2 Kronika 29:1-36

Lesson 339 - Junior

Memory Verse
“Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo” (Orin Dafidi 106:3).
Notes

Ipo Buburu ti Juda Wa

Ahasi Ọba ti fi ijọba Juda si ipo ibanujẹ. O gbe isìn ibọriṣa kalẹ; kò si si igba kan ninu gbogbo akoko ti o fi jọba ti o ṣe ohun rere kan ti o le mu ibukún wa sori awọn eniyan ti o wa labẹ ijọba rè̩. Nitori è̩ṣẹ rè̩ ati nitori è̩ṣẹ awọn eniyan rè̩, Ọlọrun mu ki awọn orilẹ-ède miiran bori wọn. Ni akoko kan awon ọmọ-ogun Israẹli pa iwọn ọkẹ mẹfa (120,000) ọkunrin Juda ninu ogun, wọn si kóọkẹ mẹwaa (200,000) obinrin ati ọmọde ni igbekun. Lẹyin eyi, awọn ara Edomu tun kó awọn ara Juda ni igbèkun. Awọn Filistini pẹlu si gba ọpọlọpọ ninu ilẹ Juda wọn si n gbe ibẹ. Gbogbo wahala yii de ba Juda nitori ti Ahasi ọba mu awọn eniyan wọnyi dè̩ṣẹ.

Ipọnju de ba awọn eniyan wọnyi nitori pe wọn ti kẹyin si Ọlọrun. A kà ninu Iwe Owe pe: “Oye rere fi ojurere fun ni; ṣugbọn ọna awọn olurekọja ṣoro” (Owe 13:15). Wolii Isaiah sọ bayi pe: “Alafia kò si fun awọn enia buburu, li OLUWA wi” (Isaiah 48:22). Kò si alaafia tootọ ninu ayé fun awọn ti o kọ Oluwa silẹ.

Ọlọrun ti ṣeleri pe bi eniyan ba ke pe Oun nigba ipọnju, Oun yoo gbà wọn, Oun yoo sọ ibanujẹ wọn di orin ayọ. Oun yoo gbà wọn kuro ninu ipọnju, yoo si fun wọn layọ. S̩ugbọn wọn ni lati tọỌ wa pẹlu ironupiwada, wọn ni lati kẹdun pe wọn ti dè̩ṣẹ si I ati pe wọn ti ṣe tan lati kọè̩ṣẹ wọn silẹ.

Ibẹrẹ Ijọba Hẹsekiah

Ahasi ọba ni ọmọkunrin kan ti a n pe ni Hẹsekiah, ẹni ti kò dabi baba rè̩ rara. Nigba ti Hẹsekiah di ọba, o n fẹ ni ibukun ti i ṣe ti awọn ti n sin Ọlorun, o si n fẹ ki awọn eniyan rè̩ ni alaafia. Ẹni ọdun mẹẹdọgbọn pere ni nigba ti o jọba, ṣugbọn o ti mọ riri isin Ọlọrun. O ṣe eyi ti o tọ loju Oluwa, gẹgẹ bi Dafidi Ọba rere ti ṣe.

A kò mọ bi Hẹsekiah ṣe ni imọ nipa Ọlọrun nigba ti gbogbo eniyan, ati baba rè̩ paapaa, jé̩ abọriṣa, ti wọn tilẹ n fi ọmọ wọn paapaa rúẹbọ sisun si oriṣa. O le jẹ pe o ti kà Iwe Ofin ti ọba kọọkan ni lati ni ni arọwọto rè̩ ti o si ni lati fi ọwọ ara rè̩ kọè̩dà rè̩. Ki a ma fa ọrọ gùn, o ni imọỌlọrun, ọkàn rè̩ n fẹ lati ṣe ohun ti o tọ ati lati sin gẹgẹ bi Ọlọrun ti fi lelẹ.

Ni ọdun kin-in-ni ijọba Hẹsekiah, o bè̩rẹ si i ṣe ayipada nipa titún ile Oluwa ṣe. Ni gbogbo ọdun mẹrindinlogun ti baba rè̩ fi jọba, awọn eniyan kò lọ si ile Ọlọrun rara bẹẹni wọn kò bikita fun awọn ohun ti i ṣe ti Ọlọrun. Iwọ naa gba eyiro bi Tẹmpili yoo ti kun fun eeri tó ti yoo si bajẹ to ni gbogbo akoko yii. Ahasi Ọba tilẹ ti kó pupọ ninu awọn ohun-elo ti a n lò ninu iṣẹ-isin, o ti ké wọn wé̩wẹ; o tilẹ gbéọkan ninu awọn pẹpẹỌlọrun lati lo o fun ibọriṣa, o huwa iwọsi si Ọlọrun lọpọlọpọ.

Kò si Ina

Laaarin gbogbo ọdun wọnyi, iná ti o wà ninu Tẹmpili ti kú. Iwọ ha kọja lara ile-isin kan ti a kò lò mọ ti koriko ti hù ninu ọgba rè̩, ti digi oju ferese rè̩ si ti fọ wé̩wẹ? Iwọ ha ti i kọja lara ile-isin bẹẹ li oru nigba pupọ lai si itanṣan imọlẹ nibẹ rara? Eyi kò ha ba ni ninu jé̩? Iwọ ha woye bi yoo ti buru jai to bi gbogbo ile-isin ba wà lokunkun ti a si ti kọ wọn silẹ patapata?

Awọn eniyan kan wà lọjọ oni ti wọn kò fẹ ki ẹnikẹni ki o sin Ọlọrun rara. Wọn n fẹ lati ti ilẹkun gbogbo ile-isin, ki won si pa gbogbo iná ti o wà nibẹ. Wo bi ayé yoo ti ṣokunkun to bi kò ba si ẹni kan ti n sin Jesu rara! Jesu ni Imọlẹ aye. Jesu mu imọlẹ ati ifẹ wá si ayé. Jesu ni orisun gbogbo ayọ tootọ.

A pe awọn Alufaa ati awọn Ọmọ Lefi

Hẹsekiah ké si awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ki wọn ya ara wọn si mimọ fun iṣẹ-isin Ọlọrun. O ṣeeṣe ki diẹ ninu awọn alufa yii ti maa sin oriṣa pẹlu. Wọn ki yoo le wà ni ipo ti wọn yoo fi le sin Ọlọrun. Nigba ti wọn kó ara wọn jọ, Hẹsekiah sọ nipa iwa buburu awọn baba wọn ati iwa buburu ti o wà ni ilẹ naa. “Awọn baba wa sa ti dẹṣẹ, nwọn si ti ṣe ibi li oju OLUWA Ọlọrun wa.” O fi ye wọn pe eyi ni eredi rè̩ ti ipọnju nla fi de ba wọn. Awọn orilẹ-ède ti o yi wọn ka n yọṣuti si wọn, wọn si n fi wọn ṣe ẹlẹya, ani awọn ti a pe ni eniyan Ọlọrun.

O yẹ ki awa ti a n pe ara wa ni ọmọỌlọrun maa gbé igbesi-ayé iwa-bi-Ọlọrun ki awọn araye le mọ pe awa jẹ ti Ọlọrun nitootọ! Bi wọn ko ba ri ẹwa Jesu ninu wa, awa ki i ṣe ọmọ Rè̩ nigba naa.

Majẹmu Hẹsekiah

Hẹsekiah n fẹ ri oju-rere Ọlọrun, o si ṣetan lati ṣe ohunkohun ti yoo gba a lati ni ibukun Ọlọrun. O ṣetan lati jẹwọè̩ṣẹ rè̩ ati ti awọn eniyan rè̩, o ṣetan lati rubọ ati lati fi ara rè̩ ji fun Oluwa ati lati le ri idariji gbà. O rán awọn ọmọ Lefi leti pe Ọlọrun ti yàn wọn lati ma ṣe iṣẹ iranṣẹ ni Tẹmpili. Awọn ẹya Lefi ni o jade wa si iha ti Oluwa ni akoko ti Aarọni fi yáẹgbọrọ-maluu wura, nigba kin-in-ni ti Israẹli kọ yi pada si ibọriṣa. Lati igba naa ni awọn ọmọ Lefi ti ni àye pataki ninu iṣẹ-isin Ọlọrun; Hẹsekiah si tun n ke si wọn lakoko yii lati dide lati ṣe iranwọ fun Oluwa.

Awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa fara mọ ohun gbogbo ti Hẹsekiah sọ. Wọn kọ wẹ ara wọn mọ; wọn si mu ki ọkàn wọn ṣe deedee pẹlu Ọlọrun, lẹyin naa wọn bẹrẹ si i gbá ile Oluwa.

Nigba ti a ba wá lati sin Ọlọrun, a gbọdọ kọè̩ṣẹ wa silẹ ki a si wè̩ wá mọ kuro ninu ọna buburu wa nipa gbigbadura si Jesu pe ki O mu è̩ṣẹ wa kuro. Nigba ti a ba sin Ọlọrun pẹlu ọkàn mimọ, isin wa ati ọrẹ wa yoo jé̩ itẹwọgba niwaju Ọlọrun.

Ile ti o Mọ

Gbogbo iṣẹ gbigbá ile Oluwa pari ni ọjọ kẹrindinlogun. Awọn ọmọ Lefi wọle tọọba lọ wọn si wi pe: “Awa ti gbá ile OLUWA mọ, ati pẹpẹẹbọ sisun, pẹlu gbogbo ohun-elo rè̩, ati tabili akara-ifihan, pẹlu gbogbo ohun-elo rè̩. Pẹlu-pẹlu gbogbo ohun-elo, ti Ahasi, ọba, ti sọ di alaimọ ninu è̩ṣẹ rè̩, li akokò ijọba rè̩, li awa ti pese ti awa si ti yà si mimọ, si kiyesi i nwọn mbẹ niwaju pẹpẹ OLUWA.”

Eyi ni ohun ti Hẹsekiah fé̩ gbọ. Wo bi inu rè̩ ti dùn toólati ri i pe iṣẹ isin tootọ tun le bẹrẹ lọtun ni ilẹ Juda! Ni kutukutu owurọ o dide o si kó awọn alaṣẹ ilu jọ, o si lọ si ile Oluwa. Nibẹ ni awọn alufaa si fi ẹran rubọ nitori è̩ṣẹọba ati ti awọn eniyan naa, gẹgẹ bi ilana Ofin Mose.

Orin Iyin

Idile kan wà laaarin awọn ọmọ Lefi ti a ti yàn lati jé̩ alo-ohun-elo-orin ati akọrin ninu Tẹmpili. Awọn pẹlu ti mura tan lati ṣe ipa ti wọn ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. “Nigbati ẹbọ sisun na si bè̩rẹ, orin OLUWA bè̩rẹ pẹlu ipè ati pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ọba Israẹli.” Gbogbo ijọ eniyan naa si wolẹ sin, awọn akọrin, n kọrin, ipè si n dún: nnkan wọnyi si n lọ bẹẹ titi ẹbọ sisun naa fi pari. A kà ninu Majẹmu Titun pe, “Ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mā fi ibere nyin hàn fun Ọlọrun” (Filippi 4:6).

Wo bi ayọ ti pọ to ni ọkan awọn eniyan naa! Lẹẹkan si i wọn tun le kọrin. Lọjọ oni isin Igbagbọ nikan ṣoṣo ni isin ti a ti maa n kọrin. Awọn ẹsin miiran le ni orin arò ati ègbè wọn ti o dà bi orin ọfọ, ṣugbọn fifi ayọ ati inu didun kọrin jẹ ami kan ti a fi n mọ Onigbagbọ.

Bawo ni inu awọn eniyan Juda wọnyi ti dun to bi wọn ti n kọrin iyin si Ọlọrun Ọrun. Wọn tẹri wọn ba niwaju Rè̩, awọn akọrin wọn “si fi inu-didùn kọrin iyin, nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si sin.” Wo bi ọjọ naa ti jẹọjọ ayọ to ni Juda! A ti yi ọkàn awọn eniyan wọnyi kuro ninu ibọriṣa ati iwa buburu, wọn si ti ri idariji gbà lọdọỌlọrun.

Idupẹ

Nisisiyii ti Ọlọrun ti tú ibukun nlanla yii da sori awọn eniyan yii, wọn ni lati wi pe, “A dupẹỌlọrun.” Nitori naa Hẹsekiah pe awọn alufaa lati mu ọrẹ-ọpẹ, ati ẹbọ-sisun ti iyasi-mimọ wọn wá. Ọpọlọpọẹbọ ni awọn eniyan ti o fi tọkàntọkàn yi pada si Ọlọrun mú wá, to bẹẹ ti awọn alufaa kò tó lati boju to awọn ẹbọ wọnyi. Ki i ṣe gbogbo awọn alufaa ni o ti ya ara wọn si mimọ fun Oluwa. “Awọn ọmọ Lefi ṣe olõtọ li ọkàn jù awọn alufa lọ lati yà ara wọn si mimọ.” Ohun è̩dun ni lati ri i nigba miiran pe awọn eniyan ti o fẹỌlọrun tọkantọkan ti wọn si n fẹ mọ gbogbo ỌrọỌlọrun a saba maa n ni ijatilẹ lọdọ awọn alufaa ti kò waasu gbogbo otitọỌrọỌlọrun ti wọn kò si fi ọwọ danindanin múọran iwa mimọ.

Awọn eniyan ti o layọ ni awọn wọnni ti n ṣiṣẹ fun Ọlọrun pẹlu iṣọkan igbagbọ; ti gbogbo wọn si jumọ n sin Ọlọrun lai jẹ ki ohunkohun ti i ṣe ohun ibajẹ ayé wọ inu igbesi-ayé ati iṣẹ-isin wọn. Ki Ọlọrun ran olukuluku wa lọwọ lati fi ohun mimọ ti Ọlọrun si ipo kin-in-ni ninu igbesi-ayé wa ki a ba le ni idapọ pẹlu Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Iru ọba wo ni Ahasi i ṣe?

  2. 2 Bawo ni Hesekiah ṣe bẹrẹ ijọba rè̩?

  3. 3 Ọmọọdun meloo ni Hẹsekiah nigba ti o bẹrẹ si jọba?

  4. 4 Ki ni ohun kin-in-ni ti awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ṣe lẹyin tiwọn ti ya ara wọn si mimọ?

  5. 5 Sọ nipa isin ti o tẹle gbigbá Tẹmpili?

  6. 6 Ipa wo ni awọn akọrin ati awọn alo-ohun-elo orin kó ninu iṣẹ-isin?

  7. 7 Awọn ẹlẹsin wo ni o maa n kọrin?

  8. 8 Awọn eniyan wo lo ni ayọ?