Iṣe Awọn Apọsteli 17:1 - 34

Lesson 335 - Junior

Memory Verse
“Ninu rè̩ li awa gbé wà li āye, ti awa nrin kiri, ti a si li ẹmi wa” (Iṣe Awọn Apọsteli 17:28).
Notes

Wiwaasu

Paulu ati Sila kò rẹwẹsi bi wọn tilẹ ni wahala. Lẹẹkan si i, wọn tun lọ si awọn ilu miiran gbogbo pẹlu ihin ayọ ti igbalà. Ni ilu Tẹssalonika, wọn ri sinagọgu awọn Ju kan nibi ti Paulu gbé ni anfaani lati waasu. Ọpọ awọn Helleni lọkunrin ati lobinrin, gba ọrọ ti Paulu sọ nipa ijiya ati ajinde Kristi kuro ninu okú gbọ.

S̩ugbọn diẹ ninu awọn Ju bẹrẹ si jowu nitori pe ọpọ eniyan feti si ti Paulu. Ni ọjọ kan awọn jagidijagan eniyan dá rogbodiyan nla silẹ ninu ilu, wọn si n wá Paulu ati Sila. Wọn rò pé awọn ajihinrere wọnyi wà ni ile Jasoni, ṣugbọn nigba ti wọn kò ri wọn nibẹ, awọn eniyan buburu wọnyi mú Jasoni lọ siwaju awọn alaṣẹ ilu. Awọn akorira otitọ wọnyii n kigbe pe, “Awọn wọnyi ti o ti yi aiye po wá si ihinyi” (Iṣe Awọn Apọsteli 17:6). Wọn sọ fun awọn alaṣẹ pe Paulu oun Sila n kọ ni nipa Ọba ti a n pe ni Jesu. Eyi mú iyọnu nla bá awọn alaṣẹ, ṣugbọn nikẹyin wọn jọwọ Jasoni lọwọ lọ. S̩ugbọn awọn ọrẹ Paulu pinnu pe o ṣanfaani pe ki o fi ilu silẹ ki wahala miiran maa ba tun ṣẹlẹ. Ni oru Paulu oun Sila lọ si Berea, nibi ti a gbe fi tọkàntọkàn gbà wọn; nibẹ wọn waasu fun ọpọ eniyan nipa Jesu.

S̩ugbọn nigba ti awọn Ju buburu ti o wa ni Tẹssalonika gbọ pé Paulu ati Sila n waasu ỌrọỌlọrun ni Berea, wọn lọ sibè̩ lẹsẹkẹsẹ wọn si rú awọn eniyan soke. O dabi ẹni pe Satani ki i ni itẹlọrun titi di igba ti o ba sa gbogbo ipa rẹ lati dá iṣẹ Oluwa duro. Laisi aniani, a funrugbin ỌrọỌlọrun ni ilu wọnyii, ani gẹgẹ bi irugbin kekere ti a gbin sinu ilẹ, yoo hù jade, yoo si dagba, yoo si so eso ninu ọkàn kọọkan ti ebi n pa.

Ni Atẹni

Lẹyin naa Paulu lọ si Atẹni ilu nla ti Giriki nibi ti o gbé n duro de Sila ati Timoteu lati dara pọ mọọn. Paulu kò joko kawọ gbera lasan ni akoko yii, gẹgẹ bẹẹ loni, ọwọ awọn ọmọỌlọrun kún fun iṣẹ fun Oluwa nigba gbogbo. Bi o si ti n rin kiri laaarin ilu yii, ọkàn rè̩ rú ninu rè̩ nitori ti o ri i pe ilu naa kun fun oriṣa ati awọn abọriṣa. Ẹnikan tilẹ sọ pe iye oriṣa ti ó wà ni Atẹni tayọ iye eniyan ti o wà nibẹ. Ni ojoojumọ ni Paulu n lọ sinu sinagọgu awọn Ju ati si awọn ibi itaja ti o si n waasu Jesu fun awọn eniyan.

Oke Areopagu

Awọn eniyan n beere pẹlu iyanu pe: iru ọlọrun ajeji lati ilẹ ajeji wo ni Paulu n sọ nipa rè̩ yi? Awọn miiran si wi pe: “Kili alahesọ yi yio ri wi?” Ọrọ Paulu dabi ọrọ ti kò ni laari, bi ọrọ were ni eti wọn. Paulu, è̩kọ tuntun wo ni o mu wá yii? Iwọ mu “ohun ajeji wá si eti wa.”

Awọn eniyan wọnyii pinnu pe ki a mu ọkunrin yii lọ si Oke Areopagu, ti i ṣe ibi-idajọ ti o ga jù lọ ni Atẹni. Ni ibi-idajọ Oke Areopagu yii, ni a mu Paulu lọ lati sọ ti ẹnu rè̩ niwaju awọn ti i ṣe ọjọgbọn ju lọ ni ilẹ Giriki. Nigba naa ni Paulu dide duro niwaju awọn ọjọgbọn wọnyii o si wi pe, “Bi mo ti nkọja lọ, … mo si ri pẹpẹ kan … FUN ỌLỌRUN AIMỌ.” O wá lati sọ fun wọn nipa Ọlọrun yii gan an -- Ọlọrun ti O dá ayé ati ohun gbogbo. O ha le jẹ pe wọn kò ti gbọ nipa Ọlọrun ti ki i gbé inu ile ti a fi ọwọ kọ? Wọn kò gbọdọ ni èrò pe Ọlọrun otitọ dabi ere wura, fadaka, tabi okuta ti a ti ọwọ eniyan ṣe. Paulu wi pe nigba kan ri Ọlọrun fara dà O si gboju fò igba aimọ wọn, ṣugbọn o tó wayii; Ọlọrun paṣẹ nisisiyi fun gbogbo eniyan nibi gbogbo lati ronupiwada. Lẹyin naa Paulu sọ fun wọn eredi rè̩ ti wọn fi ni lati ronupiwada è̩ṣẹ wọn: nitori pe Ọlọrun ti yan ọjọ kan ninu eyi ti Jesu yoo pada wá si aye ti yoo ṣe idajọ awọn eniyan nitori ohun ti wọn ti ṣe lori ilẹ aye. Paulu tẹnumọọ pe Ọlọrun ji Jesu dide kuro ninu okú lati jé̩ Olugbala wọn, ati pe Oluwa kò “jina si olukuluku wa” (Iṣe Awọn Apọsteli 17:27). Bi o ba ṣoro lati ri Oluwa, ki i ṣe nitori pe o jina si wa, ṣugbọn nitori pe awa paapaa jina si I a ko si fẹ sunmọỌn. Ni igba gbogbo ni Oun n reti pe ki ẹlè̩ṣẹ ronu piwada ki o si yi pada si Oun fun idariji.

Awọn Ẹlẹgan

Njẹ awọn ara Atẹni gba ọrọ ti Paulu sọ yii gbọ? Diẹ ninu awọn eniyan yii n fi ọran ajinde Jesu kuro ninu okúṣẹfẹ. Saa fi oju inu wo bi awọn eniyan ti ṣe ainaani ti wọn si n fi otitọ ajinde, eyi ti i ṣe ireti Onigbagbọṣẹfẹ! Paulu kọọ pe, “Bi a kò ba si ji Kristi dide, asan ni igbagbọ nyin” (1 Kọrinti 15:17). Awọn miiran wi pe ki Paulu tún pada wá ni ọjọ miiran boya awọn yoo le nifẹ si ohun ti o n sọ.

Awọn ẹlomiran n rò pe bi awọn kò bá mọ pupọ nipa Oluwa ati Ihinrere, a ki yoo beere pupọ li ọwọ wọn. Awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin miiran rò pe o tilẹṣanfaani fun wọn bi wọn ba fa sẹyin ni ile Ọlọrun ki a maa ba kà pupọ si wọn lọrun nipa imọ ati imọlẹ ti wọn i ba ni nipa ỌrọỌlọrun. Otitọ ti o daju ni pe wọn yoo dahun fun gbogbo ododo ti a gbe kalẹ ninu gbogbo ỌrọỌlọrun nitori pe ododo wọnyii wà ni arọwọto wọn. Ẹ jé̩ ki a bẹru ki a má si ṣe kuna lati lo gbogbo anfaani ti a ni lati gbọ ati lati kọ nipa ti Oluwa, nitori kò si awawi ti yoo lè gbà wá silẹ niwaju itẹ idajọỌlọrun ni ọjọ nla nì.

Awọn diẹ ni o gba ọrọ ti Paulu sọ nipa Jesu gbọ, a si kà awọn ọrọ ti o ba ni ninujẹ wọnyii pe, “Bḝni Paulu si jade kuro larin wọn.”

Ọjọ n bọ ti Kristi yoo rẹrin ti yoo si ṣe è̩fẹ awọn wọnni ti wọn kọ ipe Ọlọrun. “Emi pẹlu o rẹrin idāmu nyin; emi o ṣe è̩fẹ nigbati ibè̩ru nyin ba de” (Owe 1:26). Ọjọ ti Paulu sọ nipa rè̩ nì -- ọjọ naa ti Ọlọrun ti yàn ninu eyi ti yoo ṣe idajọ araye nitori è̩ṣẹ wọn –wa niwaju, o si n bọ wá. Ni ọjọ naa, ki i ṣe awọn ara Atẹni, Giriki, ati awọn ara Tẹssalonika ati Berea nikan ni yoo wà lai si awawi, ṣugbọn ọpọlọpọ eniyan ni gbogbo agbaye ni yoo yadi niwaju Onidajọ ododo. A ti sọ itan Ihinrere fun wọn, ṣugbọn wọn séàya wọn le. Ki Ọlọrun ran wa lọwọ lati ni eti igbọ ati aya igbaṣe si itan Jesu ati ifẹ Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni koko iwaasu Paulu?

  2. 2 Sọ iha ti awọn Ju ti Tẹssalonika kọ si Paulu?

  3. 3 Ki ni Paulu ṣe nigba ti o dé Atẹni?

  4. 4 Orukọ wo ni wọn pe Paulu ni Atẹni?

  5. 5 Sọ iwaasu Paulu lori Oke Areopagu?

  6. 6 Ki ni Oke Areopagu jẹ?

  7. 7 Ofin keloo ni o sọ pe a kò gbọdọ sin ère wura, fadaka, ati okuta?

  8. 8 Njẹ awọn eniyan gba ọrọ Paulu gbọ nipa ajinde Kristi?

  9. 9 Ki ni ohun ti Paulu sọ nipa aigba ọrọ ajinde gbọ?

  10. 10 Ki ni ajinde Kristi jẹ fun wa lọjọ oni?