Lesson 332 - Junior
Memory Verse
“Emi li OLUWA, ko si ẹlomiran” (Isaiah 45:5).Notes
Igbọran ati Aigbọran
Lati igba ti iya ba ti bẹrẹ si mi ori si ọmọ rè̩ ti o si wi fun un pe, “kai, kai,” ni ọmọ naa ni lati ni oye pe awọn ohun kan wà ti oun ko gbọdọṣe. Bi o ba si ti n dagba si i, oun yoo ri i wi pe awọn ohun kan wà ti o wu u lati ṣe, ṣugbọn ti o mọ pe oun ko gbọdọṣe; ati pe awọn nnkan miiran wà ti o gbọdọṣe, ṣugbọn ti oun ki i saba fẹ lati ṣe. S̩ugbọn a mọ wi pe awọn ọmọde ti o bá ni igbala yoo jé̩ọmọ rere ati ọmọ ti n gbọran, awọn ti kò ni igbala a maa saba ṣaigbọran si awọn obi, olukọ, tabi awọn miiran ti i ṣe aláṣẹ. A fẹ sọrọ diẹ nipa awọn ọmọ ti kò ti ni igbala.
Nigba ti awọn ọmọde ba taku sinu iwa aigbọran, nigbooṣe baba ti o tilẹ ni suuru jọjọ yoo jẹ iru ọmọ bẹẹ niya. Ni tootọ, ojuṣe awọn obi ti o fẹ ire ọmọ wọn ni lati jẹ wọn niya nigbakuugba ti o ba tọ lati ṣe bé̩ẹ, fun ire awọn ọmọ naa ni ọjọ iwaju.
Ọlọrun, ẹni ti i ṣe Baba oninuure ati olufẹ awọn ọmọ Rè̩, fẹran awọn ti o gbọran si I; gẹgẹ bi baba nipa ti ara, ti i maa ṣe, O ni lati bá awọn Ọmọ Rè̩ wi pẹlu, nigba ti wọn ba yẹ fun ibawi.
Aigbọran Israẹli
Ẹ jẹ ki a mú awọn ohun wọnni ti Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn kò gbọdọṣe wá si iranti, eyi ti wọn ṣe bi O ti kilọ fun wọn tó o nì. O mu wọn jade kuro ni Egipti kuro labè̩ Farao ọba buburu nì ni ọdun pupọ sẹyin, O si ti fi hàn fun wọn pe Oun ni Ọlọrun wọn. O sọ fun wọn gbangba pe, “Iwọ kò gbọdọ li ọlọrun miran pẹlu mi” (Ẹksodu 20:3). Ni igba pupọ ni wọn ti rú ofin yii, wọn ti bè̩ru awọn ọlọrun miiran ti i ṣe ere ati oriṣa lasan. Lẹyin eyi, bi ẹni pe oju Ọlọrun kò ri wọn lati Ọrun wá, wọn ti ṣe ohun ti kò tọ ni ikọkọ. O yẹ ki wọn mọ pe Ọlọrun ri wọn nigba ti wọn n yá awọn ere ti wọn si gbe wọn kalẹ “lori òke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo” (2 Awọn Ọba 17:10). “Nibẹ ni nwọn si sun turari ni gbogbo ibi giga wọnni, bi awọn keferi … nwọn si ṣe ohun buburu lati rú ibinu OLUWA soke” (2 Awọn Ọba 17:11). Ọlọrun wi pe, “Ẹnyin kò gbọdọṣe nkan yi” (2 Awọn Ọba 17:12), o si yẹ ki wọn ranti. Lẹẹkan si i wọn yáẹgbọrọ maluu meji wọn si n bọ irawọ, oṣupa, ati oorun, wọn si n sin Baali, oriṣa ti Elijah fi hàn pe kò le gbọran, kò le riran bẹẹ ni kò le fọhùn.
Ipe ti Ẹmi
Nigba ti Ọlọrun wi pe, “yipada” wọn wàọrun wọn kì, lọna miran ẹwẹ, a le wi pe, wọn kọ eti didi si ohùn Ọlọrun. ỌrọỌlọrun sọ wi pe, “Ẹniti a ba mbawi ti o wàọrùn ki, yio parun lojiji, laisi atunṣe” (Owe 29:1). Ọrọ yii ko yi pada titi di oni oloni.
Awọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin miiran a maa tọọna è̩ṣẹ lai yi pada si Ọlọrun. Wọn n wá sile Ọlọrun ati Ile-ẹkọỌjọ Isimi ni ọpọlọpọ igba, ṣugbọn nigba ti o ba to akoko lati lọ gbadura lori pẹpẹ, wọn a saba maa gbọna ita lọ dipo ki wọn wá sibi pẹpẹ adura. Pupọ ninu awọn obi a maa rọ awọn ọmọ wọn lati fi ọkàn wọn fun Ọlọrun; nigba miiran è̩wẹ, awọn ojiṣẹỌlọrun a maa ba awọn ipẹẹrẹ sọrọ pe ki wọn fi ọkàn wọn fun Ọlọrun, ṣugbọn awọn miiran n kọ lati ṣe bẹẹ. Awọn wọnyi n ṣe ohun kan naa ti awọn Ọmọ Israẹli ṣe: wọn “wàọrùn ki,” wọn kọ eti didi si ohùn Ọlọrun.
Ijiya
Ẹ jẹ ki a wo ohun ti o ṣẹlẹ si awọn Ọmọ Israẹli. S̩aaju ohun gbogbo, Ọlọrun jẹ ki ọba keferi lati ilẹ Assiria wá, o kó wọn lẹru kuro ni ilẹ wọn lọ si ilẹ ajeji, boya lati maa ṣe ẹru fun awọn ara Assiria. A kà pe Oluwa “ta wọn nù kuro niwaju rè̩” (2 Awọn Ọba 17:20). Oun kò le fara da è̩ṣẹ ati iwa buburu wọn mọ.
Ki a lé eniyan kuro nile nitori iwa è̩ṣẹ tó lati mu ki ẹni naa yi pada si Ọlọrun. A ranti pe a ti kà nipa ọmọ-oninakuna ti o sá kuro nile ati kuro lọdọ baba ti o fẹran rè̩. Nigba ti o ti ná gbogbo owo ọwọ rè̩ tan, o ranti ile, lai pẹ o pada si ọdọ awọn wọnni ti wọn n reti ti wọn si n ṣọna fun ipadabọ rè̩.
Awọn ara Ninefe gba wolii Ọlọrun gbọ wọn si ronu piwada è̩ṣẹ wọn. S̩ugbọn awọn olugbe Samaria wọnyi kòṣe bẹẹ. Alufaa kan wá, lati kọ awọn eniyan yii ṣugbọn wọn taku sinu è̩ṣẹ wọn. Wọn gbé oriṣiriṣi oriṣa kalẹ fun awọn eniyan lati maa foribalẹ fun: awọn ere ti wọn dabi ewurẹ, akukọ, aja, kẹtẹkẹtẹ, maluu, ẹyẹ ologe, ati ehoro. Sa fi oju inu wo iru isin ẹlẹya yii! A ka a pe awọn eniyan naa “bè̩ru OLUWA, nwọn si nsin oriṣa wọn” (2 Awọn Ọba 17:33). Ẹsin wọn ti di adalu ohun ti o tọ ati eyiti kò tọ. Iru isin bayii buru ju ti ẹni ti kò tilẹ ni ẹsin kan rara. Obinrin kan a saba maa wá si ile Ọlọrun ni Ọjọ Oluwa a si maa lọ wo sinima ati awọn ere idaraya miiran ti o mu è̩ṣẹ lọwọ laaarin ọsẹ, ṣugbọn Ọlọrun fi ye e pe a kò le kó Ihinrere ati ayé dani papọ.
Boya è̩ru Ọlọrun n ba awọn Ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọn kò bọwọ fun Un, wọn kò si ni ọkàn lati sin In. A paṣẹ fun wa pe: “Bè̩ru Ọlọrun, ki o si pa ofin rè̩ mọ: nitori eyi ni fun gbogbo enia” (Oniwasu 12:13). Wọn kò ni ifẹ lati pa ofin Ọlọrun mọ, eredi rẹ ni yii ti Oluwa fi “kọ” wọn ti O si “wahala” awọn eniyan naa ti O si “fi wọn le awọn akoni lọwọ” ti O si “ta wọn nù kuro niwaju rè̩” (2 Awọn Ọba 17:20).
Ni ilẹọlaju wa yii, awọn eniyan ki i foribalẹ fun oriṣa ti a fi igi ati okuta gbé̩, ṣugbọn a ti kọ ninu awọn è̩kọ wa ti o ti kọja pe ohunkohun ti o ba leke ifẹỌlọrun ninu ọkàn wa jẹ oriṣa ni igbesi-ayé wa. Ọkan ninu awọn ohun ti a le pe ni ibọriṣa le jẹ ifẹ lati lọ sinu ayé lọjọ kan lati lọ “jaye” diẹ. Bi o tilẹ jẹ pe awọn obi Onigbagbọ n ṣakoso awọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin miiran, sibẹsibẹ wọn a saba maa n ni ero pe bi wọn bá dagba diẹ si i, wọn yoo lọ lati jẹ igbadun è̩ṣẹ ati lati mọ bi ayé ti ri. Ọpọlọpọ ipẹẹrẹ ni o ti ṣe bẹẹ ti wọn si ti kabamọọjọ ti wọn kọ yà kuro ninu è̩kọ baba ati iya wọn.
Aanu ati Idajọ
Otitọ ni Ọlọrun jé̩Ọlọrun alaanu, onifẹ ati oninuure, ti “kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbé, bikoṣe ki gbogbo enia ki o wá si ironupiwada” (2 Peteru 3:9). Bakan naa ni O jẹỌlọrun idajọ ati è̩san; nigba ti “ago aiṣedede” ayé ti o dogbó ninu è̩ṣẹ yii bá kún, Oun yoo rán iparun sori awọn eniyan buburu.
Ọkunrin, obinrin, ọdọmọkunrin, tabi ọdọmọbinrin ti a kò ti i gba ọkàn rè̩ la wà ninu ewu ibinu ti o kú si dẹdẹ. Jẹ ki olukuluku ẹni ti kò ti i wà ni imura silẹ lati pade Oluwa ni alaafia, wá oju Rè̩ loni, nitori “nisisiyi ni akokò itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala” (2 Kọrinti 6:2).
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni ohun ti ọba Assiria ṣe fun Israẹli?
2 Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi aye silẹ pe ki nnkan bayii ṣẹlẹ si Israẹli?
3 Ewo ni ekinni ninu Ofin Mẹwaa?
4 Bawo ni awọn eniyan ṣe rú ofin yii?
5 Ki ni ṣẹlẹ nigba ti ọkan ninu awọn alufaa wá si Assiria?
6 Ta ni o yẹ ki wọn bẹru ki wọn si maa sin?
7 Ta ni o yẹ ki awọn eniyan bẹru lọjọ oni? Wọn ha n ṣe bẹẹ?
8 Darukọ diẹ ninu awọn ohun ti o le di oriṣa ninu igbesi-ayé wa.