu lati yi pada lati ṣe rere; yoo tọrọ idariji yoo si fẹ lati ṣe atunṣe awọn ohun ti o wà ni igbesi-ayé rè̩ ti kòṣe deedee pẹlu Ọlọrun ati arakunrin rè̩.
Ohun ti Hosea sọ fun awọn eniyan wọnni ti ayé wọn kún fún iwa è̩ṣẹ ni yii. O sọ fun wọn pe wọn ni lati yi pada ki wọn si sin Ọlọrun. O rán wọn leti ohun nla wọnni ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn – lati igbà ti a ti mú awọn Ọmọ Israẹli jade kuro ni ilẹ Egipti. Hosea fi abuku ti o wà ni igbesi-ayé wọn hàn wọn.
Bi Ọmọde Kekere
Nigba ti Hosea n jiṣẹ ti Oluwa rán an, o fi Israẹli wéọmọde pẹlu Ọlọrun bi Baba rè̩. Gẹgẹ bi baba ti n kọọmọ rè̩ bi a ti n rin nipa fifa a lọwọ, bakan naa ni Ọlọrun kọ Israẹli “lati lọ.” Awọn Ọmọ Israẹli ti gbẹkẹle Ọlọrun fun iranwọ, atilẹyin ati itọni.
Ni ilẹ Egipti, awọn Ọmọ Israẹli jé̩ẹrú, wọn n ṣiṣẹ fun Farao. Oluwa gbà wọn kuro loko ẹrú náà. O gbéẹru wuwo wọn kuro, O si pese ounjẹ fun wọn. Gẹgẹ bi eniyan ti i tú okùn ajaga kuro lọrun maluu ki wọn ba le ni anfaani lati jẹun, Oluwa sọ Israẹli lẹru kalẹ, O si pese ounjẹ fun wọn. Oluwa rọjo manna silẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati jẹ (Ẹksodu 16:15). S̩ugbọn wọn ranti ẹja, apálà, ewebẹ, ẹgusi ati alubọsa ti wọn ti jẹ ni Egipti. Wọn kùn si Ọlọrun, Ẹni ti o fun wọn ni ounjẹ, titi a fi jẹ wọn niya nitori kikùn wọn. (Ka Ẹkọ 99).
Okùn Ifẹ
Oluwa fi ifẹ fa awọn Ọmọ Israẹli sọdọ ara Rè̩. Oun kò fi agbára mú wọn gẹgẹ bi awọn wọnni ti wọn mọ bi a ti n fi agbára múẹranko. Ọlọrun lo ọna ti awọn eniyan rere i maa lo lati yi eniyan lọkàn pada. Oun kò fi ipa mu wọn lati sin In. Ọlọrun fẹran awọn Ọmọ Israẹli.
Ọlọrun yoo fa gbogbo eniyan sọdọ ara Rè̩ nitori ti O fẹran wọn. IfẹỌlọrun si wa ni O mu ki O rán Jesu Kristi Ọmọ Rè̩, ti a fi rubọ fun wa lori igi agbelebu ki a ba le gbà wá là. “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobḝ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rè̩ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ má bàṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun” (Johannu 3:16).
O ni lati Yàn
Ọlọrun pe olukuluku eniyan lati tọỌ lẹyin. Olukuluku ni lati yan ẹni ti oun yoo sin. Ọlọrun kò fi ipa mu ẹnikẹni lati sin In. Nigba miiran awọn eniyan a maa ṣe ohun kan lati té̩ẹlomiran lọrun nitori pe è̩ru n bà wọn. Wọn n sin ẹlomiran nitori pe è̩ru kó wọn lẹrú. Awọn eniyan Ọlọrun fara mọỌlọrun nitori Ifẹ Rè̩
Ifẹọkàn Ọlọrun ni pe ki gbogbo eniyan jé̩ Onigbagbọ. Ọlọrun ti ṣe ipa ti Rè̩ nigba ti O la ọna igbala silẹ. Olukuluku eniyan ni lati yan ẹni ti oun yoo sin, yala Ọlọrun tabi Eṣu. Ọna miiran kò si. Eniyan ni lati fé̩Ọlọrun to bẹẹ ti yoo fi maa tọỌ lẹyin tabi ki o fẹran Eṣu. “Ko si ẹniti o le sin oluwa meji: nitori yala yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio faramọọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin ko le sìn Oluwa pẹlu mammoni” (Matteu 6:24).
S̩iṣe Tinu Wọn
Hosea sọ fun awọn eniyan naa pe ti inu wọn ni wọn fẹṣe. Ọlọrun ṣe ohun pupọ fun wọn O si fẹran wọn lọpọlọpọ. Sibẹsibẹ wọn “tè̩ si ifàsẹhin.” Awọn Ọmọ Israẹli a maa tọỌlọrun lẹyin fun igba diẹ. Lẹyin naa wọn a fẹ lati ṣe ti inu ara wọn. Ewu wà ninu ṣiṣe ifẹ inu ara ẹni nitori pe, “Ọna kan wà ti o dabi ẹnipe o dara fun enia, ṣugbọn opin rè̩ li ọna ikú” (Owe 16:25). Awọn wolii Ọlọrun gba awọn eniyan naa niyanju lati yi pada si Ọlọrun, lati gbe E ga ati lati sin In. Eyi ni ohun kan naa ti Hosea n ṣe. S̩ugbọn awọn Ọmọ Israẹli tè̩ si ọna ti ara wọn.
IfẹỌlọrun tobi to bẹẹ ti O sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe, “Emi o ha ṣe jọwọ rẹ lọwọ?” Inu Rè̩ bajẹ nitori ifasẹyin wọn. S̩ugbọn alaanu ati onipamọra ni Ọlọrun. O wi pe, “Emi ki yio yipadà lati run Efraimu (Israẹli): nitori Ọlọrun li emi, ki iṣe enia.” Ọna Ọlọrun kò dabi ọna ti eniyan. Awọn ẹlomiran, ninu ibinu wọn, i ba ti fi wọn silẹ, wọn ki bá ti fun wọn ni anfaani miiran lati ronu piwada.
Èké ati È̩tàn
Awọn Ọmọ Israẹli ti ṣeke wọn si ti ṣè̩tan nipa ikuna wọn lati san è̩jé̩ ti wọn jé̩ fun Ọlọrun. Wọn ṣe ileri fun Ọlọrun wọn si kuna lati mu un ṣẹ. Ninu itàn igbesi-ayé awọn Ọmọ Israẹli, nigba miiran wọn a yi pada si Ọlọrun wọn a si ṣeleri pe wọn yoo gbọ ti Rè̩. Fun apẹẹrẹ, nigba ti Jọṣua wi pe, “Bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sin,” awọn eniyan naa n fẹṣe bẹẹ pẹlu. Wọn mọ pe Ọlọrun ni o mú wọn jade kuro ni Egipti wọn si n fẹ lati sin In. Wọn wipe, “OLUWA Ọlọrun wa li awa o ma sìn, ohùn rè̩ li awa o si ma gbọ” (Jọṣua 24:15, 24). Lẹyin ikú Jọṣua, wọn kọỌlọrun silẹ wọn si bọriṣa. Nigbakugba ni awọn Ọmọ Israẹli n ṣe eyi.
Ki i ṣe awọn Ọmọ Israẹli nikan ni o ṣe bẹẹ, ọpọlọpọ eniyan n bẹ lọjọ oni ti wọn ki i mu ileri ti wọn ṣe fun Ọlọrun ṣẹ. Nigba ti wọn gbadura fun igbala, wọn ṣeleri lati sin Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò sin In nisisiyi. Nigba pupọ nigba ti awọn eniyan ba n ṣaisan, wọn a jè̩jé̩ fun Ọlọrun ṣugbọn awọn miiran a maa gbagbe è̩jé̩ ati ileri wọn nigba ti Ọlọrun ba wò wọn sàn tan ti ara wọn si le. Ni akoko wahala ati ewu, awọn ẹlomiran ti ṣeleri fun Ọlọrun ti wọn kò jẹ muṣẹ. Eyi ki ha i ṣe èké ati è̩tan? Dafidi wi pe, “Emi o san ẹjé̩ mi fun ọ, ti ète mi ti jé̩, ti ẹnu mi si ti sọ, nigbati mo wà ninu ipọnju” (Orin Dafidi 66:13, 14).
Adura
Hosea mú awọn nnkan wọnyi wa si iranti wọn lati fi hàn wọn pe wọn ni lati ronu piwada. Wọn kò ni ọkàn ọpé̩ fun ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn. Nigba ti ẹnikan ba ka ibukun rè̩ yoo ri i pe oun jẹỌlọrun nigbese ọpé̩ ati iyin ati pé oun ni lati sin Ọlọrun ki oun si bu ọla fun Un. Awa ha n fi ọpẹ fun Ọlọrun nitori ohun ti O ṣe fun wa? Tabi a jé̩ alaimoore to bẹẹ ti a kò naani oore rè̩ si wa?
Ki i ṣe pe Hosea fi hàn wọn pe wọn ni lati ni igbala nikan, ṣugbọn o fi ọna ti wọn le gbà ni in hàn wọn, o sọ ohun ti wọn ni lati sọ, o si gbà wọn niyanju lati mu ọrọ naa tọ Oluwa lọ -- lati bá Oluwa sọrọ ati lati fi ara wọn rubọ fun Un. Eyi ni adura gbigba. Dipo ki wọn maa fi ẹran rubọ, wọn ni lati mú “ọmọ-malu” etè wọn lọ, eyi ti i ṣe iyin ati ẹjé̩ wọn si Ọlọrun. Hosea kọ wọn lati sọ pe, “Assuru ki yio gbà wa; awa ki yio gùn ẹṣin.” Itumọ eyi ni pe wọn mura tán lati gbẹkẹle Ọlọrun ju ati gbẹkẹle eniyan, bi wọn ti n ṣe tẹlẹ ri. Wọn yoo mọỌlọrun ni Ọlọrun dipo pipe iṣẹọwọ ara wọn ni awọn ọlọrun, Oluwa n fẹ ki gbogbo awọn ti a ti gbala ki o gbẹkẹle Oun, ki wọn si gba A ni Ọlọrun otitọ ati Ọlọrun alaaye.
Awọn Ileri
Ọlọrun ṣeleri lati ṣaanu fun awọn wọnni ti o ronu piwada ni tootọ -- awọn ti o jẹwọè̩ṣè̩ wọn ti wọn si kọọ silẹ (Owe 28:13). Oluwa wà nitosi awọn ti o kaanu fun è̩ṣẹ wọn, O si gbà iru awọn ti i ṣe onirora ọkàn là (Orin Dafidi 34:18).
Lẹyin aanu, ileri ibukun miiran tun wà fun awọn wọnni ti o ronu piwada ti wọn si tẹle Ọlọrun. Hosea wi pe Oluwa yoo dabi ìri si Israẹli. A sọ fun wa pe ni apa Ila-oorun iri a maa sè̩ pupọ, o si n mú ilẹ tutu. Ni apa ibomiran òjo pupọ a maa rọ, ṣugbọn ni ilẹ ti Israẹli n gbe, ìri ti n sè̩ ni o n fun wọn ni omi. Ni ọnà ti ẹmi, Ọlọrun ṣeleri lati rán omi eyi ti yoo mu ki ọkàn sọji ti yoo si tun mu ki o maa dagba. Njẹ iwọ le tọka si awọn ẹsẹỌrọỌlọrun ninu Iwe Mimọ ti o sọ nipa Omi Iye?
OhunỌgbìn
Hosea fi ẹni ti o gba “iri” naa wé ohun ọgbin. “On o tanná bi eweko lili; yio si ta gbòngbo rè̩ bi Lebanoni.” Yoo dagba bi lili -- ẹyọ gbongbo kan ṣoṣo a maa mu ọpọlọpọ itanna jade! Gbòngbo bi ti Lẹbanọni -- gbòngbo igi kedari ti Lẹbanọni a maa wọlè̩ to bẹẹ ti wiwọlẹ wọn na n gun to giga igi kedari tikalara rè̩! “Ẹwà rè̩ yio si dabi igi olifi, ati õrùn rè̩ bi Lebanoni.” Ẹwà bi ti olifi – igi naa a saba maa tutu yọyọ, o ni iye ninu a si ma so eso! Òórùn bi ti Lẹbanọni -- òórùn didun itanná ati ti awọn igi n ta sansan! A kò ri ohun-ọgbin kan ti a le fi ṣe apejuwe awọn eniyan Ọlọrun. S̩ugbọn a kó gbogbo ẹwà ti o wà lara awọn ohun-ọgbin pupọ papọ lati fi ṣe apejuwe awọn eniyan Ọlọrun – idagbasoke lili, gbongbo igi kedari ti o jinlẹ, eso ati ẹwa igi olifi. “Nwọn o sọji bi ọkà: nwọn o si tanná bi àjara.” Jesu ṣe iru apejuwe bẹẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. Ka ohun ti Jesu sọ nipa “wóro alikama” kan ti o bọ sori ilẹ ti o si kú (Johannu 12:24). Jesu tun sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pẹlu nipa bi àjara ti ṣe n dagba ati bi o ti ṣe n so eso.
Oloootọ tabi Alaiṣootọ
Pẹlu gbogbo ileri wọnyi ati ju bẹẹ lọ, ko si aafo fun ẹnikẹni lati kuna lati tẹ le Oluwa. Ẹni kọọkan le sọ bi ti Efraimu pe, “Kili emi ni fi òriṣa ṣe mọ?” tabi ki o tilẹ sọọ ni ọrọ ara rẹ pe, “Ki ni ṣe ti n o fi wà ninu è̩ṣẹ?” Iwe Hosea pari pẹlu alaye pe oriṣi eniyan meji ni o wà: olododo ati alaiṣododo; awọn ti n tẹle Oluwa ati awọn ti n tọọna ti ara wọn. Gẹgẹ bi ileri iyebiye pupọ ti wà fun awọn ti o gbọran, bakan naa ni ileri ti o ba ni lẹru wà fun awọn alaigbọran. Irú eniyan wo ni iwọ? “Ọna Oluwa tọ, awọn olododo yio si ma rin ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn.”
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni itumọ wolii “kekere”?
2 Ki ni iṣẹ ti Hosea jé̩ fun awọn Ọmọ Israẹli?
3 Irú iwa wo ni awọn Ọmọ Israẹli hù si Ọlọrun?
4 Ọna wo ni wọn gba fi iwa aimoore hàn?
5 Ki ni ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn?
6 Ki ni ironu piwada?
7 Ta ni o ni lati ronu piwada?
8 Ọna wo ni eniyan le gbà wáỌlọrun fun idariji è̩ṣẹ?
9 Ki ni anfaani ti o wà ninu gbongbo gigun ti igi kedari ni?
10 Bawo ni Ọlọrun ti fẹran eniyan tó?