Iṣe Awọn Apọsteli 19:1-20

Lesson 338 - Junior

Memory Verse
“Ibukún ni fun awọn enia na, ti ẹniti Ọlọrun OLUWA iṣe” (Orin Dafidi 144:15).
Notes

Paulu Sọ nipaẸmi Mimọ

Paulu Apọsteli bẹ Efesu wò nigba ti o n ti Kọrinti lọ si Jerusalẹmu ninu irin-ajo rè̩ keji lati tan Ihinrere kalẹ. O ti waasu fun awọn Ju ninu sinagọgu wọn fun igba diẹ, wọn si gba ọrọ iwaasu rè̩, wọn tilẹ fẹ ki o duro pẹ diẹ lọdọ wọn. S̩ugbọn oun kò le duro nigba naa, ṣugbọn ni akoko yii, ninu irin-ajo rè̩ kẹta lati tan Ihinrere kalẹ, o wá si Efesu lati wà nibẹ fun iwọn igba diẹ.

Paulu ri awọn ọmọ-ẹyin kan ni Efesu awọn ẹni ti o gbagbọ tọkàntọkàn ti wọn si n tẹle gbogbo è̩kọ ti wọn ti gbọ, nitori naa o bi wọn leere bi wọn ti gbàẸmi Mimọ. Wọn kò tilẹ loye ohun ti o n sọ rára. Wọn dahun pe, “Awa kò gbọ rara bi Ẹmi Mimọ kan wà.”

S̩isẹ N Tẹle

Nigba ti eniyan báṣẹṣẹ ni igbala, inu rè̩ yoo dùn pupọ to bẹẹ ti kò ni ranti fun iwọn igba diẹ pe ohun kan tun wà lati beere lọwọỌlọrun. S̩ugbọn bi o ba ṣe diẹ si i, oungbẹ kan yoo wọọkàn rè̩ lati tubọ tè̩ siwaju. Bi o ti n gbadura ti o si n fi ara rè̩ rubọ fun Ọlọrun, ti o si gbagbọ lati ni isọdimimọ, Ọlọrun yoo tun fi ayọ kun ọkàn rè̩ nipa fi fun un ni iriri miiran. Wo bi ọkàn rè̩ yoo ti jé̩ mimọ laulau! Wo bi alaafia yoo ti kun ọkàn rè̩ pọ tó! Ọlọrun ti fun un ni ifẹ! Nipa iriri yii a fun un ni agbára ti o tobi ju ti akọkọ lọ lati rọ mọ igbagbọ ti Ọlọrun ti fi fun un, ati lati bori è̩ṣẹ. A tu gbongbo è̩ṣẹ kuro.

Ẹnikẹni ti o bá n fẹ ohun ti o dara jù lọ lọwọỌlọrun ni anfaani lati tè̩ siwaju si i. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ki O to lọ pe ki wọn duro ni Jerusalẹmu titi wọn yoo fi gba ileri Baba, eyi ti i ṣe agbára Ẹmi Mimọ. Jesu ti gbadura fun isọdimimọ wọn, O si ti míẸmi Mimọ si wọn (Johannu 20:22), ṣugbọn wọn ni lati gba agbára Ẹmi Mimọ. Ohun kan ti o tobi ju eyi lọ si tun wà fun wọn. “A o fi Ẹmi Mimọ baptisi nyin, ki iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:5).

Agbara fun Isin

Iṣẹ pupọ ni o wà fun awọn ọmọlẹyin Jesu lati ṣe ni titan Ihinrere kalẹ. Wọn ni lati ni iranwọ lati Ọrun. Jesu wi pe “Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Agbara yii ni olukuluku ọkàn ti n fẹṣiṣẹ fun Oluwa ni lati ni.

A ko gbà wa là lati joko ki a si maa jẹ igbadun alaafia ati irọra ati itunu. Ibukun Oluwa jẹ iyanu, O si n fẹ ki a layọ: ṣugbọn kò si ẹni ti o ni ayọ bi ti ẹni ti n ṣe iṣẹ-iranṣẹ fun awọn ẹlomiran. A fun wa ni ibukun ki a ba le jẹ ibukun fun ẹlomiran. Ileri Rè̩ lati wà pẹlu wa jẹ ti awọn ti yoo jade fun Un. “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ède gbogbo, ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye” (Matteu 28:19, 20).

Eyi ni Paulu n sọrọ nipa rè̩ fun awọn ara Efesu. Njẹ wọn ha ti ni iriri ologo yii ti yoo fun wọn ni agbára lati jẹẹlẹri ni gbogbo ayé? Wọn ha ti ni Olutunu nì ninu igbesi-ayé wọn gẹgẹ bi Jesu ti ṣeleri? Wọn ko tilẹ mọ rara pe wọn le ni irú ibukun nla bayi lati ọdọỌlọrun!

Iribọmi

Paulu tun beere ibeere miiran. Bi awọn ara Efesu kò ba ti gbọ nipa Ẹmi Mimọ, njẹ ilana wo ni wọn ha tẹle nigba ti a ri wọn bọ omi? Aṣẹ ti Jesu pa nipa iribọmi ni pe ki a ri wọn bọmi “li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19). Bi a ba ti ri wọn bọmi li ọna bayi wọn i ba ti mọ pe Ẹmi Mimọ wà.

Awọn ara Efesu dahun pe a baptisi wọn si baptismu ti Johannu. Diẹ kiun ni a mọ nipa iribọmi ti Johannu; ṣugbọn a mọ pe iṣẹ Johannu ni lati pese ọkàn awọn eniyan silẹ fun bibọ Jesu. Ohun ti o n kede ni pe: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dè̩dè̩.” Ọpọlọpọ awọn eniyan ni o tọ Johannu lọ lati gbọọrọ rè̩, awọn miiran tilẹ rò pe oun ni Messia. S̩ugbọn Johannu dahun pe: “Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọju mi lọ mbọ lẹhin mi, bàta ẹniti emi ko to gbé; on ni yio fi Ẹmi Mimọ ati iná baptisi nyin” (Matteu 3:11). Nitori naa iribọmi ti Johannu kò tó.

Nigba ti Jesu pari iṣẹ irapada ti O wa ṣe laye ti O si pada lọ si Ọrun, igba titun dé. Nigba ti awọn ọgọfa eniyan ni yara oke gba agbára Ẹmi Mimọ ni ọjọ kẹwaa lẹyin ti Jesu goke re Ọrun, ni igba ti Ẹmi Mimọ ti bẹrè̩.

Fun awọn ti o Jinna rere

Ki i ṣe iba awọn eniyan ti o gba agbára Ẹmi Mimọ ni ọjọ naa nikan ni gbigba agbára Ẹmi Mimọ pin si. A ti kọè̩kọ nipa awọn Keferi ti o gba agbára Ẹmi Mimọ ni ọdun diẹ lẹyin ọjọ Pẹntekọsti (Ẹkọ 290, 304). Ọdun kẹtalelogun lẹyin ọjọ Pẹntekọsti ni akoko ti Paulu lọ lati bẹ Efesu wò yii, awọn ọkunrin mejila ninu wọn ni o si gbàẸmi Mimọ. Peteru Apọsteli ti wi pe: “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39). Awa naa wa lara awọn wọnni ti o “jina rére,” awa naa pẹlu yoo ri agbára Ẹmi Mimọ gbà bi a ba le ṣe ohun ti Ọlọrun beere lọwọ wa.

Nigba ti awọn mejila wọnyi gba Ẹmi Mimọ, wọn fi ède miiran sọrọ, ède ti awọn tikara wọn ko mọ gẹgẹ bi o ti ri fun awọn ọgọfa (120) wọnni ti o fi ède miiran sọrọ ni ọjọ Pẹntekọsti. Eyi jé̩ ami ti Ọlọrun maa n fi fun olukuluku ẹni ti o ba gba Ẹmi Mimọ.

Paulu kò gbà pe iṣẹ rè̩ ti pari nigba ti awọn eniyan mejila gba Ẹmi Mimọ. O n wọ sinagọgu lọ sibẹ lati waasu nipa Jesu ki awọn ẹlomiran le gbagbọ ki wọn si gba è̩bun Ọlọrun. S̩ugbọn bi o ti maa n ri, nibikibi ti a ba gbe n waasu Ihinrere, awọn miiran kò gbagbọ, wọn si da wahala silẹ. Paulu mọ pe kòṣanfaani rara lati maa bá awọn eniyan ti ko fẹ gbagbọ jiyan; nitori naa o ko awọn ọmọ-ẹyin rè̩, awọn wọnni ti wọn gba è̩kọ Jesu gbọ, wọn si bẹrẹ si ṣe ipade ninu ile-iwe kan nibi ti kò ni si darudapọ ati ariyànjiyàn awọn alaigbagbọ. Odidi ọdun meji ni o fi wà pẹlu awọn ọmọ-ẹyin wọnyi, titi gbogbo awọn eniyan ti o wà ni ilu ti o wà ni ayika wọn, Ju ati Helleni, fi gbọ nipa Jesu Oluwa.

Iwosan Nipa Agbára Ọlọrun

Nigba ti Paulu waasu Jesu, ko waasu lori igbala, isọdimimọ ati ifi Ẹmi Mimọ wọ ni nikan, ṣugbọn o waasu lori iwosan nipa agbára Ọlọrun pẹlu. Ki i ṣe pe Paulu n waasu rè̩ nikan, o gbagbọ pe Ọlọrun yoo dahun adura oun nigba ti oun ba gbadura fun awọn eniyan. Ọlọrun ṣe ọpọlọpọ iṣẹ-iyanu nla nitori pe Paulu gbagbọ.

Akoko yii ni fifi aṣọ ilewọ kékèké ti a ti ta ororo si ti awọn ojiṣẹỌlọrun si ti gbadura le lori ranṣẹ fun iwosan alaisan ti bẹrẹ. A fi aṣọ ilewọ kékèké ati ibanté̩ Paulu ranṣẹ si awọn alaisan ti o wà lọna jinjin rére ati awọn wọnni ti ẹmi aimọ n dá lorò pẹlu. Ọlọrun a si wò wọn sàn. Ọlọrun n gbọ O si n dahun adura igbagbọ lọjọ oni fun imularada awọn alaisan, ọpọlọpọ eniyan si ti ri ọwọ iwosan Ọlọrun lara wọn nigba ti wọn ba fi aṣọ ilewọ kékèké ti a ti ta ororo si ti a si gbadura si le ara wọn.

Awọn ẹmi eṣu gbagbọ

Awọn Ju kan wà ni Efesu ti o fẹ le ẹmi èṣu jade lọna adabọwọ ti ara wọn. O fara jọ isin awọn olusin ẹmi-èṣu ti ode-oni. Lẹyin ti wọn ti gbọ ti Paulu fi orukọ Jesu le ẹmi èṣu jade, awọn naa dawọ lee lati ṣe bẹẹ pẹlu. S̩ugbọn wọn ko i ti ni idande nipa Ẹjẹ Jesu, nitori naa wọn ko ni ẹtọ lati fi orukọ Jesu ṣe iṣẹ-iyanu. Awọn ẹmi èṣu mọ Jesu. Jakọbu sọ bayi nigba kan wi pe: “Iwọ gbagbọ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; o dara: awọn ẹmi èṣu pẹlu gbagbọ, nwọn si wariri” (Jakọbu 2:19). Eyi tayọ igbagbọ awọn ẹlomiran.

Ẹmi èṣu ti o wà ninu ọkunrin ti awọn Ju buburu wọnyi n fẹ mu larada wi pe, “Jesu emi mọ, Paulu emi si mọṣugbọn tali ẹnyin?” Ọkunrin ti o ni ẹmi èṣu na fò mọ awọn Ju buburu wọnyi, wọn si sá jade kuro ni ile naa ni ihoho ati ni ifarapa.

Nigba ti awọn eniyan gbọ ohun ti o ṣẹlẹ, è̩ru ba wọn, wọn si n fẹ mọ si i nipa Jesu. Ọpọ ninu wọn ni igbalà, wọn si kò awọn iwe iṣe-ajẹ wọn wá, wọn si daná sun wọn loju gbogbo eniyan. Ohun ribiribi ni fun wọn lati kó awọn oògùn wọn ati awọn nnkan miiran ti wọn n lo ninu isin ẹmi eṣu wọn danu. Wọn ni ero pe wọn ni lati tẹle gbogbo ilana eto ẹsin wọn ki wọn le ẹmi èṣu jinna si wọn, gẹgẹ bi ọpọlọpọ eniyan ti o ni igbagbọ ninu itan atọwọdọwọ awọn keferi ti n ṣe lọjọ oni. S̩ugbọn Ihinrere Jesu Kristi lagbara ju Satani lọ. Nigbakuugba ti awọn ti n sin Satani ba gboju soke si Jesu pẹlu igbagbọ, ti wọn ba si jẹ ki O gba ọkàn wọn là, agbára èṣu yoo dofo. Ẹmi èṣu kò ni lagbara lori wọn mọ, wọn yoo si layọ. Isin ẹmi èṣu ki i fun eniyan layọ, ṣugbọn Ihinrere Jesu Kristi maa n fun ni layọ.

Ihin Ayọ

Itumọ Ihinrere ni “ihin ayọ.” Nigba ti angẹli nì kede ibi Jesu, o wi pe, “Má bè̩ru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo” (Luku 2:10). Nigba ti Woli Joẹli n sọ nipa ti igbàẸmi Mimọ, o wi pe, “Má bè̩ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ” (Joẹli 2:21). Nigba ti Jesu fi itọni lé awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lọwọ, O wi pe, Alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn” (Johannu 13:17).

“Bḝli ọrọ Oluwa si gbilẹ si i gidigidi, o si gbilẹ,” labẹ iwaasu Paulu. Nibikibi ti a ba gbe gbéỌrọỌlọrun ga, Ọlọrun yoo ṣiṣẹ igbalàọkàn. ỌrọỌlọrun sọ nipa Jesu wi pe, “Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi” (Johannu 12:32).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Nibo ni Paulu lọ nigba ti o bẹrẹ irin-ajo rè̩ kẹta lati tan Ihinrere kalẹ?

  2. 2 Bawo ni o ti pé̩ tó ni bè̩?

  3. 3 Awọn ibeere wo ni o beere lọwọ awọn ara Efesu?

  4. 4 Ki ni isọdimimọ n ṣe fun eniyan?

  5. 5 Ki ni a maa n ri gbà lẹyin ti a bá ti gba agbara Ẹmi Mimọ?

  6. 6 Ki ni Jesu ṣeleri fun awọn ẹni ti yoo lọ si gbogbo agbaaye lati lọ waasu Ihinrere?

  7. 7 Awọn wo ni Peteru sọ pe a rán Ẹmi Mimọ si?

  8. 8 Igba meloo ni a ri akọsilẹ ninu Iwe Mimọ pe a fi Ẹmi Mimọ fun ni lẹyin ọjọ Pẹntekọsti?

  9. 9 Ki ni o ṣẹlẹ ni akoko iṣẹ-iranṣẹ Paulu ni Efesu nipa iwosan nipa agbára Ọlọrun ati lile ẹmi èṣu jade?

  10. 10 Ki ni ẹmi èṣu naa sọ fun awọn Ju buburu wọnni?