Iṣe Awọn Apọsteli 18:1-22

Lesson 336 - Junior

Memory Verse
“Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá” (1 Kọrinti 3:6).
Notes

Awọn Apàgọ

Paulu Apọsteli jé̩ apàgọ, bakan naa ni o si tun jẹ ajihinrere. Nigba ti o wà ni Kọrinti, iṣẹ agọ pipa ni o n ṣe jẹun. O n gbe ile Akuila on Priskila awọn ẹni ti i ṣe oniṣẹọna kan naa pẹlu rè̩. A kò mọ igba ti Akuila ati Priskila di Onigbagbọ. Boya wọn ti di atunbi ki wọn tilẹ to kuro ni Romu. Tabi nigba ti wọn jumọ n ṣiṣẹ pọ pẹlu Paulu ni wọn gbọ nipa Jesu ti wọn si ni iyipada ọkàn. Ọpọ eniyan ni o jẹ pe ni ẹnu iṣẹ wọn ni wọn gbé gbọ nipa Ihinrere Jesu. Nibi iṣẹ ni a ti pe awọn ẹlomiran wá si ipade. A fun awọn ẹlomiran ni iwe Ihinrere lati kà. Awọn ẹlomiran è̩wẹ, ri iwa awọn alabaṣiṣẹ pọ wọn ti i ṣe Onigbagbọ, wọn beere ijọ ti wọn n lọ, a si sọ fun wọn nipa igbalà kuro ninu è̩ṣẹ. Lilọ si ile è̩kọ jẹ apakan iṣẹ ti ọmọde ni lati ṣe. Awọn ọmọde ti o jẹ Onigbagbọ ni anfaani lati jẹ imọlẹ ni ile-iwe. Awọn ọmọde miiran wà ti o jẹ pe ọmọ ile-iwe ẹlẹgbẹ wọn ni o mu wọn wa si Ile-ẹkọỌjọ Isinmi. Lọna bayii ni wọn gbà mọ Jesu ti wọn si ri igbalà.

Ihinrere ti o MuỌgbọn Dani

Paulu kò jẹ ki iṣẹ rè̩ di i lọwọ lati lọ si Ile Ọlọrun. Nigba ti awọn eniyan ba pejọ ni sinagọgu (ti i ṣe ile-isìn awọn Ju), Paulu wà nibẹ pẹlu. Paulu kò lọ si ile-isin awọn Ju lati sìn gẹgẹ bi awọn Ju ṣe n sìn. O lọ sibẹ lati lọ waasu Jesu fun wọn. O si “nfọrọ we ọrọ” pẹlu wọn; eyi ni pe, o n ba wọn sọrọ, o si n fi ye wọn eredi rè̩ ti wọn fi ni lati gba Jesu gbọ. Wolii Isaiah kọwe: “Oluwa wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ: bi è̩ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didi; bi nwọn pọn bi alāri, nwọn o dabi irun-agutan” (Isaiah 1:18).

Ki i ṣe wi pe Paulu n fọrọ werọ pẹlu awọn Ju nikan, ṣugbọn o rọ wọn lati gbadura ki wọn le ni igbala. Paulu ni iwuwo ọkàn fun awọn eniyan ti o wà ni Kọrinti yii. O mọ pe iṣẹ oun ni lati sọ fun wọn nipa igbala. O gbà pe anfaani ni o jẹ fun oun lati sọẹri rè̩ nipa Jesu. Paulu ni ifẹ si ọkan awọn ọmọ eniyan, nibikibi ti o ba si lọ, o jẹ oloootọ si Ọlọrun rè̩ ati si awọn eniyan ẹlẹgbẹ rè̩ niti pe o n sọ fun wọn nipa Jesu.

S̩iṣe lodi si Ara Wọn

Sila on Timoteu dara pọ mọ Paulu ni Kọrinti. S̩ugbọn awọn miiran ninu awọn Ju kò fara mọ iwaasu wọn. “Nwọn si wà li òdi.” Ohun ti awọn ẹni ti o ba kọè̩kọ Jesu maa n ṣe ni eyi. Wọn n ṣe lòdi si ara wọn; wọn n ṣe ara wọn nibi, nitori pe ohun rere ni Ihinrere n ṣe ni igbesi-ayé eniyan. “Ẹniti o ba gbà a gbọ, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọỌmọ bibi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ” (Johannu 3:18).

Paulu ti waasu fun awọn Ju tọkantọkan. Bi wọn ba si fẹ kọ Jesu, iyoku di ọwọ wọn, ohun ti wọn fẹ ni wọn yan. Paulu ti sae ipa tirè̩ nipa wiwaasu igbala fun wọn ati nipa gbigbadura fun wọn. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin rè̩ pe, “Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọrọ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro nibè̩, ẹ gbọn ekuru ẹsẹ nyin fun ẹri si wọn” (Marku 6:11). Paulu “gbọn aṣọ rè̩” gẹgẹ bi ẹri si awọn Ju, awọn ẹni ti o “wà li òdi si ara wọn.”

Isin abẹIle

Ọkunrin kan ti orukọ rè̩ n jé̩ Justu n gbé nitosi sinagọgu. O lè jẹ wi pe, Paulu ṣe isin ninu ile ọkunrin yii lẹyin ti o ti fi sinagọgu silẹ nitori pe awọn Ju kò fẹ gbọ nipa Jesu mọ. Awọn kan fẹ gbọ iwaasu Paulu; nigba ti wọn si gbọ, wọn ni iyipada ọkàn. Krispu, olori sinagọgu, ati awọn ẹbi rè̩ wà ninu awọn ti o gbagbọ. Boya ni o wà ni ipo olori sinagọgu ti o jẹ tẹlẹ ri fun ọjọ pupọ lẹyin ti o ti ri igbalà. Nigbooṣe a tun kà nipa ọkunrin kan ti i ṣe olori sinagọgu.

Gbigbọ ati Gbigbagbọ

“Ọpọ ninu awọn ara Kọrinti, nigbati nwọn gbọ, nwọn gbagbọ, a si baptisi wọn.” Eyi n fi hàn bi itankalẹ Ihinrere, ẹri jijé̩, ati bibá awọn ẹlomiran sọrọ nipa Jesu ti ṣe pataki tó. Ẹnikan ha ṣe le gbagbọ bi kòṣe pe o gbọ nipa Jesu? Boya iwọ n fẹ ki ọré̩ rẹ kan tabi awọn obi rẹ ki o ba ọ wá si ile Ọlọrun ki wọn si ri igbalà. Iwọ ha ti sọ fun wọn nipa Jesu?

Paulu ri i pe ki i ṣe gbogbo awọn ti o gbọ nipa Jesu ni o gbagbọ. Bakan naa ni o ri lọjọ oni pẹlu. Awọn miiran wà bẹẹ ninu awọn ti n wá si Ile-è̩kọỌjọ Isinmi, wọn gbọè̩kọ nipa Jesu ni ibi ijoko wọn, wọn kọrin nipa Rè̩; wọn kọè̩kọ nipa ỌmọỌlọrun, gbogbo wọn ni o ha ri igbalà? Iwọ ha ti ri igbalà?

Imulọkan Le

Nigba ti Paulu wa ni Kọrinti, Oluwa ki i laya ni ojuran. Oluwa sọ fun Paulu pe ki o maa waasu ki o máṣe bè̩ru, nitori ti kò si ẹni ti yoo le pa a lara. O sọ fun Paulu pẹlu pe ọpọ eniyan ni o wà ni Kọrinti ti wọn gbagbọ ti wọn si n sin Kristi. Oluwa wi pe, “Má bè̩ru, …nitoriti emi wà pẹlu rẹ.”

Ọlọrun a saba maa ki awọn eniyan Rè̩ laya pẹlu irú ileri bayii, Oun a maa bá awọn eniyan Rè̩ wi nigba ti wọn ba yẹ fun ibawi, O si ma n gbà wọn niyanju nigba ti wọn ba yẹ fun gbigba niyanju. Ọlọrun ki awọn Ọmọ Israẹli laya nigba ti wọn lọ lati bá awọn ọtá ti wọn ni ọpọọmọ-ogun jù wọn lọ jà. O wi pe, “Máṣe bè̩ru wọn: nitori OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ” (Deuteronomi 20:1). Nigba ti Jọṣua lọ bá awọn ọba pupọ jà, Oluwa fi iru ọrọ kan naa ki i laya: “Máṣe bè̩ru nitori wọn” (Jọṣua 11:6). Jesu yọ si awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nigba ti wọn wà ninu igbì. O wi pe, “Emi ni; ẹ má bè̩ru” (Matteu 14:27). Bakan naa lati igbaani ani titi di oni-oloni ni Oluwa wà pẹlu awọn ọmọ-lẹyin Rè̩ lati ki wọn laya ni akoko iṣoro.

Paulu wà ni Kọrinti ni ọdun kan ati oṣù mẹfa. Ni akoko yii, o n fi ỌrọỌlọrun kọ awọn eniyan. Ọpọlọpọ ninu awọn ara Kọrinti ni o gbagbọ. Lai si aniani eyi ni ibẹrẹ Ijọ ni Kọrinti. Ki i ṣe gbogbo awọn ti o gbọọrọ Paulu nipa Jesu ni o gbagbọ. Ki i ṣe wi pe awọn miiran kò gbagbọ nikan, ṣugbọn wọn ṣe Paulu ni wahala.

Ẹsùn

Ni akoko kan, a mú Paulu lọ siwaju itẹ idajọ Gallioni, ẹni ti i ṣe aṣoju Ijọba Romu ni Akaia. A sun un lẹsùn pe o n yi awọn eniyan lọkan pada lati sìn Ọlọrun lodi si ilana Ofin. S̩ugbọn ki Paulu to ya ẹnu rè̩ lati sọrọ rara, Gallioni ti bẹrẹ si i bá awọn olufisun rè̩ wi. O wi pe oun ki yoo feti si ọràn naa bi o ba jẹọràn nipa ẹsin wọn ni. Àyè Gallioni gẹgẹ bi oṣiṣẹ Ijọba Romu kò fun un ni anfaani lati ṣe idajọ lori ọràn ẹsìn awọn Ju. Inu bi i wi pe awọn eniyan wọnyii mu ẹsùn ti oun kò lèṣe idajọ lori rè̩ tọọ wá. Gallioni túọràn naa ka, o si lé awọn eniyan naa kuro niwaju itẹ idajọ rè̩. Nigba naa ni diẹ ninu awọn Hellene ti o ti n wòran mú Sostene. Gẹgẹ bi olori sinagọgu, o ṣeeṣe ki o jẹ pe oun ni balogun awọn Ju ti o sun Paulu lẹsùn. Awọn Hellene lù Sostene niwaju itẹ idajọ. Gallioni kò si ṣú si i, ko tilẹ bikita pe a n hù iru iwa iwọsi ti awọn Ju ti fẹ hù si Paulu si awọn Ju tikarawọn.

Aibikita

Ki i ṣe wi pe Gallioni fi taratara gbeja Paulu. Kò si lẹyin Paulu tabi awọn Ju. O jé̩ẹni ti kò bikita, kò tilẹ naani eyikeyi ninu awọn è̩kọ yii. Boya ohun ti o leke lọkàn rè̩ ni lati té̩ Klaudiu ọba Romu, ẹni ti o fi i ṣe alaṣẹ ni Akaia, lọrun. Ọpọlọpọ eniyan lọjọ oni ni kò naani ohun ti ẹmi. Ohun ti o leke lọkàn wọn ni lati ri ojurere awọn eniyan ti ẹnu wọn tolẹ nibi iṣẹ wọn. Awọn ẹlomiran tilẹ rò pé wọn le wà lai jẹ ti Jesu tabi ti awọn alatako Rè̩. ỌrọỌlọrun kọ wa pe awọn ti kò ba wà fun Kristi n ṣe lodi si I (Matteu 12:30). Bi a ti n ka Bibeli wa, a ri i pe eniyan kò le da duro gedegbe lai fì si ọtun tabi si osi. Ọna meji ni o wa: ọna tooro ti o lọ si ibi iye ati ọna gbooro ti i ṣe ọna ikú ati iparun (Matteu 7:13, 14).

Nigba miiran, awọn eniyan ati awọn ọmọde pẹlu, kii saba rò pe wọn ni lati yan ọna kan yala lati sìn Ọlọrun tabi bẹẹ kọ. Wọn rò pé wọn le gboju fo ọran yii dá, ṣugbọn ni kikuna lati yan Kristi, wọn ti yan Satani ni Oluwa wọn. Wọn le maa lọ si Ile-è̩kọỌjọ Isinmi ati si ile isìn, ki wọṅ si maa pinnu lati sìn Ọlọrun lọjọ iwaju, ṣugbọn wọn kò si ni iha ti Oluwa, nitori pe wọn ti kuna lati gbadura ki wọn si ri igbalà. Wọn ki i ṣe ti Jesu, Ọba awọn ọba, titi di igba ti a ba dari è̩ṣẹ wọn ji wọn ti wọn si wà fun Kristi lojoojumọ.

Ohun ti o ṣẹlẹ niwaju Gallioni yii ko já Paulu laya ki o si sa ni Kọrinti. O duro nibẹ fun igba diẹ, lẹyin naa, o n waasu, o si n tan Ihinrere kalẹ. Nigba ti o tó akoko, Paulu ri i pe o yẹ ki oun tè̩ siwaju ninu irin-ajo rè̩ lati tan Ihinrere kalẹ.

Alabaṣiṣẹ Pọ

Bi o tilẹ jẹ pe Paulu fi awọn ọmọ-ẹyin silẹ ni Kọrinti, kò gbagbe wọn rara. O gbadura fun wọn. O si rán awọn ojiṣẹỌlọrun miiran si wọn lati rán wọn lọwọ. Paulu kọ iwe si wọn lati gbà wọn niyanju, akọsilẹ meji ninu awọn iwe ti o kọ si wọn wà ninu Bibeli, awọn ni a n pe ni Kọrinti Kin-in-ni ati Ekeji. Bi o tilẹ jẹ pe Paulu ni o dá Ijọ silẹ ni Kọrinti, kò fi ọlá yii fun ara rè̩. O mọ pe awọn miiran pẹlu ṣe iranlọwọ, Ọlọrun ni ọlá ati ogo yii si tọ si. Paulu wi pe, “Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá” (1 Kọrinti 3:6).

Lati Kọrinti ni Paulu gbé báọkọ oju omi lọ si Siria. Nigba ti ọkọ si gunlẹ ni Efesu, boya lẹyin ọjọ mẹjọ tabi mẹsan, ti wọn ti n tu ọkọ loju omi Paulu lọ si ile-isìn awọn Ju lati waasu Ihinrere Jesu fun wọn. Priskilla ati Akuila bá Paulu lọ si Efesu. Awọn ni ọrẹ Onigbagbọ ti Paulu ti n bá gbé. O pe wọn ni “alabaṣiṣẹ mi ninu Kristi Jesu.” O dabi ẹni pe awọn ọmọlẹyin Kristi meji wọnyii ti jọwọ ara wọn patapata fun iṣẹ Oluwa. O ṣeeṣe ki o jẹ pe wọn duro ni Efesu ati pe awọn eniyan n pejọ fun isìn ninu ile wọn (1 Kọrinti 16:19). Lẹyin eyi o ṣeeṣe ki o jẹ pe wọn kuro nibẹ lọ si Romu nibi ti wọn gbe yọọda ile wọn fun isìn (Romu 16:3-5).

Bi Ọlọrun ba Fé̩

Awọn ara Efesu n fé̩ gbọ iwaasu Paulu si i, wọn si bè̩é̩ pe ki o ba wọn gbe diẹ si i. S̩ugbọn Paulu n fé̩ lati wà ni Jerusalẹmu lati ṣe ajọọdún ti o kù si dẹdẹ nibẹ. O ṣeleri pe oun yoo tun pada wá si Efesu bi Ọlọrun ba fé̩. Awa le kọè̩kọ lati ọdọ Paulu: o wi pe, “Bi Ọlọrun ba fẹ.” Paulu kò gbéèto kan kalẹ tabi ki o ṣe ileri lai fi ifẹ Oluwa ati ilana Rè̩ pè, Paulu sọ ohun ti o fara jọ eyi fun awọn ara Kọrinti nigba ti o ni in lọkan lati tun pada sibẹ. O wi pe, “Emi nreti ati duro lọdọ nyin nigba diẹ, bi Oluwa ba fẹ” (1 Kọrinti 16:7). Ninu Episteli Jakọbu a kà pe, “ẹ bá fi wipe, bi Oluwa ba fẹ, awa o wà lāye, a o si ṣe eyi tabi eyini” (Jakọbu 4:15). Ninu è̩kọ miiran a o kọ nipa ipadabọ Paulu si Efesu.

Paulu lọ si Jerusalẹmu. Ibè̩ ni iya-ijọ iṣẹ Ihinrere gbé wà. Paulu ki awọn ọmọ-ẹyin ti o wà ni Ijọ ni Jerusalẹmu. Boya o fun wọn ni iroyin gẹgẹ bi ohun ti oun ati Barnaba ti ṣe ni opin irin-ajo kin-in-ni Paulu fun itankalẹ Ihinrere. “Nwọn rohin gbogbo ohun ti Ọlọrun fi wọn ṣe, ati bi o ti ṣi ilẹkun igbagbọ fun awọn Keferi” (Iṣe Awọn Apọsteli 14:27). Lati Jerusalẹmu, Paulu lọ si Antiọku nibi ti o gbé pari irin-ajo rè̩ keji fun itankalẹ Ihinrere.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Nibo ni ilu Kọrinti wà?

  2. 2 Ki ni ṣe ti Akuila ati Priskilla fi ilu Itali silẹ?

  3. 3 Darukọ awọn ọkunrin meji ti o jé̩ pe iṣẹ agọ-pipa ni wọn n ṣe jẹun.

  4. 4 Ki ni Paulu ṣe nigba ti awọn Ju wà ni odi si ara wọn?

  5. 5 Ta ni Justu i ṣe?

  6. 6 Darukọọkunrin ti o gba Oluwa gbọ pẹlu gbogbo ile rè̩?

  7. 7 Bawo ni Paulu ti pẹ to ni Kọrinti?

  8. 8 Iran wo ni Ọlọrun fi han Paulu nigba ti o wà ni Kọrinti?

  9. 9 Ki ni ṣe ti Paulu fi fé̩ lọ si Jerusalẹmu?

  10. 10 Nibo ni Paulu pari irin-ajo rè̩ keji fun itankalẹ Ihinrere si?