Iṣe Awọn Apọsteli 18:24-28; 1 Kọrinti 1:11, 12; 3:4-9

Lesson 337 - Junior

Memory Verse
“Bḝli awa, ti a jé̩ pipọ, a jé̩ ara kan ninu Kristi, ati olukuluku è̩ya ara ọmọnikeji rè̩” (Romu 12:5).
Notes

A fi Apollo hàn

Ni akoko ti Paulu wà ni Jerusalẹmu, Apollo, ojiṣẹỌlọrun lati Alẹksandria, ti Egipti bẹ awọn ijọ ti o wà ni Efesu wo. Oun kò i ti di ọmọlẹyin Jesu; iwaasu rè̩ lakọkọ kò dabi iwaasu Paulu, Peteru, Barnaba, ati awọn Onigbagbọ miiran ti o ti n waasu ni Efesu. Ju ni Apollo i ṣe o si mọ Iwe Mimọ daradara; ṣugbọn oun ki i waasu bi ti awọn Farisi, tabi awọn olusin gẹgẹ bi igbekalẹ awon Ju ti wọn fi dan dan lé e pe Ofin nikan ni a gbọdọ waasu. Apollo ti gbọ iwaasu Johannu Baptisti, o si gba ohun ti o gbọ lẹnu rè̩ gbọ.

Johannu ti waasu pe: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dè̩dè̩” (Matteu 3:2). Apollo ti kẹkọọ pé Messia n bọ wá; lai si aniani, o ti kà lati inu asọtẹlẹ Isaiah pe Johannu Baptisti yoo wá gẹgẹ bi “ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, ẹ tún ọna Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ ni aginjù fun Ọlọrun wa.” Nigba ti Apollo gbọ iwaasu Johannu, o gbàá gbọ.

O ṣeeṣe ki Apollo wà ni Egipti ni akoko ti Jesu n ṣe iṣẹ-iranṣẹ Rè̩, ki o má tilẹ gbọ rara pe Jesu ti dé gẹgẹ bi Messia, ati pe a ti kan An mọ agbelebu, O si ti jinde. Iroyin ki i tete tàn kaakiri ni ọjọ wọnni gẹgẹ bi o ti ri lọjọ oni. Awọn Ju ti i ṣe ọta Kristi kò tilẹ fé̩ ki ihin naa tàn kaakiri rara.

A kọ Apollo Dajudaju

Akuila ati Priskilla, awọn ẹni ti o ti n bá Paulu ṣiṣẹ pọ, ti o si wà ni Efesu gbadun iwaasu Apollo. O jẹ “ẹniti o gboná li ọkàn,” ti “o nfi āyan nsọrọ, o si nkọni ni nkan ti Oluwa.” O n waasu ohun gbogbo ti o mọ, kò si sọ ohun ti o lodi si ohun ti Paulu ti waasu rè̩. S̩ugbọn oun kò mọ pe ohun nla ti oun n sọ wi pe yoo ṣẹlẹ lai pẹ ti ṣẹlẹ sẹyin. Jesu ti wá, O ti kú, O si ti jinde kuro ninu okú.

Akuila ati Priskilla mu un lọ si ile wọn, wọn si bẹrẹ si sọ “ọna Ọlọrun fun u dajudaju.” Lai si aniani, wọn sọ ohun ti Paulu ti waasu fun un, ani wi pe Kristi ti kú lori igi agbelebu gẹgẹ bi etutu fun è̩ṣẹ, O si jinde pẹlu, lati fi hàn pe ỌmọỌlọrun ni I ṣe. Ibikibi ti Paulu ba lọ, o n waasu Olugbala ti O ti jinde ti O si lagbara lati fọ itẹgun è̩ṣẹ ati lati gba gbogbo awọn ti o ba ke pe E pẹlu igbagbọ ati ironupiwada là.

A Gba Itan naa gbọ

Bi o tilẹ jẹ pe oniwaasu pataki ni Apollo i ṣe, boya ẹni ti ọpọlọpọ eniyan n tọ lẹyin ni oun i ṣe pẹlu, tayọtayọ ni o fi tẹti lelẹ lati gbọ itàn iyanu ti Akuila ati Priskilla n sọ. Apàgọ ni wọn, ṣugbọn o mọ pe wọn ni ọrọ iye, o si gba a gbọ. Ẹni ti n fẹ otitọ tọkàntọkàn kò fẹ mọẹni ti o waasu Jesu fun un. Ọdọmọde ti o ni igbala le sọ itàn yii pẹlu irú idaniloju kan naa ti agbalagba le fi sọọ. Iwọ ha ranti ẹrubinrin nì ti o sọ fun Naamani adẹtẹ nipa wolii ti ó wà ni Israẹli. Ọmọde kekere ni oun i ṣe, o si tun jé̩ẹrú pẹlu, ṣugbọn o mọ agbára Ọlọrun Israẹli, è̩ru kò si ba a lati sọ nipa Rè̩.

Apollo rin Irin-ajo

Lẹyin ti a ti ṣe ọpọlọpọ ipade ni Efesu, Apollo lọ si Akaia lati waasu, awọn Onigbagbọ kọwe pe Apollo n waasu otitọ kan naa ti Paulu ti fi kọ wọn. Ọlọrun ni o fi iṣẹ naa le Paulu lọwọ.

Bawo ni o ti ùn tó pe Apollo lo è̩bun ọrọ sisọ ti o ni fun ogo Ọlọrun! O mọ Iwe Mimọ pẹlu, nitori eyi, o le fi yé awọn eniyan dajudaju pe Jesu ni i ṣe Kristi ni tootọ. Ẹmi Mimọ mu awọn è̩kọ ti o ti kọ tẹlẹ wá si iranti rè̩ lati fi imuṣẹỌrọỌlọrun hàn fun un.

Ariyanjiyan

Apollo waasu ni Kọrinti, ilu miiran nibi ti Paulu Apọsteli paapaa gbé ti waasu. Awọn eniyan gbàọrọ rè̩ gbọ wọn si fẹran rè̩ nitori otitọ ti o n sọ. S̩ugbọn rogbodiyan bé̩ silè̩ nitori pe awọn kan fé̩ Paulu ju Apollo, ijọ si pin si meji.

Paulu kọwe si ijọ Kọrinti, o si jẹ ki wọn mọ pé wọn n ṣe ohun ti kò tọ. Ihin Jesu ni wọn ni lati feti si ki wọn si fi sọkàn, dipo ki wọn gbe oniwaasu ka iwaju wọn.

Paulu kò wa ojurere fun ara rè̩. Jesu ni o n gbega nigba gbogbo; o tilẹ n fẹ ki oun di ẹni ifibu ki awọn Ju sa ti ri igbalà. O sọ fun awọn ara Kọrinti pe: “Emi Paulu tikarami fi inu tutù ati ìwa pẹlẹ Kristi bè̩ nyin, emi ẹni irẹlẹ loju nyin nigbati mo wà larin nyin, ṣugbọn nigbati emi kò si, mo di ẹni igboiya si nyin. S̩ugbọn emi bè̩ nyin pe ki o máṣe nigbati mo wà larin nyin ni mo fi igboiya han” (2 Kọrinti 10:1, 2). O n sọrọ pẹlu “igboiya,” nigba ti Apollo jé̩ olohun-iyọ, ṣugbọn o ni agbára Ọlọrun, Ọlọrun si lo iṣẹ-iranṣẹ rè̩ fun igbalàọpọọkàn.

Kò si iwe miiran laye yii ti o tá awọn iwe ti Paulu apọsteli kọ yọ. Ọlọrun lo o nitori ti o rẹ ara rè̩ silẹ ati pe o fi ogo fun Ọlọrun fun ohun gbogbo ti o ṣẹlẹ ninu iṣẹ-iranṣẹ rè̩.

Paulu bere pe, “Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹẹniti ẹnyin ti gbagbọ, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun” (1 Kọrinti 3:5). Agbọrọsọ lasan ni wọn jé̩ fun Ẹmi Mimọ. Wọn sọỌrọ ti Ọlọrun fi rán wọn. Ẹnikẹni ki yoo ri igbala nipasẹ iwaasu Paulu tabi Apollo bi Ẹmi Ọlọrun kò ba fi òye è̩ṣẹ yé wọn. “Ẹmi ni isọni di āye; ara kò ni ère kan” (Johannu 6:63).

Igbala Nipasẹ Orukọ Jesu

“Kò si orukọ miran labẹọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:12). Gbogbo iwaasu awọn Onigbagbọ duro lori otitọ yii pe, Ọlọrun ni Kristi i ṣe. Kò ni si agbára ninu orukọ yii yatọ si ti ẹnikẹni ninu awọn wolii tabi oniwaasu pataki miiran bi Jesu ki i báṣe ỌmọỌlọrun. Paulu wi pe, “Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwāsu wa” (1 Kọrinti 15:14). Eyi ni pé, bi Jesu ki i báṣe ỌmọỌlọrun, kòṣanfaani lati maa waasu igbagbọ ninu Kristi. S̩ugbọn Kristi jinde kuro ninu okú ninu ara ologo, ati pe a o sọ ara gbogbo awọn Onigbagbọ tootọ ti o kú ninu igbagbọ di aaye lati “bá ara ogo rè̩ mu.”

Paulu sọ fun awọn ara Romu pe Jesu jẹẹniti a pinnu Rè̩ “lati jẹ pẹlu agbara ỌmọỌlọrun, gẹgẹ bi Ẹmi iwa mimọ, nipa ajinde kuro ninu okú” (Romu 1:4). O fi hàn pe Ọlọrun paapaa ni Oun i ṣe nipa fifi Ẹmi Rè̩ lelẹ, lẹyin naa O si tún gbàá pada – ohun ti wolii, alufaa tabi ọba aye yii kan kò le ṣe.

Paulu, Apollo ati Peteru (ẹniti a pe ni Kefa nihin yii) waasu è̩kọ ipilẹṣẹ Ihinrere, tayọtayọ ni awọn eniyan si fi n gbọọrọ wọn gẹgẹ bi wọn ti n waasu ọrọ naa, olukuluku ni ọna tirẹ. Gbogbo iwaasu wọn ni lati gbé Ijọ ró. Wọn n fẹ ran awọn eniyan lọwọ ki wọn le wà ni imurasilẹ lati pade Jesu, wọn kò si waasu lati gba ogo fun ara wọn.

Iṣẹ Wà fun Gbogbo Wa

Afo wà fun olukuluku iranṣẹ Oluwa lati di, kò si eredi ti ẹnikan yoo fi jowu ẹnikeji. (Lai si aniani, bi owu-jijẹ ba wà rara, Ẹmi Ọlọrun ti fi ẹni naa silẹ.) Opin kan naa ni gbogbo awọn iranṣẹỌlọrun n lepa. Ẹnikan n funrugbin Ihinrere, ẹlomiran si wá, o n bu omi rìn irugbin naa nipa ìwaasu rè̩. Bi ọjọ ti n gori ọjọ, èpo le ti hù saarin irugbin naa, o si yẹ ki a faa tu. O ṣeeṣe ki o jẹ pe iwaasu alufaa miiran ni yoo fi ibi ti “èpo” ti o yẹ ki a fa tu naa gbe wà ninu igbesi-ayé oluwarè̩ hàn. Niwọn-igbati alufaa naa ba n waasu gbogbo ỌrọỌlọrun, ti o si n gbé igbesi-ayé ohun ti o n waasu, lai yọ kuro ninu rè̩, ti kò si gbọjè̩gé̩ nipa otitọ, iranṣẹ Oluwa ni ẹni naa i ṣe, o si yẹ ki a gbọ tirè̩ ki a si fara mọ iṣẹ-iranṣẹ rè̩, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni Apollo?

  2. 2 Nibo ni Apollo ti wá?

  3. 3 Bawo ni o ṣe waasu ni Efesu?

  4. 4 Ki ni Akuila ati Priskilla sọ fun Apollo?

  5. 5 Ki ni ede-aiyedè ti o ṣẹlẹ ni Kọrinti?

  6. 6 Ki ni Paulu sọ ninu iwe rè̩ si awọn ara Kọrinti nipa ara rè̩ ati iṣẹ-iranṣẹ Apollo?

  7. 7 Ki ni kokó iwaasu Paulu ati Apollo?