Iṣe Awọn Apọsteli 15:1 - 41

Lesson 333 - Junior

Memory Verse
“Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ” (Galatia 3:24).
Notes

Igbala Nipasẹ Kristi

“Kò si orukọ miran labẹọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:12). Orukọ naa ni orukọ Jesu. A ti kọ ninu è̩kọ wa ninu Iwe Iṣe Awọn Apọsteli pe ohun ti o jé̩ kóko è̩kọ ti Awọn Apọsteli n kọ ni ni Jesu – ti a kàn mọ agbelebu ti O si tun jinde. Ajinde Jesu kuro ninu okú fi hàn pe ỌmọỌlọrun ni Oun I ṣe. Nipasẹ orukọ Jesu, awọn Apọsteli n lọ kaakiri wọn si n ṣe iṣẹ-iyanu, ọpọlọpọ eniyan si n di ẹbi Ọlọrun.

Keferi ati Ju n ri igbala kan naa lọna kan naa. Wọn jẹwọè̩ṣẹ wọn, wọn ronu piwada iwa buburu wọn ti wọn ti hù, wọn si gbagbọ pe Jesu gbà wọn là. Ayọ nla ni o n wa laaarin awọn eniyan nibikibi ti wọn ba gbé gbadura agbayọri ti wọn si ni alaafia lọdọỌlọrun.

Olusin Gẹgẹ Bi Aṣa Awọn Ju

Nibi ti wọn gbe n yọ ayọ nla yii, awọn ọkunrin kan wá lati Judea, ti wọn fé̩ kàn án nipa fun awọn ti o ṣẹṣẹ di Onigbagbọ wọnyi lati pa Ofin Mose mọ. Fun ọpọlọpọọdún, lati igba ti a ti fun ni ni Ofin lori Oke Sinai ni awọn alufaa Ju ti n tẹle awọn eto ati ilana-isin kan. Ni akoko yii, wọn mu un lokunkundun lati maa tẹẹ mọ awọn Ju leti lati tẹle ilana yii. Bi ẹnikẹni ti ki i ṣe Ju ba fẹṣe ẹsin awọn Ju, o gbọdọ pa gbogbo ilana-isin wọnyi mọ pẹlu.

Ọpọlọpọọrọ ati ijiyan ni o wa laaarin awọn eniyan naa, nipa ohun ti awọn ti o ṣẹṣẹ di Onigbagbọ wọnyi ni lati ṣe. Wọn ti gba agbayọri adura a si ti gbà wọn là nipa igbagbọ ninu Jesu, wọn si jẹ Onigbagbọ ni tootọ. Bi wọn ba n kiyesara, ti wọn si n ka Bibeli wọn, ti wọn ba si n gbadura, wọn yoo pa ifẹỌlọrun mọ ninu ọkàn wọn. Nipa igbagbọ ni a fi gbà wọn là, ki i ṣe nipa iṣẹ ti wọn ṣe. S̩ugbọn awọn Ju ti o ti yapa wọnyi, awọn ti a n pe ni Ẹlẹsin gẹgẹ bi igbekalẹ awọn Ju, kò gbà pé igbala nikan tó. A ni lati kọ wọn nilà gẹgẹ bi Ofin Mose pẹlu.

Ọrọ pataki gidi ni ọrọ yii. Paulu, Barnaba ati Peteru lọ si Jerusalẹmu lati jiroro lori ọran yii pẹlu awọn Apọsteli iyoku. Awọn Keferi ti ni igbala nipa iwaasu Peteru lai fi ẹnu kan ọrọ Ofin rara. A gbà wọn là nipa igbagbọ, wọn si n gbadun ominira ninu Ihinrere. Ki ni o fa iru ọrọ bayii nisisiyi, ti awọn Ju n fẹ di ẹrù wuwo rù awọn Keferi ti o ṣẹṣẹ di Onigbagbọ, ẹrù ti o ṣoro fun awọn Ju tikara wọn lati rù?

Ki i ṣe pe a gba awọn Keferi là nipa igbagbọ nikan, ṣugbọn a ti sọọkàn wọn di mimọ, ọkan wọn ti di funfun. Wọn si ti gba agbára Ẹmi Mimọ pẹlu. Ki ni ohun ti wọn tun n fẹ ju eyi lọ? Dajudaju ibukun yii tayọ eyi keyi ti a le ri gbà nipa pipa eto ilana Ofin mọ. Ọlọrun kò si fi iyatọ saarin Ju ati Keferi.

Igba pupọ ni ọran yii maa n yọjú lakoko iṣẹ-iranṣẹ Paulu Apọsteli. O fẹrẹ jẹ pe ọrọ yii ni koko iwe rè̩ si awọn ara Galatia. O sọ bayii pe, “Ẹnyin alaironu ara Galatia, tani ha tàn nyin jẹ, ki ẹnyin ki o máṣe gbà otitọ gbọ, li oju ẹniti a fi Jesu Kristi hàn gbangba lārin nyin li ẹniti a kàn mọ agbelebu” (Galatia 3:1). A ti gbà wọn là nipa igbagbọ ninu Jesu. Ki ni ṣe ti wọn n fẹ lati tun pada lati maa tẹle èto Ofin? “Nipa iṣẹ ofin li ẹnyin gbàẸmi bi, tabi nipa igbọran igbagbọ?”

Ododo nipa Igbagbọ

Lati igba Abrahamu ni a ti lana rè̩ silẹ pe, “Olododo ni yio yè nipa igbagbọ,” nitori “Abrahamu ti gbàỌlọrun gbọ, a si kà a si fun u li ododo” (Galatia 3:6). O ṣee ṣe ki eniyan ki o ri igbala ki a tilẹ to fi ofin fun ni.

Ọlọrun bá Abrahamu dá majẹmu, wọn ṣe adehun. O sọ wi pe bi Abrahamu yoo bá gbọran si Oun lẹnu ki o si fi ilu ti awọn eniyan gbe n bọriṣa silẹ, ti yoo si lọ si ilẹ Kenaani, nipasẹ rè̩ li a o ti bukun fun gbogbo idile ayé. Nigbooṣe, Oun yoo rán Ẹni kan si idile Abrahamu ẹni ti yoo jé̩ Olurapada. Ẹni naa ni Jesu.

Abrahamu kò mọ bi yoo ti pé̩ tó ki a to bi Jesu, ṣugbọn o gba Ọlọrun gbọ; nipa igbagbọ rè̩ ninu Jesu a dá Abrahamu lare. O to ẹẹdẹgbaajọ (1,500) ọdun lẹyin naa ki a to bi Jesu, ṣugbọn O wi pe: “Abrahamu yọ lati ri ọjọ mi: o si ri i, o si yọ.” Abrahamu ni ayọ nipa igbagbọ rè̩ ninu Jesu gẹgẹ bi iwọ ati emi ti ni ayọ nigba ti a ba ri igbala nipa igbagbọ ninu Rè̩.

Ofin jẹ Olukọni

Njẹ bi o ti ṣe pe eniyan le ni idalare ki a to fun ni li Ofin, ki ni ṣe ti a fi fun ni li ofin? Paulu sọ fun awọn ara Galatia pe a fi ofin fun ni nitori irekọja titi di akoko ti Jesu yoo de. Jesu ni “irú-ọmọ” ti a ti ṣeleri fun Abrahamu, nipasẹẹni ti a o ti bukun-fun gbogbo idile ayé.

S̩ugbọn gbogbo awọn ọmọ Abrahamu, ani awọn ọmọ Israẹli, kò ni irú igbagbọ ti Abrahamu ni. A ni lati gbé ohun kan ti o le yé wọn ka iwaju wọn nipa Kristi ẹni ti n bọwa. Wọn dabi ọmọde kekere ti a ni lati maa sọ ohun ti wọn kò gbọdọṣe fun wọn. “Iwọ kò gbọdọ …” Nitori naa ni Ọlọrun ṣe fun wọn ni Ofin.

Ọgbọn-le-nirinwo (430) ọdun lẹyin ti Ọlọrun ti bá Abrahamu dáa majẹmu ni O lọ pade Mose lori Oke Sinai ti O si fun un ni Ofin. Awọn eniyan naa gbọ nigba ti Ọlọrun sọrọ lati Ọrun wa, wọn si gbà pe wọn yoo gbọran si gbogbo eyi ti O ti sọ. Eyi ni majẹmu keji, adehun miiran, ti o tẹle eyi ti O bá Abrahamu dá.

Paulu sọ wi pe Ofin jé̩ “Olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ.” Awọn ẹlomiran n sọ pe agbára Ofin yoo wà titi di igba Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún nigba ti Jesu yoo bá awọn Ju dá majẹmu titun. S̩ugbọn Paulu sọ pàtó pe agbára Ofin yoo wà titi di akoko Kristi. “S̩ugbọn lẹhin igbati igbagbọ ti de, awa kò si labẹ olukọni mọ” (Galatia 3:25). Bi a bá dá awọn eniyan wọnyi lare nipa igbagbọ ninu Jesu, kò tun si afo fun Ofin, tabi “olukọni,” lati mú wọn wá sọdọ Kristi.

Irú - Ọmọ Abrahamu

Awọn Ju n pe ara wọn ni ọmọ Abrahamu. Wọn sọ fun Jesu pe, “Abrahamu ni baba wa” (Johannu 8:39). S̩ugbọn Paulu sọ bayi pe: “Bi ẹnyin ba si jẹti Kristi, njẹẹnyin ni irú-ọmọ Abrahamu, ati arole gẹgẹ bi ileri” (Galatia 3:29). Nigba ti a ba di Onigbagbọ tootọ nipa igbagbọ ninu Jesu, awa pẹlu, jẹ irú-ọmọ Abrahamu. Ofin ti o de lẹyin majẹmu ti Ọlọrun dá pẹlu Abrahamu ati ṣaaju wiwá Jesu, kò ni ohunkohun ṣe pẹlu igbala wa.

Paulu fi ye awọn ara Galatia pe bi wọn ba tun fẹṣiṣẹ idalare wọn nipa iṣẹ Ofin, wọn ti di apẹyinda; “A ti yà nyin kuro lọdọ Kristi” (Galatia 5:4).

Oye ohun ti Paulu n wi ye e. O ti fi tọkàntọkàn kọ Ofin, o si ti ṣe inunibini si awọn Onigbagbọ nitori ti o ro pe wọn kò pa Ofin mọ. S̩ugbọn o wi pe oun ṣe e ninu aimọ ni, ati pe Jesu ti ṣaanu fun oun O si ti dariji oun. Ọlọrun ti mu ki o di mimọ fun un pe a ti mu Ofin ṣẹ ninu Kristi, ati pe ofin ko jamọ nkankan mọ.

Ohun ti o ṣoro ni fun Paulu nigba kan ri lati fi ohun ti o gbagbọ tẹlẹ ri silẹ, nitori naa o mọ bi oun ti ṣe le ṣe alaye fun awọn ẹlomiran nipa iyatọ ti o wa laaarin igba Ofin ati igba Ore-ọfẹ. O sọ wi pe Kristi ti fi oun kalẹ bi apẹẹrẹ fun awọn ẹlomiran ti yoo gbagbọ ninu Jesu (1 Timoteu 1:16).

Paulu ni lati tun ṣe iru asọye kan naa ninu iwe rè̩ si awọn Heberu ti o di Onigbagbọ. Awọn Heberu jé̩ olufọkansin nipa pipa Ofin mọ, ṣugbọn Paulu sọ fun wọn pe Ofin jé̩ ojiji awọn ohun ti n bọ. A gbé Ofin le wọn lọwọ titi di “akoko idande,” nigba ti Jesu yoo de. Gbogbo irubọ ti o ni tita è̩jẹẹran silẹ ninu jẹ apakan Ofin. Awọn apẹẹrẹ ti a le fi oju ri, wọn si n tọka si Jesu gẹgẹ bi Ọdọ-agutan Ọlọrun. Nigba ti Jesu ta Ẹjẹ Rè̩ silẹ, irubọ nipa tita è̩jẹẹran silẹ kasẹ nilẹ.

Majẹmu Titun

Lẹyin ti a ti fi Ofin fun ni lori Oke Sinai, Ọlọrun wi pe: “Kiyesi i, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o bá ile Israẹli ati ile Juda dá majẹmu titun. Ki iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; … Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israẹli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi ó si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mā jé̩Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mā jé̩ enia fun mi” (Heberu 8:8-10).

Eyi ni Majẹmu ti Ọlọrun yoo bá awọn Ju dá nigba ti wọn bá gba Jesu ni Messia; ṣugbọn nipa igbagbọ ninu Jesu anfaani majẹmu yii ti tè̩ wá lọwọ ná. Awọn Ju kò ni igbagbọ ninu Jesu nisisiyi, nitori naa ileri Majẹmu yii kò ti i le ṣẹ si wọn lara nisisiyi gẹgẹ bi orilẹ-ède. S̩ugbọn gbogbo awọn ti a gbala nipa igbagbọ ti di alabapin Majẹmu yii. Nigba ti Jesu wá si aye ti O si fi ara Rè̩ṣe etutu, O wi pe, “Kiyesi i, Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun.” Nipa ṣiṣe eyi, O mu Majẹmu lailai kuro, ani Ofin, O si fi Majẹmu titun rọpo rè̩ (Heberu 10:9).

Jesu ni Olori Alufaa wa. Ninu Iwe Heberu a kà a pe iṣẹ alufaa ti Rè̩ yatọ si ti ilana Ofin. Jesu ni “alufa titi lai nipa ẹsẹ Mẹlkisedeki” (Heberu 7:17). Labẹ Ofin, iran Aarọni ni a n fi joye alufaa, nigba ti wọn bá dagba, wọn a si kú. S̩ugbọn Jesu wa wà titi lai, Jesu wà li Ọrun nisisiyi, O n bẹbẹ pe ki Ọlọrun dariji olukuluku ẹni ti o ba gbadura fun igbalà.

Iwọ kò ha ri pe Jesu tayọ gbogbo awọn alufaa wọnni ti o wà labẹ Ofin? Bẹẹ gẹgẹ ni igbala wa labẹ oore-ọfẹ ta gbogbo ẹsin ti igba Ofin yọ.

Agọ Dafidi

Jesu yoo gbé ijọba Rè̩ kalẹ ninu ayé nigba ifarahàn Rè̩ nigba ti O ba tun pada wá. Nigba naa ni Oun yoo tún “agọ Dafidi pa ti o ti wó lulẹ.” Ileri ti Ọlọrun ṣe fun Dafidi ni pe bi o ba pa aṣẹỌlọrun Olodumare mọ tọkàntọkàn, a o fi idi idile rè̩ mulẹ lailai. Nipa aigbọran awọn ọmọ Dafidi, ijọba naa bẹrẹ si dinku; ṣugbọn ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun ọdún, a o tún dá ijọba pada fun un, Jesu ẹni ti i ṣe iran Dafidi yoo jé̩Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa.

Ọran Yanjú

Ni opin ajọ ti a ṣe ni Jerusalẹmu, a kọ iwe ranṣẹ si awọn ijọ nibi ti rogbodiyan naa gbéṣẹlẹ, pẹlu asọye pe a kò fi Ofin Mose de awọn Onigbagbọ, ṣugbọn ki wọn ki “o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu è̩jẹ, ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere.” Jesu ti mú Ofin ṣẹ, awọn eniyan naa wà labẹ oore-ọfẹ nisisiyi, ṣugbọn Jesu tikara Rè̩ṣe asọye pe ohun ti a n reti lọwọ Onigbagbọ ti o wà labẹ Oore-ọfẹ tilẹ ga ju ti awọn ti o wa nigba Ofin lọ.

A jiṣẹ yii fun awọn ijọ, inú olukuluku si dùn lori ipinnu ti Ẹmi Mimọ dari awọn arakunrin ti o wà ni Jerusalẹmu lati ṣe.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni eniyan ni lati ṣe ki o to le ri igbala?

  2. 2 Nipasẹ orukọ ta ni a le fi gbà wá là?

  3. 3 Ta ni ẹlẹsin nipa igbekalẹ awọn Ju?

  4. 4 Ki ni wọn n sọ fun awọn Onigbagbọ ti o ṣẹṣẹ gbagbọ ti n yọ ayọ igbala?

  5. 5 Nipa ki ni a dá Abrahamu lare?

  6. 6 Ki ni ṣe ti a fi fun ni ni Ofin?

  7. 7 Ta ni “iru-ọmọ” Abrahamu?

  8. 8 Nigba wo ni a mu Ofin ṣẹ?

  9. 9 Ta ni Olori Alufaa wa?

  10. 10 Irú majẹmu wo ni Ọlọrun yoo bá awọn Ju dá ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun ọdún?