2 Kronika 30:1-27; 31:1-21

Lesson 340 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA Ọlọrun nyin, oniyọnu ati alānu ni, ki yio si yi oju rè̩ pada kuro lọdọ nyin, bi ẹnyin ba pada sọdọ rè̩” ( 2 Kronika 30:9).
Cross References

I Ikede Hẹsekiah nipa Ajọ Irekọja

1 Lẹyin yíyà ile Oluwa si mimọ, Hẹsekiah pàṣẹ pe ki wọn pa Ajọ Irekọja mọ, 2 Kronika 30:1, 5; Ẹksodu 12:1-14; Lefitiku 23:5

2 Nitori pe awọn alufaa ati awọn eniyan ko ti i ya ara wọn si mimọ gẹgẹ bi ilana Ofin, wọn pa Ase Irekọja mọ ni oṣu keji dipo oṣu kin-in-ni, 2 Kronika 30:2-4; 29:17, 34; Numeri 9:6-14

3 Fun igba pipẹ ni a ti ṣe alai pa Ajọ Irekọja mọ, 2 Kronika 30:5; 28:1-4; 1 Awọn Ọba 12:26-28

4 A rán awọn ikọ lati yara sare lọ kede ni gbogbo ilu Juda ati Israẹli, 2 Kronika 30:6-9

5 Awọn miiran ninu awọn Ọmọ Israẹli yọṣuti si iṣẹ ti a rán si wọn lati gbà wọn ni iyanju si iwa-bi-Ọlọrun, 2 Kronika 30:10; 36:14-16; Nehemiah 4:1-3; Sekariah 14:16-18

6 Ọpọlọpọ eniyan feti si ikede naa, wọn si wá lati ibi gbogbo ninu ijọba mejeeji ni igbọran si aṣẹỌlọrun, 2 Kronika 30:11, 12

II Pipa AjọIrekọja Mọ

1 Awọn eniyan mú ibọriṣa kuro patapata, 2 Kronika 30:13, 14

2 Itara awọn eniyan rú ifẹ awọn alufaa soke, wọn si ṣe Ajọ Irekọja gẹgẹ bi ilana Ofin, 2 Kronika 30:15, 16

3 Hẹsekiah bẹbẹ fun aanu Ọlọrun lori awọn olusin tootọ ti kò le mu gbogbo ilana Ofin ṣẹ, 2 Kronika 30:17-20; 1 Samuẹli 16:7; 1 Kronika 28:9; Isaiah 1:10-20

4 A fa akoko ajọ aiwukara gùn nitori ọpọ ibukun ti o ti ọdọỌlọrun wá, 2 Kronika 30:21-23; Ẹksodu 12:15-20; 13:6-10; Lefitiku 23:5-8

III Erè Igbọran si Ofin Ọlọrun

1 Ọba gba awọn ọmọ Lefi ni iyanju ninu iṣẹ-isin wọn si Ọlọrun, o si fi ohun ini rè̩ ta wọn lọrẹ lati mú ki wọn ma a ba ase ati ẹbọ ti wọn n ṣe lọ siwaju si i, 2 Kronika 30:22-24

2 Ayọ ati àriya nla ni o wà ni Jerusalẹmu, 2 Kronika 30:25-27

3 Lẹyin Ase Irekọja awọn eniyan pada si ilu wọn; wọn si pa ibi ibọriṣa gbogbo run, 2 Kronika 31:1

4 Hẹsekiah mu apakan iṣẹ-isin Ọlọrun ti a ti ṣá ti pada bọ sipò, 2 Kronika 31:2-19; Numeri 18:8-32

5 O dara fun Hẹsekiah nitori irúìhà ti o kọ si Ofin Ọlọrun, 2 Kronika 31:20, 21; 29:2, 10, 11

Notes
ALAYE

Hẹsekiah, Olumu Isin Ọlọrun BọSipò

Lẹsẹkẹsẹ ti Hẹsekiah jọba ni Juda, o tara ṣàṣà lati tún fi idi isin Ọlọrun tootọ múlè̩. Ni oṣu kin-in-ni ijọba rè̩ o ṣilẹkun Ile Ọlọrun, o si gba awọn Ọmọ Lefi ati awọn alufaa niyanju lati tún ya ara wọn si mimọ fun isin ti Ọlọrun ti pè wọn si.

Ajọ Irekọja

“Gba ti Israẹli wa nilẹ Egipti,

Jẹki awọn eniyan mi lọ.

A ni wọn lara tobẹ, ti ẹsẹ kún wọn,

Jẹki awọn eniyan mi lọ.”

Eyi ni ibẹrẹ orin ọkan ninu awọn orin ilẹ wa. Ni ọna kan naa ni orin awọn orilẹ-ède miiran ṣe tọka si ohun nla ti o ṣẹlẹ ni ilẹ Egipti ni bi ẹẹdẹgbẹjọọdún ṣaaju ibi Kristi. Ohun ti o ṣelẹ yii ni ijadelọ Israẹli kuro ni ilẹ Egipti eyi ti a pilẹ rẹ nipa ase kan ti a n pe ni Ase Irekọja. Bi awọn Ọmọ Israẹli ti n jẹ ase irekọja ninu ile wọn gẹgẹ bi aṣẹỌlọrun, awọn ara Egipti bẹrẹ si ri ọwọ ibinu Ọlọrun ni ibugbe wọn. Angẹli apanirun la ilẹ naa kọja o si wọ olukuluku ile nibi ti a kò gbé ri ẸjẹỌdọ-agutan irekọja ni ẹnu ilẹkun ati atẹrigba ile wọn. Ọlọrun wi pe, “Nigbati emi ba ri è̩jẹ naa, emi o ré nyin kọja” (Ẹksodu 12:13). Ase ti a dá silẹ ni ọjọ naa yoo jẹ eyi ti awọn Ọmọ Israẹli yoo maa pamọ ni ọdọọdun lẹyin ti wọn ba ti de Ilẹ Ileri. A si n pe e ni Ase Irekọja nitori ileri Ọlọrun yii. Lọna bayii wọn ni lati maa ranti bi Ọlọrun ṣe dá wọn ni idè ni ilẹ Egipti.

Pupọ ninu eto ati ilana isin gẹgẹ bi Ofin Mose ni awọn Ju ode oni ti gbagbe, ṣugbọn wọn ranti, wọn si n ṣe Ajọ Irekọja. Gbogbo ile awọn Ju ti o yè ni ẹkọ ni a ti n jẹ ase yii ni alẹọjọ naa; a n ka awọn àṣàyan ỌrọỌlọrun si eti igbọ awọn eniyan bakan naa ni awọn olujẹ ase yii maa n kọ ibomiran ninu ỌrọỌlọrun lorin gẹgẹ bi wọn ti n jẹ oriṣi ounjẹkọọkan ti i ṣe apẹẹrẹ Ase Irekọja ti akọkọ. O jẹ ase ti o ṣọwọn fun gbogbo awọn Ju. A ti tun ṣẹ wọn niṣẹ ni ọdun diẹ sẹyin wọn si n wọna fun idande.

Hẹsekiah mú Ajọ Irekọja Pada Bọ Sipò

Gẹgẹ bi ọba Juda, Hẹsekiah ni ẹtọ lati pe awọn ẹmẹwa rẹ jọ fun ohunkohun ti o ba ro pe o dara fun ijọba ilẹ Juda. S̩ugbọn o ni ẹtọ miiran ti o lè lò lori gbogbo ilẹ Israẹli -- awọn ẹya mẹwaa ti o wà labẹỌba Hoṣea gẹgẹ bi awọn wọnni ti a n pè ni Juda. Gẹgẹ bi ọba orilẹ-ède, o ni ẹtọ lati pe gbogbo awọn ayanfẹỌlọrun si isin Ọlọrun, a kò si le ṣe e ni ibomiran bi kòṣe Jerusalẹmu.

Bi o ba ṣe pe Hẹsekiah kò rán awọn oniṣẹ jakejado ilẹ Israẹli lati pe gbogbo orilẹ-ède naa, lati pa Ajọ Irekọja mọ, oun i ba jẹbi nitori ai ṣe ojuṣe rè̩. Jeroboamu ti i ṣe ọba Israẹli kin-in-ni lẹyin ti ijọba naa ti pin si meji gbé isin ibọriṣa kalẹ dipo isin tootọ nitori ki awọn ẹya mẹwaa wọnni ma baa lọ si Jerusalẹmu, ki wọn ma baa le dara pọ mọ Juda ninu isin ati ninu eto oṣelu. Fun adọtalerugba ọdun awọn ẹya mẹwaa wọnyii kò lọ si Jerusalẹmu lati sin Ọlọrun, ṣugbọn wọn tẹle ẹsin ati iwa buburu ti ibọriṣa.

Ni ijọba iha guusu, awọn pẹlu kò sin Ọlọrun deedee ni igba pupọ lati igba ti ijọba ti pinya, “nigbati Rehoboamu ti fi idi ijọba rè̩ mulẹ ti o si ti mu ara rè̩ le, o kọ ofin Oluwa silẹ, ati gbogbo Israẹli pẹlu rè̩” (2 Kronika 12:1). Nisisiyii, ti a tun fẹ pada si isin otitọ, o tọ pe ki ọba ti n mu isin yii bọ sipò ki o pe gbogbo Israẹli jọ ki awọn paapaa le wá gba ibukun Ọlọrun ti yoo fara hàn nibẹ.

Ko ṣeeṣe lati pa Ajọ Irekọja mọ ni akoko rè̩ nitori a kò i ti tun Tẹmpili ṣe ki o to di akoko Ajọ Irekọja. S̩ugbọn Hẹsekiah kò fẹ ki ọdun kan tun kọja lai pa ajọ ologo yii mọ. Ninu Ofin Mose, Hesekiah ri i pe aafo kan ṣoṣo ni o ṣi silẹ ti o le mu ki a jẹ Ase Irekọja ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kin-in-ni. A fi aafo yii silẹ pe o ṣeeṣe ki a ri awọn eniyan ti kò wa ni mimọ gẹgẹ bi ilana ni akoko Ajọ Irekọja. Hẹsekiah mu aafo ti Ọlọrun ṣi silẹ lori ọràn yii lò, o si kede pe ki a pa Ajọ Irekọja mọ ni oṣu keji dipo oṣu kin-in-ni.

Imọran Hẹsekiah dara. O kọwe si Israẹli bayii pe: “Njẹ ki ẹnyin ki o máṣe ọlọrún lile, bi awọn baba nyin, ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun OLUWA, ki ẹ si wọ inu ibi-mimọ rè̩ lọ, ti on ti yà si mimọ titi lai: ki ẹ si sin OLUWA, Ọlọrun nyin, ki imuna ibinu rè̩ ki o le yipada kuro li ọdọ nyin.” Ọwọ ibinu Ọlọrun ti wà lori awọn ẹyà mẹwaa Israẹli ná, oṣu diẹ lẹyin eyi ni a kó wọn lẹru ti a si tú wọn ká patapata. A kò kóJuda lọ si igbekun titi di aadọjọọdun lẹyin naa, eyi ri bẹẹ nitori iwa-bi-Ọlọrun ti a ri ninu diẹ ninu awọn ọba Juda ati awọn isọji ti o bé̩ silẹ ni ijọba yii. Awọn ti o bẹru Ọlọrun ni Oun yoo daabo bò. Awọn ti o bu ọla fun Ọlọrun ni Oun yoo pese fún. Anfaani yii ṣi silẹ lọjọ oni gẹgẹ bi o ti ṣi silẹ nigbaanì, o wà fún wa gẹgẹ bi o ti wà fun awọn Ọmọ Israẹli.

Pipa Isin Ibọriṣa Run

S̩ugbọn ki i ṣe gbogbo Israẹli ni o jẹ ipe Hẹsekiah lati wa si Jerusalẹmu. “Nwọn fi wọn rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wọn. Sibẹ omiran ninu awọn eniyan Aṣeri ati Manasse ati Sebuluni rè̩ ara wọn silẹ, wọn si wá si Jerusalẹmu.” “Ọpọlọpọ enia si pejọ ni Jerusalẹmu … ijọ enia nlanla.”

Awọn eniyan wọnyii ti ọkàn wọn ti n poungbẹ lati ọjọ pipẹ fun anfaani lati dara pọ pẹlu awọn wọnni ti o ni irú igbagbọ kan naa ati isin Ọlọrun otitọ, ti kò ni ifẹ si agbelẹrọ isin ti awọn ọba wọn gbekalẹ. Gẹrẹ ti a fi idi isin otitọ mulẹ wọn kò fi akoko ṣòfò lori nnkan miiran bi kòṣe lati kọju si isin Ọlọrun alaayè. Wọn wó awọn pẹpẹ oriṣa ti o wà ni Jerusalẹmu lulẹ, wọn si da a sibi idalẹnu ti o wa ni odo Kidroni. Ni opin ase yii, bi wọn si ti n pada si ile wọn, wọn “jade lọ si ilu Juda wọnni, wọn si fọ awọn ere ttu, wọn si bé̩ igbo òriṣa lulẹ, wọn si bi ibi giga wọnni ati awọn pẹpẹṣubu, ninu gbogbo Juda ati Bẹnjamini, ni Efraimu pẹlu ati Manasse, titi wọn fi pa gbogbo wọn run patapata.”

Ninu ọkàn ọmọỌlọrun tootọ, kò si ifẹ fun ohunkohun bi kòṣe isin Ọlọrun tootọ. Kò ni si ẹmi igbọjẹgẹ nipa Ihinrere Jesu Kristi ninu ẹni naa. Oun yoo jé̩ onisuuru ẹni ti n fi ọwọ jẹjẹ mu awọn alailera, onifarada ati onisuuru si awọn ti n fẹ iranlọwọ ati itọni, sibẹ yoo fi ọwọ danindanin múẹkọỌrọỌlọrun. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ti o waasu Ihinrere fun oun paapaa tabi angẹli lati ọrun ni o tọọ wa lati sọ fun un pe Ihinrere kò lagbara mọ tabi o ti yi pada, oun ki yoo gbà wọn gbọ. Oun mọẹni ti oun gbà gbọ, o si da a loju pe Ọlọrun le pa ohun ti oun fi le E lọwọ mọ titi di ọjọ nì.

ỌmọỌlọrun tootọ mọ pe Ọlọrun ki i yi pada ati pe Ọrọ Rè̩ fi idi mulẹ lae ni Ọrun (Orin Dafidi 119:89). Nitori naa ọmọỌlọrun tootọ a maa fi igbẹkẹle rè̩ sinu Ọrọ ati ileri Ọlọrun a si maa duro ṣinṣin bi ogunlọgọ awọn ti o yi i ká tilẹ yi pada kuro ninu igbagbọ. Ireti lile ati ipinnu yii ni o n so Onigbagbọ ro laaarin gbogbo ipọnju, oun ni yoo si mu un de ile rẹọrun nikẹyin. O wú ni lori pupọ lati ri iru ijolootọ yii lode oni, ninu ọkàn ati igbesi-ayé awọn oloootọ diẹ ti Ọlọrun ti yàn! Ohun ti o yani lẹnu ni pe ni akoko ti o buru jù lọ ninu itàn igbesi-ayéẹya mẹwaa Israẹli, iru ẹmi bẹẹ wà ninu ọkàn ogunlọgọ ijọ eniyan ti o lọ si Jerusalẹmu lati sin Ọlọrun Ọrun!

Iyọrisi Imubọsipò Isin Tootọ

Ọlọrun bu ọla fun igbọran si Ọrọ Rè̩. Igbọran sàn ju ẹbọ tabi eto isin lọ (1 Samuẹli 15:22).

Ọkunrin afọju ti igba ayé Jesu kì bá ti ri iwosan gbà bi o ba kọ lati gbọran si ọrọ Oluwa lati wẹ amọ kuro ni oju rè̩. Naamani ara Siria kì ba ti ri iwẹnu kuro ninu è̩tè̩ rẹ bi kò ba ti ara rè̩ bọ odo Jọrdani nigba meje gẹgẹ bi eniyan Ọlọrun ti wi. InáỌlọrun kì ba ti bọ sori pẹpẹ idẹ nigba ti a dá isin Agọ silẹ bi Mose kò ba fi ara balẹ lati ṣe ohun gbogbo finnifinni gẹgẹ bi a ti fi hàn án ni ori oke. Igbọran ṣe pataki bi a ba fẹ ni ibukun Ọlọrun. Bi Ọlọrun ba paṣẹ, ti wa ni lati gbọran! O ṣanfaani lati gbọran lẹsẹkẹsẹ ti ifẹỌlọrun ba di mimọ fun wa dipo ki a maa gbéọrọ naa yè̩wò.

Gbogbo awọn ti o gbọran ni akoko Hẹsekiah ni o ri ibukun gbà. “Ayọ nla si wà ni Jerusalẹmu.” “Nigbana li awọn alufa, awọn ọmọ Lefi dide, nwọn si sure fun awọn enia na: a si gbọ ohùn wọn, adura wọn si gòke lọ si ibugbe mimọ rè̩, ani si ọrun.” Awọn eniyan naa gbọran si Ọlọrun nipa akọso ikore wọn. Wọn san idamẹwaa wọn. Wọn múọrẹ atinuwa wá. Nigba ti wọn si ṣe nnkan wọnyii, Oluwa bukun fun wọn lọpọlọpọ, O si mu wọn ṣe rere ni gbogbo ọna. Wọn fi ipin fun awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilana Ọlọrun, nipa bayii wọn le di iṣẹ ati isin Ọlọrun mú, eyi ti a gbe kalẹ fun anfaani awọn eniyan nipa ti ẹmi, ati nipa ti ara. Nipa bayii a le ri i pe orilẹ-ède yii gba ilọpo meji ibukun nitori pe wọn pa ofin Ọlọrun mọ.

Wo iru ọrọ iyanu ti a fi pari ibi ti a yàn fun ẹkọ wa! A kọọ pe Hẹsekiah “ṣe eyi ti o dara, ti o si tọ, ti o si ṣe otitọ, niwaju OLUWA Ọlọrun rè̩. Ati ninu gbogbo iṣẹ ti o bè̩rẹ ninu iṣẹ-isin ile Ọlọrun, ati ninu ofin, ati ni aṣẹ, lati wáỌlọrun, o fi gbogbo ọkàn rè̩ṣe e, o si ṣe rere.”

Eyi ni aṣiiri aṣeyọri lọnakọna ninu igbesi-ayé wa. Bi awa ba ṣe eyi ti o “dara, ti o tọ, ti o si ṣe otitọ,” niwaju Ọlọrun wa, bi a ba fi gbogbo ọkàn wa ṣe gbogbo iṣẹ ti a dawọle ninu iṣẹ-isin ile Ọlọrun, ati ninu ỌrọỌlọrun lati wáỌlọrun tọkan-tọkàn – bi a ba ṣe nnkan wọnyii, a o ni ibukun ti ẹmi, a o si ṣe rere. ỌrọỌlọrun ni eyi. Ileri Ọlọrun ni. Ẹni kan, tabiọọpọ eniyan, ha le ṣe ileri ki wọn si fun wa ni ohun ti o nilaari ju eyi lọ? Kò si ohun ti o tayọ ileri Ọlọrun, nitori kò si ohun ti o tobi ju ibukun Ọlọrun. ỌmọỌlọrun tootọ a maa wi bayii:

“Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? Kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ” (Orin Dafidi 73:25).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ajọ Ju pataki wo ni a kẹkọọ nipa rè̩? Igba meloo ni wọn ni lati pa ajọ yii mọ? Ki ni ohun nla ti o ṣẹlẹ ti wọn fi n ṣe iranti rè̩?

  2. 2 Ki ni ṣe ti a fi sún ọjọ Ajọ yii siwaju ni akoko yii gan an? Njẹ o tọ fun Hẹsekiah lati ṣe bẹẹ?

  3. 3 Ẹtọ wo ni Hẹsekiah ni gẹgẹ bi ọba Juda nikan, lati ranṣẹ si gbogbo awọn eniyan Israẹli?

  4. 4 Ọna wo ni Hẹsekiah fi rán iṣẹ naa?

  5. 5 Iha wo ni awọn eniyan kọ si ipè naa?

  6. 6 Ki ni ijọ eniyan ṣe si awọn ibi isin oriṣa?

  7. 7 Ki ni o ṣẹlẹ nigba ti awọn eniyan naa gbọran si aṣẹỌlọrun ti wọn si pa Ajọ Irekọja mọ?

  8. 8 Awọn aṣẹỌlọrun miiran wo ni wọn tun mu ṣe lẹyin Ajọ Irekọja?

  9. 9 Iru iha wo ni a ni lati kọ si awọn wọnni ti o ba fẹ mu wa kuro ninu Ihinrere otitọ?

  10. 10 Ki ni a sọ gbẹyin ninu ẹkọ wa nipa Hẹsekiah? Bawo ni o ṣe jé̩ apẹẹrẹ rere fún wa?