Iṣe Awọn Apọsteli 16:9 - 40

Lesson 334 - Junior

Memory Verse
“Bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun ji i dide kuro ninu okú, a o gbàọ là” (Romu 10:9).
Notes

Iranlọwọ

“Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ”; eyi ni ọrọ ti Paulu gbọ. O ri iran ni oru. O ri ọkunrin kan ara Makedonia ti n bẹbẹ fun iranlọwọ. O n fẹ ki Paulu ran oun lọwọ lati mọ nipa Jesu.

Paulu ti ṣe iranwọ fun ọpọlọpọ eniyan ninu irin-ajo rè̩ ekinni. O ti ṣe iranwọ fun wọn nipa ti ẹmi. O ti waasu nipa Jesu, ọpọlọpọ eniyan si gba ọrọ rè̩ gbọ. Paulu ti ṣiṣẹ fun Oluwa ati fun awọn eniyan rè̩. O dá ijọ silẹ o si yan awọn alagba ninu ijọ kọọkan.

Makedonia jé̩ ilu ti o jinna rére ni odikeji okun lọhun. Paulu yoo ha lọ si ibi ti o jinna to bayii lati lọ ran ẹnikan ti kò mọ ri lọwọ? Bẹẹni, Paulu n fẹ lati tan Ihinrere kalẹ. O gbà pe iran yii jé̩ ipe fun un lati waasu Ihinrere fun awọn ara Makedonia. Ki i ṣe igba gbogbo ni Ọlọrun maa n fi iran han awọn eniyan nigba ti o ba n pe wọn si iṣẹ ajihinrere. Nigba miiran awọn eniyan a maa kọwe lati beere fun iranlọwọ. Nigba miiran, Ọlọrun maa n fi iwuwo si ọkàn awọn eniyan Rè̩ nipa awọn eniyan kan ti o wa nibi kan. Nigba miiran è̩wẹ, Ọlọrun le fi si wa lọkàn lati pe ẹni kan wá si Ile-ẹkọỌjọ Isinmi ati sibi isin. Ki i ṣe ilu okere nikan ni iṣẹ Ajihinrere pè̩kun si. Awọn eniyan wà ni arọwọto wa ti wọn n fẹ iranwọ. Ọlọrun le lo ọmọ-kekere pẹlu ninu iṣẹ Ajihinrere Rè̩.

Lilọ Lọgán

Lẹyin ti Paulu ti gbọ ipe lati lọ si Makedonia, o mọ pe Ọlọrun n fẹ ki oun lọ si ilẹ ti o jinna réré nì. Paulu ti ni idaniloju pe Ọlọrun n fẹ ki oun lọ waasu Ihinrere fun awọn eniyan wọnyii. Eniyan lè ni idaniloju ipe ti a pe e. Eniyan le mọ ifẹỌlọrun pẹlu. Nigba ti eniyan bá gbadura, pẹlu ijọwọ-ara-ẹni-lọwọ lati lọ tabi lati duro, Ọlọrun yoo fi ohun ti yoo ṣe hàn án.

Nigba ti Paulu ti ni idaniloju ifẹỌlọrun, o mú Sila pẹlu rè̩ o si lọ si Makedonia lẹsẹ kan naa. Boya o ni irúọkan kan naa pẹlu Dafidi, ẹni ti o wi pe, “Iṣẹọba na jé̩ iṣẹ ikanju” (1 Samuẹli 21:8). Paulu n ṣiṣẹ fun Jesu, Ọba awọn ọba, o si mọ pe oun ni lati ṣiṣẹ nigba ti anfaani wà lati ṣe bẹẹ. Awọn ẹlomiran a maa fi oni dọla lati ṣe ifẹỌlọrun. Nigba miiran wọn ni ohun kan ti wọn fẹṣe ti wọn kò si fẹ fi silẹ. Nigba miiran ẹwẹ, wọn ni nkan miiran ti wọn n fẹṣe ki wọn to wáṣe ifẹỌlọrun. Nigba miiran wọn maa n fẹ lati ronu le e lori fun ọjọ pipẹ ki wọn to pinnu lati gbọran ati lati ṣe ifẹỌlọrun. Paulu kò ni ilepa miiran ninu igbesi-aye rè̩ ju pe ki o ṣe ifẹỌlọrun lọ. Paulu ṣetan lati gbọran. Nigba ti anfaani báṣi silẹ lati tan Ihinrere kalẹ ati lati ran awọn ẹlomiran lọwọ lati mọ nipa Jesu, Paulu ṣetan lati lọ, o si ṣetan lati ṣiṣẹ.

“Mo fẹ lọ, mo si fẹ duro,

Mo fẹ dipo mi mu;

Mo fẹṣiṣẹ nla tabi kekere,

Mo fẹṣe ifẹ Rẹ.”

Ni Filippi

Paulu ati Sila ṣikọ lati Troasi, nikẹyin wọn de Filippi, ti i ṣe olu ilu Makedonia. Wọn duro nibẹ fun ọjọ diẹ. Wọn ṣeto lati ni ipade adura leti odo kan lẹyin ilu. Awọn obinrin kan pejọ sibẹ, Paulu si bẹẹrẹ si ba wọn sọrọ.

Oniṣowo Elese Aluko

Ọkan ninu awọn obinrin ti o gbọọrọ Paulu ni a n pe ni Lidia. O jé̩ ara ilu kan ti a n pe ni Tiatira, ilu ti o ni okiki nitori iṣẹ aró rirẹ. Lidia n ta aró wọnyii ni Filippi. Obinrin yii jẹẹlẹsin o si n sin Ọlọrun. Bi o ti n gbọọrọ Paulu, o gbọ nipa ỌmọỌlọrun, ani Jesu Kristi. Oluwa báọkàn Lidia sọrọ. O gbagbọ ninu awọn ohun wọn ni ti Paulu sọ. O ṣi ọkàn rè̩ payá o si gba Ihinrere, o si di ọmọlẹyin Kristi.

Iribọmi

Bi eniyan ba gbadura, bi o ba mọ ara rè̩ ni ẹlẹṣẹ, ti o si bẹbẹ pe ki Ọlọrun dariji oun, ti o si gba Jesu Kristi Oluwa wa gbọ, oluwarẹ yoo ri igbala. Nigba ti eniyan ba di atunbi, oun yoo fẹṣe iribọmi. IfẹỌlọrun ni. Iribọmi jé̩ apakan Ihinrere, Oluwa si n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ gbọran si ohunkohun ti i ṣe ti Ihinrere. Nigba ti Oluwa fi Aṣẹ Nla nì fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩, O wi pe, “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ: ki ẹ ma kọ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin” (Matteu 28:19, 20).

Ninu Bibeli, ni a ri apẹẹrẹ awọn wọnni ti a gbala ti a si ṣe iribọmi fun. Ni Ọjọ Pẹntikọsti, nigba ti Peteru waasu ti o kún fun agbára Ọlọrun, “awọn ti o si fi ayọ gbàọrọ rè̩ a baptisi wọn” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:41). Filippi waasu Kristi fun iwẹfa ara Etiopia bi wọn ti n lọ li ọna ninu kẹké̩. Nigba ti wọn si de ibi ti omi wà, iwẹfa na ri i pe anfaani ṣi silẹ fun oun lati gbọran si aṣẹỌlọrun ki o le ni iriri iribọmi. Iwẹfa naa wi pe, “Wò o, omi niyi; kili o dá mi duro lati baptisi?” Filippi si dahun pe, “Bi iwọ ba gbagbọ tọkàntọkan, a le baptisi rẹ” (Wo Ẹkọ 292). Awọn mejeeji lọ sinu omi a si ri iwẹfa naa bọmi. Lẹyin naa iwẹfa yii n ba ọna rẹ lọ, o si n yọ.

Lidia ati awọn ara ile rè̩ jẹ awọn miiran ti a tun ṣe iribọmi fun. Ọkàn rè̩ kun fun ọpẹ si Ọlọrun fun ohun ti O ṣe fun un. Inu rè̩ dun nitori pe o gbọran si aṣẹ Oluwa. O fẹṣe ohun kan fun Oluwa. O fi ọpẹ rè̩ hàn nipa ṣiṣe itọju awọn eniyan Ọlọrun.

Iṣoore

Lidia bẹ Paulu ati Sila lati wọ si ile rè̩ bi wọn ba kà oun si oloootọ si Ọlọrun, ati ẹni ti o yẹ si irú anfaani bẹẹ. Lidia kà a si anfaani lati ṣe itọju awọn eniyan Ọlọrun wọnyi. O ṣe e gẹgẹ bi fun Oluwa. A kà pe: “Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mā fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, ki si iṣe fun enia: ki ẹ mọ pe lọwọ Oluwa li ẹnyin ó gbàère ogun: nitori ẹnyin nsin Oluwa Kristi” (Kolosse 3:23, 24). Ere wà fun awọn wọnni ti o ṣe awọn eniyan Ọlọrun loore. Nigba ti wọn ba si n gba ère naa, wọn o gbọ ti Kristi yoo wi pe, “Niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọẹnyin ti ṣe e fun mi” (Matteu 25:40).

Alafọṣẹ Kan

Ni ọjọ kan, bi Paulu ati Sila ti n lọ si ipade adura, ọdọmọbinrin kan tẹle wọn. O ni ẹmi eṣu, o si li ẹmi afọṣẹ. O sare tọ wọn lẹyin, o si n kigbe. Eyi ṣẹlẹ fun ọjọ pupọ. Inu Paulu bajẹ nitori pe ẹmi eṣu n dáọmọbinrin yii loro. Paulu báẹmi aimọ naa wi li orukọ Jesu Kristi, ẹmi eṣu ti o ti n dari rè̩ si fi i silẹ.

Ọdọmọbinrin yii jé̩ iranṣẹ awọn eniyan kan. O n sọ asọtẹlẹ nipa ẹmi afọṣẹ, awọn oluwa rè̩ si n gba owo iṣẹ rè̩. Nigba ti a léẹmi eṣu yii jade kuro lara rè̩, ẹmi afọṣẹ fi i silẹ, awọn oluwa rè̩ si sọọna ere rẹpẹtẹ wọn nù. Eyi kò dùn mọ wọn rara. Wọn kò kaanu fun un nigba ti ẹmi eṣu n da a loro. S̩ugbọn inu wọn bajẹ nitori pe owo ko ni wọle fun wọn lọna buburu ti o rọrùn yii mọ.

Ninu Tubu

Awọn oluwa rè̩ mu Paulu ati Sila wọn si fa wọn lọ si ọjà nibi ti ile-ẹjọ gbe wa, wọn si fi è̩sun kan wọn. Wọn wi pe, “Awọn ọkunrin wọnyi … nwọn nyọ ilu wa lẹnu jọjọ.” Iyọnu ha ni lati fi opin si iṣẹ ibi nipa ṣi ṣe rere? Awawi patapata ni ẹsun wọn jasi. Nitori ikorira ti wọn ni si Paulu ati Sila, wọn rú awọn eniyan soke si awọn eniyan Ọlọrun wọnyi. Lai fi àye silẹ fun wọn lati sọ ti ẹnu wọn, wọn hu iwa ika si Paulu ati Sila, wọn fi ọgọ lù wọn, wọn si gbe wọn ju sinu tubu. A si kilọ fun onitubu ki o “pa wọn mọ daradara,” nitori naa a fi wọn sinu tubu ti inu lọhun a si kan àba mọ wọn li ẹsẹ.

Idasilẹ

Li ọganjọ oru, ohun iyanu kan ṣẹlẹ. Awọn onde iyoku gbọ ohùn adura ati orin iyin si ogo Ọlọrun. Awọn ọkunrin meji wọnyii ti è̩yin wọn n ṣẹjẹ ti a si kan ẹsẹ wọn mọàba ha tun le yin Ọlọrun logo bi? Njẹ awọn ọkunrin meji wọnyi ti a hu iwa aitọ si yii ha tun le ni igbagbọ ninu Ọlọrun sibẹ? Awọn ọkunrin meji wọnyii ti a n jẹ niya li ainidi yii ha tun le ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun sibẹ? Dajudaju wọn ṣe bẹẹ, igbagbọ wọn ko yè̩, Ọlọrun si gbọ iyin ati adura wọn. Lojiji isẹlẹ nla sè̩. Ile tubu mi titi, ani titi de ipilẹ. Ide awọn onde tú. Gbogbo ilẹkun si ṣi silẹ.

Onitubu

Onitubu taji kuro loju oorun. Nigba ti o ri ti awọn ilẹkun ṣi silẹ, o rò pé gbogbo awọn onde ti salọ. O fẹrẹ fi ida pa ara rè̩. O mọ daju pe a o pa oun bi oun kò ba ri awọn ondè wọnyi mọ, paapaa julọ, awọn ondè meji ti a fi sinu tubu ti inu lọhun. S̩ugbọn Paulu kigbe li ohun rara pé, “Máṣe pa ara rẹ lara.” Nigba naa ni onitubu bere iná lati fi wo awọn ondè naa. O wọ inu tubu ti inu lọhun ti o tutù ti o si ṣokunkun dudu nibi ti Paulu ati Sila gbe wà. O mọ pé eniyan Ọlọrun ni wọn i ṣe. O si mọ wi pe wọn le ran oun ẹlẹṣẹ, lọwọ pẹlu. Nigba ti o ti mu wọn jade tán, o beere pe, “Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le là?”

Igbala

Paulu ati Sila sọ nipa Oluwa fun onitubu yii ati awọn ẹbi rè̩. Wọn gba ọrọ ti wọn gbọ gbọ, a si gbà wọn là. A ri wọn bọmi pẹlu lati fi hàn pe wọn ti jẹwọ igbagbọ ninu Jesu ati pe iṣẹ irapada ti inu ti ṣẹlẹ ni igbesi-ayé wọn.

Onitubu ṣe inu rere si awọn ọkunrin meji ti o ràn án lọwọ lati ri Jesu yii. O mu wọn lọ si ile rè̩. O wẹọgbẹ wọn, o si fun wọn ni ounjẹ. Inu rè̩ yoo ti dun pọ to pe oun ri igbala! Inu rè̩ ti dun pọ to pe awọn ẹbi rè̩ ri igbala! Wo bi ayọ rè̩ ti pọ to lati wà pẹlu awọn eniyan Ọlọrun wọnyii!

Jijiya fun Kristi

Lai si aniani, inu Paulu oun Sila dùn nitori pe wọn ri i pe awọn ọkàn kan ni igbala. Nina ti a na wọn kò jamọ nnkan kan, niwọn igba ti wọn ti ni anfaani lati sọrọ Jesu fun awọn eniyan. Ki ni tubu ti a gbé wọn si jamọ niwọn igba ti eyi mú ki onitubu ati awọn ẹbi rè̩ di atunbi? Paulu ati Sila kò ráhun nitori iya ti a fi jẹ wọn. Wọn kò sá jade lati sa lọ nigba ti wọn ri i ti awọn ilẹkun ṣi silẹ. Ohun ti o jẹ wọn lógún ni lati ṣe ifẹỌlọrun fun igbalà awọn ọkàn. Awọn wọnyii jẹ eniyan Ọlọrun gidi ati apẹẹrẹ rere fun wa. Njẹ a ha ni iwuwo ni ọkàn wa fun igbala awọn ẹlomiran? Njẹ a ha n yin Ọlọrun logo nigba ti a ba ni la ipọnju kọjá? Njẹ a n ṣe suuru bi, nigba ti a ba n ṣe inunibini si wa? Ọkan ninu awọn ibukun ni: “Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọrọ buburu gbogbo si nyin nitori emi. Ẹ mā yọ, ki ẹnyin ki ẹ si fò fun ayọ: nitori ère nyin pọ li ọrun: bḝni nwọn sáṣe inunibini si awọn wolĩ ti o ti mbẹṣaju nyin” (Matteu 5:11, 12).

A Tú Wọn Silẹ

Nigba ti o di owurọọjọ keji, awọn alaṣẹ ranṣẹ pe ki a “da awọn enia wọnni silẹ.” S̩ugbọn Paulu kò kanju lati lọ. A ti doju ti wọn, a si ti hu iwa aitọ si wọn nigba ti wọn wa ni “aijẹbi.” A gbe wọn sọ sinu tubu lodi si ofin, bi o tilẹ jẹ wipe ara Romu ni wọn i ṣe. A ti hu iwa aitọ si wọn ni gbangba niwaju ọpọ eniyan ṣugbọn wọn n fé̩ tú wọn silẹ ni ikọkọ. Paulu wi pe, “Ki awọn tikarawọn wá mu wa jade.”

Nigba ti awọn onidajọ gbọọrọ wọnyii, è̩ru bà wọn. Wọn ti gberaga wọn si jẹ alailaanu, ṣugbọn nisisiyi Oluwa rè̩ wọn silẹ. Lati fi hàn pe Paulu ati Sila kò jẹbi, awọn onidajọ lọ si ile tubu, wọn si dà wọn silẹ. Wọn rọ Paulu ati Sila lati jade kuro ni ilu. Lai si aniani wọn ni idalẹbi lọkàn wọn nitori iwa aitọ ti wọn hù, wọn si n fẹ ki a jawọ kuro ninu ọran naa.

Nigba ti wọn sọ fun Paulu ati Sila lati fi ilu silẹ, ohun ti wọn n sọ ni pe ki awọn ti n waasu idande fun wọn ki o maa lọ. Ni ọna bayii wọn sọ anfaani ti wọn ni lati gbọ Ihinrere ni akoko yii sọnu. A kò mọ bi awọn eniyan tun ni anfaani miiran lati gbọ iwaasu Paulu tabi ki wọn tun gbọ nipa ti idalare mọ.

Pẹlu awọn Eniyan Mimọ

Ijiya kò ba Paulu lẹru. Oun ati Sila kò sa kuro ni ilu pẹlu ibẹru pe ki a má baa tun lu wọn. Wọn jade pẹlu ọwọ wọn si pinnu lati lọ si ile Lidia. Boya nibẹ, wọn sọ iriri ti wọn ni ninu tubu ati nipa igbala onitubu. Lẹyin ti wọn ti ba awọn eniyan mimọ sọrọ ti wọn si fi ọrọ itunu gba ara wọn niyanju, Paulu ati Sila jade kuro ni Filippi lọ si ibi miiran ti o tẹle e ni ilu Makedonia nibi ti Ọlọrun n fẹ ki wọn gbe lọ waasu.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ipe ti Makedonia?

  2. 2 Ta ni ipe naa jade si?

  3. 3 Ki ni itumọ rè̩?

  4. 4 Bawo ni Lidia ṣe gbọ nipa igbalà?

  5. 5 Bawo ni o ṣe fi ẹmi imoore si Ọlọrun hàn?

  6. 6 Ki ni ṣe ti a fi gbe Paulu ati Sila sinu tubu?

  7. 7 Ki ni wọn ṣe li ọganjọ oru?

  8. 8 Bawo ni Ọlọrun ṣe dahun adura wọn?

  9. 9 Ki ni o ṣẹlẹ si onitubu?

  10. 10 Ki ni Paulu ati Sila ṣe lẹyin ti a da wọn silẹ kuro ninu tubu?